JỌ́JÍÀ | 1924-1990
Àwọn Tó Ń Wá Òtítọ́ Láyé Ìgbà Kan
ÀTỌDÚN díẹ̀ ṣáájú ọdún 1930 ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń sapá láti wá àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lójú méjèèjì kàn lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà. Lọ́dún 1924, wọ́n ṣí ọ́fíìsì kan sí ìlú Beirut, ní Lebanon, kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Àméníà, Jọ́jíà, Síríà àti Tọ́kì.
Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fún irúgbìn òtítọ́ sí orílẹ̀-èdè Jọ́jíà nígbà yẹn, àmọ́ ó dà bíi pé kò kọ́kọ́ fẹ́ méso jáde. (Mát. 13:33) Nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tàn kálẹ̀, ó sì mú kí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní Jọ́jíà yí pa dà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.
Ohun Tó Tọ́ Ló Fẹ́
Vaso Kveniashvili ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Torí pé Jọ́jíà wà lábẹ́ ìjọba Soviet Union, kò pẹ́
tí wọ́n fi mú bàbá Vaso wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Soviet. Ìyá Vaso ti kú nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ Vaso ni àkọ́bí. Bó ṣe di pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í jalè nìyẹn kó lè máa tọ́jú ara ẹ̀ àtàwọn àbúrò ẹ̀.Vaso wọ ẹgbẹ́ burúkú, ó sì wá di adigunjalè. Ó sọ pé, “Lójú tèmi, torí pé ìwà ìrẹ́jẹ ló kúnnú ayé, ó ṣì dáa kéèyàn máa hùwà ọ̀daràn ju kó máa bá wọn ṣe òṣèlú tàbí kó máa bá wọn ṣe ẹgbẹ́ kílùú-má-bà-jẹ́.” Àmọ́ Vaso wá rí i pé agbára èèyàn ò lè yanjú ìṣòro náà. Ó ní, “Ohun tó tọ́ ni mo fẹ́.”
Wọ́n pa dà mú Vaso nítorí ìwà ọ̀daràn tó ń hù, wọ́n sì rán an lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan ní Siberia. Ibẹ̀ ló ti rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tó gbà gbọ́. Vaso ní, “Ọwọ́ mi wá tẹ ohun tí mò ń wá. A ò ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́
kankan nínú ẹ̀wọ̀n yẹn o, àmọ́ mo rí i pé mo tẹ́tí sí arákùnrin yẹn dáadáa kí n lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ń bá mi sọ.”Nígbà tí wọ́n dá Vaso sílẹ̀ lọ́dún 1964, ó pa dà sí Jọ́jíà, ó sì wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ. Ní gbogbo ìgbà tó fi ń wá wọn, ó máa ń kọ lẹ́tà sí arákùnrin tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n nígbà yẹn. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá ọ̀rẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí ṣaláìsí, bí Vaso ò ṣe rí ìkankan nínú àwọn èèyàn Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀ mọ́ nìyẹn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] ọdún lẹ́yìn ìyẹn kó tó pa dà rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A máa sọ púpọ̀ nípa ẹ̀ tó bá yá.
Adùn Ló Ń Gbẹ̀yìn Ewúro
Wọ́n fi ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Valentina Miminoshvili, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jọ́jíà sẹ́wọ̀n ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì, àmọ́ adùn ló gbẹ̀yìn ewúro fún un. Inú ẹ̀wọ̀n yìí ló ti kọ́kọ́ pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbàgbọ́ wọn tí kò yẹ̀ ló
wú Valentina lórí jù lọ. Ohun tí wọ́n kọ́ ọ nínú Bíbélì wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an.Nígbà tí ogun parí, Valentina pa dà sílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ fáwọn èèyàn. Àmọ́ kò pẹ́ tọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìlú wọn fi tẹ̀ ẹ́ torí ohun tó ń ṣe, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ibẹ̀ ló tún ti pa dà rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá.
Lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lọ́dún 1967, Valentina kó lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́jíà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù níbẹ̀, àmọ́ ṣe ló ń fọgbọ́n ṣe é. Kò mọ̀ pé Jèhófà máa tó lo òun láti dáhùn àdúrà tẹ́nì kan gbà tọkàntọkàn.
Jèhófà Dáhùn Àdúrà Rẹ̀
Lọ́dún 1962, Arábìnrin Antonina Gudadze kó kúrò ní Siberia lọ sí Jọ́jíà nígbà tí ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pinnu pé òun fẹ́ pa dà sí ìlú òun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba kó lọ sí Siberia ti kọ́kọ́ ń kọ́ Antonina lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ níbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí tó ti ń gbé nílùú Khashuri, ní ìlà oòrùn Jọ́jíà, ó ti wá jìnnà sí àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀.
Antonina rántí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀, ó ní: “Lọ́jọ́ kan, mo rí ẹrù kan tí màmá mi fi ránṣẹ́ láti Siberia gbà, nígbà tí mo tú u, mo rí àwọn ìwé wa tí wọ́n tọ́jú pa mọ́ sínú ẹ̀. Bí mo ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà nìyẹn fún ọdún mẹ́fà tó tẹ̀ lé e. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti rí i gbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń tọ́ mi sọ́nà, ó ń gbé mi ró, ó sì ń tọ́jú mi.”
Síbẹ̀, Antonina ò tíì rí àwọn ará. Ó ní: “Mi ò yéé bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n tún rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi. Lọ́jọ́ kan, àwọn obìnrin méjì wọ inú ṣọ́ọ̀bù tí mo ti ń ṣiṣẹ́, àkáǹtì ọjà ni mò ń bójú tó níbẹ̀. Wọ́n bi mí pé,
‘Ṣé ìwọ ni Antonina?’ Ojú wọn tó fani mọ́ra tí mo rí ti jẹ́ kí n mọ̀ pé arábìnrin mi ni wọ́n. La bá dì mọ́ra, a sì bú sẹ́kún.”Valentina Miminoshvili ni ọ̀kan lára wọn. Inú Antonina dùn gan-an nígbà tó gbọ́ pé àwọn ará ti ń ṣèpàdé ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́jíà! Ó máa ń lọ sípàdé lẹ́ẹ̀kan lóṣù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibẹ̀ jìnnà gan-an sílé rẹ̀, ó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] kìlómítà lọ.
Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Fìdí Múlẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn Jọ́jíà
Láàárín ọdún 1960 sí 1969, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń wá bí wọ́n á ṣe kó lọ sáwọn ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà torí pé àwọn aláṣẹ ìlú kan tó wà lábẹ́ ìjọba Soviet Union ń ṣe inúnibíni sí wọn. Arákùnrin Vladimir Gladyuk wà lára wọn, ó nítara, ó sì lẹ́mìí iṣẹ́. Lọ́dún 1969, ó kó kúrò ní orílẹ̀-èdè Ukraine lọ sílùú Zugdidi, ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́jíà.
Èdè Rọ́ṣíà làwọn tó kó wá sí Jọ́jíà kọ́kọ́ fi ń ṣèpàdé. Àmọ́ bó ṣe di pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Jọ́jíà ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì
ń wá sípàdé déédéé, wọ́n ṣètò pé kí wọ́n máa fi èdè Jọ́jíà ṣèpàdé. Iṣẹ́ ìwàásù sì sèso rere gan-an níbẹ̀ torí pé ní August 1970, àwọn ọmọ ìlú yẹn méjìlá [12] ló ṣèrìbọmi.Nígbà ìrúwé ọdún 1972, Vladimir àti ìdílé rẹ̀ kó lọ síbi tó túbọ̀ jìnnà ní ìwọ oòrùn. Ìlú Sokhumi ni wọ́n kó lọ, létí Òkun Dúdú. Vladimir sọ pé: “Jèhófà ń bù kún wa gan-an nípa tẹ̀mí, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó ń ràn wá lọ́wọ́. Ìjọ tó wà nílùú yẹn tètè dàgbà.” Àsìkò yẹn ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi nílùú Sokhumi, àwọn márùndínláàádọ́ta [45] ló sì wà níbẹ̀.
“Tọkàntara Ni Mo Fi Tẹ́tí sí Wọn”
Arábìnrin Babutsa Jejelava, tó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí, wà lára àwọn tó kọ́kọ́ yára kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nílùú Sokhumi níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1973. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́
kan, mo rí àwọn obìnrin mẹ́rin tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń gbádùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ. Ẹlẹ́sìn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ni méjì nínú wọn, mo sì wá pa dà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn méjì tó kù.” Lyuba ni orúkọ ọ̀kan nínú Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà, òun ni ìyàwó arákùnrin Vladimir Gladyuk. Itta Sudarenko sì ni ẹnì kejì, aṣáájú-ọ̀nà tó nítara ni, láti orílẹ̀-èdè Ukraine.Babutsa rántí bó ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí ohun tí wọ́n ń sọ ta sí i létí, ó ní, “Tọkàntara ni mo fi tẹ́tí sí wọn.” Nígbà tó gbọ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ, lòun náà bá yára dá sí ọ̀rọ̀ táwọn obìnrin náà ń sọ, ó sì ní kí wọ́n fi han òun nínú Bíbélì. Ṣe ló ń da ìbéèrè bò wọ́n, débi pé wákàtí mẹ́ta ni wọ́n fi sọ̀rọ̀.
Ẹ̀rù wá ń ba Babutsa pé òun lè máà rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ló bá bi wọ́n pé, “Ṣé ẹ máa wá fi èmi nìkan sílẹ̀ níbí ni?”
Àwọn arábìnrin náà dá a lóhùn pé: “Rárá, a ò ní fi ẹ́ sílẹ̀. A máa pa dà wá ní Sátidé tó ń bọ̀.”
Àwọn arábìnrin yẹn pa dà wá lọ́jọ́ Sátidé lóòótọ́, inú Babutsa sì dùn gan-an! Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń parí lọ, Babutsa ń ronú nǹkan tó lè ṣe kó má bàa di pé òun ò ní fojú kan àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́. Ó ń sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé: ‘Mo ti rí àwọn èèyàn yìí ná. Mi ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́.’
Babutsa ronú ohun kan tó lè ṣe. Ó ní: “Mo mọ̀ pé Lyuba ti lọ́kọ, mo bá bi Itta bóyá òun náà ti lọ́kọ. Itta fèsì pé rárá. Ni mo bá kígbe pé, ‘Ó yá, máa kó bọ̀ lọ́dọ̀ mi! Bẹ́ẹ̀dì méjì ni mo ní, àtùpà kan sì wà láàárín méjèèjì. A lè gbé Bíbélì síbẹ̀, ká sì jọ máa sọ̀rọ̀ Ọlọ́run kódà tílẹ̀ bá tiẹ̀ ṣú!’” Itta gba ohun tí Babutsa sọ, ó sì kó lọ sílé rẹ̀.
Babutsa rántí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó ní: “Ìgbà míì, mi ò ní sùn lóru, màá máa ronú lórí ohun tí mo ti kọ́. Ìbéèrè kan lè dédé sọ sí mi lọ́kàn. Màá yára jí Itta, màá ní: ‘Itta, mo ní ìbéèrè kan. Jọ̀ọ́ gbé Bíbélì ẹ.’ Oorun ṣì máa ń wà lójú Itta, àmọ́ á sọ pé, ‘Ó dáa, ọ̀rẹ́ mi.’ Itta á wá ṣí Bíbélì ẹ̀, á sì fi ìdáhùn hàn mí níbẹ̀.” Kò ju ọjọ́ mẹ́ta tí Itta kó dé ọ̀dọ̀ Babutsa tí Babutsa fi bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù!
Babutsa ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan tó ń jẹ́ Natela Chargeishvili. Babutsa rántí ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí, ó ní: “Mo rò pé owó tó ní ò ní jẹ́ kó lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò. Àtìgbà tá a ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ ló ti gbà á, ó sì ń jó lọ́kàn rẹ̀ bí iná.” Kò pẹ́ táwọn méjèèjì fi bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn aládùúgbò wọn.