Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Ọlọrun Ti Ṣe Láti Gba Aráyé Là

Ohun Tí Ọlọrun Ti Ṣe Láti Gba Aráyé Là

Orí 7

Ohun Tí Ọlọrun Ti Ṣe Láti Gba Aráyé Là

1, 2. (a) Báwo ni balógun ọ̀rún Romu kan ṣe wá mọrírì ẹni tí Ọmọkùnrin Ọlọrun jẹ́? (b) Èéṣe tí Jehofa fi yọ̀ǹda kí Jesu kú?

Ọ̀SÁN ìgbà ìrúwé kan ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, balógun ọ̀rún Romu kan wo àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí ń kú lọ, pẹ̀lú ìrora. Sójà yẹn ṣàkíyèsí ọ̀kan nínú wọn ní pàtàkì​—⁠Jesu Kristi. Wọ́n ti kan Jesu mọ́ òpó onígi. Sánmà ọjọ́kanrí náà dúdú bí àkókò ikú rẹ̀ ti súnmọ́lé. Nígbà tí ó kú, ilẹ̀ mi tìtì, sójà náà ṣe sáàfúlà pé: “Dájúdájú Ọmọkùnrin Ọlọrun ni ọkùnrin yii.”​—⁠Marku 15:39.

2 Ọmọkùnrin Ọlọrun kẹ̀! Sójà yẹn tọ̀nà. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó tíì ṣẹlẹ̀ rí lórí ilẹ̀-ayé ni. Ní àwọn àkókò tí ó ṣáájú, Ọlọrun fúnra rẹ̀ ti pe Jesu ní Ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n. (Matteu 3:17; 17:5) Èéṣe tí Jehofa ti yọ̀ǹda fún Ọmọkùnrin rẹ̀ láti kú? Nítorí èyí jẹ́ ọ̀nà Ọlọrun láti gba aráyé là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

A YÀN ÁN FÚN ÈTE ÀKÀNṢE KAN

3. Èéṣe tí ó fi bá a mú pé Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo ti Ọlọrun ni a yàn fún ète àkànṣe nípa aráyé?

3 Gẹ́gẹ́ bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú nínú ìwé yìí, Jesu wàláàyè ṣáájú kí ó tó wá bí ẹ̀dá ènìyàn. A pè é ní “Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo” ti Ọlọrun nítorí pé Jehofa dá a ní tààràtà. Lẹ́yìn náà Ọlọrun lo Jesu láti mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn wá sí ìyè. (Johannu 3:18; Kolosse 1:16) Jesu ní ìfẹ́ ní pàtó fún ìran aráyé. (Owe 8:​30, 31) Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé Jehofa yan Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo rẹ̀ láti mú ète àkànṣe ṣẹ nígbà tí aráyé wá sábẹ́ ìdálẹ́bi ikú!

4, 5. Ṣáájú kí Jesu tó wá sórí ilẹ̀-ayé, kí ni Bibeli ṣípayá nípa Irú-Ọmọ Messia náà?

4 Nígbà tí ó ń kéde ìdájọ́ lórí Adamu, Efa, àti Satani ní ọgbà Edeni, Ọlọrun sọ̀rọ̀ nípa Olùgbanisílẹ̀ ọjọ́ iwájú náà bí “irú-ọmọ” kan. Irú-Ọmọ yìí, tàbí ọmọ-inú, yóò wá láti ṣàtúnṣe àwọn ìpọ́njú bíbanilẹ́rù tí Satani Èṣù, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa,” ti mú wá. Níti tòótọ́, Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà yóò tẹ Satani àti gbogbo àwọn tí wọ́n tẹ̀lé e rẹ́.​—⁠Genesisi 3:15; 1 Johannu 3:⁠8; Ìṣípayá 12:9.

5 Láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá, Ọlọrun ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti ṣí púpọ̀ síi payá nípa Irú-Ọmọ náà, tí a tún ń pè ní Messia. Bí a ti fi hàn nínú àwòrán ìsọfúnni tí ó wà ní ojú-ìwé 37, ọ̀pọ̀ tabua àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ni ó pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa onírúurú apá ìgbésí-ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Fún àpẹẹrẹ, òun yóò farada ìfojú ẹni gbolẹ̀ bíbanilẹ́rù kí ó baà lè mú ilà-iṣẹ́ rẹ̀ nínú ète Ọlọrun ṣẹ.​—⁠Isaiah 53:​3-⁠5.

ÌDÍ TÍ MESSIA YÓÒ FI KÚ

6. Ní ìbámu pẹ̀lú Danieli 9:​24-⁠26, kí ni Messia náà yóò ṣàṣeparí rẹ̀, báwo sì ni?

6 Àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Danieli 9:​24-⁠26 sọtẹ́lẹ̀ pé Messia náà​—⁠Ẹni Àmì Òróró Ọlọrun⁠—​yóò mú ète ńlá kan ṣẹ. Yóò wá sí ilẹ̀-ayé láti “ṣe ìparí ìrékọjá, àti láti fi èdìdì dí ẹ̀ṣẹ̀, àti láti ṣe ìlàjà fún àìṣedéédé àti láti mú òdodo” títí láé wá. Messia náà yóò mú ìdálẹ́bi ikú kúrò fún aráyé olùṣòtítọ́. Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe ṣe èyí? Àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣàlàyé pé a óò ‘ké e kúrò,’ tàbí pa á.

7. Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn Júù ṣe ń fi ẹranko rúbọ, kí ni ìwọ̀nyí sì jẹ́ àwòrán ìṣáájú fún?

7 Àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì mọ̀ nípa èrò ètùtù fún àṣìṣe. Nínú ìjọsìn wọn lábẹ́ Òfin náà tí Ọlọrun fún wọn nípasẹ̀ Mose, wọ́n ń fi ẹran ṣe ìrúbọ déédéé. Ìwọ̀nyí rán àwọn ènìyàn Israeli létí pé ẹ̀dá ènìyàn nílò ohun kan láti fi ṣètùtù fún, tàbí bo, ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Aposteli Paulu ṣàkópọ̀ ìlànà náà ní ọ̀nà yìí: “Bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde ìdáríjì kankan kì í ṣẹlẹ̀.” (Heberu 9:22) Àwọn Kristian kò sí lábẹ́ Òfin Mose pẹ̀lú àwọn ohun àbèèrè fún rẹ̀, irú bí àwọn ìrúbọ. (Romu 10:⁠4; Kolosse 2:​16, 17) Wọ́n sì tún mọ̀ pẹ̀lú pé àwọn ìrúbọ ẹran kò lè pèsè ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá tí ó wà pẹ́títí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ọrẹ-ẹbọ ìrúbọ wọ̀nyí jẹ́ òjìji ìṣáájú fún ìrúbọ tí ó túbọ̀ níyelórí púpọ̀​—⁠ti Messia náà, tàbí Kristi. (Heberu 10:​4, 10; fiwé Galatia 3:24.) Síbẹ̀, ìwọ lè béèrè pé, ‘Ó ha pọndandan níti gidi fún Messia náà láti kú bí?’

8, 9. Kí ni àwọn ohun iyebíye tí Adamu àti Efa pàdánù, báwo sì ni ìgbésẹ̀ wọn ṣe kan ìran wọn?

8 Bẹ́ẹ̀ni, Messia náà níláti kú bí aráyé yóò bá ní ìgbàlà. Láti lóye ìdí fún èyí, a gbọ́dọ̀ ronú padà lọ sí ọgbà Edeni kí a sì gbìyànjú láti lóye ìtóbi ohun tí Adamu àti Efa pàdánù nígbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun. Ìyè ayérayé ni a ti gbé kalẹ̀ sí iwájú wọn! Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọrun, wọ́n tún gbádùn ìbátan tààràtà pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ṣá ìṣàkóso Jehofa tì, wọ́n pàdánù gbogbo ìyẹn wọ́n sì mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí ìran ẹ̀dá ènìyàn.​—⁠Romu 5:12.

9 Ṣe ni ó dàbí ẹni pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti fi ọ̀rọ̀-dúkìá púpọ̀ rẹpẹtẹ kan polúkúrúmuṣu, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ara wọn sínú gbèsè rẹpẹtẹ kan. Adamu àti Efa ta àtaré gbèsè náà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-inú wọn. Nítorí pé a kò bí wa ní pípé àti láìlẹ́ṣẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a sì ń kú. Nígbà tí a bá ṣàìsàn tàbí sọ ohun kan tí ń ṣenilọ́ṣẹ́ tí a fẹ́ pé kí a lè tọrọ àforíjì fún, a ń ní ìrírí àwọn ìyọrísí gbèsè wa tí a jogún​—⁠àìpé ẹ̀dá ènìyàn. (Romu 7:​21-⁠25) Ìrètí wa kanṣoṣo wà nínú jíjèrè ohun tí Adamu pàdánù. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò lè jèrè ìjẹ́pípé ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ni ó ń dẹ́ṣẹ̀, gbogbo wa ti gba ikú, kì í ṣe ìyè.​—⁠Romu 6:23.

10. Kí ni a nílò láti ra ohun tí Adamu pàdánù padà?

10 Síbẹ̀, ohun kan ha wà tí a lè fi rúbọ ní pàṣípààrọ̀ fún ìwàláàyè tí Adamu pàdánù? Ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìdájọ́ òdodo Ọlọrun béèrè fún ìwàdéédéé, “ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.” (Eksodu 21:23) Nítorí náà, a níláti san ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ fún ìwàláàyè tí ó sọnù. Kì í wulẹ̀ ṣe ìwàláàyè èyíkéyìí ni yóò ṣiṣẹ́. Orin Dafidi 49:​7, 8 sọ nípa ẹ̀dá ènìyàn aláìpé pé: “Kò sí ẹnì kan, bí ó ti wù kí ó ṣe, tí ó lè ra arákùnrin rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lè san owó ìràpadà fún Ọlọrun nítorí rẹ̀. Nítorí ìràpadà ọkàn wọn iyebíye ni, ó sì dẹ́kun láéláé.” Nígbà náà ọ̀ràn náà ha ń múni sọ̀rètínù bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá.

11. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìràpadà” dúró fún ní èdè Heberu? (b) Ta ni ẹnì kan ṣoṣo náà tí ó lè tún aráyé ràpadà, èésìtiṣe?

11 Ní èdè Heberu, ọ̀rọ̀ náà “ìràpadà” dúró fún iye owó tí a san láti ra òǹdè kan padà ó sì túmọ̀ ní ìpìlẹ̀ sí ọgbọọgba. Ọkùnrin kan tí ó ní ìwàláàyè pípé nìkan ṣoṣo ni ó lè pèsè ohun tí ó bá ohun tí Adamu pàdánù dọ́gba. Lẹ́yìn Adamu, ọkùnrin pípé kanṣoṣo tí a bí lórí ilẹ̀-ayé ni Jesu Kristi. Nítorí náà, Bibeli pe Jesu ní “Adamu ìkẹyìn” ó sì mú un dá wa lójú pé Kristi “fúnni ní ìràpadà kan tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” (1 Korinti 15:45; 1 Timoteu 2:​5, 6) Nígbà tí ó jẹ́ pé Adamu ta àtaré ikú sọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ, ogún tí Jesu fi sílẹ̀ ni ìyè ayérayé. Korinti Kìn-⁠ínní 15:22 ṣàlàyé pé: “Gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú ninu Adamu, bẹ́ẹ̀ pẹlu ni a óò sọ gbogbo ènìyàn di ààyè ninu Kristi.” Ó bá a mu rẹ́gí nígbà náà, pé a pe Jesu ní “Baba Ayérayé.”​—⁠Isaiah 9:​6, 7.

BÍ A ṢE SAN ÌRÀPADÀ NÁÀ

12. Nígbà wo ni Jesu di Messia, irú ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé wo ni ó sì lépa lẹ́yìn náà?

12 Ní ìgbà ìwọ́wé 29 C.E., Jesu lọ sọ́dọ̀ ìbátan rẹ̀ Johannu láti ṣe batisí tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn Jehofa fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jesu. Jesu nípa báyìí di Messia, tàbí Kristi, ẹni náà tí Ọlọrun yàn. (Matteu 3:​16, 17) Lẹ́yìn náà Jesu dáwọ́lé iṣẹ́-òjíṣẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀ rẹ̀. Ó rìnrìn-àjò jákèjádò gbogbo ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀, ní wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọrun tí ó sì ń kó àwọn ọmọlẹ́yìn olùṣòtítọ́ jọ. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, láìpẹ́ àtakò lòdì síi bẹ̀rẹ̀ síí ga sókè.​—⁠Orin Dafidi 118:22; Ìṣe 4:​8-⁠11.

13. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó ṣamọ̀nà sí ikú Jesu gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwàtítọ́ mọ́?

13 Pẹ̀lú ìgboyà, Jesu túdìí àṣírí àgàbàgebè àwọn aṣáájú ìsìn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí wá láti pa á. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín wọ́n di rìkíṣí akójìnnìjìnnì báni kan tí ó ní nínú sísẹ́ni, ìfàṣẹmúni lọ́nà tí kò bófinmu, ìyẹ̀wò ẹjọ́ lọ́nà tí kò bófinmu, àti ìfẹ̀sùnkanni èké ti ìdìtẹ̀ sí ìjọba. Wọ́n gbá Jesu, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n fi ṣẹ̀sín, wọ́n nà án ní pàṣán pẹ̀lú ète láti ya ẹran-ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà gomina Romu náà Pontiu Pilatu dájọ́ ẹ̀bi ikú fún un lórí òpó igi oró. Wọ́n kàn án mọ́ òpó onígi kan wọ́n sì so ó kọ́ síbẹ̀ ní ìdúró ṣánṣán. Èémí kọ̀ọ̀kan jẹ́ èyí tí ń ronilára, ó sì gbà á ní ọ̀pọ̀ wákàtí kí ó tó kú. Jálẹ̀ gbogbo ìrírí agbonijìgì yẹn, Jesu di ìwàtítọ́ rẹ̀ aláìyẹhùn mú sí Ọlọrun.

14. Èéṣe tí Ọlọrun fi yọ̀ǹda kí Ọmọkùnrin rẹ̀ jìyà kí ó sì kú?

14 Báyìí ni ó fi jẹ́ pé ní Nisan 14, 33 C.E., Jesu fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ “ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Marku 10:45; 1 Timoteu 2:​5, 6) Láti ọ̀run, Jehofa rí Ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n tí ó ń jìyà tí ó sì kú. Èéṣe tí Ọlọrun fi fàyègba irú ohun bíbanilẹ́rù bẹ́ẹ̀ láti ṣẹlẹ̀? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìran aráyé. Jesu sọ pé: “Nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ má baà parun ṣugbọn kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Johannu 3:16) Ikú Jesu tún kọ́ wa pé Jehofa jẹ́ Ọlọrun ìdájọ́ òdodo tí ó pé. (Deuteronomi 32:4) Àwọn kan lè ṣe kàyéfì ìdí tí Ọlọrun kò fi yẹ ìdájọ́ òdodo ìlànà rẹ̀ tí ó béèrè fún ẹ̀mí fún ẹ̀mí sílẹ̀ kí ó sì ṣàìfiyèsí ohun ti ipa-ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ Adamu náni. Ìdí rẹ̀ ni pé nígbà gbogbo ni Jehofa ti ń tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ tí ó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn, kódà bí ó tilẹ̀ ná òun fúnra rẹ̀ ní iye púpọ̀.

15. Níwọ̀n bí kì yóò ti bá ìdájọ́ òdodo mú láti yọ̀ǹda kí ìwàláàyè Jesu dópin pátápátá, kí ni Jehofa ṣe?

15 Ìdájọ́ òdodo Jehofa tún béèrè pé kí ikú Jesu ní àbájáde aláyọ̀. Ó ṣetán, ìdájọ́ òdodo yóò ha wà nínú yíyọ̀ǹda kí Jesu olùṣòtítọ́ sùn nínú ikú títí láé bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ti sọtẹ́lẹ̀ pé ẹni adúróṣinṣin Ọlọrun kì yóò máa bá a lọ nínú sàréè. (Orin Dafidi 16:10; Ìṣe 13:35) Ó sùn nínú ikú fún àwọn apá díẹ̀ nínú ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́yìn náà Jehofa Ọlọrun jí i dìde sí ìyè bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan.​—⁠1 Peteru 3:18.

16. Kí ni Jesu ṣe nígbà tí ó padà dé ọ̀run?

16 Nígbà ikú rẹ̀, Jesu jọ̀wọ́ ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀ fún gbogbo ìgbà. Lẹ́yìn tí a ti jí i dìde sí ìwàláàyè ní ọ̀run, ó di ẹ̀mí afúnni ní ìyè. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tí Jesu gòkè lọ sí ibi mímọ́ jùlọ ní àgbáyé, ó tún ní ìsopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀wọ́n ó sì fún Un ní ìníyelórí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ bí ó ti yẹ kí ó rí. (Heberu 9:​23-⁠28) Ìníyelórí ìwàláàyè ṣíṣeyebíye yẹn ni a lè wá ṣàmúlò rẹ̀ fún aráyé onígbọràn. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún ọ?

ÌWỌ ÀTI ÌRÀPADÀ KRISTI

17. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi?

17 Gbé àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí ẹbọ ìràpadà Kristi fi lè ṣàǹfààní fún ọ àní nísinsìnyí yẹ̀wò. Lákọ̀ọ́kọ́, ó mú ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wá. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jesu tí a tú sílẹ̀, a ní “ìtúsílẹ̀ nipa ìràpadà,” bẹ́ẹ̀ni, “ìdáríjì awọn aṣemáṣe wa.” (Efesu 1:7) Nítorí náà bí a bá tilẹ̀ ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, a lè béèrè ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọrun ní orúkọ Jesu. Bí a bá ronúpìwàdà nítòótọ́, Jehofa yóò lo ìníyelórí ẹbọ ìràpadà Ọmọkùnrin rẹ̀. Ọlọrun ń dáríjì wá, ní fífún wa ní ìbùkún ti ẹ̀rí-ọkàn rere, dípò fífi ìyà ikú tí ó tọ́ sí wa nípa dídẹ́ṣẹ̀ jẹ wá.​—⁠Ìṣe 3:19; 1 Peteru 3:21.

18. Ní ọ̀nà wo ni ẹbọ Jesu gbà pèsè ìrètí fún wa?

18 Èkejì, ẹbọ ìràpadà Kristi pèsè ìpìlẹ̀ fún ìrètí ọjọ́-ọ̀la. Nínú ìran, aposteli Johannu ríi pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà” yóò la òpin oníjàábá òjijì ti ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ń bọ̀ yìí já. Kí ni ìdí tí wọn yóò fi là á já nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun yóò pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn run? Áńgẹ́lì kan sọ fún Johannu pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti “fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa,” Jesu Kristi. (Ìṣípayá 7:​9, 14) Níwọ̀n ìgbà tí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jesu Kristi tú sílẹ̀ tí a sì ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí a béèrè fún látọ̀runwá, a óò mọ́ tónítóní lójú Ọlọrun a óò sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.

19. Báwo ni ẹbọ Kristi ṣe fi ẹ̀rí hàn pé òun àti Baba rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ?

19 Ẹ̀kẹta, ẹbọ ìràpadà náà ni ìpẹ̀kun ẹ̀rí ìfẹ́ Jehofa. Ikú Kristi ní nínú àwọn ìṣe ìfẹ́ títóbi jùlọ méjì tí ó ṣeé rí nínú ìtàn àgbáyé: (1) ìfẹ́ Ọlọrun ní rírán Ọmọkùnrin rẹ̀ láti kú nítorí wa; (2) ìfẹ́ Jesu ní fífi tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. (Johannu 15:13; Romu 5:8) Bí a bá lo ìgbàgbọ́ nítòótọ́, ìfẹ́ yìí kan gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Aposteli Paulu sọ pé: “Ọmọkùnrin Ọlọrun . . . nífẹ̀ẹ́ mi tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.”​—⁠Galatia 2:20; Heberu 2:⁠9; 1 Johannu 4:​9, 10.

20. Èéṣe tí a fi níláti lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu?

20 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ìmoore wa hàn fún ìfẹ́ tí Ọlọrun àti Kristi fi hàn nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 3:36) Síbẹ̀, ìgbàlà wa kì í ṣe ìdí pàtàkì jùlọ fún ìwàláàyè àti ikú Jesu lórí ilẹ̀-ayé. Rárá, ìdàníyàn rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ ọ̀ràn àríyànjiyàn tí ó tilẹ̀ tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀kan tí ó jẹ́ ti àgbáyé. Bí a óò ti ríi ní orí tí ó tẹ̀lé e, ọ̀ràn àríyànjiyàn yẹn kan gbogbo wa nítorí pé ó fi ìdí tí Ọlọrun fi fàyègba ìwà ibi àti ìjìyà láti máa bá a lọ fún ìgbà pípẹ́ nínú ayé yìí hàn.

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Èéṣe tí Jesu fi níláti kú láti gba aráyé là?

Báwo ni a ṣe san ìràpadà náà?

Ní àwọn ọ̀nà wo ni o fi jàǹfààní láti inú ìràpadà náà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 67]