“Ta Ni Ó Yẹ Láti Ṣí Àkájọ Ìwé Náà?”
Orí 15
“Ta Ni Ó Yẹ Láti Ṣí Àkájọ Ìwé Náà?”
1. Kí ló ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí nínú ìran tí Jòhánù rí?
Ó GA LỌ́LÁ! ÀGBÀYANU NI! Ìran nípa ìtẹ́ Jèhófà, ìyẹn bá a ṣe gbé e kalẹ̀ láàárín àwọn fìtílà iná, àwọn kérúbù, alàgbà mẹ́rìnlélógún, àti òkun bí gíláàsì náà kàmàmà. Alàgbà Jòhánù, kí lo wá rí lẹ́yìn ìyẹn o? Jòhánù tẹjú mọ́ àárín gbùngbùn ibi ìran ọ̀run yìí, ó sì sọ fún wa pé: “Mo sì rí ní ọwọ́ ọ̀tún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àkájọ ìwé kan tí a kọ̀wé sí tinú-tẹ̀yìn, tí a fi èdìdì méje dì pinpin. Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára kan tí ń pòkìkí pẹ̀lú ohùn rara pé: ‘Ta ni ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà, kí ó sì tú àwọn èdìdì rẹ̀?’ Ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ ẹnì kan ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé tí ó lè ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí pé a kò rí ẹnì kan tí ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀.”—Ìṣípayá 5:1-4.
2, 3. (a) Kí nìdí tí Jòhánù fi ń hára gàgà pé ká rí ẹnì kan tí yóò ṣí àkájọ ìwé náà, ṣùgbọ́n kí ló dà bíi pé ó wá fẹ́ ṣẹlẹ̀ báyìí? (b) Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni àmì òróró ti ń fi ìháragàgà dúró dè nígbà tiwa?
2 Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ gbogbo ẹ̀dá fúnra rẹ̀ ló na àkájọ ìwé yẹn síta. Ó ní láti jẹ́ pé ìsọfúnni pàtàkì kún inú rẹ̀, nítorí tojú-tẹ̀yìn rẹ̀ la kọ nǹkan sí. Ara wa ti wà lọ́nà láti mọ̀ nípa rẹ̀. Kí ló wà nínú àkájọ ìwé yìí? A rántí pé ohun tí Jèhófà sọ fún Jòhánù níbẹ̀rẹ̀ ni: “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín, èmi yóò sì fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.” (Ìṣípayá 4:1) A ti ń hára gàgà láti mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n, áà, ó ṣe! Ńṣe ni wọ́n pa àkájọ ìwé náà dé pinpin, wọ́n fi èdìdì méje dì í pa!
3 Ǹjẹ́ áńgẹ́lì alágbára náà yóò rí ẹnì kan tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Kingdom Interlinear ti wí, “ọwọ́ ọ̀tún” Jèhófà ni àkájọ ìwé náà wà. Èyí fi hàn pé ńṣe ló la àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bó ṣe nà án síta. Ṣùgbọ́n ó jọ pé kò sí ẹnì kankan ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé tó kúnjú òṣùwọ̀n láti gba àkájọ ìwé yẹn kó sì ṣí i. Kò tilẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lábẹ́ ilẹ̀ ayé pàápàá, ìyẹn láàárín àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti kú, tó kúnjú òṣùwọ̀n ọlá gíga yìí. Abájọ tí inú Jòhánù fi bà jẹ́! Ṣé bí kò ṣe wá ní mọ “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀” yẹn mọ́ nìyẹn? Nígbà tiwa yìí pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni àmì òróró ṣe fi ìháragàgà dúró de Jèhófà pé kó rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ jáde sórí Ìṣípayá. Ńṣe ni yóò sì ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ní àkókò tá a yàn kalẹ̀ fún ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà, láti lè ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ lọ sí ọ̀nà “ìgbàlà títóbi lọ́lá.”—Sáàmù 43:3, 5.
Ẹni Yíyẹ Náà
4. (a) Níkẹyìn, ta ni a rí pé ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà àtàwọn èdìdì rẹ̀? (b) Èrè àti àǹfààní wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń rí ní nísinsìnyí?
4 Bẹ́ẹ̀ ni! Ẹnì kan wà tó lè ṣí àkájọ ìwé náà! Jòhánù ròyìn pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà wí fún mi pé: ‘Dẹ́kun ẹkún sísun. Wò ó! Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà, gbòǹgbò Dáfídì, ti ṣẹ́gun láti lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.’” (Ìṣípayá 5:5) Nítorí náà, Jòhánù, nu omijé rẹ! Lónìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ ọdún ni ẹgbẹ́ Jòhánù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ adúróṣinṣin fi fara da àwọn àdánwò lílekoko bí wọ́n ṣe ń fi sùúrù dúró de ìgbà tí wọ́n máa gba ìlàlóye. Èrè ńlá tó ń tuni nínú gan-an ló jẹ́ fún wa o nísinsìnyí láti lóye ìran náà, ẹ sì wo àǹfààní tó jẹ́ láti nípìn-ín nínú ìmúṣẹ rẹ̀ ní ti pé à ń pòkìkí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn!
5. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni a sọ nípa Júdà, ibo sì ni àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ti ṣàkóso? (b) Ta ni Ṣílò?
5 Áà, “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà”! Jòhánù mọ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù, baba ńlá ìran àwọn Júù, sọ nípa Júdà ọmọ rẹ̀ kẹrin dáadáa, pé: “Ọmọ kìnnìún ni Júdà. Ọmọkùnrin mi, láti inú ẹran ọdẹ ni ìwọ yóò ti gòkè lọ. Ó tẹrí ba, ó na ara rẹ̀ tàntàn bí kìnnìún, àti bí kìnnìún, ta ní jẹ́ gbójú-gbóyà láti ta á jí? Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:9, 10) Ọ̀dọ̀ Júdà ni ìlà àwọn ọba tó ń jẹ lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wá. Bẹ̀rẹ̀ látorí Dáfídì, gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù títí táwọn ará Bábílónì fi pa ìlú yẹn run jẹ́ àtọmọdọ́mọ Júdà. Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí lára wọn tó jẹ́ Ṣílò tí Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀. Ṣílò túmọ̀ sí “Ẹni Tí [Ẹ̀tọ́] Jẹ́ Tirẹ̀.” Jésù, ẹni tí Ìjọba Dáfídì nísinsìnyí jẹ́ tirẹ̀ títí lọ gbére, ni orúkọ yìí ń tọ́ka sí lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 21:25-27; Lúùkù 1:32, 33; Ìṣípayá 19:16.
6. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ẹ̀ka igi” Jésè àti “gbòǹgbò Dáfídì” pẹ̀lú?
6 Kíákíá ni Jòhánù dá gbólóhùn náà “gbòǹgbò Dáfídì” mọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pe Mèsáyà tí a ṣèlérí náà ní “ẹ̀ka igi kan . . . láti ara kùkùté Jésè [ìyẹn baba Dáfídì Ọba] . . . èéhù kan” àti “gbòǹgbò Jésè . . . tí yóò dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn.” (Aísáyà 11:1, 10) Jésù jẹ́ ẹ̀ka igi Jésè, níwọ̀n bí a ti bí i sínú ìlà ìdílé Dáfídì ọmọ Jésè, tí wọ́n ti ń jọba. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bíi gbòǹgbò Jésè, òun ni Ẹni tó mú kí ìlà ọba Dáfídì hù lẹ́ẹ̀kan sí i, tó mú kó wà láàyè tó sì ń tì í lẹ́yìn, títí láé.—2 Sámúẹ́lì 7:16.
7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ló yẹ láti gba àkájọ ìwé náà lọ́wọ́ Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà?
7 Ní pàtàkì jù lọ, Jésù ni ẹ̀dá èèyàn pípé tó fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà, àní lábẹ́ àwọn àdánwò tó le koko jù lọ. Ó pèsè ìdáhùn pípé sí ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀. (Òwe 27:11) Ìyẹn ló fi lè sọ ohun tó sọ lóru ọjọ́ tó ṣáájú ikú tó kú láti fi ṣèrúbọ, pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Ìdí nìyí tí Jèhófà fi gbé “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé” lè Jésù lọ́wọ́ nígbà tó jí i dìde. Nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, òun nìkan ṣoṣo ló kúnjú òṣùwọ̀n láti gba àkájọ ìwé náà, láti lè jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì tó wà nínú rẹ̀.—Mátíù 28:18.
8. (a) Báwo ni àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe jẹ́ kó hàn pé Jésù lẹni yíyẹ yẹn lóòótọ́? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu pé kí ọ̀kan nínú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà sọ ẹni tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà fún Jòhánù?
8 Ó bá a mu gan-an lóòótọ́, pé Jésù lẹni tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà. Látọdún 1914 ló ti di Ọba Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run, ohun púpọ̀ ni àkájọ ìwé náà sì ti jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba náà àtàwọn ohun tí yóò ṣe. Jésù fi ìṣòtítọ́ jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa Ìjọba náà nígbà tó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 18:36, 37) Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún dídé Ìjọba náà. (Mátíù 6:9, 10) Òun ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀rẹ̀ sànmánì Kristẹni tó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù yẹn ṣe máa parí lákòókò òpin. (Mátíù 4:23; Máàkù 13:10) Bákan náà, ó tún bá a mu wẹ́kú pé ọ̀kan nínú alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ló sọ fún Jòhánù pé Jésù ni ẹni tí yóò ṣí àwọn èdìdì náà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn alàgbà wọ̀nyí wà lórí ìtẹ́ wọ́n sì dé adé nítorí àjùmọ̀jogún ni wọ́n jẹ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀.—Róòmù 8:17; Ìṣípayá 4:4.
‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Tí A Pa’
9. Dípò kìnnìún, kí ni Jòhánù rí tó dúró “ní àárín ìtẹ́,” báwo ló sì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀?
9 Jòhánù tẹjú mọ́ ibẹ̀ láti rí “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà” yìí. Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu gbáà lohun tó rí! Ẹ̀dá ìṣàpẹẹrẹ tó yàtọ̀ pátápátá ló jáde wá. Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí ní ìdúró ní àárín ìtẹ́ náà àti ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà àti ní àárín àwọn alàgbà náà, ọ̀dọ́ àgùntàn kan bí ẹni pé a ti fikú pa á, tí ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn ojú tí wọ́n túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run tí a ti rán jáde sí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 5:6.
10. Ta ni “ọ̀dọ́ àgùntàn” tí Jòhánù rí, kí sì nìdí tí orúkọ náà fi bá a mu?
10 Àárín gbùngbùn gan-an, lẹ́bàá ìtẹ́ náà, láàárín agbo tí ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì àti alàgbà mẹ́rìnlélógún náà pa yí ká, ló ti rí ọ̀dọ́ àgùntàn kan! Láìsí àní-àní, kíákíá ni Jòhánù mọ̀ pé ọ̀dọ́ àgùntàn yìí ni “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà” àti “gbòǹgbò Dáfídì.” Ó mọ̀ pé nígbà tí Jòhánù Oníbatisí ń fi Jésù han àwọn Júù tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún ṣáájú, ó pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòhánù 1:29) Ní gbogbo ìgbé ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jésù ò jẹ́ kí ayé kó àbààwọ́n kankan bá òun, àní gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lálèébù rárá, tó fi lè wá fi ìwàláàyè rẹ̀ aláìlẹ́gàn rú ẹbọ fún aráyé.—1 Kọ́ríńtì 5:7; Hébérù 7:26.
11. Kí nìdí tí kì í fi í ṣe nǹkan àbùkù láti fi “ọ̀dọ́ àgùntàn kan bí ẹni pé a ti fikú pa á” ṣàpẹẹrẹ Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo?
11 Ǹjẹ́ kì í ṣe nǹkan àbùkù láti fi “ọ̀dọ́ àgùntàn kan bí ẹni pé a ti fikú pa á” ṣàpẹẹrẹ Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo? Rárá o! Ìṣẹ́gun ńlá lórí Sátánì ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, ó sì jẹ́ ìṣẹ́gun ńláǹlà fún Jèhófà Ọlọ́run. Ńṣe ni ṣíṣàpẹẹrẹ Jésù lọ́nà yìí ń fi ọ̀nà tó gbà ṣẹ́gun ayé Sátánì hàn kedere, ó sì ń múni rántí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà àti Jésù ní fún aráyé. (Jòhánù 3:16; 15:13; fi wé Kólósè 2:15.) Bá a sì ṣe wá fi hàn nìyẹn pé Jésù ni Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, tó kúnjú òṣùwọ̀n gbáà láti ṣí àkájọ ìwé náà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
12. Kí ni ìwo méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣàpẹẹrẹ?
12 Ohun mìíràn wo ló jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì “ọ̀dọ́ àgùntàn” yìí? Ó jẹ́ torí pé ó ní ìwo méje. Bíbélì sábà máa ń fi ìwo ṣàpẹẹrẹ agbára tàbí ọlá àṣẹ, jíjẹ́ tó sì jẹ́ méje yóò fi hàn pé ó pé pérépéré. (Fi wé 1 Sámúẹ́lì 2:1, 10; Sáàmù 112:9; 148:14.) Fún ìdí yìí, ìwo méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára tí Jèhófà gbé lé Jésù lọ́wọ́. Ó wà “lókè fíofío ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí nìkan, ṣùgbọ́n nínú èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.” (Éfésù 1:20-23; 1 Pétérù 3:22) Ní pàtàkì, Jésù ti ń lo agbára, ìyẹn agbára ìjọba láti ọdún 1914 tí Jèhófà ti fi jẹ ọba ní ọ̀run.—Sáàmù 2:6.
13. (a) Kí ni ojú méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wá ṣe?
13 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù kún fún ẹ̀mí mímọ́, torí pé ìyẹn lóhun tí ojú méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, tó “túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run,” ń ṣàpẹẹrẹ. Ọ̀nà kan tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀mí Jèhófà gbà ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ni nípasẹ̀ Jésù. (Títù 3:6) Ẹ̀rí fi hàn pé, ẹ̀mí kan náà yìí ló ń mú kó lè máa rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé láti ọ̀run. Jésù ní ìfòyemọ̀ pípé bíi ti Baba rẹ̀. Kò sí nǹkan kan tó pa mọ́ fún un, gbogbo rẹ̀ ló ń rí kedere. (Fi wé Sáàmù 11:4; Sekaráyà 4:10.) Ó ṣe kedere pé, Ọmọ yìí, ìyẹn olùpa ìwà títọ́ mọ́ tó ṣẹ́gun ayé; Kìnnìún ẹ̀yà Júdà; gbòǹgbò Dáfídì; ẹni tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ fún aráyé; tó ní ọlá àṣẹ pípé pérépéré, tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀mí mímọ́, àti ìfòyemọ̀ pípé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni tó ta yọ yìí gan-an ló yẹ láti gba àkájọ ìwé náà ní ọwọ́ Jèhófà. Ǹjẹ́ ó wá lọ́ tìkọ̀ láti gba iṣẹ́ yìí nínú ètò Jèhófà tó ga fíofío? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “ó . . . lọ, ó sì gbà á [ìyẹn àkájọ ìwé náà] lójú ẹsẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.” (Ìṣípayá 5:7) Àpẹẹrẹ rere gbáà ni èyí jẹ́ ní ti pé ká múra tán láti ṣègbọràn!
Orin Ìyìn
14. (a) Kí ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì àti alàgbà mẹ́rìnlélógún ṣe nígbà tí Jésù gba àkájọ ìwé náà? (b) Báwo ni ìsọfúnni tí Jòhánù rí gbà nípa alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe túbọ̀ jẹ́ ká mọ àwọn àti ipò wọn dájú?
14 Kí ni àwọn yòókù tó wà níwájú ìtẹ́ Jèhófà wá ṣe? “Nígbà tí ó sì gba àkájọ ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti àwokòtò wúrà tí ó kún fún tùràrí, tùràrí náà sì túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 5:8) Bí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó jẹ́ kérúbù tó wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run ṣe tẹrí ba náà làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe tẹrí ba fún Jésù láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà wọ̀nyí nìkan ni wọ́n ní háàpù àti àwokòtò tùràrí. a Àwọn nìkan sì ni wọ́n ń kọrin tuntun kan nísinsìnyí. (Ìṣípayá 5:9) Nípa báyìí wọ́n jọ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tí wọ́n jẹ́ mímọ́, táwọn pẹ̀lú ní háàpù tí wọ́n sì ń kọrin tuntun kan. (Gálátíà 6:16; Kólósè 1:12; Ìṣípayá 7:3-8; 14:1-4) Síwájú sí i, alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ni a fi hàn pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ kan ní ọ̀run, ìyẹn iṣẹ́ àlùfáà. Àpẹẹrẹ tiwọn ni iṣẹ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sun tùràrí fún Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn ní Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́, èyí tó ti dópin lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ọlọ́run mú Òfin Mósè kúrò ní ojú ọ̀nà, tó kàn án mọ́ igi oró Jésù. (Kólósè 2:14) Kí la rí fà yọ nínú gbogbo èyí? Òun ni pé ńṣe ni ibí yìí ń jẹ́ ká rí àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun bí wọ́n ṣe wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn gíga jù lọ, tí í ṣe ‘àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, tí wọ́n ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún.’—Ìṣípayá 20:6.
15. (a) Ní Ísírẹ́lì, ta ni ẹnì kan ṣoṣo tó láǹfààní láti wọ ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn? (b) Kí nìdí tí àlùfáà àgbà fi gbọ́dọ̀ sun tùràrí kó tó wọnú ibi Mímọ́ Jù Lọ nítorí ẹ̀mí rẹ̀?
15 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àlùfáà àgbà nìkan ló lè wọ ibi Mímọ́ Jù Lọ láti wá síwájú ibi tó ń ṣàpẹẹrẹ ibi tí Jèhófà wà. Tí àlùfáà àgbà yìí kò bá fẹ́ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ gbé tùràrí dání wá síbẹ̀. Òfin Jèhófà sọ pé: “Kí [Áárónì] mú ìkóná tí ó kún fún ẹyín iná tí ń jó láti orí pẹpẹ níwájú Jèhófà, kí ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sì kún fún àtàtà tùràrí onílọ́fínńdà, kí ó sì mú wọn wá sínú aṣọ ìkélé. Kí ó sì fi tùràrí sínú iná níwájú Jèhófà, kí ìṣúdùdù èéfín tùràrí sì bo ìbòrí Àpótí, tí ó wà lórí Gbólóhùn Ẹ̀rí, kí ó má bàa kú.” (Léfítíkù 16:12, 13) Àlùfáà àgbà ò lè rí inú ibi Mímọ́ Jù Lọ wọ̀ láàyè àyàfi tó bá sun tùràrí.
16. (a) Lábẹ́ ètò àwọn nǹkan ti Kristẹni, àwọn wo ló wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ lọ́run, èyí tí ibi mímọ́ jù lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? (b) Kí nìdí táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi ní láti ‘sun tùràrí’?
16 Nínú ètò àwọn nǹkan ti Kristẹni, Jésù Kristi, Àlùfáà Àgbà táwọn àlùfáà àgbà ìṣáájú jẹ́ àpẹẹrẹ rẹ̀, nìkan kọ́ ló wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ìyẹn ibi tí Jèhófà wà ní ọ̀run, èyí tí ibi mímọ́ jù lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Olúkúlùkù ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ àlùfáà lábẹ́ Jésù náà wọ̀ ọ́ níkẹyìn. (Hébérù 10:19-23) Àwọn àlùfáà yìí, táwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ń ṣàpẹẹrẹ, kò lè wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ náà àyàfi bí wọ́n bá ‘sun tùràrí,’ ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà kí wọ́n sì máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nígbà gbogbo.—Hébérù 5:7; Júúdà 20, 21; fi wé Sáàmù 141:2.
Orin Tuntun Kan
17. (a) Orin tuntun wo ni alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ń kọ? (b) Báwo la ṣe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “orin tuntun” nínú Bíbélì?
17 Orin adùnyùngbà kan bẹ̀rẹ̀ sí í dún wàyí. Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà làwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà, ń kọrin sí: “Wọ́n sì ń kọ orin tuntun kan, pé: ‘Ìwọ ni ó yẹ láti gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, nítorí pé a fikú pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.’” (Ìṣípayá 5:9) Ọ̀rọ̀ náà “orin tuntun” wáyé ní ìgbà mélòó kan nínú Bíbélì, ó sì sábà máa ń tọ́ka sí yíyin táwọn èèyàn ń yin Jèhófà fún àwọn iṣẹ́ ìdáǹdè ńláǹlà kan tó ṣe. (Sáàmù 96:1; 98:1; 144:9) Ìyẹn fi hàn pé orin náà jẹ́ tuntun nítorí pé ẹni tó ń kọ ọ́ á pòkìkí àwọn àfikún iṣẹ́ àgbàyanu tí Jèhófà ṣe á sì tún sọ bó ṣe mọrírì orúkọ Rẹ̀ ológo tó lẹ́ẹ̀kan sí i.
18. Torí kí ni alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe ń kọ orin tuntun láti fi yin Jésù?
18 Níhìn-ín, iwájú Jésù làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ti ń kọ orin tuntun kan dípò kó jẹ́ níwájú Jèhófà. Ṣùgbọ́n ìlànà kan náà ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Ńṣe ni wọ́n ń yin Jésù fáwọn ohun tí òun, Ọmọ Ọlọ́run, ṣe nítorí tiwọn. Ó tipa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe alárinà májẹ̀mú tuntun, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe láti mú orílẹ̀-èdè tuntun kan tó jẹ́ àkànṣe ìní Jèhófà jáde. (Róòmù 2:28, 29; 1 Kọ́ríńtì 11:25; Hébérù 7:18-25) Inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ayé làwọn tí wọ́n jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun yìí ti wá, ṣùgbọ́n Jésù so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan sínú ìjọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan.—Aísáyà 26:2; 1 Pétérù 2:9, 10.
19. (a) Ìbùkún wo ni kò ṣẹ sí Ísírẹ́lì ti ara lára nítorí àìṣòótọ́ wọn? (b) Ìbùkún wo ni orílẹ̀-èdè tuntun ti Jèhófà ń rí gbà?
19 Nígbà tí Jèhófà sọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè kan nígbà ayé Mósè lọ́hùn-ún, ó bá wọn dá májẹ̀mú ó sì ṣèlérí pé bí wọ́n bá ń bá a lọ láti pa májẹ̀mú yẹn mọ́, wọn yóò di ìjọba àwọn àlùfáà fún òun. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò máa bá a lọ láti pa májẹ̀mú náà mọ́, nítorí náà ìlérí yẹn kò ṣẹ sí wọn lára rárá. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè tuntun náà, tí a tipa májẹ̀mú tuntun tí Jésù ṣalárinà rẹ̀ dá sílẹ̀, jẹ́ olóòótọ́. Bí àwọn tí wọ́n wà nínú orílẹ̀-èdè náà ṣe dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọba nìyẹn, tí wọ́n sì tún ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà, ní ríran àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ nínú aráyé lọ́wọ́ láti padà bá Jèhófà rẹ́. (Kólósè 1:20) Gan-an bí orin tuntun náà ti sọ ọ́ ló rí, ó ní: “O sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:10) Inú alàgbà mẹ́rìnlélógún wọnnì mà dùn gan-an o, bí wọ́n ṣe ń kọ orin ìyìn tuntun yìí sí Jésù tá a ti ṣe lógo!
Orin Ọ̀run
20. Orin ìyìn wo ni wọ́n wá ń kọ sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà nísinsìnyí?
20 Kí ni àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye ẹgbẹ́ ọmọ ogun yòókù tó wà nínú ètò Jèhófà ní ọ̀run wá ṣe nípa orin tuntun yìí? Orí Jòhánù wú gan-an nígbà tó rí bí wọ́n ṣe fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú orin yìí tọkàntọkàn, ó ní: “Mo sì rí, mo sì gbọ́ ohùn ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ní àyíká ìtẹ́ àti àwọn ẹ̀dá alààyè àti àwọn alàgbà náà, iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí wọ́n ń wí ní ohùn rara pé: ‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa ni ó yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.’” (Ìṣípayá 5:11, 12) Orin ìyìn yìí mà wuni lórí o!
21. Ǹjẹ́ yíyin tí wọ́n ń yin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà bu ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run kù? Ṣàlàyé.
21 Ṣé èyí ń fi hàn pé Jésù ti wá bọ́ sípò Jèhófà Ọlọ́run ni lọ́nà kan ṣá nísinsìnyí àti pé òun ni gbogbo ẹ̀dá wá ń yìn dípò Baba rẹ̀? Kò rí bẹ́ẹ̀ o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lorin ìyìn yìí bá ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ mu pé: “Ọlọ́run . . . gbé [Jésù] sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílípì 2:9-11) Ńṣe ni wọ́n ń kókìkí Jésù níhìn-ín nítorí ipa tó kó nínú yíyanjú ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ tí gbogbo ẹ̀dá dojú kọ, ìyẹn ọ̀ràn bí yóò ṣe di mímọ̀ pé Jèhófà nìkan ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ògo tí èyí sì ti mú wá fún Baba rẹ̀ pọ̀ gan-an ni!
Orin Ìyìn Tó Túbọ̀ Ń Dún Ròkè
22. Orin ìyìn wo ni àwọn ẹ̀dá ilẹ̀ ayé náà ń kọ nínú rẹ̀?
22 Nínú ìran tí Jòhánù ń sọ fún wa, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run fi orin adùnyùngbà yin Jésù láti fi hàn pé wọ́n mọrírì ìṣòtítọ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ tó gbà lọ́run. Àwọn ẹ̀dá ilẹ̀ ayé náà ń bá wọn kọ orin yìí níwọ̀n bí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ti ń yin Baba àti Ọmọ rẹ̀. Bí àwọn àṣeyọrí ọmọ èèyàn kan ṣe lè gbé ògo àwọn òbí rẹ̀ yọ náà ni ìwà ìdúróṣinṣin Jésù ṣe mú kí òkìkí rẹ̀ kàn láàárín gbogbo ẹ̀dá “fún ògo Ọlọ́run Baba.” Ìyẹn ni Jòhánù fi ń bá a lọ láti ròyìn pé: “Àti gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé àti lórí òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé: ‘Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.’”—Ìṣípayá 5:13.
23, 24. (a) Kí ló jẹ́ ká mọ ìgbà tí orin ìyìn yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? (b) Báwo ni ìró ohùn orin ìyìn náà ṣe ń lọ sókè sí i bí ọdún ti ń gorí ọdún?
23 Ìgbà wo ni ìró orin ìyìn gíga lọ́lá tó sì bùáyà yìí dún jáde? Apá ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa ló bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà tí a lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde ní ọ̀run ni “gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run” lè jùmọ̀ fi ìṣọ̀kan kọ orin ìyìn yìí. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ sì ti fi hàn, látọdún 1919 ni ògìdìgbó èèyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé ti fi ìṣọ̀kan pa ohùn pọ̀ nínú yíyin Jèhófà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i láti orí ẹgbẹ̀rún díẹ̀ ní ìgbà náà dé iye tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ dáadáa ní ọdún 2005. b Lẹ́yìn tí a bá ti wá pa ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé run, “gbogbo ẹ̀dá . . . lórí ilẹ̀ ayé” yóò máa kọ orin ìyìn Jèhófà àti ti Ọmọ rẹ̀. Ní àkókò yíyẹ lójú Jèhófà, àjíǹde àìlóǹkà ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú yóò bẹ̀rẹ̀, nígbà náà “gbogbo ẹ̀dá . . . nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé” tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run yóò wá láǹfààní láti nípìn-ín nínú kíkọ orin ìyìn náà.
24 Ní báyìí pàápàá, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn “láti ìkángun ilẹ̀ ayé . . . òkun àti . . . erékùṣù,” ń kọ orin tuntun kan bí wọ́n ṣe ń wá sínú ètò Jèhófà kárí ayé. (Aísáyà 42:10; Sáàmù 150:1-6) Orin ìyìn aláyọ̀ yìí yóò dún dókè pátápátá rẹ̀ ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìjọba Kristi, nígbà tí a óò ti mú aráyé dé ipò ìjẹ́pípé. Sátánì, ejò ògbólógbòó nì, olórí atannijẹ, ni a óò pa run lẹ́yìn náà láti mú ọ̀rọ̀ Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣẹ délẹ̀. Nígbà yẹn, gbogbo ẹ̀dá alààyè, yálà ẹ̀dá ẹ̀mí tàbí ẹ̀dá èèyàn, yóò wá fi ayọ̀ kọrin ìṣẹ́gun ní ìṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀, pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.” Nígbà náà, kò ní sí ohùn ẹnikẹ́ni tó máa yapa rárá láyé àtọ̀run.
25. (a) Kí ni kíka àkọsílẹ̀ Jòhánù nípa orin ìyìn yìí mú ká ṣe? (b) Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti alàgbà mẹ́rìnlélógún náà fi lélẹ̀ fún wa bí ìran náà ṣe fẹ́ parí?
25 Ẹ wo bí ìgbà náà yóò ṣe jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó! Dájúdájú, ohun tí Jòhánù ṣàpèjúwe níhìn-ín mú kí ọkàn wa kún fún ayọ̀, ó sì mórí wa yá gágá láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run ní kíkọ àwọn orin ìyìn àtọkànwá sí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. Ǹjẹ́ èyí kò mú ká túbọ̀ pinnu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé a ó máa bá àwọn iṣẹ́ rere nìṣó? Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè retí pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, kálukú wa yóò wà níbẹ̀ nígbà ìparí rẹ̀ aláyọ̀, tí a ó jọ kọ orin ìyìn tí yóò gba gbogbo ayé àtọ̀run. Dájúdájú, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó jẹ́ kérúbù wọnnì àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a ti jí dìde jọ fohùn ṣọ̀kan pátápátá, nítorí bí ìran náà ṣe parí ni pé: “Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà sì ń wí pé: ‘Àmín!’ àwọn alàgbà náà sì wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn.”—Ìṣípayá 5:14.
26. A ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú kí ni, kí sì ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti ṣe tán láti ṣe?
26 Ǹjẹ́ kí ìwọ òǹkàwé wa ọ̀wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn nì, tó jẹ́ ‘ẹni yíyẹ’ náà, kó o sì gba ìbùkún bí o ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sapá láti máa sin Jèhófà, “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́” náà. Jẹ́ kí ẹgbẹ́ Jòhánù ràn ọ́ lọ́wọ́ lónìí bí wọ́n ṣe ń pèsè “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Lúùkù 12:42) Ṣùgbọ́n, wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti ṣe tán láti ṣí èdìdì méjèèje. Àwọn ìṣípayá tó wúni lórí wo la máa rí nísinsìnyí?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tá a bá fojú gírámà wo ọ̀rọ̀ náà “olúkúlùkù wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti àwokòtò wúrà tí ó kún fún tùràrí,” ó lè tọ́ka sí àwọn alàgbà àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà pa pọ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tá à ń bá bọ̀ ká tó kan gbólóhùn náà jẹ́ kó ṣe kedere pé alàgbà mẹ́rìnlélógún náà nìkan lọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí.
b Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ewé 64.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 86]