Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JỌ́JÍÀ

Ibo Lẹ Wà Látọjọ́ Yìí?

Artur Gerekhelia

Ibo Lẹ Wà Látọjọ́ Yìí?
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1956

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1991

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Oṣù mẹ́jọ péré lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó fi ilé àti iṣẹ́ rẹ̀ tó ń mówó gọbọi wọlé sílẹ̀ kó lè lọ sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i.

KÒ PẸ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi làwọn alàgbà bí mi pé ṣé ó máa wù mí kí n fi kún iṣẹ́ ìwàásù mi. Ní May 4, 1992, mo bá wọn ṣe ìpàdé tí wọ́n dìídì ṣètò fún àwọn tó fẹ́ lọ sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Lọ́jọ́ kejì, èmi àti ẹni tí wọ́n yàn pẹ̀lú mi lọ sí etíkun Batumi, ní àgbègbè Ajaria.

Nígbà àkọ́kọ́ tí mo wàásù ní Batumi, ṣe lẹ̀rù ń bà mí. Mo bi ara mi pé, ‘Báwo ni kí n ṣe bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?’ Ohun tí obìnrin àkọ́kọ́ tí màá bá sọ̀rọ̀ sọ yà mí lẹ́nu gan-an, ó sọ pé, “Ibo lẹ wà látọjọ́ yìí?” Ó ti ń wá bó ṣe máa mọ̀ sí i nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà débi pé ọjọ́ kejì ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa!

Ká tó wá sí Batumi, wọ́n fún wa ní àdírẹ́sì àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí pé a ò mọ ìlú náà dáadáa, à ń béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn ará àdúgbò. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ò mọ ibi tí à ń lọ torí pé èyí tó pọ̀ jú nínú àwọn àdúgbò náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí orúkọ rẹ̀ pa dà, àmọ́ wọ́n fetí sọ́rọ̀ wa. Kò pẹ́ sígbà yẹn tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwùjọ èèyàn bíi mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Oṣù mẹ́rin péré lẹ́yìn tá a dé, ó ti lé ní ogójì [40] èèyàn tó ń wá sípàdé wa déédéé. Torí náà, a bi ara wa pé, ‘Ta lá máa bójú tó àwọn ẹni tuntun yìí?’ Lẹ́yìn náà, ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yin ìjà tó wáyé láàárín àwọn ọmọ ogun Jọ́jíà àti àwọn tó yapa ní Abkhazia mú kí gbogbo ara ìjọ mi tẹ́lẹ̀ kó wá sí Batumi. Ọjọ́ kan péré ni ìjọ tuntun tó ní àwọn alàgbà onírìírí àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé fi dúró!