JỌ́JÍÀ
Mo Fẹ́ Káyé Mi Nítumọ̀
Davit Samkharadze
-
WỌ́N BÍ I NÍ 1967
-
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1989
-
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Alábòójútó arìnrìn-àjò ni. Àmọ́ látọdún 2013, ó ti di olùkọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì.
LỌ́DÚN 1985, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], àwọn aláṣẹ ìjọba Soviet Union mú mi wọṣẹ́ ológun. Ìwà ìrẹ́jẹ tó gbilẹ̀ láàárín àwọn ológun ò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, bí wọ́n sì ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn ò múnú mi dùn. Mo wá sọ lọ́kàn mi pé: ‘Mi ò fẹ́ dà bíi tiwọn. Mo fẹ́ kí tèmi yàtọ̀.’ Àmọ́ mo rí i pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni mo lè máa ṣe ohun tó wù mí. Mo fẹ́ káyé mi nítumọ̀.
Nígbà tí mo sin ìjọba tán lẹ́nu iṣẹ́ ológun, mo pa dà wálé. Mo lọ síbi àríyá lálẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí mo délé, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run. Mo bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí n túbọ̀ máa ṣe ohun tó dáa. Nígbà tí mò ń lọ ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ kejì, mo ya ọ̀dọ̀ àǹtí mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí mo ṣe wọnú ilé wọn, mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó kan tí wọ́n kóra jọ, wọ́n fẹ́ ṣèpàdé. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi kí mi káàbọ̀, mo bá ní kí n dúró, kí n gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ níbẹ̀.
Mo jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ni mo sì ṣèrìbọmi. Jèhófà ti tún ayé mi ṣe, ohun tágbára mi ò gbé ló ti bá mi ṣe.