Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso

Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso

Orí 10

Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso

1, 2. Báwo ni àwọn àkóso ẹ̀dá ènìyàn ṣe jásí èyí tí kò tóótun?

BÓYÁ o ti ní ìrírí ríra irinṣẹ́ kan rí, kìkì láti ríi lẹ́yìn náà pé kò ṣiṣẹ́. Jẹ́ kí a sọ pé o pe ẹni tí ń tún ẹ̀rọ ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, kété lẹ́yìn tí ó “tún” irinṣẹ́ náà “ṣe,” ó tún ṣíwọ́ iṣẹ́. Wo bí ìyẹn yóò ti jánikulẹ̀ tó!

2 Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú àkóso ẹ̀dá ènìyàn. Aráyé ti fìgbà gbogbo nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí àkóso kan tí yóò ríi dájú pé àlàáfíà àti ayọ̀ wà. Síbẹ̀, àwọn ìsapá amúnilàágùn láti ṣàtúnṣe ìwólulẹ̀ àwùjọ kò tíì yọrí sí rere nítòótọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé àdéhùn àlàáfíà ni a ti ṣe​—⁠tí a sì tàpá sí lẹ́yìn náà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àkóso wo ni ó ti lè fòpin sí òṣì, ẹ̀tanú, ìwà-ọ̀daràn, òkùnrùn, àti bíba ibùgbé àwọn ohun alààyè jẹ́? Àkóso ènìyàn ti kọjá àtúnṣe. Kódà ọlọ́gbọ́n Ọba Solomoni ti Israeli béèrè pé: “Ta ni nínú àwọn ènìyàn tí ó lè mọ ọ̀nà rẹ̀?”​—⁠Owe 20:24.

3. (a) Kí ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìwàásù Jesu? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn kan ṣe ṣàpèjúwe Ìjọba Ọlọrun?

3 Máṣe sọ̀rètínù! Àkóso kan tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ kì í ṣe àlá kan lásán. Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìwàásù Jesu nìyẹn. Ó pè é ní “ìjọba Ọlọrun,” ó sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún un. (Luku 11:⁠2; 21:31) Nítòótọ́, Ìjọba Ọlọrun ni a ń dárúkọ láàárín agbo àwọn onísìn. Níti tòótọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń gbàdúrà fún un lójoojúmọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtúnkà Àdúrà Oluwa (tí a tún ń pè ní Baba Wa Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run tàbí àdúrà àwòṣe). Ṣùgbọ́n ìdáhùn àwọn ènìyàn máa ń yàtọ̀ nígbà tí a bá béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Ìjọba Ọlọrun?” Àwọn kan sọ pé, “Ó wà nínú ọkàn-àyà rẹ.” Àwọn mìíràn pè é ní ọ̀run. Bibeli pèsè ìdáhùn tí ó ṣe kedere, bí a óò ṣe rí i.

ÌJỌBA KAN PẸ̀LÚ ÈTE

4, 5. Èéṣe tí Jehofa fi yàn láti mú kí ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ fara hàn lọ́nà titun, kí ni yóò sì ṣàṣeparí rẹ̀?

4 Nígbà gbogbo ni Jehofa Ọlọrun ti jẹ́ Ọba, tàbí Alákòóso Ọba-Aláṣẹ, gbogbo àgbáyé. Òtítọ́ náà pé ó dá gbogbo àwọn nǹkan gbé e sí ipò tí ó ga jùlọ yẹn. (1 Kronika 29:11; Orin Dafidi 103:19; Ìṣe 4:24) Ṣùgbọ́n Ìjọba tí Jesu wàásù nípa rẹ̀ jẹ́ alátìlẹyìn, tàbí igbákejì, sí ipò ọba-aláṣẹ àgbáyé Ọlọrun. Ìjọba Messia náà ní ète pàtó kan, ṣùgbọ́n kí ni?

5 Bí a ti ṣàlàyé ní Orí 6, ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ọlá-àṣẹ Ọlọrun. Nítorí àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn tí a gbé dìde, Jehofa yàn láti mú kí ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ fara hàn lọ́nà titun. Ọlọrun kéde ète rẹ̀ láti mú “irú-ọmọ” kan jáde tí yóò tẹ Ejò náà, Satani rẹ́, kí ó sì mú gbogbo ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún kúrò. Jesu Kristi ni “irú-ọmọ” onípò kìn-⁠ínní náà, “ìjọba Ọlọrun” sì ni irin iṣẹ́ tí yóò ṣẹ́gun Satani pátápátá. Nípasẹ̀ Ìjọba yìí, Jesu Kristi yóò dá agbára ìṣàkóso lórí ilẹ̀-ayé padà ní orúkọ Jehofa yóò sì dá ẹ̀tọ́ ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun láre títí láé fáàbàdà.​—⁠Genesisi 3:15; Orin Dafidi 2:​2-⁠9.

6, 7. (a) Níbo ni Ìjọba náà wà, àwọn wo sì ni Ọba àti alájùmọ̀ṣàkóso rẹ̀? (b) Àwọn wo ni ọmọ-abẹ́ Ìjọba náà?

6 Ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ kan nípa ọ̀rọ̀ Jesu fún àwọn Farisi oníwà búburú, ó sọ pé: “Ìjọba Ọlọrun ń bẹ nínú yín.” (Luku 17:21, Bibeli Mimọ) Jesu ha ní in lọ́kàn pé Ìjọba náà wà lọ́kàn-àyà búburú ti àwọn ọkùnrin oníwà ìbàjẹ́ wọnnì bí? Rárá. Ìtumọ̀ tí ó túbọ̀ péye ti èdè Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀ kà pé: “Ìjọba Ọlọrun wà ní àárín yín.” (Ìtumọ̀ Ayé Titun) Jesu, tí ó wà ní àárín wọn, tipa báyìí tọ́ka sí ara rẹ̀ bí Ọba lọ́la. Jìnnà réré sí ohun kan tí ẹnì kan ní ní ọkàn-àyà rẹ̀, Ìjọba Ọlọrun jẹ́ àkóso gidi kan, tí ń ṣiṣẹ́, tí ó ní alákòóso àti àwọn ọmọ-abẹ́. Ó jẹ́ àkóso ti ọ̀run, nítorí tí a pè é ní “ìjọba awọn ọ̀run” àti “ìjọba Ọlọrun.” (Matteu 13:11; Luku 8:10) Nínú ìran, wòlíì Danieli rí Alákòóso rẹ̀ bí “ẹnì kan bí [ọmọkùnrin] ènìyàn” tí ó wá síwájú Ọlọrun Olódùmarè a sì fi “agbára ìjọba fún un, àti ògo, àti ìjọba, kí gbogbo ènìyàn, àti orílẹ̀, àti èdè, kí ó lè máa sìn ín.” (Danieli 7:​13, 14) Ta ni Ọba yìí? Tóò, Bibeli pe Jesu Kristi ní “Ọmọkùnrin ènìyàn.” (Matteu 12:40; Luku 17:26) Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa yan Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, láti jẹ́ Ọba.

7 Jesu kò dánìkan ṣàkóso. Àwọn 144,000 tí “a ti rà lati ilẹ̀-ayé wá” wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ́ àjùmọ̀jọba àti àjùmọ̀jẹ́ àlùfáà. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3; Luku 22:​28-⁠30) Àwọn ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọrun yóò jẹ́ ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kárí-ayé tí ó tẹríba fún ipò aṣáájú Kristi. (Orin Dafidi 72:​7, 8) Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni ó ṣe lè dá wa lójú pé Ìjọba náà yóò dá ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun láre nítòótọ́ kí ó sì mú ipò paradise padàbọ̀ sí ilẹ̀-ayé wa?

ÌJÓTÌÍTỌ́ ÌJỌBA ỌLỌRUN

8, 9. (a) Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé ìṣeégbáralé àwọn ìlérí Ìjọba Ọlọrun? (b) Èéṣe tí a fi lè ní ìdánilójú òtítọ́ gidi nípa Ìjọba náà?

8 Finú yàwòrán pé iná ti jó ilé rẹ. Ní báyìí ọ̀rẹ́ tí ó ní agbára rẹ̀ ṣèlérí láti bá ọ tún ilé rẹ kọ́ kí ó sì pèsè oúnjẹ fún ìdílé rẹ. Bí ọ̀rẹ́ náà bá ti ń fi ìgbà gbogbo sọ òtítọ́ fún ọ, ìwọ kì yóò ha gbà á gbọ́ bí? Kí a sọ pé o dé ilé láti ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e tí o sì rí àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti palẹ̀ pàǹtírí tí iná náà ṣokùnfà mọ́, tí wọ́n sì ti gbé oúnjẹ wá fún ìdílé rẹ. Kò sí iyèméjì pé ìwọ yóò ní ìgbọ́kànlé pátápátá pé bí àkókò ti ń lọ, kì í wulẹ̀ ṣe pé a óò mú àwọn nǹkan padàbọ̀sípò nìkan ni ṣùgbọ́n nǹkan yóò tilẹ̀ túbọ̀ sàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

9 Lọ́nà kan náà, Jehofa fún wa ní ìdánilójú pé Ìjọba náà jẹ́ òtítọ́ gidi. Bí ìwé Bibeli náà Heberu ti fi hàn, ọ̀pọ̀ apá Òfin náà jẹ́ òjìji ìṣáájú fún ìṣètò Ìjọba náà. (Heberu 10:1) Ìjọba Israeli lórí ilẹ̀-ayé tún pèsè ẹ̀rí àrítẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun. Ìyẹn kì í ṣe àkóso kan lásán, nítorí pé àwọn alákòóso rẹ̀ jókòó sórí “ìtẹ́ Oluwa.” (1 Kronika 29:23) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ti sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pá-aládé kì yóò ti ọwọ́ Judah kúrò, bẹ́ẹ̀ ni olófin kì yóò kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣiloh yóò fi dé; òun ni àwọn ènìyàn yóò gbọ́ tirẹ̀.” (Genesisi 49:10) * Bẹ́ẹ̀ni, sínú ìlà àwọn ọba Judah yìí ni a óò bí Jesu, Ọba títílọ gbére ti àkóso Ọlọrun sí.​—⁠Luku 1:​32, 33.

10. (a) Nígbà wo ni a fi ìpìlẹ̀ Ìjọba Messia Ọlọrun sọlẹ̀? (b) Iṣẹ́ pàtàkì wo ni àwọn alájùmọ̀ṣàkóso Jesu lọ́la níláti jẹ́ òléwájú fún lórí ilẹ̀-ayé?

10 Ìpìlẹ̀ fún Ìjọba Messia Ọlọrun ni a fi lélẹ̀ pẹ̀lú yíyan àwọn aposteli Jesu. (Efesu 2:19, 20; Ìṣípayá 21:14) Àwọn wọ̀nyí ni àkọ́kọ́ lára 144,000 tí yóò ṣàkóso ní ọ̀rún bí àjùmọ̀jọba pẹ̀lú Jesu Kristi. Nígbà tí wọ́n bá ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé, àwọn alájùmọ̀ṣàkóso lọ́la wọ̀nyí yóò léwájú nínú ìgbétáásì ìjẹ́rìí kan, ní ìlà pẹ̀lú àṣẹ Jesu pé: “Ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́.”​—⁠Matteu 28:19.

11. Báwo ni a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lónìí, kí ni ó sì ń ṣàṣeparí rẹ̀?

11 Àṣẹ náà láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ-ẹ̀yìn ni a ń ṣègbọràn sí ní ọ̀nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pòkìkí ìhìnrere Ìjọba náà káàkiri gbogbo ayé, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jesu pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matteu 24:14) Bí apá kan lára iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ títóbi kan ni a ti dáwọ́lé. Ní báyìí ná àwọn wọnnì tí wọ́n juwọ́sílẹ̀ fún àwọn òfin àti ìlànà Ìjọba Ọlọrun ti ń nírìírí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tí àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn kò lè ṣàṣeyọrí rẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ ẹ̀rí tí ó ṣe kedere pé Ìjọba Ọlọrun jẹ́ òtítọ́ gidi!

12. (a) Èéṣe tí ó fi bá a mu wẹ́kú láti pé àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ní Ẹlẹ́rìí Jehofa? (b) Báwo ni Ìjọba Ọlọrun ṣe yàtọ̀ sí àkóso ẹ̀dá ènìyàn?

12 Jehofa sọ fún àwọn ọmọ Israeli pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . àti ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.” (Isaiah 43:​10-⁠12) Jesu, “Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé,” fi ìtara polongo ìhìnrere Ìjọba náà. (Ìṣípayá 1:⁠5; Matteu 4:17) Nítorí náà ó bá a mu wẹ́kú pé àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà lóde-òní ń jẹ́ orúkọ tí a yàn láti ọ̀run wá náà Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi ń lo àkókò àti ìsapá tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun? Wọ́n ń ṣe èyí nítorí pe Ìjọba náà ni ìrètí kanṣoṣo tí aráyé ní. Àkóso ẹ̀dá ènìyàn yóò dẹnu kọlẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà, ṣùgbọ́n Ìjọba Ọlọrun kì yóò dẹnu kọlẹ̀ láé. Isaiah 9:​6, 7 pe Alákòóso rẹ̀, Jesu, ní “Ọmọ-Aládé Àlàáfíà” ó sì fi kún un pé: “Ìjọba yóò bí síi, àlàáfíà kì yóò ní ìpẹ̀kun.” Ìjọba Ọlọrun kò dàbí àkóso ènìyàn​—⁠tí ó wà lónìí tí a bìṣubú lọ́la. Nítòótọ́, Danieli 2:44 sọ pé: “Ọlọrun ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títí láé: a kì yóò sì fi ìjọba náà lé orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́, . . . òun óò dúró títí láéláé.”

13. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí Ìjọba Ọlọrun yóò bójútó lọ́nà yíyọrí sí rere? (b) Èéṣe tí ó fi lè dá wa lójú pé àwọn ìlérí Ọlọrun yóò ní ìmúṣẹ?

13 Ọba ẹ̀dá ènìyàn wo ni ó lè mú ogun, ìwà-ọ̀daràn, àìsàn, ebi, àti àìrílégbé kúrò? Síwájú síi, alákòóso orí ilẹ̀-ayé wo ni ó lè jí àwọn tí wọ́n ti kú dìde? Ìjọba Ọlọrun àti Ọba rẹ̀ yóò bójútó àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Ìjọba náà kì yóò ṣaláìgbéṣẹ́, bí irinṣẹ́ tí kò ṣiṣẹ́ tí ó nílò àtúnṣe lóòrèkóòrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìjọba Ọlọrun yóò ṣàṣeyọrí sí rere, nítorí Jehofa ṣèlérí pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lófo, ṣùgbọ́n yóò ṣe èyí tí ó wù mí, yóò sì máa ṣe rere nínú ohun tí mo rán an.” (Isaiah 55:11) Ète Ọlọrun kì yóò kùnà, ṣùgbọ́n ìgbà wo ni ìṣàkóso Ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀?

ÌṢÀKÓSO ÌJỌBA​—⁠ÌGBÀ WO NI?

14. Àwọn àṣìlóye wo ni awọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní nípa Ìjọba náà, ṣùgbọ́n kí ni Jesu mọ̀ nípa agbára ìṣàkóso rẹ̀?

14 “Oluwa, iwọ ha ń mú ìjọba padàbọ̀sípò fún Israeli ní àkókò yii bí?” Ìbéèrè tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu béèrè yìí ṣí i payá pé síbẹ̀ wọn kò tí ì mọ ète Ìjọba Ọlọrun àti àkókò tí a ti yàn fún ìṣàkóso rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀. Ní kíkìlọ̀ fún wọn láti máṣe méfò lórí ọ̀ràn náà, Jesu sọ pé: “Kì í ṣe tiyín lati mọ awọn àkókò tabi àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ oun fúnra rẹ̀.” Jesu mọ̀ pé agbára ìṣàkóso rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé ni a ti fi pamọ́ fún ọjọ́-iwájú, tipẹ́tipẹ́ lẹ́yìn àjíǹde àti ìgòkè re ọ̀run rẹ̀. (Ìṣe 1:​6-⁠11; Luku 19:​11, 12, 15) Ìwé Mímọ́ ti sọ́ èyí tẹ́lẹ̀. Báwo ni?

15. Báwo ni Orin Dafidi 110:1 ṣe tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìdiwọ̀n àkókò agbára ìṣàkóso Jesu?

15 Bí ó ti tọ́ka sí Jesu lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ bí “Oluwa,” Ọba Dafidi sọ pé: “Gbólóhùn àsọjáde Jehofa fún Oluwa mi ni: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tun mi títí èmi yóò fi gbé àwọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí-ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’” (Orin Dafidi 110:1, NW; fiwé Ìṣe 2:​34-⁠36.) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé agbára ìṣàkóso Jesu kì yóò bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìgòkè re ọ̀run rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. (Heberu 10:​12, 13) Báwo ni dídúró yìí yóò ṣe pẹ́ tó? Ìgbà wo ni agbára ìṣàkóso rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀? Bibeli ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ìdáhùn náà.

16. Kí ní ṣẹlẹ̀ ní 607 B.C.E., ìsopọ̀ wo ni èyí sì ní pẹ̀lú Ìjọba Ọlọrun?

16 Ìlú-ńlá kanṣoṣo tí Jehofa fi orúkọ rẹ̀ sí lórí ilẹ̀-ayé ni Jerusalemu. (1 Ọba 11:36) Ó tún jẹ́ olú-ìlú ìjọba tí Ọlọrun fọwọ́sí lórí ilẹ̀-ayé tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ irú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun. Nítorí náà, ìparun Jerusalemu láti ọwọ́ àwọn ara Babiloni ní 607 B.C.E. jámọ́ pàtàkì. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìbẹ́gidí ìṣàkóso Ọlọrun ní tààràtà lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé fún àkókò gígùn kan. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jesu fi hàn pé sáà tí a fi bẹ́gi dí ìṣàkóso yìí ṣì wà síbẹ̀, nítorí ó sọ pé: “Awọn orílẹ̀-èdè yoo sì tẹ Jerusalemu mọ́lẹ̀, títí awọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè yoo fi pé.”​—⁠Luku 21:24.

17. (a) Kí ni “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè,” báwo ni wọn yóò sì ṣe gùn tó? (b) Nígbà wo ni “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè” bẹ̀rẹ̀ tí ó sì parí?

17 Láàárín “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè,” àwọn àkóso ayé ni a óò yọ̀ǹda fún láti bẹ́gidí agbára ìṣàkóso tí Ọlọrun fọwọ́sí. Sáà yẹn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun Jerusalemu ní 607 B.C.E., Danieli sì fi hàn pé yóò máa bá a lọ fún “ìgbà méje.” (Danieli 4:​23-⁠25) Báwo ni ìyẹn ti gùn tó? Bibeli fi hàn pé “awọn àkókò” mẹ́ta àti ààbọ̀ jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú 1,260 ọjọ́. (Ìṣípayá 12:​6, 14) Ìlọ́po méjì sáà yẹn, tàbí ìgbà méje, yóò jẹ́ 2,520 ọjọ́. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó gbàfiyèsí tí ó ṣẹlẹ̀ ní òpin sáà àkókò kúkúrú yẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, nípa ṣíṣe ìfisílò “ọjọ́ kan fún ọdún kan” sí àsọtẹ́lẹ̀ Danieli tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí ka 2,520 ọdún láti 607 B.C.E., a dé ọdún 1914 C.E.​—⁠Numeri 14:34; Esekieli 4:6.

18. Kí ni Jesu ṣe kété lẹ́yìn tí ó gba agbára Ìjọba, báwo ni èyí sì ṣe kan ilẹ̀-ayé?

18 Jesu ha bẹ̀rẹ̀ síí ṣàkóso ní ọ̀run ní ìgbà yẹn bí? A óò jíròrò àwọn ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún sísọ pé ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní orí tí ó tẹ̀lé e. Àmọ́ ṣáá o, ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Jesu ni àlàáfíà ojú-ẹsẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé kì yóò sàmì sí. Ìṣípayá 12:​7-⁠12 fi hàn pé kété lẹ́yìn tí ó bá gba Ìjọba náà, Jesu yóò lé Satani àti àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ jùnù kúrò ní ọ̀run. Èyí yóò túmọ̀ sí ègbé fún ilẹ̀-ayé, ṣùgbọ́n ó ń fúnni ní ìṣírí láti kà pé kìkì “sáà àkókò kúkúrú” ni ó ṣẹ́kù fún Èṣù. Láìpẹ́, yóò ṣeé ṣe fún wa láti yọ̀ kì í ṣe kìkì nítorí pé Ìjọba Ọlọrun ń ṣàkóso ṣùgbọ́n nítorí pé yóò mú àwọn ìbùkún wá sórí ilẹ̀-ayé àti fún àwọn aráyé onígbọràn pẹ̀lú. (Orin Dafidi 72:​7, 8) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé èyí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 9 Orúkọ náà Ṣiloh túmọ̀ sí “Ti Ẹni Tí Ó Jẹ́; Ẹni náà Tí Ó Jẹ́ Tirẹ̀.” Nígbà tí ó yá, ó dájú pé Jesu Kristi ni “Ṣiloh” náà, “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Judah.” (Ìṣípayá 5:5) Díẹ̀ lára àwọn Targum wulẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà “Messia” tàbí “ọba Messia” rọ́pò “Ṣiloh.”

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Kí ni Ìjọba Ọlọrun, láti ibo ni ó sì ti ń ṣàkóso?

Ta ni ń ṣàkóso nínú Ìjọba náà, àwọn wo sì ni ọmọ-abẹ́ rẹ̀?

Báwo ni Jehofa ti ṣe mú un dá wa lójú pé òtítọ́ gidi ni Ìjọba rẹ̀?

Nígbà wo ni “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè” bẹ̀rẹ̀ tí ó sì parí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 94]

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ PÀTÀKÌ DÍẸ̀ TÍ Ó SOPỌ̀ MỌ́ ÌJỌBA ỌLỌRUN

• Jehofa kéde ète rẹ̀ láti mú “irú-ọmọ” kan jáde tí yóò tẹ orí Ejò náà, Satani Èṣù rẹ́.​—⁠Genesisi 3:15.

• Ní 1943 B.C.E., Jehofa fi hàn pé “irú-ọmọ” yìí yóò jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Abrahamu.​—⁠Genesisi 12:1-⁠3, 7; 22:18.

• Májẹ̀mú Òfin tí a fún Israeli ní 1513 B.C.E. jẹ́ “òjìji awọn ohun rere tí ń bọ̀.”​—⁠Eksodu 24:​6-⁠8; Heberu 10:1.

• Ìjọba Israeli orí ilẹ̀-ayé bẹ̀rẹ̀ ní 1117 B.C.E., ó sì ń bá a lọ lẹ́yìn náà ní ìlà Dafidi.​—⁠1 Samueli 11:15; 2 Samueli 7:​8, 16.

• A pa Jerusalemu run ní 607 B.C.E., “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè” sì bẹ̀rẹ̀.​—⁠2 Ọba 25:​8-10, 25, 26; Luku 21:24.

• Ní 29 C.E., a yan Jesu bí Ọba-Lọ́la tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé.​—⁠Matteu 3:16, 17; 4:17; 21:9-⁠11.

• Ní 33 C.E., Jesu gòkè re ọ̀run, láti dúró níbẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun títí di ìgbà tí ìṣàkóso rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀.​—⁠Ìṣe 5:​30, 31; Heberu 10:​12, 13.

• A gbé Jesu gorí ìtẹ́ nínú Ìjọba ọ̀run ní 1914 C.E. gẹ́gẹ́ bí “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè” ti dópin.​—⁠Ìṣípayá 11:15.

• Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a ju sísàlẹ̀ sí sàkáání ilẹ̀-ayé tí èyí sì mú ègbé tí ó pọ̀ síi wá fún aráyé.​—⁠Ìṣípayá 12:​9-⁠12.

• Jesu ń ṣàbójútó ìwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun yíká-ayé.​—⁠Matteu 24:14; 28:19, 20.