Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Ní Ọjọ́-Ọ̀la Aláyọ̀!

O Lè Ní Ọjọ́-Ọ̀la Aláyọ̀!

Orí 1

O Lè Ní Ọjọ́-Ọ̀la Aláyọ̀!

1, 2. Kí ni ohun tí Ẹlẹ́dàá rẹ fẹ́ fún ọ?

ÌFỌWỌ́GBÁNIMỌ́RA tọ̀yàyà tọ̀yàyà láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan tí o nífẹ̀ẹ́. Kẹ̀búyẹrì ẹ̀rín lákòókò oúnjẹ aládùn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n. Adùn tí ó wà nínú wíwo àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n ń yọ̀ ṣìnkìn bí wọ́n ti ń ṣeré. Àwọn àkókò bí ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn àkókò aláyọ̀ nínú ìgbésí-ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó jọ pé ìgbésí-ayé ń gbé ìṣòro kan tí ó wúwo dìde tẹ̀lé òmíràn. Bí ìyẹn bá ti jẹ́ ìrírí rẹ, mọ́kànle.

2 Ìfẹ́-inú Ọlọrun ni pé kí o gbádùn ayọ̀ pípẹ́ títí lábẹ́ àwọn ipò tí ó dára jùlọ ní àwọn àyíká tí ó mìnrìngìndìn. Èyí kì í ṣe àlá lásán, nítorí pé Ọlọrun nawọ́ kọ́kọ́rọ́ sí irú ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ọ níti gidi. Ìmọ̀ ni kọ́kọ́rọ́ yẹn.

3. Ìmọ̀ wo ni ó jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí ayọ̀, èésìtiṣe tí ó fi lè dá wa lójú pé Ọlọrun lè pèsè ìmọ̀ yẹn?

3 A ń sọ̀rọ̀ nípa irú àkànṣe ìmọ̀ kan tí ó ga ju ọgbọ́n ẹ̀dá-ènìyàn lọ fíìfíì. “Ìmọ̀ Ọlọrun” ni. (Owe 2:5) Ní nǹkan bíi 2,000 ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé Bibeli kan sọ pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ lati ọwọ́ ẹni kan, ṣugbọn ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.” (Heberu 3:4) Ronú nípa ìmọ̀ tí Olùṣe gbogbo àwọn nǹkan gbọ́dọ̀ ní! Bibeli sọ pé Ọlọrun ka gbogbo àwọn ìràwọ̀ ó sì sọ wọ́n ní orúkọ. Ìyẹn jẹ́ èrò tí ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún billion àwọn ìràwọ̀ ni ó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tiwa, àwọn onímọ̀ sánmà sì sọ pé nǹkan bí ọgọ́rùn-⁠ún billion kan àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ mìíràn ni ó wà! (Orin Dafidi 147:4) Ọlọrun tún mọ ohun gbogbo nípa wa, nítorí náà, ta ni ó tún lè pèsè àwọn ìdáhùn tí ó sàn jù sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí-ayé?​—⁠Matteu 10:30.

4. Èéṣe tí a fi lè retí pé kí Ọlọrun pèsè ìtọ́ni láti tọ́ wa sọ́nà, ìwé wo ni ó sì kájú àìní yìí?

4 Finú yàwòrán àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ń gbìyànjú láti tún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn ṣe. Bí ìjákulẹ̀ ti bá ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin náà, ó da àwọn irin-iṣẹ́ rẹ̀ nù. Èkejì fi pẹ̀lẹ́tù yanjú ìṣòro náà, ó ṣíná ọkọ̀, ó bú sẹ́rìn-⁠ín bí ẹ́ńjìnnì náà ti dáhùn tí ó sì ń lọ geerege. Kò lè ṣòro fún ọ láti méfò èwo nínú àwọn ọkùnrin méjì náà ni ó ní ìwé ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣe mọ́tò náà. Kò ha bọ́gbọ́nmu pé Ọlọrun yóò pèsè àwọn ìtọ́ni láti tọ́ wa sọ́nà nínú ìgbésí-ayé bí? Bí o ti lè mọ̀, Bibeli sọ pé òun jẹ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́​—⁠ìwé ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa, tí a ṣètò láti fún wa ní ìmọ̀ Ọlọrun.​—⁠2 Timoteu 3:16.

5. Báwo ni ìmọ̀ tí ó wà nínú Bibeli ti níyelórí tó?

5 Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni ohun tí Bibeli sọ, wulẹ̀ ronú nípa àká ìmọ̀ tí ìwé yẹn yóò ní! Nínú Owe 2:​1-⁠5, ó rọ̀ wá láti wá ọgbọ́n, láti walẹ̀ fún un bí a óò ti ṣe fún ìṣúra tí a fi pamọ́​—⁠kì í ṣe nínú ilẹ̀ ìrònú ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnra rẹ̀. Bí a bá wá ibẹ̀, a óò “rí ìmọ̀ Ọlọrun.” Níwọ̀n bí Ọlọrun ti lóye ààlà àti àwọn àìní wa, ó ń fún wa ní ìtọ́ni tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé alálàáfíà tí ó sì láyọ̀. (Orin Dafidi 103:14; Isaiah 48:17) Síwájú síi, ìmọ̀ Ọlọrun ń fún wa ní ìhìnrere tí ń ru ìmọ̀lára ẹni sókè.

ÌYÈ ÀÌNÍPẸ̀KUN!

6. Ìdánilójú wo ni Jesu Kristi fúnni nípa ìmọ̀ Ọlọrun?

6 Ẹni inú ìtàn tí a mọ̀ bí ẹni mowó náà Jesu Kristi ṣàpèjúwe apá-ẹ̀ka yìí nínú ìmọ̀ Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó ṣe kedere. Ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, ati ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.” (Johannu 17:3) Rò ó wò ná​—⁠ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun!

7. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé Ọlọrun kò pète rẹ̀ pé kí a máa kú?

7 Máṣe yára fọwọ́ rọ́ ìyè àìnípẹ̀kun sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan bí àlá lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, wo ọ̀nà tí a gbà dá ara ẹ̀dá-ènìyàn. A ṣe é lọ́nà ológo ẹwà láti lè mọ ìtọ́wò, kí ó gbọ́ràn, kí ó gbóòórùn, kí ó ríran, kí ó sì nímọ̀lára. Ọ̀pọ̀ ohun ni ó wà lórí ilẹ̀-ayé wa tí ń fa agbára ìmòye wa mọ́ra​—⁠oúnjẹ dídùnyùngbà, orin gbígbádùnmọ́ni ti àwọn ẹyẹ, àwọn òdòdó olóòórùn dídùn, àwọn ohun tí ó rẹwà ní ìrísí, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ onídùnnú! Ọpọlọ wa tí ó jẹ́ kàyéfì àgbàyanu sì ju ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ayára-bí-àṣá lọ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ, nítorí tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti mọrírì kí a sì gbádùn gbogbo irú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. O ha rò pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí a kú kí a sì pàdánù gbogbo èyí bí? Kò ha túbọ̀ bọ́gbọ́nmu láti parí èrò pé òun fẹ́ kí a wà láàyè nínú ayọ̀ kí a sì gbádùn ìwàláàyè títí láé? Tóò, ohun tí ìmọ̀ Ọlọrun lè túmọ̀ sí fún ọ nìyẹn.

ÌWÀLÁÀYÈ NÍNÚ PARADISE

8. Kí ni Bibeli sọ nípa ọjọ́-ọ̀la aráyé?

8 A lè kó ohun tí Bibeli sọ nípa ọjọ́-ọ̀la ilẹ̀-ayé àti aráyé pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan​—⁠Paradise! Jesu Kristi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ fún ọkùnrin kan tí ń kú lọ pé: “Iwọ yoo wà pẹlu mi ní Paradise.” (Luku 23:43) Kò sí iyèméjì pé mímẹ́nukan Paradise mú ipò aláyọ̀ tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Adamu àti Efa wà, wá sí èrò-inú ọkùnrin yẹn. Nígbà tí Ọlọrun dá wọn, wọ́n jẹ́ pípé wọ́n sì ń gbé nínú ọgbà-ìtura tí ó rí bí ọgbà-ọ̀gbìn tí Ẹlẹ́dàá ti ṣètò tí ó sì gbìn. Lọ́nà tí ó tọ́, a pè é ní ọgbà-ọ̀gbìn Edeni, orúkọ náà tí ó tọ́ka sí ìgbádùn.

9. Báwo ni ó ti rí láti gbé nínú Paradise ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà?

9 Ọgbà-ọ̀gbìn tí ó kún fún ìdùnnú ni èyí jẹ́ nítòótọ́! Ó jẹ́ paradise kan níti gidi. Lára àwọn igi ẹlẹ́wà rẹ̀ ni àwọn tí ń so èso dídọ́ṣọ̀. Bí Adamu àti Efa ti ń mọ agbègbè wọn yìí dunjú, tí wọ́n ń mu àwọn omi atura rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣa èso àwọn igi rẹ̀, wọn kò ní ìdí láti ṣàníyàn tàbí bẹ̀rù. Àwọn ẹranko pàápàá kò halẹ̀ mọ́ wọn, nítorí pé Ọlọrun ti fi ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ ṣe alákòóso onífẹ̀ẹ́ lórí gbogbo wọn. Ní àfikún, tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní ìlera tí ó jípépé. Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Ọlọrun, ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀, títí ayé wà ní iwájú wọn. A fún wọn ní iṣẹ́ tí ń tẹ́nilọ́rùn ti bíbójútó ilé Paradise àgbàyanu wọn. Síwájú síi, Ọlọrun fún Adamu ati Efa ni àṣẹ láti ‘gbilẹ̀, kí wọ́n sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.’ Àwọn àti irú-ọmọ wọn níláti mú kí àwọn ààlà ẹnubodè Paradise náà gbòòrò títí gbogbo planẹẹti wa yóò fi di ibi ẹlẹ́wà kan tí ó kún fún ìdùnnú.​—⁠Genesisi 1:28.

10. Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa Paradise, kí ni ohun tí ó ní lọ́kàn?

10 Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí Jesu mẹ́nukan Paradise, kò sọ pé kí ọkùnrin tí ń kú lọ náà ronú nípa àkókò kan tí ó ti kọjá tipẹ́tipẹ́. Rárá o, Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la! Ó mọ̀ pé ilẹ̀-ayé tí ó jẹ́ ilé wa lódindi yóò di paradise kan. Ọlọrun yóò tipa bẹ́ẹ̀ mú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀-ayé wa ṣẹ. (Isaiah 55:​10, 11) Bẹ́ẹ̀ni, a óò mú Paradise padàbọ̀sípò! Báwo ni yóò sì ṣe rí? Jẹ́ kí Bibeli Mímọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, dáhùn.

ÌGBÉSÍ-AYÉ NÍNÚ PARADISE TÍ A MÚ PADÀBỌ̀SÍPÒ

11. Nínú Paradise tí a mú padàbọ̀sípò, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú?

11 Àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú kì yóò tún sí mọ́. “Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò sì ṣí. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò kọrin.” (Isaiah 35:​5, 6) “Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo sì wà pẹlu [aráyé]. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”​—⁠Ìṣípayá 21:​3, 4.

12. Kí ni ìdí tí a fi lè ní ìdánilójú pé nínú Paradise ọjọ́-iwájú kì yóò sí ìwà-ọ̀daràn, ìwà-ipá, àti ìwà burúkú?

12 Ìwà-ọ̀daràn, ìwà-ipá, àti ìwà burúkú yóò kọjá lọ títí láé. “A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò . . . Nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí . . . kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn-tútù ni yóò jogún ayé.” (Orin Dafidi 37:​9-⁠11) “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú ni a óò ké kúrò ní ilẹ̀-ayé, àti àwọn olùrékọjá ni a óò sì fàtu kúrò nínú rẹ̀.”​—⁠Owe 2:22.

13. Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe mú àlàáfíà wá?

13 Àlàáfíà yóò gbilẹ̀ yíká ayé. “Ó [Ọlọrun] mú ọ̀tẹ̀ tán dé òpin ayé; ó ṣẹ ọrun, ó sì ké ọkọ̀ [sí] méjì.” (Orin Dafidi 46:9) “Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀: àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà níwọ̀n bí òṣùpá yóò ti pẹ́ tó.”​—⁠Orin Dafidi 72:7.

14, 15. Kí ni Bibeli sọ nípa ilé gbígbé, iṣẹ́, àti oúnjẹ nínú Paradise tí a mú padàbọ̀sípò?

14 Ilé gbígbé yóò wà ní àìléwu iṣẹ́ yóò sì tẹ́nilọ́rùn. “Wọn óò sì kọ́ ilé, wọn óò sì gbé inú wọn . . . Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn gbé, wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ: nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi rí, àwọn [àyànfẹ́] mi yóò sì jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kì yóò ṣiṣẹ́ lásán, wọn kì yóò bímọ fún wàhálà.”​—⁠Isaiah 65:​21-⁠23.

15 Oúnjẹ tí ń fúnni ní ìlera yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó lọ́pọ̀ yanturu. “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè-ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì.” (Orin Dafidi 72:16) “Nígbà náà ni ilẹ̀ yóò tó máa mú àsunkún rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tìkára rẹ̀ yóò bù sí i fún wa.”​—⁠Orin Dafidi 67:6.

16. Èéṣe tí ìgbésí-ayé nínú Paradise yóò fi kún fún ìdùnnú?

16 Ìyè àìnípẹ̀kun lórí paradise ilẹ̀-ayé yóò kún fún ìdùnnú. “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dafidi 37:29) “Aginjù àti ilẹ̀ gbígbẹ yóò yọ̀ fún wọn; ijù yóò yọ̀, yóò sì tanná bí lílì.”​—⁠Isaiah 35:1.

ÌMỌ̀ ÀTI ỌJỌ́-Ọ̀LA RẸ

17. (a) Kí ni ohun tí ó yẹ kí o ṣe bí ìwàláàyè nínú Paradise bá fà ọ́ mọ́ra? (b) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Ọlọrun yóò mú àwọn ìyípadà ńláǹlà wá lórí ilẹ̀-ayé?

17 Bí ìwàláàyè nínú Paradise bá fà ọ́ mọ́ra, máṣe jẹ́ kí ohunkóhun fà ọ́ sẹ́yìn kúrò nínú jíjèrè ìmọ̀ Ọlọrun. Ó nífẹ̀ẹ́ aráyé yóò sì mú àwọn ìyípadà tí a nílò láti mú kí ilẹ̀-ayé di paradise wá. Ó ṣetán, bí o bá ní agbára láti fòpin sí ìṣẹ́ àti àìṣèdájọ́ òdodo tí ó gbilẹ̀ nínú ayé, ìwọ kì yóò ha ṣé bẹ́ẹ̀ bí? A óò ha retí pé kí Ọlọrun ṣe ohun kan tí ó dínkù bí? Níti gidi, Bibeli sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n nípa àkókò kan nígbà tí Ọlọrun yóò mú ètò-ìgbékalẹ̀ tí gbọ́nmisi-omi-ò-to kún inú rẹ̀ yìí kúrò tí yóò sì fi ìṣàkóso pípé, tí ó jẹ́ ti òdodo pààrọ̀ rẹ̀. (Danieli 2:44) Ṣùgbọ́n Bibeli ṣe púpọ̀ púpọ̀ síi ju pé o sọ gbogbo èyí fún wa. Ó fi hàn wá bí a ṣe lè làájá bọ sínú ayé titun tí Ọlọrun ṣèlérí.​—⁠2 Peteru 3:13; 1 Johannu 2:17.

18. Kí ni ohun tí ìmọ̀ Ọlọrun lè ṣe fún ọ nísinsìnyí?

18 O tún lè jàǹfààní púpọ̀ láti inú ìmọ̀ Ọlọrun nísinsìnyí. Bibeli dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó díjú tí ó sì ń daniláàmú jùlọ nínú ìgbésí-ayé. Gbígba ìtọ́sọ́nà rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọrun dàgbà. Ẹ wo irú àǹfààní títóbilọ́lá tí èyí jẹ́! Èyí yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti gbádùn àlàáfíà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun nìkanṣoṣo ni ó lè fúnni. (Romu 15:​13, 33) Bí o ti bẹ̀rẹ̀ síí gba ìmọ̀ ṣíṣekókó yìí sínú, o ń dáwọ́lé ìsapá tí ó ṣe pàtàkì tí ó lérè jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ. Ìwọ kì yóò kábàámọ̀ láé pé o jèrè ìmọ̀ Ọlọrun tí ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun.

19. Ìbéèrè wo ni a óò gbéyẹ̀wò ní orí tí ó tẹ̀lé e?

19 A ti tọ́ka sí Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó ní ìmọ̀ Ọlọrun nínú. Síbẹ̀, báwo ni a ṣe mọ̀ pé kì í ṣe ìwé ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn, bíkòṣe, ohun kan tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì? A óò gbé ìbéèrè yìí yẹ̀wò ní orí tí ó tẹ̀lé e.

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Èéṣe tí ìmọ̀ Ọlọrun fi lè ṣamọ̀nà rẹ lọ sí ayọ̀ ayérayé?

Báwo ni ìgbésí-ayé yóò ṣe rí nínú Paradise ilẹ̀-ayé tí ń bọ̀?

Èéṣe tí ìwọ óò fi jàǹfààní láti inú gbígba ìmọ̀ Ọlọrun sínú nísinsìnyí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]