Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá sí Àpéjọ Yìí Mọ̀
ÌRÌBỌMI Àwọn alàgbà ìjọ yín ti ṣètò tó bá àdúgbò yín mu kí àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n lè ṣèrìbọmi lẹ́yìn ìpàdé àárọ̀ Saturday.
ỌRẸ A túmọ̀ gbogbo àpéjọ yìí sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400]. Ọrẹ àtinúwá tó o bá ṣe máa ti iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn. O lè fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn lórí ìkànnì donate.pr418.com. A mọrírì gbogbo ọrẹ tá a bá rí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìwà ọ̀làwọ́ rẹ tó ń mú kó o máa ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn.
ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN AJÍHÌNRERE ÌJỌBA ỌLỌ́RUN Kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí márùndínláàádọ́rin [65], tí wọ́n fẹ́ túbọ̀ tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn kàn sí akọ̀wé ìjọ wọn, kí wọ́n sì lọ sórí ìkànnì jw.org láti kọ ọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù tó wà fún àwọn tó fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run.
Tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣètò
© 2021 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania