Fi Ṣe Góńgó-Ìlépa Rẹ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun Títí Láé
Orí 18
Fi Ṣe Góńgó-Ìlépa Rẹ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun Títí Láé
1, 2. Kí ni ohun tí a béèrè fún yàtọ̀ sí níní ìmọ̀ Ọlọrun?
RONÚWÒYE pé o dúró lẹ́nu ilẹ̀kùn kan tí a tìpa tí ó wọnú yàrá kan tí ó ní àwọn ìṣúra púpọ̀ nínú. Jẹ́ kí á sọ pé ẹni tí ó ní ọlá-àṣẹ ti fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ó sì ti sọ fún ọ láti gbádùn ara rẹ. Kọ́kọ́rọ́ náà kì yóò ṣe ọ́ ní àǹfààní kankan àyàfi bí o bá lò ó. Lọ́nà kan náà, o gbọ́dọ̀ lo ìmọ̀ bí o bá fẹ́ kí ó ṣe ọ́ láǹfààní.
2 Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nípa ìmọ̀ Ọlọrun. Nítòótọ́, ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 17:3) Síbẹ̀, ọwọ́ wa kò lè tẹ ìfojúsọ́nà yẹn nípa wíwulẹ̀ ní ìmọ̀ nìkan. Bí ìwọ yóò ti lo kọ́kọ́rọ́ kan tí ó ṣeyebíye, o níláti lo ìmọ̀ Ọlọrun nínú ìgbésí-ayé rẹ. Jesu sọ pé àwọn wọnnì tí ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ni yóò ‘wọ inú ìjọba náà.’ Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun títí láé!—Matteu 7:21; 1 Johannu 2:17.
3. Kí ni ìfẹ́-inú Ọlọrun fún wa?
3 Lẹ́yìn tí o ti mọ ohun tí ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́, ó ṣekókó láti ṣe é. Kí ni o rò pé ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́ fún ọ? A lè ṣàkópọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Ṣàfarawé Jesu. Peteru Kìn-ínní 2:21 sọ fún wa pé: “Ìlà ipa-ọ̀nà yii ni a pè yín sí, nitori Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀lé awọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” Láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, nígbà náà, o níláti tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu pẹ́kípẹ́kí bí o bá ti lè ṣe é tó. Bí o ṣe lè fi ìmọ̀ Ọlọrun sílò nìyẹn.
BÍ JESU ṢE LO ÌMỌ̀ ỌLỌRUN
4. Èéṣe tí Jesu fi mọ púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ nípa Jehofa, báwo ni ó sì ti ṣe lo ìmọ̀ yìí?
4 Jesu Kristi ní ìmọ̀ nípa Ọlọrun ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Ó gbé pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun ní ọ̀run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí ó tó wá sí orí ilẹ̀-ayé ó sì ti bá a ṣiṣẹ́. (Kolosse 1:15, 16) Kí ni Jesu sì ṣe pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ yẹn? Kò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú wíwulẹ̀ ní in. Jesu gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ onínúure, onísùúrù, àti onífẹ̀ẹ́ nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀. Jesu ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣàfarawé Bàbá rẹ̀ ọ̀run tí ó sì ń gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀ nípa àwọn ọ̀nà àti ànímọ́ Jehofa.—Johannu 8:23, 28, 29, 38; 1 Johannu 4:8.
5. Èéṣe tí Jesu fi ṣe batisí, báwo ni ó sì ti ṣe gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ batisí rẹ̀?
5 Ìmọ̀ tí Jesu ní tún sún un láti gbé ìgbésẹ̀ ṣíṣekókó kan. Ó wá sí Odò Jordani láti Galili, níbi tí Johannu ti batisí rẹ̀. (Matteu 3:13-15) Kí ni batisí Jesu dúró fún? Bíi Júù kan, a bí i sínú orílẹ̀-èdè kan tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọrun. Nípa báyìí, a ti ya Jesu sí mímọ́ láti ìgbà ìbí. (Eksodu 19:5, 6) Nípa jíjọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún batisí, ó ń fi ara rẹ̀ fún Jehofa láti ṣe ìfẹ́-inú àtọ̀runwá fún un ní àkókò yẹn. (Heberu 10:5, 7) Jesu sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ batisí rẹ̀. Ó lo ara rẹ̀ tokunra tokunra nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa, ní ṣíṣàjọpín ìmọ̀ Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní gbogbo àkókò àǹfààní. Jesu rí inúdídùn nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, ó tilẹ̀ sọ pé ó dàbí oúnjẹ fún òun.—Johannu 4:34.
6. Ní ọ̀nà wo ni Jesu gbà sẹ́ ara rẹ̀?
6 Jesu mọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé ṣíṣe ìfẹ́-inú Jehofa yóò ná òun ní ohun púpọ̀—pé yóò tilẹ̀ ná an ní ìwàláàyè rẹ̀. Bí ìyẹn tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jesu sẹ́ ara rẹ̀, ní fífi àwọn àìní ara rẹ̀ sí ipò kejì. Ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun gba ipò iwájú nígbà gbogbo. Ní ọ̀nà yìí, báwo ni a ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ pípé ti Jesu?
ÀWỌN ÌGBÉSẸ̀ TÍ Ń SINNI LỌ SÍ ÌYÈ TÍTÍ LÁÉ
7. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ gbé láti tóótun fún batisí?
7 Láìdàbí Jesu, aláìpé ni wá a sì lé dé orí kókó pàtàkì ti batisí kìkì lẹ́yìn tí a bá ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ ṣíṣe kókó mìíràn. Èyí bẹ̀rẹ̀ nípa gbígba ìmọ̀ pípéye ti Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi sínú ọkàn-àyà wa. Ṣíṣe èyí ń mú wa lo ìgbàgbọ́ kí a sì ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Ọlọrun. (Matteu 22:37-40; Romu 10:17; Heberu 11:6) Mímú ara ẹni bá àwọn òfin, ìlànà, àti àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun mu yẹ kí ó sún wa láti ronúpìwàdà, ní fífi ìkárísọ ti oníwà-bí-Ọlọ́run hàn lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àtijọ́. Èyí ń ṣamọ̀nà sí ìyílọ́kànpadà, ìyẹn ni, sí ìyípadà àti fífi ipa-ọ̀nà àìtọ́ tí a tọ̀ nígbà tí a kò ní ìmọ̀ Ọlọrun sílẹ̀. (Ìṣe 3:19) Lọ́nà ti ẹ̀dá, bí a bá ṣì ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan ní bòókẹ́lẹ́ kàkà kí a ṣe ohun tí ó tọ́, a kò tíì yípadà níti gidi, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò tan Ọlọrun. Jehofa ń ṣàwárí àgàbàgebè.—Luku 12:2, 3.
8. Ìgbésẹ̀ wo ni o níláti gbé bí o bá ní ìfẹ́ ọkàn láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba?
8 Nísinsìnyí tí o ti ń gba ìmọ̀ Ọlọrun sínú, kò ha bá a mu láti gbé àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí wò fúnra rẹ níti gidi bí? Bóyá o ń háragàgà láti sọ fún àwọn ìbátan rẹ, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn mìíràn nípa ohun tí o ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Níti tòótọ́, o ti lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí, àní bí Jesu ti ṣàjọpín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn mìíràn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. (Luku 10:38, 39; Johannu 4:6-15) Nísinsìnyí o lè fẹ́ láti ṣe púpọ̀ síi. Inú àwọn Kristian alàgbà yóò dùn láti bá ọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè pinnu bóyá o tóótun tí o sì lè nípìn-ín lọ́nà kan ṣáá nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba déédéé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí o bá tóótun, àwọn alàgbà yóò ṣètò fún ọ láti bá Ẹlẹ́rìí kan lọ sínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tẹ̀lé ìtọ́ni rẹ̀ kí wọ́n baà lè ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn létòletò. (Marku 6:7, 30; Luku 10:1) Ìwọ yóò jàǹfààní láti inú irú ìrànlọ́wọ́ kan náà bí o ti ń ṣàjọpín nínú títan ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀ láti ilé dé ilé àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn.—Ìṣe 20:20, 21.
9. Báwo ni ẹnì kan ṣe ń ṣe ìyàsímímọ́ fún Ọlọrun, báwo sì ni ìyàsímímọ́ ṣe ń nípa lórí ìgbésí-ayé ẹni náà?
9 Wíwàásù ìhìnrere náà fún onírúurú ènìyàn nínú agbègbè ìpínlẹ̀ ìjọ jẹ́ ọ̀nà kan láti rí àwọn wọnnì tí wọ́n nítẹ̀sí síhà òdodo ó sì wà lára àwọn iṣẹ́ àtàtà tí ó ń fi hàn pé o ní ìgbàgbọ́. (Ìṣe 10:34, 35; Jakọbu 2:17, 18, 26) Wíwá sí ìpàdé Kristian déédéé àti ṣíṣàjọpín lọ́nà tí ó nítumọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà tún jẹ́ àwọn ọ̀nà mìíràn láti fi hàn pé o ti ronúpìwàdà o sì ti yípadà o sì ti pinnu nísinsìnyí láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọrun. Kí ni ìgbésẹ̀ bíbọ́gbọ́nmu tí ó tẹ̀lé e? Ó jẹ́ láti ṣe ìyàsímímọ́ sí Jehofa Ọlọrun. Ìyẹn túmọ̀ sí pé nínú àdúrà àtọkànwá, o sọ fún Ọlọrun pé o ń fi ìgbésí-ayé rẹ fún un tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú àti tọkàntọkàn láti ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Ọ̀nà náà nìyí láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jehofa kí o tẹ́wọ́gba àjàgà onínúure ti Jesu Kristi.—Matteu 11:29, 30.
BATISÍ —OHUN TÍ Ó TÚMỌ̀ SÍ FÚN Ọ
10. Èéṣe tí o fi níláti ṣe batisí lẹ́yìn tí o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jehofa?
10 Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí, gbogbo àwọn wọnnì tí wọn di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe batisí. (Matteu 28:19, 20) Èéṣe tí èyí fi pọndandan lẹ́yìn tí o ti ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun? Níwọ̀n bí o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jehofa, ó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun. Ṣùgbọ́n láìsí iyèméjì ìwọ yóò fẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀ síwájú síi láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ̀ nípa ìfẹ́ rẹ fún Ọlọrun. Ó dára, batisí fún ọ ní àǹfààní kan láti jẹ́ kí ìyàsímímọ́ rẹ sí Jehofa Ọlọrun di mímọ̀ ní gbangba.—Romu 10:9, 10.
11. Kí ni ìtumọ̀ batisí?
11 Batisí kún fún ìtumọ̀ alápẹẹrẹ. Bí omi ti bò ọ́ mọ́lẹ̀, tàbí “sin ọ́,” sí ìsàlẹ̀ omi, ṣe ni ó dàbí ẹni pé o ti kú sí ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ tẹ́lẹ̀rí. Nígbà tí o jáde láti inú omi, ṣe ni ó dàbí ẹni pé o jáde sínú ìgbésí-ayé titun kan, ọ̀kan tí ìfẹ́-inú Ọlọrun ń ṣàkóso kì í sì í ṣe tirẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé o kò ní ṣe àṣìṣe mọ́ rárá, nítorí gbogbo wa jẹ́ aláìpé tí a sì tipa báyìí ń ṣẹ̀ lójoojúmọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ìránṣẹ́ Jehofa tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ àti batisí, ìwọ yóò ti wọnú àkànṣe ipò-ìbátan pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí ìrònúpìwàdà rẹ àti ìjuwọ́sílẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ fún batisí, Jehofa múra tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jesu. Batisí tipa báyìí ṣamọ̀nà sí ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ tónítóní níwájú Ọlọrun.—1 Peteru 3:21.
12. Kí ni o túmọ̀ sí láti ṣe batisí (a) “ní orúkọ Baba”? (b) ‘ní orúkọ Ọmọkùnrin’? (d) ‘ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́’?
12 Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti batisí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn titun “ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́.” (Matteu 28:19) Kí ni ohun tí Jesu ní lọ́kàn? Batisí “ní orúkọ Baba” fi hàn pé ẹni tí ń ṣe batisí náà fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́gba Jehofa Ọlọrun bí Ẹlẹ́dàá àti ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba-Aláṣẹ àgbáyé. (Orin Dafidi 36:9; 83:18; Oniwasu 12:1) Láti ṣe batisí ‘ní orúkọ Ọmọkùnrin’ túmọ̀ sí pé ẹni náà jẹ́wọ́ Jesu Kristi—àti ní pàtàkì ẹbọ ìràpadà Rẹ̀—bí ọ̀nà kanṣoṣo tí Ọlọrun pèsè fún ìgbàlà. (Ìṣe 4:12) Batisí ‘ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́’ fi hàn pé olùnàgà fún àǹfààní batisí náà mọ ẹ̀mí mímọ́ Jehofa, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́, bí ohun-èlò Ọlọrun láti mú ète Rẹ̀ ṣẹ àti láti fún àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní agbára láti ṣe ìfẹ́-inú òdodo Rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò-àjọ Rẹ̀ tí ẹ̀mí ń darí.—Genesisi 1:2; Orin Dafidi 104:30; Johannu 14:26; 2 Peteru 1:21.
O HA TI ṢETÁN FÚN BATISÍ BÍ?
13, 14. Èéṣe tí a kò fi níláti bẹ̀rù láti yàn láti sin Jehofa Ọlọrun?
13 Níwọ̀n bí batisí ti ní púpọ̀ ṣe tí ó sì jẹ́ kókó tí ó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí-ayé ẹnì kan, ó ha jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tí o níláti bẹ̀rù bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí o fojú kéré ìpinnu náà láti ṣe batisí, láìṣiyèméjì ó jẹ́ ìpinnu tí ó lọ́gbọ́n nínú jùlọ tí o lè ṣe.
14 Batisí jẹ́ ẹ̀rí pé o yàn láti ṣiṣẹ́sin Jehofa Ọlọrun. Ronú nípa àwọn ènìyàn tí o ti bá pàdé. Ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò ha ń ṣiṣẹ́sin ọ̀gá kan bí? Àwọn kan ń ṣe ẹrú fún ọrọ̀. (Matteu 6:24) Àwọn mìíràn ń fi taápọn taápọn lépa iṣẹ́ ìgbésí-ayé tàbí sin ara wọ́n nípa jíjẹ́ kí ìmúṣẹ ìfẹ́ ọkàn tiwọn fúnra wọn lékè nínú ìgbésí-ayé. Síbẹ̀ àwọn mìíràn ń sin àwọn ọlọrun èké. Ṣùgbọ́n o ti yàn láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun òtítọ́ náà, Jehofa. Kò sí ẹlòmíràn tí ó fi inúrere, ìyọ́nú, àti ìfẹ́ tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ hàn. Ọlọrun fún ẹ̀dá ènìyàn ní iyì-ọlá pẹ̀lú iṣẹ́ tí ó ní ète nínú tí ó darí wọn sí ìgbàlà. Ó ń san ẹ̀san fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun. Dájúdájú, títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu àti fífi ìgbésí-ayé rẹ fún Jehofa kì í ṣe ipa-ọ̀nà tí ó yẹ kí o bẹ̀rù. Níti gidi, ó jẹ́ ọ̀kanṣoṣo tí ó wu Ọlọrun tí ó sì bọ́gbọ́nmu délẹ̀délẹ̀.—1 Ọba 18:21.
15. Kí ni àwọn ohun ìdínà díẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ sí batisí?
15 Síbẹ̀, batisí kì í ṣe ìgbésẹ̀ tí ó yẹ kí o gbé nítorí ìkìmọ́lẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀ràn ara-ẹni kan láàárín ìwọ àti Jehofa. (Galatia 6:4) Níwọ̀n bí o ti tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí, o ti lè ṣe kàyéfì pé: “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” (Ìṣe 8:35, 36) O lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Àtakò ìdílé ha ń fà mí sẹ́yìn bí? Mo ha ṣì ń lọ́wọ́ nínú àwọn ipò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tàbí dídá ẹ̀ṣẹ̀ bí? Ó ha lè jẹ́ pé mo ń bẹ̀rù pípàdánù ojúrere ní àwùjọ bí?’ Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn kókó láti gbéyẹ̀wò, ṣùgbọ́n yẹ̀ wọ́n wò tòótọ́ tòótọ́.
16. Báwo ni ìwọ yóò ṣe jàǹfààní láti inú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa?
16 Kì í ṣe fífi ojú tòótọ́ gidi wòye láti yẹ kìkì iye tí yóò ná ọ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa wò láìfún àwọn àǹfààní tí ìwọ yóò rígbà ní àfiyèsí. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn àtakò ìdílé yẹ̀wò. Jesu ṣèlérí pé kódà bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun bá pàdánù àwọn ìbátan nítorí pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, wọn yóò jèrè ìdílé tí ó tóbi sí i nípa tẹ̀mí. (Marku 10:29, 30) Àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni wọ̀nyí yóò fi ìfẹ́ni ará hàn sí ọ, wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti farada inúnibíni, wọ́n yóò sì ṣètìlẹyìn fún ọ lójú ọ̀nà sí ìyè. (1 Peteru 5:9) Àwọn alàgbà ìjọ ní pàtàkì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro kí o sì borí àwọn ìpènijà mìíràn pẹ̀lú àṣeyọrí. (Jakọbu 5:14-16) Níti pípàdánù ojúrere nínú ayé yìí, o tún lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Kí ni ó ṣeé ṣe kí n fiwé ìtẹ́wọ́gbà Ẹlẹ́dàá àgbáyé, ní mímú inú rẹ̀ dùn lórí ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé tí mo yàn?’—Owe 27:11.
GBÍGBÉ NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ÌYÀSÍMÍMỌ́ ÀTI BATISÍ RẸ
17. Èéṣe tí o fi níláti wo batisí bí ìbẹ̀rẹ̀ kàkà kí ó jẹ́ òpin kan?
17 Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé batisí kì í ṣe òpin ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí. Ó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn títí ọjọ́-ayé sí Ọlọrun bí òjíṣẹ́ tí a fi ọlá-àṣẹ yàn àti ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé batisí ṣe pàtàkì gidigidi, kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú fún ìgbàlà. Jesu kò sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe batisí ni a óò gbàlà.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbàlà.” (Matteu 24:13) Nítorí náà, ó ṣe kókó pé kí ìwọ wá Ìjọba Ọlọrun lákọ̀ọ́kọ́ nípa fífi í ṣe ìdàníyàn pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ.—Matteu 6:25-34.
18. Lẹ́yìn batisí, kí ni díẹ̀ lára àwọn góńgó láti lépa?
18 Láti lo ìfaradà nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ sí Jehofa, ìwọ yóò fẹ́ láti gbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀ fún ara rẹ. Góńgó yíyẹ kan ni láti fikún ìmọ̀ rẹ nípa Ọlọrun nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé. Ṣètò fún Bibeli kíkà lójoojúmọ́. (Orin Dafidi 1:1, 2) Pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristian déédéé, nítorí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ìwọ yóò rí níbẹ̀ yóò ṣèrànwọ́ láti fún ọ lókun nípa tẹ̀mí. Níhà ọ̀dọ̀ tìrẹ, èéṣe tí o kò fi ṣe góńgó rẹ láti sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ní àwọn ìpàdé ìjọ kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ yin Jehofa kí o sì wá láti gbé àwọn ẹlòmíràn ró? (Romu 1:11, 12) Góńgó mìíràn tún lè jẹ́ láti mú kí ìjójúlówó àdúrà rẹ sunwọ̀n síi.—Luku 11:2-4.
19. Àwọn ànímọ́ wo ni ẹ̀mí mímọ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi hàn?
19 Bí ìwọ yóò bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú batisí rẹ, o níláti fiyè gidigidi sí ohun tí o ń ṣe, ní jíjẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun mú irú àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìdùnnú-ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inúrere, ìwàrere, ìgbàgbọ́, ìwàtútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu jáde nínú rẹ. (Galatia 5:22, 23; 2 Peteru 3:11) Rántí, Jehofa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n gbàdúrà fún un tí wọ́n sì ṣègbọràn sí i bí ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. (Luku 11:13; Ìṣe 5:32) Nítorí náà gbàdúrà sí Ọlọrun fún ẹ̀mí rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti lè fi àwọn ànímọ́ tí ó wù ú hàn. Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ yóò túbọ̀ fara hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà rẹ bí o ti ń dáhùnpadà sí ìdarí ẹ̀mí Ọlọrun. Dájúdájú, gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ìjọ Kristian ń làkàkà láti mú “àkópọ̀-ìwà titun” dàgbà láti lè túbọ̀ dàbí Kristi. (Kolosse 3:9-14) Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ń dojúkọ ìpènijà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ṣíṣe èyí nítorí a wà ní ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí. Níwọ̀n bí o ti jẹ́ aláìpé, o níláti ṣiṣẹ́ kára láti ní ànímọ́ bíi ti Kristi. Ṣùgbọ́n máṣe sọ ìrètí nù ní ìhà yìí, nítorí ó ṣeé ṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun.
20. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìwọ lè gbà farawé Jesu nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà?
20 Ó níláti wà lára àwọn góńgó tẹ̀mí rẹ láti farawé àpẹẹrẹ onídùnnú-ayọ̀ ti Jesu pẹ́kípẹ́kí síi. (Heberu 12:1-3) O nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà. Bí o bá ní àǹfààní láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà, nígbà náà, máṣe jẹ́ kí ó di àṣetúnṣe lásán. Wá ọ̀nà láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọrun bí Jesu ti ṣe. Fi àwọn ìtọ́ni tí ìjọ ń pèsè láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sunwọ̀n síi bí olùkọ́ sílò. Sì jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé Jehofa lè fún ọ ní okun láti máa bá iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ nìṣó.—1 Korinti 9:19-23.
21. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jehofa ka àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti ṣe batisí tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ sí ìṣúra? (b) Kí ni ó fi hàn pé batisí ṣe pàtàkì fún líla ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọrun sórí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí já?
21 Ẹnì kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ tí ó sì ti ṣe batisí tí ó ń sakun láti tẹ̀le Jesu jẹ́ ẹni àkànṣe kan fún Ọlọrun. Jehofa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà gbogbo billion ẹ̀dá-ènìyàn ó sì mọ̀ bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti ṣọ̀wọ́n tó. Ó kà wọ́n sí ìṣúra, “àwọn ohun fífanilọ́kànmọ́ra.” (Haggai 2:7, NW) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fi hàn pé Ọlọrun wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bí àwọn tí a sàmì sí fún líla ìmúṣẹ ìdájọ́ rẹ̀ tí ń bọ̀ láìpẹ́ sórí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí já. (Esekieli 9:1-6; Malaki 3:16, 18) O ha “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” bí? (Ìṣe 13:48) Ìfẹ́ ọkàn onítara rẹ ha jẹ́ láti di ẹni tí a sàmì sí bí ẹni tí ń sin Ọlọrun? Ìyàsímímọ́ àti batisí jẹ́ apá kan àmì yẹn, wọ́n sì ṣe kókó fún lílàájá.
22. Ìfojúsọ́nà wo ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lè máa wọ̀nà fún?
22 Lẹ́yìn Àkúnya kárí-ayé náà, Noa àti ìdílé rẹ̀ jáde láti inú áàkì sí ilẹ̀-ayé kan tí a ti fọ̀ mọ́ tónítóní. Bákan náà lónìí, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ń fi ìmọ̀ Ọlọrun sílò nínú ìgbésí-ayé wọn tí wọ́n sì jèrè ìtẹ́wọ́gbà Jehofa ní ìfojúsọ́nà láti la òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí já kí wọ́n sì gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun wíwà títí lọ lórí ilẹ̀-ayé tí a ti fọ̀ mọ́ tónítóní. (Ìṣípayá 7:9, 14) Báwo ni ìgbésí-ayé yẹn yóò ti rí?
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Báwo ni Jehofa ṣe fẹ́ kí o lo ìmọ̀ tí o ní nípa rẹ̀?
Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ tí ń ṣamọ̀nà sí batisí?
Èéṣe tí batisí kì í fi í ṣe òpin ṣùgbọ́n ìbẹ̀rẹ̀ kan?
Báwo ni a ṣe lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ àti batisí wa?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 172]
O ha ti ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun nínú àdúrà bí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 174]
Kí ni ó dí ọ lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?