Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ìpàdé Tuntun fún Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni

Ìpàdé Tuntun fún Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni

LÓPIN ìpàdé ọdọọdún tí àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ṣe ní October 3, 2015, arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí kéde pé ìpàdé tuntun, ìyẹn Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni, ló máa rọ́pò ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Arákùnrin Morris tún ṣàlàyé pé ìwé tuntun kan máa rọ́pò Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ó máa jẹ́ aláwọ mèremère, á ní ojú ìwé mẹ́jọ, oṣooṣù lá sì máa jáde, orúkọ rẹ̀ ni Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé. Ohun tí àá máa ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lá máa wà nínú ìwé yìí, á sì láwọn àwòrán tó máa jẹ́ kí Bíbélì kíkà túbọ̀ nítumọ̀ síni.

Apá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìpàdé tuntun yìí pín sí:

  1. Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun àkọ́kọ́ nínú apá yìí ni àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá tó dá lórí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ àti àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé ìpàdé. “Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni èkejì, ìbéèrè àti ìdáhùn tó máa gba ìṣẹ́jú mẹ́jọ ni, orí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló sì dá lé. Lẹ́yìn ìyẹn ni apá oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin tó jẹ́ Bíbélì kíkà.

  2. Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù. Lọ́pọ̀ ìgbà nínú apá yìí, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ta máa ṣe àṣefihàn bí a ṣe ń kọ́ni nígbà àkọ́kọ́, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

  3. Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni. Apá yìí la ti ń jíròrò béèyàn ṣe lè máa lo àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé ẹni ojoojúmọ́. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú apá yìí, ìbéèrè àti ìdáhùn sì ni.

Àwọn akéde kárí ayé sọ bí wọ́n ṣe mọyì ẹ̀kọ́ tó gbéṣẹ́ tí ìpàdé tuntun yìí ń kọ́ni. Arákùnrin kan ní Ọsirélíà kọ̀wé pé: “Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ yìí dáa gan-an! Àwọn ohun tá à ń kọ́ níbẹ̀ ti túbọ̀ wúlò fún wa nígbèésí ayé, àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ inú ẹ̀ sì rọrùn. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ìpàdé ti parí, torí pé apá kọ̀ọ̀kàn ò gùn jù, ó ṣe ṣàkó, ó sì ń wọni lọ́kàn, pàápàá àwọn fídíò tó wà níbẹ̀ àti báwọn ọmọdé ṣe ń kópa.”

Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kan lórílẹ̀-èdè Ítálì kọ̀wé pé: “A ti rí i pé ìpàdé tuntun yìí ti mú kó máa wu gbogbo wa láti túbọ̀ múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, èyí sì ti jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́. Ọ̀nà tuntun tí à ń gbà ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ yìí jẹ́ àtúnṣe ńlá tí Jèhófà ṣe sí ọ̀nà tó gbà ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Akéde kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sọ pé: ‘Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó máa ń ṣòro fún mi láti pọkàn pọ̀ nípàdé láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Àmọ́ ìpàdé tuntun yìí ti jẹ́ kí n lè máa pọkàn pọ̀, kí n sì máa múra sílẹ̀ dáadáa láti ilé.’ ”

Ìdílé kan láti orílẹ̀-èdè Austria kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀, iṣẹ́ ńlá la máa ń ṣe tí àwa àti ọmọ wa obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá bá jọ ń ka Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Àmọ́ apá ‘Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ ti jẹ́ kó máa wù wá láti dáhùn fàlàlà nípàdé. Ní báyìí, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta là ń gbádùn ẹ̀ tá a bá ń múra Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀. Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, a ti wá rí bí ọmọ wa ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.”

Ines láti orílẹ̀-èdè Jámánì ṣàlàyé pé: “Ó ti wá ń wù mí láti máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, kí n sì túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tó wà níbẹ̀. Mi ò ṣe irú ìwádìí tó jinlẹ̀ báyìí rí. Mo ti ní àjọṣe tó dáa sí i pẹ̀lú Jèhófà báyìí. Ayé Sátánì máa ń jẹ́ kó rẹ̀ mí, ó sì máa ń tán mi lókun. Àmọ́ àwọn ìpàdé yìí ló ń fún mi lókun, tó sì ń jẹ́ kí n lè máa bá a lọ.”

Àwọn ìjọ tó wà ní Erékùṣù Solomon ń gbádùn ọ̀nà tuntun tí à ń gbà ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ gan-an, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè jàǹfààní nínú rẹ̀ dáadáa. Ọ̀pọ̀ ìjọ ló wà ní àdádó, níbi tí kò síná, tí kò sì sí Íńtánẹ́ẹ̀tì, iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn ará tó wà níbẹ̀ fi ń gbéra. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe rí ohun tí wọ́n fi ń wo fídíò, tí wọ́n sì ń rọ́nà gba àwọn fídíò tó ń jáde lóṣooṣù tá a máa ń wò nípàdé? Àwọn akéde tó wà ní ìjọ kan ní erékùṣù Malaita pinnu láti jọ ṣiṣẹ́, kí wọ́n lè máa ta àgbọn gbígbẹ. Wọ́n wá fi owó tí wọ́n rí sínú àpótí ìjọ, kí wọ́n lè ra ẹ̀rọ tó ṣeé wo fídíò, èyí tó jẹ́ pé oòrùn ni wọ́n fi ń gbaná sí i lára. Báwo ni wọ́n ṣe wá ń rí fídíò gbà sórí ẹ̀rọ náà? Ńṣe ni àwọn arákùnrin máa ń rìnrìn àjò lọ sí ibi tó sún mọ́ wọn jù tí wọ́n ti lè rí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n lè wa àwọn fídíò náà jáde, lẹ́yìn náà, wọ́n á fún àwọn ará tó wà nínú ìjọ.

Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “Ó dà bíi pé ohun tí mo bá fojú rí, bí àwòrán tàbí fídíò, ló máa ń yé mi jù. Tí mo bá ń ka nǹkan kan, àfi kí n kà á lákàtúnkà kí ohun tó wà níbẹ̀ tó lè yé mi, tí màá sì lè ṣàlàyé ẹ̀ fún ẹlòmíì. Ohun tí mò ń bá fà á nìyẹn fún ohun tó lé ní ogójì [40] ọdún báyìí. Torí náà, mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún gbogbo fídíò àti àwòrán tí wọ́n fi ń kọ́ wa. Fídíò tó máa ń sọ ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan yẹn ti lọ wà jù, àwọn àwòrán tó sì wà nínú ìwé ìpàdé yẹn dáa gan-an, ohun tí mo nílò gẹ́lẹ́ nìyẹn! Ó ṣe kedere pé Jèhófà ń bù kún ìsapá yín lórí ohun tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ yìí. Ẹ ṣé gan-an ni.”

Màláwì