Dènà Àwọn Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Burúkú
Orí 12
Dènà Àwọn Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Burúkú
1. Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà nígbà tí ó bá àwọn ẹ̀mí burúkú pàdé?
KÉTÉ lẹ́yìn batisí rẹ̀, Jesu Kristi lọ sí aginjù Judea láti gbàdúrà kí ó sì ṣàṣàrò. Níbẹ̀ Satani Èṣù gbìyànjú láti mú kí ó rú òfin Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu kọ ìdẹwò Èṣù kò sì kó sínú pàkúté rẹ̀. Jesu dojúkọ àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú mìíràn nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Síbẹ̀, léraléra, ó bá wọn wí lọ́nà mímúná ó sì dènà wọn.—Luku 4:1-13; 8:26-34; 9:37-43.
2. Àwọn ìbéèrè wo ni a óò gbéyẹ̀wò?
2 Àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli tí ó ṣàpèjúwe àwọn ìbápàdé wọnnì yẹ kí ó mú wa gbàgbọ́ dájú pé àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú wà. Wọ́n ń gbìyànjú láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè dènà àwọn ẹ̀mí búburú wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ibo ni àwọn ẹ̀mí burúkú ti wá? Èéṣe tí wọ́n fi ń gbìyànjú láti tan àwọn ẹ̀dá ènìyàn jẹ? Àwọn ọ̀nà wo sì ni wọ́n ń lò láti mú ète wọn ṣẹ? Mímọ àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè bí ìwọ̀nyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dènà àwọn agbo ẹ̀mí burúkú.
ÀWỌN Ẹ̀MÍ BURÚKÚ—ÌPILẸ̀ṢẸ̀ ÀTI ÈTE-ÌLÉPA WỌN
3. Báwo ni Satani Èṣù ṣe di ẹni tí ó wà?
3 Jehofa Ọlọrun dá ògìdìgbó àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ó tó dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn. (Jobu 38:4, 7) Bí a ti ṣàlàyé ní Orí 6, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí mú ìfẹ́ ọkàn láti jẹ́ kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn máa jọ́sìn òun kàkà kí wọ́n máa jọ́sìn Jehofa dàgbà. Ní lílépa ète yẹn, áńgẹ́lì burúkú yìí takò, ó sì fọ̀rọ̀ èké ba Ẹlẹ́dàá jẹ́, tí ó tilẹ̀ sọ fún obìnrin àkọ́kọ́ pé òpùrọ́ ni Ọlọrun. Lọ́nà tí ó bá a mu, nígbà náà, ẹ̀dá ẹ̀mí ọlọ̀tẹ̀ yìí ni a wá mọ̀ sí Satani (alátakò) Èṣù (afọ̀rọ̀ èké banijẹ́).—Genesisi 3:1-5; Jobu 1:6.
4. Báwo ni àwọn áńgẹ́lì kan ṣe dẹ́ṣẹ̀ ní ìgbà ayé Noa?
4 Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì mìíràn gbè sẹ́yìn Satani Èṣù. Ní ìgbà ayé ọkùnrin olódodo náà Noa, díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí kọ iṣẹ́-ìsìn wọn ní ọ̀rún sílẹ̀ wọ́n sì gbé ẹran-ara ènìyàn wọ̀ láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fún ìbálòpọ̀ takọtabo lọ́rùn pẹ̀lú àwọn obìnrin orí ilẹ̀-ayé. Láìsí àníàní Satani ni ó nípa lórí àwọn áńgẹ́lì wọnnì láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà àìṣègbọràn yẹn. Ó ṣamọ̀nà sí bíbí àwọn àdàmọ̀di ọmọ-inú tí a pè ní Nefilimu, tí wọ́n di òṣìkà abúmọ́ni oníwà-ipá. Nígbà tí Jehofa mú kí Àkúnya ńlá ṣẹlẹ̀, ó pa aráyé oníwà-ìbàjẹ́ run àti àwọn àtọmọdọ́mọ aláìbá ìwà ẹ̀dá mu ti àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn wọ̀nyẹn. Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà yèbọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun nípa bíbọ́ ẹran-ara ènìyàn sílẹ̀ tí wọ́n sì padà sí ilẹ̀-ọba ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n Ọlọrun ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹ̀mí-èṣù wọ̀nyí nípa bíbá wọn lò bí àwọn ẹni tí a lé síta nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí. (Genesisi 6:1-7, 17; Juda 6) Bí ó ti wù kí ó rí, Satani, “olùṣàkóso awọn ẹ̀mí-èṣù,” àti àwọn áńgẹ́lì burúkú rẹ̀ ti ń bá a lọ pẹ̀lú ìṣọ̀tẹ̀ wọn. (Luku 11:15) Kí ni ète-ìlépa wọn?
5. Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ní ète ìlépa wo, kí ni wọ́n sì ń lò láti dẹkùn mú àwọn ènìyàn?
5 Ète-ìlépa ibi ti Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni láti yí àwọn ènìyàn padà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa Ọlọrun. Nítorí ìdí èyí, jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn àwọn ẹni burúkú wọ̀nyí ti ń ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà, wọ́n ń dẹ́rùbà wọ́n, wọ́n sì ń kọlù wọ́n. (Ìṣípayá 12:9) Àwọn àpẹẹrẹ òde-òní jẹ́rìí síi pé ìfinràn àwọn ẹ̀mí-èṣù ti túbọ̀ rorò síi nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Láti dẹkùn mú àwọn ènìyàn, àwọn ẹ̀mí-èṣù sábà máa ń lo ìbẹ́mìílò ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí ó pín sí. Báwo ni àwọn ẹ̀mí-èṣù ṣe ń lo ìdẹ yìí, báwo ni o sì ṣe lè gbèjà ara rẹ?
BÍ ÀWỌN Ẹ̀MÍ BURÚKÚ ṢE Ń GBÌYÀNJÚ LÁTI ṢÌ Ọ́ LỌ́NÀ
6. Kí ni ìbẹ́mìílò, kí sì ni àwọn irú oríṣi ìbẹ́mìílò tí ó wà?
6 Kí ni ìbẹ́mìílò? Níní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí-èṣù, tàbí ẹ̀mí burúkú, yálà ní tààràtà tàbí nípasẹ̀ abẹ́mìílò ni. Ìbẹ́mìílò wúlò fún àwọn ẹ̀mí-èṣù bí ìdẹ ti wúlò fún ọdẹ: Láti fa ohun ọdẹ mọ́ra. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọdẹ kan sì ti ń lo oríṣiríṣi ìdẹ láti fa àwọn ẹranko sínú pàkúté rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀mí burúkú ń ṣètìlẹyìn fún onírúurú irú-oríṣi ọ̀nà ìbẹ́mìílò láti mú àwọn ẹ̀dá ènìyàn wá sábẹ́ àkóso wọn. (Fiwé Orin Dafidi 119:110.) Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ni iṣẹ́ wíwò, idán pípa, wíwá àmì àpẹẹrẹ, iṣẹ́ oṣó tàbí àjẹ́, àsàsí, lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́mìílò, àti bíbá òku sọ̀rọ̀.
7. Báwo ni ìbẹ́mìílò ti gbòòrò tó, èésìtiṣe tí ó fi ń gbalẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí a pè ní ti Kristian?
7 Ìdẹ náà ń ṣiṣẹ́, nítorí pé ìbẹ́mìílò ń fa àwọn ènìyàn púpọ̀ mọ́ra káàkiri ayé. Àwọn tí wọ́n ń gbé nínú àwọn abúléko ń lọ sọ́dọ̀ àwọn adáhunṣe, àwọn òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì ní ìlú-ńlá sì ń tọ àwọn awòràwọ̀ lọ. Ìbẹ́mìílò gbalẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ ti a fẹnu lásán pè ní ti àwọn Kristian pàápàá. Ìwádìí fi hàn pé ní United States nìkan, nǹkan bíi 30 ìwé ìròyìn tí ó ní àpapọ̀ ìpínkiri tí ó ju 10,000,000 ni a yà sọ́tọ̀ fún onírúurú àṣà ìbẹ́mìílò. Àwọn ara Brazil ń ná iye tí ó ju 500 million owó dollar lórí àwọn ohun-èlò ìbẹ́mìílò lọ́dọọdún. Síbẹ̀, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń lọ sí ibùdó àwọn abẹ́mìílò déédéé ní orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́ àwọn Katoliki tí ó ti ṣe batisí tí wọ́n sì tún ń lọ síbi ìsìn Máàsì. Níwọ̀n bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ti ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò, ọ̀pọ̀ àwọn onísìn rò pé lílọ́wọ́ nínú rẹ̀ ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ ni ó ha rí bí?
ÌDÍ TÍ BIBELI FI DÁ ÌBẸ́MÌÍLÒ LẸ́BI
8. Kí ni ojú-ìwòye tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu nípa ìbẹ́mìílò?
8 Bí ẹnì kan bá ti kọ́ ọ pé irú oríṣi ìbẹ́mìílò kan jẹ́ ọ̀nà láti kàn sí àwọn ẹ̀mí dídára, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti kọ́ ohun tí Bibeli sọ nípa ìbẹ́mìílò. A kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn Jehofa pé: ‘Máṣe yípadà tọ àwọn tí ó ní ìmọ̀ àfọ̀ṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe wá àjẹ́ kiri, láti fi wọ́n ba ara yín jẹ́.’ (Lefitiku 19:31; 20:6, 27) Ìwé Ìṣípayá nínú Bibeli fún wa ní ìkìlọ̀ pé “awọn wọnnì tí ń bá ẹ̀mí lò” yóò rí òpin wọn nínú “adágún tí ń fi iná ati imí-ọjọ́ jó. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì [àìnípẹ̀kun].” (Ìṣípayá 21:8; 22:15) Gbogbo irú oríṣi ìbẹ́mìílò ni Jehofa Ọlọrun kò tẹ́wọ́gbà. (Deuteronomi 18:10-12) Èéṣe tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀?
9. Èéṣe tí a fi lè parí èrò sí pé àwọn ìhìn-iṣẹ́ òde-òní láti ayé ẹ̀mí kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Jehofa?
9 Jehofa rán àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí dídára, tàbí áńgẹ́lì òdodo, láti bá àwọn ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ṣáájú kí a tó parí kíkọ Bibeli. Láti ìgbà tí a ti parí rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti pèsè ìtọ́sọ́nà tí a nílò láti sin Jehofa lọ́nà tí ó tẹ́wọ́gbà. (2 Timoteu 3:16, 17; Heberu 1:1, 2) Kò pẹ́ Ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún àwọn abẹ́mìílò ní ìhìn-iṣẹ́. Gbogbo irú àwọn ìhìn-iṣẹ́ òde-òní bẹ́ẹ̀ láti ayé ẹ̀mí wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí burúkú. Lílọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò lè sinni lọ sí ìfòòró láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí-èṣù tàbí kí àwọn ẹ̀mí burúkú tilẹ̀ gbénidè pàápàá. Nítorí náà, Ọlọrun fi tìfẹ́tìfẹ́ kìlọ̀ fún wa láti máṣe lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìbẹ́mìílò èyíkéyìí. (Deuteronomi 18:14; Galatia 5:19-21) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí a bá ń bá a nìṣó láti lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò lẹ́yìn tí a ti mọ ojú-ìwòye Jehofa nípa rẹ̀, àwa yóò máa ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹ̀mí burúkú ọlọ̀tẹ̀ náà a óò sì di ọ̀tá Ọlọrun.—1 Samueli 15:23; 1 Kronika 10:13, 14; Orin Dafidi 5:4.
10. Kí ni iṣẹ́ wíwò, èésìtiṣe tí ó fi yẹ kí a yẹra fún un?
10 Irú-oríṣi ìbẹ́mìílò tí ó wọ́pọ̀ ni iṣẹ́ wíwò—gbígbìyànjú láti mọ ohun tí ó wà ní ọjọ́-iwájú tàbí èyí tí a kò mọ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí. Àwọn kan lára irú-oríṣi iṣẹ́ wíwò ni ìwòràwọ̀-sọtẹ́lẹ̀, wíwo jígí láti sọ tẹ́lẹ̀, títúmọ̀ àwọn àlá, wíwo ìlà ọwọ́ sọtẹ́lẹ̀, àti ìríran sọtẹ́lẹ̀ tí a ń fi káàdì ṣe. Ọ̀pọ̀ ka iṣẹ́ wíwò sí fàájì tí kò lè panilára, ṣùgbọ́n Bibeli fi hàn pé àwọn aríran-sọtẹ́lẹ̀ àti àwọn ẹ̀mí burúkú ń ṣiṣẹ́ papọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Ìṣe 16:16-19 mẹ́nukan “ẹ̀mí-èṣù ìwoṣẹ́” tí ó mú kí ọmọdébìnrin kan máa fi “ìsọtẹ́lẹ̀” ṣiṣẹ́ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, ó pàdánù agbára ìṣe rẹ̀ láti sọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la nígba tí a lé ẹ̀mí-èṣù náà jáde. Ó ṣe kedere nígbà náà pé, iṣẹ́ wíwò jẹ́ ìdẹ kan tí àwọn ẹ̀mí-èṣù ń lò láti ré àwọn ènìyàn sínú pàkúté wọn.
11. Báwo ni àwọn ìgbìdánwò láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú ṣe lè dẹkùn múni?
11 Bí o bá ń ṣọ̀fọ̀ ikú mẹ́ḿbà ìdílé olùfẹ́ ọ̀wọ́n kan tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan, ìdẹ mìíràn lè fi ìrọ̀rùn fà ọ́ lọ. Abẹ́mìílò kan lè fún ọ ní àkànṣe ìsọfúnni kan tàbí kí ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn kan tí ó dàbí ti ẹni tí ó ti kú náà. Ṣọ́ra! Ìgbìdánwò láti bá àwọn tí ó ti kú sọ̀rọ̀ ń sinni lọ sínú pàkúté. Èéṣe? Nítorí àwọn òkú kò lè sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí o rántí pé, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ ní kedere pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ó “padà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.” Àwọn òkú “kò mọ ohun kan” rárá. (Orin Dafidi 146:4; Oniwasu 9:5, 10) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, níti gidi àwọn ẹ̀mí-èṣù ni a ti mọ̀ tí wọ́n ń ṣàfarawé ohùn olóògbé náà tí wọ́n sì ń fún abẹ́mìílò ní ìsọfúnni nípa ẹni náà tí ó ti kú. (1 Samueli 28:3-19) Nítorí náà “abókùúlò” kan ni àwọn ẹ̀mí burúkú ti dẹ pàkúté mú tí ó sì ń gbégbèésẹ̀ ní ìlòdì sí ohun tí ìfẹ́-inú Jehofa Ọlọrun jẹ́.—Deuteronomi 18:11, 12; Isaiah 8:19.
LÁTI ÌFÀMỌ́RA SÍ ÌGBÉJÀKÒ
12, 13. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé àwọn ẹ̀mí-èṣù ń bá a lọ nínú ìgbìdánwò wọn láti dẹ àwọn ènìyàn wò kí wọ́n sì fòòró wọn?
12 Nígbà tí o bá mú ara rẹ bá ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mu nípa ìbẹ́mìílò, ìwọ yóò kọ ìdẹ àwọn ẹ̀mí-èṣù sílẹ̀. (Fiwé Orin Dafidi 141:9, 10; Romu 12:9.) Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn ẹ̀mí burúkú yóò dáwọ́ ìgbìyànjú láti mú ọ nígbèkùn dúró bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Lẹ́yìn dídẹ Jesu wò nígbà mẹ́ta, Satani “fàsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Luku 4:13) Lọ́nà kan náà, kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn ẹ̀mí-èṣù olóríkunkun ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún ń gbéjàkò wọ́n pẹ̀lú.
13 Rántí ìgbéyẹ̀wò wa ìṣáájú nípa ìgbéjàkò Satani lórí ìránṣẹ́ Ọlọrun náà Jobu. Èṣù ṣokùnfà ìpàdánù ẹran ọ̀sìn rẹ̀ àti ikú ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Satani tilẹ̀ pa àwọn ọmọ Jobu. Lẹ́yìn náà, ó kọlu Jobu fúnra rẹ̀ pẹ̀lú òkùnrùn aronilára. Ṣùgbọ́n Jobu pa ìwàtítọ́ rẹ̀ sí Ọlọrun mọ́ a sì bùkún fún un lọ́pọ̀lọpọ̀. (Jobu 1:7-19; 2:7, 8; 42:12) Láti ìgbà náà, àwọn ẹ̀mí-èṣù ti mú kí àwọn ènìyàn kan yadi tàbí fọ́jú tí wọ́n sì ti ń bá a lọ láti máa yọ̀ ṣìnkìn nígbà tí ènìyàn bá ń jìyà. (Matteu 9:32, 33; 12:22; Marku 5:2-5) Lónìí, ìròyìn fi hàn pé àwọn ẹ̀mí-èṣù ń fi ìbálòpọ̀ fòòró àwọn kan tí wọ́n sì ń ya àwọn mìíràn ní wèrè. Síbẹ̀ wọn ń sún àwọn mìíràn sí ìpànìyàn àti ìpara-ẹni, èyí tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun. (Deuteronomi 5:17; 1 Johannu 3:15) Bí ó ti wù kí ó rí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn tí àwọn ẹ̀mí búburú wọ̀nyí ti dẹkùn mú nígbà kan ti já ara wọn gbà lómìnira. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe fún wọn? Wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ nípa gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ ṣíṣekókó kan.
BÍ A ṢE LÈ DÈNÀ ÀWỌN Ẹ̀MÍ BURÚKÚ
14. Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ àwọn Kristian ará Efesu ní ọ̀rúndún kìn-ínní, báwo ni o ṣe lè dènà àwọn ẹ̀mí burúkú?
14 Kí ni ọ̀nà kan tí o lè gbà dènà àwọn ẹ̀mí burúkú kí o sì dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ kúrò lọ́wọ́ ìdẹkùn wọn? Àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ínní ní Efesu tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò ṣáájú kí wọ́n tó di onígbàgbọ́ gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ṣe ṣàkó. A kà pé “ọ̀pọ̀ lára awọn wọnnì tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ṣe kó awọn ìwé wọn papọ̀ wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.” (Ìṣe 19:19) Àní bí ìwọ kò bá tíì lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò, kó ohunkóhun tí ó ní ìlò ìbẹ́mìílò nínú tàbí tí ó níí ṣe pẹ̀lú rẹ̀ dànù. Èyí kan àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, fídíò, ìwé àlẹ̀mógiri, ohùn orin tí a gbà sílẹ̀, àti ohunkóhun tí a ń lò fún ète ìbẹ́mìílò. Ó tún kan àwọn ère, ìgbàdí àti àwọn ohun mìíràn tí a ń wọ̀ fún ààbò, àti àwọn ẹ̀bùn tí àwọn tí ń bẹ́mìílò bá fúnni. (Deuteronomi 7:25, 26; 1 Korinti 10:21) Láti ṣàkàwé: Ẹ̀mí-èṣù ti ń fòòró tọkọtaya kan tí ń gbé ní Thailand fún ìgbà pípẹ́. Lẹ́yìn náà wọ́n kò àwọn ohun tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò dànù. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Wọ́n ní ìtura lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ẹ̀mí-èṣù wọ́n sì tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí níti gidi lẹ́yìn náà.
15. Ní dídènà àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú, kí ni ìgbésẹ̀ mìíràn tí ó pọndandan?
15 Láti dènà àwọn ẹ̀mí burúkú, ìgbésẹ̀ mìíràn tí ó pọndandan ni fífi ìmọ̀ràn aposteli Paulu sílò láti gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí tí Ọlọrun fifúnni wọ̀. (Efesu 6:11-17) Àwọn Kristian níláti fokun fún ìgbèjà wọn lòdìsí àwọn ẹ̀mí burúkú. Kí ni ohun tí ìgbésẹ̀ yìí ní nínú? Paulu wí pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ óò lè fi paná gbogbo awọn ohun-ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú naa.” Nítòótọ́, bí ìgbàgbọ́ rẹ bá ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ láti dènà agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú yóò ṣe pọ̀ tó.—Matteu 17:14-20.
16. Báwo ni o ṣe lè fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun?
16 Báwo ni o ṣe lè fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun? Nípa bíbá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kí o sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ. Bí ìgbàgbọ́ ẹnì kan ṣe lókun tó sinmi púpọ̀púpọ̀ lórí bí ìpìlẹ̀ rẹ̀—ìmọ̀ Ọlọrun—ṣe fi ìdí múlẹ̀ gbọnyin tó. Ìwọ kò ha gbà pé ìmọ̀ pípéye tí o ti jèrè tí o sì ti fi sọ́kàn bí o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti gbé ìgbàgbọ́ rẹ ró bí? (Romu 10:10, 17) Láìṣiyèméjì, nígbà náà, bí o ti ń bá a lọ pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí tí o sì sọ ọ́ di àṣà rẹ láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni a óò túbọ̀ fún lókun sí i. (Romu 1: 11, 12; Kolosse 2:6, 7) Yóò jẹ́ ìdáàbòbò lòdì sí ìkọlù àwọn ẹ̀mí-èṣù.—1 Johannu 5:5.
17. Ìgbésẹ̀ síwájú sí i wo ni ó lè pọndandan ní dídènà agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú?
17 Ìgbésẹ̀ síwájú síi wo ni ẹnì kan tí ó ti pinnu láti dènà agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú lè gbé? Àwọn Kristian ní Efesu nílò ààbò nítorí pé wọ́n ń gbé nínú ìlú kan tí ẹ̀mí-èṣù kún fọ́fọ́. Nítorí èyí, Paulu sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà ninu ẹ̀mí.” (Efesu 6:18) Níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú ayé kan tí ẹ̀mí-èṣù kún fọ́fọ́, gbígbàdúrà lọ́nà gbígbóná janjan fún ààbò Ọlọrun ṣekókó ní dídènà àwọn ẹ̀mí burúkú. (Matteu 6:13) Ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí àti àdúrà àwọn alàgbà tí a yànsípò nínú ìjọ Kristian ń ṣèrànlọ́wọ́ níhà yìí.—Jakọbu 5:13-15.
TẸRA MỌ́ ÌJÀ RẸ LÒDÌ SÍ ÀWỌN Ẹ̀MÍ BURÚKÚ
18, 19. Kí ni ẹnì kan lè ṣe bí àwọn ẹ̀mí-èṣù bá tún dà á láàmú?
18 Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ ṣíṣekókó wọ̀nyí pàápàá, àwọn kan ni àwọn ẹ̀mí búburú ti dà láàmú. Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan ní Côte d’Ivoire kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì pa gbogbo àwọn ìgbàdí rẹ̀ run. Lẹ́yìn náà, ó tẹ̀síwájú gidigidi, ó ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ sí Jehofa, ó sì ṣe batisí. Ṣùgbọ́n ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn batisí rẹ̀, àwọn ẹ̀mí-èṣù bẹ̀rẹ̀ síí yọ ọ́ lẹ́nu lẹ́ẹ̀kan síi, àwọn ohùn sì sọ fún un pé kí ó pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí tì. Bí èyí bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, yóò ha túmọ̀ sí pé o ti pàdánù ààbò Jehofa bí? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀.
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin pípé náà Jesu Kristi ní ààbò àtọ̀runwá, ó gbọ́ ohùn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú náà Satani Èṣù. Jesu fi ohun tí ó yẹ láti ṣe nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ hàn. Ó sọ fún Èṣù pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Satani!” (Matteu 4:3-10) Lọ́nà kan náà, o gbọ́dọ̀ kọ̀ láti fetísílẹ̀ sí àwọn ohùn láti ayé ẹ̀mí. Dènà àwọn ẹ̀mí burúkú nípa kíképe Jehofa fún ìrànlọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ni, gbàdúrà sókè ní lílo orúkọ Ọlọrun. Owe 18:10 sọ pé: “Orúkọ [Jehofa, NW], ilé-ìṣọ́ agbára ni: Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì là.” Ọkùnrin Kristian náà ní Côte d’Ivoire ṣe èyí, àwọn ẹ̀mí burúkú kò sì fòòró rẹ̀ mọ́.—Orin Dafidi 124:8; 145:18.
20. Ní àkópọ̀, kí ni o lè ṣe láti dènà àwọn ẹ̀mí burúkú?
20 Jehofa ti fàyègba àwọn ẹ̀mí burúkú láti máa wà nìṣó, ṣùgbọ́n ó ń fi agbára rẹ̀ hàn, ní pàtàkì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni a sì ń polongo ní gbogbo ilẹ̀-ayé. (Eksodu 9:16) Bí o bá súnmọ́ Ọlọrun pẹ́kípẹ́kí, kò sí ìdí fún ọ láti bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí burúkú. (Numeri 23:21, 23; Jakọbu 4:7, 8; 2 Peteru 2:9) Agbára wọn láàlà. A jẹ wọ́n níyà ní ìgbà ayé Noa, a lé wọn kúrò ní ọ̀run lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nísinsìnyí wọ́n ń dúró de ìdájọ́ tí ó kẹ́yìn. (Juda 6; Ìṣípayá 12:9; 20:1-3, 7-10, 14) Níti tòótọ́, wọ́n fòyà ìparun wọn tí ń bọ̀. (Jakọbu 2:19) Nítorí náà bóyá àwọn ẹ̀mí burúkú gbìyànjú láti fa ọ́ mọ́ra pẹ̀lú irú ìdẹ kan tàbí gbéjàkò ọ́ lọ́nàkọnà, o lè dènà wọn. (2 Korinti 2:11) Yẹ gbogbo irú oríṣi ọ̀nà ìbẹ́mìílò sílẹ̀, fi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò, kí o sì wá ìtẹ́wọ́gbà Jehofa. Ṣe èyí láìjáfara, nítorí ìwàláàyè rẹ sinmi lórí dídènà tí o bá dènà àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú!
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Báwo ni àwọn ẹ̀mí búburú ṣe ń gbìyànjú láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà?
Èéṣe tí Bibeli fi dá ìbẹ́mìílò lẹ́bi?
Báwo ni ẹnì kan ṣe lè já ara rẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú?
Èéṣe tí o fi níláti máa báa nìṣó láti dènà àwọn ẹ̀mí burúkú?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 110]
Ojú wo ni o fi ń wo ìbẹ́mìílò ní gbogbo irú oríṣi rẹ̀?