Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JỌ́JÍÀ

Mò Ń Wò Ó Pé Ayé Mi Ti Dáa

Madona Kankia

Mò Ń Wò Ó Pé Ayé Mi Ti Dáa
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1962

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1990

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọmọ Ẹgbẹ́ Ìjọba Kọ́múní ìsì ní Jọ́jíà ni tẹ́lẹ̀, ó sì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ­kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lọ́dún 2015, ó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì àkọ́kọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run nílùú Tbilisi.

NÍGBÀ tí mo kọ́kọ́ gbọ́ òtítọ́ inú Bíbélì lọ́dún 1989, ọ̀kan pàtàkì nínú Ẹgbẹ́ Ìjọba Kọ́múníìsì ni mo jẹ́ ní Senaki, ìlú ìbílẹ̀ mi. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń wà nínú ìpàdé tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga ti Jọ́jíà bá ṣe, ìyẹn dà bí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin òde òní. Mo sì tún ní ọ̀dọ́kùnrin kan tí mò ń fẹ́ sọ́nà, torí náà mo máa ń wò ó pé ayé mi ti dáa.

Mọ́mì àti Dádì mi ti gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sí mi lọ́kàn. Torí náà, mo gba Ọlọ́run gbọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóṣèlú ìjọba Kọ́múníìsì ni mí. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí gbogbo àwọn ìbéèrè mi, torí náà, mo pinnu láti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Àmọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí mi, àwọn ọ̀rẹ́ mi, àwọn ará ibi iṣẹ́ mi àti àfẹ́sọ́nà mi kò fara mọ́ ìpinnu tí mo ṣe.

Ìsìn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí mú kí àwọn èèyàn mi pa mí tì, ìgbàgbọ́ mi ò sì bá iṣẹ́ olóṣèlú tí mò ń ṣe mu. Mo ní kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe, àfi kí n filé sílẹ̀, kí n fi ẹni tí mò ń fẹ́ sílẹ̀, kí n sì kọ̀wé fiṣẹ́ silẹ̀, títí kan iṣẹ́ mi nínú Ẹgbẹ́ Ìjọba Kọ́múníìsì àti ti Ìgbìmọ̀ Aṣòfin. Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ mi túbọ̀ fúngun mọ́ mi. Torí pé gbajúmọ̀ ni mí nílùú mi, mo kó lọ sílùú Kutaisi, ojú ẹsẹ̀ ni mo sì bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀.

Tí àwọn èèyàn bá bi mí pé, ṣé ìsìn tí mo gbà tó gbogbo bí mo ṣe fira mi jìyà, kíákíá ni mo máa ń sọ fún wọn pé ìpinnu tí mo ṣe ń múnú mi dùn gidigidi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi ò mọ ìdí tí mo fi ṣe àwọn ìpinnu tí mo ṣe, inú mi dùn pé wọ́n kọ́ mi láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò mi. Èyí ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbèésí ayé mi.