Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tún Padà Ní Ìfẹ́ Tó O Ní Níṣàájú!

Tún Padà Ní Ìfẹ́ Tó O Ní Níṣàájú!

Orí 7

Tún Padà Ní Ìfẹ́ Tó O Ní Níṣàájú!

ÉFÉSÙ

1. Ìjọ wo ló ni àkọ́kọ́ lára iṣẹ́ tí Jésù fi rán Jòhánù, kí ni Jésù sì rán àwọn alábòójútó létí rẹ̀?

 ÌJỌ tó wà ní Éfésù ló gba iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Jésù fi rán Jòhánù. Ní àkókò yẹn, Éṣíà Kékeré ni ìlú Éfésù wà, ó ń gbèrú, ìlú etíkun ni, ìtòsí erékùṣù Pátímọ́sì ló sì wà. Jésù pàṣẹ fún Jòhánù pé: “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Éfésù pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹni tí ó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà. (Ìṣípayá 2:1) Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, ó pe àfiyèsí sí ọ̀kan lára àwọn ohun tó fi ipò àṣẹ tó wà hàn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ tó rán sí ìjọ mẹ́fà tó kù. Ó rán àwọn alábòójútó ní Éfésù létí pé abẹ́ àbójútó àti ààbò òun ni gbogbo alàgbà wà àti pé òun ń bẹ gbogbo ìjọ wò. Títí di àkókò tá a wà yìí, Jésù ń bá a lọ láti fìfẹ́ lo ipò orí rẹ̀, ó ń fìṣọ́ ṣọ́ àwọn alàgbà ó sì ń finúure ṣolùṣọ́ àgùntàn gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ. Látìgbàdégbà, ó ń ṣe àtúnṣe sí ètò ìjọ kí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí lè máa túbọ̀ mọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ni Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn agbo Ọlọ́run.—Mátíù 11:28-30; 1 Pétérù 5:2-4.

2. (a) Àwọn ohun rere wo ni Jésù tìtorí rẹ̀ gbóríyìn fún ìjọ Éfésù? (b) Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wo ló hàn gbangba pé àwọn alàgbà Éfésù tẹ̀ lé?

2 Lẹ́yìn náà Jésù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún gbogbo wa nípa fífi ìgbóríyìn bẹ̀rẹ̀ márùn-ún lára iṣẹ́ tó rán sí ìjọ méje náà. Iṣẹ́ tó rán sí àwọn ará Éfésù ni pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti òpò àti ìfaradà rẹ, àti pé ìwọ kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra, àti pé ìwọ ti dán àwọn tí wọ́n sọ pé àpọ́sítélì ni àwọn wò, ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, o sì rí wọn ní òpùrọ́. Ìwọ ń fi ìfaradà hàn pẹ̀lú, o sì ti rọ́jú nítorí orúkọ mi, àárẹ̀ kò sì mú ọ.” (Ìṣípayá 2:2, 3) Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ Éfésù nípa “àwọn aninilára ìkookò,” ìyẹn àwọn apẹ̀yìndà tí ń yọ agbo lẹ́nu, ó sì sọ fáwọn alàgbà náà pé kí wọ́n “máa wà lójúfò” nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ àìṣàárẹ̀ tòun. (Ìṣe 20:29, 31) Bí Jésù ṣe wá gbóríyìn fún wọn nísinsìnyí fún iṣẹ́ takuntakun, ìfaradà àti àìṣàárẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé wọ́n ti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò.

3. (a) Báwo làwọn “èké àpọ́sítélì” ṣe wá ọ̀nà láti tan àwọn olùṣòtítọ́ jẹ ní àkókò wa yìí? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Pétérù fúnni nípa àwọn apẹ̀yìndà?

3 Ní ọjọ́ Olúwa pẹ̀lú, àwọn “èké àpọ́sítélì” tí wọ́n ń “sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn” ti fara hàn. (2 Kọ́ríńtì 11:13; Ìṣe 20:30; Ìṣípayá 1:10) Lójú wọn, gbogbo àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ìmọ̀ wọn ò ṣọ̀kan ló dára, wọ́n sọ pé Ọlọ́run ò ní ètò kankan, wọ́n sì sọ pé Jésù kò gba agbára Ìjọba ní 1914. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú 2 Pétérù 3:3, 4 ṣẹ sí wọn lára. Ó kà pé: “Nítorí ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’”

4. (a) Báwo ni ìgbéraga àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn apẹ̀gàn ṣe fara hàn gbangba? (b) Láti fi hàn pé à ń ṣe bíi tàwọn ará Éfésù, kí làwa Kristẹni lónìí máa ń ṣe fáwọn alátakò tó ń parọ́?

4 Àwọn ẹlẹ́gàn wọ̀nyí ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn ò lè máa lọ polongo ìgbàgbọ́ àwọn fáwọn èèyàn. (Róòmù 10:10) Wọ́n wá ìtìlẹyìn àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n tún wá ìrànlọ́wọ́ àwọn ìwé ìròyìn àti ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n láti tan ìròyìn èké kálẹ̀ nípa àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Kò pẹ́ táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ fi rí i pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn ẹlẹ́tàn wọ̀nyí àti pé ìwà wọn kò bá òtítọ́ mu. Bíi tàwọn ará Éfésù, àwa Kristẹni lónìí “kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra,” nítorí náà à ń yọ wọ́n lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ. a

5. (a) Àìlera wo ni Jésù sọ pé àwọn ará Éfésù ní? (b) Ọ̀rọ̀ wo ló yẹ kí àwọn ará Éfésù ti rántí?

5 Àmọ́, Jésù tọ́ka sí ìṣòro ńlá kan, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe nínú iṣẹ́ tó rán sí márùn-ún lára ìjọ méje náà. Ó sọ fáwọn ará Éfésù pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣípayá 2:4) Kò yẹ kó jẹ́ pé lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ni wọ́n á ti kùnà, nítorí ní ọdún márùndínlógójì [35] ṣáájú ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn ó sì sọ nípa ‘ìfẹ́ ńlá tí’ Ọlọ́run “fi nífẹ̀ẹ́ wa,” ó wá rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín.” (Éfésù 2:4; 5:1, 2) Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sọ́kàn, pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo, kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:29-31) Àwọn ará Éfésù kò ní ìfẹ́ tí wọ́n ní níṣàájú mọ́.

6. (a) Yálà ó ti pẹ́ tá a ti wà nínú ìjọ tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀, ewu wo àtàwọn ohun wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún? (b) Kí ló yẹ kí ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run sún wa ṣe?

6 Yálà ó ti pẹ́ tá a ti wà nínú ìjọ tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa pàdánù ìfẹ́ tá a kọ́kọ́ ní sí Jèhófà. Báwo la ṣe lè pàdánù rẹ̀? A lè pàdánù rẹ̀ tá a bá jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, ìfẹ́ láti kó owó tabua jọ tàbí ìlépa adùn di ohun pàtàkì nígbèésí ayé wa. Èyí lè mú kí ọkàn wa máa wà lórí àwọn ohun tara dípò kó máa wà lórí àwọn ohun tẹ̀mí. (Róòmù 8:5-8; 1 Tímótì 4:8; 6:9, 10) Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ sí wa, ó yẹ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà sún wa láti ṣàtúnṣe ká sì ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́,’ ká bàa lè ‘kó ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara wa ní ọ̀run.’—Mátíù 6:19-21, 31-33.

7. (a) Kí ló yẹ kó sún wa ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà? (b) Kí ni Jòhánù sọ nípa ìfẹ́?

7 Ká jẹ́ kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tá a ní sí Jèhófà máa sún wa ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe sí i. Ẹ jẹ́ ká ní ìmọrírì àtọkànwá fún gbogbo nǹkan tí Jèhófà àti Kristi ti ṣe fún wa. Ohun tí Jòhánù kọ̀wé rẹ̀ lẹ́yìn náà nìyẹn, ó ní: “Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Jòhánù ń bá a lọ láti sọ fún wa pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́, ẹni tí ó bá sì dúró nínú ìfẹ́ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Láé, ká má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà, ìfẹ́ tá a ní sí Jésù Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ tá a ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà láàyè, dín kù! Yàtọ̀ sí fífi ìfẹ́ yìí hàn nípa fífi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà, a tún lè fi hàn nípa ṣíṣègbọràn sí ‘àṣẹ yìí tí a gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, pé ẹni náà tí ó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní láti máa nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.’—1 Jòhánù 4:10, 16, 21; Hébérù 4:12; tún wo 1 Pétérù 4:8; Kólósè 3:10-14; Éfésù 4:15.

“Ṣe Àwọn Iṣẹ́ ti Ìṣáájú”

8. Kí ni Jésù ní káwọn ara Éfésù ṣe?

8 Àwọn ará Éfésù gbọ́dọ̀ padà ní ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní bí wọn ò bá fẹ́ pàdánù. Jésù sọ fún wọn pé: “Nítorí náà, rántí inú ohun tí o ti ṣubú, kí o sì ronú pìwà dà, kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti ìṣáájú. Bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣe ni èmi yóò gbé ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní àyè rẹ̀, àyàfi bí o bá ronú pìwà dà.” (Ìṣípayá 2:5) Kí làwọn Kristẹni nínú ìjọ Éfésù ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí? A ò mọ̀. Ṣùgbọ́n a lérò pé wọ́n ronú pìwà dà wọ́n sì ta ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà jí. Bí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù á fẹ́ fìtílà wọn pa, á sì gbé ọ̀pá fìtílà wọn kúrò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n á pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti máa tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́.

9. (a) Ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni Jésù ní láti sọ fáwọn ará Éfésù? (b) Báwo làwọn ìjọ lẹ́yìn ìgbà ayé Jòhánù kò ṣe ka ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ará Éfésù sí?

9 Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jésù ní ọ̀rọ̀ ìṣírí kan láti sọ fáwọn ará Éfésù. Ó ní: “Síbẹ̀, ìwọ ní èyí, pé o kórìíra àwọn iṣẹ́ ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì, èyí tí èmi pẹ̀lú kórìíra.” (Ìṣípayá 2:6) Ó kéré tán wọ́n kórìíra ẹ̀ya ìsìn bí Jésù Kristi Olúwa ṣe kórìíra rẹ̀. Àmọ́ bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ ìjọ ò ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí sí. Níní tí wọn ò ní ìfẹ́ fún Jèhófà, fún òtítọ́, àti fún ara wọn mú kí wọ́n sú lọ sínú òkùnkùn tẹ̀mí. Ni wọ́n bá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí àìlóǹkà ẹ̀ya ìsìn tó ń ta ko ara wọn. Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tí wọ́n jẹ́ adàwékọ tí wọn kò ní ìfẹ́ kankan fún Jèhófà yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Gíríìkì. Níní tí wọn ò ní ìfẹ́ tún mú kí wọ́n máa fi àwọn ẹ̀kọ́ Bábílónì àti ti Gíríìkì kọ́ni, irú bíi hẹ́ẹ̀lì oníná, pọ́gátórì, àti Mẹ́talọ́kan, wọ́n sọ pé ẹ̀kọ ìsìn Kristẹni ni. Púpọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti òtítọ́, nítorí náà, wọ́n ṣíwọ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tó wá ń ṣàkóso lé wọn lórí ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà onímọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n ṣe ìjọba fún ara wọn lórí ilẹ̀ ayé.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 4:8.

10. Báwo ni nǹkan ti rí fún ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì ní 1918?

10 Nígbà tí ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run lọ́dún 1918, gbangba gbàǹgbà ni ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn ẹ̀ya ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe ìtìlẹyìn fáwọn tó ń jà nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n ń rọ àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì níhà méjèèjì tó ń bára wọn jà pé kí wọ́n máa pa ara wọn. (1 Pétérù 4:17) Àwọn ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì kò dà bí ìjọ Éfésù tó kórìíra ohun tí ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì ń ṣe. Ìdí ni pé ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ẹ̀kọ́ èké tó ta ko Ọlọ́run ti ba àwọn ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà wọn sì ti di alátìlẹyìn ayé tí Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan rẹ̀. (Jòhánù 15:17-19) Níwọ̀n bí àwọn ìjọ wọn kò ti mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ni ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì, wọn kì í ṣe ọ̀pá fìtílà tó ń tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn to wà nínú ìjọ wọn kì í ṣe ara tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà. Àwọn aṣáájú wọn lọ́kùnrin (àti lóbìnrin) kì í ṣe ìràwọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àṣírí wọn tú pé wọ́n wà lára àwọn tó para pọ̀ di “ọkùnrin oníwà àìlófin” náà.—2 Tẹsalóníkà 2:3; Málákì 3:1-3.

11. (a) Ní 1918, àwùjọ àwọn Kristẹni wo ló ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ará Éfésù? (b) Kí ni ẹgbẹ́ Jòhánù ń ṣe láti 1919 wá?

11 Àmọ́ ẹgbẹ́ Jòhánù jáde wá látinú wàhálà àkókò Ogun Àgbáyé Kìíní tàwọn ti ìfẹ́ fún Jèhófà, wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, èyí tó ń sún wọn láti máa fi ìtara sin Jèhófà. Lọ́dún 1916, lẹ́yìn ikú Charles T. Russell tó jẹ́ ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society, àwọn kan fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, ìdí tí wọ́n sì fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè mú ẹ̀ya ìsìn wọlé, àmọ́ ẹgbẹ́ Jòhánù kò gbà fún wọn. Ó hàn gbangba pé lẹ́yìn tí inúnibíni àti ìpọ́njú ti kọ́ àwùjọ àwọn Kristẹni yìí lẹ́kọ̀ọ́, ìdájọ́ “o káre láé” ni Ọ̀gá wọn ṣe fún wọn, ó sì tún pè wọ́n pé kí wọ́n wọnú ayọ̀ òun. (Mátíù 25:21, 23) Látinú àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti látinú ìrírí tí àwọn fúnra wọn ní, wọ́n rí ìmúṣẹ àmì tí Jésù sọ pé ó máa fi hàn pé òun ti wà níhìn-ín láìṣeé-fojú-rí nínú agbára Ìjọba. Láti 1919, wọ́n tẹ̀ síwájú láti túbọ̀ nípìn-ín nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí Jésù sọ, pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 6:9, 10; 24:3-14) Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà tẹ́lẹ̀ kù díẹ̀ káàtó láwọn ọ̀nà kan, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí pé láti 1919 yẹn ni iná ìfẹ́ wọn ti ń jó lala.

12. (a) Ní àpéjọ àgbègbè mánigbàgbé tó wáyé lọ́dún 1922, ìpè wo ló jáde lọ? (b) Orúkọ wo làwọn Kristẹni tòótọ́ tẹ́wọ́ gbà ní 1931, kí ni wọ́n sì ronú pìwà dà rẹ̀?

12 Ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún àwọn Kristẹni wọ̀nyí ló pé jọ sí àpéjọ àgbègbè mánigbàgbé kan tó wáyé ní Cedar point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní September 5 sí 13, 1922. Ní ìpàdé náà, ìpè kan jáde lọ pé: “Ẹ padà sí pápá, ẹ̀yin ọmọ Ọlọ́run gíga jù lọ! . . . Ayé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run àti pé Jésù Kristi ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. . . . Nítorí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Àwọn Kristẹni wọ̀nyí túbọ̀ ń gbé orúkọ ńlá Jèhófà lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, ní àpéjọ àgbègbè kan ní Columbus, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní 1931, inú wọn dùn láti tẹ́wọ́ gba orúkọ tí Ọlọ́run fi hàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ìyẹn, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10, 12) Látorí Ilé Ìṣọ́ March 1, 1939, wọ́n yí orúkọ ìwé ìròyìn pàtàkì tí ètò yìí ń lò padà sí Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà, nípa bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá wa àti àkóso rẹ̀ ni ìwé ìròyìn náà ń bu ọlá tó ga jù lọ fún. Pẹ̀lú bí ìfẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní sí Jèhófà ṣe dọ̀tun, tó bá jẹ́ pé láwọn ìgbà tó ti kọjá, a ti kùnà lọ́nà kan ṣá láti bọlá fún orúkọ ológo Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ tí a kò sì gbé e ga, a ti ronú pìwà dà èyí.—Sáàmù 106:6, 47, 48.

“Ẹni Tí Ó Bá Ṣẹ́gun”

13. (a) Ìbùkún wo ló dúró de àwọn ará Éfésù bí wọ́n bá “ṣẹ́gun”? (b) Báwo làwọn Kristẹni ní Éfésù yóò ṣe “ṣẹ́gun”?

13 Níkẹyìn, Jésù pe àfiyèsí sí ẹ̀mí mímọ́ pé òun ló ń tipasẹ̀ òun sọ èrè táwọn olóòótọ́ á rí gbà fún ìṣòtítọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe pe àfiyèsí sí i nínú iṣẹ́ tó rán sí ìjọ mẹ́fà tó kù. Ó sọ fáwọn ará Éfésù pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ: Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jẹ nínú igi ìyè, èyí tí ń bẹ nínú párádísè Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 2:7) Àwọn tí wọ́n ní etí-ìgbọ́ yóò hára gàgà láti fiyè sí ohun tó wà nínú iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù rán sí wọn yẹn, wọ́n á mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jésù kọ́ ló ti pilẹ̀ṣẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ náà, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, tàbí agbára ìṣiṣẹ́ Rẹ̀. Báwo wá ni wọ́n á ṣe “ṣẹ́gun”? Wọ́n á ṣẹ́gun tí wọ́n bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó pa ìwà títọ́ mọ́ títí dé ojú ikú tó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòhánù 8:28; 16:33; tún wo 1 Jòhánù 5:4.

14. Kí ni “párádísè Ọlọ́run” tí Jésù mẹ́nu kàn ní láti tọ́ka sí?

14 Níwọ̀n bí àwọn ẹni àmì òróró, irú bí àwọn ará Éfésù, kò ti nírètí láti gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀nà wo la gbà san èrè fún wọn nípa jíjẹ “nínú igi ìyè, èyí tí ń bẹ nínú párádísè Ọlọ́run”? Èyí kò lè jẹ́ Párádísè tá a mú bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ Éfésù jẹ́ ara rẹ̀, ni a ti rà láti inú aráyé láti ṣàkóso pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Kristi Jésù, lórí Òkè Síónì ti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tẹ̀mí. (Éfésù 1:5-12; Ìṣípayá 14:1, 4) Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé ohun tí gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí ni ọ̀run tó dà bí ọgbà, èyí tí àwọn aṣẹ́gun wọ̀nyí jogún rẹ̀. Níbẹ̀, “nínú párádísè Ọlọ́run,” àní níwájú Jèhófà gan-an, àwọn tó ṣẹ́gun wọ̀nyí tí a ti fún ní àìleèkú yóò máa bá a lọ láti wà láàyè títí láé, èyí tí jíjẹ nínú igi ìyè náà ṣàpẹẹrẹ.

15. Kí nìdí tí ìṣírí tí Jésù fúnni láti ṣẹ́gun fi jẹ́ ohun tí ogunlọ́gọ̀ ńlá nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi lónìí?

15 Àwọn tó ń fi àìyẹsẹ̀ ṣètìlẹyìn fún ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àwọn ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń bá àwọn ẹni àmì òróró kẹ́gbẹ́ náà ń ṣẹ́gun. Ṣùgbọ́n ìrètí wọn dá lórí wíwọ Párádísè orí ilẹ̀ ayé, níbi tí wọ́n á ti mu nínú “odò omi ìyè” tí wọ́n á sì rí ìmúláradá láti inú “ewé àwọn igi” tí a gbìn sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ odò yẹn. (Ìṣípayá 7:4, 9, 17; 22:1, 2) Tó bá jẹ́ pé ara àwùjọ yìí lo wà, kí ìwọ náà máa fi ìfẹ́ rẹ hàn sí Jèhófà kó o sì ṣẹ́gun nínú ogun jíjà ti ìgbàgbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀ ọwọ́ rẹ lè tẹ ayọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Fi wé 1 Jòhánù 2:13, 14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn nípa bí àwọn èké àpọ́sítélì ṣe fara hàn, wo ojú ewé 37 sí 44 nínú ìwé náà, Reasoning From the Scriptures, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 36]

Yíyin Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀ Tìfẹ́tìfẹ́

Nínú ìwé orin táwa èèyàn Jèhófà ṣe ní 1905, ìlọ́po méjì àwọn orin tá a fi ń yin Jèhófà la fi ń yin Jésù. Nínú ìwé orin wa ti 1928, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé iye kan náà ni orin tá a fi ń yin Jèhófà àti orin tá a fi ń yin Jésù. Ṣùgbọ́n nínú ìwé orin tó dé gbẹ̀yìn ní 1984, iye àwọn orin tá a fi ń bọlá fún Jèhófà jẹ́ ìlọ́po mẹ́rin èyí tá a fi ń bọlá fún Jésù. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ, pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Ìfẹ́ fún Jèhófà ló gbọ́dọ̀ gba iwájú, lọ́wọ́ kan náà, ká ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Jésù ká sì fi ìmọrírì hàn fún ẹbọ iyebíye tó rú nítorí wa àti ipò tó wà gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà Ọlọ́run.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 34]

Bí Ìmọ̀ràn Jésù Ṣe Lọ

(orí àti ẹsẹ tí ìmọ̀ràn rẹ̀ wà nínú ìwé Ìṣípayá)

O ránṣẹ́ Àṣẹ tó ní Ìgbóríyìn Ó fi ìṣòro Ìbáwí Ìbùkún tí

sí ìjọ láti fúnni ló fi bẹ̀rẹ̀ wọn hàn àti/tàbí yóò yọrí sí

nímọ̀ràn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kedere ìṣírí

Éfésù 2:1 2:2, 3 2:4 2:5, 6 2:7

Símínà 2:8 2:92:10 2:11

Págámù 2:12 2:13 2:14, 15 2:16 2:17

Tíátírà 2:18 2:19 2:20, 21 2:24, 25 2:26-28

Sádísì 3:13:1, 2 3:3, 4 3:5

Filadéfíà 3:7 3:83:8-11 3:12

Laodíkíà 3:143:15-17 3:18-20 3:21