Títẹ Orí Ejò Náà Fọ́
Orí 40
Títẹ Orí Ejò Náà Fọ́
Ìran 14—Ìṣípayá 20:1-10
Ohun tó dá lé: Gbígbé Sátánì sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún, ìdánwò ìkẹyìn fún aráyé, àti ìparun Sátánì
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Láti òpin ìpọ́njú ńlá sí ìgbà ìparun Sátánì
1. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ṣe ń nímùúṣẹ?
ǸJẸ́ o rántí àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì? Jèhófà Ọlọ́run ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀hún nígbà tó sọ fún Ejò náà pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Wàyí o, ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà ti sún mọ́ òpin rẹ̀! A ti ń fọkàn bá ìtàn ogun náà lọ, èyí tí Sátánì ń bá ètò Jèhófà ti ọ̀run tá a fi wé obìnrin jà. (Ìṣípayá 12:1, 9) Irú-ọmọ Ejò náà lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú ìsìn, ìṣèlú, àti iṣẹ́ ajé ńlá rẹ̀, ti ṣe inúnibíni tó burú jáì sí irú-ọmọ obìnrin náà, ìyẹn Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 8:37, 44; Gálátíà 3:16, 29) Sátánì mú kí Jésù kú ikú oró. Ṣùgbọ́n ń ṣe ni èyí wulẹ̀ dà bí ọgbẹ́ gìgísẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run jí Ọmọ rẹ̀ olóòótọ́ yìí dìde ní ọjọ́ kẹta.—Ìṣe 10:38-40.
2. Báwo la ṣe pa Ejò náà ní orí, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí irú-ọmọ Ejò náà ti orí ilẹ̀ ayé?
2 Ejò náà àti irú-ọmọ rẹ̀ wá ńkọ́? Ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà gígùn kan sáwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù. Ní ìparí lẹ́tà náà, ó gbà wọ́n níyànjú nípa sísọ pé: “Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà yóò tẹ Sátánì rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ yín láìpẹ́.” (Róòmù 16:20) Èyí kì í ṣe ìpalára fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lásán. Títẹ̀ la máa tẹ Sátánì rẹ́! Ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tá a pè ní syn·triʹbo ni Pọ́ọ̀lù lò níhìn-ín, èyí tó túmọ̀ sí kéèyàn lu nǹkan títí tó fi máa rọ̀ pọ̀ṣọ̀pọ̀ṣọ̀, kéèyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kéèyàn pa á run pátápátá nípa fífọ́ ọ sí wẹ́wẹ́. Ìyọnu ńláǹlà ló tọ́ sáwọn èèyàn tó jẹ́ irú-ọmọ Ejò náà ní ọjọ́ Olúwa, ìyọnu náà yóò sì dé òpin rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tí Bábílónì Ńlá àtàwọn ètò ìṣèlú ayé rẹ́ yóò pa run pátápátá, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn oníṣòwò àtàwọn ológun tó jẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. (Ìṣípayá, orí 18 àti 19) Nípa bẹ́ẹ̀ Jèhófà yóò mú ìṣọ̀tá tó wà láàárín irú-ọmọ méjèèjì náà wá sópin. Irú-Ọmọ obìnrin Ọlọ́run yóò ṣẹ́gun irú-ọmọ Ejò náà ti orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí mọ́!
A Gbé Sátánì Sọ Sínú Ọ̀gbun Àìnísàlẹ̀
3. Kí ni Jòhánù sọ fún wa pé yóò ṣẹlẹ̀ sí Sátánì?
3 Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí Sátánì fúnra rẹ̀ àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀? Jòhánù sọ fún wa pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ tú u fún ìgbà díẹ̀.”—Ìṣípayá 20:1-3.
4. Ta ni áńgẹ́lì tó ní kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ lọ́wọ́, báwo la sì ṣe mọ̀?
4 Ta ni áńgẹ́lì yí? Ó ní láti ní agbára ńlá tí yóò fi lè mú olórí ọ̀tá Jèhófà kúrò. Ó ní “kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá.” Ǹjẹ́ èyí ò rán wa létí ìran àkọ́kọ́? Ìran náà sọ pé Ọba àwọn eéṣú ni “áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣípayá 9:11) Nítorí náà á tún rí i níhìn-ín lẹ́ẹ̀kan sí i pé, Jésù Kristi tí a ti ṣe lógo, tí í ṣe Aṣáájú àwọn tó ń fi hàn pé Jèhófà nìkan ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, wà lẹ́nu iṣẹ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni olú áńgẹ́lì tó lé Sátánì kúrò lọ́run, tó ṣèdájọ́ Bábílónì Ńlá tó sì máa pa “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn” run ní Amágẹ́dọ́nì, ó dájú pé kò ní jẹ́ kí áńgẹ́lì mìíràn tó rẹlẹ̀ sí i ṣe iṣẹ́ bàǹtà-banta ti jíju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀!—Ìṣípayá 12:7-9; 18:1, 2; 19:11-21.
5. Kí ni áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà ṣe sí Sátánì Èṣù, kí sì nìdí?
5 Nígbà tá a fi dírágónì ńlá aláwọ̀ iná náà sọ̀kò sísàlẹ̀ láti ọ̀run, ìwé Ìṣípayá sọ pé òun ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:3, 9) Nígbà tí wọ́n sì gbá a mú láti gbé e sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n tún sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé òun ni ‘dírágónì náà, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì.’ Ẹni ibi tó jẹ́ ajẹnirun, atannijẹ, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, àti alátakò yìí ni wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè tí wọ́n sì fi sọ̀kò “sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” lẹ́yìn náà wọ́n pa á dé wọ́n sì fi èdìdì dì í pinpin, “kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.” Ẹgbẹ̀rún ọdún ni Sátánì yóò fi wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ yìí. Láàárín àkókò náà, agbára rẹ̀ lórí aráyé kó ní ju ti ẹlẹ́wọ̀n kan tó wà nínú àjà ilẹ̀ jíjìn. Áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà mú Sátánì kúrò lórí ilẹ̀ ayé pátápátá kó má bàa ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ìjọba òdodo náà. Ẹ ò rí i pé ìtura ńlá lèyí máa jẹ́ fún aráyé!
6. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé àwọn ẹ̀mí èṣù yóò lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀? (b) Kí ló máa bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn náà, kí sì nìdí?
6 Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹ̀mí èṣù? A fi àwọn náà “pa mọ́ de ìdájọ́.” (2 Pétérù 2:4) Sátánì ni Bíbélì pè ní “Béélísébúbù olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Lúùkù 11:15, 18; Mátíù 10:25) Nítorí pé ọjọ́ ti pẹ́ táwọn àti Sátánì ti jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe irú ìdájọ́ kan náà ló yẹ kí wọ́n rí gbà? Tipẹ́tipẹ́ ni ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ti jẹ́ ohun ìbẹ̀rù fáwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyẹn; lákòókò kan nígbà tí Jésù kò wọ́n lójú, “wọ́n . . . ń pàrọwà fún un láti má ṣe pàṣẹ fún wọn láti lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Lúùkù 8:31) Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù bá gbé Sátánì sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, ó dájú pé á fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ náà sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. (Fi wé Aísáyà 24:21, 22.) Lẹ́yìn tó bá ti gbé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi máa tó bẹ̀rẹ̀.
7. (a) Ipò wo ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, báwo la sì ṣe mọ̀? (b) Ṣé ọ̀kan náà ni Hédíìsì àti ọ̀gbun àìnísàlẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
7 Ṣé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò máa báṣẹ́ lọ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà? Ó dáa, ṣó o rántí ẹranko ẹhànnà olórí méje, aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà tó ‘ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò sí, síbẹ̀ tó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀’? (Ìṣípayá 17:8) Nígbà tí ẹranko náà wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, “kò sí.” Ó jẹ́ aláìlè-ṣiṣẹ́, aláìlè-ta-pútú, ká kúkú sọ pé ó ti kú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó ní: “‘Ta ni yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀?’ èyíinì ni, láti mú Kristi gòkè wá láti inú òkú.” (Róòmù 10:7) Nígbà tí Jésù wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ yẹn, òkú ni. a Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò ní lè ṣe ohunkóhun, wọ́n á dà bí òkú fún ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n máa lò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Ẹ ò rí i pé ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn olùfẹ́ òdodo!
Àwọn Onídàájọ́ fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún
8, 9. Kí ni Jòhánù sọ fún wa nípa àwọn tó jókòó sórí ìtẹ́, ta sì ni wọ́n?
8 Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún náà, a óò tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún àkókò kúkúrú. Nítorí kí ni? Kí Jòhánù tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún náà, ó ní: “Mo sì rí àwọn ìtẹ́, àwọn tí ó jókòó lórí wọn sì ń bẹ, a sì fún wọn ní agbára ṣíṣèdájọ́.” (Ìṣípayá 20:4a) Àwọn wo làwọn tó jókòó lórí ìtẹ́ tí wọ́n sì ń ṣàkóso ní ọ̀run pẹ̀lú Jésù tá a ti ṣe lógo?
9 Àwọn ni “àwọn ẹni mímọ́” tí Dáníẹ́lì sọ pé wọ́n ń ṣàkóso nínú Ìjọba pẹ̀lú Ẹnì kan “bí ọmọ ènìyàn.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 18) Wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] tó jókòó lórí ìtẹ́ ọ̀run ní iwájú Jèhófà gan-an. (Ìṣípayá 4:4) Àwọn àpọ́sítélì méjìlá [12] wà lára wọn, àwọn ni Jésù ṣèlérí fún pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Mátíù 19:28) Pọ́ọ̀lù náà wà lára wọn, àtàwọn Kristẹni ará Kọ́ríńtì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (1 Kọ́ríńtì 4:8; 6:2, 3) Àwọn tó ṣẹ́gun nínú àwọn ará ìjọ Laodíkíà yóò wà lára wọn pẹ̀lú.—Ìṣípayá 3:21.
10. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe wá ṣàpèjúwe àwọn ọba tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]? (b) Látinú ohun tí Jòhánù ti sọ fún wa tẹ́lẹ̀, àwọn wo ló wà lára àwọn ọba tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] yìí?
10 Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ìtẹ́ la pèsè sílẹ̀ fáwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ aṣẹ́gun wọ̀nyí, ìyẹn àwọn tá a “rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 14:1, 4) Jòhánù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo rí ọkàn àwọn tí a fi àáké pa nítorí ẹ̀rí Jésù tí wọ́n jẹ́ àti nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà tàbí ère rẹ̀ àti àwọn tí kò gba àmì náà sí iwájú orí wọn àti sí ọwọ́ wọn.” (Ìṣípayá 20:4b) Nítorí náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ajẹ́rìíkú wà lára àwọn ọba wọ̀nyẹn. Àtìgbà tá a ti ṣí èdìdì karùn-ún làwọn ajẹ́rìíkú wọ̀nyí ti ń béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé báwo ni yóò ṣe dúró pẹ́ tó kó tó gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn. Lákòókò yẹn, a fún wọn ní aṣọ funfun kan a sì sọ fún wọn pé kí wọ́n dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa ti bá wọn gbẹ̀san nípa pípa Bábílónì Ńlá run, nípa pípa àwọn orílẹ̀-èdè run, àti nípa gbígbé Sátánì jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.—Ìṣípayá 6:9-11; 17:16; 19:15, 16.
11. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká lóye gbólóhùn náà, “fi àáké pa”? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ló kú ikú ìrúbọ?
11 Ǹjẹ́ gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] yìí tí wọ́n jẹ́ ọba àti onídàájọ́ ni wọ́n “fi àáké pa”? Ó jọ bí ẹni pé àwọn díẹ̀ lára wọn ni. Àmọ́ a lo gbólóhùn yìí láti fi kó gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n fara da ikú ajẹ́rìíkú ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn pa pọ̀. b (Mátíù 10:22, 28) Dájúdájú, Sátánì yóò fẹ́ láti fi àáké pa gbogbo wọn, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù ni wọ́n kú bí ajẹ́rìíkú. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló kú nítorí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó. Bó ti wù kó rí, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú wà lára àwùjọ tí Jòhánù wá rí báyìí. Lọ́rọ̀ kan, gbogbo wọn ló kú ikú ìrúbọ. (Róòmù 6:3-5) Yàtọ̀ síyẹn, kò sí ìkankan nínú wọn tó jẹ́ apá kan ayé. Ìdí nìyẹn tí ayé fi kórìíra gbogbo wọn, ká kúkú sọ pé wọ́n ti di òkú lójú ayé. (Jòhánù 15:19; 1 Kọ́ríńtì 4:13) Kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà tàbí ère rẹ̀, nígbà tí wọ́n sì kú, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó ní àmì ẹranko ẹhànnà náà lára. Gbogbo wọn ló kú gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun.—1 Jòhánù 5:4; Ìṣípayá 2:7; 3:12; 12:11.
12. Kí ni Jòhánù sọ nípa àwọn ọba tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ìgbà wo sì ni wíwá tí wọ́n wá sí ìyè ṣẹlẹ̀?
12 Wàyí o, àwọn aṣẹ́gun wọ̀nyí tún wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i! Jòhánù sọ pé: “Wọ́n sì wá sí ìyè, wọ́n sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún.” (Ìṣípayá 20:4d) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn onídàájọ́ wọ̀nyí kò ní jíǹde títí dìgbà tá a bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run tán tá a sì gbé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀? Rárá o. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti wà láàyè báyìí níwọ̀n bí wọ́n ti gẹṣin pẹ̀lú Jésù láti bá àwọn orílẹ̀-èdè jà ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 2:26, 27; 19:14) Kódà, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àjíǹde wọn bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn tí wíwàníhìn-ín Jésù bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 àti pé a jí àwọn kan dìde ṣáájú àwọn yòókù. (1 Kọ́ríńtì 15:51-54; 1 Tẹsalóníkà 4:15-17) Nítorí náà, wíwá tí wọ́n wá sí ìyè yìí ṣẹlẹ̀ ní sáà àkókò tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń gba ẹ̀bùn ìyè àìleèkú ní ọ̀run.—2 Tẹsalóníkà 1:7; 2 Pétérù 3:11-14.
13. (a) Kí ló yẹ kó jẹ́ èrò wa nípa ẹgbẹ̀rún ọdún táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì fi máa ṣàkóso, kí sì nìdí? (b) Kí ni èrò Papias ti Hierapolis nípa ẹgbẹ̀rún ọdún náà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
13 Ẹgbẹ̀rún ọdún ni wọ́n fi máa jọba tí wọ́n á sì ṣe ìdájọ́. Ṣé ẹgbẹ̀rún ọdún gidi lèyí àbí ká kàn wò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí àkókò gígùn kan tí a kò sọ iye rẹ̀ ní pàtó? “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún” lè túmọ̀ sí iye tó pọ̀, tí kò ṣe pàtó, gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú 1 Sámúẹ́lì 21:11. Àmọ́ “ẹgbẹ̀rún” gidi là ń sọ níhìn-ín, nítorí pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la pè é ní “ẹgbẹ̀rún ọdún náà” nínú Ìṣípayá 20:5-7. Pọ́ọ̀lù pe àkókò ìdájọ́ yìí ní “ọjọ́ kan” nígbà tó sọ pé: “Ó [Ọlọ́run] ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo.” (Ìṣe 17:31) Níwọ̀n bí Pétérù ti sọ fún wa pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún, ó bá a mu wẹ́kú pé Ọjọ́ Ìdájọ́ yìí ní láti jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún. c—2 Pétérù 3:8.
Ìyókù Àwọn Òkú
14. (a) Gbólóhùn ọ̀rọ̀ wo ni Jòhánù fi kún ọ̀rọ̀ tó sọ nípa “ìyókù àwọn òkú” náà? (b) Báwo làwọn ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ náà “wá sí ìyè”?
14 Ṣùgbọ́n, àwọn wo làwọn ọba wọ̀nyí yóò dá lẹ́jọ́ bọ́rọ̀ bá rí bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe fi kún un pé, “(ìyókù àwọn òkú kò wá sí ìyè títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà fi dópin)”? (Ìṣípayá 20:5a) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọ̀rọ̀ náà, “wá sí ìyè,” la ní láti lóye ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká. Ọ̀rọ̀ yìí lè ní onírúurú ìtumọ̀ ní onírúurú ibi tó bá ti fara hàn. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn Kristẹni tí wọ́n jọ jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Ẹ̀yin ni Ọlọ́run sọ di ààyè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” (Éfésù 2:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí yàn ni a “sọ di ààyè,” kódà ní ọ̀rúndún kìíní, níwọ̀n bá a ti polongo wọn ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ Jésù.—Róòmù 3:23, 24.
15. (a) Báwo làwọn tó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run? (b) Báwo làwọn àgùntàn mìíràn ṣe “wá sí ìyè,” ìgbà wo sì ni wọn yóò ni ilẹ̀ ayé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
15 Bákan náà, àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé la polongo ní olódodo ní ti pé wọ́n bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́; àti pé Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù la sọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí “alààyè” bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú. (Mátíù 22:31, 32; Jákọ́bù 2:21, 23) Bó ti wù kó rí, àwọn àti gbogbo àwọn ìyókù tí wọ́n á jí dìde, pa pọ̀ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àgùntàn mìíràn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já àti ọmọ èyíkéyìí tí wọ́n bá bí nínú ayé tuntun, ni a óò sọ di ẹni pípé. Ọlọ́run yóò lo Kristi àtàwọn tí yóò jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún náà láti ṣe èyí lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Nígbà tó bá fi máa di òpin Ọjọ́ yẹn, “ìyókù àwọn òkú” yóò ti “wá sí ìyè” ní ti pé wọ́n á di ẹni pípé. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i, wọ́n gbọ́dọ̀ yege ìdánwò ìkẹyìn, ṣùgbọ́n wọ́n á ti di ẹni pípé ṣáájú ìgbà ìdánwò náà. Nígbà tí wọ́n bá yege ìdánwò náà, Ọlọ́run yóò polongo wọn ní ẹni tó yẹ láti wà láàyè títí láé, tó sì jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà. Wọ́n á wà níbẹ̀ nígbà tí ìlérí Ọlọ́run bá nímùúṣẹ láìkù síbi kankan. Ìlérí náà ni pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Ẹ ò rí i pé ọjọ́ iwájú máa dùn gan-an fáwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn!
Àjíǹde Èkíní
16. Kí ni Jòhánù pe àjíǹde àwọn tó máa bá Kristi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, kí sì nìdí?
16 Nígbà tí Jòhánù tún ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó “wá sí ìyè [tí] wọ́n sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi,” ó kọ̀wé pé: “Èyí ni àjíǹde èkíní.” (Ìṣípayá 20:5b) Báwo ló ṣe jẹ́ èkíní? Ó jẹ́ “àjíǹde èkíní” ní ti àkókò tó wáyé, nítorí pé àwọn tó jíǹde náà jẹ́ “àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 14:4) Ó tún jẹ́ èkíní ní ti ìjẹ́pàtàkì, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn tí àjíǹde náà kàn yóò bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run, wọ́n á sì ṣèdájọ́ ìyókù aráyé. Lákòótán, ó tún jẹ́ èkíní ní ti pé òun ló dára jù lọ. Yàtọ̀ sí Jésù Kristi fúnra rẹ̀, àwọn tá a jí dìde nínú àjíǹde èkíní nìkan làwọn ẹ̀dá tí Bíbélì sọ pé ó gba àìleèkú.—1 Kọ́ríńtì 15:53; 1 Tímótì 6:16.
17. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ohun àgbàyanu táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń retí? (b) Kí ni “ikú kejì,” kí sì nìdí tí kò fi ní “àṣẹ kankan” lórí àwọn aṣẹ́gun tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì?
17 Ẹ ò rí i pé ìrètí aláyọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí! Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ti sọ: “Aláyọ̀ àti mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní; ikú kejì kò ní àṣẹ kankan lórí àwọn wọ̀nyí.” (Ìṣípayá 20:6a) Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Jésù ṣe fáwọn Kristẹni tó wà ní Símínà, àwọn aṣẹ́gun tó nípìn-ín nínú “àjíǹde èkíní” náà yóò bọ́ lọ́wọ́ ewu “ikú kejì,” èyí tó túmọ̀ sí ìparẹ́, ìparun yán-ányán-án láìsí ìrètí àjíǹde. (Ìṣípayá 2:11; 20:14) Ikú kejì “kò ní àṣẹ kankan” lórí irú àwọn aṣẹ́gun bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọ́n á ti gbé àìdíbàjẹ́ àti àìleèkú wọ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:53.
18. Kí ni Jòhánù wá sọ nípa àwọn tó máa ṣàkóso lórí ayé, kí ni wọ́n sì máa gbé ṣe?
18 Ẹ ò rí i pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ọba ilẹ̀ ayé tó ń ṣàkóso lákòókò tí Sátánì ṣì ń lo ọlá àṣẹ rẹ̀ yìí! Ó pọ̀ a ò rírú ẹ̀ rí, nǹkan bí àádọ́ta tàbí ọgọ́ta ọdún làwọn wọ̀nyí fi ń ṣàkóso, kódà ọdún díẹ̀ péré lèyí tó pọ̀ jù lára wọn ń lò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti ni àwọn èèyàn lára. Ǹjẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè lè jàǹfààní tó wà pẹ́ títí lábẹ́ àwọn alákòóso tó ń yí padà nígbà gbogbo, táwọn ìlànà wọn pẹ̀lú sì ń yí padà nígbà gbogbo? Rárá. Àmọ́, ohun tí Jòhánù sọ nípa àwọn tó máa ṣàkóso lórí ayé yàtọ̀ sí ìyẹn, ó ní: “Ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6b) Àwọn àti Jésù yóò jùmọ̀ dá ìjọba kan ṣoṣo sílẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Iṣẹ́ ìsìn wọn bí àlùfáà tó máa mú kí wọ́n lo àǹfààní ẹbọ tí Jésù fi ara èèyàn pípé rẹ̀ rú, yóò sọ àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn di pípé nípa tẹ̀mí, nípa tara àti ní ti ìwà híhù. Iṣẹ́ ìsìn wọn bí ọba yóò yọrí sí fífi ìdí àwùjọ èèyàn kan kárí ayé múlẹ̀, èyí tó máa fi òdodo àti ìjẹ́mímọ́ Jèhófà hàn. Iṣẹ́ onídàájọ́ tí wọ́n máa ṣe fún ẹgbẹ̀rún ọdún yóò mú káwọn àti Jésù fìfẹ́ ṣamọ̀nà àwọn èèyàn tó jẹ elétí ọmọ dé ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 3:16.
Ìdánwò Ìkẹyìn Náà
19. Ipò wo ni ilẹ̀ ayé àti aráyé yóò wà nígbà tó bá fi máa di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà, kí ni Jésù yóò wá ṣe?
19 Nígbà tó bá fi máa di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò ti dà bí Édẹ́nì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Yóò jẹ́ ojúlówó párádísè kan ní tòótọ́. Aráyé tó ti di pípé kò tún ní nílò àlùfáà àgbà tí yóò máa bá a bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọ́run mọ́, níwọ̀n bí a ó ti mú gbogbo ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kúrò tí a ó sì sọ ọ̀tá ìkẹyìn, ìyẹn ikú, dòfo. Ìjọba Kristi yóò ti ṣàṣeyọrí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, ìyẹn ni láti mú kí ayé jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo. Ìgbà yẹn gan-an ni Jésù yóò wá fi “ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:22-26; Róòmù 15:12.
20. Kí ni Jòhánù sọ fún wa pé yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí àkókò ìdánwò ìkẹyìn bá tó?
20 Lẹ́yìn náà, àkókò ìdánwò ìkẹyìn á wá dé. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn tá a ti sọ di pípé yóò pa ìwà títọ́ wọn mọ́ kí wọ́n sì ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn àkọ́kọ́ ní Édẹ́nì? Jòhánù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa, ó ní: “Wàyí o, gbàrà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá ti dópin, a óò tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀, yóò sì jáde lọ láti ṣi orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọpọ̀ fún ogun. Iye àwọn wọ̀nyí rí bí iyanrìn òkun. Wọ́n sì rìn jìnnà kárí ìbú ilẹ̀ ayé, wọ́n sì pagbo yí ká ibùdó àwọn ẹni mímọ́ àti ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—Ìṣípayá 20:7-9a.
21. Kí ni Sátánì máa ṣe bó bá ṣe ń sapá rẹ̀ ìkẹyìn, kí sì nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn kan yóò tẹ̀ lé Sátánì kódà lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà?
21 Kí ló máa jẹ́ àbájáde ìsapá ìkẹyìn tí Sátánì máa ṣe yìí? Yóò tan ‘orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé jẹ, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù,’ yóò sì ṣamọ̀nà wọn lọ sínú “ogun.” Ǹjẹ́ ẹnì kan tún lè gbè sẹ́yìn Sátánì lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Ọlọ́run tí yóò máyọ̀ wá tí yóò sì gbéni ró? Tóò, má ṣe gbàgbé pé ó ṣeé ṣe fún Sátánì láti ṣi Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé lọ́nà nígbà tí wọ́n ń gbádùn ìwàláàyè nínú Párádísè ọgbà Édẹ́nì. Ó sì ṣeé ṣe fún un láti ṣi àwọn áńgẹ́lì ọ̀run lọ́nà lẹ́yìn tí wọ́n ti rí àbájáde búburú tó tẹ̀yìn ọ̀tẹ̀ tó kọ́kọ́ wáyé lọ́gbà Édẹ́nì yọ. (2 Pétérù 2:4; Júúdà 6) Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn ènìyàn pípé kan yóò tẹ̀ lé Sátánì kódà lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún aládùn ti ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.
22. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé” túmọ̀ sí? (b) Kí nìdí tá a fi pe àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ní “Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù”?
22 Bíbélì pe àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí ní “orílẹ̀-èdè wọnnì ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.” Èyí kò túmọ̀ sí pé a óò tún pín aráyé yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dá dúró. Ó wulẹ̀ fi hàn pé àwọn wọ̀nyí yóò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó jẹ olódodo àti adúróṣinṣin sí Jèhófà, wọn á sì fi ẹ̀mí búburú kan náà hàn, ìyẹn ẹ̀mí táwọn orílẹ̀-èdè ń fi hàn lónìí. Wọn yóò “gbìrò ìpètepèrò tí ń ṣeni léṣe,” gẹ́gẹ́ bí Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù inú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ti ṣe, pẹ̀lú èrò láti pa ìjọba Ọlọ́run run lórí ilẹ̀ ayé. (Ìsíkíẹ́lì 38:3, 10-12) Ìdí nìyẹn tá a fi pè wọ́n ní “Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù.”
23. Kí ni bí iye àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe rí “bí iyanrìn òkun” túmọ̀ sí?
23 Iye àwọn tó dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ yóò rí “bí iyanrìn òkun.” Mélòó nìyẹn? Ọlọ́run ò pinnu iye kankan. (Fi wé Jóṣúà 11:4; Onídàájọ́ 7:12.) Àròpọ̀ gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà níkẹyìn yóò sinmi lórí ọwọ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá fi mú ìtànjẹ Sátánì. Láìsí àní-àní, iye náà yóò pọ̀, nítorí pé wọ́n á rò pé àwọn lágbára tó láti ṣẹ́pá “ibùdó àwọn ẹni mímọ́ àti ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”
24. (a) Kí ni “ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” náà báwo ni wọ́n sì ṣe lè pagbo yí i ká? (b) Kí ni “ibùdó àwọn ẹni mímọ́” dúró fún?
24 “Ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n” náà ní láti jẹ́ ìlú ńlá tí Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Ìṣípayá 3:12. Ìlú náà ló tún pè ní “ìlú ńlá Ọlọ́run mi, Jerúsálẹ́mù tuntun tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi.” Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ ètò ti ọ̀run, báwo ló ṣe wá ṣeé ṣe fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun orí ilẹ̀ ayé wọ̀nyẹn láti ‘pagbo yí i ká’? Ní ti pé wọ́n pagbo yí ká “ibùdó àwọn ẹni mímọ́.” Ibùdó máa ń wà lẹ́yìn òde ìlú; nítorí náà, “ibùdó àwọn ẹni mímọ́” ní láti dúró fún àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n ò sí ní òkè ọ̀run níbi tí Jerúsálẹ́mù Tuntun wà, àmọ́ tí wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin ṣètìlẹyìn fún ìṣètò ìjọba Jèhófà. Nígbà táwọn ọlọ̀tẹ̀ tó wà lábẹ́ Sátánì bá gbéjà ko àwọn olóòótọ́ wọ̀nyẹn, Jésù Olúwa yóò kà á sí pé òun ni wọ́n gbéjà kò. (Mátíù 25:40, 45) “Orílẹ̀-èdè wọnnì” yóò gbìyànjú láti mú gbogbo ohun tí Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ọ̀run ti ṣe láti sọ ilẹ̀ ayé di párádísè kúrò. Nítorí náà, bí wọ́n ṣe ń gbéjà ko “ibùdó àwọn ẹni mímọ́,” ńṣe ni wọ́n ń gbéjà ko “ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n” náà.
Adágún Iná àti Imí Ọjọ́
25. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe àbájáde ogun táwọn ọlọ̀tẹ̀ gbé ti “ibùdó àwọn ẹni mímọ́,” kí ni yóò sì jẹ́ àbájáde èyí fún Sátánì?
25 Ǹjẹ́ ipá tí Sátánì máa sà kẹ́yìn yìí á kẹ́sẹ járí? Ó dájú pé kò ní kẹ́sẹ járí. Bẹ́ẹ̀ náà ni ogun tí Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù máa gbé ti Ísírẹ́lì tẹ̀mí lákòókò tiwa yìí kò ní kẹ́sẹ járí! (Ìsíkíẹ́lì 38:18-23) Jòhánù ṣàpèjúwe àbájáde náà lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Ṣùgbọ́n iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá, ó sì jẹ wọ́n run. A sì fi Èṣù tí ń ṣì wọ́n lọ́nà sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko ẹhànnà náà àti wòlíì èké náà ti wà nísinsìnyí.” (Ìṣípayá 20:9b-10a) Dípò kí Jésù kàn wulẹ̀ gbé Sátánì tí í ṣe ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí ńṣe ló máa tẹ̀ ẹ́ rẹ́ tí kò fi ní sí mọ́, á lọ̀ ọ́ lúúlúú, á pa á rẹ́ ráúráú bí ẹní fi iná sun ún.
26. Kí nìdí tí “adágún iná àti imí ọjọ́” kò fi lè jẹ́ ibi ìdálóró?
26 A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé “adágún iná àti imí ọjọ́” kò lè jẹ́ ibi ìdálóró. (Ìṣípayá 19:20) Tó bá jẹ́ pé Sátánì á máa jìyà ìdálóró tó lékenkà níbẹ̀ títí ayérayé, a jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ kó wà láàyè nìyẹn. Bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn ni ìwàláàyè jẹ́, kì í ṣe ìyà. Ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀, Bíbélì sì sọ pé, àwọn ẹ̀dá tó ti kú kò lè jẹ̀rora kankan mọ́. (Róòmù 6:23; Oníwàásù 9:5, 10) Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún kà á lẹ́yìn náà pé ikú fúnra rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú Hédíìsì, la gbé jù sínú adágún iná àti imí ọjọ́ kan náà yìí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó dájú pé ikú àti Hédíìsì kò lè jẹ̀rora!—Ìṣípayá 20:14.
27. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sódómù àti Gòmórà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ọ̀rọ̀ náà adágún iná àti imí ọjọ́?
27 Gbogbo èyí túbọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé adágún iná àti imí ọjọ́ jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ. Síwájú sí i, mímẹ́nukan iná àti imí ọjọ́ ránni létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sódómù àti Gòmórà ìgbàanì, àwọn tí Ọlọ́run pa run nítorí pé ìwà wọn burú kọjá ààlà. Nígbà tí àkókò wọn dé, “Jèhófà mú kí òjò imí ọjọ́ àti iná rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ọ̀run, sórí Sódómù àti sórí Gòmórà.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:24) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìlú méjèèjì náà la pè ní “ìyà ìdájọ́ iná àìnípẹ̀kun.” (Júúdà 7) Síbẹ̀, kì í ṣe pé ìlú méjèèjì yẹn ń jìyà ìdálóró àìnípẹ̀kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, a pa wọ́n rẹ́ kúrò, a pa wọ́n run tèfètèfè, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùgbé inú wọn tí wọ́n jẹ́ oníwà ìbàjẹ́. Àwọn ìlú yẹn kò sí mọ́ lónìí, kò sì sí ẹnì kankan tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun mọ ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀.
28. Kí ni adágún iná àti imí ọjọ́, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí ikú, Hédíìsì, àti ọ̀gbun àìnísàlẹ̀?
28 Lọ́nà tó bá èyí mu, Bíbélì fúnra rẹ̀ ṣàlàyé ìtumọ̀ adágún iná àti imí ọjọ́ pé: “Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.” (Ìṣípayá 20:14) Lọ́nà tó ṣe kedere, ohun kan náà ni adágún iná yìí àti Gẹ̀hẹ́nà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó jẹ́ ibi ìparun ayérayé fáwọn ẹni ibi, kì í ṣe ibi tá a ti ń dá wọn lóró títí láé. (Mátíù 10:28) Ó jẹ́ ìparun pátápátá, láìsí ìrètí àjíǹde. Abájọ tí kọ́kọ́rọ́ fi wà fún ikú, Hédíìsì, àti ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, àmọ́ tí Bíbélì ò mẹ́nu kan kọ́kọ́rọ́ kankan tó wà fún ṣíṣí adágún iná àti imí ọjọ́. (Ìṣípayá 1:18; 20:1) Adágún iná náà kò ní tú àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láé.—Fi wé Máàkù 9:43-47.
Wọ́n Ń Joró Tọ̀sán-Tòru Títí Láé
29, 30. Kí ni Jòhánù sọ nípa Èṣù àti ẹranko ẹhànnà àti wòlíì èké náà, báwo ló sì ṣe yẹ ká lóye èyí?
29 Nígbà tí Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa Èṣù àti ẹranko ẹhànnà àti wòlíì èké náà, ó sọ fún wa pé: “A ó sì máa mú wọn joró tọ̀sán-tòru títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 20:10b) Kí ni èyí lè túmọ̀ sí? Gẹ́gẹ́ bá a ti mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, kò bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, bí ẹranko ẹhànnà àti wòlíì èké, títí kan ikú àti Hédíìsì, lè jìyà ìdálóró ní ti gidi. Nítorí náà, a kò nídìí kankan láti gbà gbọ́ pé Sátánì yóò máa jìyà títí ayérayé. Ńṣe ni a óò pa á rẹ́ ráúráú.
30 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ba·sa·niʹzo, tá a lò níhìn-ín fún “ìdálóró,” túmọ̀ sí “láti fi òdiwọ̀n dán ìjójúlówó (irin) wò.” Ìtumọ̀ kejì ni “láti wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu èèyàn nípasẹ̀ lílo ìdálóró.” (Ìwé The New Thayer’s Greek-English Lexicon of the New Testament) Nínú àyíká ọ̀rọ̀ náà, ìlò ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sátánì la óò máa lò títí láé gẹ́gẹ́ bí òdiwọ̀n nínú ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti máa ṣàkóso àti jíjẹ́ tí ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọ̀ràn nípa ìṣàkóso ọba aláṣẹ àgbáyé la óò ti yanjú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tí a kò tún ní yanjú rẹ̀ mọ́ láé. Láéláé, kò tún ní sí pé Jèhófà ń lo àkókò gígùn kó tó lè fi hàn pé ìpèníjà tí ẹnikẹ́ni bá gbé dìde sí ipò òun gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kò tọ́.—Fi wé Sáàmù 92:1, 15.
31. Báwo ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì tó tan mọ́ èyí tó túmọ̀ sí “ìdálóró” ṣe jẹ́ ká lóye ìyà tí Sátánì Èṣù yóò jẹ?
31 Láfikún sí i, ọ̀rọ̀ tó tan mọ́ ọn, ìyẹn ba·sa·ni·stesʹ, “adánilóró,” ló túmọ̀ sí “onítúbú” nínú Bíbélì. (Mátíù 18:34, Kingdom Interlinear) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, a óò sé Sátánì mọ́ inú adágún iná títí láé; a kì yóò tú u sílẹ̀ láé. Lákòótán, nínú Septuagint lédè Gíríìkì, èyí tí Jòhánù mọ̀ dáadáa, ọ̀rọ̀ tó tan mọ́ ọn, baʹsa·nos, ni a lò láti tọ́ka sí ìtẹ́nilógo tàbí ẹ̀tẹ́ tó ń yọrí sí ikú. (Ìsíkíẹ́lì 32:24, 30) Èyí jẹ́ ká rí i pé ìyà tí Sátánì máa jẹ́ ni ikú ẹ̀sín, ikú àìnípẹ̀kun nínú adágún iná àti imí ọjọ́. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yóò kú pẹ̀lú rẹ̀.—1 Jòhánù 3:8.
32. Ìyà wo ni àwọn ẹ̀mí èṣù yóò jẹ, báwo la sì ṣe mọ̀?
32 Ẹsẹ yìí pẹ̀lú kò mẹ́nu kan àwọn ẹ̀mí èṣù. Ṣé a máa tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú Sátánì ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà ni, ṣé wọ́n á sì jẹ ìyà ikú àìnípẹ̀kun pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn náà? Ẹ̀rí fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni. Nínú òwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, Jésù sọ pé àwọn ewúrẹ́ yóò lọ̀ “sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Mátíù 25:41) Ọ̀rọ̀ náà “iná àìnípẹ̀kun” ní láti tọ́ka sí adágún iná àti imí ọjọ́ níbi tí a óò fi Sátánì sọ̀kò sí. Àwọn áńgẹ́lì Èṣù ni a lé jáde kúrò ní ọ̀run pẹ̀lú rẹ̀. Ó hàn gbangba pé, wọ́n bá a lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà. Bákan náà ni wọn yóò ṣe pa run pẹ̀lú rẹ̀ nínú adágún iná àti imí ọjọ́.—Mátíù 8:29.
33. Èwo ló kù nínú àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 tó máa wá nímùúṣẹ, ọ̀ràn wo sì ni ẹ̀mí Jèhófà darí àfiyèsí Jòhánù sí báyìí?
33 Lọ́nà yìí, èyí tó kù nínú àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 á wá nímùúṣẹ. Nígbà tá a bá fi Sátánì sọ̀kò sínú adágún iná, yóò kú pátápátá gẹ́gẹ́ bí ejò tí a fi gìgísẹ̀ irin lọ orí rẹ̀. Òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò ní sí mọ́ láé. Kò síbi tá a tún ti mẹ́nu kàn wọ́n mọ́ nínú ìwé Ìṣípayá. Ní báyìí tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé àwọn wọ̀nyí á pa run, ẹ̀mí Jèhófà wá darí àfiyèsí Jòhánù sí ọ̀ràn kan tó kan àwọn tó ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé gbọ̀ngbọ̀n. Ọ̀ràn náà ni pé: Kí ni ìjọba ọ̀run ti “Ọba àwọn ọba” àti ti “àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀” máa ṣe fún ọmọ aráyé? (Ìṣípayá 17:14) Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, Jòhánù dá wa padà lẹ́ẹ̀kan sí i sí ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn sọ pé Jésù wà nínú Hédíìsì nígbà tó kú. (Ìṣe 2:31) Àmọ́, a kò ní láti rò pé gbogbo ìgbà ni Hédíìsì àti ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà. Nígbà tó jẹ́ pé inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni ẹranko ẹhànnà náà àti Sátánì lọ, kìkì àwọn ènìyàn ni Bíbélì sọ pé ó máa ń lọ sí Hédíìsì, níbi tí wọ́n ti ń sùn nínú ikú títí di ìgbà àjíǹde wọn.—Jóòbù 14:13; Ìṣípayá 20:13.
b Ó jọ pé àáké (peʹle·kus lédè Gíríìkì) làwọn ará Róòmù fi máa ń pa èèyàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé idà ni wọ́n ń lò jù lọ nígbà ayé Jòhánù. (Ìṣe 12:2) Nítorí náà, ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, pe·pe·le·kis·meʹnon (“fi àáké pa”), tá a lò níhìn-ín wulẹ̀ túmọ̀ sí ni “fi ikú pa.”
c Ó dùn mọ́ni pé Eusebius tó jẹ́ òpìtàn ọ̀rúndún kẹrin sọ pé Papias ará Hierapolis, tá a gbọ́ pé ó gba díẹ̀ lára ìmọ̀ Bíbélì tó ní látọ̀dọ̀ àwọn tí Jòhánù, tó kọ ìwé Ìṣípayá, kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gbà gbọ́ pé ẹgbẹ̀rún ọdún gidi ni Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi (bó tilẹ̀ jẹ́ pé Eusebius fúnra rẹ̀ kò gbà pé òótọ́ lohun tí Papias sọ yìí).—ÌwéThe History of the Church, Eusebius, III, 39.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 293]
Òkun Òkú. Ibi tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀gangan ibi tí Sódómù àti Gòmórà wà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 294]
“Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀”