Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlá-Àṣẹ Ti Ta Ni Ó Yẹ Kí O Tẹ́wọ́gbà?

Ọlá-Àṣẹ Ti Ta Ni Ó Yẹ Kí O Tẹ́wọ́gbà?

Orí 14

Ọlá-Àṣẹ Ti Ta Ni Ó Yẹ Kí O Tẹ́wọ́gbà?

1, 2. Gbogbo irú ọlá-àṣẹ ni ó ha ń ṣèpalára bí? Ṣàlàyé.

“ỌLÁ-ÀṢẸ” jẹ́ ọ̀rọ̀ má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Èyí lè yéni, nítorí pé a sábà máa ń ṣi ọlá-àṣẹ lò​—⁠lẹ́nu iṣẹ́, nínú ìdílé, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn alákòóso. Bibeli sọ níti gidi pé: “Ẹnì kan ń [jẹgàba, NW] lórí ẹnì kejì rẹ̀ fún ìfarapa rẹ̀.” (Oniwasu 8:9) Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pọ̀ ti jẹgàba lórí àwọn mìíràn nípa híhùwà ní ọ̀nà òǹrorò tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́sin ara wọn.

2 Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ọlá-àṣẹ ni ó ń ṣèpalára. Fún àpẹẹrẹ, a lè sọ pé ara wa ń lo ọlá-àṣẹ lórí wa. Ó “ń pàṣẹ” fún wa láti mí, jẹun, mumi, kí a sì sùn. Ìyẹn ha ń panilára bí? Ó tì. Ṣíṣègbọràn sí àwọn ìbéèrè dandangbọ̀n wọ̀nyí jẹ́ fún ire wa. Nígbà tí ìjuwọ́sílẹ̀ fún àwọn ohun ti ara tí a nílò yìí lè má jẹ́ ohun tí a lè ṣàkóso, irú ọlá-àṣẹ mìíràn wà tí ó béèrè fún ìtẹríba tí a mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò.

ALÁṢẸ ONÍPÒ ÀJÙLỌ

3. Èéṣe tí a fi pe Jehofa ní “Oluwa Ọba-Aláṣẹ” gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́?

3 Ní iye ìgbà tí ó ju 300 lọ nínú Bibeli, Jehofa ni a pè ní “Oluwa Ọba-Aláṣẹ.” Ọba-aláṣẹ ni ẹnì kan tí ó ní ọlá-aṣẹ gíga jùlọ. Kí ni ó fún Jehofa ní ẹ̀tọ́ sí ipò yìí? Ìṣípayá 4:11 dáhùn pé: “Jehofa, àní Ọlọrun wa, iwọ ni ó yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbára, nitori pé iwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati nitori ìfẹ́-inú rẹ ni wọ́n ṣe wà tí a sì dá wọn.”

4. Báwo ni Jehofa ṣe yàn láti lo ọlá-àṣẹ rẹ̀?

4 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa, Jehofa ní ẹ̀tọ́ láti lo ọlá-àṣẹ rẹ̀ bí ó ṣe fẹ́. Èyí lè dẹ́rù báni, ní pàtàkì nígbà tí a bá ronú pé Ọlọrun ní “ọ̀pọ̀ yanturu okun inú alágbára-iṣẹ́.” A pè é ní “Ọlọrun Olódùmarè”​—⁠èdè ìsọ̀rọ̀ kan ní èdè Heberu tí ó gbé èrò agbára kan tí ń boni mọ́lẹ̀ yọ. (Isaiah 40:26, NW; Genesisi 17:1) Síbẹ̀, Jehofa fi agbára rẹ̀ hàn ní ọ̀nà ẹlẹ́mìí ìṣoore, nítorí ànímọ́ rẹ̀ tí ó hàn gbangba jùlọ ni ìfẹ́.​—⁠1 Johannu 4:16.

5. Èéṣe tí kò fi ṣòro láti juwọ́sílẹ̀ fún ọlá-àṣẹ Jehofa?

5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa kìlọ̀ pé òun yóò mú ìjìyà wá sórí àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronúpìwàdà, Mose mọ̀ ọ́n ní pàtàkì sí “Ọlọrun olóòótọ́, tí ń pa májẹ̀mú mọ́ àti àánú fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì pa òfin rẹ̀ mọ́.” (Deuteronomi 7:9) Wulẹ̀ rò ó wò ná! Aláṣẹ Onípò-Àjùlọ ní àgbáyé kò fi ipá mú wa láti jọ́sìn òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, a fà wá súnmọ́ ọn nítorí ìfẹ́ rẹ̀. (Romu 2:⁠4; 5:8) Jíjuwọ́sílẹ̀ fún ọlá-àṣẹ Jehofa tilẹ̀ gbádùnmọ́ni, nítorí àwọn òfin rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún ire wa dídára jùlọ nígbà gbogbo.​—⁠Orin Dafidi 19:​7, 8.

6. Báwo ni ọ̀ràn-àríyànjiyàn nípa ọlá-àṣẹ ṣe dìde ní ọgbà Edeni, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?

6 Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kọ ipò ọba-aláṣẹ Ọlọrun. Wọ́n fẹ́ láti pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú fún ara wọn. (Genesisi 3:​4-⁠6) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, a lé wọn jáde kúrò nínú ilé Paradise wọn. Lẹ́yìn náà Jehofa yọ̀ǹda fún àwọn ènìyàn láti ṣèdásílẹ̀ àwọn ìṣètò ọlá-àṣẹ tí yóò yọ̀ǹda fún wọn láti gbé nínú ẹgbẹ́ àwùjọ kan bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ tí ó wà létòlétò. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọlá-àṣẹ wọ̀nyí, dé ìwọ̀n àyè wo sì ni Ọlọrun retí pé kí a tẹríba fún wọn?

“ÀWỌN ALÁṢẸ ONÍPÒ GÍGA”

7. Àwọn wo ni “àwọn aláṣẹ onípò gíga,” ìsopọ̀ wo sì ni ipò wọn ní pẹ̀lú ọlá-àṣẹ Ọlọrun?

7 Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ awọn aláṣẹ onípò gíga, nitori kò sí ọlá-àṣẹ kankan àyàfi lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.” Àwọn wo ni “awọn aláṣẹ onípò gíga”? Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu ní àwọn ẹsẹ̀ tí ó tẹ̀lé e fi hàn pé ènìyàn ni wọ́n tí ń ṣàkóso bí aláṣẹ. (Romu 13:​1-⁠7; Titu 3:1) Jehofa kò pilẹ̀ àwọn aláṣẹ ènìyàn tí ń ṣàkóso, ṣùgbọ́n wọ́n wà lábẹ́ ìyọ̀ọ̀da rẹ̀. Nítorí náà Paulu lè kọ̀wé pé: “Awọn ọlá-àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.” Kí ni èyí fi hàn nípa irú ọlá-àṣẹ orí ilẹ̀-ayé bẹ́ẹ̀? Pé ó wà lábẹ́, tàbí pé ó rẹlẹ̀ lọ́lá, sí ọlá-àṣẹ Ọlọrun. (Johannu 19:​10, 11) Nítorí náà, nígbà tí ìforígbárí bá wà láàárín òfin ènìyàn àti òfin Ọlọrun, ẹ̀rí-ọkàn tí a ti fi Bibeli dá lẹ́kọ̀ọ́ ni ó gbọ́dọ̀ tọ́ àwọn Kristian sọ́nà. Wọ́n “gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.”​—⁠Ìṣe 5:29.

8. Báwo ni o ṣe ń jàǹfààní láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ onípò gíga, báwo ni o sì ṣe lè fi ìtẹríba rẹ hàn fún wọn?

8 Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn aláṣẹ onípò gíga tí ń ṣàkóso ń ṣiṣẹ́ bí ‘òjíṣẹ́ Ọlọrun fún ire wa.’ (Romu 13:4) Ní àwọn ọ̀nà wo? Ó dára, ronú nípa ọ̀pọ̀ ìpèsè fún lílò tí àwọn aláṣẹ onípò gíga ń pèsè, bí ìfìwéránṣẹ́, ọlọ́pàá àti panápaná, ìmọ́tótó, àti ìmọ̀-ẹ̀kọ́. Paulu kọ̀wé pé: “Ìdí nìyẹn tí ẹ̀yin fi ń san owó-orí pẹlu; nitori wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun sí gbogbo ènìyàn ní sísìn nígbà gbogbo fún ète yii gan-⁠an.” (Romu 13:6) Níti owó-orí tàbí ìbéèrè àìgbọdọ̀máṣe mìíràn tí ó bófinmu, a níláti “hùwà láìṣàbòsí.”​—⁠Heberu 13:18.

9, 10. (a) Báwo ni àwọn aláṣẹ onípò gíga ṣe bá ìṣètò Ọlọrun mu? (b) Èéṣe tí kì yóò fi tọ̀nà láti tako àwọn aláṣẹ onípò gíga?

9 Nígbà mìíràn àwọn aláṣẹ onípò gíga ń ṣi agbára wọn lò. Ìyẹn ha tú wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹrù-iṣẹ́ wa láti wà lábẹ́ wọn bí? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Jehofa rí àwọn ìwà àìtọ́ àwọn aláṣẹ wọ̀nyí. (Owe 15:3) Bí ó ti fàyègba ìṣàkóso ènìyàn kò túmọ̀ sí pé ó pa ojú dé sí ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò sì retí pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. Nítòótọ́, láìpẹ́ Ọlọrun yóò “fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run,” ní fífi àkóso òdodo tirẹ̀ rọ́pò wọn. (Danieli 2:44) Ṣùgbọ́n títí di ìgbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, àwọn aláṣẹ onípò gíga yóò ṣì máa sìn fún ète tí ó dára kan.

10 Paulu ṣàlàyé pé: “Ẹni tí ó bá tako ọlá-àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọrun.” (Romu 13:2) Àwọn aláṣẹ onípò gíga jẹ́ “ìṣètò” Ọlọrun níti pé dé ìwọ̀n àyè kan wọ́n mú kí nǹkan wà létòlétò, bí kò bá sí wọn júujùu àti rúgúdù yóò gbalẹ̀. Títakò wọ́n kì yóò bá Ìwé Mímọ́ mú kì yóò sì mọ́gbọ́ndání. Láti ṣàkàwé: Ronú pé o lọ fún iṣẹ́-abẹ tí àwọn fọ́nrán tí wọ́n fi rán ara pọ̀ sì ń ṣiṣẹ́ láti mú kí ọgbẹ́ náà jinná. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fọ́nrán tí wọ́n fi rán ara pọ̀ náà jẹ́ àjèjì sí ara, wọ́n ṣiṣẹ́ fún ète kan fún ìgbà díẹ̀. Títú wọn kúrò láìtọ́jọ́ lè ṣèpalára. Lọ́nà kan náà, àwọn aláṣẹ ènìyàn tí ń ṣàkóso kì í ṣe apákan ète Ọlọrun ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, títí di ìgbà tí Ìjọba rẹ̀ yóò máa ṣàkóso ilẹ̀-ayé pátápátá, àwọn alákòóso ènìyàn ṣì kó àwùjọ ènìyàn jọpọ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, ní ṣíṣe àwọn iṣẹ́ kan tí ó bá ìfẹ́-inú Ọlọrun ṣe déédéé fún àkókò wa. Nipa bẹ́ẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, bí a ti ń fi òfin Ọlọrun àti ọlá-àṣẹ rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́.

ỌLÁ-ÀṢẸ NÍNÚ ÌDÍLÉ

11. Báwo ni o ṣe lè ṣàlàyé ìlànà ipò orí?

11 Ìdílé jẹ́ ẹ̀ka ìpìlẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn. Nínú rẹ̀ ọkọ àti aya lè rí àjọṣepọ̀ tí ń mérè wá, àwọn ọmọ ni a sì lè dáàbòbò kí a sì tọ́ dàgbà. (Owe 5:​15-⁠21; Efesu 6:​1-⁠4) Ó yẹ kí a ṣe irú ètò tí ó dára kan bẹ́ẹ̀ ní ọ̀nà kan tí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé láti gbé ní àlàáfíà àti ìbáramuṣọ̀kan. Ọ̀nà Jehofa fún ṣíṣàṣeparí èyí jẹ́ nípasẹ̀ ìlànà ipò orí, tí a ṣàkópọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí a rí nínú 1 Korinti 11:3 pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀ orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀ orí Kristi ni Ọlọrun.”

12, 13. Ta ni olórí ìdílé, kí ni a sì lè kọ́ láti inú ọ̀nà tí Jesu ń gba lo ipò orí rẹ̀?

12 Ọkọ ni olórí ìdílé. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan wà ní orí rẹ̀​—⁠Jesu Kristi. Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ awọn aya yín, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Efesu 5:25) Ọkọ kan ń fi ìwàlábẹ́ Kristi rẹ̀ hàn nígbà tí ó bá ń bá aya rẹ̀ lò ní ọ̀nà tí Jesu gbà ń bá ìjọ lò nígbà gbogbo. (1 Johannu 2:6) Ọlá-àṣẹ ńlá ni a ti fi lé Jesu lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó ń lò ó pẹ̀lú ìṣepẹ̀lẹ́, pẹ̀lú ìfẹ́, àti ìlọ́gbọ́n nínú tí ó ga jùlọ. (Matteu 20:​25-⁠28) Bí ènìyàn kan, Jesu kò fi ìgbà kankan ṣi ipò ọlá-àṣẹ rẹ̀ lò. “Onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” ni, ó sì pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní “ọ̀rẹ́” kàkà kí ó pè wọ́n ní “ẹrú.” Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Emi yoo sì tù yín lára,” ohun tí ó sì ṣe gan-⁠an nìyẹn.​—⁠Matteu 11:​28, 29; Johannu 15:15.

13 Àpẹẹrẹ Jesu kọ́ àwọn ọkọ pé ipò orí Kristian kì í ṣe ipò ìjẹgàba léni lórí lọ́nà lílekoko. Kàkà bẹ́ẹ̀, ti ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ni. Dájúdájú èyí yóò fagilé híhùwà ìkà sí ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó níti ara-ìyára tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu. (Efesu 4:29, 31, 32; 5:28, 29; Kolosse 3:19) Bí ọkùnrin Kristian kan bá níláti hùwà ìkà sí aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn iṣẹ́ rere rẹ̀ mìíràn yóò jásí asán, àwọn àdúrà rẹ̀ yóò sì ní ìdílọ́wọ́.​—⁠1 Korinti 13:1-⁠3; 1 Peteru 3:7.

14, 15. Báwo ni ìmọ̀ Ọlọrun ṣe ń ran aya kan lọ́wọ́ láti wà lábẹ́ ipò orí ọkọ rẹ̀?

14 Nígbà tí ọkọ kan bá tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi, ó rọrùn fún aya rẹ̀ láti mú ara rẹ̀ bá àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Efesu 5:​22, 23 mu pé: “Kí awọn aya wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Oluwa, nitori pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti jẹ́ orí ìjọ.” Gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ọkọ kan ti níláti tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni aya kan níláti wà lábẹ́ ọkọ rẹ̀. Bibeli tún mú kí ó ṣe kedere pé àwọn aya tí ó dáńgájíá yẹ fún ọlá àti ìyìn fún ọgbọ́n oníwà-bí-Ọlọ́run àti akitiyan wọn.​—⁠Owe 31:​10-⁠31.

15 Ìtẹríba aya Kristian kan fún ọkọ rẹ̀ ní ààlà. Èyí túmọ̀ sí pé kì í ṣe ènìyàn bíkòṣe Ọlọrun ni ó gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí bí títẹríba nínú ọ̀ràn kan yóò bá yọrí sí títẹ òfin àtọ̀runwá lójú. Àní síbẹ̀ pàápàá, aya kan níláti fi “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ati ti ìwàtútù” kún ìdúró gbọn-⁠in gbọn-⁠in rẹ̀. Ó níláti hàn pé ìmọ̀ Ọlọrun ti mú kí ó di aya tí ó sàn jù. (1 Peteru 3:​1-⁠4) Bákan náà ni ọ̀ràn yóò ṣe rí pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Kristian ṣùgbọ́n tí aya rẹ̀ jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìgbọràn rẹ̀ sí àwọn ìlànà Bibeli níláti mú kí ó di ọkọ kan tí ó sàn jù.

16. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe lè farawé àpẹẹrẹ tí Jesu fi lélẹ̀ nígbà tí ó wà ní èwe?

16 Efesu 6:1 la iṣẹ́ àwọn ọmọ lẹ́sẹẹsẹ, ní sísọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí awọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Oluwa, nitori èyí jẹ́ òdodo.” Àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ Kristian ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu, ẹni tí ó wà lábẹ́ àwọn òbí rẹ̀ bí ó ti ń dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kan tí ó jẹ́ onígbọràn, ó “sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ninu ọgbọ́n ati ninu ìdàgbàsókè ti ara-ìyára ati ninu ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọrun ati ènìyàn.”​—⁠Luku 2:​51, 52.

17. Ọ̀nà tí àwọn òbí ń gbà lo ọlá-àṣẹ wọn lè ní irú ipa wo lórí àwọn ọmọ wọn?

17 Ọ̀nà tí àwọn òbí ń gbà bójútó àwọn ẹrù-iṣẹ́ wọn lè ní ipa lórí bóyá àwọn ọmọ yóò bọ̀wọ̀ fún ọlá-àṣẹ tàbí wọn yóò ṣọ̀tẹ̀ sí i. (Owe 22:6) Nítorí náà àwọn òbí lè béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, ‘Mo ha ń lo ọlá-àṣẹ mi lọ́nà onífẹ̀ẹ́ tàbí lọ́nà lílekoko? Mo ha ń gbọ̀jẹ̀gẹ́ bí?’ A retí pé kí òbí oníwà-bí-Ọlọ́run kan jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti olùgbatẹnirò, síbẹ̀ kí ó dúró gbọn-⁠in ní rírọ̀mọ́ àwọn ìlànà Ọlọrun. Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ máṣe máa sún awọn ọmọ yín bínú [lóréfèé, ‘sún wọn sí ìrunú’], ṣugbọn ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.”​—⁠Efesu 6:⁠4; Kolosse 3:21.

18. Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn òbí lo ìbáwí wọn?

18 Àwọn òbí níláti máa yẹ ọ̀nà ìgbàṣe ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn wò fínnífínní, pàápàá ní pàtàkì bí wọ́n bá ní ìfẹ́ ọkàn pé kí àwọn ọmọ wọn jẹ́ onígbọràn kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìdùnnú-ayọ̀ wá fún wọn. (Owe 23:​24, 25) Nínú Bibeli, èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìbáwí jẹ́ ìtọ́ni ní ìpìlẹ̀. (Owe 4:⁠1; 8:33) A so ó pọ̀ mọ́ ìfẹ́ àti ìwàtútù, kì í ṣe ìbínú àti ìwà òkú-òǹrorò. Nítorí náà, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristian níláti hùwà pẹ̀lú ọgbọ́n kí wọ́n sì ṣàkóso ara wọn nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí.​—⁠Owe 1:7.

ỌLÁ-ÀṢẸ NÍNÚ ÌJỌ

19. Báwo ni Ọlọrun ti ṣe pèsè fun ìṣètò dídára nínú ìjọ Kristian?

19 Níwọ̀n bí Jehofa ti jẹ́ Ọlọrun ètò, ó lọ́gbọ́n nínú pé òun yóò pèsè ipò aṣáájú tí a ṣètò dáradára tí ó sì ní ọlá-àṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó ti yan Jesu bí Orí ìjọ Kristian. (1 Korinti 14:​33, 40; Efesu 1:​20-⁠23) Lábẹ́ ipò aṣáájú Kristi tí a kò lè fojúrí, Ọlọrun ti fàṣẹ sí ìṣètò kan nínú èyí tí àwọn alàgbà tí a yàn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò ti máa ṣolùṣọ́ àgùtàn pẹ̀lú ìháragàgà, tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú, àti tìfẹ́tìfẹ́. (1 Peteru 5:​2, 3) Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ń ràn wọn lọ́wọ́ ní onírúurú ọ̀nà wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́-ìsìn tí ó níyelórí láàárín ìjọ.​—⁠Filippi 1:1.

20. Èéṣe tí ó fi yẹ kí a tẹríba fún àwọn Kristian alàgbà tí a yànsípò, èésìtiṣe tí èyí fi ṣàǹfààní?

20 Níti àwọn Kristian alàgbà, Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí awọn wọnnì tí ń mú ipò iwájú láàárín yín kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́mìí ìjuwọ́sílẹ̀ ní ìtẹríba, nitori wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí awọn wọnnì tí yoo ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹlu ìdùnnú-ayọ̀ kì í sì í ṣe pẹlu ìmí-ẹ̀dùn, nitori èyí yoo fa ìfarapa bá yín.” (Heberu 13:17) Lọ́nà ọgbọ́n, Ọlọrun ti fi ẹrù-iṣẹ́ láti bójútó àwọn àìní tẹ̀mí àwọn ìjọ wọnnì lé àwọn Kristian alábòójútó lọ́wọ́. Àwọn alàgbà wọ̀nyí kò parapọ̀ di ẹgbẹ́ àlùfáà. Ìránṣẹ́ àti ẹrú Ọlọrun ni wọ́n jẹ́, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti bójútó àìní àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá wa, Jesu Kristi, ti ṣe. (Johannu 10:​14, 15) Mímọ̀ pé àwọn ọkùnrin tí ó tóótun ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ń fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ìtẹ̀síwájú wa àti ìdàgbàsókè wa nípa tẹ̀mí ń fún wa ní ìṣírí láti fọwọ́sowọ́pọ̀ kí a si juwọ́sílẹ̀ ní ìtẹríba.​—⁠1 Korinti 16:16.

21. Báwo ni àwọn alàgbà tí a yànsípò ṣe ń wá ọ̀nà láti ran àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí?

21 Ní àwọn ìgbà mìíràn, àgùtàn lè ṣako lọ tàbí kí àwọn nǹkan ayé tí ń panilára wu ú lewu. Lábẹ́ ipò aṣáájú Olórí Olùṣọ́ Àgùtàn, àwọn alàgbà bí àwọn olùṣọ́ àgùtàn ọmọ abẹ́ wà lójúfò sí àìní àwọn wọnnì tí a fi sí abẹ́ àbójútó wọn, wọ́n sì ń fi taápọn taápọn fún wọn ní àfiyèsí ara-ẹni. (1 Peteru 5:4) Wọ́n ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìjọ wọ́n sì ń fún wọn ní ọ̀rọ̀ ìṣírí. Ní mímọ̀ pé Èṣù ń wá ọ̀nà láti dí àlàáfíà àwọn ènìyàn Ọlọrun lọ́wọ́, àwọn alàgbà ń lo ọgbọ́n tí ó ti òkè wá láti bójútó àwọn ìṣòro èyíkéyìí. (Jakọbu 3:​17, 18) Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti pa ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ ìgbàgbọ́ mọ́, ohun kan tí Jesu fúnra rẹ̀ gbàdúrà fún.​—⁠Johannu 17:20-⁠22; 1 Korinti 1:10.

22. Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn alàgbà ń pèsè nínú àwọn ọ̀ràn ìwà àìtọ́?

22 Kí ni bí Kristian kan bá ń jìyà lọ́wọ́ ibi kan tàbí tí ó rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé ó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan? Ìmọ̀ràn Bibeli tí ń máratuni àti àdúrà àtọkànwá àwọn alàgbà nítorí rẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti mú un padà sí ìlera tẹ̀mí. (Jakọbu 5:​13-⁠15) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, tí ẹ̀mí mímọ́ yànsípò, tún ní ọlá-àṣẹ láti fún ẹnì kan tí ń lépa ipa-ọ̀nà ìwà àìtọ́ tàbí tí ń wu ìmọ́tónítóní tẹ̀mí àti ti ìwàrere ìjọ léwu ní ìbáwí kí wọ́n sì tọ́ ọ sọ́nà. (Ìṣe 20:28; Titu 1:⁠9; 2:15) Láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní, ó lè pọndandan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo síta. (Lefitiku 5:1) Bí Kristian kan tí ó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bá gba ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ tí ó sì fi ẹ̀rí ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn, a óò ràn án lọ́wọ́. Dájúdájú, ẹnì kan tí ó ń bá a lọ láti tẹ òfin Ọlọrun lójú tí kò sì ronúpìwàdà ni a óò yọlẹ́gbẹ́.​—⁠1 Korinti 5:​9-⁠13.

23. Kí ni àwọn Kristian alábòójútó ń pèsè fún ire ìjọ?

23 Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé lábẹ́ Jesu Kristi bí Ọba, àwọn ọkùnrin tí ó dàgbà nípa tẹ̀mí ni a óò yàn láti pèsè ìtùnú, ààbò, àti ìtura fún àwọn ènìyàn Ọlọrun. (Isaiah 32:​1, 2) Wọ́n yóò jẹ́ aṣáájú gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, olùṣọ́ àgùtàn, àti olùkọ́ni láti lè gbé ìdàgbàsókè tẹ̀mí ga. (Efesu 4:​11, 12, 16) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà mìíràn àwọn Kristian alábòójútó lè fìbáwí tọ́nisọ́nà, bániwí kíkankíkan, kí wọ́n sì gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn níyànjú, ìfisílò ẹ̀kọ́ tí ń fúnni ní ìlera ti àwọn alàgbà tí wọ́n gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí gbogbo ènìyàn wà lójú ọ̀nà sí ìyè.​—⁠Owe 3:11, 12; 6:23; Titu 2:1.

GBA OJÚ-ÌWÒYE JEHOFA NÍPA ỌLÁ-ÀṢẸ

24. Ọ̀ràn àríyànjiyàn wo ni a fi ń dán wa wò lójoojúmọ́?

24 A dán ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ wò lórí ọ̀ràn àríyànjiyàn ti ìtẹríba fún ọlá-àṣẹ. Kò yanilẹ́nu pé irú ìdánwò kan náà ń dojúkọ wá lójoojúmọ́. Satani Èṣù ti gbé ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ ga láàárín aráyé. (Efesu 2:2) Ipa-ọ̀nà òmìnira ni a mú kí ó fanimọ́ra lọ́nà tí ó ga ju ti ìtẹríba.

25. Kí ni àwọn àǹfààní ti kíkọ ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ ayé yìí kí a sì wà ní ìtẹríba fún ọlá-àṣẹ tí Ọlọrun ń lò tàbí tí ó fàyègbà?

25 Bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ kọ ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ inú ayé sílẹ̀. Ní ṣíṣe èyí, a óò ríi pé ìtẹríba oníwà-bí-Ọlọ́run ń mú èrè-ẹ̀san tí ó dọ́ṣọ̀ wá. Fún àpẹẹrẹ, a óò yẹra fún àwọn àníyàn àti ìjákulẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ń fa ìṣòro fún ara wọn lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ayé. A óò dín gbún-⁠úngbùn-⁠ùngbún tí ó gbalẹ̀ láàárín ìdílé kù. A óò sì gbádùn àwọn àǹfààní àjọṣepọ̀ ọlọ́yàyà, onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristian onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìtẹríba oníwà-bí-Ọlọ́run wa yóò yọrí sí ìbátan rere kan pẹ̀lú Jehofa, Aláṣẹ Onípò Àjùlọ.

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Báwo ni Jehofa ṣe ń lo ọlá-àṣẹ rẹ̀?

Àwọn wo ni “àwọn aláṣẹ onípò gíga,” báwo ni a sì ṣe ń bá a lọ láti wà lábẹ́ wọn?

Ẹrù-iṣẹ́ wo ni ìlànà ipò orí gbé ka mẹ́ḿbà ìdílé kọ̀ọ̀kan?

Báwo ni a ṣe lè fi ìtẹríba hàn nínú ìjọ Kristian?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 134]

OLÙTẸRÍBA, KÌ Í ṢE OLÙDOJÚ-NǸKAN-DÉ

Nípasẹ̀ ìgbòkègbodò ìwàásù wọn ní gbangba, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pe àfiyèsí sí Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìrètí aráyé kanṣoṣo fún àlàáfíà àti ààbò tòótọ́. Ṣùgbọ́n àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọrun onítara wọ̀nyí kì í ṣe adojú àkóso ibi tí wọ́n ń gbé dé. Ní òdìkejì, àwọn Ẹlẹ́rìí wà lára àwọn aráàlú tí wọ́n lọ́wọ̀ tí wọ́n sì ń pa òfin mọ́ jùlọ. Ìjòyè òṣìṣẹ́ kan ní orílẹ̀-èdè Africa kan sọ pé: “Bí gbogbo àwọn ẹ̀ka ìsìn bá dàbí ti àwọn ẹlẹ́rìí Jehofa, kì yóò sí ìṣìkàpànìyàn, ìdigunjalè, ìyapòkíì, àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti àwọn bọ́m̀bù átọ́míìkì. A kì yóò máa ti ara wa mọ́lé lójoojúmọ́.”

Ní mímọ èyí, àwọn onípò àṣẹ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ti yọ̀ǹda iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí láti máa bá a lọ láìní ìdílọ́wọ́. Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, àwọn ìfòfindè tàbí ìkálọ́wọ́kò ni a ti gbé kúrò nígbà tí àwọn aláṣẹ mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ipa fún rere. Bí aposteli Paulu ti kọ̀wé nípa ìgbọràn sí aláṣẹ onípò gíga gẹ́lẹ́ ni ó rí: “Máa ṣe rere, iwọ yoo sì gba ìyìn lati ọ̀dọ̀ rẹ̀.”​—⁠Romu 13:​1, 3.