Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọrun

Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọrun

Orí 17

Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọrun

1, 2. Báwo ni ipò aráyé ṣe dàbí ti àwọn ènìyàn ní agbègbè tí ìjì ti ṣèparun?

RONÚWÒYE pé ìjì líle kan ti run agbègbè ibi tí o ń gbé bàjẹ́. Ilé rẹ bàjẹ́, o sì pàdánù gbogbo àwọn ohun-ìní rẹ. Oúnjẹ wọ́n. Ipò náà dàbí èyí tí ń múni sọ̀rètínù. Nígbà náà, láìròtẹ́lẹ̀ àwọn ìpèsè ìtura dé. Oúnjẹ àti aṣọ ni a pèsè ní ọ̀pọ̀ yanturu. Wọ́n kọ ilé titun fún ọ. Ó dájú pé ìwọ yóò fi ìmoore hàn fún ẹni náà tí ó mú kí àwọn ìpèsè wọ̀nyí wà lárọ̀ọ́wọ́tó.

2 Ohun kan tí ó farajọ èyí ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Bí ìjì yẹn, ìṣọ̀tẹ̀ Adamu àti Efa ti ṣe ọṣẹ́ púpọ̀ fún ìran ẹ̀dá ènìyàn. Aráyé ti pàdánù ilé Paradise wọn. Láti ìgbà náà, àwọn àkóso ènìyàn ti kùnà láti dáàbòbo àwọn ènìyàn kúrò lọ́wọ́ ogun, ìwà-ọ̀daràn, àti àìṣèdájọ́ òdodo. Ìsìn ti fi ògìdìgbó àwọn ènìyàn tí ebi ń pa sílẹ̀ láìsí oúnjẹ sísunwọ̀n nípa tẹ̀mí. Bí ó ti wù kí ó rí, ní sísọ̀rọ̀ lọ́nà ti ẹ̀mí, Jehofa Ọlọrun ń mú oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé wá. Báwo ni ó ṣe ń ṣe ìyẹn?

“OLÙṢÒTÍTỌ́ ATI ỌLỌ́GBỌ́N-INÚ ẸRÚ”

3. Báwo ni Jehofa ṣe ń ṣe ìpèsè fún aráyé, bí a ti fi hàn nípasẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ wo?

3 Àwọn ìpèsè ìtura ni a sábà máa ń pín fúnni nípasẹ̀ ipa-ọ̀nà kan tí a ṣètò, lọ́nà kan náà Jehofa ti mú kí ìpèsè tẹ̀mí ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Israeli jẹ́ “ìjọ ènìyàn Oluwa” fún ọdún bíi 1,500. Àwọn wọnnì tí wọ́n ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ipa-ọ̀nà Ọlọrun láti kọ́ni ní Òfin rẹ̀ wà láàárín wọn. (1 Kronika 28:⁠8; 2 Kronika 17:​7-⁠9) Ní ọ̀rúndún kìn-⁠ínní C.E., Jehofa mú ètò-àjọ Kristian jáde. Àwọn ìjọ ni a dásílẹ̀, wọ́n sì ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarísọ́nà ẹgbẹ́ olùṣàkóso kan tí ó ní àwọn aposteli àti àwọn àgbà ọkùnrin nínú. (Ìṣe 15:​22-⁠31) Bákan náà lónìí, Jehofa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lo nípasẹ̀ ẹgbẹ́ kan tí a ṣètò. Báwo ni a ṣe mọ èyí?

4. Ta ni ẹ̀rí ti fi hàn pé ó jẹ́ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ní òde-òní, báwo sì ni àwọn ìpèsè tẹ̀mí Ọlọrun ṣe ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó?

4 Jesu sọ pé ní àkókò wíwàníhìn-⁠ín òun nínú agbára Ìjọba, a óò rí “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” tí yóò máa pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu” fún àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀. (Matteu 24:​45-⁠47) Nígbà tí a gbé Jesu gorí ìtẹ́ bí Ọba ọ̀run ní 1914, ta ni ó jẹ́ “ẹrú” yìí? Dájúdájú kì í ṣe àwùjọ àlùfáà Kristẹndọm. Ní èyí tí ó pọ̀ jùlọ, wọ́n ń fi àwọn ìgbékèéyíde tí ń ṣètìlẹyìn fún àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè wọn nínú Ogun Àgbáyé I bọ́ agbo wọn. Ṣùgbọ́n oúnjẹ tẹ̀mí tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu tí ó sì bọ́ sí àkókò ni àwùjọ àwọn Kristian tòótọ́ tí a fi ẹ̀mí Ọlọrun yànsípò ń pín wọ́n sì jẹ́ apá kan ohun tí Jesu pè ní “agbo kékeré.” (Luku 12:32) Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí ń wàásù Ìjọba Ọlọrun kàkà kí ó jẹ́ ti àkóso ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí wá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àgùtàn mìíràn” tí wọ́n tẹ̀ síhà òdodo ti darapọ̀ mọ́ “ẹrú” ẹni-àmì-òróró náà ní ṣíṣe ìsìn tòótọ́. (Johannu 10:16) Ní lílò ‘ẹrú olùṣòtítọ́’ náà àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ ti òde-òní, Ọlọrun ń darí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ṣètòjọ sọ́nà láti mú kí oúnjẹ tẹ̀mí, aṣọ, àti ibùgbé wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn tí ó fẹ́ láti ní àwọn ìpèsè wọ̀nyí.

“OÚNJẸ NÍ ÀKÓKÒ TÍ Ó BẸ́TỌ̀Ọ́MU”

5. Ipò tẹ̀mí wo ni ó wà nínú ayé lónìí, ṣùgbọ́n kí ni Jehofa ń ṣe nípa èyí?

5 Jesu sọ pé: “Ènìyàn gbọ́dọ̀ wà láàyè, kì í ṣe nípasẹ̀ búrẹ́dì nìkanṣoṣo, bíkòṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn àsọjáde tí ń jáde wá lati ẹnu Jehofa.” (Matteu 4:4) Bí ó ti wù kí ó rí, ó baninínújẹ́ pé, èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ènìyàn kò fiyèsí àsọjáde ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bí wòlíì Jehofa náà Amosi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀, “ìyàn . . . kì í ṣe ìyàn oúnjẹ, tàbí òùngbẹ fún omi, ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa” wà. (Amosi 8:11) Kódà ìyàn tẹ̀mí ń mú àwọn onísìn paraku. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìfẹ́-inú Jehofa ni pé kí “gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (1 Timoteu 2:​3, 4) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní ọ̀pọ̀ yanturu. Ṣùgbọ́n níbo ni a ti lè gbà á?

6. Báwo ni Jehofa ti ṣe ń bọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí ní ìgbà àtijọ́?

6 Jálẹ̀jálẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn, Jehofa ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní oúnjẹ tẹ̀mí bí àwùjọ kan. (Isaiah 65:13) Fún àpẹẹrẹ, àwọn àlùfáà ní Israeli kó àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé jọ láti fún wọn ní ìtọ́ni nínú Òfin Ọlọrun bí àwùjọ kan. (Deuteronomi 31:​9, 12) Lábẹ́ ìdarísọ́nà ẹgbẹ́ olùṣàkóso, àwọn Kristian ní ọ̀rúndún kìn-⁠ínní ṣètò àwọn ìjọ wọ́n sì ṣe àwọn ìpàdé fún ìtọ́ni àti ìṣírí gbogbo ènìyàn. (Romu 16:⁠5; Filemoni 1, 2) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ̀lé àpẹẹrẹ yìí. A fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà késí ọ láti pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé wọn.

7. Báwo ni pípésẹ̀ sí ìpàdé Kristian ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́?

7 Dájúdájú, o lè ti kọ́ ohun púpọ̀ láti inú ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ. Bóyá ẹnì kan ti ràn ọ́ lọ́wọ́. (Ìṣe 8:​30-⁠35) Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ rẹ ni a lè fiwé koríko kan tí ó lè gbẹ kí ó sì kú tí kò bá rí ìtọ́jú tí ó yẹ. Nípa báyìí, o gbọ́dọ̀ gba oúnjẹ tẹ̀mí tí ó tọ́. (1 Timoteu 4:6) Àwọn ìpàdé Kristian ń pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni tí ń bá a nìṣó ti a wéwèé láti foúnjẹ bọ́ ọ nípa tẹ̀mí kí ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa mú ìgbàgbọ́ rẹ dàgbà síi bí o ti ń pọ̀ síi nínú ìmọ̀ Ọlọrun.​—⁠Kolosse 1:​9, 10.

8. Èéṣe tí a fi fún wa ní ìṣírí láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?

8 Àwọn ìpàdé ń ṣiṣẹ́ fún ète ṣíṣekókó mìíràn. Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì lati ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.” (Heberu 10:​24, 25) Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí ‘lati ru sókè’ tún lè túmọ̀ sí “láti pọ́n.” Òwe Bibeli kan sọ pé: “Irin a máa pọ́n irin: bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ípọ́n ojú ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Owe 27:17) Gbogbo wá nílò ‘pípọ́n’ tí ń bá a lọ. Àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ojoojúmọ́ láti inú ayé lè sọ ìgbàgbọ́ wa dòkú. Nígbà tí a bá lọ sí àwọn ìpàdé Kristian, pàṣípààrọ̀ ìṣírí máa ń ṣẹlẹ̀. (Romu 1:​11, 12) Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ń tẹ̀lé ìṣílétí aposteli Paulu láti “máa tu ara [wọn] nínú lẹ́nìkínní kejì kí [wọ́n] sì máa gbé ara [wọn] ró lẹ́nìkínní kejì,” irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sì ń pọ́n ìgbàgbọ́ wa. (1 Tessalonika 5:11) Wíwá sí àwọn ìpàdé Kristian déédéé tún fi ìfẹ́ wa fún Ọlọrun hàn ó sì yọ̀ǹda àǹfààní fún wa láti yìn ín.​—⁠Orin Dafidi 35:18.

“Ẹ FI ÌFẸ́ WỌ ARA YÍN LÁṢỌ”

9. Báwo ni Jehofa ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní fífi ìfẹ́ hàn?

9 Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nitori ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kolosse 3:14) Pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́, Jehofa ti pèsè aṣọ yìí fún wa. Ní ọ̀nà wo? Àwọn Kristian lè fi ìfẹ́ hàn nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èso tí Ọlọrun ń fifúnni ti ẹ̀mí mímọ́ Jehofa. (Galatia 5:​22, 23) Jehofa fúnra rẹ̀ ti fi ìfẹ́ tí ó ga jùlọ hàn nípa rírán Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo rẹ̀ wá kí á baà lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 3:16) Ìfihàn ìfẹ́ tí ó ga jùlọ yìí pèsè àwòṣe kan fún wa ní fífi ànímọ́ yìí hàn. Aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé bayii ni Ọlọrun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà naa awa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe lati nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nìkínní kejì.”​—⁠1 Johannu 4:11.

10. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti ọ̀dọ̀ “gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará”?

10 Lílọ tí o bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yóò fún ọ ní àǹfààní títayọlọ́lá láti fi ìfẹ́ hàn. Ìwọ yóò pàdé onírúurú ọ̀pọ̀ ènìyàn níbẹ̀. Kò sí iyèméjì pé púpọ̀ lára wọn yóò fà ọ́ mọ́ra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dájúdájú, àwọn ànímọ́ yàtọ̀ àní láàárín àwọn olùjọ́sìn Jehofa. Bóyá tẹ́lẹ̀ ìwọ wulẹ̀ ń yẹra fún àwọn ènìyàn tí kò ṣàjọpín ìwà-ànímọ́ rẹ tàbí àwọn ohun tí o lọ́kàn ìfẹ́ sí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristian níláti “máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará.” (1 Peteru 2:17) Nítorí náà, fi í ṣe góńgó rẹ láti di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba​—⁠kódà àwọn tí ọjọ́-orí, ànímọ́, ẹ̀yà-ìran, tàbí ìpele ẹ̀kọ́ wọn lè yàtọ̀ sí tìrẹ. Ó ṣeé ṣe pé ìwọ yóò ríi pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn tayọ nínú àwọn ànímọ́ kan tí ń fanimọ́ra.

11. Èéṣe tí ìyàtọ̀ nínú ànímọ́ láàárín àwọn ènìyàn Jehofa kò fi yẹ kí ó kó ìdààmú bá ọ?

11 Ìyàtọ̀ àwọn ànímọ́ nínú ìjọ kò yẹ kí ó dà ọ́ láàmú. Láti ṣàpèjúwe, ronú pé ọ̀pọ̀ ọkọ ni ó ń rìnrìn-àjò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ ní ojú títì. Kì í ṣe gbogbo wọn ní ń sáré bákan náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo wọ́n ni ó dára bákan náà. Àwọn kan ti rìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ kìlómítà, ṣùgbọ́n bí ìwọ, àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí sí, gbogbo wọn ní wọ́n ń rìn lójú títì. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó parapọ̀ di ìjọ kan. Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n mú àwọn ànímọ́ Kristian dàgbà lọ́nà kan náà. Síwájú sí i, kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n rí bakan náà níti ara-ìyára àti ti èrò-inú. Àwọn kan ti ń jọ́sìn Jehofa fún ọ̀pọ̀ ọdún; àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Síbẹ̀, gbogbo wọn ń rìn lójú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, tí a so “pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ninu èrò-inú kan naa ati ninu ìlà ìrònú kan naa.” (1 Korinti 1:10) Nítorí náà, wo àwọn ànímọ́ dídára àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú ìjọ kì í ṣe àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú ọkàn-àyà rẹ yọ̀, nítorí ìwọ yóò mọ̀ pé nítòótọ́ Ọlọrun wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Àti pé dájúdájú ibi tí o fẹ́ láti wà nìyí.​—⁠1 Korinti 14:25.

12, 13. (a) Bí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣẹ̀ ọ́, kí ni o lè ṣe? (b) Kí ni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a máṣe gbin ìbínú sínú?

12 Níwọ̀n bí gbogbo ènìyàn ti jẹ́ aláìpé, nígbà mìíràn ẹnì kan nínú ìjọ lè sọ tàbí ṣe ohun kan tí ó bí ọ nínú. (Romu 3:23) Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu sọ bí ó ti rí gan-⁠an pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹni kan kò bá kọsẹ̀ ninu ọ̀rọ̀, ẹni yii jẹ́ ènìyàn pípé.” (Jakọbu 3:2) Báwo ni ìwọ yóò ṣe hùwàpadà bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ọ́? Òwe Bibeli kan sọ pé: “Ìmòye ènìyàn mú un lọ́ra àti bínú; ògo rẹ̀ sì ni láti ré ẹ̀ṣẹ̀ kọjá.” (Owe 19:11) Láti ní ìmòye túmọ̀ sí láti rí ju ohun tí ó hàn níta nínú ọ̀ràn kan, láti lóye àwọn ìdí tí ó mú kí ẹnì kan sọ̀rọ̀ tàbí hùwà ní ọ̀nà pàtó kan. Ọ̀pọ̀ jùlọ lára wa ń lo ìmòye láti fi wí àwíjàre fún àwọn àṣìṣe wa. Èéṣe tí a kò fi lò ó láti lóye kí a sì fi bo àwọn àìpé àwọn ẹlòmíràn?​—⁠Matteu 7:​1-⁠5; Kolosse 3:13.

13 Máṣe gbàgbé pé a gbọ́dọ̀ dáríji àwọn ẹlòmíràn bí àwa fúnra wa yóò bá gba ìdáríjì Jehofa. (Matteu 6:​9, 12, 14, 15) Bí a bá ń ṣe òtítọ́, a óò bá àwọn ẹlòmíràn lò ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́. (1 Johannu 1:6, 7; 3:14-⁠16; 4:20, 21) Nítorí náà, bí o bá bá ìṣòro pàdé pẹ̀lú ẹnì kan nínú ìjọ, jà lòdì sí gbígbin ìbínú sínú. Bí o bá wọ ìfẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò làkàkà láti yanjú ìṣòro náà, ìwọ kì yóò sì lọ́ra láti tọrọ àforíjì bí o bá ti ṣẹ àwọn ẹlòmíràn.​—⁠Matteu 5:23, 24; 18:15-⁠17.

14. Àwọn ànímọ́ wo ni a gbọ́dọ̀ fi wọ ara wa ní aṣọ?

14 Aṣọ wa nípa tẹ̀mí níláti ní nínú àwọn ànímọ́ mìíràn tí ó sopọ̀ pẹ́kípẹ́kí mọ́ ìfẹ́. Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” Àwọn ìwà-ànímọ́ wọ̀nyí, tí ó rọ̀gbà yí ìfẹ́ ká, jẹ́ apá kan “àkópọ̀-ìwà titun” ti ìwà-bí-Ọlọ́run. (Kolosse 3:​10, 12) Ìwọ yóò ha ṣe ìsapá náà láti wọ ara rẹ láṣọ ní ọ̀nà yìí? Ní pàtàkì bí ìwọ bá fi ìfẹ́ni ará wọ ará rẹ láṣọ ni ìwọ lè ní àmì ìdánimọ̀ ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, nítorí òun wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”​—⁠Johannu 13:35.

IBI ÀÀBÒ KAN

15. Báwo ni ìjọ ṣe dàbí ibi ìdáàbòbò kan?

15 Ìjọ tún ń ṣiṣẹ́ bí ibi ìdáàbòbò kan, ibi ìsádi ìdáàbòbò kan níbi tí o ti lè nímọ̀lára ààbò. Níbẹ ìwọ yóò rí àwọn aláìlábòsí ọkàn tí wọ́n ń làkàkà láti ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Ọlọrun. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ti kọ àwọn àṣà àti ìwà búburú tí ìwọ lè máa jìjàkadì láti borí sílẹ̀. (Titu 3:3) Wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí a sọ fún wa láti “máa bá a lọ ní ríru awọn ẹrù-ìnira ara [wa] lẹ́nìkínní kejì.” (Galatia 6:2) Lọ́nà ti ẹ̀dá, lílépa ipa-ọ̀nà kan tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ tìrẹ fúnra rẹ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. (Galatia 6:⁠5; Filippi 2:12) Síbẹ̀, Jehofa ti pèsè ìjọ Kristian bí ọ̀nà àgbàyanu kan láti ràn wá lọ́wọ́ kí ó sì tì wá lẹ́yìn. Láìka bí ìṣòro rẹ ti lè kó wàhálà bá ọ tó sí, o ní ojútùú ṣíṣeyebíye kan ní àrọ́wọ́tó rẹ​—⁠ìjọ onífẹ̀ẹ́ kan tí yóò dúró tì ọ́ ní àkókò ìpọ́njú tàbí ìpàdánù.​—⁠Fiwé Luku 10:​29-⁠37; Ìṣe 20:35.

16. Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn alàgbà nínú ìjọ ń pèsè?

16 Lára àwọn tí yóò dìde sí ìrànlọ́wọ́ rẹ láti ṣètìlẹyìn fún ọ ni “awọn ẹ̀bùn ninu ènìyàn”​—⁠àwọn alàgbà ìjọ, tàbí alábòójútó tí a yàn, tí ń ṣolùṣọ́ àgùtàn agbo náà tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú àti pẹ̀lú ìháragàgà. (Efesu 4:8, 11, 12; Ìṣe 20:28; 1 Peteru 5:​2, 3) Nípa wọn, Isaiah sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ẹnì kan yóò sì jẹ́ ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì; bí odò-omi ní ibi gbígbẹ, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.”​—⁠Isaiah 32:2.

17. (a) Ní pàtàkì irú ìrànlọ́wọ́ wo ni Jesu ń fẹ́ láti pèsè? (b) Ìpèsè wo ni Ọlọrun ṣèlérí láti ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀?

17 Nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀-ayé, o baninínújẹ́ pé kò sí àbójútó onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn. Ipò àwọn ènìyàn náà dùn ún wọra, ó sì fẹ́ gidigidi láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Àánú wọn ṣe Jesu nítorí pé “a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.” (Matteu 9:36) Ẹ wo bí ìyẹn ti ṣàpèjúwe ipò ọ̀ràn ìṣòro òde òní nípa ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń farada àwọn ìṣòro tí ń kó làásìgbò báni láìsí ẹnikẹ́ni láti yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú nípa tẹ̀mí! Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Jehofa ní ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí nítòótọ́, nítorí òun ṣèlérí pé: “Èmi óò gbé olùṣọ́ àgùtàn dìde fún wọn, tí yóò bọ́ wọn: wọn kì yóò bẹ̀rù mọ́, tàbí wọn kì yóò sì dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan nínú wọn kì yóò sì sọnù.”​—⁠Jeremiah 23:4.

18. Èéṣe tí a fi níláti tọ alàgbà kan lọ bí a bá nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí?

18 Di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tí a yànsípò nínú ìjọ rẹ. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìrírí ní fífi ìmọ̀ Ọlọrun sílò, nítorí wọ́n ti kájú àwọn ìtóótun fún alábòójútó èyí tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sínú Bibeli. (1 Timoteu 3:​1-⁠7; Titu 1:​5-⁠9) Máṣe lọ́tìkọ̀ láti tọ̀ wọ́n lọ bí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí láti borí àṣà tàbí ìwà ànímọ́ kan tí ó forígbárí pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè. Ìwọ yóò rí i pé àwọn alàgbà ń tẹ̀lé ìṣílétí Paulu pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún awọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.”​—⁠1 Tessalonika 2:7, 8; 5:14.

GBÁDÙN ÀÀBÒ PẸ̀LÚ ÀWỌN ÈNÌYÀN JEHOFA

19. Àwọn ìbùkún wo ni Jehofa ti fi jíǹkí àwọn wọnnì tí wọ́n ń wá ààbò nínú ètò-àjọ rẹ̀?

19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé lábẹ́ àwọn ipò aláìpé nísinsìnyí, Jehofa ń pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ìdáàbòbò fún wa nípa tẹ̀mí. Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ dúró de ayé titun tí Ọlọrun ṣèlérí kí a tó lè nírìírí àwọn àǹfààní paradise kan níti gidi. Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ apá kan ètò-àjọ Jehofa ń gbádùn ààbò ti paradise tẹ̀mí kan nísinsìnyí. Nípa wọn, Esekieli sọtẹ́lẹ̀ pé: “Wọn óò wà ní àlàáfíà ẹnikẹ́ni kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n.”​—⁠Esekieli 34:28; Orin Dafidi 4:8.

20. Báwo ni Jehofa yóò ṣe san ìfidípò fún ohunkóhun tí a lè fi rúbọ nítorí ìjọsìn rẹ̀?

20 Ẹ wo bí a ti lè kún fún ìmoore tó pé Jehofa ṣe àwọn ìpèsè tẹ̀mí onífẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò-àjọ rẹ̀! Súnmọ́ àwọn ènìyàn Ọlọrun. Máṣe fà sẹ́yìn nínú ìbẹ̀rù ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan lè rò nípa rẹ nítorí pé o gba ìmọ̀ Ọlọrun sínú. Àwọn kan lè má faramọ́ ọn nítorí pé o ń darapọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì ń lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ṣùgbọ́n Ọlọrun yóò bùkún fún ọ ní jìgbìnnì fún ohunkóhun tí o bá fi rúbọ nítorí ìjọsìn rẹ̀. (Malaki 3:10) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jesu sọ pé: “Kò sí ẹni kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tabi awọn arákùnrin tabi awọn arábìnrin tabi ìyá tabi baba tabi awọn ọmọ tabi awọn pápá nitori mi ati nitori ìhìnrere tí kì yoo gba ìlọ́po ọgọ́rùn-⁠ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yii, awọn ilé ati awọn arákùnrin ati awọn arábìnrin ati awọn ìyá ati awọn ọmọ ati awọn pápá, pẹlu awọn inúnibíni, ati ninu ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Marku 10:​29, 30) Bẹ́ẹ̀ni, láìka ohun yòówù tí o bá fi sílẹ̀ sẹ́yìn tàbí tí o gbọ́dọ̀ faradà sí, o lè rí àjọṣepọ̀ dídùn àti ààbò tẹ̀mí láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun.

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Ta ni “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú naa”?

Ìpèsè wo ni Jehofa ti ṣe láti bọ́ wa nípa tẹ̀mí?

Báwo ni àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ Kristian ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]