Jesu Kristi Kọ́kọ́rọ́ Náà Sí Ìmọ̀ Ọlọrun
Orí 4
Jesu Kristi Kọ́kọ́rọ́ Náà Sí Ìmọ̀ Ọlọrun
1, 2. Báwo ni àwọn ìsìn ayé ti ṣe yí kọ́kọ́rọ́ sí ìmọ̀ Ọlọrun sódì?
O DÚRÓ lẹ́nu ilẹ̀kùn, o ń ṣe èyí-ni-òun-kọ́ pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ. Otútù ń mú ilẹ̀ sì ti ṣú, o sì ń háragàgà láti wọlé—ṣùgbọ́n kọ́kọ́rọ́ náà kò ṣiṣẹ́. Ó dàbí ẹni pé òun ni, síbẹ̀ àgádágodo náà kò ṣí. Ìyẹn mà lè jánikulẹ̀ o! O tún wo àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ lẹ́ẹ̀kan síi. Èyí tí ó tọ́ ni o ha ń lò bí? Ẹnì kan ha ti ba kọ́kọ́rọ́ náà jẹ́ ni bí?
2 Àkàwé tí ó ṣe wẹ́kú nìyẹn nípa ohun tí ìdàrúdàpọ̀ nínú ìsìn ayé yìí ti ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọrun. Ìyọrísí èyí ni pé, kọ́kọ́rọ́ náà tí a lè fi ṣí i kí a sì lóye rẹ̀—Jesu Kristi—ni ọ̀pọ̀ ti yí sódì. Àwọn ìsìn kan ti yọ kọ́kọ́rọ́ náà kúrò, tí wọ́n tilẹ̀ ṣàìfiyèsí Jesu pátápátá. Àwọn mìíràn ti yí ipa-iṣẹ́ Jesu padà, tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ bí Ọlọrun Olódùmarè. Bí ó ti wù kí ọ̀ràn rí, ìmọ̀ Ọlọrun ṣì wà ní títìpa sí wa bí a kò bá ní ìmọ̀ pípéye nípa ẹni sàràkí yìí, Jesu Kristi.
3. Èéṣe tí a fi lè pe Jesu ní kọ́kọ́rọ́ sí ìmọ̀ Ọlọrun?
3 O lè rántí pé Jesu sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, ati ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.” (Johannu 17:3) Ní sísọ èyí, kì í ṣe pé Jesu jẹ́ afọ́nnu. Léraléra ni Ìwé Mímọ́ tẹnumọ́ àìní náà fún ìmọ̀ pípéye nípa Kristi. (Efesu 4:13; Kolosse 2:2; 2 Peteru 1:8; 2:20) Aposteli Peteru sọ pé: “[Jesu Kristi] ni gbogbo awọn wòlíì jẹ́rìí sí.” (Ìṣe 10:43) Aposteli Paulu sì kọ̀wé pé: “Ní inú [Jesu] ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ti ìmọ̀ pamọ́ sí.” (Kolosse 2:3) Paulu tilẹ̀ sọ pé gbogbo àwọn ìlérí Jehofa jásí òtítọ́ nítorí Jesu. (2 Korinti 1:20) Nítorí náà, Jesu Kristi ni kọ́kọ́rọ́ náà gan-an sí ìmọ̀ Ọlọrun. Ìmọ̀ wa nípa Jesu kò gbọ́dọ̀ ní ìfèrúyípadà kankan níti irú ẹni tí ó jẹ́ àti ipa-iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọrun. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu fi rò pé òun ni ó ṣe pàtàkì jùlọ fún àwọn ète Ọlọrun?
MESSIA TÍ A ṢÈLÉRÍ NÁÀ
4, 5. Àwọn ìrètí wo ni a gbé karí Messia náà, ojú wo sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu fi wò ó?
4 Láti ìgbà ayé ọkùnrin olùṣòtítọ́ náà Abeli, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ti ń fi ìháragàgà wo ọjọ́ iwájú fún Irú-Ọmọ tí Jehofa Ọlọrun fúnra rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀. (Genesisi 3:15; 4:1-8; Heberu 11:4) A ti ṣíi payá pé Irú-Ọmọ náà yóò ṣiṣẹ́ fún ète Ọlọrun bíi Messia, tí ó túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.” Òun yóò “fi èdídí dí ẹ̀ṣẹ̀,” ògo Ìjọba rẹ̀ ni a sì sọtẹ́lẹ̀ nínú psalmu. (Danieli 9:24-26, NW; Orin Dafidi 72:1-19) Ta ni yóò wá jẹ́ Messia náà?
5 Ronú nípa ìtara ọkàn tí ọ̀dọ́ Júù tí ń jẹ́ Anderu ti níláti ní nígbà tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ara Nasareti. Anderu yára lọ sọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀ Simoni Peteru ó sì sọ fún un pé: “Awa ti rí Messia naa.” (Johannu 1:41) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbọ́ dájú pé òun ni Messia tí a ṣèlérí náà. (Matteu 16:16) Àwọn Kristian tòótọ́ sì ti múratán láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ lórí ìgbàgbọ́ pé nítòótọ́ Jesu ni Messia, tàbí Kristi tí a sọtẹ́lẹ̀ náà. Ẹ̀rí ìdánilójú wo ni wọ́n ti ní? Jẹ́ kí a gbé ẹ̀rí mẹ́ta tí ń pèsè ìsọfúnni yẹ̀wò.
Ẹ̀RÍ PÉ JESU NI MESSIA NÁÀ
6. (a) Ìlà ìran wo ni yóò mú Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà wá, báwo ni a sì ṣe mọ̀ pé Jesu wá láti ìlà ìdílé yẹn? (b) Èéṣe tí kò fi lè ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni tí ó wàláàyè lẹ́yìn 70 C.E. láti sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé òun ni Messia náà?
6 Ìlà ìran Jesu fìdí ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ fún dídá a mọ̀ bíi Messia Genesisi 22:18; 26:2-5; 28:12-15; 49:10) Ìlà ibi tí Messia náà ti ṣẹ̀wá ni a túbọ̀ sọ di tóóró síi ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà nígbà tí a sọ fún Ọba Dafidi pé ìlà ìdílé rẹ̀ ni yóò mú Ẹni yìí jáde. (Orin Dafidi 132:11; Isaiah 11:1, 10) Àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere ti Matteu àti Luku jẹ́rìí síi pé Jesu wá láti ìlà ìdílé yẹn. (Matteu 1:1-16; Luku 3:23-38) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀tá tí inú wọn ń rugùdù, kò sí èyíkéyìí lára wọn tí ó ṣe awuyewuye sí ìlà tí ó ti ṣẹ̀wá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ bí ẹni mowó. (Matteu 21:9, 15) Dájúdájú, nígbà náà, ìlà ìran rẹ̀ kọjá ohun tí ẹnikẹ́ni lè gbé ìbéèrè dìde sí. Bí ó ti wù kí ó rí, àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn Júù ni a parun nígbà tí àwọn ará Romu piyẹ́ Jerusalemu ní 70 C.E. Lẹ́yìn náà, kò sí ẹni tí ó tún lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé òun ni Messia tí a ṣèlérí náà.
náà tí a ṣèlérí múlẹ̀. Jehofa ti sọ fún Abrahamu ìránṣẹ́ Rẹ̀ pé Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà yóò wá láti inú ìdílé rẹ̀. Isaaki ọmọkùnrin Abrahamu, Jekọbu ọmọkùnrin Isaaki, àti Juda ọmọkùnrin Jekọbu ni àwọn náà gba irú ìlérí bẹ́ẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. (7. (a) Kí ni ẹ̀rí kejì tí ń pèsè ìsọfúnni pé Jesu ni Messia náà? (b) Báwo ni Mika 5:2 ṣe ní ìmúṣẹ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Jesu?
7 Àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní ìmúṣẹ jẹ́ ẹ̀rí kejì tí ń pèsè ìsọfúnni. Ọ̀pọ̀ tabua àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ṣàpèjúwe onírúurú ìhà ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé Messia náà. Ní ọ̀rúndún kẹjọ B.C.E., wòlíì Mika sọtẹ́lẹ̀ pé alákòóso títóbi yìí ni a óò bí ní ìlú tí kò gbajúmọ̀ náà Betlehemu. Àwọn ìlú Israeli méjì ni a ń pè ní Betlehemu, ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ èyí tí ó jẹ́ ní pàtó: Betlehemu Efrata, níbi tí a bí Ọba Dafidi sí. (Mika 5:2) Àwọn òbí Jesu, Josefu àti Maria, ń gbé ní Nasareti, 150 kìlómítà síhà àríwá Betlehemu. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí Maria wà nínú oyún, alákòóso Romu náà Kesari Augustu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ènìyàn forúkọ sílẹ̀ ní ìlú-ńlá ìbílẹ̀ wọn. * Nítorí náà Josefu níláti mú aya rẹ̀ tí ó lóyún lọ sí Betlehemu, níbi tí a bí Jesu sí.—Luku 2:1-7.
8. (a) Nígbà wo àti pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni “ọ̀sẹ̀” 69 náà bẹ̀rẹ̀? (b) Báwo ni “ọ̀sẹ̀” 69 náà ṣe gùn tó, kí sì ni ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n dópin?
8 Ní ọ̀rúndún kẹfà B.C.E., wòlíì Danieli sọtẹ́lẹ̀ pé “Messia Aṣáájú” yóò fara hàn ní “ọ̀sẹ̀” 69 lẹ́yìn tí àṣẹ náà ti jáde lọ láti tún Jerusalemu ṣe, àti láti tún un kọ́. (Danieli 9:24, 25, NW) Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn “ọ̀sẹ̀” wọ̀nyí jẹ́ ọdún méje ní gígùn. * Ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn Bibeli àti ti ayé, àṣẹ láti tún Jerusalemu kọ́ jáde ní 455 B.C.E. (Nehemiah 2:1-8) Nítorí náà, ó yẹ kí Messia fara hàn ní 483 (69 nígbà 7) ọdún lẹ́yìn 455 B.C.E. Ìyẹn mú wa dé 29 C.E., ọdún náà gan-an tí Jehofa fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jesu. Jesu tipa báyìí di “Kristi náà” (tí ó túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró”), tàbí Messia.—Luku 3:15, 16, 21, 22.
9. (a) Báwo ni Orin Dafidi 2:2 ṣe ní ìmúṣẹ? (b) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn wo ni wọ́n ní ìmúṣẹ nínú Jesu? (Wo àwòrán ìsọfúnni.)
9 Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó tẹ́wọ́gba Jesu bí Messia tí a ṣèlérí náà, Ìwé Mímọ́ sì ti sọ èyí tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bi a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Orin Dafidi 2:2, Ọba Dafidi ni a mí sí láti ọ̀run wá láti sọtẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọba ayé kẹ́sẹ̀ jọ, àti àwọn ìjòyè ń gbìmọ̀ pọ̀ sí Oluwa àti sí Ẹni-òróró rẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé àwọn aṣáájú láti ilẹ̀ tí ó ju ọ̀kan lọ yóò parapọ̀ láti gbéjàko Ẹni Àmì Òróró, tàbí Messia Jehofa. Ohun tí ó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù, Ọba Herodu, àti gómìnà Romu náà Pontiu Pilatu ni gbogbo wọn ko ipa kan nínú pípa Jesu. Herodu àti Pilatu tí wọ́n ti jẹ́ ọ̀tá tẹ́lẹ̀rí di ọ̀rẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ìgbà náà lọ. (Matteu 27:1, 2; Luku 23:10-12; Ìṣe 4:25-28) Fún àfikún ẹ̀rí ìdánilójú pé Jesu ni Messia náà, jọ̀wọ́ wo àwòrán ìsọfúnni tí ó wà níhìn-ín tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Díẹ̀ Títayọlọ́lá Nípa Messia.”
10. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa gbà jẹ́rìí síi pé Jesu ni Ẹni Àmì Òróró tí òun ṣèlérí náà?
10 Gbólóhùn ẹ̀rí ti Jehofa Ọlọrun ni ẹ̀rí kẹta tí ń pèsè ìsọfúnni tí ó ṣètìlẹyìn fún jíjẹ́ Messia Jesu. Jehofa rán àwọn áńgẹ́lì láti fi tó àwọn ènìyàn létí pé Jesu ni Messia tí a ṣèlérí náà. (Luku 2:10-14) Níti tòótọ́, lákòókò iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu lórí ilẹ̀-ayé, Jehofa fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá, ní sísọ ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ fún Jesu jáde. (Matteu 3:16, 17; 17:1-5) Jehofa Ọlọrun fún Jesu ní agbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára ìwọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú síwájú síi pé Jesu ni Messia náà, nítorí Ọlọrun kì yóò fúnni ní agbára jìbìtì láti ṣe iṣẹ́ ìyanu láé. Jehofa tún lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mí sí àwọn àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere, kí ẹ̀rí ipò jíjẹ́ Messia Jesu baà lè di apákan Bibeli, ìwé tí a tíì túmọ̀ tí a sì pín kiri jùlọ nínú ìtàn.—Johannu 4:25, 26.
11. Báwo ni àwọn ẹ̀rí tí ó wà pé Jesu ni Messia náà ṣe pọ̀ tó?
11 Lápapọ̀, gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òkodoro òtítọ́ nínú tí ó fi Jesu hàn yàtọ̀ bí Messia tí a ṣèlérí náà. Ní kedere, nígbà náà, lọ́nà tí ó tọ́, àwọn Kristian tòótọ́ ti wò ó bí ‘ẹni naa tí gbogbo awọn wòlíì jẹ́rìí sí’ àti kọ́kọ́rọ́ náà sí ìmọ̀ Ọlọrun. (Ìṣe 10:43) Ṣùgbọ́n púpọ̀ síi ṣì wà láti kọ́ nípa Jesu Kristi ju òtítọ́ náà pé òun ni Messia. Ibo ni ó ti wá? Irú ẹni wo ni ó jẹ́?
WÍWÀLÁÀYÈ JESU ṢÁÁJÚ DÍDI Ẹ̀DÁ ÈNÌYÀN
12, 13. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jesu wàláàyè ní ọ̀run ṣáájú kí ó tó wá sórí ilẹ̀-ayé? (b) Ta ni “Ọ̀rọ̀ naa,” kí sì ni ó ṣe ṣáájú kí ó tó di ẹ̀dá ènìyàn?
12 A lè pín ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé Jesu sí ìpele mẹ́ta. Èkínní bẹ̀rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí a tó bí i sórí ilẹ̀-ayé. Mika 5:2 sọ pé ìpilẹ̀ṣẹ̀ Messia náà jẹ́ “láti ìgbàanì, láti ayérayé.” Jesu sì sọ ní kedere pé òun wá láti “awọn ilẹ̀-àkóso òkè,” ìyẹn ni pé, láti ọ̀run. (Johannu 8:23; 16:28) Báwo ni ó ti pẹ́ tó tí ó ti wà ní ọ̀run kí ó tó wá sórí ilẹ̀-ayé?
13 A pe Jesu ní “Ọmọkùnrin bíbí . . . kanṣoṣo” ti Ọlọrun nítorí pé Jehofa dá a ní tààràtà fúnra rẹ̀. (Johannu 3:16) Gẹ́gẹ́ bí “àkọ́bí ninu gbogbo ìṣẹ̀dá,” Ọlọrun lo Jesu lẹ́yìn náà láti ṣẹ̀dá gbogbo àwọn nǹkan yòókù. (Kolosse 1:15; Ìṣípayá 3:14) Johannu 1:1 sọ pé “Ọ̀rọ̀ naa” (Jesu nígbà wíwà rẹ̀ ṣáájú kí ó tó di ẹ̀dá ènìyàn) wà pẹ̀lú Ọlọrun “ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ náà wà pẹ̀lú Jehofa nígbà tí ó dá “ọ̀run òun ayé.” Ọlọrun ń bá Ọ̀rọ̀ náà sọ̀rọ̀ nígbà tí Ó sọ pé: “Jẹ́ kí á dá ènìyàn ní àwòrán wa.” (Genesisi 1:1, 26) Bákan náà, Ọ̀rọ̀ náà gbọ́dọ̀ ti jẹ́ “ọ̀gá oníṣẹ́” olùfẹ́ ọ̀wọ́n ti Ọlọrun, tí a ṣàpèjúwe nínú Owe 8:22-31 (NW) gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a sọ di ẹni gidi, tí ó ń ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jehofa ní ṣíṣe ohun gbogbo. Lẹ́yìn tí Jehofa ti mú kí ó wà, Ọ̀rọ̀ náà lo ọ̀pọ̀ ọdún pẹ̀lú Ọlọrun ní ọ̀run ṣáájú kí ó tó di ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé.
14. Èéṣe tí a fi pe Jesu ní “àwòrán Ọlọrun tí a kò lè rí”?
14 Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé Kolosse 1:15 pe Jesu ní “àwòrán Ọlọrun tí a kò lè rí”! Jálẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìbárẹ́ pẹ́kípẹ́kí, Ọmọkùnrin onígbọràn náà ti wá dàbí Baba rẹ̀, Jehofa, gẹ́lẹ́. Ìdí mìíràn nìyí tí Jesu fi jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí ìmọ̀ Ọlọrun tí ń fúnni ní ìyè. Gbogbo ohun tí Jesu ṣe nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé jẹ́ ohun tí Jehofa ìbá ti ṣe gẹ́lẹ́. Nítorí ìdí èyí, wíwá láti mọ Jesu tún túmọ̀ sí mímú ìmọ̀ wa nípa Jehofa pọ̀ síi. (Johannu 8:28; 14:8-10) Ní kedere, nígbà náà, ó ṣe kókó láti kọ́ púpọ̀ síi nípa Jesu Kristi.
IPA-Ọ̀NÀ ÌGBÉSÍ-AYÉ JESU LÓRÍ ILẸ̀-AYÉ
15. Báwo ni ó ṣe ṣẹlẹ̀ pé a bí Jesu bí ọmọ-ọwọ́ pípé kan?
15 Ìpele kejì ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé Jesu jẹ́ níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé. Ó fínnúfíndọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ nígbà tí Ọlọrun ta àtaré ìwàláàyè rẹ̀ láti ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù olùṣòtítọ́ kan tí ń jẹ́ Maria. Ẹ̀mí mímọ́ alágbára ti Jehofa, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀, ‘ṣíjibo’ Maria, ní mímú kí ó lóyún kí ó sì bí ọmọ-ọwọ́ pípé kan nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. (Luku 1:34, 35) Jesu kò jogún àìpé, níwọ̀n bí ìwàláàyè rẹ̀ ti wá láti Orísun pípé kan. A tọ́ ọ dàgbà nínú ilé tí kò jọjú kan bí ọmọkùnrin àgbàṣọmọ Josefu káfíńtà ó sì jẹ́ àkọ́bí nínú àwọn ọmọ mélòókan tí ìdílé náà ní.—Isaiah 7:14; Matteu 1:22, 23; Marku 6:3.
16, 17. (a) Níbo ni Jesu ti rí agbára tí ó fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, kí sì ni díẹ̀ lára wọn? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí Jesu fi hàn?
16 Ìfọkànsìn jíjinlẹ̀ tí Jesu ní fún Jehofa Ọlọrun ti hàn gbangba nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 12. (Luku 2:41-49) Lẹ́yìn tí ó ti dàgbà tí ó sì ti dáwọ́lé iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ẹni 30 ọdún, Jesu tún fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní fún ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ hàn. Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun fún un ní agbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, tìyọ́nú tìyọ́nú ni ó fi wo àwọn aláìsàn, arọ, aláàbọ̀ ara, afọ́jú, adití, àti adẹ́tẹ̀ sàn. (Matteu 8:2-4; 15:30) Jesu fi oúnjẹ bọ́ àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí ebi ń pa. (Matteu 15:35-38) Ó mú kí ìjì tí ń halẹ̀ mọ́ ààbò àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ rọlẹ̀. (Marku 4:37-39) Níti tòótọ́, òun tilẹ̀ jí òkú dìde. (Johannu 11:43, 44) Àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí jẹ́ òkodoro òtítọ́ ìtàn tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dáradára. Àní àwọn ọ̀tá Jesu pàápàá gbà pé ó “ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì.”—Johannu 11:47, 48.
17 Jesu rìnrìn-àjò jákèjádò ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀, ní kíkọ́ àwọn ènìyàn nípa Ìjọba Ọlọrun. (Matteu 4:17) Ó tún fi àpẹẹrẹ tí tayọ lélẹ̀ nínú sùúrù àti ìfòyebánilò. Àní nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ já a kulẹ̀, ó fi tẹ̀dùn tẹ̀dùn wí pé: “Nítòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣugbọn ẹran-ara ṣe aláìlera.” (Marku 14:37, 38) Síbẹ̀, Jesu jẹ́ onígboyà kì í sì í fi ọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n fojú tẹ́ḿbẹ́lú òtítọ́ tí wọ́n sì ń ni àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́ lára. (Matteu 23:27-33) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ṣàfarawé àpẹẹrẹ ìfẹ́ ti Bàbá rẹ̀ láìkùsíbìkan. Jesu tilẹ̀ tún múratán láti kú kí aráyé aláìpé baà lè ní ìrètí fún ọjọ́-ọ̀la. Nígbà náà, kò yanilẹ́nu, pé pẹ̀lú ẹ̀tọ́, a lè tọ́ka sí Jesu bíi kọ́kọ́rọ́ náà sí ìmọ̀ Ọlọrun! Bẹ́ẹ̀ni, òun ni kọ́kọ́rọ́ tí ń bẹ láàyè náà! Ṣùgbọ́n èéṣe tí a fi sọ pé kọ́kọ́rọ́ tí ń bẹ láàyè? Èyí mú wa dé orí ìpele kẹta ti ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀.
JESU LÓNÌÍ
18. Àwòrán wo ni ó yẹ kí a ní nínú ọkàn wa nípa Jesu Kristi lónìí?
18 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bibeli ròyìn nípa ikú Jesu, ó wàláàyè nísinsìnyí! Níti tòótọ́, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn tí wọ́n wàláàyè ní ọ̀rúndún kìn-ínní C.E. jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí òtítọ́ náà pé ó ti jíǹde. (1 Korinti 15:3-8) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀, lẹ́yìn náà ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀, ó sì ń dúró láti gba agbára ìjọba ní ọ̀run. (Orin Dafidi 110:1; Heberu 10:12, 13) Nítorí náà àwòrán wo ni ó yẹ kí a ní nípa Jesu lónìí? Ó ha yẹ kí a ronú nípa rẹ̀ bí aláìlólùgbèjà ọmọ-ọwọ́ kan tí ó wà ní ibùjẹ-ẹran? Tàbí bí òjìyà ọkùnrin kan tí ń kú lọ? Rárá. Ó jẹ́ Ọba alágbára, tí ń jọba! Láìpẹ́ sí ìsinsìnyí, yóò fi agbára ìṣàkóso rẹ̀ hàn lórí ilẹ̀-ayé wa ti wàhálà ti débá.
19. Ìgbésẹ̀ wo ni Jesu yóò gbé ní ọjọ́-ọ̀la tí kò jìnnà mọ́?
19 Nínú Ìṣípayá 19:11-15, Ọba náà Jesu Kristi ni a ṣàpèjúwe ní kedere pé ó ń bọ̀ pẹ̀lú agbára ńlá láti pa àwọn olùṣe burúkú run. Ẹ wo bí Alákòóso ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yìí ti ń háragàgà láti fòpin sí ìjìyà tí ń pọ́n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ aráyé lójú lónìí! Ó sì tún ń háragàgà bákan náà láti ran àwọn wọnnì tí wọ́n ń làkàkà láti ṣàfarawé àpẹẹrẹ pípé tí ó fi lélẹ̀ nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé lọ́wọ́. (1 Peteru 2:21) Ó ń fẹ́ láti dáàbòbò wọ́n la “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olódùmarè,” tí a sábà máa ń pè ní Armageddoni tí ń yára kánkán bọ̀ já, kí wọ́n baà lè wàláàyè títí láé bí àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọrun ti ọ̀run lórí ilẹ̀-ayé.—Ìṣípayá 7:9, 14; 16:14, 16.
20. Kí ni Jesu yóò ṣe fún aráyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀?
20 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso alálàáfíà ti Jesu tí a sọtẹ́lẹ̀, òun yóò ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu fún gbogbo aráyé. (Isaiah 9:6, 7; 11:1-10; Ìṣípayá 20:6) Jesu yóò wo gbogbo àìsàn sàn yóò sì fòpin sí ikú. Yóò jí ọ̀pọ̀ billion dìde kí àwọn pẹ̀lú baà lè ní àǹfààní láti gbé lórí ilẹ̀-ayé títí láé. (Johannu 5:28, 29) Yóò ru ìmọ̀lára rẹ sókè láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi nípa Ìjọba Messia rẹ̀ níwájú. Jẹ́ kí èyí dá ọ lójú pé: A kò tilẹ̀ lè fọkàn yàwòrán bí ìgbésí-ayé wa yóò ti jẹ́ àgbàyanu tó lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ Jesu Kristi síi! Bẹ́ẹ̀ni, ó ṣe kókó pé kí a máṣe gbàgbé Jesu, kọ́kọ́rọ́ tí ń bẹ́ láàyè náà sí ìmọ̀ Ọlọrun tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 7 Ìforúkọsílẹ̀ yìí mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe fún Ilẹ̀-Ọba Romu láti fọ̀ranyàn béèrè owó orí. Nítorí ìdí èyí, láìmọ̀ tẹ́lẹ̀ ni Augustu ṣèrànwọ́ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa alákòóso kan tí yóò mú “agbowóòde kan rékọjá nínú ògo ìjọba” ṣẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yẹn sọtẹ́lẹ̀ pé “ọmọ-aládé májẹ̀mú,” tàbí Messia, ni a óò ‘fọ́ túútúú’ ní ọjọ́ ẹni tí yóò gbapò alákòóso yìí. Wọ́n pa Jesu lákòókò ìṣàkóso Tiberiu, ẹni tí ó gbapò Augustu.—Danieli 11:20-22.
^ ìpínrọ̀ 8 Àwọn Júù ìgbàanì ní gbogbogbòò ń ronú nípa àwọn ọ̀sẹ̀ ti àwọn ọdún. Fún àpẹẹrẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọjọ́ keje ti jẹ́ ọjọ́ Sábáàtì, gbogbo ọdún keje jẹ́ ọdún Sábáàtì.—Eksodu 20:8-11; 23:10, 11.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Báwo ni ìlà ìran Jesu ṣe ṣètìlẹyìn fún ìjẹ́wọ́ rẹ̀ pé òun ni Messia náà?
Kí ni díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Messia tí ó ní ìmúṣẹ nínú Jesu?
Báwo ni Ọlọrun ní tààràtà ṣe fi hàn pé Jesu ni Ẹni Àmì Òróró òun?
Èéṣe tí Jesu fi jẹ́ kọ́kọ́rọ́ tí ń bẹ láàyè sí ìmọ̀ Ọlọrun?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 37]
ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ DÍẸ̀ TÍTAYỌLỌ́LÁ NÍPA MESSIA
ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÌṢẸ̀LẸ̀ ÌMÚṢẸ
KÙTÙKÙTÙ ÌGBÉSÍ-AYÉ RẸ̀
Isaiah 7:14 Wúńdíá kan ni ó bí i Matteu 1:18-23
Jeremiah 31:15 A pa àwọn ọmọ-ọwọ́ Matteu 2:16-18
lẹ́yìn ìbí rẹ̀
IṢẸ́-ÒJÍṢẸ́ RẸ̀
Isaiah 61:1, 2 Iṣẹ́ tí a rán an láti Luku 4:18-21
ọ̀dọ̀ Ọlọrun
Isaiah 9:1, 2 Iṣẹ́-òjíṣẹ́ mú kí àwọn Matteu 4:13-16
ènìyàn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá
Orin Dafidi 69:9 Ní ìtara fún ilé Jehofa Johannu 2:13-17
Isaiah 53:1 Wọn kò gbà á gbọ́ Johannu 12:37, 38
Sekariah 9:9; Wíwọ Jerusalemu lórí Matteu 21:1-9
Orin Dafidi 118:26 agódóńgbó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan;
a kókìkí rẹ̀ bí ọba àti bí ẹni
náà tí ń bọ̀ ní orúkọ Jehofa
DÍDÀ Á ÀTI IKÚ RẸ̀
Orin Dafidi 41:9; Aposteli kan jẹ́ aláìṣòótọ́; Ìṣe 1:15-20
109:8 ó da Jesu a sì fi ẹlòmíràn
rọ́pò rẹ̀ lẹ́yìn náà
Sekariah 11:12 A dà á fún 30 ẹyọ Matteu 26:14, 15
fàdákà
Orin Dafidi 27:12 A lo àwọn ẹlẹ́rìí èké Matteu 26:59-61
lòdì sí i
Orin Dafidi 22:18 A ṣẹ́ kèké lé ẹ̀wù Johannu 19:23, 24
àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀
Isaiah 53:12 A kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ Matteu 27:38
Orin Dafidi 22:7, 8 A kẹ́gàn rẹ̀ nígbà Marku 15:29-32
tí ó ń kú lọ
Orin Dafidi 69:21 A fún un ní ọtí kíkan mu Marku 15:23, 36
Isaiah 53:5; A gún un ní ọ̀kọ̀ Johannu 19:34, 37
Isaiah 53:9 A sin ín pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ Matteu 27:57-60
Orin Dafidi 16:8-11, NW, A jí i dìde kí ó tó rí Ìṣe 2:25-32;
ìdibàjẹ́ àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé Iṣe 13:34-37
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 35]
Ọlọrun fún Jesu ní agbára láti mú àwọn aláìsàn láradá