Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ra Wúrà Tí A Fi Iná Yọ́ Mọ́

Ra Wúrà Tí A Fi Iná Yọ́ Mọ́

Orí 13

Ra Wúrà Tí A Fi Iná Yọ́ Mọ́

LAODÍKÍÀ

1, 2. Ibo lèyí tó kẹ́yìn lára ìjọ méjèèje tí Jésù tó ti dẹni ògo ránṣẹ́ sí, kí sì ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó wà nínú ìlú náà?

 LAODÍKÍÀ ló kẹ́yìn lára ìjọ méje tí Jésù tó jí dìde ránṣẹ́ sí. Ìhìn tó sì wà nínú iṣẹ́ náà jẹ́ èyí tí ń ṣíni níyè tó sì ń fúnni níṣìírí!

2 Lónìí, o lè rí àwókù Laodíkíà nítòsí ìlú Denizli tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́rùn-ún [90] kìlómítà sí gúúsù ìlú Alasehir. Ní ọ̀rúndún kìíní, Laodíkíà jẹ́ ìlú aláásìkí. Nítorí pé ìkòríta pàtàkì kan ló wà, ó mú kó jẹ́ ojúkò ètò ìfowópamọ́ àti káràkátà. Oògùn ojú kan tó ń tà fi kún ọlà rẹ̀, ó sì tún lórúkọ nídìí títa ojúlówó ẹ̀wù tí wọ́n fi irun àgùntàn dúdú múlọ́múlọ́ ṣe ládùúgbò yẹn. Àìsí omi, tí ì bá jẹ́ ìṣòro pàtàkì nílùú náà ti dohun ìgbàgbé látàrí bí wọ́n ṣe mú kí omi tí wọ́n fà láti ìsun omi gbígbóná kan tó jìnnà díẹ̀ gba abẹ́lẹ̀ kọjá. Nípa báyìí, ìgbà tí omi náà bá fi máa dé àárín ìlú, á ti di lílọ́wọ́ọ́wọ́.

3. Báwo ni Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Laodíkíà?

3 Laodíkíà ò jìnnà sí Kólósè. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Kólósè, ó mẹ́nu ba lẹ́tà kan tó fi ránṣẹ́ sáwọn ará Laodíkíà. (Kólósè 4:15, 16) A ò mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sínú lẹ́tà yẹn, ṣùgbọ́n iṣẹ́ tí Jésù ń rán sáwọn ará Laodíkíà báyìí fi hàn pé ìjọsìn wọn mẹ́hẹ púpọ̀. Bó ti wù kó rí, bó ṣe máa ń ṣe, Jésù kọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tóun jẹ́, ó ní: “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Laodíkíà pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí Àmín wí, ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 3:14.

4. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ “Àmín”?

4 Kí nìdí tí Jésù fi pe ara rẹ̀ ní “Àmín”? Orúkọ oyè yìí mú kí ìdájọ́ tó wà nínú iṣẹ́ tó rán sí ìjọ Laodíkíà túbọ̀ rinlẹ̀. “Àmín” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú ní olówuuru látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “dájúdájú,” “kó rí bẹ́ẹ̀,” a sì ń lò ó ní òpin àdúrà láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, sáwọn gbólóhùn àdúrà náà. (1 Kọ́ríńtì 14:16) Jésù jẹ́ “Àmín” nítorí pé ìwà títọ́ rẹ̀ tí kò kù síbì kan àti ikú ìrúbọ tó kú ló mú kó dáni lójú pé gbogbo àwọn ìlérí àgbàyanu Jèhófà ló máa nímùúṣẹ. (2 Kọ́ríńtì 1:20) Látìgbà yẹn, Jèhófà là ń darí gbogbo àdúrà wa sí ní tààràtà nípasẹ̀ Jésù.—Jòhánù 15:16; 16:23, 24.

5. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́”?

5 Jésù pẹ̀lú ni “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.” Tí Bíbélì bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, ó sábà máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bí ìṣòtítọ́, òtítọ́, àti òdodo, nítorí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 45:4; Aísáyà 11:4, 5; Ìṣípayá 1:5; 19:11) Òun ni Ẹlẹ́rìí gíga jù lọ fún Jèhófà. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, látìbẹ̀rẹ̀ pàá ni Jésù ti ń polongo ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Òwe 8:22-30) Nígbà tó jẹ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́rìí sí òtítọ́. (Jòhánù 18:36, 37; 1 Tímótì 6:13) Lẹ́yìn tó jíǹde, ó ṣèlérí ẹ̀mí mímọ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni wá ni Jésù ti ń darí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí láti máa wàásù ìhìn rere “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Ìṣe 1:6-8; Kólósè 1:23) Ní tòótọ́, Jésù yẹ lẹ́ni tá a gbọ́dọ̀ pè ní ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́. Báwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Laodíkíà bá fetí sílẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á ṣe wọ́n láǹfààní.

6. (a) Báwo ni Jésù ṣe ṣàpèjúwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó wà ní Laodíkíà? (b) Àpẹẹrẹ rere tí Jésù fi lélẹ̀ wo làwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà kọ̀ láti tẹ̀ lé?

6 Iṣẹ́ wo ni Jésù rán sáwọn ará Laodíkíà? Kò gbóríyìn fún wọn rárá. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, ó sọ fún wọn pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o kò tutù bẹ́ẹ̀ ni o kò gbóná. Èmi ì bá fẹ́ kí o tutù tàbí kẹ̀ kí o gbóná. Nípa báyìí, nítorí pé o lọ́wọ́ọ́wọ́, tí o kò sì gbóná tàbí tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ní ẹnu mi.” (Ìṣípayá 3:15, 16) Báwo ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ Jésù Kristi Olúwa ṣe máa rí lára rẹ? Ǹjẹ́ o ò ní í ta kìjí kó o sì ṣàyẹ̀wò ara rẹ? Dájúdájú, àwọn ará Laodíkíà wọnnì gbọ́dọ̀ fúnra wọn níṣìírí, nítorí pé wọ́n ti di ọ̀lẹ́dàrùn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, ó sì hàn gbangba pé wọ́n ti fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 6:1.) Ṣe ni Jésù, ẹni tó yẹ káwọn Kristẹni wọ̀nyẹn fara wé máa ń fi ìtara amú-bí-iná ṣe iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́. (Jòhánù 2:17) Síwájú sí i, àwọn ọlọ́kàn tútù ti rí i pé ní gbogbo ìgbà, ẹni jẹ́jẹ́ àti oníwà tútù ni, ó sì ń mára tuni bí ìgbà téèyàn ń mu omi tútù nini nínú oòrùn ọ̀sán gangan. (Mátíù 11:28, 29) Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni ní Laodíkíà ò gbóná bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì tutù. Bí omi tó ń ṣàn wá sínú ìlú wọn, ńṣe ni wọ́n ń lọ́wọ́ọ́wọ́. Wọ́n yẹ lẹ́ni tí Jésù ń pa tì pátápátá, kó ‘pọ̀ wọ́n jáde kúrò lẹ́nu’! Ǹjẹ́ káwa ní tiwa máa sapá tìtaratìtara, bíi Jésù, láti máa mú ìtura bá àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—Mátíù 9:35-38.

“Ìwọ Wí Pé: ‘Ọlọ́rọ̀ Ni Mí’”

7. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi ohun tó fa ìṣòro àwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà hàn? (b) Kí nìdí tí Jésù fi pe àwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà ní “afọ́jú àti ẹni ìhòòhò”?

7 Kí ló fa ìṣòro àwọn ará Laodíkíà? Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó tẹ̀ lé e mú ká lóye ìṣòro náà: “Nítorí ìwọ wí pé: ‘Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,’ ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.” (Ìṣípayá 3:17; fi wé Lúùkù 12:16-21.) Torí pé ìlú tó láásìkí ni wọ́n ń gbé, ọkàn wọ́n balẹ̀ nítorí ọrọ̀ wọn. Ó ṣeé ṣe kí pápá ìṣeré, àwọn gbọ̀ngàn ìwòran, àtàwọn gbọ̀ngàn ìṣeré ìfarapitú ti nípa lórí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn, tó fi jẹ́ pé wọ́n ti di “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” a (2 Tímótì 3:4) Síbẹ̀ tálákà làwọn ará Laodíkíà tí wọ́n lọ́rọ̀ nípa tara yìí torí wọn ò lọ́rọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Díẹ̀ kíún ni ‘ìṣúra tí wọ́n tò jọ sí ọ̀run,’ ìyẹn bí wọ́n bá tiẹ̀ ní rárá. (Mátíù 6:19-21) Wọn ò jẹ́ kí ojú wọn mú ọ̀nà kan nípa fífi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Lóòótọ́ ni wọ́n wà nínú òkùnkùn, wọ́n fọ́jú, wọ́n ò sì rí òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kankan. (Mátíù 6:22, 23, 33) Yàtọ̀ síyẹn, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀wù dáradára tí wọ́n lè ti fi ọlà tí wọ́n ní rà, lójú Jésù, ìhòòhò ni wọ́n wà. Wọn ò ní àwọn ẹ̀wù nípa tẹ̀mí tó jẹ ìwà Kristẹni tó lè fi wọ́n hàn bíi Kristẹni.—Fi wé Ìṣípayá 16:15.

8. (a) Ọ̀nà wo lohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Laodíkíà gbà jọ èyí tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí? (b) Báwo làwọn Kristẹni kan ṣe tan ara wọn jẹ nínú ayé oníwọra yìí?

8 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí mà burú jáì o! Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ irú nǹkan wọ̀nyí kì í sábà ṣẹlẹ̀ lónìí? Kí ló ń fà á? Ìjọra-ẹni-lójú ni. Kò sì sí nǹkan méjì tó ń fà ìjọra-ẹni-lójú ju gbígbára lé dúkìá àti gbígbára lé àwọn tó dà bí onílàákàyè ẹ̀dá láwùjọ. Bíi tàwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn kan lára àwa èèyàn Jèhófà ti tan ara wọn jẹ nípa ríronú pé àwọn ṣì lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ báwọn bá ṣáà ti ń lọ sí ìpàdé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Jíjẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” lọ́nà gbà-máà-pó-ò-rọ́wọ́-mi ti tẹ́ wọn lọ́rùn. (Jákọ́bù 1:22) Láìka àwọn ìkìlọ̀ àsọtúnsọ látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ Jòhánù sí, wọ́n ti gbé ọkàn wọn lé àwọn aṣọ aláràbarà, àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ibùgbé, àti ìgbésí ayé tó dá lórí eré ìnàjú àti adùn. (1 Tímótì 6:9, 10; 1 Jòhánù 2:15-17) Gbogbo àwọn nǹkan yìí kì í jẹ́ kéèyàn lóye ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. (Hébérù 5:11, 12) Dípò tí wọ́n á fi jẹ́ ẹni tí ò nítara, tó ń lọ́ wọ́ọ́wọ́, ṣe ni wọ́n gbọ́dọ̀ koná mọ́ “iná ẹ̀mí” kí wọ́n sì fi ìháragàgà “wàásù ọ̀rọ̀ náà” lákọ̀tun.—1 Tẹsalóníkà 5:19; 2 Tímótì 4:2, 5.

9. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wo ló yẹ kó mú àwọn Kristẹni tó lọ́wọ́ọ́wọ́ ta kìjí, kí sì nìdí? (b) Báwo ni ìjọ ṣe lè ran “àwọn àgùntàn” tó ń ṣáko lọ lọ́wọ́?

9 Irú ojú wo ni Jésù fi wo àwọn Kristẹni lílọ́wọ́ọ́wọ́? Bó ṣe sọ ojú abẹ níkòó gbọ́dọ̀ ta wọ́n kìjí. Ó ni: “O kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.” Ẹ̀rí-ọkàn wọn ti kú débi pé wọn ò tiẹ̀ mọ inú ipò bíburú jáì tí wọ́n wà. (Fi wé Òwe 16:2; 21:2.) A ò gbọ́dọ̀ gbójú fo ìṣòro ńlá yìí nínú ìjọ. Báwọn alàgbà bá jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú jíjẹ́ onítara, tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ ṣe olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àtàwọn mìíràn tí wọ́n yanṣẹ́ fún á lè tóótun láti ta àwọn “àgùntàn” tó ń ṣáko lọ jí. Àwọn àgùntàn náà á sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀.—Lúùkù 15:3-7.

Ìmọ̀ràn Lórí ‘Dídi Ọlọ́rọ̀’

10. Kí ni “wúrà” tí Jésù sọ pé káwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà rà lọ́wọ́ òun?

10 Ǹjẹ́ ojútùú wà fún ohun tó ń bani nínú jẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ ní Laodíkíà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà, báwọn Kristẹni yẹn bá máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé: “Mo gbà ọ́ nímọ̀ràn láti ra wúrà tí a fi iná yọ́ mọ́ lọ́dọ̀ mi kí o lè di ọlọ́rọ̀.” (Ìṣípayá 3:18a) “Wúrà” Kristẹni tòótọ́, tí iná ti yọ́ mọ́ tí gbogbo ìdàrọ́ rẹ̀ sì ti kúrò, á sọ wọ́n dẹni tó ní “ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:21) Ibo ni wọ́n ti lè rí irú wúrà bẹ́ẹ̀ rà? Kì í ṣe lọ́dọ̀ àwọn tó ni ilé iṣẹ́ ìfowópamọ́ àdúgbò, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Jésù! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tí wúrà yẹn jẹ́ nígbà tó sọ fún Tímótì láti fún àwọn Kristẹni tó lọ́rọ̀ ní ìtọ́ni “[láti] máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la.” Àfi tí wọ́n bá lè lo ara wọn lọ́nà yìí nìkan ni wọ́n fi lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:17-19) Ì bá sì dáa ká ní àwọn tó lọ́rọ̀ ní Laodíkíà yìí lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ọrọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Tún wo Òwe 3:13-18 pẹ̀lú.

11. Àwọn wo ló ń ra “wúrà tí iná ti yọ́ mọ́” lóde òní?

11 Ǹjẹ́ àwọn tó ń ra “wúrà tí iná ti yọ́ mọ́” wà lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà! Kódà nígbà tí ọjọ́ Olúwa kù díẹ̀ kó dé, àwùjọ kékeré kan tá a mọ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lójúfò láti mọ̀ pé èké làwọn ẹ̀kọ́ Bábílónì táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gbà gbọ́, irú bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, ìdálóró nínú iná hẹ́ẹ̀lì, ìbatisí ọmọ ọwọ́, àti ìjọsìn àwọn ère (títí kan àgbélébùú àtàwọn ère Màríà). Ní ṣíṣe agbátẹrù òtítọ́ Bíbélì, àwọn Kristẹni wọ̀nyí pòkìkí Ìjọba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo táráyé ní, wọ́n sì sọ pé lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù lèèyàn fi lè rí ìgbàlà. Nígbà tó ti ku nǹkan bí ogójì [40] ọdún ni wọ́n ti sọ pé ọdún 1914 ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pè ní òpin àkókò àwọn Kèfèrí, èyí tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó mi ayé tìtì bá rìn.—Ìṣípayá 1:10.

12. Kí lorúkọ ọ̀kan lára àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jí bọ̀ lójú oorun, báwo ló sì ṣe fi àpẹẹrẹ tí ò ṣeé gbàgbé lélẹ̀ ní títo àwọn ìṣúra jọ sí ọ̀run?

12 Charles Taze Russell ló mú ipò iwájú láàárín àwọn Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jí lójú oorun, òun ló sì dá kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sílẹ̀ ní Allegheny (tó jẹ́ apá kan Pittsburgh nísinsìnyí), Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1870. Russell àti bàbá rẹ̀ ni wọ́n jo dòwò pọ̀ ní gbogbo ìgbà tó fi ń wá bó ṣe máa lóye òtítọ́ Bíbélì, kódà ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún un láti di oníbú owó nígbà náà. Àmọ́ ó ta gbogbo ìpín tó ní nínú iṣẹ́ ajé náà, ó sì ná owó tó rí sórí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lọ́dún 1884, Russell di ààrẹ àkọ́kọ́ fún àjọ tá a wá mọ̀ lónìí sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Látàrí àárẹ̀ tó mú un nígbà tó wà lẹ́nu ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀ lọ sí ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó kú nínú ọkọ̀ rélùwéè nítòsí Pampa, Texas, nígbà tó ń lọ sí New York lọ́dún 1916. Àpẹẹrẹ tí ò ṣeé gbàgbé ló fi lélẹ̀ ní ti bó ṣe yẹ kéèyàn to ìṣúra iṣẹ́ ìsìn àfọkànṣe jọ sí ọ̀run, àpẹẹrẹ kan tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn akínkanjú aṣáájú-ọ̀nà ń tẹ̀ lé lónìí.—Hébérù 13:7; Lúùkù 12:33, 34; fi wé 1 Kọ́ríńtì 9:16; 11:1.

Lílo Oògùn Ojú Nípa Tẹ̀mí

13. (a) Báwo ni oògùn ojú tẹ̀mí á ṣe dín ìṣòro àwọn ará Laodíkíà kù? (b) Irú ẹ̀wù wo ni Jésù dámọ̀ràn, kí sì nìdí?

13 Jésù tún fún àwọn ará Laodíkíà wọnnì ní ìṣílétí gidigidi pé: “Ra . . . ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun kí o lè di ẹni tí ó wọṣọ, kí ìtìjú ìhòòhò rẹ má bàa sì di èyí tí ó fara hàn kedere, àti oògùn ojú láti fi pa ojú rẹ, kí o bàa lè ríran.” (Ìṣípayá 3:18b) Wọ́n gbọ́dọ̀ wá bí ojú wọn tó fọ́ nípa tẹ̀mí ṣe máa là nípa ríra oògùn ojú tó ń jẹ́ kí ojú là, kì í ṣe èyí táwọn oníwòsàn àdúgbò ń tà ṣùgbọ́n irú èyí tó jẹ́ Jésù nìkan lo ní in. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa rìn ní “ipa ọ̀nà àwọn olódodo” bí ojú wọn á ṣe máa tàn yanran sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Òwe 4:18, 25-27) Nípa báyìí wọ́n lè wọ “ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun” èyí tó máa fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, dípò àwọn ẹ̀wù onírun àgùntàn dúdú olówó gọbọi tó ti àgbègbè Laodíkíà wá.—Fi wé 1 Tímótì 2:9, 10; 1 Pétérù 3:3-5.

14. (a) Oògùn ojú nípa tẹ̀mí wo ló ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó látọdún 1879? (b) Kí lorísun owó táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ná? (d) Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí àwọn mìíràn tó bá di pé ká lo ọrẹ?

14 Ǹjẹ́ oògùn ojú nípa tẹ̀mí wà lárọ̀ọ́wọ́tó lónìí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Lọ́dún 1879, Pásítọ̀ Russell, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń fìfẹ́ pè é nígbà yẹn, bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn tí gbogbo ayé wá mọ̀ lónìí sí Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà, jáde láti fi gbèjà òtítọ́. Nínú ìtẹ̀jáde ẹlẹ́ẹ̀kejì, ó polongo pé: “A gbà gbọ́ pé JÈHÓFÀ ni alátìlẹyìn wa lórí bá a ṣe ń tẹ̀ [ìwé ìròyìn yìí] jáde, nípa bẹ́ẹ̀, ìwé ìròyìn yìí ò ní ṣagbe láé, kò sì ní bẹ̀bẹ̀ fún ìtìlẹyìn lọ́dọ̀ àwọn èèyàn. Nígbà tí Ẹni tó sọ pé: ‘Gbogbo wúrà àti fàdákà orí àwọn òkè ńlá jẹ́ tèmi,’ bá kọ̀ láti pèsè owó tá a nílò, á jẹ́ pé ó ti tó àkókò láti dáwọ́ ìtẹ̀jáde náà dúró.” Ṣe làwọn ajíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n kó dúkìá jọ tìrìgàngàn, tí wọ́n sì ń gbé nínú fàájì àìnítìjú (àti ti oníṣekúṣe nígbà míì). (Ìṣípayá 18:3) Láìdà bíi wọn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a mọ̀ lónìí sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti lo gbogbo ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe láti fi ṣètò iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé àti láti fi mú ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ náà, èyí tó dá lórí Ìjọba Jèhófà tó ń bọ̀. Títí dòní yìí, ẹgbẹ́ Jòhánù ló ń darí títẹ Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àwọn ìwé ìròyìn tí àpapọ̀ ìpínkiri wọn ju mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gọ́ta [59,000,000] lọ lọ́dún 2006. À ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde ní nǹkan bí àádọ́jọ [150] èdè. Òun ni olórí ìwé ìròyìn ìjọ tí iye àwọn Kristẹni tó wà ńbẹ̀ ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ, àwọn tí wọ́n ti lo oògùn ojú nípa tẹ̀mí, èyí tó jẹ́ kí ojú wọ́n là kí wọ́n lè dá ìsìn èké mọ̀ kí wọ́n sì mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó.—Máàkù 13:10.

Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìtọ́sọ́nà àti Ìbáwí

15. Kí nìdí tí Jésù fi fún àwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà nímọ̀ràn tó lè bẹ́ẹ̀, báwo ló sì ṣe yẹ kó rí lára ìjọ náà?

15 Ẹ jẹ́ ká padà sọ́dọ̀ àwọn ará Laodíkíà. Báwo ni ìmọ̀ràn líle koko tí Jésù fún wọn ṣe rí lára wọn? Ṣó yẹ kí wọ́n sọ̀rètí nù kí wọ́n sì rò pé Jésù ò fẹ́ káwọn jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn rárá. Ó sọ fún wọn pé: “Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí. Nítorí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.” (Ìṣípayá 3:19) Gẹ́gẹ́ bí ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà, ìbáwí Jésù jẹ́ àmì pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn ni. (Hébérù 12:4-7) Ó yẹ kí ìjọ Laodíkíà rí ìfẹ́ tí Jésù fi bá wọn lò bí àǹfààní kan kí wọ́n sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. Ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni ìlọ́wọ́ọ́wọ́ jẹ́, kí wọ́n sì ronú pìwà dà. (Hébérù 3:12, 13; Jákọ́bù 4:17) Àfi káwọn alàgbà wọn yáa dẹ́kun líle ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kiri, kí wọ́n sì “rú” ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wọn “sókè bí iná.” Bí oògùn ojú nípa tẹ̀mí bá sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ẹnu kára tú gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ ni bí ìgbà téèyàn bu omi tútù mu látinú àmù.—2 Tímótì 1:6; Òwe 3:5-8; Lúùkù 21:34.

16. (a) Báwo ni Jésù ṣe ń fi ìfẹ́ àti àníyàn tó ní sí wà hàn lónìí? (b) Bí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tó le, báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa?

16 Àwa náà ńkọ́ lónìí? Jésù ń bá a lọ láti máa “nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé.” Kò ní yé nífẹ̀ẹ́ wọn “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Jòhánù 13:1; Mátíù 28:20) Ó ń fi ìfẹ́ àti àníyàn tó ní sí wọ́n hàn nípasẹ̀ ẹgbẹ́ Jòhánù òde òní àtàwọn ìràwọ̀, tàbí àwọn alàgbà, nínú ìjọ Kristẹni. (Ìṣípayá 1:20) Láwọn àkókò amunilómi yìí, tọkàntọkàn làwọn alàgbà fi ń wá ọ̀nà láti ran gbogbo wa lọ́wọ́, lọ́mọdé àti lágbà, láti má ṣe ré kọjá àwọn ààlà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, ká má ṣe ní ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe, ìfẹ́ ọrọ̀, ká má sì lọ́wọ́ sí ìwà ẹ̀gbin ayé. Bí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tàbí ìbáwí tó le nígbà mìíràn, ká rántí pé “àwọn ìtọ́sọ́nà inú ìbáwí . . . ni ọ̀nà ìyè.” (Òwe 6:23) Aláìpé ni gbogbo wa, a sì ní láti máa tètè ronú pìwà dà bó bá ṣe pọn dandan ká bàa lè tún èrò wa ṣe ká sì dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.—2 Kọ́ríńtì 13:11.

17. Báwo ni ọlà ṣe lè wu ìjọsìn wa léwu?

17 À ò gbọ́dọ̀ gbà kí ìfẹ́ àwọn ohun tara, aásìkí, tàbí àìnító sọ wá dẹni tó ń lọ́wọ́ọ́wọ́. Ọrọ̀ níní lè jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ṣí ilẹ̀kùn iṣẹ́ ìsìn tuntun sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún léwu. (Mátíù 19:24) Ẹnì kan tó rí já jẹ lè rò pé kò pọn dandan fóun láti jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìwàásù bí àwọn yòókù, bóun bá ti ń fi ọrẹ tó jọjú sílẹ̀ látìgbà dégbà. Ó tiẹ̀ lè rò pé ó yẹ káwọn àǹfààní kan tọ́ sóun torí bí òun ṣe ní lọ́wọ́. Láfikún, ọ̀pọ̀ adùn àtàwọn àkókò ìgbà ọwọ́ dilẹ̀ lẹni tó ní lọ́wọ́ lè gbádùn, èyí tí agbára àwọn yòókù kò ká. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ń gba àkókò, wọ́n sì lè mú káwọn tí ò kíyè sára dẹwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, èyí tó lè sọ àwọn aláìlóye dẹni tó ń lọ́wọ́ọ́wọ́. Ǹjẹ́ ká yẹra fún gbogbo irú ìdẹkùn bẹ́ẹ̀, ká máa bá a lọ ní ‘ṣíṣiṣẹ́ kára, ka sì máa sapá’ tọkàntọkàn ká lè gba ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—1 Tímótì 4:8-10; 6:9-12.

‘Jíjẹ Oúnjẹ Alẹ́’

18. Àǹfààní wo ni Jésù fi lọ àwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà?

18 Jésù ń bá a lọ pé: “Wò ó! Mo dúró lẹ́nu ilẹ̀kùn, mo sì ń kànkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi tí ó sì ṣí ilẹ̀kùn, dájúdájú, èmi yóò wọ ilé rẹ̀, èmi yóò sì jẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ àti òun pẹ̀lú mi.” (Ìṣípayá 3:20) Ẹ wo bí ì bá ṣe dáa tó ká ní àwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà lè gba Jésù láyè nínú ìjọ wọn, ṣe ní ì bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ìlọ́wọ́ọ́wọ́ wọn!—Mátíù 18:20.

19. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ṣèlérí jíjẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú ìjọ tó wà ní Laodíkíà?

19 Kò síyè méjì pé oúnjẹ tí Jésù jẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló máa wá sọ́kàn àwọn ará Laodíkíà nígbà tí Jésù sọ nípa oúnjẹ alẹ́. (Jòhánù 12:1-8) Irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ máa ń ṣàlékún òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn tó bá wà ńbẹ̀ ń ní. Bákan náà, àwọn àkókò pàtàkì kan wáyé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ìyẹn ìgbà tó jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn àkókò náà sì fún wọn lókun gidigidi. (Lúùkù 24:28-32; Jòhánù 21:9-19) Èyí fi hàn pé, ìlérí tó ṣe láti bẹ ìjọ Laodíkíà wò kó sì jẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú wọn jẹ́ ìlérí kan láti mú kí òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé wọn yékéyéké ìyẹn bí wọ́n bá fẹ́ o.

20. (a) Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọjọ́ Olúwa, kí ni ìlọ́wọ́ọ́wọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yọrí sí? (b) Báwo ni ìdájọ́ Jésù ṣe kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

20 Ìṣílétí onífẹ̀ẹ́ tí Jésù fún àwọn ará Laodíkíà ní ìtumọ̀ àkànṣe fún àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí. Àwọn kan nínú wọn rántí pé, nígbà tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti di lílọ́wọ́ọ́wọ́ dé ìwọ̀n tó burú púpọ̀. Dípò fífi inú dídùn kí Olúwa wa káàbọ̀ lọ́dún 1914, ṣe lẹgbẹ́ àwọn àlùfáà kó wọnú ìpakúpa Ogun Àgbáyé Kìíní, bẹ́ẹ̀ sì rèé, orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélógún [24] nínú méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tí wọ́n ń bá ara wọn jà ló ń pera wọn ní Kristẹni. Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó máa wà lọ́rùn wọn ò ní ṣeé kó! Ẹ̀ṣẹ̀ ìsìn èké “wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run” ní ti Ogun Àgbáyé Kejì tó jẹ́ pé nínú èyí tó pọ̀ lára àwọn ibi tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ logun ọ̀hún ti wáyé. (Ìṣípayá 18:5) Síwájú sí i, àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà ti kẹ̀yìn sí Ìjọba Jèhófà tó ń bọ̀ wá nípa ṣíṣe ìtìlẹyìn fún Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àti àjọ ìgbòkègbodò ìjọba tiwa-n-tiwa, ìyípadà àfọ̀tẹ̀ṣe, síbẹ̀ kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó tíì lè yanjú àwọn ìṣòro aráyé. Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Jésù ti pa àwọn àlùfáà tì, lẹ́yìn tó ṣèdájọ́ wọn lọ́nà tó tọ́, ó dà wọ́n nù, bí ìgbà tí apẹja kan bá da ẹja tí kò yẹ tí àwọ̀n rẹ̀ kó nù. Ìbànújẹ́ tó bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lónìí jẹ́rìí sí í pé wọ́n ti jẹ̀bi. Ǹjẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa!—Mátíù 13:47-50.

21. Látọdún 1919 wá, báwo làwọn Kristẹni tó wà nínú ìjọ Ọlọ́run ṣe gba àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà?

21 Kódà láàárín ìjọ Ọlọ́run pàápàá, àwọn kọ̀ọ̀kan wà tí wọ́n lọ́ wọ́ọ́wọ́ tí wọ́n dà bí ohun mímu tí kò gbóná janjan, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò tutù nini. Ṣùgbọ́n Jésù ṣì nífẹ̀ẹ́ tó dénú sí ìjọ rẹ̀. Ó ṣe tán láti lọ bá àwọn Kristẹni tí wọ́n bá fẹ́ kó bá àwọn lálejò, ọ̀pọ̀ ló sì ti gbà á lálejò, bí ẹni pé sí ibi oúnjẹ alẹ́. Èyí ti mú kí ojú wọn là sí ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì látọdún 1919 wá. Wọ́n ti wá tipa bẹ́ẹ̀ lóye tó pọ̀ gan-an.—Sáàmù 97:11; 2 Pétérù 1:19.

22. Oúnjẹ alẹ́ ọjọ́ iwájú wo ló ṣeé ṣe kí Jésù ní lọ́kàn, àwọn wo ló sì máa wà ńbẹ̀?

22 Ó lè jẹ́ pé oúnjẹ míì ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ń bá àwọn ará Laodíkíà sọ̀rọ̀. Torí pé lẹ́yìn ìyẹn la kà nínú Ìṣípayá pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ké sí wá síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Èyí ló máa jẹ́ àsè ìjagunmólú tí wọ́n fi ń yin Jèhófà lẹ́yìn tó bá ti mú ìdájọ́ wá sórí ìsìn èké—àsè ńlá tí Kristi àti gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ ìyàwó rẹ̀ ní ọ̀run máa jẹ. (Ìṣípayá 19:1-9) Àwọn elétí ọmọ nínú ìjọ Laodíkíà ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ ara ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àtàwọn olùṣòtítọ́ arákùnrin Kristi Jésù lónìí, tí wọ́n wọ ẹ̀wù ìdánimọ̀ mímọ́ tónítóní gẹ́gẹ́ bí àwọn ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró ni wọ́n máa jàsè pẹ̀lú Ọkọ wọn nígbà oúnjẹ alẹ́ yẹn. (Mátíù 22:2-13) Ìṣírí yìí ti gbọ́dọ̀ sún wọn láti tètè ronú pìwà dà!

Ìtẹ́ fún Àwọn Aṣẹ́gun

23, 24. (a) Èrè mìíràn wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Ìgbà wo ni Jésù jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ ìdájọ́ àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́? (d) Ìlérí tó fa kíki wo ni Jésù ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀?

23 Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa èrè kan síwájú sí i, ó ní: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.” (Ìṣípayá 3:21) Kí àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì tó wà ní Sáàmù 110:1, 2, bàa lè nímùúṣẹ, Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ ṣẹ́gun ayé, ó sì jí dìde lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run mú kó dẹni tó ń jókòó pẹ̀lú òun [Baba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Rẹ̀] lọ́run. (Ìṣe 2:32, 33) Ọdún míì tí kò tún ṣeé gbà gbé ni ọdún 1914. Ọdún yẹn ni Jésù dé láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tó jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́. Ìdájọ́ náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1918 lórí àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́. Àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun tí wọ́n kú ṣáájú ìgbà yẹn jí dìde, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Jésù nínú Ìjọba rẹ̀. (1 Pétérù 4:17) Ó ti ṣèlérí èyí fún wọn tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ń dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.”—Lúùkù 22:28-30.

24 Iṣẹ́ ńlá gbáà ni—láti jókòó pẹ̀lú Ọba ti ń jọba lákòókò “àtúndá” kí wọ́n sì bá a lọ́wọ́ sí mímú kí aráyé onígbọràn di pípé bíi ti ọgbà Édẹ́nì, èyí tó máa ṣeé ṣe lọ́lá ẹbọ rẹ̀ tó ṣe rẹ́gí! (Mátíù 19:28; 20:28) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jòhánù sọ fún wa, Jésù mú kí àwọn tí wọ́n ṣẹ́gun “jẹ́ ìjọba kan, àlùfáà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀,” láti jókòó lórí ìtẹ́ tó yí ìtẹ́ ọlọ́lá ńlá Jèhófà fúnra rẹ̀ ká ní ọ̀run. (Ìṣípayá 1:6; 4:4) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa—yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí ẹgbẹ́ ti ilẹ̀ ayé tuntun tó ń retí láti lọ́wọ́ nínú mímú Párádísè padà bọ̀ sípò—fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ará Laodíkíà sọ́kàn!—2 Pétérù 3:13; Ìṣe 3:19-21.

25. (a) Gẹ́gẹ́ bó ti rí pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ tí Jésù rán sí àwọn ìjọ yòókù, báwo ló ṣe kádìí iṣẹ́ tó rán sí Laodíkíà? (b) Kí ló yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún ìjọ tó wà ní Laodíkíà sún Kristẹni kọ̀ọ̀kan lónìí láti ṣe?

25 Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe kádìí iṣẹ́ tó rán sáwọn ìjọ tó kù, ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó fi kádìí rẹ̀ ni pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.” (Ìṣípayá 3:22) A ti wọnú àkókò òpin jìnnà. Ẹ̀rí wà yí wa ká pé kò sí ìfẹ́ olóókan láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Láìdà bíi wọn, ǹjẹ́ káwa tá a jẹ́ Kristẹni tòótọ́ fi taratara fi iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ tó wà ní Laodíkíà sílò, bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ tí Olúwa wa rán sí gbogbo ìjọ méjèèje. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ bá a bá ń fi gbogbo agbára wa nípìn-ín nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí Jésù sọ fún ọjọ́ wa: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:12-14.

26. Ìgbà wo ni Jésù tún bá Jòhánù sọ̀rọ̀ tààràtà, kí ló sì lọ́wọ́ sí?

26 Ìmọ̀ràn Jésù sí ìjọ méjèèje ti parí. Kò tún bá Jòhánù sọ̀rọ̀ mọ́ nínú Ìṣípayá àfi nínú orí ìwé tó kẹ́yìn; ṣùgbọ́n ó lọ́wọ́ nínú ọ̀pọ̀ ìran tí Jòhánù rí, bí àpẹẹrẹ, ní mímú àwọn ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ. Ẹ wá jẹ́ ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Jòhánù nínú ṣíṣàyẹ̀wò ìran pípẹtẹrí kejì tí Jésù Kristi Olúwa ṣí payá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìlú Laodíkíà làwọn awalẹ̀pìtàn ti hú àwọn ibi tá à ń wí wọ̀nyí jáde.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 73]

Ìyàtọ̀ Láàárín Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì àti Ọgbọ́n

Lọ́dún 1956, akọ̀ròyìn kan kọ̀wé pé: “Ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn, a fojú bù ú pé nǹkan méjìléláàádọ́rin [72] lẹnì kan tó jẹ́ mẹ̀kúnnù fẹ́, nínú èyí, nǹkan mẹ́rìndínlógún [16] péré ló jẹ́ kòṣeémáàní. Lóde òní, a fojú bù ú pé nǹkan ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [474] lẹnì kan tó jẹ́ mẹ̀kúnnù ń fẹ́, mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [94] péré ló sì jẹ́ kòṣeémáàní nínú èyí. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ọgọ́rùn-ún méjì [200] ni nǹkan tí wọ́n ń fi ọgbọ́n ìtajà rọ mẹ̀kúnnù láti rà—ṣùgbọ́n lónìí ẹgbẹ̀rìndínlógún [32,000] ni ohun tí mẹ̀kúnnù kan ní láti di ojú rẹ̀ sí káwọn òǹtàjà ẹlẹ́nú-dùn-juyọ̀ má bàa tì í rà á. Àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní fún ẹ̀dá ò pọ̀, àwọn ohun tó wu ẹ̀dá ni ò lópin.” Lónìí, èrò pé àwọn ohun tara àti dúkìá nìkan ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ló gba àwọn èèyàn lọ́kàn. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ti dágunlá sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Oníwàásù 7:12 pé: “Nítorí ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 67]

Ṣe ni omi tó ṣàn wá sí Laodíkíà máa ń lọ́wọ́ọ́wọ́ kò sì bára dé. Ẹ̀mí lílọ́wọ́ọ́wọ́ táwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà ní ò dáa