Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n:

Ọlọ́run fi ìran àgbàyanu kan han wòlíì Ìsíkíẹ́lì ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó rí kẹ̀kẹ́ gìrìwò kan, ìyẹn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ló sì ń darí rẹ̀. Ohun tó jọni lójú jù lọ nípa kẹ̀kẹ́ náà ni bó ṣe ń rìn. Ó ń sáré lọ bí ìgbà tí mànàmáná bá kọ, ó sì lè yí bìrí bó ṣe ń lọ láìtiẹ̀ dẹwọ́ eré tàbí kó yíjú sẹ́gbẹ̀ẹ́!Ìsík. 1:4, 9, 12, 14, 16-27.

Ìran yẹn rán wa létí pé apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà kò fìgbà kan dáwọ́ eré dúró. Apá ti ilẹ̀ ayé náà ò dáwọ́ eré dúró, lọ́nà wo? Ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá ti jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà létòlétò lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà tó wúni lórí.

Apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà kò fìgbà kan dáwọ́ eré dúró

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbí, ọwọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì dí bí wọ́n ṣe ń kó kúrò ní Brooklyn lọ sí oríléeṣẹ́ wa tuntun nílùú Warwick, ní New York, àwọn kan ń lọ sí àwọn ọ́fíìsì wa míì, àwọn míì sì ń lọ sí pápá. Láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì kárí ayé, ọwọ́ àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì dí bí àwọn kan nínú wọn ṣe ń kọ́lé, táwọn kan ń ṣe àtúntò, tí wọ́n ń pa àwọn ọ́fíìsì kan pọ̀, táwọn míì sì ń kó lọ sáwọn ọ́fíìsì tuntun. Ìwọ náà ńkọ́? Ká tiẹ̀ ló ò kó lọ ibì kankan, ó dájú pé ọwọ́ tiẹ̀ náà dí láwọn ọ̀nà míì.

Inú àwa Ìgbìmọ̀ Olùdarí dùn gan-an, ó sì wú wa lórí pé ọwọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé ti dí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí wọ́n ṣe ń bá ètò Ọlọ́run rìn. Ọ̀pọ̀ ló ti lọ sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Àwọn míì sì ti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn kan ti gbìyànjú ọ̀nà tuntun láti wàásù. Ọ̀pọ̀ ló sì ti fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run láwọn ọ̀nà míì. Gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́, títí kan àwọn àgbàlagbà àtàwọn tí ara wọn ò le, ló ń sá eré ìje ìyè náà láìdẹwọ́, ọwọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n lè tú Sátánì fó pé òpùrọ́ ni!1 Kọ́r. 9:24.

Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà mọyì ẹ̀mí tí ẹ̀ ń fi hàn. (Héb. 6:10) Bí ẹ ṣe ń yọ̀ǹda ara yín tinútinú mú wa rántí Ábúráhámù àti Sárà. Ábúráhámù ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún nígbà tó kó kúrò nílùú Úrì nílẹ̀ Kálídíà tòun ti ìdílé rẹ̀ lọ sí ìyànníyàn ilẹ̀ Kénáánì, níbi tó ti ń gbé inú àgọ́, ibẹ̀ ló sì ti lo ọgọ́rùn-ún [100] ọdún tó lò kẹ́yìn láyé. Àbẹ́ ò rí ẹ̀mí tó dáa tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ọ̀wọ́n fi hàn!Jẹ́n. 11:31; Ìṣe 7:2, 3.

Ṣé irú ẹ̀mí yẹn náà lo ní? Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ olóòótọ́ bẹ́ ẹ ṣe ń fara da ìṣòro lákòókò tí nǹkan le yìí lẹ̀ ń ṣe ohun tí Jésù ní ká ṣe. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.”Mát. 28:19.

Bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ẹ lọ” fi hàn pé ó yẹ kí ọwọ́ wa dí. Ẹ wo bó ṣe wúni lórí tó láti rí ohun táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n nítara gbé ṣe lọ́dún tó kọjá! Ó ṣe kedere pé Jèhófà ń rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ń lọ ní gbogbo orílẹ̀-èdè.Máàkù 13:10.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́dún tó kọjá, iye akéde jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta [8,340,847], iye yìí ló sì ròkè jù. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́fà àti igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [10,115,264]. Ó ṣe kedere pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ò dáwọ́ eré dúró, ẹ̀yin náà ò sì kẹ̀rẹ̀! Ẹ máa bá iṣẹ́ rere yín lọ ní àkókò díẹ̀ tó kù yìí kí Jèhófà ti ilẹ̀kùn ìgbàlà pa.

Ẹ ò rí i pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2017 bá a mu wẹ́kú, ó sọ pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”! (Sm. 37:3) Tẹ́ ẹ bá ń ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, tí ẹ̀ ń ṣe rere, ìyẹn tí ẹ̀ ń fún Jèhófà ní ìjọsìn mímọ́, ṣe lẹ̀ ń fi hàn pé ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e. A fẹ́ kó máa wà lọ́kàn yín pé ẹ ò dá wà. Jésù ò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ó ní: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”Mát. 28:20.

Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà ò ní dáwọ́ ìbùkún rẹ̀ dúró lórí iṣẹ́ ìsìn tí ẹ̀ ń fi òótọ́ inú ṣe. Bóyá ohun tí ẹ̀ ń ṣe kéré àbí ó pọ̀, ohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà ni pé kó jẹ́ gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe lẹ̀ ń ṣe, kó sì jẹ́ ọkàn tó dáa lẹ fi ń ṣe é. Irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ máa ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀, tayọ̀tayọ̀ ló sì máa ń tẹ́wọ́ gbà á. (2 Kọ́r. 9:6, 7) Torí náà, ẹ máa gbàdúrà déédéé, ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, ẹ sì máa lọ sóde ìwàásù déédéé. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ̀ẹ́ máa sún mọ́ Bàbá yín onífẹ̀ẹ́.

Títí “àkókò kúkúrú” tó kù fún Èṣù, ọlọ̀tẹ̀ burúkú yẹn, máa fi dópin, ó ti pinnu láti lo gbogbo ohun tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ kó lè mú ká kúrò lójú ọ̀nà ìwà títọ́ wa sí Jèhófà. (Ìṣí. 12:12) Ẹ má fi Jèhófà sílẹ̀ o! Tí ẹ ò bá fi í sílẹ̀, gbogbo ọgbọ́n tó wù kí Èṣù dà, ó dájú pé ó máa pòfo. (Sm. 16:8) A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an, a sì mọyì ìrànlọ́wọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́wọ́ ti ire Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ ỌDÚN 2017:

“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”