Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JỌ́JÍÀ

Ìfẹ́ Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Yẹ̀

Ìfẹ́ Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Yẹ̀

Igor: Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Tkvarcheli, ní Abkhazia ni àwa méjèèjì wà. Torí pé ìjọ tí àwùjọ wa ń dara pọ̀ mọ́ wà ní ìlú Jvari, tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́rùn-ún [85] sí ibi tá a wà, oṣooṣù ni mo máa ń rìnrìn àjò lọ sílùú Jvari láti kó ìwé wá fún àwùjọ wa tó wà ní àdádó. Lọ́dún 1992, lẹ́yìn tí ìjọba Soviet Union kógbá wọlé, àwọn èèyàn àgbègbè Abkhazia fẹ́ gbòmìnira. Lọ̀rọ̀ ọ̀hún bá di ogun láàárín wọn àtàwọn ọmọ ogun Jọ́jíà, èyí sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà.

Gizo Narmania and Igor Ochigava

Àwọn arákùnrin méjì yìí jọ ṣiṣẹ́ láti ran àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn lọ́wọ́ nígbà ogun Abkhazia.

Gizo: Mo ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mọ́kànlélógún [21], ọdún yẹn ló sì ṣáájú ọdún tí ìjà náà bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, ẹ̀rù kọ́kọ́ ń ba àwọn ará, wọn ò sì mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe máa rí. Àmọ́ arákùnrin Igor, tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àtàtà, fún wá níṣìírí, ó ní: “Àkókò yìí gan-an ni àwọn èèyàn nílò ìtùnú. Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí àjọṣe àwa àti Jèhófà máa lágbára ni pé ká máa wàásù.” Torí náà, ojoojúmọ́ là ń bá àwọn aládùúgbò wa sọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ a máa ń ṣọ́ra ṣe.

Igor: Nítorí ogun náà, a ò lè gba ibi tí a máa ń gbà lọ sí ìlú Jvari mọ́ láti lọ kó ìwé, a ò sì lè gbabẹ̀ pa dà. Àmọ́ torí pé àgbègbè yẹn ni mo dàgbà sí, mo wá ọ̀nà tó fini lọ́kàn balẹ̀ nínú oko tí wọ́n ń gbin ewé tíì sí àti níbi tí àwọn òkè wà. Síbẹ̀, ewu wà! Èèyàn lè bá àwọn tó ń jagun pàdé tàbí kéèyàn tiẹ̀ lọ gbẹ́sẹ̀ lé ibi tí wọ́n ri bọ́ǹbù sí. Àmọ́, mi ò fẹ́ fi ẹ̀mí àwọn arákùnrin mi sínú ewu, torí náà, mo máa ń dá nìkan rìnrìn àjò náà lẹ́ẹ̀kan lóṣù. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, gbogbo ìgbà ni mò ń rí oúnjẹ tẹ̀mí kó délé, èyí sì ń mú ká lókun nípa tẹ̀mí.

Bo tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí wàhálà ní Tkvarcheli, kò pẹ́ tí wọ́n fi sé wa mọ́ ìlú, bí àwa náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mọ wàhálà ogun náà lára nìyẹn. Nígbà tí àkókò òtútù ń sún mọ́, oúnjẹ ti ń tán nílé, gbogbo wa sì ń dààmú bá a ṣe máa rí nǹkan jẹ. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó nígbà tá a gbọ́ pé àwọn ará wa ní Jvari ti ṣètò láti ràn wá lọ́wọ́!

Gizo: Lọ́jọ́ kan, Igor béèrè lọ́wọ́ ìdílé wa bóyá a lè jẹ́ kí wọ́n máa tọ́jú oúnjẹ táwọn ará kó wá sínú ilé wa, kí wọ́n sì máa pín in fáwọn ara látibẹ̀. Lákòókò yìí, Igor ń ṣọ̀nà bó ṣe máa lọ kó oúnjẹ wá láti Jvari. Ọkàn wa ò balẹ̀ sí ìrìn tó fẹ́ rìn yìí, torí a mọ̀ pé ó máa gba oríṣiríṣi ibi tí wọ́n ti máa ń yẹ èèyàn wò kó tó kọjá, ó sì lè pàdé àwọn ọmọ ogun tàbí àwọn olè.Jòh. 15:13.

Inú wa dùn gan-an pé Igor dé láyọ̀ àti àlàáfíà lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tó ti lọ, ó wa ọkọ̀ tí oúnjẹ kún inú rẹ̀ dé, oúnjẹ náà sì máa tó wa jẹ láwọn oṣù tójò á fi rọ̀! Láwọn àkókò tó le yẹn, àwa fúnra wa rí i kedere pé ìfẹ́ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ ní kì í yẹ̀.1 Kọ́r. 13:8.