Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2019
Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 87
Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 240
Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 119,712
Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 20,919,041
Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 20,526
Góńgó Akéde *: 8,683,117
Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 8,471,008
Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2018: 103,208
Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi *: 303,866
Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé * Lóṣooṣù: 1,277,738
Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 464,980
Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 2,088,560,437
Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì * Lóṣooṣù: 9,618,182
Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2019, * àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́rìnlélógún (224) mílíọ̀nù dọ́là láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé méjìdínlọ́gọ́ta (20,858). Gbogbo wọn wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 7 Akéde ni àwọn tó ń kéde tàbí tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa bá a ṣe mọ iye wọn, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?” lórí ìkànnì jw.org/yo.
^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ohun tẹ́nì kan máa ṣe kó tó ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” lórí ìkànnì jw.org/yo.
^ ìpínrọ̀ 11 Aṣáájú-ọ̀nà ni Ẹlẹ́rìí kan tó ti ṣe ìrìbọmi tó sì níwà tó dáa. Ó pinnu láti máa lo iye wákàtí kan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lóṣooṣù.
^ ìpínrọ̀ 14 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kí Là Ń Pè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” lórí ìkànnì jw.org/yo.
^ ìpínrọ̀ 15 Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2019 bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2018, ó sì parí ní August 31, 2019.