Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ọlọrun Tòótọ́ Náà?

Ta Ni Ọlọrun Tòótọ́ Náà?

Orí 3

Ta Ni Ọlọrun Tòótọ́ Náà?

1. Èéṣe tí ọ̀pọ̀ fi fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú Bibeli?

NÍGBÀ tí o wo ojú sánmà ní alẹ́ tí ó mọ́lẹ̀ kedere kan, ẹnu kò ha yà ọ́ láti rí àwọn ìràwọ̀ tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀? Báwo ni o ṣe lè ṣàlàyé bí wọ́n ṣe wà? Àwọn ohun alààyè mìíràn lórí ilẹ̀-ayé ń kọ́​—⁠àwọn òdòdó aláwọ̀ mèremère, àwọn ẹyẹ pẹ̀lú àwọn orin wọn dídùn, àwọn ẹja àbùùbùtán tí ń tọ sókè nínú agbami òkun? Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kò lópin. Gbogbo èyí kò lè jẹ́ àkọsẹ̀bá. Abájọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú Bibeli pé: “Ní àtètèkọ́ṣe Ọlọrun dá ọ̀run òun ayé”!​—⁠Genesisi 1:1.

2. Kí ni Bibeli sọ nípa Ọlọrun, kí sì ni ó fún wa ní ìṣírí láti ṣe?

2 Aráyé pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ gan-⁠an lórí ọ̀rọ̀ nípa Ọlọrun. Àwọn kan ronú pé Ọlọrun jẹ́ ipá aláìnímọ̀lára kan. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń jọ́sìn àwọn babańlá tí wọ́n ti kú, ní gbígbàgbọ́ pé Ọlọrun ti jìnnà jù láti súnmọ́. Ṣùgbọ́n Bibeli ṣí i payá pé Ọlọrun tòótọ́ náà jẹ́ ẹni gidi kan tí ń fi ọkàn-ìfẹ́ ọlọ́yàyà hàn nínú wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Ìdí nìyẹn tí ó fi fún wa ní ìṣírí láti “wá Ọlọrun,” ní sísọ pé: “Kò jìnnà sí ẹni kọ̀ọ̀kan wa.”​—⁠Ìṣe 17:27.

3. Kí ni ìdí rẹ̀ tí kò fi ṣeé ṣe láti ya àwòrán Ọlọrun?

3 Báwo ni Ọlọrun ṣe rí? Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mélòókan ti rí àwọn ìrísí ìran nípa bí ó ṣe wà nínú ògo. Nínú ìwọ̀nyí ó fàmìṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, tí ìmọ́lẹ̀yòò tí ń múni bẹ̀rù sì ń wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí wọ́n rí irú ìrísí ìran bẹ́ẹ̀ kò fìgbà kan ṣàpèjúwe ojú tí ó fara hàn kedere kan. (Danieli 7:​9, 10; Ìṣípayá 4:​2, 3) Ìyẹn jẹ́ nítorí pé “Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí”; òun kò ní ara tí ó ṣeé fojúrí. (Johannu 4:24) Níti tòótọ́, kò ṣeé ṣe láti ya àwòrán pípéye nípa bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe rí, nítorí “kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọrun nígbà kankan rí.” (Johannu 1:18; Eksodu 33:20) Síbẹ̀, Bibeli kọ́ wa ní ohun púpọ̀ nípa Ọlọrun.

ỌLỌRUN TÒÓTỌ́ NÁÀ NÍ ORÚKỌ KAN

4. Kí ni díẹ̀ lára àwọn orúkọ oyè tí ó nítumọ̀ tí a lò fún Ọlọrun nínú Bibeli?

4 Nínú Bibeli, Ọlọrun tòótọ́ náà ni a dámọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bí “Ọlọrun Olódùmarè,” “Ẹni Gíga Jùlọ,” “Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá,” “Atóbilọ́la Olùkọ́ni,” “Oluwa Ọba-Aláṣẹ,” àti “Ọba ayérayé.” (Genesisi 17:⁠1; Orin Dafidi 50:14, NW; Oniwasu 12:⁠1, NW; Isaiah 30:20, NW; Ìṣe 4:24; 1 Timoteu 1:17) Ríronú lórí irú àwọn orúkọ oyè bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìmọ̀ wa nípa Ọlọrun ga síi.

5. Kí ni orúkọ Ọlọrun, báwo ni ó sì ṣe fara hàn léraléra tó nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu?

5 Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọrun ní orúkọ kan tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó fara hàn ní nǹkan bíi 7,000 ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nìkan​—⁠lọ́pọ̀ ìgbà ju èyíkéyìí lára àwọn orúkọ oyè rẹ̀. Ní nǹkan bí 1,900 ọdún sẹ́yìn, àwọn Júù dáwọ́ pípe orúkọ àtọ̀runwá náà dúró nítorí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Èdè Heberu ti àkókò Bibeli ni a kọ láìní àwọn fáwẹ́ẹ̀lì. Nítorí náà, kò sí bí a ṣe lè mọ bí Mose, Dafidi, tàbí àwọn mìíràn ní ìgbàanì ṣe pe kọnsonanti mẹ́rin náà (יהוה) tí ó parapọ̀ di orúkọ àtọ̀runwá náà gẹ́lẹ́. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti dámọ̀ràn pé ó lè jẹ́ “Yahweh” ni a ń pe orúkọ Ọlọrun, ṣùgbọ́n kò dá wọn lójú. Ọ̀nà ìgbà pé ọ̀rọ̀ náà “Jehofa” lédè Yorùbá ni a ti ń lò fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, alábàádọ́gba rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ èdè ni a sì tẹ́wọ́gbà ní ọ̀pọ̀ ibi lónìí.​—⁠Wo Eksodu 6:3 àti Isaiah 26:4.

ÌDÍ TÍ O FI YẸ KÍ O LO ORÚKỌ ỌLỌRUN

6. Kí ni Orin Dafidi 83:18 sọ nípa Jehofa, èésìtiṣe tí a fi níláti lo orúkọ rẹ̀?

6 Jehofa, aláìlẹ́gbẹ́ orúkọ Ọlọrun, ṣiṣẹ́ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín òun àti gbogbo àwọn ọlọrun mìíràn. Ìdí nìyẹn tí orúkọ yẹn fi fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bibeli, ní pàtàkì nínú apá tí a kọ lédè Heberu. Ọ̀pọ̀ àwọn olùtumọ̀ kùnà láti lo orúkọ àtọ̀runwá náà, ṣùgbọ́n Orin Dafidi 83:18 sọ ní kedere pé: “Ìwọ, orúkọ ẹni kanṣoṣo tí íjẹ́ Jehofa, ìwọ ni Ọ̀gá-ògo lórí ayé gbogbo.” Nítorí náà ó bá a mú wẹ́kú fún wa láti lo orúkọ Ọlọrun fúnra rẹ̀ nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

7. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ náà Jehofa kọ́ wa nípa Ọlọrun?

7 Orúkọ náà Jehofa jẹ́ ẹ̀dàya ọ̀rọ̀-ìṣe Heberu kan tí ó túmọ̀ sí “láti di.” Nípa báyìí, orúkọ Ọlọrun túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Jehofa Ọlọrun tipa báyìí fi ara rẹ̀ hàn bí Olùpète Títóbilọ́lá náà. Ó má ń mú kí àwọn ète rẹ̀ ní ìmúṣẹ nígbà gbogbo. Ọlọrun òtítọ́ kanṣoṣo náà ni ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ jẹ́ orúkọ yìí, nítorí àwọn ẹ̀dá ènìyàn kò lè fi ìgbà kan ní ìdánilójú pé àwọn ìwéwèé wọn yóò kẹ́sẹjárí. (Jakọbu 4:​13, 14) Jehofa nìkan ṣoṣo ni ó lè sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò rí. . . . Yóò . . . máa ṣe rere nínú ohun tí mo rán an.”​—⁠Isaiah 55:11.

8. Ète wo ni Jehofa kéde nípasẹ̀ Mose?

8 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn bàbá olórí ìdílé Heberu náà Abrahamu, Isaaki, àti Jekọbu “ké pe orúkọ Jehofa,” ṣùgbọ́n wọn kò mọ ìjẹ́pàtàkì orúkọ àtọ̀runwá náà ní kíkún. (Genesisi 21:33; 26:25, NW; 32:9; Eksodu 6:3) Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jehofa ṣí ète rẹ̀ payá láti dá àwọn ọmọ ìran wọn, àwọn ọmọ Israeli nídè kúrò ní oko-ẹrú ní Egipti kí ó sì fún wọn ní “ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,” èyí lè ti dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe. (Eksodu 3:17) Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọrun tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì àìnípẹ̀kun ti orúkọ rẹ̀ nípa sísọ fún wòlíì rẹ̀ Mose pé: “Báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún àwọn ọmọ Israeli; [Jehofa, NW], Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, àti Ọlọrun [Jekọbu], ni ó rán mi sí yín: èyí ni orúkọ mi títíláé, èyí sì ni ìrántí mi láti ìrandíran.”​—⁠Eksodu 3:15.

9. Ojú wo ni Farao fi wo Jehofa?

9 Mose sọ fún Farao, ọba Egipti, pé kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israeli lọ láti jọ́sìn Jehofa ní aginjù. Ṣùgbọ́n Farao, ẹni tí wọ́n ń wo òun fúnra rẹ̀ bí ọlọrun tí ó sì ń jọ́sìn àwọn ọlọrun Egipti mìíràn, dáhùn pé: “Ta ni [Jehofa, NW], tí èmi óò fi gba ohùn rẹ̀ gbọ́ láti jẹ́ kí Israeli kí ó lọ? Èmi kò mọ [Jehofa, NW] náà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí Israeli kí ó lọ.”​—⁠Eksodu 5:​1, 2.

10. Ní Egipti ìgbàanì, ìgbésẹ̀ wo ni Jehofa gbé láti mú ète rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israeli ṣẹ?

10 Lẹ́yìn náà ni Jehofa gbé ìgbésẹ̀ tí ń bá a nìṣó láti mú ète rẹ̀ ṣẹ, ní gbígbé ìgbésẹ̀ ní ìbáramu pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀. Ó mú ìyọnu àjàkálẹ̀ mẹ́wàá wá sórí Egipti ìgbàanì. Ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ó kẹ́yìn pa gbogbo àkọ́bí Egipti, títí kan ọmọkùnrin Farao agbéraga. Nígbà náà ni àwọn ará Egipti bẹ̀rẹ̀ sí háragàgà pé kí Israeli máa lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ará Egipti kan ni agbára Jehofa wọ̀ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Israeli láti jáde kúrò ní Egipti.​—⁠Eksodu 12:​35-⁠38.

11. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jehofa ṣe ní Òkun Pupa, kí sì ni a fagbára mú àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti gbà?

11 Farao olóríkunkun àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, gbéra láti tún àwọn ẹrú rẹ̀ kó. Bí àwọn ará Egipti ti ń súnmọ́tòsí, lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, Ọlọrun pín Òkun Pupa níyà kí àwọn ọmọ Israeli baà lè kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn tí ń lé wọn bọ̀ dé àárín ilẹ̀ òkun, Jehofa “yẹ kẹ̀kẹ́ wọn, wọ́n sì ń wọ́ tuuru.” Àwọn jagunjagun ará Egipti kébòòsí pé: “Ẹ jẹ́ kí a sá kúrò níwájú Israeli; nítorí tí [Jehofa, NW] ń bá àwọn ará Egipti jà fún wọn.” Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù. Odi omi mùmùrara ya wálẹ̀ ó sì “bo kẹ̀kẹ́, àti àwọn ẹlẹ́ṣin, àti gbogbo ogun Farao.” (Eksodu 14:​22-25, 28) Jehofa tipa báyìí ṣe orúkọ títóbi kan fún ara rẹ̀, a kò sì tíì gbàgbé ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn títí di òní olónìí.​—⁠Joṣua 2:​9-⁠11.

12, 13. (a) Ìtumọ̀ wo ni orúkọ Ọlọrun ní fún wa lónìí? (b) Kí ni ó jẹ́ kánjúkánjú fún àwọn ènìyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, èésìtiṣe?

12 Orúkọ tí Ọlọrun ti ṣe fún ara rẹ̀ ní ìtumọ̀ títóbi fún wa lónìí. Orúkọ rẹ̀, Jehofa, jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú pé gbogbo ohun tí ó ti pète ni yóò mú kí ó jásí òótọ́. Ìyẹn ní nínú ṣíṣàṣeparí ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí ilẹ̀-ayé wa di paradise kan. (Genesisi 1:28; 2:8) Fún ète yẹn, Ọlọrun yóò mú gbogbo àwọn alátakò ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ lónìí kúrò, nítorí ó ti sọ pé: “Wọn óò sì mọ̀ pé èmi ni [Jehofa, NW].” (Esekieli 38:23) Lẹ́yìn náà, Ọlọrun yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti dá àwọn olùjọsìn rẹ̀ nídè wọ inú ayé titun òdodo kan.​—⁠2 Peteru 3:13.

13 Gbogbo àwọn tí ń fẹ́ ojúrere Ọlọrun gbọ́dọ̀ kọ́ láti ké pe orúkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Bibeli ṣèlérí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jehofa ni a óò gbàlà.” (Romu 10:13) Bẹ́ẹ̀ni, orukọ náà Jehofa ní ìtumọ̀ gidi. Kíké pe Jehofa bí Ọlọrun àti Olùdáǹdè rẹ lè ṣamọ̀nà rẹ sí ayọ̀ tí kò lópin.

ÀWỌN ÀNÍMỌ́ ỌLỌRUN TÒÓTỌ́ NÁÀ

14. Àwọn ànímọ́ ṣíṣe kókó ti Ọlọrun wo ni Bibeli tẹnumọ́?

14 Ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdáǹdè Israeli kúrò ní Egipti tẹnumọ́ ànímọ́ ṣíṣe kókó mẹ́rin tí Ọlọrun ní tí ó wà déédéé lọ́nà pípé pérépéré. Ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú Farao ṣí agbára rẹ̀ tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ payá. (Eksodu 9:16) Ọ̀nà afọ̀gáhàn tí Ọlọrun gbà bójútó ipò ọ̀ràn tí ó díjúpọ̀ yẹn fi ọgbọ́n rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ hàn. (Romu 11:33) Ó ṣí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ payá nípa fífi ìyà jẹ àwọn olóríkunkun alátakò tí wọ́n ń ni àwọn ènìyàn rẹ̀ lára. (Deuteronomi 32:4) Ànímọ́ títayọ jùlọ ti Ọlọrun ni ìfẹ́. Jehofa fi ìfẹ́ tí ó tayọ hàn nípa mímú ìlérí rẹ̀ ṣẹ níti àwọn ọmọ ìran Abrahamu. (Deuteronomi 7:8) Ó tún fi ìfẹ́ hàn nípa yíyọ̀ǹda kí àwọn ará Egipti mélòókan ṣá àwọn ọlọrun èké tì kí wọ́n sì jàǹfààní ńláǹlà nípa mímú ìdúró wọn fún Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo náà.

15, 16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọrun ti gbà fi ìfẹ́ hàn?

15 Bí o ti ń ka Bibeli, ìwọ yóò ṣàkíyèsí pé ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ Ọlọrun, ó sì ń fi èyí hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, láti inú ìfẹ́ rẹ̀ ni ó fi di Ẹlẹ́dàá tí ó sì kọ́kọ́ ṣàjọpín ìdùnnú-ayọ̀ ìwàláàyè pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn áńgẹ́lì wọnnì nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun wọ́n sì ń yìn ín. (Jobu 38:​4, 7; Danieli 7:10) Ọlọrun tún fi ìfẹ́ hàn ní dídá ilẹ̀-ayé tí ó sì múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn aláyọ̀ láti wà níbẹ̀.​—⁠Genesisi 1:​1, 26-⁠28; Orin Dafidi 115:16.

16 A ń jàǹfààní láti inú ìfẹ́ Ọlọrun ní àwọn ọ̀nà tí ó pọ̀ púpọ̀ jù láti kà. Ní ọ̀nà kan, tìfẹ́tìfẹ́ ni Ọlọrun dá ara wa ní irú ọ̀nà ìyanu kan tí a fi lè gbádùn ìwàláàyè. (Orin Dafidi 139:14) Ìfẹ́ rẹ̀ ni a fi hàn níti pé ó pèsè “òjò lati ọ̀run ati awọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ ati ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà [wa] dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Ọlọrun tilẹ̀ “ń mú kí oòrùn rẹ̀ là sórí awọn ènìyàn burúkú ati rere tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí awọn olódodo ati aláìṣòdodo.” (Matteu 5:45) Ìfẹ́ tún sún Ẹlẹ́dàá wa láti ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ Ọlọrun kí a sì ṣiṣẹ́sìn ín tayọ̀tayọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn rẹ̀. Nítòótọ́, “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.” (1 Johannu 4:8) Ṣùgbọ́n ohun púpọ̀ ṣì wà nípa ànímọ́ rẹ̀.

“ỌLỌRUN ALÁÀÁNÚ ÀTI OLÓORE-Ọ̀FẸ́”

17. Kí ni a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nípa Ọlọrun nínú Eksodu 34:​6, 7?

17 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli ti sọdá Òkun Pupa, wọ́n ṣì níláti mọ Ọlọrun síwájú síi. Mose nímọ̀lára àìní yìí ó sì gbàdúrà pé: “Ǹjẹ́ nísinsìnyí, èmí bẹ̀ ọ́, bí mo bá rí oore-ọ̀fẹ́ ní ojú rẹ, fi ọ̀nà rẹ hàn mí nísinsìnyí, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́, kí èmi kí ó lè rí oore-ọ̀fẹ́ ní ojú rẹ.” (Eksodu 33:13) Mose wá mọ Ọlọrun dáadáa nígbà tí ó gbọ́ ìpolongo Ọlọrun fúnra rẹ̀: “[Jehofa, Jehofa, NW], Ọlọrun aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní oore àti òtítọ́; ẹni tí ó ń pa àánú mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí ó ń dárí àìṣedéédéé, àti ìrékọjá, àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, àti nítòótọ́ tí kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà.” (Eksodu 34:​6, 7) Ọlọrun mú kí ìfẹ́ rẹ̀ wà déédéé pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo, láìdáàbò bo àwọn amọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àbájáde ìwà àìtọ́ wọn.

18. Báwo ni Jehofa ti ṣe fi ara rẹ̀ hàn ní aláàánú?

18 Gẹ́gẹ́ bí Mose ti rí i, Jehofa ń fi àánú hàn. Ẹni tí ó ní àánú a máa káàánú àwọn wọnnì tí wọ́n ń jìyà ó sì ń gbìyànjú láti mú ìtura wá fún wọn. Nípa báyìí Ọlọrun ti fi ìyọ́nú hàn fún aráyé nípa ṣíṣe ìpèsè fún ìtura wíwà pẹ́ títí kúrò lọ́wọ́ ìjìyà, àìsàn, àti ikú. (Ìṣípayá 21:​3-⁠5) Àwọn tí wọ́n ń jọ́sìn Ọlọrun lè nírìírí àwọn àjálù nítorí àwọn ipò nǹkan nínú ayé burúkú yìí, tàbí kí wọ́n gbégbèésẹ̀ lọ́nà tí kò lọ́gbọ́n nínú kí wọ́n sì ko ìjàngbọ̀n. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá yíjú sí Jehofa tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, yóò tù wọ́n nínú yóò sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Èéṣe? Nítorí pé ó ń fi àánú ka àwọn olùjọsìn rẹ̀ sí lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.​—⁠Orin Dafidi 86:15; 1 Peteru 5:​6, 7.

19. Èéṣe tí a fi lè sọ pé Ọlọrun jẹ́ olóore-ọ̀fẹ́?

19 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ ń bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà tí ó lekoko. Ní òdìkejì, ẹ wo bí Jehofa ti jẹ́ olóore-ọ̀fẹ́ tó sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni aláṣẹ tí ó ga jùlọ ní àgbáyé, ó ń fi inúrere tí ó tayọ hàn sí gbogbo ayé lápapọ̀ ní ọ̀nà gbogbo. (Orin Dafidi 8:​3, 4; Luku 6:35) Jehofa tún jẹ́ olóore-ọ̀fẹ́ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan, ní dídáhùn àwọn ẹ̀bẹ̀ pàtó wọn fún ojúrere. (Eksodu 22:​26, 27; Luku 18:​13, 14) Àmọ́ ṣáá o, Ọlọrun kò sí lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti fi ojúrere tàbí àánú hàn sí ẹnikẹ́ni. (Eksodu 33:19) Nítorí náà, a níláti fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún àánú àti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.​—⁠Orin Dafidi 145:​1, 8.

Ó LỌ́RA LÁTI BÍNÚ, KÌ Í ṢE OJÚSÀÁJÚ, Ó SÌ JẸ́ OLÓDODO

20. Kí ní fi hàn pé Jehofa lọ́ra láti bínú tí kì í sì í ṣe ojúsàájú?

20 Jehofa lọ́ra láti bínú. Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé òun kì í gbé ìgbésẹ̀, nítorí ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní pípa Farao olóríkunkun àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ run nínú Òkun Pupa. Pẹ̀lúpẹ̀lú Jehofa kì í ṣe ojúsàájú. Nítorí èyí, àwọn ọmọ Israeli, àwọn ènìyàn tí wọ́n rí ojúrere rẹ̀, pàdánù ojúrere rẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín nítorí wọ́n ń bá a nìṣó nínú ìwà àìtọ́. Ọlọrun tẹ́wọ́gba àwọn ènìyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn rẹ̀, ṣùgbọ́n kìkì àwọn wọnnì tí wọ́n mú ara wọn bá àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀ mu.​—⁠Ìṣe 10:​34, 35.

21. (a) Kí ni Ìṣípayá 15:​2-⁠4 kọ́ wa nípa Ọlọrun? (b) Kí ni yóò mú kí ó rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí Ọlọrun sọ pé ó tọ́?

21 Ìwé Bibeli náà Ìṣípayá tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì kíkọ́ nípa “awọn àṣẹ àgbékalẹ̀” Ọlọrun “tí ó jẹ́ òdodo.” Ó sọ fún wa pé àwọn ẹ̀dá ọ̀run kọrin pé: “Títóbi ati àgbàyanu ni awọn iṣẹ́ rẹ, Jehofa Ọlọrun, Olódùmarè. Òdodo ati òótọ́ ni awọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yoo bẹ̀rù rẹ níti gidi, Jehofa, tí kì yoo sì yin orúkọ rẹ lógo, nitori pé iwọ nìkan ni adúróṣinṣin? Nitori gbogbo awọn orílẹ̀-èdè yoo wá wọn yoo sì jọ́sìn níwájú rẹ, nitori a ti fi awọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.” (Ìṣípayá 15:​2-⁠4) A ń fi ìbẹ̀rù sísunwọ̀n, tàbí ọ̀wọ̀ onífọkànsìn hàn fún Jehofa, nípa mímú ara wa bá ohun tí ó sọ pé ó tọ́ mu. Èyí ni a ń mú rọrùn síi nígbà tí a bá ń rán ara wa létí ọgbọ́n àti ìfẹ́ Ọlọrun. Gbogbo àṣẹ rẹ̀ jẹ́ fún ire wa.​—⁠Isaiah 48:​17, 18.

‘JEHOFA ỌLỌRUN WA JẸ́ Ọ̀KAN’

22. Èéṣe tí àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́gba Bibeli kò fi ń jọ́sìn Mẹ́talọ́kan?

22 Àwọn ará Egipti ìgbàanì ń jọ́sìn ọ̀pọ̀ àwọn ọlọrun, ṣùgbọ́n Jehofa jẹ́ “Ọlọrun tí ń fi dandangbọ̀n béèrè ìjọsìn tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé.” (Eksodu 20:5, NW) Mose rán àwọn ọmọ Israeli létí pé “Jehofa Ọlọrun wa jẹ́ Jehofa kan.” (Deuteronomi 6:4, NW) Jesu Kristi tún ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sọ. (Marku 12:​28, 29) Nítorí náà, àwọn tí wọ́n gba Bibeli bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò jọ́sìn Mẹ́talọ́kan kan tí ó ní ẹni tàbí ọlọrun mẹ́ta nínú ọ̀kan. Níti tòótọ́, ọ̀rọ̀ náà “Mẹ́talọ́kan” kò tilẹ̀ fara hàn nínú Bibeli. Ọlọrun tòótọ́ náà jẹ́ Ẹnì kan, tí ó yàtọ̀ sí Jesu Kristi. (Johannu 14:28; 1 Korinti 15:28) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun kì í ṣe ẹni gidi kan. Ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Jehofa ni ó jẹ́, tí Olódùmarè ń lò láti ṣàṣeparí àwọn ète rẹ̀.​—⁠Genesisi 1:⁠2; Ìṣe 2:1-⁠4, 32, 33; 2 Peteru 1:​20, 21.

23. (a) Báwo ni ìfẹ́ rẹ fún Ọlọrun yóò ṣe ga síi? (b) Kí ni Jesu sọ nípa nínífẹ̀ẹ́ Ọlọrun, kí ni ó sì yẹ kí a kẹ́kọ̀ọ́ nípa Kristi?

23 Bí o bá ṣàgbéyẹ̀wò bí Jehofa ti jẹ́ àgbàyanu tó, o kò ha fohùnṣọ̀kan pé ó yẹ fún ìjọsìn rẹ bí? Bí o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìwọ yóò wá láti mọ̀ ọ́n síi ìwọ yóò sì mọ ohun tí ó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ fún ire àlàáfíà àti ayọ̀ rẹ ayérayé. (Matteu 5:​3, 6) Ní àfikún, ìfẹ́ rẹ fún Ọlọrun yóò ga síi. Ìyẹn bá a mu, nítorí Jesu sọ pé: “Iwọ sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo èrò-inú rẹ ati pẹlu gbogbo okun rẹ.” (Marku 12:30) Ní kedere, Jesu ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Ọlọrun. Ṣùgbọ́n kí ni Bibeli ṣípayá nípa Jesu Kristi? Kí ni ipa-iṣẹ́ rẹ̀ nínú ète Jehofa?

DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ

Kí ni orúkọ Ọlọrun, báwo ni a sì ṣe lò ó léraléra tó nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu?

Kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí o lo orúkọ Ọlọrun?

Èwo nínú àwọn ànímọ́ Jehofa Ọlọrun ni ó fà ọ́ mọ́ra níti gidi?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Báwo ni o ti mọ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo dáradára tó?