Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2022
Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 86
Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 239
Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 117,960
Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 19,721,672
Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 21,150
Góńgó Akéde a: 8,699,048
Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 8,514,983
Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2021: 34,836
Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi b: 145,552
Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé c Lóṣooṣù: 1,465,202
Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 381,310
Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 1,501,797,703
Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì d Lóṣooṣù: 5,666,996
Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2022, e àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná ọgọ́rùn-ún méjì ó lé méjìlélógójì (242) mílíọ̀nù dọ́là láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (21,629). Gbogbo wọn jẹ́ ara Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
a Akéde ni ẹni tó ń kéde tàbí tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Tó o bá fẹ́ àlàyé nípa bá a ṣe mọ iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?” lórí ìkànnì jw.org/yo.
b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ohun tẹ́nì kan máa ṣe kó tó ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” lórí ìkànnì jw.org/yo.
c Aṣáájú-ọ̀nà ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ti ṣe ìrìbọmi tó sì níwà tó dáa. Ó pinnu láti máa lo iye wákàtí kan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lóṣooṣù.
d Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?” lórí ìkànnì jw.org/yo.
e Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2022 bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2021, sí August 31, 2022.