Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2017

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2017
  • Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 90

  • Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 240

  • Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 120,053

  • Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 20,175,477

  • Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 18,564

  • Góńgó Akéde *: 8,457,107

  • Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 8,248,982

  • Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2016: 116,260

  • Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi *: 284,212

  • Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé * Lóṣooṣù: 1,249,946

  • Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 439,571

  • Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 2,046,000,202

  • Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì * Lóṣooṣù: 10,071,524

Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2017, * ó ju igba ó lé méjì [202] mílíọ̀nù owó dọ́là táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Kárí ayé, iye àwọn tó ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ọgbọ̀n [19,730]. Gbogbo wọn wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 7 Akéde tọ́ka sí àwọn tó ń kéde tàbí tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa bá a ṣe mọ iye wọn, wo àpilẹ̀kọ náà “ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ohun tẹ́nì kan máa ṣe kó tó ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “ Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ ìpínrọ̀ 11 Aṣáájú-ọ̀nà ni Ẹlẹ́rìí kan tó ti ṣe ìrìbọmi tó sì níwà tó dáa. Ó pinnu láti máa lo iye wákàtí kan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lóṣooṣù.

^ ìpínrọ̀ 14 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kí Là Ń Pè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ ìpínrọ̀ 15 Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2017 bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2016, ó sì parí ní August 31, 2017.