Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n:

Jèhófà Baba wa ọ̀rún ló fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ fún wa. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé alágbára gbogbo ni Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò fìgbà kan rí sọ pé, “Ọlọ́run jẹ́ agbára.” Ìfẹ́ ni Ọlọ́run fi ń ṣe àbójútó wa. Inú wa mà dùn o pé a ní irú Ọlọ́run yìí!

Inú wa dùn pé Jèhófà ò fipá mú wa láti sin òun. Kì í ṣe apàṣẹwàá. Ó fẹ́ ká máa sin òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun látọkànwá. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a fara mọ́ Ìjọba rẹ̀, pé a mọ̀ pé ó ń ṣàkóso lé wa lórí lọ́nà tó tọ́ àti pé a rọ́wọ́ ìfẹ́ rẹ̀ lára wa. Àtìgbà tí ẹ̀dà èèyàn sì ti wà lórí ilẹ̀ ayé ló ti rí bẹ́ẹ̀.

Jèhófà ò sọ pé dandan ni kí Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sóun, kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wọn láǹfààní láti yan ohun tó wù wọ́n. Àmọ́, abaraámóorejẹ ẹ̀dá ni wọ́n, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbà kí Sátánì mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí Jèhófà.

Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè sọ fún wọn nínú ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tó bá wọn sọ pé: “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi, sí iwájú rẹ lónìí.” (Diu. 30:15) Àwọn fúnra wọn ló máa yan irú ìgbésí ayé tí wọ́n máa gbé. Jóṣúà náà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ó bá burú ní ojú yín láti máa sin Jèhófà, lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín.” Ohun táwọn èèyàn náà sì fi dá Jóṣúà lóhùn ni pé: “Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti fi Jèhófà sílẹ̀.” (Jóṣ. 24:15, 16) Bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wa lónìí nìyẹn. “Kò ṣeé ronú kàn” fún wa pé ká fi Jèhófà sílẹ̀. A nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a mọ̀ pé a lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá. Àwọn alàgbà lè fún wa nímọ̀ràn, kódà wọ́n lè bá wa wí, àmọ́ wọn kì í jẹ gàba lé wa lórí tàbí kí wọ́n máa fi dandan lé e pé irú ìgbésí ayé báyìí la gbọ́dọ̀ máa gbé tàbí bó ṣe yẹ ká máa sin Ọlọ́run nìyí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.”—2 Kọ́r. 1:24.

Ẹ wo bó ṣe máa ń rí lára wa tá a bá ṣe nǹkan látọkànwá dípò kó jẹ́ pé ẹnì kan ló fipá mú wa ṣe é! Jèhófà sọ fún wa pé ká jẹ́ kí ìfẹ́ máa sún wa ṣe ohun tó tọ́. Ohun tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí ìfẹ́ máa sún wa ṣe nǹkan, ó sọ pé: “Bí mo bá sì yọ̀ǹda gbogbo nǹkan ìní mi láti fi bọ́ àwọn ẹlòmíràn, tí mo sì fi ara mi léni lọ́wọ́, kí èmi bàa lè ṣògo, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò ní èrè rárá.”—1 Kọ́r. 13:3.

Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń sin Jèhófà torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn. Ó dájú pé èyí mú ìyìn bá Jèhófà, ó sì múnú rẹ̀ dùn gan-an!

Ọmọlójú Jèhófà ni gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́, títí kan ẹ̀yin ọmọ wa kéékèèké, àtẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ̀ ń fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ẹ sì ti fi hàn pé ẹ ò nífẹ̀ẹ́ ayé àti ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an ni.—Lúùkù 12:42, 43.

Láti fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́, lọ́dún tó kọjá ẹ̀yin ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin àtẹ̀yin èwe wa lo bílíọ̀nù kan, mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje àti méjìdínláàádọ́ta, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó dín mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta [1,748,697,447] wákàtí láti fi wàásù ìhìn rere náà. Ìfẹ́ ló tún mú kí àwa mílíọ̀nù méje, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé méjìlélọ́gọ́rin àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìndínláàádọ́ta [7,782,346] máa wàásù kárí ayé. Inú wa dùn gan-an pé àwọn ẹni tuntun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé méjìdínláàádọ́rin àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [268,777] tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ ọ̀dọ́ ló ya ara wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé iye èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún márùn àti méjìdínláàádọ́jọ [5,168] ló ń ṣèrìbọmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Èyí wú wa lórí gan-an ni!

Lákòókò òpin tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ ìṣòro ṣì lè máa bá àwa èèyàn Ọlọ́run fínra, ìbànújẹ́ lè dorí wa kodò, wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa, àìsàn àti ọjọ́ ogbó sì lè máa bá àwọn ẹlòmíì fínra. Àmọ́ a ti pinnu pé bíná ń jó, bí ìjì ń jà, a ò ní “fà sẹ́yìn” láé, a ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun mú ká “juwọ́ sílẹ̀.” A nífẹ̀ẹ́ yín gan-an ni. Ire o.—Héb. 10:39; 2 Kọ́r. 4:16.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà