Ìwé Náà Tí Ó Ṣí Ìmọ̀ Ọlọrun Payá
Orí 2
Ìwé Náà Tí Ó Ṣí Ìmọ̀ Ọlọrun Payá
1, 2. Èéṣe tí a fi nílò ìtọ́sọ́nà Ẹlẹ́dàá wa?
Ó WULẸ̀ bọ́gbọ́nmu pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ yóò pèsè ìwé ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà kan fún aráyé. Ìwọ kò ha sì fohùnṣọ̀kan pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn nílò ìtọ́sọ́nà bí?
2 Ní ohun tí ó ju 2,500 ọdún lọ, wòlíì àti òpìtàn kan kọ̀wé pé: “Kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Jeremiah 10:23) Lónìí, ìjótìítọ́ gbólóhùn yẹn túbọ̀ ṣe kedere ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Nípa báyìí, òpìtàn William H. McNeill sọ pé: “Ìrírí ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀wọ́ àwọn yánpọnyánrin àti ìdabarú tí ń bá a nìṣó lórí ètò tí ẹgbẹ́ àwùjọ gbé kalẹ̀.”
3, 4. (a) Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli? (b) Báwo ni a óò ṣe bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò Bibeli?
3 Bibeli kájú gbogbo àìní wa fún ìdarísọ́nà ọlọgbọ́n. Òtítọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ ń nímọ̀lára àìnírànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò Bibeli. Ìwé ńlá ni, apákan lára rẹ̀ sì ṣòro láti lóye. Ṣùgbọ́n bí a bá fún ọ ní ìwé-àṣẹ ìhágún tí ó ṣètòlẹ́sẹẹsẹ ohun tí o níláti ṣe kí o ba lè rí ogún tí ó ṣeyebíye gbà, ìwọ kì yóò ha wá àkókò láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀ dáradára? Bí o bá rí apá kan nínú ìwé-àṣẹ náà tí ó ṣòro láti lóye, ó ṣeé ṣe pé ìwọ yóò béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ẹnì kan tí ó nírìírí nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Èéṣe tí o kò fi yẹ Bibeli wò pẹ̀lú ìṣarasíhùwà kan náà? (Ìṣe 17:11) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó ní nínú ju ogún ohun-ìní ti ara lọ. Bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ ní orí tí ó ṣáájú, ìmọ̀ Ọlọrun lè sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.
4 Jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ìwé tí ó ṣí ìmọ̀ Ọlọrun payá. Lákọ̀ọ́kọ́, a óò pèsè àkópọ̀ ṣókí nípa Bibeli. Lẹ́yìn náà, a óò jíròrò àwọn ìdí tí ọ̀pọ̀ amòye ènìyàn fi gbàgbọ́ pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí Ọlọrun.
OHUN TÍ Ó WÀ NÍNÚ BIBELI
5. (a) Kí ni ohun tí ó wà nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu? (b) Kí ni ohun tí Ìwé Mímọ́ Lédè Griki ní nínú?
5 Bibeli ní ìwé 66 tí ó pín sí apá méjì, tí a sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Titun nínú. Ìwé 39 nínú Bibeli ni ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kìkì èdè Heberu ni a fi kọ wọ́n tí 27 sì jẹ́ ní èdè Griki. Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, tí ó ní Genesisi títí dé Malaki nínú, kárí ìṣẹ̀dá àti 3,500 ọdún àkọ́kọ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Nípa ṣíṣàyẹ̀wò apá yìí nínú Bibeli, a kọ́ nípa ìbálò Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli—láti ìgbà tí a ti bí wọn bí orílẹ̀-èdè kan ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún B.C.E. títí di ọ̀rúndún karùn-ún B.C.E. * Ìwé Mímọ́ Lédè Griki, tí ó ní ìwé Matteu títí dé Ìṣípayá nínú, pe àfiyèsí sí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìgbòkègbodò Jesu Kristi àti ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìn-ínní C.E.
6. Èéṣe tí a fi níláti ṣàyẹ̀wò odindi Bibeli?
6 Àwọn kan sọ pé “Májẹ̀mú Láéláé” wà fún àwọn Júù tí “Májẹ̀mú Titun” sì wà fún àwọn Kristian. Ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú 2 Timoteu 3:16, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní.” Nítorí náà, ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ ní gbogbo odidi Bibeli nínú. Níti gidi, àwọn apá Bibeli méjèèjì jẹ́ àṣekún ara wọn, wọ́n sopọ̀ lọ́nà tí ó báramu láti gbé ẹṣin-ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo kalẹ̀.
7. Kí ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ Bibeli?
7 Bóyá o ti ń lọ sí ibi ìsìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí o sì ti gbọ́ tí wọ́n ka apá kan Bibeli sókè ketekete. Tàbí o ti lè ka àwọn
àyọkà láti inú rẹ̀ fúnra rẹ. O ha mọ̀ pé Bibeli ní èrò kan náà tí ó sokọ́ra láti Genesisi títí dé Ìṣípayá bí? Bẹ́ẹ̀ni, ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí ó báramu kan ni a lè rí nínú Bibeli. Kí ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà? Ìdáláre ẹ̀tọ́ Ọlọrun láti ṣàkóso aráyé àti ìmúṣẹ ète onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ni. Nígbà tí ó bá yá, a óò ríi bí Ọlọrun yóò ṣe mú ète yìí ṣẹ níti gidi.8. Kí ni Bibeli ṣípayá nípa ànímọ́ Ọlọrun?
8 Ní àfikún sí ṣíṣètòlẹ́sẹẹsẹ ète Ọlọrun, Bibeli ṣí ànímọ́ rẹ̀ payá. Fún àpẹẹrẹ, a kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bibeli pé Ọlọrun ní ìmọ̀lára àti pé àwọn yíyàn tí a bá ṣe kan an. (Orin Dafidi 78:40, 41; Owe 27:11; Esekieli 33:11) Orin Dafidi 103:8-14 sọ pé Ọlọrun jẹ́ “aláàánú àti olóore, ó lọ́ra àti bínú, ó sì pọ̀ ní àánú.” Ó ń fi ìyọ́nú bá wa lò, ‘ní rírántí pé erùpẹ̀ ni wa’ tí a sì ń padà síbẹ̀ nígbà ikú. (Genesisi 2:7; 3:19) Ẹ wo àwọn ànímọ́ yíyanilẹ́nu tí òun fi hàn! Èyí kì í ha ṣe irú Ọlọrun tí o fẹ́ láti jọ́sìn bí?
9. Báwo ni Bibeli ṣe fún wa ní ojú-ìwòye tí ó ṣe kedere nípa àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun, báwo sì ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀?
1 Àwọn Ọba 5:4; 11:4-6; 2 Kronika 15:8-15) Láìsí iyèméjì kíka irú àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ gidi wọ̀nyí yóò ní ipa lórí ọkàn-àyà wa. Bí a bá gbìyànjú láti fojú inú wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, a lè ní ìmọ̀lára tí àwọn ènìyàn tí ọ̀ràn kàn ní. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ rere a sì lè yẹra fún àwọn ọ̀fìn tí ó dẹkùn mú àwọn oníwà àìtọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbéèrè ṣíṣekókó yìí nílò ìdáhùn: Báwo ni ó ṣe lè dá wa lójú pé nítòótọ́ ni ohun tí a kà nínú Bibeli ní ìmísí Ọlọrun?
9 Bibeli pèsè ojú-ìwòye tí ó ṣe kedere nípa àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun. Nígbà mìíràn, ìwọ̀nyí ni a là sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n hàn nínú àwọn ìlànà tí a kọ́ láti inú àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ṣeé rí. Ọlọrun mú kí a kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nígbà ìtàn àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì sílẹ̀ fún àǹfààní wa. Àwọn àkọsílẹ̀ tí ó jẹ́ òtítọ́ wọ̀nyí fi ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá ṣiṣẹ́ ní ìbáramu pẹ̀lú ète Ọlọrun hàn, àti àbájáde bíbaninínújẹ́ nígbà tí wọ́n bá yàn láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́. (O HA LÈ GBẸ́KẸ̀LÉ BIBELI BÍ?
10. (a) Èéṣe tí àwọn kan fi nímọ̀lára pé Bibeli kò bá ìgbà mu? (b) Kí ni 2 Timoteu 3:16, 17 sọ fún wa nípa Bibeli?
10 Bóyá o ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn ń di èyí tí kò bá ìgbà mu mọ́ lẹ́yìn ọdún díẹ̀ péré. Bibeli ń kọ́? Ó ti lọ́jọ́ lórí gan-an, 2,000 ọdún sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọjá lẹ́yìn tí a kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́yìn nínú rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí èyí, àwọn kan nímọ̀lára pé kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú sànmánì ìgbàlódé wa. Ṣùgbọ́n bí Bibeli bá ní ìmísí Ọlọrun, ìmọ̀ràn rẹ̀ níláti bá ìgbà mu ní gbogbo ìgbà láìka ọ̀pọ̀ ọdún rẹ̀ sí. Ìwé Mímọ́ náà ṣì níláti “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí ninu òdodo, kí ènìyàn Ọlọrun lè pegedé ní kíkún, tí a mú 2 Timoteu 3:16, 17.
gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—11-13. Èéṣe tí a fi lè sọ pé Bibeli gbéṣẹ́ fún ọjọ́ wa?
11 Àyẹ̀wò kínníkínní ṣípayá pé àwọn ìlànà Bibeli ṣeé fi sílò lónìí bákan náà gan-an bí ó ti rí nígbà tí a kọ́kọ́ kọ wọ́n sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, bí ó bá kan ìwà ẹ̀dá ènìyàn, Bibeli ṣàgbéyọ òye jíjinlẹ̀ tí ó ṣeé fi sílò fún gbogbo ìran aráyé. A lè tètè rí èyí nínú Ìwàásù Jesu Lórí Òkè, tí ó wà nínú ìwé Matteu, orí 5 sí 7. Ìwàásù yìí wọ olóògbé olórí ilẹ̀ India náà Mohandas K. Gandhi lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí ìròyìn fi sọ pé ó sọ fún aláṣẹ Britain kan pé: “Nígbà tí orílẹ̀-èdè tìrẹ àti tèmi bá lè jùmọ̀ fohùnṣọ̀kan lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Kristi fi lélẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè yìí, a óò ti yanjú àwọn ìṣòro gbogbo ayé lápapọ̀ kì í ṣe ti orílẹ̀-èdè wa nìkan.”
12 Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé ẹ̀kọ́ Jesu wọ àwọn ènìyàn lọ́kàn! Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, ó fi ọ̀nà sí ayọ̀ tòótọ́ hàn wá. Ó ṣàlàyé bí a ṣe lè yanjú awuyewuye. Jesu pèsè ìtọ́ni lórí bí a ṣe lè gbàdúrà. Ó tọ́ka sí ìṣarasíhùwà tí ó lọ́gbọ́n nínú jùlọ láti ní síhà àwọn ohun-ìní ti ara ó sì fún wa ní Òfin Oníwúrà fún àjọṣepọ̀ tí ó tọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bí a ṣe lè jádìí jìbìtì ìsìn àti bí a ṣe lè ní ọjọ́-ọ̀la aláìléwu tún wà lára àwọn kókó tí ó mẹ́nukàn nínú ìwàásù yìí.
13 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè àti jálẹ̀ àwọn ojú-ìwé rẹ̀ tí ó kù, ní kedere ni Bibeli sọ fún wa ohun tí ó yẹ kí a ṣe àti ohun tí ó yẹ kí a yẹra fún láti lè mú kí ìpín-ìní wa nínú ìgbésí-ayé sunwọ̀n síi. Ìmọ̀ràn rẹ̀ gbéṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí a fi sún ọ̀mọ̀wé kan láti sọ pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ olùdámọ̀ràn ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga pẹ̀lú oyè-ẹ̀kọ́ ìpele àkọ́kọ́ àti èkejì ní yunifásítì tí mo sì ti ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé lórí ìlera ọpọlọ àti ìrònú ẹ̀dá, mo ṣàwárí pé ìmọ̀ràn Bibeli lórí irú àwọn nǹkan bíi ṣíṣe àṣeyọrí sí rere nínú ìgbéyàwó, ṣíṣèdílọ́wọ́ fún ìyapòkíì màjèṣí àti bí a ṣe lè rí, kí a sì ní àwọn ọ̀rẹ́ ga lọ́la ju ohunkóhun mìíràn tí mo tíì kà tàbí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ rí ní kọ́lẹ́ẹ̀jì.” Ní àfikún sí jíjẹ́ èyí tí ó gbéṣẹ́ tí ó sì bá ìgbà mu, Bibeli ṣeé gbáralé.
Ó PÉYE Ó SÌ ṢEÉ FỌKÀNTẸ̀
14. Kí ní fi hàn pé Bibeli péye níti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀?
14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bibeli kì í ṣe ìwé-ẹ̀kọ́ lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ó péye níti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Fún àpẹẹrẹ, ní ìgbà tí ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn gbàgbọ́ pé ilẹ̀-ayé rí pẹrẹsẹ, wòlíì Isaiah tọ́ka sí i bí “òbírí” kan (Heberu, chugh, tí ó gbé èrò “òbíríkítí” jáde níhìn-ín). (Isaiah 40:22) Èrò nípa ilẹ̀-ayé olóbìíríkítí kan ni a kò tẹ́wọ́gbà níbi gbogbo títí fi di ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ọjọ́ Isaiah. Síwájú síi, Jobu 26:7—tí a kọ ní èyí tí ó ju 3,000 ọdún sẹ́yìn—sọ pé Ọlọrun “fi ayé rọ̀ ní ojú òfo.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bibeli kan sọ pé: “Bí Jobu ṣe mọ òtítọ́ náà, tí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmà fi hàn, pé ayé sorọ̀ láìní ohun kankan tí ó ṣeé rí tí ó gbé e dúró lójú òfúúrufú, jẹ́ ìbéèrè kan tí kò rọrùn láti yanjú lọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n sẹ́ ìmísí Ìwé Mímọ́.”
15. Báwo ni ọ̀nà ìgbàkọ̀ròyìn ṣe túbọ̀ fún ìgbọ́kànlé nínú Bibeli lókun?
15 Ọ̀nà ìgbàkọ̀ròyìn tí a rí nínú Bibeli tún fún ìgbọ́kànlé wa lókun nínú ìwé tí ó lọ́jọ́ lórí yìí. Láìdàbí ìtàn àròsọ, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bibeli mẹ́nukàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn àti déètì gidi pàtó. (1 Awọn Ọba 14:25; Isaiah 36:1; Luku 3:1, 2) Bí ó sì ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn òpìtàn ìgbàanì máa ń sọ àsọdùn nípa ìṣẹ́gun àwọn alákòóso wọn tí wọ́n a sì bo ìfìdírẹmi àti àwọn àṣìṣe wọn mọ́lẹ̀, àwọn òǹkọ̀wé Bibeli jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlábòsí—kódà nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tiwọn fúnra wọn.—Numeri 20:7-13; 2 Samueli 12:7-14; 24:10.
ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀ KAN
16. Kí ni ẹ̀rí tí ó lágbára jùlọ pé Bibeli ní ìmísí Ọlọrun?
16 Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ pèsè ẹ̀rí tí kò ṣeé jáníkoro pé Bibeli ní ìmísí Ọlọrun. Bibeli ní ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní ìmúṣẹ ní kíkún nínú. Ní kedere, ẹ̀dá ènìyàn kankan kò lè jẹ́ okùnfà fún èyí. Nígbà náà, kí ní wà lẹ́yìn àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí? 2 Peteru 1:21) Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò.
Bibeli fúnra rẹ̀ sọ pé “a kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nipa ìfẹ́-inú ènìyàn, ṣugbọn awọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun bí ẹ̀mí mímọ́,” tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun, “ti ń darí wọn.” (17. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ó sọ ṣáájú nípa ìṣubú Babiloni, báwo sì ni àwọn wọ̀nyí ṣe ní ìmúṣẹ?
17 Ìṣubú Babiloni. Isaiah àti Jeremiah sọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Babiloni láti ọwọ́ àwọn ará Media àti Persia. Lọ́nà tí ó pẹtẹrí, àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni a kọ sílẹ̀ nígbà tí Babiloni wà ní òtéńté agbára rẹ̀, nǹkan bíi 200 ọdún ṣáájú ìparun Babiloni! Àwọn apá tí ó tẹ̀lé e yìí nípa àsọtẹ́lẹ̀ náà ti di ọ̀ràn àkọsílẹ̀ ìtàn nísinsìnyí: mímú kí Odò Eufrate gbẹ nípa dídarí omi inú rẹ̀ lọ sínú adágún àtọwọ́dá kan (Isaiah 44:27; Jeremiah 50:38); fífi ìwà àìbìkítà ṣàìpèsè ààbò sí àwọn ẹnubodè odò Babiloni (Isaiah 45:1); àti ìṣẹ́gun láti ọwọ́ olùṣàkóso kan tí ń jẹ́ Kirusi.—Isaiah 44:28.
18. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣe ní ìmúṣẹ níti ìdìde àti ìṣubú “ọba [ilẹ̀ Griki]”?
18 Ìdìde àti ìṣubú “ọba [ilẹ̀ Griki].” Nínú ìran kan, Danieli rí òbúkọ tí ó lu agbo kan bolẹ̀, tí ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Lẹ́yìn náà, ìwo ńlá ewúrẹ́ náà ni a ṣẹ́, tí ìwo mẹ́rin sì dìde ní ipò rẹ̀. (Danieli 8:1-8) A ṣàlàyé fún Danieli pé: “Àgbò náà tí ìwọ rí tí ó ní ìwo méjì nì, àwọn ọba Media àti Persia ni wọ́n. Òbúkọ onírun nì ni ọba [ilẹ̀ Griki]: ìwo ńlá tí ó wà láàárín ojú rẹ̀ méjèèjì ni ọba èkínní. Ǹjẹ́ bí èyíinì sì ti ṣẹ́, tí ìwo mẹ́rin mìíràn sì dìde dúró nípò rẹ̀, ìjọba mẹ́rin ni yóò dìde nínú orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n kì yóò ṣe nínú agbára rẹ̀.” (Danieli 8:20-22) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn náà, “ọba [ilẹ̀ Griki],” Alexander Ńlá, bi Ilẹ̀-Ọba Media àti Persia oníwo-méjì náà ṣubú. Alexander kú ní 323 B.C.E. tí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ mẹ́rin sì rọ́pò rẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìjọba tí ó dìde lẹ́yìn náà tí ó lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbára ilẹ̀-ọba Alexander.
19. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ó ní ìmúṣẹ nínú Jesu Kristi?
Mika 5:2; Luku 2:4-7) Isaiah, alájọgbáyé Mika, sọtẹ́lẹ̀ pé Messia náà ni a óò lù tí a óò sì tutọ́ sí lára. (Isaiah 50:6; Matteu 26:67) Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ṣáájú, Sekariah sọtẹ́lẹ̀ pé Messia náà ni a óò fi léni lọ́wọ́ fún 30 ẹyọ fàdákà. (Sekariah 11:12; Matteu 26:15) Ní èyí tí ó ju ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú àkókò, Dafidi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àyíká ipò tí ó sopọ̀ mọ́ ikú Messia náà Jesu. (Orin Dafidi 22:7, 8, 18; Matteu 27:35, 39-43) Ní nǹkan bí ọ̀rúndún márùn-ún ṣáájú, àsọtẹ́lẹ̀ Danieli ṣí ìgbà tí Messia náà yóò fara hàn payá àti gígùn iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ àti àkókò ikú rẹ̀. (Danieli 9:24-27) Èyí wulẹ̀ jẹ́ kìkì àpẹẹrẹ díẹ̀ tí a gbéyẹ̀wò lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní ìmúṣẹ nínú Jesu Kristi. Ìwọ yóò rí i bí ohun tí ó lérè láti ka púpọ̀ púpọ̀ síi nípa rẹ̀ nígbà tí ó bá yá.
19 Ìgbésí-ayé Jesu Kristi. Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ìbí, iṣẹ́-òjíṣẹ́, ikú, àti àjíǹde Jesu múṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, ní èyí tí ó ju 700 ọdún ṣáájú, Mika sọtẹ́lẹ̀ pé Messia náà, tàbí Kristi, ni a óò bí ní Betlehemu. (20. Ìgbọ́kànlé wo ni ó yẹ kí àkọsílẹ̀ pípéye ti àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tí ó ní ìmúṣẹ fún wa?
20 Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli alákòókò gígùn ti ní ìmúṣẹ. O lè béèrè pé: ‘Ṣùgbọ́n báwo ni èyí ṣe kan ìgbésí-ayé mi?’ Ó dára, bí ẹnì kan bá ti ń sọ òtítọ́ fún ọ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ìwọ yóò ha ṣàdéédé ṣiyèméjì nípa rẹ̀ nígbà tí ó bá sọ ohun titun kan bí? Rárá! Ọlọrun ti sọ òtítọ́ jálẹ̀jálẹ̀ Bibeli. Kò ha yẹ kí ìyẹn fún ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú àwọn ìlérí Bibeli lókun, irú bí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa paradise ilẹ̀-ayé tí ń bọ̀? Nítòótọ́, a lè ní ìgbọ́kànlé kan náà tí Paulu, ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní ọ̀rúndún kìn-ínní ní, tí ó kọ̀wé pé ‘Ọlọrun kò lè purọ́.’ (Titu 1:2) Síwájú síi, nígbà tí a bá ka Ìwé Mímọ́ tí a sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, a ń lo ọgbọ́n tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn kò lè dá jèrè fúnra wọn, nítorí Bibeli ni ìwé tí ó ṣí ìmọ̀ Ọlọrun tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun payá.
“NÍ ÌYÁNHÀNHÀN” FÚN ÌMỌ̀ ỌLỌRUN
21. Kí ni ó yẹ kí o ṣe bí àwọn ohun kan tí o kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bibeli bá dàbí èyí tí ń mú ọkàn rẹ pòrúùru?
21 Bí o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó ṣeé ṣe kí o kọ́ àwọn ohun tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a ti kọ́ ọ tẹ́lẹ̀. O tilẹ̀ lè ríi pé àwọn àṣà ìsìn tí o nífẹ̀ẹ́ sí kò wu Ọlọrun. Ìwọ yóò kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọrun ní àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ tí ó ga ju àwọn tí ó wọ́pọ̀ nínú ayé onígbọ̀jẹ̀gẹ́ yìí lọ. Èyí lè dàbí ohun tí ń mú ọkàn rẹ pòrúùru lákọ̀ọ́kọ́. Ṣùgbọ́n mú sùúrù! Farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ láti rí ìmọ̀ Ọlọrun. Ṣí ọkàn rẹ sílẹ̀ fún ṣíṣeéṣe náà pé ìmọ̀ràn Bibeli lè béèrè fún àtúnṣe nínú ìrònú àti àwọn ìgbésẹ̀ rẹ.
22. Èéṣe tí o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, báwo sì ni o ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti lóye èyí?
22 Àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí tí wọ́n ní èrò rere lè tako ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ nínú Bibeli, ṣùgbọ́n Jesu sọ pé: “Nígbà naa, olúkúlùkù ẹni Matteu 10:32, 33) Àwọn kan lè bẹ̀rù pé ìwọ yóò lọ́wọ́ nínú ẹgbẹ́ awo kan tàbí pé ìwọ yóò di agbawèrèmẹ́sìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ní tòótọ́, o wulẹ̀ ń sapá láti jèrè ìmọ̀ pípéye ti Ọlọrun àti òtítọ́ rẹ̀ ni. (1 Timoteu 2:3, 4) Láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti lóye èyí, fòyebánilò, máṣe jiyàn, nígbà tí o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí o ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (Filippi 4:5) Rántí pé ọ̀pọ̀ ni a “jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan” nígbà tí wọ́n bá rí ẹ̀rí pé ìmọ̀ Bibeli ń ṣe àwọn ènìyàn láǹfààní níti gidi.—1 Peteru 3:1, 2.
tí ó bá jẹ́wọ́ ìrẹ́pọ̀ pẹlu mi níwájú awọn ènìyàn, dájúdájú emi pẹlu yoo jẹ́wọ́ ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní awọn ọ̀run; ṣugbọn ẹni yòówù tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹlu mi níwájú awọn ènìyàn, dájúdájú emi pẹlu yoo sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹlu rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní awọn ọ̀run.” (23. Báwo ni o ṣe lè “ní ìyánhànhàn” fún ìmọ̀ Ọlọrun?
23 Bibeli rọ̀ wá pé: “Gẹ́gẹ́ bí awọn ọmọdé jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa.” (1 Peteru 2:2) Ọmọdé jòjòló kan gbáralé oúnjẹ àfibọ́ni láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ ó sì ń tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé kí á kájú àìní yẹn. Lọ́nà kan náà, a gbáralé ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. “Ní ìyánhànhàn” fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa bíbá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó. Nítòótọ́, fi í ṣe góńgó rẹ láti máa ka Bibeli lójoojúmọ́. (Orin Dafidi 1:1-3) Èyí yóò mú ìbùkún ọlọ́ràá wá fún ọ, nítorí Orin Dafidi 19:11 sọ nípa àwọn òfin Ọlọrun pé: ‘Ní pípa wọn mọ́ èrè púpọ̀ ń bẹ.’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 B.C.E. túmọ̀ sí “ṣáájú Sànmánì Tiwa,” èyí tí ó tọ̀nà ju B.C. (“ṣáájú Kristi”). C.E. dúró fún “Sànmánì Tiwa,” tí a sábà máa ń pè ní A.D., fún anno Domini, tí ó túmọ̀ sí “ní ọdún Oluwa wa.”
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Ní àwọn ọ̀nà wo ni Bibeli fi yàtọ̀ sí àwọn ìwé mìíràn?
Èéṣe tí o fi lè gbẹ́kẹ̀lé Bibeli?
Kí ni ohun tí ó fún ọ ní ẹ̀rí pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
LO BIBELI RẸ LỌ́NÀ RERE
Kò yẹ kí ó ṣòro láti mọ Bibeli dunjú. Lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ kókó-ẹ̀kọ́ inú ìwé tí ó wà nínú rẹ̀ láti mọ ibi tí ìwé Bibeli kọ̀ọ̀kan wà àti bí a ṣe ṣètò rẹ̀.
Àwọn ìwé Bibeli ní àwọn orí àti ẹsẹ̀ fún ìtọ́kasí rírọrùn. Pípín sí orí ni a fi kún un ní ọ̀rúndún kẹtàlá, ó sì dàbí ẹni pé òǹtẹ̀wé ará France kan ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ni ó pín àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Griki sí àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ bí wọ́n ṣe wà lónìí. Odindi Bibeli tí ó kọ́kọ́ ní nọ́ḿbà orí àti ẹsẹ̀ jẹ́ ẹ̀dà èdè French, tí a tẹ̀jáde ní 1553.
Nígbà tí a bá tọ́ka sí àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ nínú ìwé yìí, nọ́ḿbà àkọ́kọ́ fi orí hàn, èyí tí ó tẹ̀lé e sì dúró fún ẹsẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìtọ́kasí náà “Owe 2:5” túmọ̀ sí ìwé Owe, orí 2, ẹsẹ̀ 5. Nípa yíyẹ àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí wò, yóò tètè rọrùn fún ọ láti rí àwọn ẹsẹ̀ Bibeli náà.
Ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti mọ Bibeli dunjú ni láti kà á lójoojúmọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, èyí lè dàbí ìpèníjà kan. Ṣùgbọ́n bí o bá ń ka orí mẹ́ta sí márùn-ún lọ́jọ́ kan, ó sinmi lórí bí ó bá ṣe gùn tó, ìwọ yóò parí kíka odindi Bibeli ní ọdún kan. Èéṣe tí o kò bẹ̀rẹ̀ lónìí?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
BIBELI—ÌWÉ KAN TÍ KÒ LẸ́GBẸ́
• “Ọlọrun mí sí” Bibeli. (2 Timoteu 3:16) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, Ọlọrun tọ́ èrò wọn sọ́nà, kí Bibeli ba lè jẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọrun” níti gidi.—1 Tessalonika 2:13.
• A kọ Bibeli fún ohun tí ó ju sáà ọ̀rúndún 16, láti ọwọ́ àwọn 40 olùṣètìlẹyìn tí wọ́n ti ipò àtilẹ̀wá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá. Láìka èyí sí, àpapọ̀ iṣẹ́ náà báramu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.
• Bibeli ti la àríyànjiyàn púpọ̀ já ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ. Ní Sànmánì Agbedeméjì, a sun àwọn ènìyàn lórí òpó igi kìkì nítorí pé wọ́n ní ẹ̀dà kan Ìwé Mímọ́.
• Bibeli gba ipò kìn-ínní bí ìwé tí ó tà jùlọ lágbàáyé. A ti túmọ̀ rẹ̀, lódindi tàbí lápákan, sí èdè tí ó lé ní 2,000. Ọ̀pọ̀ billion ẹ̀dà ni a ti tẹ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ibi kankan lórí ilẹ̀-ayé tí a kò ti lè rí ẹ̀dà kan.
• Apá tí ó lọ́jọ́lórí jùlọ nínú Bibeli ti wà láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún B.C.E. Èyí jẹ́ ṣáájú kí Rig-Veda ti ìsìn Hindu (ní nǹkan bíi 1300 B.C.E.) tó jẹyọ, tàbí “Àkájọ ti Àwọn Agbọ̀n Mẹ́ta” ti ìsìn Buddha (ọ̀rúndún karùn-ún B.C.E.), tàbí Koran ti ìsìn Islam (ọ̀rúndún keje C.E.), bákan náà sì ni Nihongi ti ìsìn Shinto (720 C.E.).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]