JỌ́JÍÀ
‘Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe Lọ́dọ̀ Ọlọ́run’
Natela Grigoriadis
-
WỌ́N BÍ I NÍ 1960
-
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1987
-
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Torí pé Natela mọ̀ nípa káràkátà, ó sì mọ̀ọ̀yàn dáadáa, kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn ará lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ lábẹ́lẹ̀.
LÁÀÁRÍN ọdún 1985 sí 1989, tá a bá ń ṣèpàdé, ẹni tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nìkan ló máa ń ní ìwé lọ́wọ́, èyí tí wọ́n fọwọ́ dà kọ ló sì sábà máa ń jẹ́. Mo lọ bá arákùnrin Genadi Gudadze, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà, mo sì dá a lábàá pé ká máa tẹ ìwé fúnra wa.
Kó tó dìgbà yẹn, ẹ̀rọ kan táwọn ará ṣe, ìyẹn mimeograph ni wọ́n máa ń fi tẹ ìwé, ìwọ̀nba ni wọ́n sì máa ń rí tẹ̀. Tí wọ́n bá fẹ́ máa tẹ̀wé jáde déedée, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rọ mimeograph tó dáa jùyẹn lọ, kí wọ́n ní ẹnì kan tó mọ ìwé tẹ̀ dáadáa àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, kí wọ́n sì ní ibi tí wọ́n á ti máa rí bébà rà. Àmọ́ gbogbo ohun tí wọ́n fi ń tẹ̀wé, títí kan bébà, ni ìjọba gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí kéèyàn tó lè ní in, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ló sì ń bójú tó wọn.
Mo mọ ẹnì kan tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìtẹ̀wé, mo sì rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ torí ó mọ ibi tí wọ́n máa ń kó àwọn ẹ̀rọ tí wọn ò lò mọ́ sí, tí kò sí lábẹ́ àbójútó ìjọba mọ́. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mọ ìwé tẹ̀ dáadáa, ó sì lè máa bá wa tẹ̀wé. Àwọn ará wá ṣe ẹ̀rọ
tuntun kan tí wọ́n á máa fi tẹ̀wé, wọ́n sì wá ibi tí wọ́n á ti máa ra bébà. Gbogbo ètò tá a ṣe ló bọ́ sí i, kò sì pẹ́ tá a fi ṣe ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ wa àkọ́kọ́ lédè Jọ́jíà.Àmọ́ ìṣòro kan yọjú. Lọ́jọ́ kan, Genadi sọ fún mi pé, “A máa ní láti wá ọ̀nà míì tá ó fi máa rí bébà rà.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ó rí àwọn bébà yẹn ní iléeṣẹ́ ìjọba kan, àmọ́ kò lè lọ rà á fúnra ẹ̀ torí pé àwọn agbófinró ń ṣọ́ ọ. Báwo la ṣe máa wá rí i rà? Ṣe ni mo ṣáà ń sọ pé, “Kò lè ṣeé ṣe!” Ni Genadi bá fìgboyà sọ pé, “Má sọ pé ‘Kò lè ṣeé ṣe.’ ‘Ohun gbogbo ṣeé ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run’!”
Lọ́jọ́ kejì, mo gbọ̀nà iléeṣẹ́ ìjọba náà lọ. Ọ̀rọ̀ yẹn ni mò ń rò ṣáá, ẹ̀rù sì ń bà mí bí mo ṣe ń lọ. Àmọ́, Jèhófà gbé mi pàdé obìnrin dáadáa kan tó máa ń tẹ̀wé. Mo sọ ohun tí mo bá wá fún un, ó sì sọ pé òun máa fi tó ọ̀gá iléeṣẹ́ náà létí. Àṣé ọkọ ẹ̀ lọ̀gá yẹn! Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rí bébà rà ní iléeṣẹ́ yìí nìyẹn o, a ò sì níṣòro kankan mọ́ látìgbà yẹn lórí bá a ṣe máa rí bébà rà.