Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nígbà Tí Ìmọ̀ Ọlọrun Yóò Bo Ilẹ̀-Ayé

Nígbà Tí Ìmọ̀ Ọlọrun Yóò Bo Ilẹ̀-Ayé

Orí 19

Nígbà Tí Ìmọ̀ Ọlọrun Yóò Bo Ilẹ̀-Ayé

1, 2. Báwo ni ìpalára ṣe dé bá ìṣẹ̀dá Jehofa?

KÍ A sọ pé ọ̀gá ayàwòrán kan ṣẹ̀ṣẹ̀ parí àwòrán àfọ̀dàkùn tí ó lẹ́wà kan. Pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ó wò ó bí èyí tí ó dára gidigidi​—⁠àgbà iṣẹ́ ọnà kan! Ṣùgbọ́n ní òru mọ́jú òjòwú abánidíje kan bà á jẹ́. Lọ́nà tí ó lè yéni, èyí fa ìrora jíjinlẹ̀ fún ayàwòrán náà. Ẹ wo bí yóò ti háragàgà tó láti rí i kí a gbé ọ̀bàyéjẹ́ náà jù sí ẹ̀wọ̀n! O sì lè ronúwòye bí ayàwòrán náà yóò ti máa yánhànhàn tó láti rí i kí a mú ohun tí o yà náà padàbọ̀ sí ipò ẹlẹ́wà tí ó wà tẹ́lẹ̀rí.

2 Bí ayàwòrán yẹn, Jehofa ṣẹ̀dá àgbà iṣẹ́ ọnà kan ní mímúra ilẹ̀-ayé yìí sílẹ̀ tí ó sì fi aráyé sínú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó dá ọkùnrin àti obìnrin, ó kéde nípa gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé pé “dáradára ni.” (Genesisi 1:31) Adamu àti Efa jẹ́ àwọn ọmọ Ọlọrun fúnra rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. O fọkàn yàwòrán ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀ kan, tí ó lógo fún wọn. Nítòótọ́, Satani sìn wọ́n lọ sínú ìṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n àgbàyanu ìṣẹ̀dá Ọlọrun kò bàjẹ́ kọjá àtúnṣe.​—⁠Genesisi 3:23, 24; 6:11, 12.

3. Kí ni “ìyè tòótọ́ gidi”?

3 Ọlọrun ti pinnu láti mú àwọn nǹkan tọ́. Ó fẹ́ gidi gan-⁠an láti rí wa tí a ń gbé ní ọ̀nà náà tí òun pète rẹ̀ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ìwàláàyè wa onígbà kúkúrú tí ó sì kún fún ìjàngbọ̀n kì í ṣe “ìyè tòótọ́ gidi,” nítorí ó rẹlẹ̀ lọ́lá gidi gan-⁠an sí ohun tí Jehofa ní lọ́kàn. “Ìyè tòótọ́ gidi” tí Ọlọrun fẹ́ fún wa jẹ́ “ìyè àìnípẹ̀kun” lábẹ́ àwọn ipò pípé.​—⁠1 Timoteu 6:​12, 19.

4, 5. (a) Báwo ni a ṣe mú ìrètí Paradise ṣẹ? (b) Èéṣe tí ó fi yẹ kí a ronú nípa ìrètí wa fún ọjọ́-ọ̀la?

4 Ìmọ̀ Ọlọrun mú ẹrù-iṣẹ́ wá níwájú Jehofa. (Jakọbu 4:17) Ṣùgbọ́n ronú nípa àwọn ìbùkún tí ìwọ yóò gbádùn bí o bá fi ìmọ̀ yẹn sílò tí o sì nàgà fún ìyè àìnípẹ̀kun. Nínú Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jehofa Ọlọrun ti ya àwòrán ẹlẹ́wà kan nípa bí ìgbésí-ayé yóò ti rí nínú Paradise ilẹ̀-ayé tí ó ti súnmọ́lé pẹ́kípẹ́kí. Níti gidi, bí àwọn ènìyàn Jehofa, a kò sin Ọlọrun kìkì nítorí ìfẹ́ ọkàn láti gba èrè. A ń sin Ọlọrun nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Marku 12:​29, 30) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a kò ṣiṣẹ́ jèrè ìwàláàyè nípa sísin Jehofa. Ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọrun. (Romu 6:23) Yóò ṣe wá láǹfààní bí a bá ronú lórí irú ìgbésí-ayé kan bẹ́ẹ̀ nítorí ìrètí Paradise ń rán wa létí irú Ọlọrun tí Jehofa jẹ́​—⁠“olùsẹ̀san” onífẹ̀ẹ́ “fún awọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.” (Heberu 11:6) Ìrètí kan tí ń rànyòò nínú èrò-inú àti ọkàn-àyà wa yóò ràn wá lọ́wọ́ láti farada àwọn ìnira nínú ayé Satani.​—⁠Jeremiah 23:20.

5 Nísinsìnyí jẹ́ kí a pọkànpọ̀ sórí ìrètí tí a gbékarí Bibeli nípa ìyè àìnípẹ̀kun nínú Paradise ọjọ́-ọ̀la lórí ilẹ̀-ayé. Báwo ni ìwàláàyè yóò ti rí nígbà tí ìmọ̀ Ọlọrun bá bo ilẹ̀-ayé?

LẸ́YÌN ARMAGEDDONI—PARADISE ILẸ̀-AYÉ KAN

6. Kí ni Armageddoni, kí ni yóò sì túmọ̀ sí fún aráyé?

6 Bí a ti fi hàn ní ìṣáájú, Jehofa Ọlọrun yóò pa ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí run láìpẹ́. Ayé ń yára kánkán súnmọ́ ohun tí Bibeli pè ní Har–Magedoni, tàbí Armageddoni. Ọ̀rọ̀ yẹn lè mú kí àwọn ènìyàn kan ronú nípa ogun apanirundeérú alágbára átọ́míìkì tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń jagun ṣokùnfà rẹ̀, ṣùgbọ́n Armageddoni kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Bí Ìṣípayá 16:​14-⁠16 ti fi hàn, Armageddoni jẹ́ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olódùmarè.” Ó jẹ́ ogun kan tí ó kan “awọn ọba gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá,” tàbí àwọn orílẹ̀-èdè. Ọmọkùnrin Jehofa Ọlọrun, Ọba tí a yànsípò, yóò gẹṣin lọ sínú ìjà-ogun láìpẹ́. Àbájáde rẹ̀ dájú láìní iyèméjì. Gbogbo àwọn tí wọ́n tako Ìjọba Ọlọrun tí wọ́n sì jẹ́ apá kan ètò-ìgbékalẹ̀ búburú Satani ni a óò mú kúrò láìpẹ́. Kìkì àwọn tí wọ́n dúróṣinṣin ti Jehofa ni yóò làájá.​—⁠Ìṣípayá 7:9, 14; 19:11-⁠21.

7. Níbo ni Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ yóò wà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, báwo ni èyí yóò sì ṣe ṣàǹfààní fún aráyé?

7 Ronúwòye pé ìwọ la ìjábá òjijì yẹn já. Báwo ni ìgbésí-ayé yóò ti rí lórí ilẹ̀-ayé nínú ayé titun tí Ọlọrun ṣèlérí? (2 Peteru 3:13) Kò sídìí láti méfò, nítorí Bibeli sọ fún wa, ohun tí ó sì sọ ń rùmọ̀lára ẹni sókè. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a óò gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn, a óò fi wọ́n sẹ́wọ̀n nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ti àìlèṣiṣẹ́mọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jesu Kristi. Àwọn ẹ̀dá búburú, onínú-burúkú wọnnì kì yóò tún sí mọ́ láé láti máa lúgọ sẹ́yìn ìran, láti dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ kí wọ́n sì gbìyànjú láti sún wa sínú àwọn ìṣe àìṣòótọ́ lòdì sí Ọlọrun. Ìtura kan mà ni èyí o!​—⁠Ìṣípayá 20:​1-⁠3.

8, 9. Nínú ayé titun, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ìpọ́nnilójú, àìlera, àti ọjọ́ ogbó?

8 Ní àkókò rẹ̀, gbogbo onírúurú àìsàn yóò pòórá. (Isaiah 33:24) Nígbà náà arọ yóò dìde dúró, yóò rìn, yóò sáré, yóò sì jó lórí àwọn ẹsẹ̀ tí ó lera tí ó sì lágbára. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún ìgbésí-ayé láìlè gbọ́ ohunkóhun, àwọn adití yóò gbọ́ àwọn ìró onídùnnú-ayọ̀ tí ó wà yí wọn ká. Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ yóò bo àwọn afọ́jú bí ayé kan tí ó kún fún ẹwà níti àwọ̀ àti ìrísí ti ń di òtítọ́ ní ojú wọn. (Isaiah 35:​5, 6) Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, wọn yóò rí ojú àwọn olólùfẹ́ wọn! Bóyá nígbà náà agbára ìríran wọn kì yóò ríran rekete fún ìgbà díẹ̀ nítorí omijé ìdùnnú-ayọ̀.

9 Wulẹ̀ rò ó wò ná! Kò sí awò ojú mọ́, kò sí ọ̀pá ìtilẹ̀ mọ́, kò sí egbòogi mọ́, kò sí àwọn ilé-ìtọ́jú eyín tàbí ilé-ìwòsàn mọ́! Àìlera èrò-ìmọ̀lára àti ìsoríkọ́ kì yóò tún du àwọn ènìyàn ní ayọ̀ mọ́ láé. Òkùnrùn kì yóò pani ní rèwerèwe mọ́. Ọṣẹ́ tí ọjọ́ ogbó ń ṣe ni a óò ti yípadà. (Jobu 33:25) A óò ní ìlera àti okun sí i. Lóròòwúrọ̀ a óò dìde láti inú oorun alẹ́ tí ó tunilára pẹ̀lú okun tí a sọdọ̀tun, tí ó kún fún okunra tí a sì ń háragàgà fún ọjọ́ titun ti ìwàláàyè tí ó jípépé àti iṣẹ́ tí ń tẹ́nilọ́rùn.

10. Iṣẹ́ àyànfúnni wo ni àwọn olùla Armageddoni já yóò ṣe?

10 Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí ó gbádùnmọ́ni yóò wà fún àwọn olùla Armageddoni já láti ṣe. Wọ́n yóò yí ilẹ̀-ayé yìí padà di paradise kan. Ìràlẹ̀rálẹ̀ èyíkéyìí ti ètò-ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó tí ó léèérí ni a óò ti gbá kúrò. Àwọn ọgbà ìtura àti àwọn ọgbà-ọ̀gbìn yóò rúyọ ní ipò àwọn àdúgbò onílé ẹgẹrẹmìtì àti ilẹ̀ tí a bàjẹ́. Gbogbo ènìyàn yóò gbádùn ilé tí ó tura tí ó sì lẹ́wà. (Isaiah 65:21) Bí àkókò ti ń lọ, apá ilẹ̀-ayé tí ó ti rí bíi ti paradise yóò gbèrú yóò sì dàpọ̀ títí gbogbo àgbáyé yóò fi dé ìwọ̀n ẹwà tí Ẹlẹ́dàá náà gbékalẹ̀ lẹ́yìn lọ́hùn-⁠ún ní ọgbà-ọ̀gbìn Edeni. Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti tẹ́nilọ́rùn tó láti nípìn-⁠ín nínú iṣẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò yẹn!

11. Ìbáṣepọ̀ ọjọ́-ọ̀la wo ni aráyé yóò ní pẹ̀lú àyíká ilẹ̀-ayé àti ìwàláàyè àwọn ẹranko?

11 Gbogbo èyí ni a óò ṣe lábẹ́ ìdarísọ́nà àtọ̀runwá kí ìpalára kankan má baà ṣẹlẹ̀ sí àyíká. Ẹ̀dá ènìyàn yóò wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹranko. Dípò pípa wọn ní ìpakúpa, ènìyàn yóò tún bẹ̀rẹ̀ ẹrù-iṣẹ́ iṣẹ́ ìríjú rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, ní ṣíṣàbójútó wọn lọ́nà dídára. Finúyàwòrán ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùtàn, kìnnìún àti ọmọ ewúrẹ́, tí wọ́n jùmọ̀ ń jẹun​—⁠àwọn ẹran àgbéléjẹ̀ sì wà láìséwu pátápátá. Àní ọmọ kékeré pàápàá kì yóò ní ohunkóhun láti bẹ̀rù lára àwọn ẹranko ẹhànnà, àwọn ìkà, òǹrorò ènìyàn kì yóò sì sí níbẹ̀ láti dí ìtòròmini ayé titun lọ́wọ́. (Isaiah 11:​6-⁠8) Ayé titun alálàáfíà ni ìyẹn yóò mà jẹ́ o!

A PA ARÁYÉ DÀ

12. Báwo ni Isaiah 11:9 ṣe ń ní ìmúṣẹ lónìí, báwo ni yóò sì ṣe ní ìmúṣẹ nínú Paradise?

12 Isaiah 11:9 sọ ìdí rẹ̀ tí kì yóò fi sí ìpalára kankan ní gbogbo ilẹ̀-ayé fún wa. Ó sọ pé: “Ayé yóò kún fún ìmọ̀ Oluwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.” Èyí kan àwọn ènìyàn nítorí pé àwọn ẹranko kò lè gba “ìmọ̀ Oluwa” kí wọ́n sì ṣe ìyípadà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìtẹ̀sí ìwà àdánidá ni ó ń darí wọn. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ Ẹlẹ́dàá wa ń yí àwọn ènìyàn padà. Láìṣiyèméjì ìwọ ti ṣe àwọn ìyípadà kan fúnra rẹ nítorí o fi ìmọ̀ Ọlọrun sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀ síí ní ìmúṣẹ ní báyìí ná lórí àwọn wọnnì tí wọ́n ń sin Jehofa. Síbẹ̀, ó tún tọ́ka sí àkókò kan nígbà tí àwọn ènìyàn yíká ayé yóò bọ́ ànímọ́ ìwà ẹranko tàbí oníwà-ipá sílẹ̀ tí wọn yóò sì di ẹni àlàáfíà títí láé.

13. Ètò ìmọ̀-ẹ̀kọ́ wo ni yóò wáyé lórí ilẹ̀-ayé?

13 Ẹ wo bí yóò ti kọyọyọ tó nígbà tí ìmọ̀ Ọlọrun bá bo ilẹ̀-ayé! Ètò ìmọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó gbòòrò yóò wà lábẹ́ ìdarísọ́nà Ọba náà Jesu Kristi àti àwọn 144,000 alájùmọ̀ṣàkóso rẹ̀. “Awọn àkájọ ìwé” titun ni a óò wá bẹ̀rẹ̀ síí lò. Ó dàbí ẹni pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìtọ́ni Ọlọrun tí a kọ sílẹ̀ tí yóò ṣiṣẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún kíkọ́ àwọn olùgbé ilẹ̀-ayé. (Ìṣípayá 20:12) Aráyé yóò kọ́ àlàáfíà, kì í ṣe ogun. Gbogbo àwọn ohun ìjà aṣèparun yóò ti wábi gbà. (Orin Dafidi 46:9) Àwọn olùgbé inú ayé titun náà ni a óò kọ́ láti bá àwọn ẹ̀dá-ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lò pẹ̀lú ìfẹ́, ọ̀wọ̀, àti iyì-ọlá.

14. Báwo ni ayé yóò ṣe yàtọ̀ nígbà tí aráyé bá di ìdílé kan tí ó sopọ̀ṣọ̀kan?

14 Aráyé yóò di ìdílé kanṣoṣo tí ó wà ní ìṣọ̀kan. Kì yóò sí ìdènà kankan sí ìṣọ̀kan àti àjọṣepọ̀. (Orin Dafidi 133:​1-⁠3) Kò sí ilé ẹnì kankan tí a óò tìpa láti dènà àwọn olè. Àlàáfíà yóò jọba ní ọkàn-àyà olúkúlùkù, ní gbogbo ilé, ní gbogbo apá ilẹ̀-ayé.​—⁠Mika 4:4.

ÀJÍǸDE ONÍDÙNNÚ-AYỌ̀

15. Àwùjọ méjì wo ni a óò jí dìde sórí ilẹ̀-ayé?

15 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn, àjíǹde yóò wáyé. Àwọn wọnnì tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀, nípa gbígbégbèésẹ̀ láìronúpìwàdà ní ìlòdì sí ìfarahàn tàbí ìdarísọ́nà rẹ̀ ni a kì yóò jí dìde. (Matteu 23:​15, 33; Heberu 6:​4-⁠6) Dájúdájú, Ọlọrun yóò pinnu ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà yẹn. Ṣùgbọ́n àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yóò ní àjíǹde​—⁠“awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo.” (Ìṣe 24:15) Níwọ̀n bí ètò tí ó gbéṣẹ́ yóò ti wà, ó bọ́gbọ́nmu láti parí èrò pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí a óò kí káàbọ̀ sí ìyè lórí ilẹ̀-ayé yóò jẹ́ àwọn olódodo, àwọn wọnnì tí wọ́n sin Jehofa pẹ̀lú ìdúróṣinṣin.​—⁠Heberu 11:​35-⁠39.

16. (a) Àwọn wo ni yóò wà lára “àwọn olódodo” tí a jí dìde sórí ilẹ̀-ayé? (b) Èwo ní pàtàkì lára àwọn olùṣòtítọ́ ìgbàanì ni o fẹ́ láti pàdé, èésìtiṣe?

16 Dípò kí a máa gbọ́ ìròyìn nípa ogun, ìjábá, àti ikú, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa yóò gba àwọn àgbàyanu ìròyìn nípa àjíǹde. Yóò ru ìmọ̀lára ẹni sókè láti kọ́ nípa ìpadàbọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ bí Abeli, Enoku, Noa, Abrahamu, Sara, Jobu, Mose, Rahabu, Rutu, Dafidi, Elija, Esteri. Ẹ sì wo àwọn òtítọ́ ìtàn tí ń runilọ́kàn sókè tí wọn yóò pèsè bí wọ́n ti ń fún wa ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìpìlẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ìròyìn inú Bibeli! Kò sí iyèméjì pé àwọn àti àwọn olódodo tí wọ́n ti kú ní ẹnu àìpẹ́ yìí yóò túbọ̀ háragàgà láti kọ́ nípa òpin ètò-ìgbékalẹ̀ Satani àti bí Jehofa ṣe ya orúkọ mímọ́ rẹ̀ sí mímọ́ tí ó sì dá ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ láre.

17. Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn olùṣòtítọ́ yóò fún àwọn tí a jí dìde?

17 Ẹ wo ìrànlọ́wọ́ tí àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí yóò jẹ́ nígbà ìpele àjíǹde tí ó kàn, nígbà tí a bá tú ọ̀pọ̀ billion “awọn aláìṣòdodo” sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìdè ikú! Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú aráyé ni kò fìgbàkan ní àyè láti mọ Jehofa. Satani ti ‘fọ́ èrò-inú wọn.’ (2 Korinti 4:4) Ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ Èṣù ni a óò sọ dòfo. Àwọn aláìṣòdodo yóò padà wá sínú ilẹ̀-ayé ẹlẹ́wà tí ó lálàáfíà. Àwọn ènìyàn tí yóò kí wọn káàbọ̀ yóò jẹ́ àwọn tí a ti ṣètò dáradára láti kọ́ wọn nípa Jehofa àti Jesu Kristi, Ọmọkùnrin rẹ̀ tí ń ṣàkóso. Bí ọ̀pọ̀ billion tí a jí dìde ti wá mọ Ẹlẹ́dàá wọn tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìmọ̀ Jehofa yóò bo ilẹ̀-ayé ní ọ̀nà kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí.

18. Báwo ni o ṣe rò pé ìwọ yóò nímọ̀lára nígbà tí o bá ń kí àwọn olólùfẹ́ tí a jí dìde káàbọ̀?

18 Ẹ wo ìdùnnú-ayọ̀ tí àjíǹde yóò mú wá sí ọkàn-àyà wa! Ta ni kò ti jìyà nítorí ọ̀tá wa ikú? Nítòótọ́, ta ni kò ti nímọ̀lára ìjákulẹ̀ tí ó burú jáì nígbà tí ìdè ìfẹ́ tàbí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bá já bí àìsàn, ọjọ́ ogbó, ìjàm̀bá, tàbí ìwà-ipá ti ń mú olólùfẹ́ ẹni lọ? Nígbà náà, ronúwòye ìdùnnú-ayọ̀ ìrẹ́pọ̀ lẹ́ẹ̀kan síi nínú Paradise. Àwọn màmá àti bàbá, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ọ̀rẹ́ àti ìbátan, yóò gbá ara wọn mú, pẹ̀lú ẹ̀rín àti omijé ìdùnnú-ayọ̀.

ÌJẸ́PÍPÉ NÍGBẸ̀YÌN GBẸ́YÍN!

19. Iṣẹ́ ìyanu wo ni yóò wáyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún?

19 Jálẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún, àgbàyanu iṣẹ́ ìyanu kan yóò máa ṣẹlẹ̀. Fún aráyé, bóyá yóò jẹ́ apá tí ń runilọ́kàn sókè jùlọ ti Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Jehofa yóò darí Ọmọkùnrin rẹ̀ lati fi àǹfààní ẹbọ ìràpadà náà sílò fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù olùṣòtítọ́ ọkùnrin àti obìnrin onígbọràn. Ní ọ̀nà yẹn, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ní a óò mú kúrò tí a óò sì gbé aráyé dìde sí ìjẹ́pípé.​—⁠1 Johannu 2:⁠2; Ìṣípayá 21:​1-⁠4.

20. (a) Kí ni yóò túmọ̀ sí láti di pípé? (b) Nígbà wo ni àwọn olùla Armageddoni já àti àwọn tí a jí dìde yóò bẹ̀rẹ̀ síí gbé ìgbésí-ayé ní èrò-ìtumọ̀ tí ó kún rẹ́rẹ́?

20 Ìjẹ́pípé! Kí ni ìyẹn yóò túmọ̀ sí? Yóò túmọ̀ sí pípadà sínú irú ìgbésí-ayé tí Adamu àti Efa gbádùn ṣáájú kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀ lòdì sí Jehofa Ọlọrun. Níti ara ìyára, èrò-orí, èrò ìmọ̀lára, ìwàrere, nípa tẹ̀mí​—⁠ní gbogbo ọ̀nà tí ó ṣeé ronú kàn⁠—​àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé yóò kúnjú àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun ní kíkún. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn nígbà náà yóò ha rí bákan náà bí? Àgbẹdọ̀! Àwọn ìṣẹ̀dá Jehofa​—⁠igi, òdòdó, ẹranko⁠—​gbogbo ìwọ̀nyí kọ́ wa pé ó nífẹ̀ẹ́ onírúurú. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé yóò ní oríṣiríṣi ànímọ́ àti agbára ìṣe. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò gbádùn ìwàláàyè bí Ọlọrun ti pète pé kí ó rí. Ìṣípayá 20:5 sọ pé: “Ìyókù awọn òkú kò wá sí ìyè títí ẹgbẹ̀rún ọdún naa fi dópin.” Bí ogunlọ́gọ̀ ńlá tí yóò la Armageddoni já, àwọn tí a jíǹde yóò wá sí ìyè pátápátá nígbà tí wọ́n bá dé ìjẹ́pípé aláìlẹ́ṣẹ̀.

21. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi? (b) Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Satani àti gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣètìlẹyìn fún un?

21 Àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé yóò dojúkọ àdánwò ìkẹyìn kan. Ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a óò túsílẹ̀ láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún àkókò kúkúrú a óò sì yọ̀ǹda fún wọn láti ṣe ìsapá ìkẹyìn láti yí àwọn ènìyàn padà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa. Àwọn kan yóò fi ìfẹ́ ọkàn àìtọ́ ṣáájú ìfẹ́ fún Ọlọrun, ṣùgbọ́n ìṣọ̀tẹ̀ yìí ni a óò ké kúrú. Jehofa yóò pa àwọn onímọtara-ẹni nìkan wọ̀nyí papọ̀ pẹ̀lú Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀. Gbogbo àwọn oníwà-àìtọ́ wọ̀nyí kì yóò sí mọ́ títí láé nígbà náà.​—⁠Ìṣípayá 20:​7-⁠10.

KÍ NI ÌWỌ YÓÒ ṢE?

22. Kí ni o ń fojúsọ́nà láti ṣe nínú Paradise?

22 Ayérayé yóò nà gbòòrò níwájú àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun tí wọ́n sì ń gbé nínú Paradise ilẹ̀-ayé. Ekukáká ni a lè fi ronúwòye ìdùnnú-ayọ̀ wọn, ìwọ pẹ̀lú sì lè nípìn-⁠ín nínú èyí. Ohùn-orin, ọgbọ́n-ọnà, iṣẹ́-ọnà​—⁠họ́wù, àṣeyọrí pípé ti aráyé yóò rékọjá iṣẹ́ tí ó dára jùlọ ti àwọn lọ́gàálọ́gàá nínú ayé ògbólógbòó! Ó ṣetán, ẹ̀dá ènìyàn yóò di pípé àkókò tí kì yóò láàlà yóò sì wà níwájú wọn. Ronúwòye ohun tí ìwọ yóò lè ṣe bí ẹ̀dá ènìyàn pípé kan. Ronú, pẹ̀lú, nípa ohun tí ìwọ àti àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ yóò kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá Jehofa​—⁠láti ọ̀pọ̀ billion àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ní àgbáyé títí dé egunrín ohun alààyè tín-⁠íntìn-⁠ìntín tí ó kéré jùlọ. Ohunkóhun tí aráyé bá tún ṣàṣeyọrí rẹ̀ yóò tún mú inúdídùn wá sí ọkàn-àyà Jehofa, Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́.​—⁠Orin Dafidi 150:​1-⁠6.

23. Èéṣe tí ìgbésí-ayé nínú Paradise kì yóò fi súni láé?

23 Nígbà náà ìgbésí-ayé kì yóò súni mọ́. Yóò máa fanilọ́kànmọ́ra síi bí àkókò ti ń lọ. Ṣe o rí i, ìmọ̀ Ọlọrun kò ní òpin. (Romu 11:33) Jálẹ̀jálẹ̀ ayérayé, nígbà gbogbo ni ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan yóò wà láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àti àwọn ìdáwọ́lé titun láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀. (Oniwasu 3:11) Bí o sì ti ń bá a lọ láti kọ́ nípa Jehofa Ọlọrun, ìwọ yóò máa bá a lọ láti wàláàyè​—⁠kì í ṣe fún kìkì ọdún díẹ̀ ṣùgbọ́n títí láé!​—⁠Orin Dafidi 22:26.

24, 25. Èéṣe tí ó fi yẹ fún ọ nísinsìnyí láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọrun?

24 Ọjọ́-ọ̀la tí ó kún fún inúdídùn kò ha yẹ fún ìsapá èyíkéyìí tàbí ìrúbọ tí o bá lè ṣe? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Tóò, Jehofa ti nawọ́ kọ́kọ́rọ́ sí ọjọ́-ọ̀la ológo-ẹwà yẹn sí ọ. Kọ́kọ́rọ́ yẹn ni ìmọ̀ Ọlọrun. Ìwọ yóò ha lò ó bí?

25 Bí o bá nífẹ̀ẹ́ Jehofa, ìwọ yóò ní inúdídùn nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. (1 Johannu 5:3) Bí o ti ń lépa ipa-ọ̀nà yẹn, wo irú ìbùkún tí iwọ yóò nírìírí rẹ̀! Bí o ba fi ìmọ̀ Ọlọrun sílò, ó lè fún ọ ní ìgbésí-ayé aláyọ̀ àní nínú ayé oníṣòro yìí. Àwọn èrè-ẹ̀san ọjọ́-ọ̀la sì pọ̀ jọjọ, nítorí èyí jẹ́ ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun! Ìsinsìnyí ni àkókò tí ó wọ̀ fún ọ láti gbégbèésẹ̀. Pinnu láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọrun. Fi ìfẹ́ rẹ fún Jehofa hàn. Bọlá fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ kí o sì fi Satani hàn ní òpùrọ́. Lẹ́yìn náà, Jehofa Ọlọrun, Orísun ọgbọ́n àti ìmọ̀ tòótọ́, yóò yọ̀ nítorí rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ títóbilọ́lá àti onífẹ̀ẹ́. (Jeremiah 31:⁠3; Sefaniah 3:17) Yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ títí láé!

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Kí ni “ìyè tòótọ́ gidi”?

Lẹ́yìn Armageddoni, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé?

Àwọn wo ni a óò jí dìde sórí ilẹ̀-ayé?

Báwo ni aráyé ṣe lè di pípé kí a sì dán wọn wò nígbẹ̀yìn gbẹ́yín?

Kí ni ìrètí rẹ nípa Paradise?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 188, 189]

O ha nírètí láti gbé nínú Paradise, nígbà tí ìmọ̀ Ọlọrun yóò bo ilẹ̀-ayé bí?