Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pípa Bábílónì Ńlá Run

Pípa Bábílónì Ńlá Run

Orí 35

Pípa Bábílónì Ńlá Run

1. Báwo ni áńgẹ́lì náà ṣe ṣàlàyé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yẹn, irú ọgbọ́n wo la sì nílò láti lóye àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ inú Ìṣípayá?

 ÁŃGẸ́LÌ náà tún ṣàlàyé síwájú sí i fún Jòhánù nípa ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí Ìṣípayá 17:3 sọ náà, ó ní: “Níhìn-ín ni ibi tí làákàyè tí ó ní ọgbọ́n ti wọlé: Orí méje náà túmọ̀ sí òkè ńlá méje, níbi tí obìnrin náà jókòó lé. Ọba méje ni ó sì ń bẹ: márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà, ọ̀kan tí ó kù kò tí ì dé, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.” (Ìṣípayá 17:9, 10) Ọgbọ́n tó wá látòkè ni áńgẹ́lì yìí ń sọ, ìyẹn ọgbọ́n kan ṣoṣo tó lè mú wa lóye àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ inú ìwé Ìṣípayá. (Jákọ́bù 3:17) Ọgbọ́n yìí ló ń mú kí ẹgbẹ́ Jòhánù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lóye bí àkókò tá à ń gbé yìí ti ṣe pàtàkì tó. Ó ń jẹ́ káwọn tó ń fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà mọrírì àwọn ìdájọ́ Jèhófà tó máa wáyé láìpẹ́, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tó yẹ. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 9:10 ṣe wí: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” Kí ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣí payá fún wa nípa ẹranko ẹhànnà yìí?

2. Kí ni ìtumọ̀ orí méje ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, báwo ló sì ṣe jẹ́ pé “márùn-ún ti ṣubú, [tí] ọ̀kan [sì] wà”?

2 Orí méje ẹranko tó rorò yẹn túmọ̀ sí “òkè ńlá” méje, tàbí “ọba” méje. Ìwé Mímọ́ lo èdè méjèèjì náà láti tọ́ka sí agbára ìṣàkóso. (Jeremáyà 51:24, 25; Dáníẹ́lì 2:34, 35, 44, 45) Bíbélì mẹ́nu kan agbára ayé mẹ́fà tí wọ́n ti ní ipa kan tàbí òmíràn lórí ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn agbára ayé náà ni: Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, àti Róòmù. Lákòókò tí Jòhánù rí ìran Ìṣípayá yìí, márùn-ún lára àwọn agbára ayé náà ò sí mọ́, Róòmù ló wà nípò gẹ́gẹ́ bí agbára ayé nígbà náà. Èyí bá gbólóhùn náà mu pé, “márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà.” Ṣùgbọ́n èwo ni “ọ̀kan tí ó kù” tí ò tíì dé?

3. (a) Báwo ni Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe pín sí méjì? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé ní apá ti Ìwọ̀ Oòrùn? (d) Kí ló yẹ kó jẹ́ èrò wa nípa àgbègbè tí wọ́n ń pè ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́?

3 Ilẹ̀ Ọba Róòmù wà fúngbà pípẹ́, kódà ó tiẹ̀ tún gbòòrò sí i fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Jòhánù pàápàá. Lọ́dún 330 Sànmánì Kristẹni, Olú Ọba Kọnsitatáìnì sọ ìlú Bìsáńṣíọ̀mù di olú ìlú rẹ̀ dípò ìlú Róòmù, ó sì yí orúkọ ìlú yìí padà sí Kọnsitantinópù. Nígbà tó di ọdún 395 Sànmánì Kristẹni ilẹ̀ ọba Róòmù pín sí méjì, ó di Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìwọ̀ Oòrùn. Ọba kan tó ń jẹ́ Alaric ṣẹ́gun ìlú Róòmù lọ́dún 410 Sànmánì Kristẹni. Alaric yìí jẹ́ ọba àwọn Visigoth tí í ṣe ẹ̀yà kan nílẹ̀ Jámánì tí wọ́n di ara ẹ̀ya ìsìn Kristẹni kan tí Arius dá sílẹ̀. Àwọn ẹ̀yà kan nílẹ̀ Jámánì táwọn náà jẹ́ “Kristẹni” ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Sípéènì àti ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbègbè tí Róòmù ń ṣàkóso ní Àríwá Áfíríkà. Àwọn ọ̀rúndún kan wà tí nǹkan ò fara rọ nílẹ̀ Yúróòpù, tó jẹ́ pé rògbòdìyàn òun wàhálà ṣíṣe onírúurú àtúntò ni ṣáá. Àwọn olú ọba alágbára bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìwọ̀ Oòrùn, irú bíi Charlemagne tó bá Póòpù Leo Kẹta wọnú àdéhùn ní ọ̀rúndún kẹsàn-án àti Frederick Kejì tó ṣàkóso ní ọ̀rúndún kẹtàlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ni wọ́n ń pe àgbègbè tí wọ́n ṣàkóso lé lórí, síbẹ̀ ó kéré jọjọ bá a bá fi wé ibi tí ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti tẹ́lẹ̀ dé nígbà tó gbòòrò jù lọ. Àgbègbè tí wọn ṣàkóso lé lórí tí wọn pè ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ kì í ṣe ilẹ̀ ọba tuntun, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n kàn ṣàtúnṣe sí ilẹ̀ ọba ti tẹ́lẹ̀ tàbí bíi pé ilẹ̀ ọba ti tẹ́lẹ̀ náà ló ṣì wà.

4. Àwọn àṣeyọrí wo ni apá kan Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn ṣe, ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ sí púpọ̀ lára àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ìgbàanì ní Àríwá Áfíríkà, Sípéènì, àti Síríà?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàhálà ń wáyé láàárín Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn tí ibùjókòó ìjọba rẹ̀ wà ní Kọnsitantinópù àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìwọ Oòrùn, apá ti Ìlà Oòrùn ń bá ìṣàkóso rẹ̀ lọ. Ní ọ̀rúndún kẹfà, olú ọba ti Ìlà Oòrùn tó ń jẹ́ Justinian Kìíní ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ àgbègbè ní Àríwá Áfíríkà, ó sì tún dá sí ọ̀ràn orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Ítálì. Ní ọ̀rúndún keje, Justinian Kejì gba gbogbo ilẹ̀ tó wà ní Makedóníà padà èyí táwọn ẹ̀yà Slav tó ṣẹ́gun wọn tẹ́lẹ̀ gbà. Ṣùgbọ́n, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹjọ, púpọ̀ lára ibi tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ìgbàanì ní Àríwá Áfíríkà, Sípéènì, àti Síríà ti kúrò lábẹ́ Kọnsitantinópù àti Róòmù, ó sì ti di tàwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàkóso.

5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́gun ìlú Róòmù lọ́dún 410 Sànmánì Kristẹni, báwo ló ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sí i kọjá kó tó di pé ọwọ́ àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù kúrò láwùjọ pátápátá?

5 Ìlú Kọnsitantinópù ní tirẹ̀ wà bó ṣe wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Lemọ́lemọ́ làwọn ará Páṣíà, Arébíà, Bulgaria, àti Rọ́ṣíà bá ìlú náà jà tí wọn ò borí ẹ̀ kí wọ́n tó wá ṣẹ́gun rẹ̀ lọ́dún 1203. Àmọ́ kì í ṣe àwọn Mùsùlùmí ló ṣẹ́gun rẹ̀, àwọn Ajagun ẹ̀sìn Kristẹni tó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn nítorí àtigba Ilẹ̀ Mímọ́ padà ló ṣẹ́gun rẹ̀. Nígbà tó wá di ọdún 1453, Mehmed Kejì tó jẹ́ Mùsùlùmí tó ń ṣojú àwọn Ottoman ṣẹ́gun ìlú Kọnsitantinópù, kò sì pẹ́ tí ìlú náà fi di olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ottoman, tàbí Turkey. Nípa báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́gun ìlú Róòmù lọ́dún 410 Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sí i ló kọjá kó tó di pé ọwọ́ àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù kúrò láwùjọ pátápátá. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń kan ipa rẹ̀ lágbo ìsìn nípasẹ̀ àwọn póòpù tó ń ṣàkóso ní Róòmù àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn Ayé.

6. Àwọn orílẹ̀-èdè wo tó fẹ́ máa ṣàkóso gbogbo ayé ló bọ́ sójútáyé, èwo ló sì kẹ́sẹ járí jù lọ nínú wọn?

6 Ṣùgbọ́n, nígbà tó di ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún, àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà àtidá àwọn ilẹ̀ ọba tuntun sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara àwọn ibi tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ń ṣàkóso nígbà kan rí ni díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń gbèrò àtidi ilẹ̀ ọba wọ̀nyí, ìṣàkóso wọn yàtọ̀ sí ti Róòmù pátápátá. Ilẹ̀ Potogí, Sípéènì, Faransé àti Holland wá ń gbókèèrè ṣàkóso àwọn ilẹ̀ mìíràn. Ṣùgbọ́n Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló kẹ́sẹ járí jù lọ nítorí pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń ṣàkóso lé lórí tó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ ọba gbígbòòrò kan tó jẹ́ pé bí oòrùn bá ṣe ń wọ̀ ní apá kan ilẹ̀ ọba rẹ̀ ni yóò máa yọ ní ibòmíràn. Díẹ̀díẹ̀ ni àkóso ilẹ̀ ọba yìí ń tàn títí tó fi dé ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti Àríwá, Áfíríkà, Íńdíà, àti Ìlà Oòrùn Éṣíà tó fi mọ́ àwọn Gúúsù Pàsífíìkì tó lọ salalu.

7. Báwo ló ṣe di pé orílẹ̀-èdè méjì para pọ̀ di agbára ayé, báwo sì ni Jòhánù ṣe sọ pé ‘orí’ keje, tàbí agbára ayé keje, ṣe máa pẹ́ tó?

7 Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, díẹ̀ lára àwọn ibi tí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń gbókèèrè ṣàkóso lé lórí ní Amẹ́ríkà ti Àríwá ti kúrò lábẹ́ Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì para pọ̀ di Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ rògbòdìyàn òṣèlú ṣì ń bá a lọ láàárín orílẹ̀-èdè tuntun náà àti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n Ogun Àgbáyé Kìíní jẹ́ kí orílẹ̀-èdè méjèèjì rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n jọ fìmọ̀ ṣọ̀kan, ni wọ́n bá jọ wọnú àjọṣe tó jinlẹ̀. Bí orílẹ̀-èdè méjèèjì, ìyẹn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ báyìí àti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso ibi tó pọ̀ jù lọ ṣe para pọ̀ di agbára ayé nìyẹn, tí wọ́n jọ ń ṣàkóso gbogbo ayé. Ìṣàkóso tá à ń sọ yìí ni ‘orí’ keje, tàbí agbára ayé keje, èyí tó ṣì wà lójú ọpọ́n ní àkókò òpin yìí, tó sì ń ṣàkóso àgbègbè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní kọ́kọ́ fìdí múlẹ̀ sí. Bá a bá fi ìwọ̀n àkókò tí orí keje fi ṣàkóso wé èyí tí orí kẹfà fi ṣàkóso, “ìgbà kúkúrú” ni orí keje fi máa wà títí dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run fi máa pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó kù run.

Ọba Kẹjọ Kẹ̀?

8, 9. Kí ni áńgẹ́lì náà pe ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò, ọ̀nà wo ló sì gbà jáde wá látinú àwọn méje náà?

8 Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé síwájú sí i fún Jòhánù pé: “Ẹranko ẹhànnà tí ó sì ti wà tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò sí, òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ, ṣùgbọ́n ó jáde wá láti inú àwọn méje náà, ó sì kọjá lọ sínú ìparun.” (Ìṣípayá 17:11) Ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò jẹ́ ère “ẹranko ẹhànnà” ìṣáájú tó gòkè wá “láti inú òkun.” Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí “jáde wá láti inú” àwọn orí méje “ẹranko ẹhànnà” ìṣáájú náà, ìyẹn ni pé àwọn orí méje náà ló bí i, tàbí lédè mìíràn, àwọn ló jẹ́ kó wà. Ọ̀nà wo ló fi jáde wá látinú àwọn orí méje náà? Bó ṣe rí rèé: Lọ́dún 1919, Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni agbára ayé tó ń ṣàkóso láàárín orí méje náà. Orí mẹ́fà tó ṣáájú ti subú, ipò agbára ayé sì ti bọ́ sọ́wọ́ orí méjì tó para pọ̀ yìí, òun ló sì ń ṣàkóso gbogbo ayé. Orí keje yìí, tó jẹ́ agbára ayé tó wà lójú ọpọ́n láàárín àwọn agbára ayé mẹ́fà tó ti wà tẹ́lẹ̀, ló fi Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ́lẹ̀, òun kan náà ló sì ń ṣe agbátẹrù Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó sì ń pèsè owó ìná fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ìyẹn ọba kẹjọ tí í ṣe Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti lẹ́yìn náà, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, “jáde wá láti inú” orí méje àkọ́kọ́. Bá a bá wò ó lọ́nà yìí, gbólóhùn náà pé ó jáde wá látinú orí méje wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá ìṣáájú tó sọ pé ẹranko ẹhànnà náà tó ní ìwo méjì bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn (ìyẹn agbára ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, tí í ṣe orí keje ẹranko ẹhànnà ìṣáájú yẹn) ń ṣìpẹ̀ pé kí wọ́n ṣe ère náà, tó sì fún un ní ìyè.—Ìṣípayá 13:1, 11, 14, 15.

9 Láfikún, yàtọ̀ sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn orílẹ̀-èdè míì tó para pọ̀ dá àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ jẹ́ àwọn ìjọba tó ti ṣàkóso ní àwọn àgbègbè tí àwọn orí tàbí agbára ayé ti ìṣáájú wà tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn àwọn bíi Gíríìsì, orílẹ̀-èdè Iran (ìyẹn Páṣíà ayé ọjọ́un), àti Ítálì (ìyẹn agbára ayé Róòmù ayé ọjọ́un). Nígbà tó yá, àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba tó ń ṣàkóso àgbègbè tó wà lábẹ́ àwọn agbára ayé mẹ́fà ìṣáájú wá ń ṣètìlẹyìn fún ère ẹranko ẹhànnà náà. Lọ́nà yìí pẹ̀lú, a lè sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde wá látinú àwọn agbára ayé méje náà.

10. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò “fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ”? (b) Báwo ni ọ̀kan lára àwọn aṣáájú Ìjọba Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí ṣe ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn?

10 Kíyè sí i pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí kan náà tún “ni ọba kẹjọ.” Nípa báyìí, ṣe ní wọ́n gbé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kalẹ̀ bí ìjọba tó ń ṣàkóso gbogbo ayé. Kódà nígbà mìíràn, ó máa ń ṣe bí ọba gbogbo ayé nípa bó ṣe máa ń rán àwọn ọmọ ogun lọ sójú ogun láti lọ pẹ̀tù sí ìjà àárín àwọn orílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ní Kòríà, ní àgbègbè Sínáì tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí ká, láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, àti ní Lẹ́bánónì. Ṣùgbọ́n ère ọba kan ló wulẹ̀ jẹ́. Bíi ti ère ìsìn, kò lè dá nǹkan gidi kan ṣe kò sì dá agbára kan ní yàtọ̀ sí èyí táwọn tó gbé e kalẹ̀ tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ bá fún un pé kó lò. Láwọn ìgbà míì, ó máa ń dà bíi pé ó rẹ ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ yìí; ṣùgbọ́n kò tíì sígbà kan táwọn orílẹ̀-èdè aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tó wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pátápátá rí bí wọ́n ṣe kọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ tó fi lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Ìṣípayá 17:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn aṣáájú Ìjọba Soviet Union nígbà kan rí kò fara mọ́ èrò àwọn mìíràn lórí àwọn nǹkan kan, síbẹ̀ ní ọdún 1987, òun náà dara pọ̀ mọ́ àwọn póòpù Róòmù láti ṣètìlẹyìn fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Kódà ó ní “káwọn ṣètò ààbò tó máa délé dóko ní gbogbo ayé” káwọn sì fi sí ìkáwọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Bí Jòhánù ṣe mọ̀ nígbà tó yá, ìgbà kan ń bọ̀ tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè á lo àṣẹ ńlá. Lẹ́yìn náà, òun fúnra ẹ̀ á “lọ sínú ìparun.”

Ọba Mẹ́wàá fún Wákàtí Kan

11. Kí ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ nípa ìwo mẹ́wàá ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò?

11Ìṣípayá orí kẹrìndínlógún, áńgẹ́lì kẹfà àti ìkeje da àwọn àwokòtò ìbínú Ọlọ́run jáde. Èyí fi yé wa pé àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń kóra jọ sí ogun Ọlọ́run ní Amágẹ́dọ́nì àti pé ‘a óò rántí Bábílónì Ńlá níwájú Ọlọ́run.’ (Ìṣípayá 16:1, 14, 19) Ní báyìí, á fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ lé wọn lórí. Tún gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Jòhánù. “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí túmọ̀ sí ọba mẹ́wàá, tí kò tíì gba ìjọba, ṣùgbọ́n wọ́n gba ọlá àṣẹ bí ọba fún wákàtí kan pẹ̀lú ẹranko ẹhànnà náà. Àwọn wọ̀nyí ní ìrònú kan ṣoṣo, nítorí náà, wọ́n fún ẹranko ẹhànnà náà ní agbára àti ọlá àṣẹ wọn. Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”—Ìṣípayá 17:12-14.

12. (a) Kí ni ìwo mẹ́wàá náà túmọ̀ sí? (b) Ọ̀nà wo ni ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ náà ò fi ‘tíì gba ìjọba’ ní ọ̀rúndún kìíní? (d) Báwo ni ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe ní “ìjọba” kan nísinsìnyí, báwo ló sì ṣe máa pẹ́ tó?

12 Ìwo mẹ́wàá náà dúró fún gbogbo àwọn ìjọba tí wọ́n ń ṣàkóso báyìí lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì ń ṣètìlẹ́yìn fún ère ẹranko ẹhànnà náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lónìí ni ò sí nígbà ayé Jòhánù. Àwọn tó sì wà nígbà náà, irú bí Íjíbítì àti Páṣíà (tá a mọ̀ báyìí sí Iran), ní ètò ìjọba tó yàtọ̀ pátápátá lónìí. Fún ìdí yìí, ní ọ̀rúndún kìíní, ‘ìwo mẹ́wàá náà ò tíì gba ìjọba.’ Ṣùgbọ́n ní báyìí tá a ti wà ní ọjọ́ Olúwa, wọ́n ní “ìjọba” kan, tàbí agbára ìṣàkóso. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tuntun ló ti yọjú látàrí báwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá tí wọ́n jẹ́ agbókèèrè-ṣàkóso ṣe fọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n ti wà tipẹ́, ló máa bá ẹranko ẹhànnà náà ṣàkóso fún àkókò kúkúrú, ìyẹn “wákàtí kan” péré, kí Jèhófà tó mú òpin bá gbogbo ètò ìjọba ayé ní Amágẹ́dọ́nì.

13. Ọ̀nà wo ni ìwo mẹ́wàá náà gbà ní “ìrònú kan ṣoṣo,” kí sì ni èrò tí wọ́n ní yìí mú kó dájú pé wọ́n á ṣe sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?

13 Lónìí, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó lágbára jù lọ tó ń ti àwọn ìwo mẹ́wàá náà. Wọ́n ní “ìrònú kan ṣoṣo” ní ti pé dípò kí wọ́n tẹ́wọ́ gba Ìjọba Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n ń wá ọ̀nà bí àkóso tó wà níkàáwọ́ wọn ò ṣe ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Èyí ló mú kí wọ́n fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí àlàáfíà lè wà kárí ayé, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn fúnra wọn á lè máa wà nìṣó. Irú èrò táwọn ìwo náà ní yìí ló jẹ́ kó dájú pé wọ́n á ta ko Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí í ṣe “Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,” nítorí pé Jèhófà ti ṣètò bó ṣe máa mú kí Ìjọba rẹ̀ lábẹ́ Jésù Kristi rọ́pò gbogbo ìjọba wọ̀nyí láìpẹ́.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 24:30; 25:31-33, 46.

14. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fáwọn tó ń ṣàkóso ayé láti bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, kí ló sì máa yọrí sí?

14 Ó dájú pé kò sí nǹkan kan táwọn tó ń ṣàkóso ayé yìí lè fi Jésù ṣe. Wọ́n ò lè débi tó wà ní ọ̀run lọ́hùn-ún. Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin Jésù, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sì hàn gbangba pé, ọwọ́ rẹ̀ lè tó wọn. (Ìṣípayá 12:17) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwo náà ti ta kò wọ́n lọ́nà tó burú jáì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun. (Mátíù 25:40, 45) Bó ti wù kó rí, kò ní pẹ́ tí àkókò fi máa tó fún Ìjọba Ọlọ́run láti “fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, [tí yóò] sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn ọba ilẹ̀ ayé á wá bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wọ̀yá ìjà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láìpẹ́. (Ìṣípayá 19:11-21) Níbi tá a dé yìí, a ti kọ́ ohun tó pọ̀ tó láti mọ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè ò ní kẹ́sẹ járí. Àwọn àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ì bà á ní “ìrònú kan ṣoṣo” jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọn ò lè ṣẹ́gun “Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,” bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò lè ṣẹ́gun “àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀,” tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé wà lára wọn. Àwọn náà á ti di aṣẹ́gun ní ti pé wọ́n á ti pa ìṣòtítọ́ wọn mọ́ láti fi hàn pé irọ́ làwọn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Róòmù 8:37-39; Ìṣípayá 12:10, 11.

Bí Aṣẹ́wó Náà Ṣe Máa Pa Run

15. Kí ni áńgẹ́lì yẹn sọ nípa aṣẹ́wó náà, irú ẹ̀mí wo ló sọ pé ìwo mẹ́wàá àti ẹranko ẹhànnà náà máa ní sí i, kí ló sì sọ pé wọn máa ṣe fún un?

15 Àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan kọ́ ni ìwo mẹ́wàá náà máa bá ṣọ̀tá. Áńgẹ́lì náà wá dá Jòhánù padà sórí ọ̀rọ̀ aṣẹ́wó náà, ó ní: “Ó sì wí fún mi pé: ‘Àwọn omi tí ìwọ rí, níbi tí aṣẹ́wó náà jókòó, túmọ̀ sí àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n. Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.’”—Ìṣípayá 17:15, 16.

16. Kí nìdí tí Bábílónì Ńlá ò fi ní lè gbójú lé àwọn omi rẹ̀ láti ṣètìlẹyìn fún un kí wọ́n sì dáàbò bò ó nígbà táwọn ìjọba ayé bá yíjú padà sí i lọ́nà rírorò?

16 Gẹ́lẹ́ bí Bábílónì ìgbàanì ṣe gbójú lé omi tó yí i ká gẹ́gẹ́ bí ààbò, bẹ́ẹ̀ náà ni Bábílónì Ńlá ṣe gbójú lé ọ̀kẹ́ àìmọye “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n” tí wọ́n wà nínú rẹ̀. Ó dáa tí áńgẹ́lì yìí kọ́kọ́ rán wá létí èyí, kó tó wá sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń múni gbọ̀n rìrì yìí, pé: Àwọn ìjọba òṣèlú ayé yìí á yíjú padà sí Bábílónì Ńlá lọ́nà rírorò. Kí ni gbogbo “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n” wọ̀nyẹn á wá rí ṣe sí i? Lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń kìlọ̀ fún Bábílónì Ńlá pé omi odò Yúfírétì máa gbẹ. (Ìṣípayá 16:12) Omi wọ̀nyẹn ò ní sí mọ́ rárá. Wọn ò ní lè fún ohun ìríra àtayébáyé yẹn, ìyẹn aṣẹ́wó náà ní ìtìlẹyìn tó mọ́yán lórí ní wákàtí tó nílò ìrànlọ́wọ́ wọn.—Aísáyà 44:27; Jeremáyà 50:38; 51:36, 37.

17. (a) Kí nìdí tí ọlà Bábílónì Ńlá ò fi ní gbà á là? (b) Ọ̀nà wo ni òpin tó máa bá Bábílónì Ńlá fi máa jẹ́ ẹ̀tẹ́? (d) Yàtọ̀ sí ìwo mẹ́wàá náà, tàbí àwọn orílẹ̀-èdè, ohun mìíràn wo ló tún máa lọ́wọ́ sí ìparun Bábílónì Ńlá?

17 Ó dájú pé arabarìbì ọlà tí Bábílónì Ńlá ní ò ní lè gbà á là. Àfi tó bá tún máa mú kí ìparun ọ̀hún túbọ̀ yá torí ìran náà jẹ́ ká rí i pé nígbà tí wọ́n bá gbéjà kò ó lọ́nà rírorò nítorí kíkó tí wọ́n kórìíra rẹ̀, ṣe ni wọ́n á gba aṣọ ìgúnwà ayaba àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye tó wà lára ẹ̀. Wọn á kó ọlà rẹ̀ lọ. Wọ́n á ‘tú u sí . . . ìhòòhò,’ ní ti pé wọ́n á fi irú ẹni tó jẹ́ gan-an hàn. Ìparun yán-ányán-án yìí á mà ga o! Ẹ̀tẹ́ gbáà ni òpin rẹ̀ máa jẹ́. Wọ́n á ba tiẹ̀ jẹ́, wọ́n á “jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán,” wọ́n á sì sọ ọ́ di kìkì egungun aláìlẹ́mìí. Ní paríparí rẹ̀, wọ́n á “fi iná sun ún pátápátá.” Wọn ò ní sin ín nísin ẹ̀yẹ, ńṣe ni wọ́n á finá sun ún bí ìgbà téèyàn bá finá sun ẹran tó ní àjàkálẹ̀ àrùn lára kí àrùn náà má bàa ran èèyàn. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwo mẹ́wàá náà dúró fún nìkan kọ́ ló máa pa aṣẹ́wó ńlá náà run, ṣùgbọ́n “ẹranko ẹhànnà náà,” ìyẹn àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, pẹ̀lú máa dara pọ̀ mọ́ wọn láti pa á run. Ó máa fọwọ́ sí ìparun ìsìn èké. Kódà ṣáájú ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ lára igba ó dín mẹ́wàá [190] orílẹ̀-èdè àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fi hàn nínú ìbò tí wọ́n dì pé àwọn kórìíra ìsìn, pàápàá ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.

18. (a) Kí ló ti jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwọn orílẹ̀-èdè gbéjà ko Bábílónì Ńlá? (b) Kí ló mú kí aṣẹ́wó ńlá náà kàgbákò tó burú bẹ́ẹ̀?

18 Kí ló jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè ṣe ohun tó burú bẹ́ẹ̀ sẹ́ni tó jẹ́ àlè wọn nígbà kan rí? Ohun tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ti fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí Bábílónì Ńlá. Àtakò tí ìjọba ń ṣe sí ìsìn tí mú kí agbára tí ìsìn ní làwọn ilẹ̀ bí orílẹ̀-èdè Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí àti Ṣáínà dín kù gan-an. Láwọn ibi tí ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí kì í ṣe ara Kátólíìkì, pọ̀ sí ní Yúróòpù, ẹ̀mí àgunlá tó tàn kálẹ̀ àti iyè méjì táwọn èèyàn ní sí ìsìn ti sọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì dòfo, tó bẹ́ẹ̀ tí ìsìn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa rẹ́. Ọ̀tẹ̀ àti àìfohùnṣọ̀kan ti fọ́ ìsìn Kátólíìkì tó gbilẹ̀ rẹrẹẹrẹ, apá àwọn aṣáájú ìjọ náà ò sì ká a. Òtítọ́ kan la ò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá, ìyẹn ni pé àgbákò ìkẹyìn tó máa bá Bábílónì Ńlá yìí ò ṣẹ̀yìn ìdájọ́ tí kò ṣeé yí padà tí Ọlọ́run mú wá sórí aṣẹ́wó ńlá náà.

Bí Ìrònú Ọlọ́run Ṣe Máa Ṣẹ

19. (a) Báwo la ṣe lè fi ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni ṣàlàyé irú ìdájọ́ tó máa ṣe fún aṣẹ́wó náà? (b) Kí ni Jerúsálẹ́mù tó dahoro, tí kò sí olùgbé kankan nínú rẹ̀ lẹ́yìn ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni ṣàpẹẹrẹ lákòókò tiwa yìí?

19 Báwo ni Jèhófà ṣe mú ìdájọ́ yìí ṣẹ? Ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì tó di apẹ̀yìndà lè jẹ́ ká lóye bó ṣe máa ṣe ti ọ̀tẹ̀ yìí, àwọn tó sọ nípa wọn pé: “Mo . . . ti rí àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ nínú àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù, ṣíṣe panṣágà àti rírìn nínú èké; wọ́n sì ti fún ọwọ́ àwọn aṣebi lókun kí olúkúlùkù wọn má bàa padà nínú ìwà búburú rẹ̀. Sí mi, gbogbo wọn dà bí Sódómù, àti àwọn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà.” (Jeremáyà 23:14) Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, Jèhófà lo Nebukadinésárì láti ‘bọ́ ẹ̀wù kúrò lọ́rùn’ ìlú panṣágà nípa tẹ̀mí yẹn ‘láti kó àwọn ohun èlò ẹlẹ́wà rẹ̀ lọ, àti láti fi í sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ní ìhòòhò goloto.’ (Ìsíkíẹ́lì 23:4, 26, 29) Jerúsálẹ́mù ìgbà yẹn bá ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì òde òní mu, gẹ́gẹ́ bí ìran tí Jòhánù sì kọ́kọ́ rí, Jèhófà yóò fi irú ìyà kan náà jẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ìsìn èké yòókù. Bí Jerúsálẹ́mù ṣe dahoro tí ò sí olùgbé kankan nínú rẹ̀ lẹ́yìn ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni jẹ́ ká rí bí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe máa rí lẹ́yìn tí ọlà bá kúrò lára rẹ̀ tí àṣírí rẹ̀ sì wá tú lọ́nà tó máa tì í lójú. Bó sì ṣe máa rí fún ìyókù Bábílónì Ńlá náà nìyẹn.

20. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe fi hàn pé, lẹ́ẹ̀kan sí i Jèhófà yóò lo àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso láti ṣèdájọ́? (b) Kí ni “ìrònú” Ọlọ́run? (d) Báwo làwọn orílẹ̀-èdè á ṣe mú “ìrònú kan ṣoṣo” tiwọn ṣẹ, ṣùgbọ́n ta lẹni náà gan-an tí wọ́n mú ìrònú rẹ̀ ṣẹ?

20 Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà yóò lo àwọn èèyàn tó jẹ́ olùṣàkóso láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. “Nítorí Ọlọ́run fi í sínú ọkàn-àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ, àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà ní ìjọba wọn, títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.” (Ìṣípayá 17:17) Kí ni “ìrònú” Ọlọ́run? Ìrònú Ọlọ́run ni láti ṣètò bí àwọn tó máa mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Bábílónì Ńlá ṣe máa para pọ̀, kí wọ́n lè pa á run pátápátá. Ó dájú pé ohun tó máa mú kí àwọn olùṣàkóso gbéjà kò ó ni láti mú “ìrònú kan ṣoṣo” tiwọn ṣẹ. Wọn á rò pé ire orílẹ̀-èdè àwọn làwọn ń wá báwọn ṣe gbéjà ko aṣẹ́wó ńlá náà. Wọ́n lè rò pé tí ìsìn kan tó wà lágbègbè àwọn bá ń wà nìṣó, á wu ìṣàkóso àwọn léwu. Ṣùgbọ́n Jèhófà gan-an lẹni tó máa mú káwọn alákòóso náà ṣe bẹ́ẹ̀; wọn á mú ìrònú Jèhófà ṣẹ ní ti pé wọ́n á pa ọ̀tá rẹ̀ tó jẹ́ panṣágà látọjọ́ tó ti pẹ́ run.—Fi wé Jeremáyà 7:8-11, 34.

21. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ló máa pa Bábílónì Ńlá run, kí ló hàn gbangba pé àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè?

21 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn orílẹ̀-èdè máa lo ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, láti pa Bábílónì Ńlá run. Kì í ṣe pé wọ́n ń ṣe ohun tó wù wọ́n, nítorí Jèhófà ló fi í sí wọn lọ́kàn “àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà ní ìjọba wọn.” Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn orílẹ̀-èdè á rí i kedere pé ó pọn dandan pé káwọn fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lókun. Wọn á fún un ní eyín, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, nípa gbígbé àṣẹ àti agbára yòówù tí wọ́n ní fún un kó bàa lè yíjú padà sí ìsìn èké kó sì ṣẹ́gun rẹ̀ “títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.” Èyí ló máa sọ aṣẹ́wó àtayébáyé yìí di àwáàrí. À-kú-tún-kú ẹ̀ láé!

22. (a) Nínú Ìṣípayá 17:18, kí ni ọ̀nà tí áńgẹ́lì náà gbà parí gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀ fi hàn? (b) Ki làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nítorí rírí tá a rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ náà?

22 Bí ìgbà tí áńgẹ́lì náà fẹ́ tẹnu mọ́ bó ṣe dájú tó pé ìdájọ́ Jèhófà lórí gbogbo ìsìn èké àgbáyé máa ṣẹ ní kíkún, ó parí gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀ nípa wíwí pé: “Obìnrin tí ìwọ sì rí túmọ̀ sí ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:18) Bíi ti Bábílónì tó wà nígbà ayé Bẹliṣásárì, Ọlọ́run ti wọn Bábílónì Ńlá ‘wò lórí òṣùwọ̀n ó sì rí i pé kò kúnjú òṣùwọ̀n.’ (Dáníẹ́lì 5:27, The New English Bible) Ìdájọ́ ìkẹyìn tó máa wá sórí rẹ̀ máa yára kánkán. Ki làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nítorí rírí tá a rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ aṣẹ́wó ńlá àti ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà? À ń fi ìtara pòkìkí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà, a sì ń dá àwọn tó ń fi inú kan wá òtítọ́ kiri lóhùn “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.” (Kólósè 4:5, 6; Ìṣípayá 17:3, 7) Gẹ́gẹ́ bí orí tó tẹ̀ lé e ṣe máa jẹ́ ká mọ̀, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ láti là á já nígbà tí Ọlọ́run bá ṣèdájọ́ aṣẹ́wó ńlá náà gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ní kíákíá!

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 252]

Ìtòtẹ̀léra Àwọn Ọba Ayé Méje

ÍJÍBÍTÌ

ÁSÍRÍÀ

BÁBÍLÓNÌ

MÍDÍÀ ÀTI PÁṢÍÀ

GÍRÍÌSÌ

RÓÒMÙ

GẸ̀Ẹ́SÌ ÀTI AMẸ́RÍKÀ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 254]

“Òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 255]

Wọ́n kẹ̀yìn sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, “wọ́n fún ẹranko ẹhànnà náà ní agbára àti ọlá àṣẹ wọn”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 257]

Bí Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ṣe pa run pátápátá ni ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá tó yọrí ọlá jù lọ nínú Bábílónì Ńlá náà ṣe máa pa run