Gbígbé Ìdílé Kan Tí Ó Bọlá Fún Ọlọrun Ró
Orí 15
Gbígbé Ìdílé Kan Tí Ó Bọlá Fún Ọlọrun Ró
1-3. Èéṣe tí àwọn kan kò fi lè yanjú àwọn ìṣòro tí ó wọ́pọ̀ nínú ìgbéyàwó àti jíjẹ́ òbí, ṣùgbọ́n èéṣe tí Bibeli fi lè ṣèrànlọ́wọ́?
KÍ Á sọ pé o wéwèé láti kọ ilé ara rẹ. O ra ilẹ̀. Pẹ̀lú ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà, o rí ilé rẹ titun pẹ̀lú ojú inú rẹ. Bí o kò bá ní irin-iṣẹ́ àti òye iṣẹ́ ìkọ́lé ń kọ́? Wo bí ìyẹn yóò ti já ìsapá kulẹ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya ti kó wọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú àwòrán ìdílé aláyọ̀ kan lọ́kàn wọn, síbẹ̀ wọn kò ní yálà irin-iṣẹ́ tàbí òye iṣẹ́ láti gbé ọ̀kan ró. Ní kété lẹ́yìn ọjọ́ ìgbéyàwó, àwọn àṣà búburú yọjú. Ìjà àti asọ̀ di ìrírí ojoojúmọ́. Nígbà tí wọ́n bí àwọn ọmọ, bàbá àti ìyá titun náà ríi pé àwọn kò ní òye iṣẹ́ lórí jíjẹ́ òbí bí wọn kò ti ní in lórí mímú kí ìgbéyàwó wọn jẹ́ aláyọ̀.
3 Bí ó ti wù kí ó rí, ó múni láyọ̀ pé Bibeli lè ṣèrànlọ́wọ́. Àwọn ìlànà rẹ̀ dàbí irin-iṣẹ́ tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ìdílé aláyọ̀ kan ró. (Owe 24:3) Jẹ́ kí a wo bí ìyẹn ṣe rí bẹ́ẹ̀.
ÀWỌN IRIN-IṢẸ́ FÚN GBÍGBÉ ÌGBÉYÀWÓ ALÁYỌ̀ RÓ
4. Èéṣe tí a fi lè retí àwọn ìṣòro nínú ìgbéyàwó, kí sì ni àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n tí Bibeli pèsè?
4 Láìka bí ó ṣe lè dàbí ẹni pé tọkọtaya kan bá ara wọn mu tó sí, wọ́n yàtọ̀ níti ìmí-ẹ̀dùn, àwọn ìrírí ìgbà ọmọdé, àti ipò àtilẹ̀wá ti ìdílé. Nítorí náà, àwọn ìṣòro kan wà tí a lè retí lẹ́yìn ìgbéyàwó. Báwo ni a óò ṣe bójútó wọn? Tóò, nígbà tí àwọn kọ́lékọ́lé bá ń kọ́ ilé kan, wọn máa ń yẹ àwòrán ilé náà wò. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìtọ́sọ́nà tí a níláti tẹ̀lé. Bibeli pèsè àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun fún gbígbé ìdílé aláyọ̀ kan ró. Jẹ́ kí a gbé díẹ̀ lára ìwọ̀nyí yẹ̀wò.
5. Báwo ni Bibeli ṣe tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì ìdúróṣinṣin nínú ìgbéyàwó?
5 Ìdúróṣinṣin. Jesu sọ pé: “Ohun tí Ọlọrun ti sopọ̀ sábẹ́ àjàgà kí ènìyàn kankan máṣe yà á sọ́tọ̀.” * (Matteu 19:6) Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nitori Ọlọrun yoo dá awọn àgbèrè ati awọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Heberu 13:4) Nítorí náà, àwọn ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó níláti nímọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe sí Jehofa láti jẹ́ olùṣòtítọ́ sí ẹnì kejì wọn.—Genesisi 39:7-9.
6. Báwo ni ìdúróṣinṣin ṣe lè ṣèrànwọ́ láti pa ìgbéyàwó kan mọ́?
6 Ìdúróṣinṣin ń mú kí ìgbéyàwó ní iyì-ọlá àti ààbò. Àwọn tọkọtaya tí ó dúróṣinṣin mọ̀ pé, láìka ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀ sí, wọn yóò ti ara wọn lẹ́yìn. (Oniwasu 4:9-12) Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ tó sí àwọn tí wọ́n ṣá ìgbéyàwó wọn tì ní kété tí wọ́n bá kọ́kọ́ kófìrí ìjàngbọ̀n! Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń yára parí rẹ̀ sí pé wọn ‘yan ẹni àìtọ́,’ pé wọn ‘kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́,’ pé ẹnì kejì titun kan nìkanṣoṣo ni ojútùú náà. Ṣùgbọ́n èyí kò fún èyíkéyìí nínú àwọn méjèèjì ní àǹfààní láti dàgbà níti èrò ìmọ̀lára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tí kò dúróṣinṣin náà lè gbé àwọn ìṣòro kan náà dé ọ̀dọ̀ ẹnì kejì titun náà. Bí ẹnì kan bá ní ilé àtàtà kan ṣùgbọ́n tí ó ríi pé òrùlé rẹ̀ ń jò, ó dájú pé yóò gbìyànjú láti tún un ṣe. Òun kò ní kó lọ sí ilé mìíràn. Lọ́nà kan náà, pípààrọ̀ ẹnì kejì kì í ṣe ọ̀nà láti yanjú ọ̀ràn tí ó farapamọ́ sábẹ́ gbọ́nmisi-omi-ò-to nínú ìgbéyàwó. Nígbà tí ìṣòro bá dìde, máṣe gbìyànjú láti fòpin sí ìgbéyàwó náà, ṣùgbọ́n ṣiṣẹ́ kára láti pa á mọ́. Irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ ń fi ìgbéyàwó náà hàn bí ohun tí ó yẹ kí a dáàbòbò, kí á tọ́jú, kí a sì ṣìkẹ́.
7. Èéṣe tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ fi sábà máa ń ṣòro fún àwọn tọkọtaya, ṣùgbọ́n báwo ni gbígbé “àkópọ̀ ìwà titun wọ̀” ṣe lè ṣèrànwọ́?
7 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Òwe Bibeli kan sọ pé: “Láìsí ìgbìmọ̀, èrò a dasán.” (Owe 15:22) Síbẹ̀, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ṣòro fún àwọn tọkọtaya kan. Èéṣe tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé àwọn ènìyàn ní ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó yàtọ̀ síra. Èyí ni òtítọ́ tí ó sábà máa ń ṣamọ̀nà sí ọ̀pọ̀ àìgbọ́ra-ẹni-yé àti ìmújákulẹ̀. Bí a ṣe tọ́ ẹnì kan dàgbà lè kó ipa kan nínú èyí. Fún àpẹẹrẹ, a ti lè tọ́ àwọn kan dàgbà ní àyíká kan tí àwọn òbí ti máa ń ní asọ̀. Nísinsìnyí bí àgbàlagbà tí ó ti ṣègbéyàwó, wọ́n lè má mọ bí ó ti yẹ kí wọ́n bá ẹnì kejì wọn sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ kí ilé rẹ lọ sẹ́yìn di ‘ilé tí ó kún fún ìjà.’ (Owe 17:1) Bibeli tẹnumọ́ gbígbé “àkópọ̀ ìwà titun wọ̀,” kò sì gbojú bọ̀rọ̀ fún ìkorò onínú-burúkú, ìlọgun, àti ọ̀rọ̀ èébú.—Efesu 4:22-24, 31.
8. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ nígbà tí o kò bá fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ?
8 Kí ni o lè ṣe nígbà tí àìfohùnṣọ̀kan bá wà? Bí ìbínú bá bẹ̀rẹ̀ sí ru, yóò dára bí o bá tẹ̀lé ìmọ̀ràn Owe 17:14 pé: “Fi ìjà sílẹ̀ kí ó tó di ńlá.” Bẹ́ẹ̀ni, o lè sọ ìjíròrò náà di ìgbà mìíràn lẹ́yìn náà, nígbà tí ara yóò ti tu ìwọ àti ẹnì kejì rẹ. (Oniwasu 3:1, 7) Ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀, sakun láti “yára nipa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nipa ìrunú.” (Jakọbu 1:19) Góńgó rẹ níláti jẹ́ láti yanjú ọ̀ràn náà, kì í ṣe láti mókè nínú àríyànjiyàn. (Genesisi 13:8, 9) Ṣe àṣàyàn àwọn ọ̀rọ̀ àti ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ tí yóò mú ara rọ ìwọ àti ẹnìkejì rẹ. (Owe 12:18; 15:1, 4; 29:11) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ máṣe máa báa lọ láti wà ní ipò ìtánnísùúrù, ṣùgbọ́n ẹ wá ìrànlọ́wọ́ nípa jíjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun nínú àdúrà àjùmọ̀gbà tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀.—Efesu 4:26, 27; 6:18.
9. Kí ni ìdí rẹ̀ tí a fi lè sọ pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ń bẹ̀rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà?
9 Òwe kan nínú Bibeli sọ pé: “Àyà ọlọgbọ́n mú ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, ó sì mú ẹ̀kọ́ pọ̀ ní ètè rẹ̀.” (Owe 16:23) Nítòótọ́, nígbà náà, kọ́kọ́rọ́ náà sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ aláṣeyọrí wà nínú ọkàn-àyà, kì í ṣe ní ẹnu. Kí ni ìṣarasíhùwà rẹ sí ẹnìkejì rẹ? Bibeli fún àwọn Kristian níṣìírí láti fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn. (1 Peteru 3:8) O ha lè ṣe èyí bí ẹnìkejì rẹ nínú ìgbéyàwó bá ń ní ìrírí àníyàn oníwàhálà ìdààmú? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bí ó ṣe yẹ kí o dáhùn.—Isaiah 50:4.
10, 11. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi ìmọ̀ràn 1 Peteru 3:7 sílò?
10 Ọlá àti Ọ̀wọ̀. Àwọn Kristian ọkọ ni a sọ fún láti bá àwọn aya wọn gbé “ní ìbámu pẹlu ìmọ̀, kí [wọ́n] máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun-ìlò aláìlerató, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Peteru 3:7) Bíbọlá fún aya ẹni ní nínú mímọyì ìníyelórí rẹ̀. Ọkọ kan tí ń gbé pẹ̀lú aya rẹ̀ “ní ìbámu pẹlu ìmọ̀” ní ìkàsí gíga fún ìmọ̀lára, okun, ọgbọ́n-òye, àti iyì-ọlá rẹ̀. Ó tún níláti fẹ́ láti kọ́ nípa ojú tí Jehofa fi ń wo àwọn obìnrin àti bí ó ṣe fẹ́ kí a bá wọn lò.
11 Nínú ilé rẹ, jẹ́ kí a sọ pé o ní ajọgbá wíwúlò kan tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́ gidigidi. Ìwọ kì yóò ha fi ìṣọ́ra gíga lò ó bí? Tóò, Peteru lo èdè ìsọ̀rọ̀ náà “ohun-ìlò aláìlerató” ní ọ̀nà tí ó farajọra, èyí sì yẹ kí ó sún Kristian ọkọ kan láti ka aya rẹ̀ ọ̀wọ́n sí lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.
12. Báwo ni aya kan ṣe lè fi hàn pé òun fún ọkọ òun ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀?
12 Ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn wo ni Bibeli fún aya kan? Paulu kọ̀wé pé: “Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Efesu 5:33) Gẹ́gẹ́ bí aya kan ṣe níláti nímọ̀lára pé ẹnìkejì òun bọlá ó sì nífẹ̀ẹ́ òun jinlẹ̀jinlẹ̀, ọkọ kan níláti nímọ̀lára pé aya òun bọ̀wọ̀ fún òun. Àyà kan tí ó lọ́wọ̀ kì yóò máa fi àìnírònú pariwo àwọn àṣìṣe ọkọ rẹ̀ fáyégbọ́, yálà ó jẹ́ Kristian tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Kì yóò dù ú ní iyì-ọlá rẹ̀ nípa ṣíṣe lámèyítọ́ rẹ̀ tàbí fífojú kéré rẹ̀ yálà níkọ̀kọ̀ tàbí ní gbangba.—1 Timoteu 3:11; 5:13.
13. Báwo ni a ṣe lè fi ojú-ìwòye wa hàn ní ọ̀nà alálàáfíà?
13 Èyí kò túmọ̀ sí pé aya kan kò lè sọ èrò rẹ̀ jáde. Bí ohun kan bá ń dà á láàmú, ó lè sọ èyí jáde tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Genesisi 21:9-12) Gbígbé èrò kan jáde sí ọkọ rẹ̀ ni a lè fiwé jíju bọ́ọ̀lù kan sí i. Ó lè rọra tì í síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó baà rọrùn fún un láti mú, ó sì lè jù ú pẹ̀lú ipa tóbẹ́ẹ̀ tí yóò fi ṣe ìpalára fún un. Ẹ wo bí yóò ti sàn jù tó bí àwọn méjèèjì bá yẹra fún sísọ̀kò ẹ̀sùn lu ara wọn, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà pẹ̀lẹ́, tí ó sì nínúure!—Matteu 7:12; Kolosse 4:6; 1 Peteru 3:3, 4.
14. Kí ni ìwọ níláti ṣe bí ẹnì kejì rẹ kò bá fi ọkàn ìfẹ́ tí ó pọ̀ tó hàn nínú fífi àwọn ìlànà Bibeli sílò nínú ìgbéyàwó?
14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, àwọn ìlànà Bibeli lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbéyàwó aláyọ̀ kan ró. Ṣùgbọ́n kí ni bí ẹnìkejì rẹ kò bá fi ọkàn ìfẹ́ púpọ̀ hàn nínú ohun tí Bibeli ní láti sọ? O ṣì lè ṣàṣeparí ohun tí ó pọ̀ bí o bá fi ìmọ̀ Ọlọrun sílò nínú ipa-iṣẹ́ tìrẹ. Peteru kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ tiyín, kí ó baà lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ naa, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà awọn aya wọn, nitori jíjẹ́ tí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ìwà mímọ́ yín papọ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Peteru 3:1, 2) Dájúdájú, ohun kan náà ṣeé fisílò fún ọkọ kan tí ìyàwó rẹ̀ dágunlá sí Bibeli. Láìka ohun tí ẹnì kejì rẹ yàn láti ṣe sí, jẹ́ kí àwọn ìlànà Bibeli mú ọ jẹ́ alájùmọ̀ṣègbéyàwó tí ó sàn jù. Ìmọ̀ Ọlọrun tún lè mú ọ jẹ́ òbí tí ó sàn jù.
TÍTỌ́ ÀWỌN ỌMỌ DÀGBÀ NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ÌMỌ̀ ỌLỌRUN
15. Nígbà mìíràn báwo ni a ṣe máa ń ta àtaré àwọn ọ̀nà tí ó ní àṣìṣe tí a gbà ń tọ́ ọmọ, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè yí ọ̀nà yìí padà?
15 Wíwulẹ̀ ní ìfági àti òòlù kan kò sọ ẹnì kan di káfíńtà kan tí ó ní òye iṣẹ́. Bákan náà, wíwulẹ̀ ní àwọn ọmọ kò sọ ẹnì kan di òbí tí ó ní òye iṣẹ́. Bóyá wọ́n mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀, àwọn òbí sábà máa ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà ní ọ̀nà kan náà tí a gbà tọ́ wọn dàgbà. Nípa báyìí, àwọn ọ̀nà tí ó ní àṣìṣe tí a ń gbà tọ́ ọmọ ni a sábà máa ń ta àtaré rẹ̀ láti ìran kan sí èyí tí ó tẹ̀lé e. Òwe Heberu kan ní ìgbàanì sọ pé: “Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan, eyín àwọn ọmọ sì kan.” Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ẹnì kan kò níláti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà tí àwọn òbí rẹ̀ fi lélẹ̀. Ó lè yan ipa-ọ̀nà tí ó yàtọ̀, ọ̀kan tí àwọn ìlànà-òfin Jehofa ń darí.—Esekieli 18:2, 14, 17.
16. Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti pèsè fún ìdílé rẹ, kí ni èyí sì ní nínú?
16 Jehofa retí pé kí àwọn Kristian òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́sọ́nà àti àbójútó tí ó tọ́. Paulu kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún awọn wọnnì tí [wọ́n] jẹ́ tirẹ̀, ati ní pàtàkì fún awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Timoteu 5:8) Àwọn ọ̀rọ̀ alágbára nìwọ̀nyẹn! Mímú ìlà-iṣẹ́ rẹ ṣẹ bí olùpèsè, tí ó kan bíbójútó àìní àwọn ọmọ rẹ níti ara-ìyára, tẹ̀mí, àti ti èrò-ìmọ̀lára, jẹ́ àǹfààní àti ẹrù-iṣẹ́ ẹni oníwà-bí-Ọlọ́run kan. Bibeli pèsè àwọn ìlànà tí ó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti gbé àyíká aláyọ̀ ró fún àwọn ọmọ wọn. Gbé díẹ̀ lára ìwọ̀nyí yẹ̀wò.
17. Kí ni ó pọndandan bí àwọn ọmọ rẹ bá níláti ní òfin Ọlọrun nínú ọkàn-àyà wọn?
17 Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. A pàṣẹ fún àwọn òbí ní Israeli pé: “Kí ìwọ kí ó sì máa fi [àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun] kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ ísọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.” Àwọn òbí níláti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun. Ṣùgbọ́n ìṣílétí yìí ní ọ̀rọ̀ àsọṣáájú yìí: “Àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo paláṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní [ọkàn-àyà rẹ, NW].” (Deuteronomi 6:6, 7) Bẹ́ẹ̀ni, àwọn òbí kò lè fúnni ní ohun tí wọn kò ní. O gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ àwọn òfin Ọlọrun sínú ọkàn-àyà tìrẹ bí o bá fẹ́ kí a kọ wọ́n sínú ọkàn-àyà àwọn ọmọ rẹ.—Owe 20:7; fiwé Luku 6:40.
18. Ní fífi ìfẹ́ hàn, báwo ni Jehofa ti ṣe fi àpẹẹrẹ tí ó tayọ lélẹ̀ fún àwọn òbí?
18 Mú ìfẹ́ rẹ dá wọn lójú. Nígbà batisí Jesu, Jehofa polongo pé: “Iwọ ni Ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti fi ojúrere tẹ́wọ́gbà ọ́.” (Luku 3:22) Jehofa tipa báyìí jẹ́wọ́ fi Ọmọkùnrin rẹ̀ hàn, ní fífi ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ hàn fàlàlà tí ó sì mú ìfẹ́ Rẹ̀ dá a lójú. Lẹ́yìn náà Jesu sọ fún Bàbá rẹ̀ pé: “Iwọ nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Johannu 17:24) Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí òbí oníwà-bí-Ọlọ́run, fi ìfẹ́ rẹ hàn fún àwọn ọmọ rẹ nípa ọ̀rọ̀ ẹnu àti lọ́nà tí ó ṣeé fojúrí—sì ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra. Máa rántí nígbà gbogbo pé “ìfẹ́ a máa gbéniró.”—1 Korinti 8:1.
19, 20. Kí ni bíbá àwọn ọmọ wí lọ́nà tí ó tọ́ ní nínú, báwo sì ni àwọn òbí ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ Jehofa?
19 Ìbáwí. Bibeli tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì ìbáwí onífẹ̀ẹ́. (Owe 1:8) Ó dájú pé àfàìmọ̀ ni àwọn tí wọ́n bá yẹ ẹ̀rù-iṣẹ́ wọn láti tọ́ àwọn ọmọ sílẹ̀ lónìí kò fi ní dojúkọ àbáyọrí bíbaninínújẹ́ lọ́la. Síbẹ̀, a kìlọ̀ fún àwọn òbí lòdì sí lílọ rékọjá ààlà. Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe máa dá awọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà soríkodò.” (Kolosse 3:21) Àwọn òbí gbọ́dọ̀ yẹra fún títọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà rékọjá ààlà tàbí títẹnumọ́ àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọn lemọ́lemọ́ àti ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn ìsapá wọn.
20 Jehofa Ọlọrun, Bàbá wa ọ̀run, fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa ní fífúnni ní ìbáwí. Kò sí ìgbà kan rí tí ìtọ́sọ́nà rẹ̀ lọ rékọjá ààlà. Ọlọrun sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Èmi óò bá ọ wí ní ìwọ̀n.” (Jeremiah 46:28) Àwọn òbí níláti farawé Jehofa ní ìhà yìí. Ìbáwí tí ó bá rékọjá ààlà tí ó lọ́gbọ́n nínú tàbí tí ó bá rékọjá ète tí a fi ń tọ́nisọ́nà tí a sì fi ń kọ́ni dájúdájú ń dánilágara.
21. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè pinnu bóyá ìbáwí wọn gbéṣẹ́?
21 Báwo ni àwọn òbí ṣe lè mọ̀ bí ìbáwí wọn bá gbéṣẹ́? Wọ́n lè béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, ‘Kí ni ìbáwí mi ṣàṣeparí rẹ̀?’ Ó níláti kọ́ni. Ó yẹ kí ọmọ rẹ lóye ìdí tí a fi bá a wí. Àwọn òbí tún níláti dàníyàn nípa ìyọrísí ìtọ́sọ́nà wọn. Lóòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ọmọ ni yóò kọ́kọ́ bínú sí ìbáwí. (Heberu 12:11) Ṣùgbọ́n ìbáwí kò níláti kó jìnnìjìnnì bá ọmọ kan tàbí kí ó mú un nímọ̀lára ìpatì tàbí kí ó fún un ní èrò náà pé òun jẹ́ ẹni búburú lọ́nà àjogúnbá. Ṣáájú kí ó tó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ́nà, Jehofa sọ pé: “Má bẹ̀rù, . . . nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ.” (Jeremiah 46:28) Bẹ́ẹ̀ni, ìtọ́sọ́nà ni o níláti fúnni ní ọ̀nà kan tí ọmọ rẹ yóò fi nímọ̀lára pé o wà pẹ̀lú rẹ̀ bí òbí onífẹ̀ẹ́, tí ń ṣètìlẹyìn.
JÍJÈRÈ “ÌGBÌMỌ̀ ỌGBỌ́N”
22, 23. Báwo ni o ṣe lè jèrè ìdarísọ́nà tí o nílò láti gbé ìdílé aláyọ̀ ró?
22 A lè kún fún ìmoore pé Jehofa ti pèsè irinṣẹ́ tí a nílò láti gbé ìdílé aláyọ̀ kan ró. Ṣùgbọ́n wíwulẹ̀ ní irinṣẹ́ nìkan kò tó. A gbọ́dọ̀ kọ́ bí ó ṣe yẹ kí a lò wọ́n lọ́nà tí ó tọ́. Fún àpẹẹrẹ, kọ́lékọ́lé kan lè mú àwọn àṣà tí kò dára dàgbà nínú ọ̀nà tí ó ń gbà lo irinṣẹ́ rẹ̀. Ó lè lo àwọn mìíràn ní ọ̀nà tí kò tilẹ̀ tọ̀nà rárá. Lábẹ́ àwọn ipò wọ̀nyí, ọgbọ́n ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ṣeé ṣe kí ó yọrí sí ìmújáde tí kì í ṣe ojúlówó. Lọ́nà kan náà, nísinsìnyí o lè wá mọ̀ nípa àṣà kan tí ó léwu tí ó ti yọ́ wọnú ìdílé rẹ. Àwọn kan lè fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in kí wọ́n sì ṣòro láti yípadà. Bí ó ti wù kí ó rí, tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bibeli náà: “Ọlọ́gbọ́n yóò gbọ́, yóò sì máa pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́; àti ẹni òye yóò gba ìgbìmọ̀ ọgbọ́n.”—Owe 1:5.
23 O lè jèrè ìgbìmọ̀ ọgbọ́n nípa bíba a lọ láti gba ìmọ̀ Ọlọrun sínú. Wà lójúfò sí àwọn ìlànà Bibeli tí ìdílé rẹ lè fi sílò, kí o sì ṣe àwọn àtúnṣe tí ó yẹ. Ṣàkíyèsí àwọn Kristian tí wọ́n dàgbàdénú tí wọ́n fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ bí tọkọtaya àti òbí. Bá wọn sọ̀rọ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kó gbogbo àwọn ìdàníyàn rẹ lọ bá Jehofa nínú àdúrà. (Orin Dafidi 55:22; Filippi 4:6, 7) Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí-ayé ìdílé aláyọ̀ tí ó bọlá fún un.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 Ìdí kanṣoṣo tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìkọ̀sílẹ̀ tí ó yọ̀ǹda fún títún ìgbéyàwó ṣe ni “àgbèrè”—ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó.—Matteu 19:9.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Báwo ni ìdúróṣinṣin, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, ọlá, àti ọ̀wọ̀ ṣe ń fikún ìgbéyàwó kan tí ó jẹ́ aláyọ̀?
Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn òbí lè gbà mú ìfẹ́ wọn dá àwọn ọmọ wọn lójú?
Àwọn kókó abájọ wo ni ìbáwí títọ́ ní nínú?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 147]