À Ń Wàásù A sì Ń Kọ́ni Kárí Ayé
KÁRÍ AYÉ
-
ILẸ̀ 239
-
IYE AKÉDE 7,782,346
-
ÀRÒPỌ̀ WÁKÁTÌ TÁ A FI WÀÁSÙ 1,748,697,447
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 8,759,988
-
ILẸ̀ 58
-
IYE ÈÈYÀN 968,989,710
-
IYE AKÉDE 1,312,429
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 2,999,639
Kò Ṣẹ́yún Náà Mọ́
Obìnrin oníṣòwò kan wà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Saba nílùú Addis Ababa, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Etiópíà. Lọ́jọ́ kan, àwọn arábìnrin méjì wàásù dé ọ̀dọ́ rẹ̀, wọ́n fún un ní Jí! kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́yún. Saba ní kí àwọn arábìnrin náà wọlé. Pẹ̀lú omijé lójú ló fi ń sọ fún wọn pé ohun tóun ń rò lọ́wọ́lọ́wọ́ ni bóun ṣe máa lọ ṣẹ́ oyún inú òun. Nígbà tó rojọ́ fún wọn, orí
àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wú débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Lọ́jọ́ yẹn, Saba pèrò dà, ó lóun ò ní ṣẹ́ oyún náà, ó sì sọ fún ọkọ rẹ̀. Nígbà tó yá, ó bí arẹwà ọmọbìnrin kan. Ni obìnrin yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi. Ní báyìí, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà. Ọkọ rẹ̀ náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ yìí, ó ti di arákùnrin wa. Ọmọbìnrin tí wọ́n bí náà ní ẹ̀gbọ́n méjì, àwọn náà sì ti ṣèrìbọmi ní April ọdún 2012.‘Ṣé A Lè Bá Wọn Sọ̀rọ̀?’
Alábòójútó àyíká kan àti akéde kan ń wàásù láti ilé dé ilé lórílẹ̀-èdè Etiópíà. Nígbà tí wọ́n dé ilé kan, ọmọ ọ̀dọ̀ ni wọ́n bá, wọ́n bi í pé ṣé àwọn lè bá onílé sọ̀rọ̀? Ó dáhùn pé kò lè ṣeé ṣe, wọ́n wá béèrè pé, ṣé àwọn lè fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún ọ̀gá rẹ̀? Ló bá wọlé lọ láti lọ bi ọ̀gá ẹ̀, nígbà tó pa dà dé, ó sọ pé ọ̀gá òun kọ́kọ́ fẹ́ rí ìwé náà.
Àwọn arákùnrin náà fún un ní ìwé ìròyìn kan. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, ó pa dà wá, ó sì sọ pé ọ̀gá ní òun á ka ìwé náà. Ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin náà sọ pé, “Tí ọ̀gá ò bá lè jáde, ṣé àwa lè wọlé lọ bá wọn sọ̀rọ̀?” Ọmọ ọ̀dọ̀ bá tún lọ béèrè lọ́wọ́ ọ̀gá. Lọ́tẹ̀ yìí, ó pẹ́ díẹ̀ kó tó dé, àwọn arákùnrin náà tiẹ̀ ń wò ó pé bóyá ló máa pa dà wá mọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ó pa dà dé, ó sì ní kí wọ́n máa wọlé bọ̀. Ìgbà táwọn arákùnrin wa dé ọ̀dọ̀ bàbá àgbàlagbà tó jẹ́ onílé náà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yirgu ni wọ́n tó mọ̀ pé ó ti ń ṣàìsàn láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, kò tiẹ̀ lè dìde jókòó lórí bẹ́ẹ̀dì. Ohun tó jẹ́ kí
ọmọ ọ̀dọ̀ náà pẹ́ kó tó jáde lẹ́ẹ̀kejì ni pé ó ń múra fún bàbá náà, ó sì ń tún yára náà ṣe.Àwọn arákùnrin náà wàásù fún bàbá yìí. Ohun tó gbọ́ dùn mọ́ ọn nínú gan-an, ó sì ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, ara ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá díẹ̀díẹ̀. Kò pẹ́ tí bàbá yìí fi ń dá dìde lórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì lè lọ kiri fúnra rẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ arọ. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, ó sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan tá a ṣe láìpẹ́ yìí.
Ṣọ́ọ̀ṣì Tó Ṣe Àwọn Ìwé Yìí Ni Kó O Máa Lọ
Ọmọ ọdún mẹ́rin ni Calvin nígbà tí bàbá rẹ̀ kú. Orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè ló ń gbé. Ohun kan ṣoṣo tí bàbá rẹ̀ fi sílẹ̀ fún un ni báàgì kan báyìí tí ìwé méjì wà nínú rẹ̀, ìyẹn Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá 1. Nígbà tí bàbá rẹ̀ ṣì wà láyé, ó sọ fún un pé ṣọ́ọ̀ṣì tó ṣe àwọn ìwé yìí ni kó máa lọ, torí pé àwọn ló ń kọni ní òtítọ́.
Kò pẹ́ tí ìyá Calvin náà kú, ló bá lọ ń gbé lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ àgbà. Odindi ọdún mẹ́sàn-án ni Calvin fi kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò ní tẹ̀ lé ìyá àgbà lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, ó ṣáà ta kú pé lọ́jọ́ kan òun á rí ṣọ́ọ̀ṣì tó ṣe ìwé tí bàbá òun fóun.
Lọ́jọ́ kan ìyá rẹ̀ àgbà pàdé obìnrin kan, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sọ fún obìnrin yìí pé òun lọ́mọ alágídí kan tó lóun ò ní tẹ̀ lé òun lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ó sọ fún obìnrin náà pé ilé lọmọ náà kàn máa ń jókòó sí lọ́jọ́ Sunday táá máa ka ìwé kan báyìí tí bàbá rẹ̀ fi sílẹ̀ fún un. Obìnrin náà wá béèrè orúkọ ìwé náà. Ìyá yìí sọ pé ó dà bíi pé ìwé àwọn ajẹ́rìí agbawèrèmẹ́sìn ni. Kò mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni obìnrin tó ń bá sọ̀rọ̀ yìí.
Arábìnrin wa yìí sọ pé òun máa fẹ́ rí ọmọ rẹ̀ yìí. Ńṣe ló dà bíi pé oówo ńlá kan tú lára Calvin nígbà tó rí arábìnrin yìí. Lójú ẹsẹ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyá rẹ̀ àgbà fojú rẹ̀ rí màbo, kò yéé lọ sípàdé. Ó pinnu pé òun ò ní fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí sílẹ̀, ó sì ń fayọ̀ retí ìgbà àjíǹde tí yóò tún pa dà rí bàbá àti ìyá rẹ̀. Ní oṣù August ọdún 2012, Calvin ṣèrìbọmi.“Alágbára ni Ọlọ́run Tó Ò Ń Sìn”
Caro àti ọkọ ẹ̀, Martin ń gbé ní orílẹ̀-èdè Uganda. Babaláwo ni ọkọ rẹ̀ yìí. Kò tíì ju oṣù kan lọ tí Caro bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ọkọ rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí i ṣenúnibíni sí i. Ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Àwọn baba ńlá mi ò lè wọlé wá mọ́ torí àwọn ìwé tó o kó wálé.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ ẹ́, ó sì ń halẹ̀ mọ ọ́n pé òun máa pa á tí kò bá jáwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe. Nígbà tó yá, kò fún òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ lówó oúnjẹ mọ́. Caro ò jáyà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dáko káwọn ọmọ ẹ̀ lè róúnjẹ jẹ, ó sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. Àmọ́ nígbà tó ti wá rí i pé ẹ̀mí òun wà nínú ewu ó yáa sá kúrò nílé. Nǹkan ò rọrùn fún un, àmọ́ ó ṣà ń yí i mọ́ ọn. Síbẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn, ó lọ fi ìwọ̀nba owó tó ti tọ́jú ra oògùn fún wọn.
Nígbà tó yá, ọkọ Caro pè é lórí fóònù. Ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, mo fẹ́ kó o kó pa dà wálé. Mo ti wá rí i pé alágbára ni Ọlọ́run tó ò ń sìn, kò sì pa dà lẹ́yìn rẹ. Mo fẹ́ kó o sọ fún àwọn tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n wá máa kọ́ èmi náà. Ó tó gẹ́ẹ́, èmi náà fẹ́ di ẹ̀dá tuntun.” Martin ò fọ̀rọ̀ yìí ṣeré o! Òun àtìyàwó ẹ̀ ti ń fayọ̀ gbé pa pọ̀ báyìí. Paríparí ẹ̀, Martin àti Caro ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan lóṣù August ọdún 2012.
Ẹnì Kan Tó Ń Dá Wàásù Lábúlé
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ David lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó ń gbé nílùú kan tó jìnnà
sílùú rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Àmọ́ kò pẹ́ tó fi pa dà sílùú ẹ̀, ìyẹn abúlé kan tó ń jẹ́ Lokichar. Apá ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà ni abúlé yìí wà. Ìlú Lodwar ni ìjọ tó sún mọ́ ọn jù lọ wà, ó sì máa rin ìrìn àjò ọgọ́jọ [160] kìlómítà kó tó débẹ̀. Torí bí ọ̀nà yìí ṣe jìn, David ò fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn Ẹlẹ́rìí fún ọdún mẹ́rin, síbẹ̀ ó ń sọ ohun tó kọ́ fáwọn aládùúgbò rẹ̀ àtàwọn ẹbí rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn míì fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi láwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́dún 2007, ó kàn sáwọn ará tó wà ní Lodwar, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pa dà, àmọ́ èyí gba pé kó máa lọ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù, á kọ́kọ́ gun ọ̀kadà dé ìgboro, lẹ́yìn náà á wọ takisí, kó tó wá wọ bọ́ọ̀sì dé ibi tó ń lọ.Bí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ ṣe ń wọ̀ ọ́ lọ́kàn sí i ni ìtara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ń pọ̀ sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣèrìbọmi, ó kọ́ ilé alámọ̀ tí wọ́n fi koríko bò sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé rẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n ń lò bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ti ń kọ́ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́. Àmọ́, ṣe lọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí ti ẹni tá ò fẹ́ nílùú tó ń dárin, torí pé kì í ṣe gbogbo ará abúlé ni inú wọn dùn sí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe. Odindi ọdún méjì ni wọ́n sì fi ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí i, wọ́n tiẹ̀ máa ń lù ú pàápàá. Ìgbà kan wà táwọn kan tiẹ̀ lù ú bí kíkú-bí-yíyè, wọ́n ní ṣọ́ọ̀ṣì Èṣù ló mú wọ abúlé àwọn. Àmọ́ nígbà tó yá, David fẹjọ́ wọn sun àwọn agbófinró, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n fi í sílẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ. David sọ pé: “Ẹ̀mí mi ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti mò ń kọ́ yìí. Kò sírú ìyà tí wọ́n lè fi jẹ mi, mi ò ní jáwọ́.”
David ṣèrìbọmi lọ́dún 2009, ó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí. Òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nìkan ni akéde lábúlé wọn. Àmọ́ nígbà Ìrántí Ikú Kristi tó wáyé ní oṣù April ọdún 2012, ó tó ọgọ́ta [60] àwọn ará abúlé tó
wá síbi ìpàdé tí wọ́n ṣe nínú ilé alámọ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé David.“Ìwọ Náà Lo Bíbélì Tìẹ Láti Fi Já Irọ́ Ẹ̀”
Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Janet lórílẹ̀-èdè Gánà. Ó ń ka ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bó ṣe ń rìnrìn-àjò gígùn kan lọ nínú ọkọ̀ èrò tó wọ̀. Oníwàásù kan wọnú ọkọ̀ náà, ó sì ń wàásù fáwọn èrò ọkọ̀, bó ṣe parí, ó ní káwọn èèyàn fowó ṣètọrẹ fóun. Janet wá sọ pé: “O sọ pé ọ̀kan náà ni Jésù àti Ọlọ́run. Ta ló wá bá Jésù sọ̀rọ̀ nígbà tó ṣèrìbọmi?”
Oníwàásù yẹn sọ pé àdìtú lọ́rọ̀ náà, pé kò sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n
Janet ṣí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni sí orí Kẹrin, ó tọ́ka sáwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan, ó sì ní káwọn èrò ọkọ̀ kan kà á. Ó wá ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jésù àti Ọlọ́run Alágbára ńlá gbogbo tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà.
Oníwàásù náà sọ pé, “Àjẹ́ ni ọ́.”
Làwọn èrò inú ọkọ̀ náà bá dẹnu bo oníwàásù náà pé, “Ìwọ náà lo Bíbélì tiẹ̀ láti fi já irọ́ rẹ̀. Má pè é lájẹ̀ẹ́ rárá.” Inú bí oníwàásù náà, ó sì yára bọ́ọ́lẹ̀ ní ibùdókọ̀ kan. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jókòó ti Janet sọ fún pé: “Èmi rò pé ṣọ́ọ̀ṣì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lọ ni wọ́n ń pè ní Jèhófà ni. Òní ni mo tó wá mọ̀ pé orúkọ Ọlọ́run ni.”
Bí wọ́n ṣe jọ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nìyẹn, Janet wá gba nọ́ńbà fóònù obìnrin yẹn, ó sì ṣèlérí fún pé òun máa kàn sí i. Nígbà tí obìnrin náà délé, ó sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ìyá rẹ̀ àgbà. Ó ya ìyá àgbà lẹ́nu láti gbọ́ pé orúkọ Ọlọ́run ló ń jẹ́ Jèhófà. Nígbà tó yá, Janet ṣètò báwọn Ẹlẹ́rìí míì á ṣe máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ obìnrin náà àti ìyá rẹ̀ àgbà lọ. Ní báyìí, àwọn méjèèjì ti ń wá sípàdé.
-
ILẸ̀ 57
-
IYE ÈÈYÀN 946,087,916
-
IYE AKÉDE 3,861,145
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 4,196,922
Ibi Tí Kò Fọkàn sí Ló Ti Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́
Ọmọ ogún ọdún ni ọmọbìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Andrea nígbà tí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Bọ̀lífíà. Ikun imú tọ̀tún àwọn wọ́dà fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí tòsì kí wọ́n tó lè tì í mọ́ ẹ̀wọ̀n torí pé bí wọ́n ṣe ń gbé e lọ, bẹ́ẹ̀ ló ń ṣépè tó sì ń halẹ̀. Fìrìgbọ̀n ẹ̀ bani lẹ́rù, kò sẹ́ni tó lè kò ó lójú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà, ó sì tún lágbára. Obìnrin kan wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yẹn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, orúkọ rẹ̀ ni Leidy,
kò mọ́wọ́ kò mẹ́sẹ̀ lórí ẹ̀sùn tó gbé e dé ẹ̀wọ̀n. Obìnrin yìí kì í bẹ̀rù Andrea, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń káàánú rẹ̀. Láràárọ̀, Leidy máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ orin tó wà nínú ìwé orin wa jáde. Lọ́jọ́ kan tọ́rọ̀ náà ta sí Andrea létí, ó béèrè pé, “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín ni?”Leidy dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, Andrea wá sọ pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mọ́mì mi náà, mo sì máa ń tẹ̀ lé wọn lọ sípàdé nígbà kan. Wọ́n tún máa ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ni Andrea bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Bí Leidy ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá Andrea sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ nìyẹn o, ọ̀rọ̀ yìí sì máa ń wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Nígbà tí àkókò tó láti dá ẹjọ́ Andrea, àwọn méjèèjì gbàdúrà pé kí Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà, kó sì tọ́ àwọn sọ́nà. Wọ́n dá Andrea sílẹ̀, ó sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó. Kò pẹ́ rárá tó fi di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Kódà, kò ní pẹ́ ṣèrìbọmi.
Leidy ò kárí sọ torí pé wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án, ó lo àǹfààní yẹn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kànlélógún [21] kó tó di pé wọ́n dá a sílẹ̀. Ní báyìí, ó máa ń pa dà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀ láti lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
Ẹ Wo Ohun Tí Ìkànnì www.pr418.com Ṣe
Lọ́jọ́ Sunday kan lọ́dún 2011, ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Marc-André àti ìyàwó rẹ̀ Josée àtàwọn ọmọ wọn múra dáadáa, wọ́n sì gbọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba kan lọ lórílẹ̀-èdè Kánádà. Àwọn ará rò pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá láti ìlú míì ni wọ́n. Àmọ́ lójú ẹsẹ̀ tí Dominic, tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ níjọ yẹn àti ọkùnrin tóun àti ìdílé ẹ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ríra ni wọ́n ti dá ara wọn mọ̀. Dominic ti kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọdún
mẹ́tàdínlógún [17] sẹ́yìn. Láti ọdún méjì sẹ́yìn ni tọkọtaya yìí ti máa ń wa Ilé Ìṣọ́ àti Jí! jáde lórí Ìkànnì www.pr418.com ó sì ti wá yé wọn pé ṣe ló yẹ kí gbogbo àwọn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Látìgbà yẹn, ìdílé náà ò pa ìpàdé kankan jẹ. Kò ju oṣù méjì péré tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ táwọn náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Ìjọsìn Ìdílé wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wọ́n tẹ̀ síwájú dáadáa, nígbà tó sì di May ọdún 2012, Josée ṣe iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.‘Ó Fún Mi lóúnjẹ, Ó sì Tún Fún Mi ní Àkẹtẹ̀ Rẹ̀’
Nígbà tí ọmọ ọdún mẹ́wàá kan tó ń jẹ́ Marcelo lọ sí àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2010 ní orílẹ̀-èdè Chile, ó rí i pé kò síwèé kankan lọ́wọ́ bàbá àgbàlagbà kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Victor lorúkọ bàbá àgbàlagbà yìí.
Ló bá sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí màmá rẹ̀ létí pé, “Bàbá yìí ò ní Bíbélì.”
Ìyá rẹ̀ náà dáhùn pé, “Ẹ jọ máa lo tìẹ.” Ni Marcelo bá sún mọ́ ọn kí wọ́n lè jọ máa lo Bíbélì tirẹ̀, ó sì ń ṣí gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá pè. Nígbà tí àsìkò ìsinmi ọ̀sán tó, Marcelo sọ fún màmá rẹ̀ pé: “Wọn ò mà lóúnjẹ ọ̀sán.” Màmá rẹ̀ ni kó fún bàbá náà lára oúnjẹ rẹ̀. Ni Marcelo bá fún bàbá náà lára oúnjẹ ọ̀sán rẹ̀. Bí bàbá náà ṣe ń jẹun rẹ̀ lọ, Marcelo ń fi gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè rántí hàn án látinú Bíbélì.
Nígbà tó di ọ̀sán, oòrùn tó mú kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Marcelo bá tún sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Mọ́mì, wọn ò ní àkẹtẹ̀.”
Màmá rẹ̀ sọ fún un pé: “Fún wọn ní tìẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí àpéjọ parí Marcelo àti bàbá náà dágbére fún ara wọn.
Nígbà àpéjọ ọdún tó tẹ̀ lé e, Marcelo wò káàkiri bóyá òun á rí bàbá náà. Inú ẹ̀ dùn láti rí i. Lọ́tẹ̀ yìí,
bàbá náà múra dáadáa, ó de táì! Bí bàbá yìí ṣe tajú kán rí Marcelo, ó sọ fún àwọn tó wà nítòsí pé: “Ọmọkùnrin yìí ló jẹ́ kí n wà níbí lónìí. Ẹnì kan ló fìwé pè mí wá sí àpéjọ àgbègbè lọ́dún tó kọjá, mo sì wá. Àmọ́ ọmọkùnrin yìí ló ń ṣí Bíbélì rẹ̀ fún mi tá a jọ ń kà á, ó fún mi lára oúnjẹ ọ̀sán ẹ̀, ó sì tún fún mi ní àkẹtẹ̀. Èmi rèé lónìí, mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!” Bàbá ọjọ́sí mà ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi báyìí.Akọ̀ròyìn Kan Yìn Wá
Obìnrin kan wà tó jẹ́ gbajúgbajà akọ̀ròyìn ní orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà. Ó kọ ohun tí ojú rẹ̀ rí sínú abala tó máa ń kọ ìròyìn sí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé nígbà tó pe ilé iṣẹ́ fóònù kan láti sọ ìṣòro tó ní pẹ̀lú fóònù rẹ̀ fún wọn, ẹni tó gba ìpè rẹ̀ kàn dá a lóhùn ṣákálá, kò bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, èyí ò sì jẹ́ kí akọ̀ròyìn yìí rí ojútùú sí ìṣòro rẹ̀. Ló bá tún pè pa dà lẹ́ẹ̀kejì, lọ́tẹ̀ yìí, ọ̀dọ́kùnrin kan tó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Misael ló gbé e, ó dá a lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bá a yanjú ìṣòro rẹ̀. Obìnrin yìí wá kọ̀wé pé: “Bí ọ̀dọ́kùnrin yìí ṣe ní sùúrù fún mi, tó dá mi lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tó sì fara balẹ̀ gbọ́ mi títí tí mo fi sọ ohun tó jẹ́ ìṣòro mi jọ mí lójú gan-an. Òun ló ràn mí lọ́wọ́ tí ìṣòro mi fi yanjú tó sì tún jẹ́ kí n mọ ohun tí mo lè ṣe tírú ẹ̀ bá tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”
Nígbà tí obìnrin náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin yìí fún òun to ṣe, ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé torí pé òun jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun máa ń fẹ́ hùwà tó dáa sáwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ pé ká máa ṣe. Akọ̀ròyìn náà sọ pé òun fẹ́ bá ọ̀gá Misael sọ̀rọ̀, ó sì sọ̀rọ̀ Misael dáadáa lójú ọ̀gá náà pé òun mọrírì ohun tó ṣe. Nígbà tó yá, ó gbé e jáde nínú ìròyìn, ó sọ pé, ọmọ Fẹnẹsúélà rere ni Misael àti pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ni. Ó wá kádìí ìròyìn rẹ̀ pé: “Irú èèyàn tá a fẹ́ kó wà ní gbogbo ilé iṣẹ́ tó ń gbọ́ tara ìlú rèé.”
“Ẹ Má Ya Aláìgbọràn!”
Ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan wà tó ń jẹ́ Gabriela, ó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ecuador. Adití ni, inú ẹ̀ sì dùn gan-an nígbà tó ṣèrìbọmi ní October 2011 ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ti sọ èdè adití. Inú ẹ̀ dùn débi pé nígbà tó pa dà síléèwé rẹ̀ ní ọjọ́ Monday, ó sọ fún olùkọ́ rẹ̀ pé kó jẹ́ kí òun sọ ohun kékeré kan fáwọn ọmọ kíláàsì òun. Olùkọ́ rẹ̀ gbà, Gabriela bá dúró níwájú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi tayọ̀tayọ̀ bá wọn sọ̀rọ̀ lédè adití, ó sọ pé: “Inú mi dùn láti sọ fún yín pé ní ọjọ́ Friday, Saturday, àti Sunday tó kọjá yìí, mo lọ sí àpéjọ àgbègbè, mo sì ti ṣèrìbọmi, mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a ti wà lákòókò òpin. Àkókò tó kù ti dín kù gan-an! Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ tètè yí pa dà.
Ẹ má ya aláìgbọràn o. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run!” Ohun tó sọ yìí wú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ lórí.Nígbà tó di àkókò oúnjẹ ọ̀sán, ọmọbìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Katty wá bá a. Adití lòun ná, Ẹlẹ́rìí sì ni, àmọ́ kò ṣe dáadáa mọ́. Ó wá bá Gabriela kó lè béèrè nípa àpéjọ àgbègbè náà. Àmọ́ Gabriela sọ fún ní tààràtà pé: “Ó dùn joyin lọ! Ṣó o mọ̀ pé mo ti ṣèrìbọmi, mo sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí láé. Torí náà, mo fẹ́ kó o mọ̀ pé èmi àtìẹ ò lè ṣọ̀rẹ́ mọ́, torí ìgbésí ayé tí kò mọ́ lò ń gbé, ó sì lè kó bá àjọṣe èmi àti Ọlọ́run. Àfi kó o yí pa dà o. Ó ṣe pàtàkì pé kó o tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà kó o sì lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà. Mo mọ̀ pé o ṣì lè yí pa dà.” Ọ̀rọ̀ tó sojú abẹ níkòó, àmọ́ tó fi ìfẹ́ tí Gabriela ní sí Katty hàn yìí mú kó tọ àwọn alàgbà lọ, wọ́n ràn án lọ́wọ́, ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí.
Ó Lo Kọ̀ǹpútà Alágbèéká Olùkọ́ Rẹ̀
Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìndínlógún kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́jọ́ kan, gbogbo ọmọ kíláàsì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ó nípa ẹ̀sìn rẹ̀, àmọ́ kò ní ìwé wa kankan lọ́wọ́, kò tiẹ̀ mú Bíbélì dáni pàápàá. Ló bá yá kọ̀ǹpútà olùkọ́ rẹ̀ kó lè fi wọ Ìkànnì www.pr418.com, torí pé ó fẹ́ kí wọ́n rí ìdáhùn látinú Ìwé Mímọ́. Ó dáhùn gbogbo ìbéèrè wọn, ó tún kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lo ìkànnì náà. Ó sọ fún wọn pé nígbàkigbà tí ohunkóhun bá rú wọn lójú látinú Bíbélì, tí kò sì sí Ẹlẹ́rìí kankan nítòsí tó lè ṣàlàyé fún wọn, wọ́n lè lọ sórí ìkànnì wa, wọ́n á rí ìdáhùn níbẹ̀. Nígbà tó yá, ó kíyè sí i pé àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ béèrè ìbéèrè mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Ó bi wọ́n pé kí lò ó fà á tí wọn ò fi béèrè ìbéèrè mọ́, ohun tí àwọn kan sọ ni pé àwọn ń wọ Ìkànnì jw.org lórí fóònù àwọn, àwọn sì ń rí ìdáhùn táwọn fẹ́ níbẹ̀. Olùkọ́ wọn gan-an náà ti ń ṣe bẹ́ẹ̀!
-
ILẸ̀ 48
-
IYE ÈÈYÀN 4,222,869,785
-
IYE AKÉDE 674,608
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 662,736
Ìwé Tí Kò Jẹ́ Kí Ìjà Ìgboro Bẹ́ Sílẹ̀
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń rìnrìn àjò gba abúlé kan lórílẹ̀-èdè Indonesia, wọ́n fẹ́ lọ ibi ìsìnkú. Bí wọ́n ṣe ń lọ, aṣáájú-ọ̀nà kan bá àwọn ọ̀dọ́ kan tó kóra jọ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà sọ̀rọ̀, ó sì fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọrun Kó O Lè Wà Láàyè. Láìpẹ́ sígbà náà,
arábìnrin wa kan gba ọ̀nà yẹn pa dà bó ṣe ń lọ ilé rẹ̀. Lọkùnrin kan bá lọ bá arábìnrin wa yìí, tòun ti ìwé pẹlẹbẹ náà lọ́wọ́, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó fún àwọn ọmọ òun ní ìwé náà. Ọkùnrin náà sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ ìwé yìí ni ò jẹ́ kí n ṣòfò ọmọ!” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arábìnrin wa yìí ò mọ Ẹlẹ́rìí tó fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ náà, ó béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà. Bàbá àwọn ọmọ yìí sọ pé àwọn ọmọ òun fẹ́ lọ fa wàhálà ní abúlé kan. Ṣe ni wọ́n fẹ́ lọ gbẹ̀san ìwà àìdáa kan tí wọ́n hù sí ọ̀rẹ́ wọn, torí pé àṣà àwọn nìyẹn ládùúgbò náà. Àmọ́ nígbà táwọn ọmọ náà ka ìwé pẹlẹbẹ yìí, wọ́n rí i níbẹ̀ pé àwọn tó bá ń jà ò ní jogún Párádísè tó ń bọ̀. Torí náà, inú wọn rọ̀, wọ́n sì pa dà sílé, wọn ò fa wàhálà náà mọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí ni ò jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín ìlú méjì, èyí tó lè yọrí sí ìpakúpa.Ọkùnrin Kan Tó Ń Ṣe bí Obìnrin Yí Pa Dà
Ilé rere ni wọ́n ti bí Rek ní orílẹ̀-èdè Cambodia. Ọkùnrin ni, àmọ́ láti kékeré lòun àti ìbejì ẹ̀ tóun náà jẹ́ ọkùnrin ti gbà pé obìnrin làwọn. Wọ́n gbádùn kí wọ́n máa fi bèbí ṣeré, wọ́n sì máa ń múra bí obìnrin. Èyí rú ìyá wọn lójú, ó tiẹ̀ ń kó ìtìjú bá a, kò sì mọ bó ṣe máa gba àṣà náà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n á múra bí ọkùnrin kúrò nílé tí wọ́n bá ń lọ síléèwé, àmọ́ gbàrà tí wọ́n bá ti dé iléèwé, wọ́n á kó sí aṣọ obìnrin. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] làwọn ìbejì náà tí wọ́n ti lọ ṣe ìdíje àwọn ọkùnrin tó ń ṣe bí obìnrin. Àwọn ilé iṣẹ́ amúlùúdùn kan ló ṣètò rẹ̀. Ètò yìí àtàwọn ètò apanilẹ́rìn míì ló jẹ́ kí wọ́n dẹni àpéwò lórí tẹlifíṣọ̀n. Kò pẹ́ tí Rek
fi di abẹ́yà-kan-náà lòpọ̀, àwọn ọkùnrin tó ń ṣe bí obìnrin ló sì ń bá ṣọ̀rẹ́.Ìyá Rek bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì ní kí Rek náà máa tẹ̀lé òun. Ó gbà láti máa wọṣọ ọkùnrin, àmọ́ kò gbà láti gé irun rẹ̀ tó gùn bíi ti obìnrin. Pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ máa ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí Rek, ó sì máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí irú ìgbésí ayé tó ń gbé. Rek ò fi ṣèbínú, ó ṣì gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣọ́ọ̀ṣì yìí. Lọ́sẹ̀ àkọ́kọ́ tó lọ, ó fi kẹ̀kẹ́ rin ìrìn-àjò ọ̀pọ̀ kìlómítà, àmọ́ pásítọ̀ náà sọ pé òun ò lè kọ́ irú èèyàn bíi tiẹ̀ ní nǹkan kan. Ohun kan náà ló tún ṣẹlẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, inú bá bí Rek.
Nígbà tí Rek fi máa pa dà délé, ìbejì rẹ̀ sọ fún un pé obìnrin kan wá, ó sì sọ pé òun á máa kọ́ àwọn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Obìnrin náà fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Arábìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ìbejì náà lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́, ìbejì Rek pinnu pé òun ò ṣe tán láti yí ìgbésí ayé òun pa dà, kò sì ṣèkẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Àmọ́ ohun tí Rek kà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10 wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ohun tó yẹ kó ṣe sì wá ṣe kedere sí i. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ gidi mú ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, ó ń ka Bíbélì déédéé, ó máa ń gbàdúrà, kò sì fi ìpàdé ṣeré. Àwọn nǹkan yẹn ló ràn án lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Ìyá Rek náà ń kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Nígbà tí Rek ṣèrìbọmi, omijé ayọ̀ bọ́ lójú ìyá rẹ̀, ó sọ pé, “Inú mi dùn láti rí ọmọ mi tó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin.” Ní báyìí, Rek ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
Ìyálóòṣà Kan Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ìyálóòṣà paraku ni Or-Ya, ó máa ń ṣèwòsàn, ó ń gbani nímọ̀ràn, ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀. Lọ́jọ́ kan, tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń sìn nílùú Haifa, lórílẹ̀-èdè Israel wàásù fún obìnrin yìí nígbà tí wọ́n ń wàásù
láti ilé dé ilé. Ó sọ fún wọn nígbà tó ń kí wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ fẹ́ sọ, ẹ máa wọlé bọ̀!” Ṣe nilé rẹ̀ kún fàwọn nǹkan abàmì lóríṣiríṣi tó fi ń bọ̀rìṣà, àtèyí tó fi ń bọ àwọn baba ńlá tó ti kú. Ó lóun máa ń gbóhùn Ọlọ́run, nígbà míì, ó lè jẹ́ nípasẹ̀ baba ńlá wọn kan tó ti kú.Inú ẹ̀ dùn nígbà tí wọ́n sọ fún un pé wọ́n á máa fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ìwòyí ìjẹ́ta, káwọn tọkọtaya náà tó wà sílé ẹ̀, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rán ẹnì kan tó lè kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sóun, àmọ́ kó má ṣe jẹ́ irú ẹ̀kọ́ táwọn olórí ẹ̀sìn wọn, tí wọ́n ń pè ní rábì, máa ń kọ́ni. Láàárín oṣù kan tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, ó béèrè pé: “Ṣé àwọn míì tún wà tó ń ṣe ẹ̀sìn yìí?” Ó lọ sípàdé, inú ẹ̀ sì dùn sí báwọn ara ṣe gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀ àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí i. Látìgbà yẹn, kò pa ìpàdé kankan jẹ.
Lẹ́yìn oṣù méjì tí Or-Ya ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ó béèrè ìbéèrè kan nípa àpéjọ tó ń bọ̀ lọ́nà, ó ní: “Ṣebí àpéjọ ni èèyàn ti máa ń ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, oṣù méjì péré ló kù, ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé mo ṣèrìbọmi!” Ohun tó kọ́kọ́ ṣe ni pé ó kó gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ òrìṣà rẹ̀ dà nù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó ńlá ló fi rà wọ́n. Lẹ́yìn náà, ó jáwọ́ nínú iṣẹ́ náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn èèyàn. Ó máa ń fún àwọn aláìsàn tó ń tọ́jú tẹ́lẹ̀ àtàwọn oníbàárà rẹ̀ ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kódà nígbà tó ṣàìsàn, kò lo ẹ̀mí èṣù tó ń lò tẹ́lẹ̀ láti fi wo ara rẹ̀ sàn. Odindi oṣù mẹ́rin gbáko ni ọ̀dá owó fi dá a torí pé kò ṣiṣẹ́ tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Pẹ̀lú bí kò ṣe níṣẹ́ lọ́wọ́ yìí, ó tún lójú iṣẹ́ tó fẹ́ láti ṣe, ìyẹn iṣẹ́ tí kò ní ju ọjọ́ mẹ́rin lọ lọ́sẹ̀, tó sì máa jẹ́ wákàtí mẹ́fà lójúmọ́, kí òun lè ráyè fi èyí tó kù ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́,
ìpàdé àti òde ẹ̀rí. Ó sì rí irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tó yá. Lẹ́yìn náà, ó ta ilé ńlá tó ní, ó sì lọ gba ilé tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi.Nígbà tó yá, Or-Ya tóótun láti ṣèrìbọmi, àmọ́ nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n lọ sí àpéjọ, ó fẹsẹ̀ dá. Kò jẹ́ kíyẹn dí i lọ́wọ́, ó ṣèrìbọmi náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sìmẹ́ǹtì ẹsẹ̀ rẹ̀. Ní báyìí, akéde tó nítara gan-an ni Or-Ya, ó máa ń jẹ́rìí fáwọn oníbàárà rẹ̀ àtijọ́, ó sì ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ọmọ Ẹgbẹ́ Òkùnkùn Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Àwọn ìbejì kan tí wọ́n jẹ́ adití ń gbé ní àdádó kan níbi tí òkè wà lórílẹ̀-èdè Philippines. Àwọn ìbejì náà wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn kan tí wọ́n gbà pé kò sí nǹkan ìjà èyíkéyìí tó lè ràn wọ́n tí wọ́n bá ṣáà ti wọ ońdè, tí wọ́n sì wé aṣọ péńpé kan mórí. Wọ́n ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè fi ọ̀bẹ, àdá àti ìbọn jà, wọ́n sì ti ja àìmọye ìjà pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ míì lágbègbè tí wọ́n ń gbé. Àwọn ará bá wọn pàdé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ìbejì náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹgbẹ́ awo tí wọ́n ń ṣe gbà wọ́n láàyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí ò ní fipá mú àwọn ìbejì náà láti fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.
Àmọ́ àwọn ará rọ àwọn ìbejì náà pé kí wọ́n ronú lórí àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ látinú Bíbélì kí wọ́n sì ṣèpinnu fúnra wọn. Ọ̀kan nínú ìbejì náà ronú pé kò dájú pé òun á lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó yẹ, torí pé òun ò ṣe tán láti yí ìgbésí ayé òun pa dà. Àmọ́, ìkejì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. Nígbà tí arákùnrin tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ gbà á níyànjú, ó ka ibì kan nínú Bíbélì, ó sì ṣàlàyé fún un ní èdè àwọn adití pé: “Orúkọ ẹ ni Samuel, ó wà nínú Bíbélì. Sámúẹ́lì tó wà nínú Bíbélì sin Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ títí di ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ìwọ náà lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó o ṣègbọràn sí i.” Ọ̀rọ̀ yìí wọ Samuel lọ́kàn gan-an. Ó wá rò ó pé: “Tí orúkọ mi bá wà nínú Bíbélì, a jẹ́ pé èmi
náà gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà.” Ló bá sọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ pé òun fẹ́ kúrò lágbègbè náà, ó dáná sun gbogbo ońdè àtàwọn nǹkan míì tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ òkùnkùn, ó sì wá ń ṣe dáadáa. Ní báyìí, ó ti ṣèrìbọmi, ó sì ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń fìtara ran àwọn adití míì lọ́wọ́ káwọn náà lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Ọmọdé Kan
Rajiv ń gbé ní abúlé oko kan ní ìwọ̀ oòrùn Íńdíà. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án, tó sì wà ní kíláàsì kẹrin nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, olùkọ́ kan níléèwé rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
láti fi kọ́ àwọn ọmọ iléèwé náà ní ìwà ọmọlúàbí. Inú Rajiv dùn gan-an sí òun tó kọ́ yìí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi hùwà. Ó sọ fún olùkọ́ rẹ̀ pé òun ò parọ́ mọ́, òun ò bá àwọn ọmọ iléèwé òun jà mọ́, òun sì máa ń fún ẹni tí kò bá ní oúnjẹ ọ̀sán lára oúnjẹ òun.“Ẹ ti fipá tẹ orí mi ba níwájú ère yìí, àmọ́ ẹ ò lè fipá yí ọkàn mi pa dà”
Bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run pé ayé máa tó di Párádísè, bẹ́ẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìròyìn ayọ̀ yìí fáwọn ará abúlé ẹ̀ àti nígbà tó bá wà nínú ọkọ ojú irin. Ohun tí ọmọ yìí ń ṣe bí àwọn òbí rẹ̀ nínú, ó sì ń dójú tì wọ́n. Wọ́n sọ fún un pé àwọn ò gbọ́dọ̀ gbọ́rọ̀ Jèhófà àti Jésù lẹ́nu rẹ̀ mọ́. Wọ́n nà án nígbà tó kọ̀ tí kò jáwọ́, ìyá rẹ̀ tiẹ̀ máa ń kó aṣọ ẹ̀ pamọ́ tó bá ti dé láti iléèwé torí kó má bàa lè jáde láti sọ ẹ̀kọ́ tó ṣẹ̀sẹ̀ kọ́ yìí fáwọn èèyàn. Wọn ò jẹ́ kó sùn lórí bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ mọ́, wọn sì ń febi pa á. Ìgbà tí gbogbo èyí ò tu irun kan lára ọmọ yìí, wọ́n pe babalóòṣà kan pé kó báwọn yí i lọ́kàn pa dà.
Babalóòṣà náà lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ nílé àwọn Rajiv níbi tó ti fẹ́ fi fipá mú kí Rajiv wolẹ̀ fún ère kan. Rajiv sọ fún babalóòṣà náà pé òkúta lásán ni ère náà àti pé kò lẹ́ẹ̀mí, babalóòṣà wá sọ fún Rajiv pé kó fi ojú ẹ̀mí wò ó, á rí i pé òkúta lásán kọ́ láwọn gbé sílẹ̀. Rajiv wá kọ 100 rupees sórí bébà kékeré kan, bí ìgbà téèyàn kọ ọgọ́rùn-ún naira. Ó mú un fún bàbá náà pé kó bá òun fi ra súìtì wá kó sì gba ṣéńjì bọ̀. Babalóòṣà náà sọ pé nígbà tóun kì í ṣe dìndìnrìn, pé bébà lásán ló gbé lé òun lọwọ́. Rajiv sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá fi ojú ẹ̀mí wo bébà yìí, ẹ̀ẹ́ rí i pé owó gidi ni mo fún yín.” Inú bí babalóòṣà yìí, ló bá fipá tẹ orí Rajiv mọ́lẹ̀ níwájú ère náà. Rajiv sọ pé: “Ẹ ti fipá tẹ orí mi ba níwájú ère yìí, àmọ́ ẹ ò lè fipá yí ọkàn mi pa dà.” Ìgbà tó sú babalóòṣà yìí, ó lóun ń lọ, pé òun
ò lágbára àtiyí ọmọ náà lọ́kàn pa dà àti pé tí òun bá pẹ́ ju báyìí lọ nílé wọn, ọmọ náà ló máa yí òun lọ́kàn pa dà. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, àwọn òbí Rajiv mú un lọ síléèwé míì. Àmọ́, ọmọ yìí ṣì ń sọ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ gbọ́ nípa Jèhófà àti ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti sọ ayé di Párádísè. Ó ti pé ọmọ ọdún mẹ́wàá báyìí. Ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa gbára lé Jèhófà kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.Ó Rí Bíbélì Tó Ń Wá
Bí Larisa tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Armenia ṣe ń wàásù fún òṣìṣẹ́ ilé ìtàwé kan, obìnrin kan wọlé, ó lóun fẹ́ ra Bíbélì “Ayé Tuntun.” Òṣìṣẹ́ náà sọ fún un pé òun kò ní, àmọ́ òun ní Bíbélì míì tí wọ́n fi èdè Armenia kọ. Obìnrin tó fẹ́ ra Bíbélì náà béèrè pé, “Ṣé Bíbélì náà rọrùn láti kà?” Òṣìṣẹ́ ilé ìtàwé náà ka ẹsẹ díẹ̀ nínú Bíbélì náà, ó sì sọ pé, “Ó jọ pé ó yéèyàn.” Àmọ́ èyí ò tẹ́ obìnrin náà lọ́rùn, ó sọ pé Bíbélì “Ayé Tuntun” gangan lòun fẹ́. Larisa wá rántí pé Bíbélì òun wà nínú báàgì òun. Ó fi han obìnrin náà, ó sì sọ pé kó ka àkọlé rẹ̀. Ló bá kà á jáde: “Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.” Bíbélì tí obìnrin náà ń wá gan-an nìyí!
Obìnrin náà ṣàlàyé pé ọmọ òun àti ọkọ rẹ̀ tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Gíríìsì sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí pé wọn ò sì tíì kọ́ èdè Gíríìkì, wọ́n ní kí ìyá àwọn mú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Armenia bọ̀ tó bá fẹ́ wá kí àwọn. Larisa fún obìnrin yìí ní Bíbélì náà, ó wá sọ pé, “Ẹ fún wọn ní Bíbélì yìí, kẹ́ ẹ sì sọ fún wọn pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni.” Inú obìnrin náà dùn gan-an nígbà tí Larisa tún sọ pé òun lè wá máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n gba nọ́ńbà fóònù ara wọn torí kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní gbàrà tí obìnrin náà bá dé láti orílẹ̀-èdè Gíríìsì.
-
ILẸ̀ 47
-
IYE ÈÈYÀN 738,679,198
-
IYE AKÉDE 1,595,888
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 841,260
Ó Dá Pọ́ọ̀sì Pa Dà
Aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bosnia ń kọ́ ìdílé kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́jọ́ kan, ọmọ wọn obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá rí pọ́ọ̀sì kan nílẹ̀ẹ́lẹ̀ tí owó, káàdì tí wọ́n fi ń gba owó àtàwọn ìwé míì wà nínú rẹ̀. Ká ní ìgbà tí kò tíì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló rí pọ́ọ̀sì yìí ni, ì bá kà á sí pé òun rìnnà kore, àmọ́ lẹ́yìn tó sọ fún màmá rẹ̀, ó mú pọ́ọ̀sì náà lọ fún
ọlọ́pàá. Ohun tí ọmọ yìí ṣe wúni lórí gan-an torí pé nǹkan ò rọrùn fún ìdílé náà, kódà àtirówó jẹun fún wọn gan-an máa ń nira. Ẹnu ya ọlọ́pàá tí wọ́n fún ní pọ́ọ̀sì náà gan-an. Ní nǹkan bíi wákàtí méjì lẹ́yìn náà, wọ́n pè wọ́n pé kí wọ́n máa bọ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá. Ẹni tó ni pọ́ọ̀sì náà fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn kó sì fi ìmọrírì hàn. Tá a bá ṣẹ́ owó tó fún wọn sówó náírà, ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé àádọ́ta [4,650] náírà, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí owó iṣẹ́ ọjọ́ méjì lórílẹ̀-èdè Bosnia.Àkòrí Náà Wọ̀ Ọ́ Lọ́kàn
Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ tá a fẹ́ sọ nípa rẹ̀ yìí jẹ́ fun Nihad tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bosnia. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣíwọ́ lóde ẹ̀rí ni. Bó ṣe sún mọ́ ọkọ̀ rẹ̀, ó rí i pé ọkùnrin kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ náà. Ó kí i, ọkùnrin náà sì sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má bínú o, mo rí àkọlé kan lẹ́yìn ìwé tó wà nínú ọkọ̀ yìí tó ní, ‘Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere.’ Mo fẹ́ kẹ́ ẹ fún mi ni. Ó ti tó wákàtí kan tí mo ti ń dúró de ẹni tó ni ọkọ̀ yìí. Ẹ jọ̀ọ́, ṣẹ́ ẹ lè fún mi?” Nihad fún un ní ìwé náà, ó sì tún fi àǹfààní yẹn wàásù fún ọkùnrin náà.
Àwọn Òṣìṣẹ́ Ọkọ̀ Okùn Kan Rí Ìtùnú
Tọkọtaya kan tó ń wàásù ní etíkun kan nílùú Rotterdam lórílẹ̀-èdè Netherlands lọ sídìí ọkọ̀ òkun kan, wọ́n sì rí i tí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ náà kárísọ. Pẹ̀lú omijé lójú ni ọ̀gákọ̀ náà fi ṣàlàyé fún wọn pé ṣe ni àjálù kan ń ré lu òmíì látìgbà táwọn ti wà lójú omi, ó ní ó kù díẹ̀ kí ọkọ̀ àwọn larí mọ́ ọkọ̀ míì, ọkọ̀ àwọn sì ti bà jẹ́ gan-an. Ó wá sọ pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbàdúrà fún wa.” Tọkọtaya náà ṣèlérí fáwọn òṣìṣẹ́ náà pé àwọn á wá sọ
àsọyé atunilára kan fún wọn. Láago méje ìrọ̀lẹ́ lọ́jọ́ kejì, tọkọtaya náà àtàwọn tọkọtaya méjì míì lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ okùn yìí, wọ́n sì mú wọn wọlé lọ síwájú níbi tí wọ́n ti ń tukọ̀ náà. Àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́rìndínlógún ló ti wà níkàlẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n gbàdúrà ìbẹ̀rẹ̀, arákùnrin kan sọ̀rọ̀ lórí kókó tó dá lórí bóyá àmúwá Ọlọ́run làwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀. Àwọn akéde náà kó Bíbélì tó pọ̀ tó dání. Torí náà, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ló ní Bíbélì, wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ náà ló ṣì wà lórí ìjókòó lẹ́yìn àdúrà ìparí, wọ́n ń bá àwọn akéde náà sọ̀rọ̀. Inú àwọn atukọ̀ náà dùn, ọkàn wọn sì fúyẹ́. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Ohun tá à ń gbàdúrà fún gan-an nìyí.” Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba ogún ìwé, wọ́n sì tún gba Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì. Ọ̀gákọ̀ náà wá fún àwọn akéde náà ní àpòòwé tówó wà nínú rẹ̀ láti fi ṣètìlẹ́yìn fáwọn ìwé tí wọ́n gbà. Iye náà ni igba [200] dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31,000] náírà.Ó Gbàdúrà Pé Kóun Lè Rẹ́ni Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Irene tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sweden kọ̀wé pé: “Ọmọ ọgọ́rin [80] ọdún ni mi. Àìsàn ò sì jẹ́ kí n lè jáde òde ẹ̀rí mọ́. Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí n lè rí ẹnì kan tí mo ti dé ọ̀dọ̀ ẹ̀ rí tó má fẹ́ kí n máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
“Lọ́jọ́ kan, fóònù ilé wa dún, ọkọ mi sì gbé e. Obìnrin kan ló ń pè, ó ní: ‘Ẹ̀ jọ̀ọ́, ẹ máà bínú o, ẹ̀yin nìkan ni mo rántí, ìdí nìyẹn tí mo fi pè yín. Ẹ jọ̀ọ́, ṣé ìyàwó yín lè wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Mò ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ọdún sẹ́yìn, àmọ́ ọkọ mi gbógun tì mi, mo bá dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, àmọ́ ní báyìí ọkọ mi ti kú.’
“Mo rántí pé mo ti tẹ̀ lé arábìnrin tó ń bá a ṣe ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ síbẹ̀ rí. Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé obìnrin náà ṣì rántí mi. Inú mi dùn gan-an, mo bá tètè wá bí màá ṣe kàn sí i. Látìgbà yẹn, à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ó wá sí Ìrántí Ikú Kristi àti àkànṣe àsọyé. Bákan náà, ó máa ń wá sípàdé. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó dáhùn àdúrà mi.”
A Kì Í Fi Ṣokoléètì Sínú Àpótí Ọrẹ
Sergio, ọmọ ọdún mẹ́jọ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ítálì fẹ́ káwọn alàgbà mọ̀ lóòótọ́ pé òun ti ṣe tán láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Lọ́jọ́ kan ó tẹ̀ lé bàbá rẹ̀ lọ síbi iṣẹ́. Lọ́jọ́ yìí bàbá rẹ̀ lọ bá àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún ṣe kọ́kọ́rọ́ ilẹ̀kùn ilé wọn. Sergio ti kó ìwé ìròyìn sínú báàgì rẹ̀ lóríṣiríṣi. Ó sọ pé: “Bí bàbá mi ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ, mo lọ fún bàbá onílé náà ní ìwé ìròyìn. Ó yà á lẹ́nu gan-an débi pé ó pe ìyàwó rẹ̀, ó sì fàwọn ìwé náà hàn án. Mo wá béèrè orúkọ wọn àti àdírẹ́sì wọn àti nọ́ńbà fóònù wọn, kí n bàa lè pa dà wá ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ìyàwó rẹ̀ dá mi lóhùn gbogbo ohun tí mò ń béèrè, ó sì fún mi ní ṣokoléètì ńlá kan.” Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, alàgbà kan tẹ̀ lé Sergio láti lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tọkọtaya yìí. Sergio tẹ aago ẹnu ọ̀nà, ìyàwó ló dá a lóhùn, ó sì sọ fún un pé òun fẹ́ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Inú obìnrin náà dùn láti gbà á. Ó sì tún fún un ní ṣokoléètì ńlá kan. Sergio sọ pé, “Torí pé mi ò lè fi ṣokoléètì sínú àpótí ọ̀rẹ́, mo bá kúkú jẹ ẹ́. Àwọn alàgbà wá rí i pé ó wù mí gan-an láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.”
Pásítọ̀ Fẹ́ Mọ̀ Sí I
Pásítọ̀ ni Simeon tó ń gbé nílùú Gurkovo lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan nílùú yìí. Ohun tó ti kà nínú Bíbélì jẹ́ kó rí ìyàtọ̀ nínú ohun tí Bíbélì
sọ àti ohun táwọn pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ni. Lọ́jọ́ kan tó ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú irin, ó gba àwọn ìwé ìròyìn wa kan. Inú Simeon dùn láti mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti pé Ọlọ́run kì í ṣe mẹ́talọ́kan. Torí pé ó ń wù ú láti mọ púpọ̀ sí i, ó kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àti sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó mọ̀. Ṣọ́ọ̀ṣì kan ṣoṣo ló fèsì lẹ́tà rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé kó má dààmú ara rẹ̀ lórí ohun tí kò níláárí. Àmọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣètò pé káwọn arákùnrin láti ìlú Kazanlŭk rìnrìn àjò ọgbọ̀n kìlómítà lọ síbẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun àti ìdílé rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú Simeon dùn sí ohun tó ń kọ́ yìí, ó sì tún pe àwọn aládùúgbò àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé káwọn náà wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìpẹ́, èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ló ń wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí aládùúgbò rẹ̀ kan, ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] bá wọn jókòó síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fúngbà àkọ́kọ́, ó wá sọ pẹ̀lú omijé lójú pé: “Ohun tí mo kọ́ láàárín wákàtí kan yìí ju gbogbo ohun tí mo ti ń kọ́ láti ọgbọ̀n ọdún tí mo ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ.” Ó tó ọgọ́ta [60] èèyàn tó máa ń wá sípàdé táwọn arákùnrin láti ìlú Kazanlŭk máa ń ṣe nílùú Gurkovo lóṣooṣù. Èèyàn mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] ló sì wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.“Ohun tí mo kọ́ láàárín wákàtí kan yìí ju gbogbo ohun tí mo ti ń kọ́ láti ọgbọ̀n ọdún tí mo ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ”
“Jọ̀ọ́, Má Yíwà Pa Dà O”
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Valya ń gbé lórílẹ̀-èdè Ukraine. Lọ́jọ́ kan, ó kíyè sí i pé olùkọ́ òun kan wọ aṣọ dúdú wá síléèwé, ojú ẹ̀ sì fi hàn pé ó ń sunkún. Valya wá pa dà mọ̀ pé ìyá olùkọ́ òun yẹn ló kú, ó wá pinnu láti lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde láti fi tù ú nínú. Ló bá mú Bíbélì àti ìwé pẹlẹbẹ méjì, ìyẹn Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú? àti Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, ó sì pinnu pé òun máa lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ náà. Ó sọ pé: “Àyà mi bẹ̀rẹ̀ sí í já, bí mo ṣe dúró lẹ́nu ọ̀nà ọ́fíìsì wọn, mo bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́.”
Olùkọ́ náà béèrè lọ́wọ́ Valya ohun tó wá ṣe ní ọ́fíìsì òun.
Valya sọ pé, “Mo wá kí n lè tù yín nínú, torí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí yín ti ṣe èmi náà rí. Bàbá mi àgbà kú ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.”
Ohun tí Valya ṣe yìí jọ olùkọ́ rẹ̀ lójú gan-an. Olùkọ́ náà sọ pẹ̀lú omijé lójú pé kò sẹ́ni tó bá òun kẹ́dùn báyìí nínú àwọn ẹbí òun tàbí àwọn táwọn jọ ń ṣiṣẹ́. Valya wá ka ìwé Ìṣípayá 21:3, 4, ó sì ṣàlàyé rẹ̀. Olùkọ́ rẹ̀ gba àwọn ìwé pẹlẹbẹ tó kó wá fún un, ó sì sọ pé: “O yàtọ̀ pátápátá sáwọn ọmọléèwé tó kù.”
Valya sọ pé: “Mo máa ń sa gbogbo ipá mi láti máa ka Bíbélì, kí n sì máa fi ohun tí mo bá kà sílò, mo tún máa ń gbọ́rọ̀ sáwọn òbí mi lẹ́nu.”
Olùkọ́ náà béèrè àwọn ìwé míì, Valya bá mú Bíbélì àti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni wá fún un. Olùkọ́ náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Valya, ó sì sọ fún un pé: “Ẹ̀sìn tòótọ́ ni ẹ̀sìn tó ò ń ṣe, o sì láwọn òbí gidi tí wọ́n kọ́ ẹ ní ohun tó tọ́. Jọ̀ọ́, má yíwà pa dà o.”
Ọ̀tọ̀ Ni Nọ́ńbà Tó Pè
Ní àpéjọ àgbègbè ọdún 2011 tí wọ́n ṣe ní ìlú Malakasa lórílẹ̀ èdè Gíríìsì, Natalie fi fóònù rẹ̀ pe bàbá rẹ̀ lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà, ó fẹ́ sọ fún bàbá rẹ̀ nípa ọkọ̀ tó gbé àwọn wá sí àpéjọ náà. Àmọ́ ọ̀tọ̀ ni nọ́ńbà tó lọ pè, wọn ò sì gbé ìpè náà. Kò pẹ́ rárá tí ẹni tó ṣèèṣì pè náà fi pè pa dà kó lè mọ ẹni tó pe òun. Àmọ́ ìpàdé ti bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn, bí Natalie ṣe gbọ́ tí fóònù ẹ̀ ń dún, ló bá tẹ̀ ẹ́ láti pa á, àmọ́, kàkà kó pa á, ńṣe ló tẹ bọ́tìnnì téèyàn fi máa ń gba ìpè. Bí ẹni tó pè náà ṣe gbọ́ díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ alága àpéjọ náà nìyẹn látorí fóònù, èyí sì wọ̀ ọ́ lọkàn gan-an, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Natalie ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀.
Ọkùnrin tó pè pa dà náà wá tẹ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ó sọ pé: “Ta ni ẹ́? Ṣé àlùfáà ni ẹ́ ni?” Nígbà tí ìpàdé ọ̀sán parí Natalie rí àtẹ̀jíṣẹ́ náà, òun náà bá fèsì, ó ní: “Mi kì í ṣe àlùfáà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, mo sì wà ní àpéjọ àgbègbè kan báyìí.”
Ọkùnrin náà tún pè ní ọjọ́ Sátidé kó lè mọ̀ bóyá wọ́n ṣì ń ṣe àpéjọ náà. Bàbá Natalie jẹ́rìí fún un látorí fóònù. Ọkùnrin náà wá sọ pé: “Láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ látorí fóònù yẹn dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ti ń da ọkàn mi rú.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn ẹ̀mí èṣù ń da ọkùnrin náà àti ìdílé rẹ̀ láàmù, wọn ò sì mọ ohunkóhun nípa àwọn ẹ̀mí èṣù yìí àti ìdí tírú nǹkan
bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ó sọ pé: “Kó tó di òní, mi ò kì í fẹ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ rárá, àmọ́ tó bá ṣeé ṣe, mo fẹ́ bá ọkùnrin tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ látorí fóònù yẹn sọ̀rọ̀.”Ó kúkú ṣeé ṣe fún un láti bá a sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ Sunday, ọkùnrin náà wá, ẹnú yà á gan-an bó ṣe rí i táwọn tọkọtaya àtàwọn ọmọ wọn múra dáadáa, tí gbogbo wọn sì láyọ̀. Kò sí ìdọ̀tí láyìíká, kò sẹ́ni tó ń ṣépè, kò sẹ́ni tó ń fa sìgá. Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ rárá pé irú ẹ̀dá bíi tiyín wà láyé yìí! Ṣe ló dà bíi pé ayé míì ni mo wà.” Bàbá Natalie mú un lọ sí ọ́fíìsì alága, ó sì bá alága náà sọ̀rọ̀. Ohun tó rí ní àpéjọ náà àtàwọn ohun tí wọ́n bá a sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ó gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì, wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò.
-
ILẸ̀ 29
-
IYE ÈÈYÀN 38,495,300
-
IYE AKÉDE 94,924
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 59,431
“Mi Ò Gbọ́ Orin Tó Dùn Tó Báyìí Rí”
Níléèwé kan nílùú Savaii, lórílẹ̀-èdè Samoa, orin ni wọ́n fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ti wà lórí ìlà. Àmọ́ àṣà yìí ò bá Celina tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún àti Levaai tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà lára mu. Wọ́n ṣàlàyé fún ọ̀gá iléèwé wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé àwọn ò ní lè máa bá wọn kọrin torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Àmọ́ bí ẹní fọwọ́ pa idà iléèwé lójú ni téèyàn bá lóun ò kọrin. Ọ̀gá
àgbà náà wá ronú òun tó máa ṣe, ó ní tóun bá dójú ti àwọn ọmọ náà, wọ́n á kọrin. Ló bá sọ fún wọn pé: “Ó dáa, tẹ́ ẹ bá lẹ́ ò ní kọ orin tiwa, ẹ kọ tiyín ká gbọ́.” Celina àti Levaai bá dẹ́nu lé orin 111, “Òun Yóò Pè,” tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ wọn nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn. Nígbà tí wọ́n kọ orin náà tán, ṣe lomi ń dà lójú ọ̀gá iléèwé wọn. Ló bá sọ pé: “Mi ò gbọ́ orin tó dùn tó báyìí rí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tún orin náà kọ.” Làwọn ọmọ náà bá tún orin yìí kọ. Ló wá sọ fún wọn pé: “Láti oní lọ, mi ò tún ní sọ pé kẹ́ ẹ kọ orin tiwa mọ́, orin tiyín lẹ ó máa kọ.”“Láti oní lọ, mi ò tún ní sọ pé kẹ́ ẹ kọ orin tiwa mọ́, orin tiyín lẹ ó máa kọ”
Jésù Nìkan Ló Máa Ń Gbàdúrà Sí
Lórílẹ̀-èdè Fíjì, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan wà tó máa ń jókòó ti ẹnì kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ló ti gbọ́ pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run. Ohun tó gbọ́ yìí dà á lọ́kàn rú débi pé kò lè sùn lóru. Nígbà tí ìyàwó ẹ̀ rí i, ó sọ fún un pé: “Ẹ má fetí sáwọn èèyàn yẹn mọ́ o jàre!” Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà ò kúrò lọ́kàn rẹ̀. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó tún wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì yìí, ló bá gba ṣọ́ọ̀ṣì ẹ̀ lọ, ó sọ fún wọn pé òun ò ṣe pásítọ̀ mọ́. Ẹ má gbàgbé pé wọn ò tíì máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ o. Làwọn ará ilé rẹ̀ àtàwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ bá tutọ́ sókè, tí wọ́n sì fojú gbà á. Kí ló fà á? Wọ́n ní kì í ṣe pé ó fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ nìkan ni, àmọ́ iṣẹ́ tó ń mówó ribiribi wọlé ló fi sílẹ̀ yìí. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti wá mú kó mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an báyìí, síbẹ̀ kò rọrùn fún un láti gbàdúrà sí Jèhófà torí pé Jésù ló ti máa
ń gbàdúrà sí ní gbogbo ayé rẹ̀. Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà. Ní báyìí, tọmọdé tàgbà ló ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, tó sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì káwọn náà lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín.Àwọn Èèyàn Erékùṣù Kékeré Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Erékùṣù kékeré kan wà tí wọ́n ń pè ní Makatea ní Gúúsù Òkun Pàsífíìkì. Àwọn èèyàn méjìlélọ́gọ́ta [62] péré ló ń gbébẹ̀. Àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè Tahiti ló máa ń wàásù fáwọn èèyàn náà. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn mẹ́sàn-án lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí fóònù. Wọ́n ṣètò pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà máa pàdé nílé ọkàn lára wọn, àwọn bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló máa ń pé jọ láti gbádùn ìpàdé tó ń lọ ní Tahiti, tí wọ́n á sì máa gbọ́ ọ lórí fóònù. Lára àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí ni obìnrin kan tó jẹ́ abẹnugan nínú ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ, kódà wọ́n ti ń ronú láti fi obìnrin náà joyè díákónì obìnrin. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn, obìnrin yìí lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tóun ò fi wá sí ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́. Ó fi Bíbélì ṣàlàyé pé kò yẹ kí obìnrin máa kọ́ni nínú ìjọ. Ó tún ṣàlàyé irú ẹni tí Jésù Kristi jẹ́ àti bó ṣe yẹ kéèyàn máa rántí ikú Kristi, pé kì í ṣe gbogbo ọjọ́ Sunday ló yẹ kí wọ́n máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, bí kò ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] nìkan ló ń lọ sọ́run tí wọ́n á sì wà pẹ̀lú Kristi, àti pé àwọn nìkan ló gbọ́dọ̀ jẹ búrẹ́dì, kí wọ́n sì mu wáìnì lọ́jọ́ Ìrántí náà. Ìtara tí obìnrin yìí ní wú obìnrin kan lórí débi pé òun náà fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. Ní báyìí, òun náà ti ní káwọn Ẹlẹ́rìí wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Gbogbo Ìdílé Rẹ̀ Ló Wá
Láwọn erékùṣù tí wọ́n ń pè ní Solomon Islands, àwọn alàgbà ṣètò bí wọ́n ṣe máa pe àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún tó kọjá. Torí náà, wọ́n rán méjì lára wọn sọ́dọ̀ Joshua, tó jẹ́ pé ọdún 1998
ló ti wá sípàdé gbẹ̀yìn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, á gba Joshua ní wákàtí méjì kó tó lè dé ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí náà. Àmọ́ Joshua ò fìyẹn pè, ó wá, ogun èèyàn látinú ìdílé rẹ̀ ló sì tún tẹ̀ lé e. Báwọn ará ṣe gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ wú Joshua lórí débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Kódà, ọ̀pọ̀ lára wọn ló tún wá sí àkànṣe àsọyé tó wáyé lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn ìpàdé ọjọ́ yẹn, wọ́n sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ṣètò láti wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nínú wọn lo ti ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́.Ó Mọ Ìdáhùn Ìbéèrè Náà Lóòótọ́
Àwọn erékùṣù tó wà lábẹ́ àbójútó ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Guam lé ní ẹgbẹ̀rún [1,000] kan, àmọ́ èyí táwọn
èèyàn ń gbénú lé díẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún [100]. Mẹ́tàlá nínú àwọn erékùṣù náà ni ìjọ wà. Torí náà, àìmọye lèyí táwọn ará kò lè dé, síbẹ̀ àwọn ará ń wá gbogbo ọ̀nà tí wọ́n á fi lè kàn sáwọn erékùṣù tó kù náà. Lóṣù April 2012, àwọn akéde kan wọkọ̀ ojú omi lọ sí erékùṣù Polowat, tó wà lára èyí tó jìnnà jù lọ. Ṣe ló dà bíi pé ayé ojú dúdú ni erékùṣù yìí ṣì wà, àwọn nǹkan ìgbàlódé ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀. Àwọn ọkùnrin ṣì ń sán bàǹtẹ́, ọkọ̀ òbèlè ni wọ́n ṣì ń lò, iṣẹ́ àgbẹ̀ ni wọ́n sì mọ̀.Akéde kan bi ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń gbébẹ̀ léèrè pé: “Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá kú?”
Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé, “Mo mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn!” Ló bá dìde, ó sì lọ mú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye wá lédè Chuuk. Kíá ló ṣí ìwé náà síbi tí wọ́n to ohun tó wà nínú rẹ̀ sí, ló bá tọ́ka sí orí 8 tó ní àkòrí náà, “Kinni Nṣẹlẹ Nigba Iku?” Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tó ti kà nínú ìwé náà.
Àmọ́ báwo ló ṣe rí ìwé náà? Àwọn akéde kan láti erékùṣù Chuuk ṣètò láti lọ wàásù létíkun lọ́dún 2009, níbi táwọn èèyàn ti máa ń wọkọ̀ ojú omi lọ sáwọn erékùṣù kéékèèké míì. Lára ìwé tí wọ́n fún àwọn èèyàn náà ni ìwé Iwọ Le Walaaye. Ọ̀kan lára àwọn èèyàn náà ni wọ́n gbé páálí ìwé kan fún, pé kó pín in fáwọn èèyàn wọn. Bí ọ̀kan ṣe dọ́wọ́ ọmọkùnrin yìí nìyẹn o.
Kó tó di pé àwọn ará fi erékùṣù Polowat sílẹ̀, wọ́n ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọmọkùnrin náà lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n bá a kẹ́kọ̀ọ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lè túbọ̀ lágbára. Wọ́n sì tún kọ́ ọ béèyàn ṣe lè máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀. Láfikún, wọ́n jẹ́ kó mọ bó ṣe lè máa wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe lè máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì sí àyè tó wà nínú ìwé tó bá ń kà.
Ó má wúni lórí o, pé kódà láwọn erékùṣù tó wà lójú agbami, àwọn ìwé wa ń dá bírà, wọ́n ń mú káwọn èèyàn mọ òtítọ́ lédè àbínibí wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí rédíò, tẹlifíṣọ̀n, ìwé ìròyìn tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì!
Àlàyé Mẹ́ta, Ọta Ìbọn Mẹ́ta
Ogun abẹ́lé túbọ̀ ń le sí i ní erékùṣù Bougainville lórílẹ̀-èdè Papua New Guinea. Anna tó ti lé lọ́mọ ogún ọdún ò tíì ṣèrìbọmi nígbà yẹn. Lọ́dún 1991, òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà àtàwọn ọmọ kéékèèké méje láti ìjọ Arawa ní láti sá lọ sínú igbó. Nǹkan díẹ̀ sì ni wọ́n lè mú dání nínú ẹrù wọn. Odindi ọdún méjì ni wọ́n fi gbé láwọn ilé tó ti dahoro, tí wọ́n sì ń wá oúnjẹ kiri. Ìwé méjì péré tí wọ́n rí mú dání ni wọ́n fi ń ṣe ìpàdé, àwọn ìwé náà ni Bíbélì tó jẹ́ ti Anna àti ìwé Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa. Wọ́n máa gbàdúrà pa pọ̀, wọ́n á kọrin, wọ́n á sì wàásù fáwọn tí wọ́n bá rí.
Àwọn ọmọ ogun ajàjàgbara kan rí wọn níbi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì fẹ́ káwọn arákùnrin méjì tó wà láàárín wọn dara pọ̀ mọ́ wọn. Àmọ́, nígbà tí wọ́n ṣàlàyé fún àwọn ológun náà àwọn kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ogun, wọ́n gbà pẹ̀lú wọn. Ọmọ ogun kan tiẹ̀ fi ọta ìbọn mẹ́ta han Anna, ó wá sọ fún un pé: “Tó ò bá fẹ́ mi, màá pa ẹ́.” Anna sọ ìdí mẹ́ta tí òun ò fi ní fẹ́ ẹ, ó ṣe tán, ọta ìbọn mẹ́tà ló sọ pé ó máa fi pa òun. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Bíbélì sọ pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Ọkùnrin náà bá yí pa dà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.
“Kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró. Ogun ì báà jà jù bẹ́ẹ̀ lọ”
Lọ́dún 2012, Anna tó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé gbọ́ pé wọ́n nílò àwọn oníwàásù ní ìlú Arawa, ni òun àti ẹnì kejì rẹ̀ tí wọ́n jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà bá pa dà síbẹ̀ láti lọ dá àwùjọ àdádó sílẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n bi í bó ṣe rí lára rẹ̀ láti pa dà sílùú tí wọ́n ti pa àwọn èèyàn nípakúpa, tí ojú òun náà sì rí màbo níbẹ̀ nígbà ogun, ó sọ pé: “Inú mi dùn láti pa dà wá síbí. Kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró. Ogun ì báà jà jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
“Oṣù méjì péré ló kù, ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé mo ṣèrìbọmi!”