Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe àpéjọ àgbègbè nílùú Tacoma, Washington, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1917

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1917

ILÉ ÌṢỌ́ January 1, 1917 sọ pé, “Títí a fi wọ ọdún tuntun, ṣe ni wàhálà ń ṣẹlẹ̀, tí gbogbo nǹkan ń dà rú, táwọn èèyàn sì ń para wọn nípakúpa.” Ìgbà yẹn ni Ogun Àgbáyé Kìíní ń jà, táwọn èèyàn sì ń para wọn nípakúpa kárí ayé. Ogun Ńlá ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí nígbà yẹn, kò sì rọlẹ̀ rárá nílẹ̀ Yúróòpù.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò tíì mọ ohun tó túmọ̀ sí délẹ̀délẹ̀ pé káwọn Kristẹni má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló yẹra fún ohun tó máa mú kí wọ́n tàjẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì wúni lórí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè England, Stanley Willis tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] pinnu pé òun ò ní dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Kó tó di pé ó fojú ba ilé ẹjọ́ torí pé kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ológun, ó kọ̀wé pé: “Àǹfààní ńlá ni mo kà á sí pé wọ́n fún mi láyè láti sọ tẹnu mi. Ọ̀gá ológun sọ fún mi láàárọ̀ yìí pé wọ́n á pa á láṣẹ fún mi pé kí n wọ aṣọ ológun, tí mo bá sì kọ̀, màá fojú ba ilé ẹjọ́.”

Nígbà tí Stanley kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Àmọ́ kò bọkàn jẹ́. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, ó kọ̀wé pé: “‘Ẹ̀mí agbára’ tí Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fúnni máa ń jẹ́ kéèyàn lè ní sùúrù, kó sì fara da . . . àwọn ohun tó le gan-an fáwọn míì láti fara dà.” Ó fi àkókò tó lò lẹ́wọ̀n ṣe ohun tó dáa, ó sọ pé: “Ọ̀kan lára ìbùkún tó ga jù tí mo rí nínú àwọn àdánwò tí mo kojú lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni pé mo máa ń ní àkókò tí àyíká pa rọ́rọ́ láti gbàdúrà, láti ṣe àṣàrò, kí n sì dá kẹ́kọ̀ọ́.”

Kò pẹ́ tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi dara pọ̀ mọ́ ogun náà. Ní April 2, 1917, Ààrẹ Woodrow Wilson bá Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀, ó sì ní kí wọ́n kéde pé orílẹ̀-èdè náà máa gbógun ja orílẹ̀-èdè Jámánì. Ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ ogun. Bó ṣe di pé ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn Kristẹni lórílẹ̀-èdè náà pé kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológun nìyẹn.

Torí pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nílò ọmọ ogun ní kánjúkánjú, nígbà tó di oṣù May, wọ́n ṣe Òfin kan tó gba ìjọba láyè láti mú ẹnikẹ́ni wọṣẹ́ ológun. Oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n tún ṣe Òfin míì nípa àwọn tí kò bá fẹ́ wọṣẹ́ ológun. Òfin tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe mú kó ṣeé ṣe fún ìjọba Amẹ́ríkà láti fa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkùnrin wọṣẹ́ ológun, èyí tí wọ́n sì ṣe tẹ̀ lé e sọ ìyà tó máa jẹ ẹni tí kò bá ṣe ohun tí òfin sọ. Kò pẹ́ tí àwọn tó ń ta ko òtítọ́ fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo òfin yìí láti “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n” fún àwọn èèyàn àlàáfíà tó ń sin Jèhófà.Sm. 94:20.

Kò ya àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu pé ogun ń jà kárí ayé, nǹkan sì ń dà rú. Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń kéde ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lẹ́nu yà nígbà tí àríyànjiyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé láàárín àwọn èèyàn Jèhófà kan.

Ìdánwò àti Ìyọ́mọ́

Kò pẹ́ tí arákùnrin Charles Taze Russell kú tí wàhálà fi bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀rọ̀ bí wọ́n á ṣe máa bójú tó àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lohun tó wà nílẹ̀. Àtọdún 1884 ni Arákùnrin Russell ti dá àjọ Zion’s Watch Tower Tract Society sílẹ̀ lábẹ́ òfin, òun sì ni ààrẹ títí ó fi kú ní October 1916. Nígbà tí arákùnrin Joseph F. Rutherford wá bẹ̀rẹ̀ sí í darí àwọn èèyàn Ọlọ́run, àwọn mélòó kan tí wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ètò Ọlọ́run, títí kan àwọn mẹ́rin tó wà nínú ìgbìmọ̀ tó ń darí, bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ńlá.

Bí Arákùnrin Rutherford ṣe ń ṣe nǹkan ò tẹ́ àwọn mẹ́rin yìí àtàwọn míì lọ́rùn. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni ohun tó ṣe lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ Paul S. L. Johnson, tó jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò.

Kí Arákùnrin Russell tó kú, ó ti ṣètò láti rán Johnson lọ sí orílẹ̀-èdè England gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò tó ń ṣojú fún ètò Ọlọ́run. Iṣẹ́ Johnson ni pé tó bá ti débẹ̀, kó máa wàásù, kó máa bẹ ìjọ wò, kó sì máa ròyìn bí iṣẹ́ ṣe ń lọ lórílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó dé England ní November 1916, tayọ̀tayọ̀ làwọn ará níbẹ̀ fi gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé gbogbo bí wọ́n ṣe ń gbé e gẹ̀gẹ̀ mú kó ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, ó sì ń wò ó pé òun ló yẹ kóun gba ipò Arákùnrin Russell lẹ́yìn tó kú.

Johnson lé àwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú England lọ láì gbàṣẹ, torí pé wọn ò fara mọ́ bó ṣe ń ṣe nǹkan. Kódà, ó gbìyànjú láti sọ owó ètò Ọlọ́run tó wà ní báńkì nílùú London di tirẹ̀, ni arákùnrin Rutherford bá ní kó máa pa dà bọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Johnson pa dà sí Brooklyn, àmọ́ kàkà tí ì bá fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí wọ́n fún un, ṣe ló ń rọ arákùnrin Rutherford lemọ́lemọ́ pé kó jẹ́ kóun pa dà sí England, kóun lè máa bá iṣẹ́ òun lọ níbẹ̀. Bí Johnson ṣe rí i pé ọ̀rọ̀ ti ń bẹ́yìn yọ, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í yí àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ tó ń darí lérò pa dà, mẹ́rin lára wọn sì gbè sẹ́yìn rẹ̀.

Bí arákùnrin Rutherford ṣe rí i pé àwọn ọkùnrin yìí lè fẹ́ sọ owó ètò Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà di tiwọn, bí Johnson ṣe gbìyànjú ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní England, ló bá gbé ìgbésẹ̀ bó ṣe máa yọ wọ́n nínú ìgbìmọ̀ tó ń darí. Ohun tí òfin sọ ni pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ni kó máa yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó máa wà nínú ìgbìmọ̀ yìí lọ́dọọdún. Àmọ́, níbi ìpàdé ọdọọdún tí ẹgbẹ́ náà ṣe ní January 6, 1917, àwọn mẹ́ta péré ni wọ́n yàn nínú gbogbo àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà, ìyẹn Joseph F. Rutherford, Andrew N. Pierson àti William E. Van Amburgh. Arákùnrin Rutherford ló bọ́ sípò ààrẹ, arákùnrin Pierson jẹ́ igbá kejì, arákùnrin Amburgh sì jẹ́ akọ̀wé àti akápò. Wọn ò yan ẹnì kankan sí ipò àwọn mẹ́rin tó kù. Bí wọ́n ṣe yan àwọn mẹ́ta yẹn ni wọ́n yan àwọn yòókù tẹ́lẹ̀, ìyẹn àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́rin yẹn, àwọn kan sì ti gbà pé wọn ò lè kúrò nípò náà tí wọ́n á fi kú. Àmọ́ bí wọn ò ṣe yàn wọ́n níbi ìpàdé ọdọọdún yẹn fi hàn lábẹ́ òfin pé, wọn ò sí lára ìgbìmọ̀ tó ń darí mọ́! Torí náà, ní oṣù July ọdún 1917, Arákùnrin Rutherford lo àṣẹ tó ní láti yan àwọn ọkùnrin olóòótọ́ mẹ́rin míì tó máa dí àyè àwọn mẹ́rin ti tẹ́lẹ̀.

Inú bí àwọn mẹ́rin tí wọ́n gbapò lọ́wọ́ wọn yẹn gan-an, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti gba ipò wọn pa dà, ìyẹn ò sì yani lẹ́nu. Àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn já sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì dá ètò tiwọn sílẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kò yẹsẹ̀. Dọ̀la, àwọn mẹ́rin náà ò pa dà sí ipò adarí tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀.

Ìbàjẹ́ Èèyàn Kò Lè Dáṣẹ́ Ọlọ́run Dúró

Lákòókò náà, Arákùnrin Rutherford àti àwọn ará tó jẹ́ olóòótọ́ ní Bẹ́tẹ́lì ń bá iṣẹ́ wọn lọ kí ire Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú. Iye àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tí wọ́n ń pè ní arìnrìn-àjò ìsìn nígbà yẹn pọ̀ sí i, láti mọ́kàndínláàádọ́rin [69] sí mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93]. Iye àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé ròkè sí i láti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìléláàádọ́rin [372] sí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mọ́kànlélọ́gọ́ta [461]. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n yan àwọn àkànṣe apínwèé-ìsìn-kiri, àwọn tí a lè pè ní olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà lóde ònì, ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyẹn tí wọ́n máa ṣerú ẹ̀. Àwọn ìjọ kan tiẹ̀ ní tó ọgọ́rùn-ún [100] àwọn òṣìṣẹ́ tó nítara yìí.

Wọ́n mú ìwé The Finished Mystery jáde ní July 17, 1917. Nígbà tí ọdún yẹn fi máa parí, àwọn èèyàn ti gbà á tán, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé àádọ́ta [850,000] sì ni wọ́n béèrè sí i lọ́dọ̀ iléeṣẹ́ tá a ti ń tẹ àwọn ìwé wa. *

Lọ́dún 1917, wọ́n parí àtúntò iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì tí Arákùnrin Russell bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1916. Ní December ọdún yẹn, Ilé Ìṣọ́ sọ pé: “Iṣẹ́ àtúntò Ọ́fíìsì . . . ti parí, ó ti ń já geere báyìí, gbogbo nǹkan sì wà létòlétò bó ṣe yẹ kí ètò èyíkéyìí tí wọ́n ń mójú tó dáadáa rí . . . Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì náà kà á sí àǹfààní láti wà níbẹ̀, pé kì í ṣe ohun tí àwọn lẹ́tọ̀ọ́ sí.”

Ní September 1917, Ilé Ìṣọ́ tún sọ pé: “Láti January 1, oṣooṣù ni [ìwé tí à ń fi síta] ń pọ̀ sí i, tí a bá fi wé oṣù kan náà lọ́dún 1916 . . . Ìyẹn jẹ́ ká rí i kedere pé ìbùkún Olúwa wà lórí iṣẹ́ tí à ń ṣe ní Brooklyn.”

Ìdánwò àti Ìyọ́mọ́ Kò Tíì Parí

Wọ́n gbá àwọn alátakò tó wà nínú ètò Ọlọ́run dà nù, ohun tí àwọn ará nínú ìjọ káàkiri sì sọ, èyí tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ló wà lẹ́yìn Arákùnrin Rutherford àti àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ ìdánwò àwọn ọkùnrin yìí ò tíì parí. Òótọ́ ni pé ohun pàtàkì ló bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1918, àmọ́ ó tún máa jẹ́ àkókò tí nǹkan le gan-an nínú ìtàn wa òde òní.

^ ìpínrọ̀ 18 Títí di ọdún 1920, àwọn iléeṣẹ́ tó ń tẹ̀wé ló ń bá wa tẹ àwọn ìwé wa.