Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èéṣe Tí A Fi Ń Darúgbó Tí A Sì Ń Kú?

Èéṣe Tí A Fi Ń Darúgbó Tí A Sì Ń Kú?

Orí 6

Èéṣe Tí A Fi Ń Darúgbó Tí A Sì Ń Kú?

1. Kí ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè ṣàlàyé nípa ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn?

ÀWỌN onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò mọ ìdí rẹ̀ tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú. Ó dàbí ẹni pé àwọn sẹ́ẹ̀lì wa lè máa bá a lọ ní dídi ọ̀tun kí a sì wàláàyè títí láé. Ìwé náà Hyojun Soshikigaku (Ìlànà Ẹ̀kọ́ Sẹ́ẹ̀lì Inú Ara) sọ pé: “Ìsopọ̀ tí ó wà láàárín bí àwọn sẹ́ẹ̀lì ti ń gbó sí bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ti ń gbó tí ó sì ń kú jẹ́ àdììtú ńlá kan.” Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbàgbọ́ pé “ohun àdámọ́ni, tí a jogúnbá” wà tí ń pààlà sí ìwàláàyè. O ha lérò pé wọ́n tọ̀nà bí?

2. Kí ni àwọn kan ti ṣe nítorí ìwàláàyè tí kì í wà pẹ́?

2 Ìgbà gbogbo ni àwọn ènìyàn ti ń yánhànhàn fún ẹ̀mí gígùn tí wọ́n sì tilẹ̀ ti gbìyànjú kí ọwọ́ wọn lè tó àìleèkú. Láti ọ̀rúndún kẹrin B.C.E., àwọn oògùn líle tí a sọ pé a ṣe láti mú àìleèkú ṣeé ṣe fa àfiyèsí àwọn ọ̀tọ̀kùlú ará China mọ́ra. Àwọn olú-ọba ilẹ̀ China mélòókan lẹ́yìn náà gbìyànjú àjídèwe​—⁠tí a fi èròjà mercury ṣe⁠—​síbẹ̀ wọ́n kú! Káàkiri ayé, àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé ikú kì í ṣe òpin ìwàláàyè wọn. Àwọn onísìn Buddha, Hindu, Musulumi, àti àwọn mìíràn ní àwọn ìrètí mímọ́lẹ̀yòò nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Ní Kristẹndọm, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń fojúsọ́nà fún ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ti aláyọ̀ pípé pérépéré ní ọ̀run.

3. (a) Èéṣe tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ń yánhànhàn fún ìyè ayérayé? (b) Àwọn ìbéèrè wo nípa ikú ni ó yẹ kí a rí ìdáhùn sí?

3 Àwọn èròǹgbà ayọ̀ lẹ́yìn ikú fi ìyánhànhàn fún ìyè ayérayé hàn. Nípa èrò ayérayé tí Ọlọrun gbìn sí wa nínú, Bibeli sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi ayérayé sí wọn ní àyà.” (Oniwasu 3:11) Ó dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ pẹ̀lú ìfojúsọ́nà pé kí wọ́n lè wàláàyè títí láé lórí ilẹ̀-ayé. (Genesisi 2:​16, 17) Nígbà náà, èéṣe tí àwọn ènìyàn fi ń kú? Báwo ni ikú ṣe wọ inú ọ̀ràn aráyé? Ìmọ̀ Ọlọrun tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.​—⁠Orin Dafidi 119:105.

ÌDÌMỌ̀LÙ IBI KAN

4. Báwo ni Jesu ṣe fi ọ̀daràn tí ó ṣokùnfà ikú ẹ̀dá ènìyàn hàn?

4 Ọ̀daràn kan a máa gbìyànjú láti fi àwọn ẹ̀rí tí ó lè wé ọ̀ràn mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ pamọ́. Èyí ti jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú níti ẹni tí ó jẹ́ okùnfà fún ìwà-ọ̀daràn kan tí ó ti yọrí sí ikú ọ̀pọ̀ billion. Ó ti fọgbọ́n darí àwọn nǹkan láti daṣọ bo ikú ẹ̀dá ènìyàn pé ó jẹ́ àdììtú kan. Jesu Kristi fi ọ̀daràn yìí hàn nígbà tí Ó sọ fún àwọn tí wọ́n ń wá láti pa Á pé: “Lati ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ lati ṣe awọn ìfẹ́-ọkàn baba yín. Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin ninu òtítọ́, nitori pé òtítọ́ kò sí ninu rẹ̀.”​—⁠Johannu 8:31, 40, 44.

5. (a) Kí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹni náà tí ó di Satani Èṣù? (b) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ náà “Satani” àti “Èṣù” túmọ̀ sí?

5 Òtítọ́ ni, “apànìyàn” aláràn-ánkàn ni Èṣù. Bibeli ṣí i payá pé ẹni gidi kan ni, kì í wulẹ̀ ṣe ibi tí ó wà nínú ọkàn-àyà ẹnì kan. (Matteu 4:​1-⁠11) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a dá a bí áńgẹ́lì olódodo kan, ‘kò dúró ṣinṣin ninu òtítọ́.’ Ẹ wo bí ó ti bá a mu gẹ́lẹ́ nígbà náà pé a pè é ní Satani Èṣù! (Ìṣípayá 12:9) A pè é ní “Satani,” tàbí “alátakò,” nítorí ó ti lòdì sí Jehofa ó sì ti takò ó. Ọ̀daràn yìí ni a tún pè ní “Èṣù,” tí ó túmọ̀ sí “afọ̀rọ̀ èké banijẹ́,” nítorí pé ó ti ṣojú fún Ọlọrun lọ́nà òdì.

6. Èéṣe tí Satani fi ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun?

6 Kí ni ó sún Satani láti ṣọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọrun? Wọ̀bìà. Ó fi wọ̀bìà ṣojúkòkòrò ìjọsìn tí Jehofa ń gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn. Èṣù kò kọ ìfẹ́-ọkàn láti gba irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀, tí ó fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ jẹ́ ti Ẹlẹ́dàá nìkan ṣoṣo. (Fiwé Esekieli 28:​12-⁠19.) Kàkà bẹ́ẹ̀, áńgẹ́lì náà tí ó di Satani tọ́ ìfẹ́-ọkàn oníwọ̀bìà náà dàgbà títí tí ó fi lóyún tí ó sì bí ẹ̀ṣẹ̀.​—⁠Jakọbu 1:​14, 15.

7. (a) Kí ní fa ikú ẹ̀dá ènìyàn? (b) Kí ni ẹ̀ṣẹ̀?

7 A ti dá ọ̀daràn náà tí ìwà ọ̀daràn rẹ̀ ti yọrí sí ikú àwọn ẹ̀dá ènìyàn mọ̀. Ṣùgbọ́n kí ni ṣokùnfà ikú ẹ̀dá ènìyàn gan-⁠an? Bibeli sọ pé: “Oró-ìtani tí ń mú ikú jáde ni ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Korinti 15:56) Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀? Láti lóye ọ̀rọ̀ yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ tí ó gbé rù nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti Bibeli. Ọ̀rọ̀ ìṣe Heberu ati Griki tí a sábà máa ń túmọ̀ sí “láti ṣẹ̀” túmọ̀ sí “láti tàsé” ní èrò títàsé ìlà kan tàbí ṣíṣàìbá góńgó kan. Ìlà wo ni gbogbo wa ti tàsé rẹ̀? Ìlà ìgbọràn pípé sí Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni a ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wọnú ayé?

BÍ RÌKÍṢÍ NÁÀ ṢE ṢẸLẸ̀

8. Báwo ni Satani ṣe gbìyànjú láti jèrè ìjọsìn àwọn ẹ̀dá ènìyàn?

8 Satani fi tìṣọ́ra tìṣọ́ra hùmọ̀ rìkíṣí kan tí ó lérò pé yóò ṣamọ̀nà sí kí òun máa ṣàkóso gbogbo ẹ̀dá ènìyàn kí òun sì rí ìjọsìn wọn gbà. Ó pinnu láti rọ tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Adamu ati Efa, lọ́kàn láti ṣẹ̀ lòdì sí Ọlọrun. Jehofa ti fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní ìmọ̀ tí ìbá ti sìn wọ́n lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Wọn mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wọn dára nítorí ó fi wọ́n sínú ọgbà Edeni ẹlẹ́wà náà. Adamu ní pàtàkì nímọ̀lára ìwàrere Bàbá rẹ̀ ọ̀run nígbà tí Ọlọrun fún un ní aya rírẹwà àti olùrànlọ́wọ́. (Genesisi 1:26, 29; 2:7-⁠9, 18-⁠23) Ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́ náà tí ń bá a nìṣó sinmi lórí ìgbọràn wọn sí Ọlọrun.

9. Àṣẹ wo ni Ọlọrun fún ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, èésìtiṣe tí èyí fi lọ́gbọ́n nínú?

9 Ọlọrun pàṣẹ fún Adamu pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ kí ó máa jẹ. Ṣùgbọ́n nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú nì, ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀: nítorí pé ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀ kíkú ni ìwọ óò kú.” (Genesisi 2:​16, 17) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wọn, Jehofa Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ láti gbé ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwàhíhù kalẹ̀ kí ó sì pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Òfin rẹ̀ lọ́gbọ́n nínú nítorí pé Adamu àti Efa lómìnira láti jẹ èso gbogbo igi mìíràn nínú ọgbà náà. Wọ́n lè fi ìmọrírì wọn hàn fún ẹ̀tọ́ Jehofa láti ṣàkóso nípa ṣíṣègbọràn sí òfin yìí dípò kí wọ́n fi ìgbéraga gbé àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwàhíhù tiwọn fúnra wọn kalẹ̀.

10. (a) Báwo ni Satani ṣe tọ ẹ̀dá ènìyàn lọ láti fà wọ́n sí ìhà ọ̀dọ̀ rẹ̀? (b) Kí ni èrò búburú tí Satani jẹ́wọ́ rẹ̀ nípa Jehofa? (d) Kí ni o rò nípa àtakò Satani lòdì sí Ọlọrun?

10 Èṣù pète láti fa ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. Láti fà wọ́n wá sí ìhà ọ̀dọ̀ tirẹ̀, Satani purọ́. Ní lílo ejò kan, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ọlọ́sanyìn kan ti ń lo ọmọlangidi, Èṣù béèrè lọ́wọ́ Efa pé: “Òótọ́ ni Ọlọrun wí pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ gbogbo èso igi ọgbà?” Nígbà tí Efa mẹ́nukan àṣẹ Ọlọrun, Satani polongo pé: “Ẹ̀yin kì yóò kú ikú kíkú kan.” Lẹ́yìn náà ó jẹ́wọ́ èrò búburú nípa Jehofa nípa sísọ pé: “Ọlọrun mọ̀ pé, ní ọjọ́ tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, nígbà náà ni ojú yín yóò là, ẹ̀yin óò sì dàbí Ọlọrun, ẹ óò mọ rere àti búburú.” (Genesisi 3:​1-⁠5) Èṣù tipa báyìí sọ pé Ọlọrun ń fawọ́ ohun rere kan sẹ́yìn. Ẹ wo irú ìfọ̀rọ̀ èké banijẹ́ tí ìyẹn jẹ́ sí Jehofa, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́!

11. Báwo ni Adamu àti Efa ṣe di abániṣebi pẹ̀lú Satani?

11 Efa wo igi náà lẹ́ẹ̀kan síi, ó sì jọ pé nísinsìnyí èso rẹ̀ fanimọ́ra yàtọ̀. Nítorí náà ó mú èso náà ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ darapọ̀ mọ́ ọn nínú ìgbésẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ti ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọrun yìí. (Genesisi 3:6) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tan Efa jẹ, òun àti Adamu ti ìpètepèrò Satani lẹ́yìn láti ṣàkóso ìran ẹ̀dá ènìyàn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọn di abániṣebi pẹ̀lú rẹ̀.​—⁠Romu 6:16; 1 Timoteu 2:14.

12. Kí ni ìyọrísí ìṣọ̀tẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn sí Ọlọrun?

12 Adamu àti Efa níláti dojúkọ àbájáde ìgbésẹ̀ wọn. Wọn kò dàbí Ọlọrun, pẹ̀lú àkànṣe ìmọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú tì wọ́n, wọ́n sì fi ara wọn pamọ́. Jehofa pe Adamu fún ìjíhìn ó sì kéde ìdájọ́ yìí: “Ní òógùn ojú rẹ ni ìwọ óò máa jẹun, títí ìwọ óò fi padà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.” (Genesisi 3:19) “Ní ọjọ́” náà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, Ọlọrun dájọ́ fún wọn, wọ́n sì kú ní ojú-ìwòye rẹ̀. Lẹ́yìn náà ó lé wọn jáde kúrò nínú Paradise wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀kalẹ̀ sínú ikú ti ara ìyára.

BÍ Ẹ̀ṢẸ̀ ÀTI IKÚ ṢE GBILẸ̀

13. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lọ yíká dé ọ̀dọ̀ gbogbo ìran ẹ̀dá ènìyàn?

13 Ó dàbí ẹni pé Satani ti ṣàṣeyọrí nínú ìpètepèrò rẹ̀ láti gba ìjọsìn ẹ̀dá ènìyàn. Síbẹ̀, òun kò lè pa àwọn olùjọsìn rẹ̀ mọ́ láàyè. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, wọn kò lè ta àtaré ìjẹ́pípé sí irú-ọmọ wọn mọ́. Bí àkọlé tí a gbẹ́ sára òkúta, a fín ẹ̀ṣẹ̀ jinlẹ̀ wọnú apilẹ̀-àbùdá àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Nípa báyìí, wọ́n wulẹ̀ lè mú irú-ọmọ aláìpé jáde. Níwọ̀n bí Adamu àti Efa ti lóyún gbogbo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, irú-ọmọ wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.​—⁠Orin Dafidi 51:⁠5; Romu 5:12.

14. (a) Àwọn wo ni a lè fi àwọn tí wọ́n sẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn wé? (b) Báwo ni a ṣe mú àwọn ọmọ Israeli mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀?

14 Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò gbà pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Ní àwọn apá ibì kan ní ayé, èròǹgbà ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún kò wọ́pọ̀ rárá. Ṣùgbọ́n ìyẹn kì í ṣe ẹ̀rí pé ẹ̀ṣẹ̀ kò sí. Ọmọdékùnrin kan tí ojú rẹ̀ dọ̀tí lè sọ pé òun mọ́ tónítóní, ó wulẹ̀ lè yí èrò rẹ̀ padà kìkì lẹ́yìn tí ó bá wo jígí. Àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì dàbí irú ọmọdékùnrin bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n gba Òfin Ọlọrun nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀ Mose. Òfin náà mú kí ó ṣe kedere pé ẹ̀ṣẹ̀ wà. Aposteli Paulu ṣàlàyé pé: “Níti gidi emi kì bá tí wá mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí kì í bá ṣe nitori Òfin.” (Romu 7:​7-⁠12) Bíi ti ọmọdékùnrin tí ń wo jígí, nípa lílo Òfin náà láti wo ara wọn, àwọn ọmọ Israeli lè rí i pé àwọn jẹ́ aláìmọ́ ní ojú Jehofa.

15. Kí ni wíwo inú jígí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣípayá?

15 Nípa wíwo jígí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí a sì ṣàkíyèsí àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n rẹ̀, a lè ríi pé a jẹ́ aláìpé. (Jakọbu 1:​23-⁠25) Fún àpẹẹrẹ, gbé ohun tí Jesu Kristi sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹ̀wò nípa nínífẹ̀ẹ́ Ọlọrun àti àwọn aládùúgbò, bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Matteu 22:​37-⁠40. Ẹ wo bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ti ń tàsé ìlà ní àwọn apá wọ̀nyí léraléra tó! Ẹ̀rí-ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò tilẹ̀ sọ kúlú lórí ìkùnà wọn láti fi ìfẹ́ hàn fún Ọlọrun tàbí fún aládùúgbò wọn.​—⁠Luku 10:​29-⁠37.

ṢỌ́RA FÚN ÀWỌN ỌGBỌ́N-Ẹ̀WẸ́ SATANI!

16. Kí ni a lè ṣe láti yẹra fún dídi òjìyà àwọn ìpètepèrò Satani, èésìtiṣe tí èyí fi ṣòro?

16 Satani ń wá láti sún wa láti mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀. (1 Johannu 3:8) Ọ̀nà èyíkéyìí ha wà láti gbà yẹra fún dídi òjìyà àwọn ìpètepèrò rẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n èyí béèrè pé kí a bá àwọn ìtẹ̀sí èrò síhà mímọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ jà. Èyí kò rọrùn nítorí pé ìtẹ̀sí tí a bímọ́ wa láti dẹ́ṣẹ̀ lágbára gan-⁠an. (Efesu 2:3) Paulu níláti jìjàkadì gidigidi. Èéṣe? Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ń gbé nínú rẹ̀. Bí a bá fẹ́ ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ bá àwọn ìtẹ̀sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà nínú wa jà.​—⁠Romu 7:14-⁠24; 2 Korinti 5:10.

17. Kí ní mú kí ìjà lòdìsí àwọn ìtẹ̀sí ẹlẹ́ṣẹ̀ wa túbọ̀ ṣòro síi?

17 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé léraléra ni Satani ń wá àwọn àǹfààní láti tàn wá sínú rírú àwọn òfin Ọlọrun, ìjà tí a ń bá ẹ̀ṣẹ̀ jà kò rọrùn. (1 Peteru 5:8) Ní fífi ìdàníyàn hàn fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Paulu sọ pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò naa ti sún Efa dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò ninu òtítọ́-inú ati ìwàmímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.” (2 Korinti 11:3) Satani ń lo ìtẹ̀sí irú èrò kan náà lónìí. Ó ń gbìyànjú láti gbin àwọn èso iyèméjì nípa ìwàrere Jehofa àti àwọn àǹfààní ìṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọrun. Èṣù ń gbìyànjú láti lo àǹfààní ìtẹ̀sí àìpé sí ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún kí ó sì sún wa lépa ipa-ọ̀nà ìgbéraga, wọ̀bìà, ìkórìíra, àti ẹ̀tanú.

18. Báwo ni Satani ṣe ń lo ayé láti gbé ẹ̀ṣẹ̀ lárugẹ?

18 Ọ̀kan lára àwọn irin-iṣẹ́ tí Èṣù ń lò lòdì sí wa ni ayé, èyí tí ó wà lábẹ́ agbára rẹ̀. (1 Johannu 5:19) Bí a kò bá ṣọ́ra, àwọn oníwà ìbàjẹ́ àti alábòsí inú ayé tí ó yí wa ká yóò fi agbára mú wa láti tẹ̀lé ipa ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ń tẹ àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwàhíhù Ọlọrun lójú. (1 Peteru 4:​3-⁠5) Ọ̀pọ̀ ṣàìfiyèsí òfin Ọlọrun tí wọ́n sì ń kọ̀ láti fiyèsí ìgbúnníkẹ́ṣẹ́ ẹ̀rí-ọkàn wọn, nígbẹ̀yìn gbẹ́yín wọn yóò sọ ọ́ di aláìnímọ̀lára. (Romu 2:14, 15; 1 Timoteu 4:​1, 2) Àwọn kan ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ń tẹ̀lé ipa-ọ̀nà tí ẹ̀rí-ọkàn aláìpé wọ́n kò tilẹ̀ gbà wọ́n láyè láti tọ̀ tẹ́lẹ̀rí.​—⁠Romu 1:​24-⁠32; Efesu 4:​17-⁠19.

19. Èéṣe tí kò fi tó láti wulẹ̀ gbé ìgbésí-ayé tí ó mọ́ tónítóní?

19 Àṣeyọrí kan ni ó jẹ́ láti gbé ìgbésí-ayé tí ó mọ́ tónítóní nínú ayé yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, láti wu Ẹlẹ́dàá wa, púpọ̀ síi ni a béèrè. A tún gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun kí a sì nímọ̀lára ẹrù-iṣẹ́ fún un. (Heberu 11:6) Jakọbu ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Bí ẹni kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́ síbẹ̀ tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” (Jakọbu 4:17) Bẹ́ẹ̀ni, mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìfiyèsí Ọlọrun àti àwọn àṣẹ rẹ̀ pàápàá jẹ́ irú ẹ̀ṣẹ̀ kan.

20. Báwo ni Satani ṣe lè gbìyànjú láti ṣèdíwọ́ fún ọ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n kí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dènà irú àwọn ìkìmọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀?

20 Ó ṣeé ṣe kí Satani fẹ́ná àtakò rẹ̀ mọ́ ìlépa rẹ láti ní ìmọ̀ Ọlọrun nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. A retí nítòótọ́ pé ìwọ kì yóò jẹ́ kí irú ìkìmọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ọ láti ṣe ohun tí ó tọ́. (Johannu 16:2) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jesu lákòókò iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀, wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀ nítorí wọ́n bẹ̀rù pé a óò yẹra fún wọn ládùúgbò. (Johannu 12:​42, 43) Pẹ̀lú ìsánjú ni Satani fi ń gbìyànjú láti mú àyà ẹnikẹ́ni tí ó ń wá ìmọ̀ Ọlọrun pami. Bí ó ti wù kí ó rí, o yẹ kí o máa rántí kí o sì mọrírì àwọn ohun yíyanilẹ́nu tí Jehofa ti ṣe nígbà gbogbo. Ó tilẹ̀ lè ran àwọn alátakò lọ́wọ́ láti jèrè irú ìmọrírì kan náà.

21. Báwo ni a ṣe lè ṣẹ́gun ayé àti àwọn ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa fúnra wa?

21 Níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì jẹ́ aláìpé, a óò máa dẹ́ṣẹ̀. (1 Johannu 1:8) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìrànlọ́wọ́ wà láti ja ìjà yìí. Bẹ́ẹ̀ni, ó ṣeé ṣe láti jẹ́ aṣẹ́gun nínú ìjà wa lòdì sí ẹni búburú náà, Satani Èṣù. (Romu 5:21) Ní òpin iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu lórí ilẹ̀-ayé, ó fún àwọn ọmọlẹ́yìn ní ìṣírí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ninu ayé ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣugbọn ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Johannu 16:33) Àní fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, ó ṣeé ṣe láti ṣẹ́gun ayé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun. Satani kò lè di àwọn wọnnì tí wọ́n kọ ojú ìjà sí i tí wọ́n sì ‘fi ara wọn sábẹ́ Ọlọrun’ mú pinpin. (Jakọbu 4:⁠7; 1 Johannu 5:18) Gẹ́gẹ́ bí a óò ti ríi, Ọlọrun ti pèsè ọ̀nà àbájáde kúrò nínú ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Ta ni Satani Èṣù?

Èéṣe tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú?

Kí ni ẹ̀ṣẹ̀?

Báwo ni Satani ṣe ń fa àwọn ènìyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ dá sí Ọlọrun?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 54]