Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Lọ́dún tó Kọjá

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Lọ́dún tó Kọjá

Apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà ń lọ geerege! Ṣé wàá fẹ́ mọ àwọn nǹkan ribiribi tó ṣẹlẹ̀ ní bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn? Máa bá wa ká lọ.

Àwọn Ilé Tá A Tà Àtèyí Tá A Rà

A Fẹ́ Gbé Oríléeṣẹ́ Wa Lọ sí Ibòmíì

Ní July 2009, a ra ilẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ la sì ní lọ́kàn pé a máa gbé oríléeṣẹ́ wa lọ. Sarè igbá ó lé mẹ́tàléláàádọ́ta [253] ni ilẹ̀ náà. Ó wà ní apá àríwá ìwọ̀ oòrùn Brooklyn, New York, níbi tí oríléeṣẹ́ wa wà láti ọdún 1909 títí di báyìí, nǹkan bí ọgọ́rin [80] kìlómítà ló sì fi jìnnà sí Brooklyn.

Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì lá máa gbé ilé tuntun yìí tí wọ́n á sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Lára àwọn ilé tó máa wà níbẹ̀ ni ọ́fíìsì kan, ilé tí wọ́n ti ń ṣe onírúurú iṣẹ́, èyí tí wọ́n ti ń tún àwọn ohun èlò ṣe, àti ilé gbígbé mẹ́rin. A máa kọ́ ilé kékeré kan tá a ó máa tọ́jú àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ mọ́ ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí.

Gbogbo ilé tá a máa kọ́ sórí ilẹ̀ náà kò ní gbà ju sarè márùnlélógójì [45] lọ lára gbogbo ilẹ̀ náà, àá wá fi ìyókù ilẹ̀ náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Àwọn ibi tá a bá kọ́lé sí nìkan la máa fi koríko àtàwọn òdòdó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn onírúurú igi tó bá wà lórí ilẹ̀ náà máa mú kí àwọn ilé tá a máa kọ náà dùn-ún wò. Àwọn tó yàwòrán bí ilé náà ṣe máa rí yà á lọ́nà tó jẹ́ pé tá a bá kọ́ ọ tán á ò ní máa lo iná púpọ̀, á sì dín ìnáwó wa kù. Bákàn náà, a ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa lo àwọn nǹkan tó lè ba afẹ́fẹ́ jẹ́, èyí á sì tún dín ìnáwó kù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn koríko tó rọ́kú, tí wọ́n lè gbomi dúró la fi máa ṣe òrùlé àwọn ilé náà. Kò ní sí pé à ń pààrọ̀ wọn lemọ́lemọ́, ooru ò sí ní máa mú nínú ilé torí pé àwọn koríko náà lè gbomi dúró. Ìtànṣán oòrùn la ó fi máa ríran láwọn ọ́fíìsì yìí dípò iná mànàmáná. A tún máa kọ́ ọ lọ́nà tá ò fi ní máa fomi ṣòfò.

Kí ló fà á tá a fi fẹ́ ṣí kúrò níbi tá a wà báyìí? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ilé iṣẹ́ wa ní Brooklyn nìkan la ti máa ń tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, àmọ́ ní báyìí, à ń tẹ̀ wọ́n láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láwọn ilẹ̀ míì. Ẹ ò ní gbàgbé pé a ní ọ́fíìsì míì ní Wallkill, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó tó nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́jọ [145] sí Brooklyn. Torí pé a fẹ́ dín ìwé títẹ̀ kù ní Brooklyn, lọ́dún 2004, a ní kí ọ́fíìsì yìí máa tẹ àwọn ìwé wa kó sì máa kó wọn ránṣẹ́. Ìdí míì ni pé a fẹ́ dín owó tá à ń ná kù. Owó kékeré kọ́ ló ń ná wa láti máa tọ́jú àwọn ilé àtàwọn onírúurú irinṣẹ́ tá à ń lò ní Brooklyn, ọjọ́ sì ti pẹ́ tá a ti ń lò wọ́n. Tá a bá wà níbi tí ilé ò ti pọ̀ tó ti tẹ́lẹ̀, ìnáwó á dín kù, àá sì lè ná owó yẹn lọ́nà tó túbọ̀ dára.

A Pa Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Kan Pọ̀

Ní September 2012, a pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó lé ní ogún [20] pọ̀, a sì ní káwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó tóbi máa bójú tó àwọn ilẹ̀ tọ́rọ̀ náà kàn. Ohun méjì ló fà á tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀:

1. Ẹ̀rọ ìgbàlódé mú kí iṣẹ́ túbọ̀ rọrùn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti mú kó túbọ̀ rọrùn láti máa kàn síra ẹni àti láti máa tẹ ìwé. Èyí mú kó ṣeé ṣe láti dín àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó tóbi kù. Báwọn èèyàn ṣe dín kù yìí mú káwọn yàrá kan ṣí sílẹ̀ fáwọn ará wa tó wá láti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kéékèèké.

Ní báyìí tí àwọn ará ti kóra jọpọ̀ sójú kan láti ṣiṣẹ́, ó ti wá ṣeé ṣe láti rí àwọn ará tó nírìírí táá máa bójú tó iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ní báyìí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mẹ́síkò ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù láwọn orílẹ̀-èdè bíi Costa Rica, El Salvador, Guatemala, Honduras, Nicaragua àti Panama. Èyí mú ká ti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yẹn pa. Ogójì [40] lára àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì láwọn orílẹ̀-èdè yẹn ti kó lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mẹ́síkò, nígbà tí márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95] míì ṣì wà lórílẹ̀-èdè wọn. Àwọn wọ̀nyí ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Àwọn tó ṣẹ́ kù tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì láwọn orílẹ̀-èdè yẹn ń bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè lọ láwọn ibi tá a kọ́ fáwọn atúmọ̀ èdè. Abẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì Mẹ́síkò làwọn náà sì wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn atúmọ̀ èdè bí ogún ló wà ní Panama tí wọ́n ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sáwọn èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà. Lórílẹ̀-èdè Guatemala, àwọn mẹ́rìndínlógún ló ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè mẹ́rin lórílẹ̀-èdè náà. Àtúntò tá a ṣe yìí ti mú ki iye àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì dín kù. Dípò ọ̀ọ́dúnrún [300] tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mẹ́fà náà tẹ́lẹ̀, wọn ò ju márùndínlọ́gọ́rin [75] lọ báyìí.

2. Kí àwọn òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún lè pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ní báyìí tá a ti pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan pọ̀, àwọn ará kan tó ti ń sìn tẹ́lẹ̀ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kéékèèké yìí ti wá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Arákùnrin kan nílẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ní kó lọ máa sìn ní pápá sọ pé: “Ó kọ́kọ́ ṣòro díẹ̀ fún bí oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí mo kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, bí mo ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí lójoojúmọ́ mú kínú mi máa dùn, mo sì rọ́wọ́ Jèhófà lára mi. Ní báyìí, ogún èèyàn ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn kan nínú wọn sì ti ń wá sípàdé.”

Àmì Kan Tó Ti Wà Láti Ọ̀pọ̀ Ọdún

Lójoojúmọ́ làwọn tó ń gbé nílùú New York máa ń rí àwọn lẹ́tà gàdàgbà pupa tá a fi kọ orúkọ wa sára oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lẹ́tà yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ilé alájà méjì nídùúró, ó sì ti lé ní ogójì [40] ọdún tí wọ́n ti wà níbẹ̀. Aago àtohun téèyàn lè fi díwọ̀n ojú ọjọ́ wà lára ohun tí wọ́n so mọ́ ara ilé yìí, àwọn èèyàn sì máa ń lò wọ́n gan-an.

Àwa náà bá aago àtohun ìdíwọ̀n ojú ọjọ́ náà níbẹ̀ ni, àwọn tó ń lo ilé náà tẹ́lẹ̀ ló gbé e kọ́ síbẹ̀. Ó sì ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún tó ti wà níbẹ̀. Àmọ́, a tún un ṣe lẹ́yìn tá a ra ilé náà lọ́dún 1969.

Àwọn arákùnrin ń tó lẹ́tà tá a fi kọ orúkọ “Watchtower” sára ilé lọ́dún 1970

Àìmọye ìgbà la ti tún aago àtohun ìdíwọ̀n yìí ṣe kí wọ́n lè ṣeé gbára lé. Láàárín ọdún 1985 sí 1989, a ṣe àfikún tó máa jẹ́ káwọn èèyàn lè mọ bójú ọjọ́ ṣe rí kí wọ́n sì díwọ̀n rẹ̀ ní oríṣi ọ̀nà méjì tí wọ́n ń gbà díwọ̀n ojú ọjọ́.

Òdìkejì oríléeṣẹ́ wa lobìnrin kan tó ń jẹ́ Eboni ń gbé, ó sọ pé: “Ó ti mọ́ mi lára láti máa yọjú lójú wíńdò kí n lè mọ ohun tí aago sọ àti bójú ọjọ́ ṣe rí kó tó di pé màá jáde lọ síbi iṣẹ́. Kì í jẹ́ kí n pẹ́ dé ibiṣẹ́, ó sì ń jẹ́ kí n mọ irú aṣọ tó yẹ kí n wọ̀ táá bá bójú ọjọ́ ṣe rí mu.”

Ṣé àmì yìí á ṣì wà níbẹ̀ di ogójì [40] ọdún míì? Àwa ò ní pẹ́ kúrò níbẹ̀ mọ́, torí náà ọwọ́ àwọn tó bá máa ra ilé náà ló kù sí.

À Ń Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà

Omi Tuntun Rú Nílùú Manhattan

Ní November 2011, àwọn ará wa kan gba ọ̀nà míì yọ láti mú káwọn èèyàn tó ń gbé lágbègbè Manhattan gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n to àwọn ìwé wa sórí tábìlì àti káńtà lọ́nà tó ń fani mọ́ra. Àgbègbè táwọn ará ṣètò sí yìí làwọn èèyàn pọ̀ sí jù nílùú New York City. Ibẹ̀ sì ni àwọn èèyàn kọ́kọ́ tẹ̀dó sí. Yàtọ̀ síyẹn, èrò máa ń gbabẹ̀ gan-an. Ibi mẹ́rin ni wọ́n to àwọn ìwé náà sí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ibi táwọn tó ń lọ tó ń bọ̀ ti lè dúró kí wọ́n sì yà láti wo àwọn ìwé tí wọ́n pàtẹ, wọ́n sì tún lè béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ lọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà tó wà nítòsí. Àwọn ibi tí wọ́n pàtẹ sí yìí jẹ́ níbi táwọn ẹgbàágbèje èèyàn ti sábà máa ń wọkọ̀ tàbí kó má jìnnà síbẹ̀.

Tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà ń fi ìwé ìròyìn lọ ẹnì kan níbi tí wọ́n pàtẹ sí ní Grand Central Station nílùú New York City

Àwọn èèyàn máa ń béèrè ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì ń rí ìdáhùn tó bá Bíbélì mu níbi táwọn ará pàtẹ sí yìí. Àwọn tójú bá ń kán máa ń mú èyí tí wọ́n fẹ́ lára àwọn ìwé náà kí wọ́n lè kà wọ́n tọ́wọ́ wọn bá dilẹ̀. Àwọn ìwé náà wà ní onírúurú. Tí ìwé ò bá sí lédè tẹ́nì kan fẹ́, àwọn ará á ṣètò bó ṣe máa rí i gbà lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà.

Tọmọdé-tàgbà lohun táwọn ará ṣe yìí wú lórí, kódà inú àwọn aláṣẹ dùn sí i. Ọ̀gá ọlọ́pàá kan sọ pé: “Níbo lẹ wà tẹ́lẹ̀? Ohun táráyé ń fẹ́ gan-an ló wà lọ́wọ́ yín yìí.” Ńṣe lọkùnrin kan dúró lójijì nígbà tó tajú kán rí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó ní òun pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n ń ka ìwé yìí, òun wá ń ronú pé ibo ni wọ́n ti rí ìwé náà. Ó ti wá mọ̀ ibẹ̀ báyìí.

Ó lé lóṣù kan tí ọ̀dọ́kùnrin kan ti máa ń gba ọ̀kan lára ibi tá a pàtẹ sí kọjá lójoojúmọ́ tó bá ń lọ ibiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan ló dúró, ó wá sọ pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ràn mí lọ́wọ́.” Tayọ̀tayọ̀ làwọn ará wa fi béèrè ohun tó fẹ́. Wọ́n fún un ní Bíbélì, wọ́n sì jẹ́ kó mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ṣe é láǹfààní. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gba àwọn ibi tá a pàtẹ sí yìí la ti bá sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àní láàárín oṣù mẹ́jọ péré, ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méje àti méjìdínláàádọ́ta [1,748] èèyàn ló ti ní ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó fi máa di June 2012, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [27,934] ìwé ìròyìn àti ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gọ́ta ó lé mọ́kàndínlógún [61,019] ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ làwọn èèyàn ti gbà.

Àtúnṣe Dé Bá Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa, Wọ́n sì Tún Ń Jáde Lédè Tó Pọ̀ Sí I

Bẹ̀rẹ̀ láti January 2013, ìwé ìròyìn Jí! àti Ilé Ìṣọ́ tá a ń fi sóde di olójú ìwé mẹ́rìndínlógún [16] dípò méjìlélọ́gbọ̀n [32] tó jẹ́ tẹ́lẹ̀. Torí pé àpilẹ̀kọ inú wọn kò pọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀, ó ti wá ṣeé ṣe láti máa túmọ̀ wọn sáwọn èdè tó túbọ̀ pọ̀ sí i. Ní báyìí, èdè méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98] là ń túmọ̀ ìwé ìròyìn Jí! sí nígbà tí ti Ilé Ìṣọ́ jẹ́ igba ó lé mẹ́rin [204]. Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní tiẹ̀ ò yí pa dà, á ṣì máa ní ojú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n [32].

Ní báyìí, orí Ìkànnì www.pr418.com/yo nìkan làwọn èèyàn ti ń rí àwọn àpilẹ̀kọ kan tá a máa ń gbé jáde tẹ́lẹ̀. Lára wọn ni “Abala Àwọn Ọ̀dọ́,” “Ẹ̀kọ́ Bíbélì,” àti ìròyìn nípa àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tó máa ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tá a ń fi sóde. Bákàn náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú “Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé” àti “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” tó máa ń wà nínú Jí!

Láfikún, onírúurú àpilẹ̀kọ ti wà lórí Ìkànnì wa tó ń jẹ́ káwọn èèyàn ka àlàyé tó ṣe pàtó, tá a fi dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n máa ń béèrè nípa Bíbélì àti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n sì tún lè wa àwọn ìwé wa jáde lórí ìkànnì náà. Téèyàn bá ti ní kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ẹ̀rọ alágbèéká kan, kó máa gbádùn àwọn ìwé wa lórí Ìkànnì www.pr418.com lọ fàlàlà ló kù, ní èyíkéyìí lára èdè tó ju òjì-lé-nírinwó [440] tó wà níbẹ̀.

A Tún Ti Dárà sí Ìkànnì Wa

Láwọn oṣù mélòó kan sẹ́yìn, àwọn ará tó wà ní oríléeṣẹ́ wa ní New York ṣiṣẹ́ takuntakun láti mú kí Ìkànnì www.pr418.com túbọ̀ fani mọ́ra, kó sì túbọ̀ rọrùn láti lò lórí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ẹ̀rọ alágbèéká kan. Wọ́n tún wá dárà sí i, ìdí méjì ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀:

1. Láti sọ gbogbo ìkànnì wa di ẹyọ kan. Àwọn ìkànnì mẹ́tà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò la ti pa pọ̀ di ẹyọ kan báyìí, ìyẹn www.pr418.com. A ò lo àwọn méjì tó kù mọ́, ìyẹn, www.watchtower.org àti www.jw-media.org. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, kò tún sí pé èèyàn ń ti ìkànnì kan lọ sórí ìkànnì míì kéèyàn tó lè mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè ka Bíbélì àtàwọn ìwé wa, ó lè tẹ́ ẹ̀ jáde tàbí kó tẹ́tí sí i ní èdè yòówù tó bá fẹ́ lára àwọn èyí tó wà.

A tún Ìkànnì www.pr418.com wa tò, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti August 28, 2012

2. Láti fi kún àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀. Àtúnṣe tá a ṣe yìí mú káwọn èèyàn lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn nípa Bíbélì, wọ́n sì ń rí àlàyé nípa iṣẹ́ ìwàásù wa, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Abala tá a pè ní “Ìròyìn” máa ń sọ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa kárí ayé. Àwọn apá tó gbádùn mọ́ni náà wà fáwọn ìdílé, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ọmọdé.

Lójoojúmọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń ka àwọn ìwé wa lórí ìkànnì yìí. Wọ́n máa ń wa ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì mílíọ̀nù ìsọfúnni jáde lónírúurú ọ̀nà tá a gbà ṣe wọ́n, ó lè jẹ́ àtẹ́tísí tàbí EPUB tàbí PDF, títí kan àwọn fídíò tó wà fáwọn adití. Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn tó máa ń sọ pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún [100].

À Ń Ran Onírúurú Èèyàn Lọ́wọ́

Bíbélì Tó Ga Tó Èèyàn ní Ìdúró!

Iṣẹ́ ti parí lórí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ṣe fáwọn afọ́jú lédè Gẹ̀ẹ́sì, Sípáníìṣì àti Ítálì. Ìdìpọ̀ ogún [20] sí méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ni gbogbo rẹ̀, téèyàn bá tó wọ́n lórí ara, ó gá tó èèyàn ní ìdúró, tá a bá sì to gbogbo rẹ̀ síbi ìkówèésí, ó gba àyè tó gùn tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà àtààbọ̀! Àwọn ìwé tó wà fáwọn afọ́jú tá a ṣe lọ́nà míì ò fi bẹ́ẹ̀ gbàyè tó bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rọ ìgbàlódé kan ti wà báyìí fáwọn afọ́jú tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa kọ nǹkan sílẹ̀ kí wọ́n sì tún máa ka ohun tó wà lákọọ́lẹ̀. Kódà, ẹ̀rọ yìí ṣeé gbé káàkiri. Yàtọ̀ síyẹn, ètò orí kọ̀ǹpútà wà tó máa jẹ́ kí àwọn afọ́jú lè wá ìtẹ̀jáde lórí kọ̀ǹpútà tó sì tún máa ka ọ̀rọ̀ inú ìwé náà sí wọn létí.

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún báyìí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì fáwọn afọ́jú, èdè mọ́kàndínlógún [19] ni wọ́n sì ti wà báyìí. A kì í béèrè owó lọ́wọ́ àwọn afọ́jú tó ń gba àwọn ìwé yìí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn látọkàn wọn wá.

Arákùnrin Anthony Bernard ní Sri Lanka ń lo Bíbélì rẹ̀ tó wà lédè táwọn afọ́jú lè kà láti darí Ìjọsìn Ìdílé

A ti ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà tó ń mú káwọn afọ́jú lè ka ìwé wa ní onírúurú èdè tí wọ́n gbọ́. Ẹ ṣáà kúkú mọ̀ pé èdè yàtọ̀ síra, tá a bá ti to lẹ́tà tí èdè kọ̀ọ̀kan fi ń kọ̀wé jọ, tá a sì tẹ̀ lé ìlànà tó yẹ, ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà á wá yí i sí èdè táwọn afọ́jú lè kà. Á sì wá ṣe é lọ́nà tó máa túbọ̀ rọrùn fáwọn afọ́jú láti lè kà á. Pẹ̀lú ètò orí kọ̀ǹpútà tá a ṣe yìí, bóyá ni ìtẹ̀jáde kankan á wà tá ò ní lè ṣe jáde lónírúurú èdè fáwọn afọ́jú, títí kan Bíbélì, táwọn èdè náà bá ṣáà ti ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ̀wé fáwọn afọ́jú.

Tẹ́lẹ̀ láwọn àpéjọ àgbègbè wa, a máa ń sọ pé àwọn ìwé tuntun tá a mú jáde máa wà lédè táwọn afọ́jú lè kà, wọ́n sì lè kọ̀wé béèrè tó bá yá. Àmọ́, lọ́dún tó kọjá, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣèwádìí lọ́wọ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan láti mọ àpéjọ táwọn afọ́jú tó wà níjọ wọn máa fẹ́ lọ àti èyí tí wọ́n máa fẹ́ lára onírúurú ọ̀nà tí ìwé wọn wà (bóyá èyí tó wà lórí bébà, èyí tó máa ń wà lórí ẹ̀rọ tó ń ṣe àkọsílẹ̀ tàbí èyí tí kọ̀ǹpútà máa kà jáde).

Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n kó èyí táá ṣe sórí bébà ránṣẹ́ sáwọn àpéjọ tí afọ́jú èyíkéyìí bá wà, tó fi jẹ́ pé báwọn ará yòókù ṣe ń gba ìwé tuntun, bẹ́ẹ̀ làwọn afọ́jú náà ń gba ìwé tiwọn. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa fi èyí tó ṣeé kà lórí ẹ̀rọ ìgbàlódé àti kọ̀ǹpútà ránṣẹ́ sáwọn tó béèrè fún un.

Arábìnrin kan tí kò ríran sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ìgbà kan náà ni mo gbàwé pẹ̀lú àwọn ará yòókù. Sáàmù 37:4 sọ pé Jèhófà máa fún wa lóhun tó ń jẹ wá lọ́kàn. Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn lópin ọ̀sẹ̀ yìí!” Ṣe ni arákùnrin afọ́jú míì ń sunkún, ó wá sọ pé, “O ṣeun Jèhófà bó o ṣe ń tọ́jú wa, tó o sì ń ṣìkẹ́ wa!”

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ló Ti Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà

Lọ́dún 2011, àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà la ràn lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ìrànlọ́wọ́ yìí ò mọ síbì kan, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè la ti ń ṣe é:

Gánà: Àwọn tá a ràn lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sẹ́yìn ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000].

Kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà kan rèé ní Sáńbíà

Mòsáńbíìkì: Àwọn tó ti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà lẹ́nu ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sẹ́yìn ti lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún [19,000]. Felizarda tó ti jàǹfààní ilé ẹ̀kọ́ yìí sọ pé: “Mi ò lè sọ bínú mi ṣe dùn tó, èmi tí ò lè fìdí ìgò kọ ‘ó’ tẹ́lẹ̀ ni mo wá ń ka Bíbélì fáwọn èèyàn báyìí.”

Solomon Islands: Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀, àwọn tó ń gbé ní ìgbèríko ò rílé ìwé lọ. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn òbí kì í sábà rán àwọn ọmọbìnrin wọn lọ sílé ìwé. Ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà yìí ti ṣe àwọn obìnrin ní pàtàkì láǹfààní gan-an. Nígbà tí wọ́n bá fi máa parí ẹ̀kọ́ wọn, ńṣe lára wọn máa ń yá gágá láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.”

Sáńbíà: Láti ọdún 2002, èèyàn bí ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] ló ti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Agnes, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin [82] sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ṣèfilọ̀ pé wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, wéré ni mo forúkọ sílẹ̀. Ọjọ́ àkọ́kọ́ ni mo ti lè kọ orúkọ ara mi!”

Orin Ìyìn sí Ọlọ́run Lónírúurú Èdè

Solomon Islands: Àwọn ará ń kọrin ní èdè Pidgin tí wọ́n ń sọ ní Solomon Islands

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè tí ó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600]. Iṣẹ́ ńlá gbáà ni láti túmọ̀ orin márùndínlógóje [135] tó wà nínú ìwé orin wa. Síbẹ̀, láàárín ọdún mẹ́ta péré, a ti túmọ̀ ìwé orin tuntun náà, Kọrin sí Jèhófà sí èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116]. Ní àfikún, àwọn èdè márùndínlọ́gọ́ta [55] kan wà tó jẹ́ pé márùndínlọ́gọ́ta [55] lára orin náà la ti túmọ̀ sí èdè wọn, iṣẹ́ ṣì ń lọ ní pẹrẹu láti mú ìwé orin yìí jáde láwọn èdè míì.

Àwọn tó ń túmọ̀ orin máa ń wá àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀, tó dùn-ún gbọ́ létí, tó sì ṣeé rántí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn gbólóhùn tí wọ́n máa lò gbọ́dọ̀ rọrùn gan-an, kó ṣeé lóye fẹ́ni tó ń kọ orin náà, kí ó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Èdè yòówù kó jẹ́, ọ̀rọ̀ orin àti ohùn orin náà gbọ́dọ̀ bá bí wọ́n ṣe ń kọrin mu, bí ẹni pé ẹni tó ń kọrin náà ló ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ orin náà.

Ọgbọ́n wo làwọn atúmọ̀ èdè ń dá tí wọ́n fi ń rí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà gbé kalẹ̀? Ọgbọ́n tí wọ́n dá ni pé wọn ò kàn tú àwọn gbólóhùn inú ìwé orin tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì ní olówuuru. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n wá àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó máa jẹ́ kéèyàn lóye ohun tí orin náà ń sọ. Wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ lédè wọn, tó wà lẹ́nu àwọn èèyàn, téèyàn á sì tètè rántí. Síbẹ̀, wọ́n rí i pé gbólóhùn táwọn lò bá ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ tá a gbé orin kọ̀ọ̀kàn kà mu.

Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n á túmọ̀ ọ̀rọ̀ orin náà sí èdè wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n á ni kẹ́ni tó mọ̀ nípa orin gbìyànjú láti kọ ọ́ lórin. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹnì náà á ṣe àwọn àtúnṣe kan títí àwọn ọ̀rọ̀ náà á fi dùn-ún kọ lórin. Torí pé àwọn atúmọ̀ èdè yìí ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ inú ìwé orin náà ta ko Ìwé Mímọ́, wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà ṣe. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ńlá ni fáwọn atúmọ̀ èdè kí wọ́n tó lè túmọ̀ ìwé orin, àmọ́ inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń dùn bí kálukú wa ṣe ń fi èdè ìbílẹ̀ wa kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.

Ọ́fíìsì Tá A Kọ́ Fáwọn Atúmọ̀ Èdè

Ìwé Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹni àmì òróró tó wà lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí pé wọ́n á máa pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 22:17) “Gbogbo . . . ènìyàn àti ahọ́n” ni wọ́n sì ń pè. (Ìṣí. 7:9) Tẹ́lẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè kan lọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè máa ń wà, bí ò tiẹ̀ sí níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè àbínibí wọn. Èyí mú kó ṣòro fún wọn láti máa gbọ́ èdè wọn sétí lójoojúmọ́, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìwé tí wọ́n ń túmọ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ wọ àwọn tó ń kà wọ́n lọ́kàn. Àmọ́ ní báyìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn atúmọ̀ èdè ló ti kó lọ sí ibi tá a kọ́ fún wọn láwọn ìlú tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ lèyí mú wá. Ẹnu oníkàn la ti ń gbọ́ pọ̀n-ún, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn atúmọ̀ èdè fúnra wọn sọ.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè Maya lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Ṣe ni mo dà bí ẹyẹ tó wà nínú àgò tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá tú sílẹ̀.” Arákùnrin kan tó ń túmọ̀ èdè tí wọ́n ń sọ ní Gúúsù ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé a bọ́ sáyé tuntun nígbà tí wọ́n gbé wa lọ sáàárín àwọn tó ń sọ èdè wa. Kì í ṣe báwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ làwọn tó ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n, àwọn tó ń kọ̀wé àtàwọn tó ń kọ̀rọ̀ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe ń sọ ọ́. Tó o bá fẹ́ káwọn èèyàn gbádùn ìwé tó ò ń túmọ̀, à fi kó o máa tẹ́tí sí báwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, ohun táwa sì ń ṣe nìyẹn.”

“Ṣe ni mo dà bí ẹyẹ tó wà nínú àgò tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá tú sílẹ̀”

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè Tshiluba lórílẹ̀-èdè Kóńgò sọ pé: “Èdè wa là ń sọ lójoojúmọ́, nílè lóko, lọ́nà ọjà, yálà à ń bá aládùúgbò wa sọ̀rọ̀ ni o tàbí à ń wàásù fáwọn èèyàn, ohun náà là ń sọ nípàdé wa. Àwa náà ń fi ìwé tá a tú kẹ́kọ̀ọ́, a sì ń lò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀ bóyá àwọn èèyàn lóye ohun tá a tú.”

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè Lhukonzo tí wọ́n ń sọ nílẹ̀ Uganda sọ pé: “Ẹní bá rójú wa, á mọ̀ pé ayọ̀ wa ò lẹ́gbẹ́ nígbàkigbà tá a bá lọ ṣe ìpàdé lédè tá à ń sọ tá a sì tún ń túmọ̀. A tún máa ń gbádùn òde ẹ̀rí dọ́ba, torí pé ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lédè àbínibí wa.”

Àǹfààní kékeré kọ́ làwọn ìjọ táwọn atúmọ̀ èdè yìí wà ń rí. Nínú ìjọ táwọn atúmọ̀ èdè Maya wà, arábìnrin kan sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ńlá là ń kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró táwọn atúmọ̀ èdè yìí máa ń sọ, àpẹẹrẹ rere ni wọ́n sì jẹ́. Ṣe ló dà bíi pé Bẹ́tẹ́lì kékeré wà nínú ìjọ wa, ẹ wò ó, oyin mọmọ ni.”

Àwọn atúmọ̀ èdè Luo nílùú Kisumu, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà

Kì í ṣe ìjọ nìkan ló jàǹfààní, àwọn atúmọ̀ èdè náà ṣe bẹ́ẹ̀. Atúmọ̀ èdè kan ní Kẹ́ńyà sọ pé: “Bóyá nìwé kankan tiẹ̀ wà lédè Luo. Torí bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn ò gbà pé ẹnikẹ́ni máa ṣe ìwé jáde lédè wọn, ká má tíì wá sọ nípa ìwé tó jojú ní gbèsè tá à ń fún wọn. Abájọ tínú wọn fi máa ń dùn gan-an nígbà tá a bá fún wọn níwèé wa. Nígbà tí mo rí bínú wọn ṣe dùn tó, ó wú mi lórí gan-an. Mo wá pinnu pé mi ò ní fiṣẹ́ tí mo ń ṣe yìí sílẹ̀, kódà màá túbọ̀ tẹra mọ́ ọn ni.”

Ọ̀pọ̀ lára àwọn atúmọ̀ èdè yìí ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ẹ̀mí rere ni wọ́n ní, ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn Jèhófà ló sì máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Jèhófà mọyì wọn gan-an, ó sì máa ń bù kún wọn. Atúmọ̀ èdè Xhosa kan lórílẹ̀-èdè South Africa sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè pé: “Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe pé kí wọ́n kó àwa atúmọ̀ èdè lọ́ sí ọ́fíìsì tí wọ́n kọ́ fún wa dára gan-an ni. A gbádùn bá a ṣe wà ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ ilé wa la dé ní báyìí tá a ti wà ní ọ́fíìsì tó wà fún àwa atúmọ̀ èdè.”

Ìròyìn Tó Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́ Nípa Àwọn Ará Wa

“Àwọn Ará Tọ́jú Wa Gan-an Ni”

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Sunday, June 3, 2012, nílùú Èkó, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ṣàdédé ni ọkọ̀ òfuurufú kan jábọ́, tó sì gbiná. Èèyàn mẹ́tàléláàádọ́jọ [153] ló wà nínú ọkọ̀ òfuurufú náà. Àgbègbè kan táwọn èèyàn pọ̀ sí lọkọ̀ náà já sí, ó sì pa gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀ àtàwọn kan tá ò mọye wọn lágbègbè náà.

Lagos, Nàìjíríà: Lẹ́yìn tọ́kọ̀ òfuurufú já bọ́

Àjà kẹta nínú ilé alájà mẹ́ta kan ni Arákùnrin Collins Eweh àti ìdílé rẹ̀ ń gbé, ilé yìí sì ni ọkọ̀ òfuurufú náà kọlù. Àmọ́ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀, wọn ò sí nílè, wọ́n ti lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ní nǹkan bí aago mẹ́ta ààbọ̀ ọ̀sán, nígbà tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ń lọ lọ́wọ́, Collins àtìyàwó rẹ̀ Chinyere ṣàkíyèsí pé ìpè ṣáà ń wọlé sórí fóònù wọn, àmọ́ wọn ò jẹ́ kíyẹn dí wọn lọ́wọ́. Gbàrà tí ìpàdé parí, Chinyere gbé ìpè náà. Wọ́n sọ fún un pé ilé wọn ti gbiná. Nígbà tí wọ́n fi máa pa dà délé, wọ́n rí i pé ọkọ̀ òfuurufú ti já wọ ilé wọn ó sì dúró sórí ilé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwọn, ibẹ̀ sì ni iná ti sọ.

Chinyere sọ pé, “Kò sọ́gbọ́n ẹ̀, tá a bá wà ńlé ni, òkú wa làwọn èèyàn ì bá gbé jáde. Ohun tó kù wá kù ò jù aṣọ tó wà lọ́rùn wa yìí lọ, àmọ́ ẹ̀mí wa ṣì wà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni alábòójútó àyíká yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù. Àwọn arákùnrin yìí tọ́jú wa gan-an, a ò jẹ́ gbàgbé wọn láé.”

Collins sọ pé: “Àwọn ìbátan mi tínú wọn ò dùn pé mo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá pèrò dà báyìí. Ọ̀kan nínú wọn sọ fún mi pé: ‘Jèhófà ẹ gbọ́ àdúrà ẹ gan-an. Má fi Ọlọ́run tó ò ń sìn sílẹ̀ o, òun ló kó ẹ yọ.’ Ẹlòmíì lára wọn sọ pé: ‘Bó o ṣe ń sin Ọlọ́run ẹ náà ni kó o máa sìn ín lọ, máà mú nǹkan míì mọ́ ọn o.’ A rọ́wọ́ Jèhófà lára wa. Inú mi dùn gan-an ni.”

Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Fọwọ́ Sí Í Pé Káwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Máa Jọ́sìn

Budapest, Hungary: Àwọn ará wa ń wàásù fáwọn àlejò ní gbogbo ibi tí wọ́n ti pàdé wọn

Ní February 27, 2012, ìjọba orílẹ̀-èdè Hungary fọwọ́ sí i pé káwọn onísìn míì náà jàǹfààní lábẹ́ òfin tó gba àwọn ṣọ́ọ̀ṣì láyè. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé onísìn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà, a sì lè jọlá òfin yìí. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, àá túbọ̀ lè máa wàásù ìhìn rere bá a ṣe fẹ́ lórílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, ìsìn wa ò tún ní máa san owó orí mọ́, àá lè máa gba ọrẹ táwọn èèyàn bá fi ṣètìlẹyìn, àá sì lè máa ṣèbẹ̀wò sáwọn tó wà lẹ́wọ̀n àtàwọn tó wà nílé ìwòsàn.

Ìrántí Ikú Kristi Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń sìn nílùú Rundu, lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà, sọ nípa bí Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n ṣe lábúlé kan ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀. Wọ́n rí àwọn bíi mélòó kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wọn, torí náà, wọ́n pinnu pé àwọn máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tọ́dún yẹn níbẹ̀ àti pé èdè Rumanyo tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ làwọn máa fi sọ àsọyé lọ́jọ́ náà. Irú ẹ̀ ò sì tíì wáyé rí. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe náà sọ pé: “Ìta gbangba la ṣètò sí, òṣùpá ràn rokoṣo, ojú ọjọ́ sì mọ́lẹ̀ kedere, a sì tún wá ṣètò àtùpà elépo àti tọ́ọ̀ṣì mélòó kan.” Lára wọn, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n jókòó ti Jèhófà. Ohun ìyanu kan ni pé akéde kan péré ló wà lábúlé yẹn, kò sì tíì tóṣù méjì tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, ìyẹn lóṣù March, síbẹ̀ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [275] làwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi níbẹ̀ lóṣù April!

Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Yà Sí Mímọ́ Ń Fògo fún Jèhófà

Ọjọ́ mánigbàgbé ni November 19, 2011, jẹ́ nínú ìtàn àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Central African Republic àti Chad. Lọ́jọ́ yẹn, igba ó lè mọ́kàndínláàádọ́rin [269] àwọn ará ló pé jọ sí gbàgede kan tó dojú kọ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Inú àwọn ará dùn gan-an láti rí Arákùnrin Samuel Herd, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Òun ló ya Bẹ́tẹ́lì tuntun náà sí mímọ́ fún Jèhófà àti fún iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀. Wọ́n sọ ìtàn bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè méjèèjì náà. Ọdún 1947 niṣẹ́ ìwàásù bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Central African Republic, ó sì bẹ̀rẹ̀ ní Chad lọ́dún 1959. Nínú àsọyé tí wọ́n sọ lẹ́yìn náà, wọ́n sọ bíṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣe lọ títí wọ́n fi parí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Arákùnrin Herd wá fi ìkíni àwọn ará láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jíṣẹ́ kó tó di pé ó sọ àsọyé tó fi ya ilé náà sí mímọ́. Méjìlélógójì [42] làwọn tó ń ṣiṣẹ́ sìn nínú Bẹ́tẹ́lì yìí, wọ́n sì mọrírì ilé náà gan-an. Ilé tuntun náà ní ọ́fíìsì mẹ́jọ fáwọn atúmọ̀ èdè, ilé ìdáná kan, ilé ìjẹun kan àti ilé ìfọṣọ kan. Àwọn apá míì lára ilé tuntun náà ní yàrá méjìlélógún [22] tí wọ́n á máa gbé, ọ́fíìsì ìgbàlejò kan, ọ́fíìsì tó wà fáwọn alábòójútó àti ibì kan tí wọ́n á ti máa fẹrù ránṣẹ́ sáwọn ìjọ.

Èyí ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àkọ́kọ́ tá a máa yà sí mímọ́ lórílẹ̀-èdè Kóńgò

Arákùnrin Jackson ń sọ àsọyé ìyàsímímọ́ ní Kinshasa, Kóńgò

Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ Sátidé May 26, 2012, jẹ́ fáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa). Ọjọ́ yẹn ni wọ́n ya ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè náà sí mímọ́, lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ tí wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tuntun kan tí wọ́n sì ṣàtúnṣe sáwọn kan. Ìyàsímímọ́ eléyìí yàtọ̀. Ìdí ni pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta [50] ọdún tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ti wà nílẹ̀ Kóńgò, àmọ́ èyí nìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣètò láti ya ilé náà sí mímọ́. Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ ilé tuntun náà. Ẹgbẹ̀rún méjì, irínwó ó lé méjìlélógún [2,422] èèyàn ló pé jọ síbẹ̀. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn lo ti ṣèrìbọmi lóhun tó lé lógójì ọdún. Àwọn àlejò mẹ́tàdínlọ́gọ́fà [117] ló wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún [23]. Àwọn míṣọ́nnárì tó ti sìn ní Kóńgò lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn náà sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní. Inú gbogbo wọn ló dùn, wọ́n sì pinnu pé ìjọsìn Jèhófà nìkan làwọn máa lo ilé tuntun náà fún.

Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́ Tó Wà Nílé Ẹjọ́

Ní June 30, 2011, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) ṣèdájọ́ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Faransé fi ẹ̀tọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wá nígbà tí wọ́n ní ká máa sanwó orí. Ìjọba ilẹ̀ Faransé pàṣẹ pé ká san ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá ọrẹ táwọn ará wa ń fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè náà látọdún 1993 sí 1996. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ilé Ẹjọ́ náà rọ ìjọba orílẹ̀-èdè Faransé pé kí wọ́n lọ yanjú ọ̀ràn dídá owó náà pa dà fún àwọn ará wa ní ìtùnbí-ìnùbí, síbẹ̀, ìjọba orílẹ̀-èdè Faransé kọ̀ jálẹ̀. Kódà wọ́n sọ pé àwọn ò lùfin rárá, torí náà àwọn ò ní ọ̀rọ̀ kan táwọn fẹ́ sọ ní ìtùnbí-ìnùbí pẹ̀lú àwọn ará wa. Torí bẹ́ẹ̀, a gbé ẹjọ́ náà pa dà sílé ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn (ECHR). Ní July 5, 2012, Ilé Ẹjọ́ náà ní kí ìjọba orílẹ̀-èdè Faransé dá gbogbo ohun tó jẹ mọ́ owó orí tí wọ́n ti gbà lọ́wọ́ wa pa dà. Lára owó tí wọ́n máa dá pa dà ni mílíọ̀nù mẹ́rin, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó dín mẹ́wàá, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín márùn-ún owó Yúrò [4,590,295]. Ìyẹn mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé márùndínlọ́gọ́rùn-ún, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún kan ó lé méje àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [895,107,525] náírà. Wọ́n tún máa san èlé tó gun gbogbo owó tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wa náà, wọ́n á sì tún san ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́ta owó Yúrò [55,000] gẹ́gẹ́ bí owó tá a san fún àwọn agbẹjọ́rò. Ìyẹn mílíọ̀nù lọ́nà mẹ́wàá àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [10,725,000] náírà.

Lórílẹ̀-èdè Eritrea, ìjọba ti fi ẹ̀tọ́ àti àǹfààní táwọn ará wa ní gẹ́gẹ́ ọmọ ìlú dù wọ́n torí pé wọ́n rọ̀ mọ́ ìlànà Ọlọ́run pé ká má ṣe dá sí ọ̀ràn ogun. (Aísá. 2:4) Fóhun tó lé lọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] báyìí ni wọ́n ti ń fàṣẹ ọba mú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àádọ́ta [50] làwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n, títí kan àwọn arábìnrin tó jẹ́ arúgbó, àwọn ọmọdé, àní àwọn ọmọ ọlọ́dún méjì pàápàá wà lẹ́wọ̀n. Ó báni nínú jẹ́ pé Arákùnrin Misghina Gebretinsae ni Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ tó máa kú sẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Eritrea, ìyẹn ní July 2011. Kó tó di pé ó kú, inú ilé kan tí wọ́n fi páànù kọ́ ni wọ́n tì í mọ́ fún odidi ọ̀sẹ̀ kan gbáko. Ìròyìn tiẹ̀ fi hàn pé ikú tó pa á rúni lójú gan-an. Síbẹ̀, àwọn ará wa ṣì ń sa gbogbo ipá wọn láti jẹ́ káwọn aláṣẹ mọ̀ pé èèyàn àlàáfíà ni wá. Àti pé, bá ò tiẹ̀ dá sí ogun tó ń lọ nílùú, a ṣì ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba orílẹ̀-èdè náà.

Íńdíà: Ọ̀kan lára àwọn ará wa rèé, ìta kóòtù yìí ló wà kí wọ́n tó gbé e lọ sẹ́wọ̀n

Àwọn jàǹdùkú ò yéé fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbolẹ̀ lórílẹ̀-èdè Íńdíà nígbàkigbà tí wọ́n bá pàdé wọn lóde ìwàásù. Wọ́n rọ̀jò èébú sí wọn lórí, wọ́n tiẹ̀ lu àwọn kan ní àlùbami, títí kan àwọn ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbàlagbà. Àní wọ́n lu ìyá àgbà ẹni ọgọ́ta [60] ọdún àtọmọ ọlọ́dún kan ààbọ̀. Wọ́n tún bọ́ ẹ̀wù lọ́rùn àwọn mélòó kan, tí wọ́n sì halẹ̀ pé àwọn máa pa wọ́n. Báwọn èèyàn ṣe ń pọ́n àwọn ará wa lójú tún légbá kan torí pé àwọn ọlọ́pàá ṣe bí ẹni pé àwọn ò rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ṣe ni wọ́n tiẹ̀ tún ń súnná sọ̀rọ̀ náà. Dípò táwọn ọlọ́pàá ì bá fi fàṣẹ ọba mú àwọn ọ̀daràn náà, ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ni wọ́n fi ń kan àwọn ará wa, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ tì wọ́n mọ́lé. Kì í ṣe owó kékeré làwọn ọlọ́pàá máa ń béèrè ká tó lè gba ìdúró àwọn ará wa látìmọ́lé, wọ́n sì máa ń fi imú wọn dánrin ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá tì wọ́n mọ́lé. Wọ́n máa ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn, wọn ń febi pa wọ́n, kò sì omi bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìtọ́jú ìṣègùn. Wá-lónìí, wá-lọ́la ò lóǹkà ní kóòtù níbi tí wọ́n ti ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n á ní wọn ò jẹ̀bi, kí wọ́n máa lọ ilé. Àìmọye ẹjọ́ la ti mú lọ sọ́dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní orílẹ̀-èdè náà pé kí wọ́n dákun, kí wọ́n gbẹjọ́ àwọn ará wa rò.

Orílẹ̀-èdè Tọ́kì: Láìka ohun tí wọ́n fojú Arákùnrin Feti Demirtaş rí, kò dáṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ tó ń fìtara ṣe dúró

Ní November 2011, àwọn adájọ́ tó wà ní kóòtù Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù [ECHR] fẹnu kò pé ìjọba orílẹ̀-èdè Tọ́kì fi ẹ̀tọ́ tí Arákùnrin Yunus Erçep ní dù ú. Arákùnrin yìí sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gba òun láyè, pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun àti pé òun ò lè ṣe iṣẹ́ ológun. Èyí ló mú kí ìjọba jù ú sẹ́wọ̀n. Tá a bá kà á léní, èjì, láti March 1998, ó tí tó ìgbà mọ́kàndínlógójì [39] tí wọ́n ti ń fìwé pé Arákùnrin Erçep pé kó wá káṣọ ológun wọ̀, ó sì ti tó ọgbọ̀n [30] ìgbà tó ti fojú ba ilé ẹjọ́. Wọ́n bu owó ìtanràn lé Arákùnrin Erçep, wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n, wọ́n sì tún mú un lọ sílé ìwòsàn tí wọ́n ti ń wo wèrè, wọ́n ní ẹ̀sìn ti fẹ́ yà á ní wèrè.

Ní October 2004, Arákùnrin Erçep gbẹ́jọ́ rẹ̀ lọ sí kóòtù ECHR. Nígbà tí wọ́n ń dájọ́ náà, àwọn adájọ́ kóòtù náà sọ pé “kì í ṣe torí àǹfààní ara ẹni tọ́kùnrin yìí máa rí ló mú kó sọ pé òun ò ní wọṣẹ́ ológun, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé kò bá ìlànà Bíbélì tóun gbà gbọ́ mu.”

Ẹlẹ́rìí míì tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun lórílẹ̀-èdè yìí kan náà ni Feti Demirtaş. Ọdún 2005 ni wọ́n pè é, àmọ́ torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, wọ́n mú un, wọ́n lù ú, wọ́n pè é lẹ́jọ́, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n ọdún kan àtoṣù méje, kó tó di pé wọ́n dá a sílẹ̀ ní June 2007. Torí pé Arákùnrin Demirtaş rọ̀ mọ́ ohun tó kọ́ nínú Bíbélì, ìjọba ní kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ pé orí arákùnrin náà ti dàrú. Nígbà tí ilé ẹjọ́ ECHR ń ṣèdájọ́ rẹ̀, wọ́n ní ìwà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Tọ́kì hù sí Arákùnrin Demirtaş burú jáì àti pé ṣe ni wọ́n fi ẹ̀tọ́ tó ní láti yan ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ gbà á láyè láti ṣe dù ú.

Ìdájọ́ méjèèjì tílé ẹjọ́ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe yìí fara pẹ́ ìgbẹ́jọ́ mánigbàgbé kan tí wọ́n ṣe ní July 2011 (ìyẹn ẹjọ́ tó wáyé láàárín Arákùnrin Bayatyan àti orílẹ̀-èdè Armenia). Àwùjọ Àwọn Adájọ́ Àgbà ti Ilé Ẹjọ́ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù fàyè gba ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà láti ṣe iṣẹ́ ológun. Ìpinnu yìí sì kan gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù, títí kan orílẹ̀-èdè Tọ́kì.

Kóòtù ECHR kan náà yìí dá orílẹ̀-èdè Armenia lẹ́bi nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Bukharatyan àti orílẹ̀-èdè Armenia àtèyí tó wáyé láàárín Tsaturyan àti orílẹ̀-èdè Armenia ní January 2012. Ìgbẹ́jọ́ àwọn méjì yìí tún fi hàn pé lóòótọ́ ni orílẹ̀-èdè náà ń fọwọ́ ọlá gbá àwọn ará wa lójú torí pé wọ́n láwọn ò ṣe iṣẹ́ ológun. Nígbà tílé ẹjọ́ yìí máa dájọ́, wọ́n tọ́ka sí ìdájọ́ tí wọ́n ṣe nípa ẹjọ́ tó wáyé láàárín Arákùnrin Bayatyan àti orílẹ̀-èdè Armenia.

Pẹ̀lú gbogbo bí ilé ẹjọ́ ṣe dá orílẹ̀-èdè Armenia lẹ́bi yìí, síbẹ̀, wọ́n ṣì ń fìyà jẹ àwọn ará wa, wọ́n ń dẹ́bi fún wọn, wọ́n sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ìjọba Armenia ti ṣe àtúnṣe sí Òfin tó gba èèyàn láyè láti ṣe iṣẹ́ míì dípò iṣẹ́ ológun lóṣù March 2012. Àmọ́ títí di bá a ti ń sọ yìí, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kò tíì fara mọ́ ọn. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà ti ìjọba orílẹ̀-èdè Armenia máa tẹ̀ lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe, tí wọ́n á sì dá àwọn ará wa tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ò fẹ́ ṣiṣẹ́ ológun sílẹ̀.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ṣì ń fojú àwọn ará wa rí màbo. Bí wọ́n ṣe ń da àwọn ìpàdé wọn rú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ará wa torí pé wọ́n wà nípàdé. Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn ló ń pinnu ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa lò. Wọn ò jẹ́ káwọn ará wa tó wá látilẹ̀ òkèèrè dúró nílùú, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti òkò ọ̀rọ̀ táwọn ọlọ́pàá ń sọ, pa pọ̀ pẹ̀lú ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ará wa. Pabanbarì ẹ̀ ni pé, wọ́n láwọn máa yọ orúkọ wa kúrò lára àwọn ẹ̀sìn tí òfin gbà láyè. Látìgbà tí Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ àti Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ti sọ pé òfin ò gbà wá láyè mọ́, àwọn ọlọ́pàá wá múṣẹ́ ṣe lójú méjèèjì. Wọ́n ń da àwọn ìpàdé wa rú, wọn ò jẹ́ ká ráyè wàásù, wọn ò sì jẹ́ káwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa wọlé látòkè òkun. Ilé ẹjọ́ sì ti sọ pé ẹni tí wọ́n bá mú tó ń pín ìwé wa tàbí tó wà nípàdé máa san owó ìtanràn gọbọi. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní kí arábìnrin kan san ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-an ó lé mẹ́sàn-án [1,909] owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, torí pé ó lọ sípàdé nílùú Ganja. Ìyẹn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-an ó dín márùn-ún [295,895] náírà. Ohun tí ìjọba ń ṣe yìí ń fi ẹ̀tọ́ tá a ní láti jọ́sìn dù wa. Ó ṣe tán, Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn sọ pé ẹ̀tọ́ wa ni. Torí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ti gbẹ́jọ́ wọn lọ sí kóòtù ECHR, wọ́n sì retí pé èyí á mú kí ìjọba dẹ́kun inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wa nílẹ̀ Azerbaijan.

Láwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ńṣe làwọn agbófinró ń fòòró ẹ̀mí àwọn ará wa tí wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n. Wọ́n tún máa ń rọ ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n dá sẹ̀ríà fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé à ń jọ́sìn Ọlọ́run wa fàlàlà. Wọ́n gbófin kan kalẹ̀ pé kò sáyè fáwọn agbawèrèmẹ́sìn, òfin yìí làwọn ilé ẹjọ́ nílẹ̀ Rọ́ṣíà wá lò láti fòfin de mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] lára àwọn ìwé wa, wọ́n pè wọ́n ní ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lọ́yà kan ní kí wọ́n fòfin de ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn ọmọdé nípa Jésù Kristi, ìyẹn Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìlú lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nilé ẹjọ́ ti ní kí wọ́n ti Ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa. Wọ́n ti gba àwọn agbófinró láyè pé kí wọ́n máa fimú fínlẹ̀ láti wá àwọn ará wa, àní wọ́n tiẹ̀ gbé kámẹ́rà tí wọ́n fi ń ṣọ́ wa sáwọn ibi kọ́lọ́fín, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n máa ń já àwọn lẹ́tà tó jẹ́ tàwọn ará wa. Látàrí èyí, àwọn ọlọ́pàá lọ máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn aládùúgbò tí kò fẹ́ràn wa, wọ́n máa ń wá túlé àwọn ará, wọ́n á sì kó àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn nǹkan ìní wọn. Ọ̀pọ̀ ará ni wọ́n ti mú nígbà tí wọ́n ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n ń wakọ̀ tàbí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin. Àwọn ọlọ́pàá máa ń lọ da àwọn ìpàdé wa rú, wọ́n á sì gbé àwọn alàgbà lọ sílé ẹjọ́ torí pé wọn ń bójú tó àwọn ará wa tó wà nínú ìjọ. Kódà láwọn ibi kán lórílẹ̀-èdè náà, àwọn kan ń jà fitafita pé kí ilé ẹjọ́ fòfin de àjọ tá à ń lo nílẹ̀ náà, ìyẹn Local Religious Organizations (LRO) of Jehovah’s Witnesses.

Ní May 2012 wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn ará wa mẹ́tàdínlógún [17] nílùú Taganrog, pé ṣe ni wọ́n ń fẹ̀sìn bojú láti hùwà ọ̀daràn. Àgbègbè yìí náà ni wọ́n ti fòfin de àjọ tá à ń lò lọ́dún 2009, tí wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé Gbọ̀ngàn Ìjọba wa torí pé wọ́n ní agbawèrèmẹ́sìn ni wá. Látàrí èyí, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í lo ilé àdáni tàbí gbọ̀ngàn ìlú láti máa ṣèpàdé wọn. Àmọ́ ní báyìí, àwọn aláṣẹ tún ti ń wá bí wọ́n ṣe máa ṣí wa lọ́wọ́ ìjọsìn wa. Ní July 2012, wọ́n mú tọkọtaya tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lágbègbè Chita nílùú Siberia. Kí lẹ̀ṣẹ̀ wọn? Torí pé wọ́n fún àwọn èèyàn ní Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Làwọn aláṣẹ bá sọ pé ńṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn láti máa kórìíra torí pé ìwé náà wà lára èyí tí wọ́n fòfin dè. Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ àṣekára fún igba [200] wákàtí. Àmọ́ tọkọtaya náà ti pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Ẹ ò ní gbàgbé pé nílé lóko ni wọ́n ti ròyìn rẹ̀ nígbà tí ilé ẹjọ́ ECHR dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún 2007, nínú ẹjọ́ tí Kuznetsov àtàwọn míì pe orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtèyí tó wáyé lọ́dún 2010 láàárín Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Moscow àti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Síbẹ̀, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ náà kọ etí ikún sí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga yìí dá. Torí bẹ́ẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí ti mú ẹjọ́ mọ́kàndínlógún [19] míì lọ ilé ẹjọ́ ECHR. Ìrètí wa ni pé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ yìí á dá máa mú kí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà dẹ́kun bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Jèhófà, tí wọ́n á sì gbà wọ́n láyè láti máa gbé “ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.”—1 Tím. 2:2.

Orílẹ̀-èdè South Korea ṣì wà lẹ́nu kí wọ́n máa kó àwọn ọ̀dọ́ wa sẹ́wọ̀n torí wọ́n láwọn ò ṣiṣẹ́ ológun. Wọ́n máa ń ju nǹkan bíi márùnlélógójì [45] àwọn ọ̀dọ́ wa sẹ́wọ̀n lóṣooṣù tí wọ́n á ní kí wọ́n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún kan ààbọ̀. Ìdí rèé tí iye àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Korea ní báyìí fi fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún méje ààbọ̀ [750]. Èyí ló tíì pọ̀ jù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń ju àwọn ará wa sẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. Tá a bá ṣírò rẹ̀ látọdún 1950, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] làwọn ará wa tí wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún, àròpọ̀ ọdún tí wọ́n sì ní kí wọ́n lò lẹ́wọ̀n ju ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000] ọdún lọ.

Lọ́dún 2012, àwọn aláṣẹ ti wá gboró sí i pẹ̀lú àwọn ará wa tó láwọn ò ṣe iṣẹ́ ológun. Látọdún yẹn wá, bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ pẹ́nrẹ́n pé òun ò ṣe iṣẹ́ ológun, ẹ̀wọ̀n ló ń lọ. Tẹ́lẹ̀, wọ́n gbà pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sanwó ìtanràn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n lè pe ẹnì kan fún iṣẹ́ ológun, tó bá sì ti kọ̀, onítọ̀hún tún dèrò ẹ̀wọ̀n nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ní November 2011, wọ́n ní kí Arákùnrin Ho-jeong Son lọ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́jọ. Nígbà tó máa di June 2012, wọ́n tún gbé e wá sílé ẹjọ́, wọ́n ní kó lọ ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbé e jù sátìmọ́lé. Àmọ́, wọ́n gba onídùúró ẹ̀ nígbà tó yá, wọ́n sì dá a sílẹ̀ títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ náà. Àmọ́, ó ti lo bí oṣù kan lẹ́wọ̀n ná. Ní báyìí, ilé ẹjọ́ ní kó lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún kan àtoṣù méjì.

Ní South Korea, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí márùnlélógójì [45] ni ilé ẹjọ́ máa ń jù sẹ́wọ̀n lóṣooṣù tí wọ́n á ní kí wọ́n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún kan ààbọ̀

Àìmọye ìgbà ni Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti bẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba South Korea ṣe ń fìtínà àwọn tó sọ pé ẹ̀rí ọkàn àwọn ò ṣe iṣẹ́ ológun. A tún ti gbẹ́jọ́ wa lọ sọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ yìí àti Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè South Korea, kí wọ́n lè bá wa dá sọ́ràn náà.