Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò
Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò
(látinú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun)
1. Àdúrà
A. Àwọn àdúrà tí Ọlọ́run máa ń gbọ́
Lóòótọ́ ni Ọlọ́run máa ń fetí sí àdúrà àwọn ènìyàn. Sm 145:18; 1Pe 3:12
Kì í gbọ́ ti aláìṣòdodo àyàfi bí ó bá yí padà. Ais 1:15-17
A gbọ́dọ̀ gbàdúrà ní orúkọ Jésù. Joh 14:13, 14; 2Kọ 1:20
A gbọ́dọ̀ gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. 1Jo 5:14, 15
Ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì. Jak 1:6-8
B. Àtúnwí asán, àdúrà sí Màríà tàbí àwọn “ẹni mímọ́” kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀
A gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run ní orúkọ Jésù. Joh 14:6, 14; 16:23, 24
Àtúnwí ọ̀rọ̀ ni a kò ní gbọ́. Mt 6:7
2. Àgbélébùú
A. A gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi ìfikúpani gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gàn
A gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi ìfikúpani tàbí igi. Iṣe 5:30; 10:39; Ga 3:13
Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé òpó igi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gàn. Mt 10:38; Lk 9:23
Fífi òpó igi Jésù hàn káàkiri jẹ́ ẹ̀gàn. Heb 6:6; Mt 27:41, 42
Lílo àgbélébùú nínú ìjọsìn jẹ́ ìbọ̀rìṣà. Ẹk 20:4, 5; Jer 10:3-5
Jésù jẹ́ ẹ̀mí, kò sí lórí òpó igi mọ́. 1Ti 3:16; 1Pe 3:18
3. Àjíǹde
Gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ibojì ni a óò gbé dìde. Joh 5:28, 29
Àjíǹde Jésù jẹ́ ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà. 1Kọ 15:20-22; Iṣe 17:31
Àwọn tí ó ṣẹ̀ sí ẹ̀mí kì yóò jíǹde. Mt 12:31, 32
A mú un dájú fún àwọn tí ń fi ìgbàgbọ́ hàn. Joh 11:25
B. Àjíǹde sí ìyè ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé
Gbogbo ènìyàn ń kú nínú Ádámù; ń rí ìyè nínú Jésù. 1Kọ 15:20-22; Ro 5:19
Ìyàtọ̀ nínú irú ẹ̀dá àwọn tí a gbé dìde. 1Kọ 15:40, 42, 44
Àwọn tí yóò wà lọ́dọ̀ Jésù yóò dà bí rẹ̀. 1Kọ 15:49; Flp 3:20, 21
Àwọn tí kò ní ṣàkóso yóò wà lórí ilẹ̀ ayé. Iṣi 20:4b, 5, 13; 21:3, 4
4. Amágẹ́dónì
A. Ogun Ọlọ́run láti fi òpin sí ìwà burúkú
Àwọn orílẹ̀-èdè ń gbárajọ sí Amágẹ́dónì. Iṣi 16:14, 16
Ọlọ́run yóò jà, yóò lo Ọmọ àti àwọn áńgẹ́lì. 2Tẹ 1:6-9; Iṣi 19:11-16
Bí a ṣe lè là á já. Se 2:2, 3; Iṣi 7:14
Ayé ti bàjẹ́ pátápátá. 2Ti 3:1-5
Ọlọ́run ní sùúrù, ṣùgbọ́n ìdájọ́ òdodo béèrè ìgbésẹ̀. 2Pe 3:9, 15; Lk 18:7, 8
Ẹni burúkú gbọ́dọ̀ kọjá lọ kí olódodo lè láásìkí. Owe 21:18; Iṣi 11:18
5. Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́
A. Dídarapọ̀ mọ́ àwọn ìsìn mìíràn kì í ṣe ọ̀nà Ọlọ́run
Ọ̀nà kan ṣoṣo, tóóró ni, díẹ̀ ni ó ń rí i. Ef 4:4-6; Mt 7:13, 14
A kìlọ̀ fúnni pé ẹ̀kọ́ èké ń sọni di eléèérí. Mt 16:6, 12; Ga 5:9
A pàṣẹ fún wa láti ta kété. 2Ti 3:5; 2Kọ 6:14-17; Iṣi 18:4
B. “Gbogbo ìsìn ni ó ní rere tirẹ̀” kì í ṣe òtítọ́
Àwọn kan ní ìtara ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Ro 10:2, 3
Búburú a máa ba rere yòówù tí ó bá wà jẹ́. 1Kọ 5:6; Mt 7:15-17
Àwọn olùkọ́ èké a máa mú ìparun wá. 2Pe 2:1; Mt 12:30; 15:14
Ìjọsìn tí ó mọ́ ń béèrè fún ìfọkànsìn pátápátá. Di 6:5, 14, 15
6. Àtakò, Inúnibíni
A. Ìdí fún àtakò sí àwọn Kristẹni
A kórìíra Jésù, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àtakò. Joh 15:18-20; Mt 10:22
Rírọ̀mọ́ àwọn ìlànà títọ́ ń dá ayé lẹ́bi. 1Pe 4:1, 4, 12, 13
Sátánì, ọlọ́run ètò yìí, ń tako Ìjọba náà. 2Kọ 4:4; 1Pe 5:8
Kristẹni kì í bẹ̀rù, Ọlọ́run ń tini lẹ́yìn. Ro 8:38, 39; Jak 4:8
B. Aya kò gbọ́dọ̀ gba ọkọ láyè láti ya òun nípa sí Ọlọ́run
A kìlọ̀ tẹ́lẹ̀; ẹlòmíràn lè fún ọkọ ní ìsọfúnni èké. Mt 10:34-38; Iṣe 28:22
Òun gbọ́dọ̀ máa wo ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti Kristi. Joh 6:68; 17:3
Nípa ìṣòtítọ́, ó lè gbà á là pẹ̀lú. 1Kọ 7:16; 1Pe 3:1-6
Ọkọ ni orí, ṣùgbọ́n kì í ṣe láti pàṣẹ ìjọsìn. 1Kọ 11:3; Iṣe 5:29
D. Ọkọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí aya dí òun lọ́wọ́ sísin Ọlọ́run
Ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya àti ìdílé, kí ó fẹ́ ìyè fún wọn. 1Kọ 7:16
Òun ló ni ẹrù iṣẹ́ láti pinnu, láti pèsè. 1Kọ 11:3; 1Ti 5:8
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ọkùnrin tí ó bá dúró fún òtítọ́. Jak 1:12; 5:10, 11
Jíjuwọ́sílẹ̀ nítorí àlàáfíà ń mú ìbínú Ọlọ́run wá. Heb 10:38
Ṣamọ̀nà ìdílé sí ayọ̀ nínú Ayé Tuntun. Iṣi 21:3, 4
7. Àyànmọ́
A. A kò yan àyànmọ́ kankan fún ènìyàn
Ète Ọlọ́run dájú. Ais 55:11; Jẹ 1:28
Olúkúlùkù ni a fún ní òmìnira yíyàn láti sin Ọlọ́run. Joh 3:16; Flp 2:12
8. Bíbélì
Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó sún àwọn ènìyàn láti kọ̀wé. 2Pe 1:20, 21
Ó ní àsọtẹ́lẹ̀ nínú: Da 8:5, 6, 20-22; Lk 21:5, 6, 20-22; Ais 45:1-4
Gbogbo Bíbélì ní ìmísí ó sì ṣàǹfààní. 2Ti 3:16, 17; Ro 15:4
B. Ó jẹ́ amọ̀nà wíwúlò fún ọjọ́ wa
Ṣíṣàìka ìlànà Bíbélì sí lè ṣekú pani. Ro 1:28-32
Ọgbọ́n ènìyàn kì í ṣe arọ́pò. 1Kọ 1:21, 25; 1Ti 6:20
Ààbò kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá lílágbára jù lọ. Ef 6:11, 12, 17
Ó ń ṣamọ̀nà ènìyàn ní ọ̀nà títọ́. Sm 119:105; 2Pe 1:19; Owe 3:5, 6
D. A kọ ọ́ fún ènìyàn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ìran gbogbo
A bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì ní Ìlà-Oòrùn. Ẹk 17:14; 24:12, 16; 34:27
Ìpèsè Ọlọ́run kì í ṣe fún àwọn ará Yúróòpù nìkan. Ro 10:11-13; Ga 3:28
Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba gbogbo onírúurú ènìyàn. Iṣe 10:34, 35; Ro 5:18; Iṣi 7:9, 10
9. Ère
A. Lílo àwọn ère, ère ìrántí, nínú ìjọsìn jẹ́ ẹ̀gàn sí Ọlọ́run
Ère Ọlọ́run kò ṣeé yà. 1Jo 4:12; Ais 40:18; 46:5; Iṣe 17:29
A kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni lòdì sí ère. 1Kọ 10:14; 1Jo 5:21
Ọlọ́run ni a ní láti sìn ní ẹ̀mí, òtítọ́. Joh 4:24
B. Ìjọsìn ère yọrí sí ikú fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì
A ka ìjọsìn ère léèwọ̀ fún àwọn Júù. Ẹk 20:4, 5
Kò lè gbọ́ràn, sọ̀rọ̀; àwọn tí ń ṣe wọ́n dà bí wọn. Sm 115:4-8
Ó mú ìdẹkùn, ìparun wá. Sm 106:36, 40-42; Jer 22:8, 9
D. Ìjọsìn “aláàlà” ni a kò pa láṣẹ
Ọlọ́run kò fàyè gba ìjọsìn “aláàlà” fún ara rẹ̀. Ais 42:8
Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni “Olùgbọ́ àdúrà.” Sm 65:1, 2
10. Èṣù, Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
Kì í ṣe ìwà ibi nínú ènìyàn bí kò ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí kan. 2Ti 2:26
Èṣù jẹ́ ẹ̀dá kan gẹ́gẹ́ bí àwọn áńgẹ́lì. Mt 4:1, 11; Job 1:6
Ó sọ ara rẹ̀ di Èṣù nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn àìtọ́. Jak 1:13-15
B. Èṣù ni ẹni tí a kò lè rí tí ń ṣàkóso ayé
Ayé wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ bí ọlọ́run. 2Kọ 4:4; 1Jo 5:19; Iṣi 12:9
A fi í sílẹ̀ títí a ó fi yanjú àríyànjiyàn. Ẹk 9:16; Joh 12:31
A ó sọ ọ́ sínú ọ̀gbun, lẹ́yìn náà, a ó pa á run. Iṣi 20:2, 3, 10
D. Àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣọ̀tẹ̀ ni àwọn ẹ̀mí èṣù
Wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì ṣáájú Ìkún Omi. Jẹ 6:1, 2; 1Pe 3:19, 20
A rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, a ké wọn kúrò nínú gbogbo ìlàlóye. 2Pe 2:4; Jud 6
Wọ́n ń bá Ọlọ́run jà, wọn ń ni aráyé lára. Lk 8:27-29; Iṣi 16:13, 14
A ó pa wọ́n run pẹ̀lú Sátánì. Mt 25:41; Lk 8:31; Iṣi 20:2, 3, 10
11. Ẹ̀jẹ̀
A. Gbígba ẹ̀jẹ̀ sára rú òfin ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀
A sọ fún Nóà pé ẹ̀jẹ̀ jẹ́ mímọ́, òun ni ìwàláàyè. Jẹ 9:4, 16
Májẹ̀mú Òfin ka jíjẹ ẹ̀jẹ̀ léèwọ̀. Le 17:14; 7:26, 27
A tún ìkàléèwọ̀ rẹ̀ sọ fún àwọn Kristẹni. Iṣe 15:28, 29; 21:25
B. Ọ̀ràn gbígba ẹ̀mí là kò dáni láre láti rú òfin Ọlọ́run
Ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ. 1Sa 15:22; Mk 12:33
Fífi ẹ̀mí ẹni ṣáájú òfin Ọlọ́run ń ṣe ikú pani. Mk 8:35, 36
12. Ẹlẹ́rìí Jèhófà
A. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Jèhófà fi àwọn ẹlẹ́rìí tirẹ̀ hàn. Ais 43:10-12; Jer 15:16
Ìlà àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ébẹ́lì. Heb 11:4, 39; 12:1
Jésù jẹ́ ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́. Joh 18:37; Iṣi 1:5; 3:14
13. Ẹ̀mí, Ìbẹ́mìílò
Ipá agbéṣẹ́ṣe Ọlọ́run, kì í ṣe ẹnì kan. Iṣe 2:2, 3, 33; Joh 14:17
A lò ó nínú ìṣẹ̀dá, ìmísí Bíbélì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jẹ 1:2; Isk 11:5
A fi bí, a fi yan, ẹ̀yà ara Kristi. Joh 3:5-8; 2Kọ 1:21, 22
Ó ń fi agbára fún, ń ṣamọ̀nà ènìyàn Ọlọ́run lónìí. Ga 5:16, 18
B. Ipá ìwàláàyè ni a ń pè ní ẹ̀mí
Ìlànà ìwàláàyè, a mú un dúró nípasẹ̀ èémí. Jak 2:26; Job 27:3
Agbára lórí ipá ìwàláàyè wà lọ́wọ́ Ọlọ́run. Sek 12:1; Onw 8:8
Ti Ọlọ́run ni ipá ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn, ẹranko. Onw 3:19-21
A fi ẹ̀mí lé Ọlọ́run lọ́wọ́ pẹ̀lú ìrètí àjíǹde. Lk 23:46
D. A gbọ́dọ̀ kọ ìbẹ́mìílò sílẹ̀ bí iṣẹ́ àwọn ẹ̀mí èṣù
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà á léèwọ̀. Ais 8:19, 20; Le 19:31; 20:6, 27
Àfọ̀ṣẹ jẹ́ bíbá ẹ̀mí èṣù lò; a dá a lẹ́bi. Iṣe 16:16-18
Ó ń yọrí sí ìparun. Ga 5:19-21; Iṣi 21:8; 22:15
A ka wíwo ìràwọ̀ léèwọ̀. Di 18:10-12; Jer 10:2
14. Ẹ̀sìn
A. Ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ni ó wà
Ìrètí kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan. Ef 4:5, 13
A pa á láṣẹ láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Mt 28:19; Iṣe 8:12; 14:21
Èso rẹ̀ ni a ó fi mọ̀ ọ́n. Mt 7:19, 20; Lk 6:43, 44; Joh 15:8
Ìfẹ́, ìfohùnṣọ̀kan láàárín àwọn mẹ́ńbà. Joh 13:35; 1Kọ 1:10; 1Jo 4:20
B. A wọ́gi lé ẹ̀kọ́ èké lọ́nà tí ó tọ́
Jésù wọ́gi lé ẹ̀kọ́ èké. Mt 23:15, 23, 24; 15:4-9
Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún ààbò àwọn tí a ti fọ́ lójú. Mt 15:14
Òtítọ́ sọ wọ́n di òmìnira láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Joh 8:31, 32
D. Yíyí ẹ̀sìn ẹni padà ṣe kókó bí a bá fi hàn pé kò tọ̀nà
Òtítọ́ ń sọni di òmìnira; ń fi hàn pé ọ̀pọ̀ ti kùnà. Joh 8:31, 32
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn mìíràn, fi ìjọsìn ìṣáájú sílẹ̀. Joṣ 24:15; 2 Ọba 5:17
Kristẹni ìjímìjí yí ojú ìwòye padà. Ga 1:13, 14; Iṣe 3:17, 19
Pọ́ọ̀lù yí ẹ̀sìn rẹ̀ padà. Iṣe 26:4-6
Gbogbo ayé ni a tàn jẹ; a gbọ́dọ̀ yí èrò padà. Iṣi 12:9; Ro 12:2
E. “Rere ń bẹ nínú gbogbo ẹ̀sìn” tí a ń wí kò mú ojú rere Ọlọ́run dájú
Ọlọ́run gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n kalẹ̀ fún ìjọsìn. Joh 4:23, 24; Jak 1:27
Kò dára bí kì í bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ro 10:2, 3
A lè kọ “àwọn iṣẹ́ rere” tì. Mt 7:21-23
Èso ni a fi ń mọ̀ ọ́n. Mt 7:20
15. Ẹ̀ṣẹ̀
Rírú òfin Ọlọ́run, ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ pípé. 1Jo 3:4; 5:17
Ènìyàn, bí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, ní láti jíhìn fún un. Ro 14:12; 2:12-15
Òfin fi ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ó jẹ́ kí ènìyàn mọ̀ ọ́n. Ga 3:19; Ro 3:20
Aráyé wà nínú ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n kùnà ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé Ọlọ́run. Ro 3:23; Sm 51:5
B. Ìdí tí gbogbo ènìyàn fi ń jìyà nípa ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù
Ádámù mú àìpé, ikú kọjá sórí gbogbo ènìyàn. Ro 5:12, 18
Ọlọ́run jẹ́ aláàánú ní fífaradà á fún aráyé. Sm 103:8, 10, 14, 17
Ìrúbọ Jésù ni ó ń wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nù. 1Jo 2:2
Ẹ̀ṣẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ Èṣù mìíràn ni a ó nù kúrò. 1Jo 3:8
D. Èso tí a kàléèwọ̀ jẹ́ àìgbọràn, kì í ṣe ìbálòpọ̀ takọtabo
Ìkàléèwọ̀ igi ni a ti ṣe kí a tó dá Éfà. Jẹ 2:17, 18
A sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n ní àwọn ọmọ. Jẹ 1:28
Ọmọ kì í ṣe ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀, bí kò ṣe ìbùkún Ọlọ́run. Sm 127:3-5
Éfà ṣẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ rẹ̀ kò sí níbẹ̀, ó kánjú. Jẹ 3:6; 1Ti 2:11-14
Ádámù, gẹ́gẹ́ bí orí, ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Ọlọ́run. Ro 5:12, 19
E. Ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ (Mt 12:32; Mk 3:28, 29)
Ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá kì í ṣe irúfẹ́ èyíinì. Ro 5:8, 12, 18; 1Jo 5:17
Ẹnì kan lè mú ẹ̀mí bínú, síbẹ̀ kí ó padà bọ̀ sípò. Ef 4:30; Jak 5:19, 20
Mímọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà a máa yọrí sí ikú. 1Jo 3:6-9
Ọlọ́run a máa dá irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́jọ́, a mú ẹ̀mí rẹ̀ kúrò. Heb 6:4-8
A kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún irúfẹ́ àwọn aláìronú-pìwàdà bẹ́ẹ̀. 1Jo 5:16, 17
16. Hẹ́ẹ̀lì (Hédíìsì, Ṣìọ́ọ̀lù)
A. Kì í ṣe ibi gidi kan tí a ti ń fi iná dáni lóró
Jóòbù tí ń jẹ̀rora gbàdúrà láti lọ síbẹ̀. Job 14:13
Ibi àìlè-ṣe-nǹkankan. Sm 6:5; Onw 9:10; Ais 38:18, 19
A gbé Jésù dìde kúrò nínú isà òkú, hẹ́ẹ̀lì. Iṣe 2:27, 31, 32; Sm 16:10
Hẹ́ẹ̀lì yóò jọ̀wọ́ òkú inú rẹ̀ lọ́wọ́, a ó pa á run. Iṣi 20:13, 14
B. Iná ṣàpẹẹrẹ ìparun yán-án yán-án
Ìkékúrò sínú ikú ni a fi iná ṣàpẹẹrẹ. Mt 25:41, 46; 13:30
Ẹni ibi aláìronú-pìwàdà yóò pa run láé bí ẹni pé nípasẹ̀ iná. Heb 10:26, 27
Ikú ayérayé ni iná “ìdálóró” Sátánì. Iṣi 20:10, 14, 15
D. Ìròyìn nípa ọlọ́rọ̀ àti Lásárù kì í ṣe ẹ̀rí ìdálóró ayérayé
Kì í ṣe ináyìíná bí oókan àyà kì í ti í ṣe oókan àyà Ábúráhámù gan-an. Lk 16:22-24
Ojú rere Ábúráhámù pẹ̀lú jẹ́ ìfiwéra pẹ̀lú òkùnkùn. Mt 8:11, 12
Ìparun yán-án-yán Bábílónì ni a pè ní ìdálóró oníná. Iṣi 18:8-10, 21
17. Ìbatisí
A. Ohun kan tí a ń béèrè lọ́wọ́ Kristẹni
Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Mt 3:13-15; Heb 10:7
Àmì sísẹ́ ara ẹni tàbí ìyàsímímọ́. Mt 16:24; 1Pe 3:21
Kìkì fún àwọn tí ó dàgbà tó láti kẹ́kọ̀ọ́. Mt 28:19, 20; Iṣe 2:41
Ìrìbọmi nínú omi ni ọ̀nà tí ó tọ̀nà. Iṣe 8:38, 39; Joh 3:23
A kò batisí Jésù láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù. 1Pe 2:22; 3:18
Ẹ̀jẹ̀ Jésù ni ó ń wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù. 1Jo 1:7
18. Ìgbàlà
A. Ìgbàlà ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù
Ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. 1Jo 4:9, 14; Ro 6:23
Ìgbàlà ṣeé ṣe kìkì nípasẹ̀ ẹbọ Jésù. Iṣe 4:12
Iṣẹ́ kankan kò ṣeé ṣe nínú “ìrònúpìwàdà lórí ibùsùn ikú.” Jak 2:14, 26
A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ tokuntokun láti rí ìgbàlà. Lk 13:23, 24; 1Ti 4:10
B. “Ìgbàlà lẹ́ẹ̀kan, ìgbàlà gbogbo ìgbà” kò bá Ìwé Mímọ́ mu
Àwọn tí ó jẹ́ alábàápín ẹ̀mí mímọ́ lè ṣubú. Heb 6:4, 6; 1Kọ 9:27
A pa ọ̀pọ̀ lára ọmọ Ísírẹ́lì run bí a tilẹ̀ gbà wọ́n là kúrò ní Íjíbítì. Jud 5
Ìgbàlà kì í ṣe lẹ́sẹ̀ kan náà. Flp 2:12; 3:12-14; Mt 10:22
Àwọn tí ń yí padà burú ju ti ìṣáájú lọ. 2Pe 2:20, 21
D. “Ìgbàlà gbogbo ayé” kò bá Ìwé Mímọ́ mu
Ìrònúpìwàdà kò ṣeé ṣe fún àwọn kan. Heb 6:4-6
Ọlọ́run kò ní inúdídùn sí ikú ẹni burúkú. Isk 33:11; 18:32
Ṣùgbọ́n ìfẹ́ kò lè gbójúfo àìṣòdodo dá. Heb 1:9
A ó pa àwọn ẹni burúkú run. Heb 10:26-29; Iṣi 20:7-15
19. Ìgbéyàwó
A. Ìdè ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ ní ọlá
A fi í wé Kristi àti ìyàwó. Ef 5:22, 23
Ibùsùn ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlẹ́gbin. Heb 13:4
A fún tọkọtaya ní ìtọ́ni láti má ṣe pínyà. 1Kọ 7:10-16
Por·neiʹa nìkan ni ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìkọ̀sílẹ̀. Mt 19:9
B. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìlànà ipò orí
Ọkọ gẹ́gẹ́ bí orí ní láti nífẹ̀ẹ́, bójútó ìdílé. Ef 5:23-31
Aya, wà ní ìtẹríba, nífẹ̀ẹ́, ṣe ìgbọràn sí ọkọ. 1Pe 3:1-7; Ef 5:22
Àwọn ọmọ ní láti jẹ́ onígbọràn. Ef 6:1-3; Kol 3:20
D. Ẹrù iṣẹ́ àwọn Kristẹni òbí sí àwọn ọmọ
Gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ hàn, lo àkókò pẹ̀lú wọn, àfiyèsí. Tit 2:4
Má ṣe mú wọn bínú. Kol 3:21
Ṣe ìpèsè, títí kan àwọn ohun tẹ̀mí. 2Kọ 12:14; 1Ti 5:8
Fún wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ìyè. Ef 6:4; Owe 22:6, 15; 23:13, 14
E. Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé kìkì Kristẹni níyàwó
Gbéyàwó kìkì “nínú Olúwa.” 1Kọ 7:39; Di 7:3, 4; Ne 13:26
Ẹ. Ìkóbìnrinjọ kò bá Ìwé Mímọ́ mu
Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, aya kan ni ọkùnrin kan gbọ́dọ̀ ní. Jẹ 2:18, 22-25
Jésù dá ọ̀pá ìdiwọ̀n yìí padà fún Kristẹni. Mt 19:3-9
Àwọn Kristẹni ìpilẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe akóbìnrinjọ. 1Kọ 7:2, 12-16; Ef 5:28-31
20. Ìjẹ́rìí
A. Gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́rìí, kí wọ́n sọ ìhìn rere
A gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ Jésù níwájú ènìyàn láti rí ìtẹ́wọ́gbà. Mt 10:32
A gbọ́dọ̀ jẹ́ olùṣe Ọ̀rọ̀, kí a fi ìgbàgbọ́ hàn. Jak 1:22-24; 2:24
Àwọn ẹni tuntun, pẹ̀lú, ní láti di olùkọ́. Mt 28:19, 20
Ìpolongo ní gbangba ń mú ìgbàlà wá. Ro 10:10
B. Àìní wà fún ìbẹ̀wò léraléra, ìjẹ́rìí àìdabọ̀
A gbọ́dọ̀ fúnni ní ìkìlọ̀ nípa òpin. Mt 24:14
Jeremáyà kéde òpin Jerúsálẹ́mù fún ọ̀pọ̀ ọdún. Jer 25:3
Bí àwọn Kristẹni ìjimìjí, a kò lè dáwọ́ dúró. Iṣe 4:18-20; 5:28, 29
D. A gbọ́dọ̀ jẹ́rìí kí a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀
A gbọ́dọ̀ kìlọ̀ nípa òpin tí ó sún mọ́lé. Isk 33:7; Mt 24:14
Ìkùnà mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wá. Isk 33:8, 9; 3:18, 19
Pọ́ọ̀lù bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀; ó sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òtítọ́. Iṣe 20:26, 27; 1Kọ 9:16
Ó ń gba ẹlẹ́rìí àti ẹni tí ń gbọ́ là. 1Ti 4:16; 1Kọ 9:22
21. Ìjọba
A. Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe fún aráyé
Láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Mt 6:9, 10; Sm 45:6; Iṣi 4:11
Ìjọba kan tí ó ní ọba àti àwọn òfin. Ais 9:6, 7; 2:3; Sm 72:1, 8
Yóò pa ìwà burúkú run, ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé. Da 2:44; Sm 72:8
Ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso láti mú aráyé, Párádísè, padà bọ̀ sípò. Iṣi 21:2-4; 20:6
B. Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ọ̀tá Kristi ṣì wà láàyè síbẹ̀
Lẹ́yìn tí a gbé Kristi dìde, ó dúró pẹ́. Sm 110:1; Heb 10:12, 13
Ó gba agbára, bá Sátánì jagun. Sm 110:2; Iṣi 12:7-9; Lk 10:18
A gbé Ìjọba kalẹ̀ nígbà náà, ègbé ayé tẹ̀ lé e. Iṣi 12:10, 12
Ìdààmú ìsinsìnyí túmọ̀ sí àkókò láti fara mọ́ Ìjọba náà. Iṣi 11:15-18
D. Kì í ṣe ‘nínú ọkàn-àyà,’ a kò mú un dàgbà nípasẹ̀ ìsapá ènìyàn
Ìjọba náà ń bẹ ní ọ̀run, kì í ṣe ilẹ̀ ayé. 2Ti 4:18; 1Kọ 15:50; Sm 11:4
Kì í ṣe ‘nínú ọkàn-àyà’; Farisí ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Lk 17:20, 21
Kì í ṣe apákan ayé yìí. Joh 18:36; Lk 4:5-8; Da 2:44
Yóò rọ́pò àwọn ìjọba, ọ̀pá ìdiwọ̀n ayé. Da 2:44
22. Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá
A. Ìjọsìn àwọn baba ńlá jẹ́ asán
Àwọn baba ńlá ti kú, wọn kò mọ nǹkan kan. Onw 9:5, 10
Àwọn baba ńlá ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò yẹ ní jíjọ́sìn. Ro 5:12, 14; 1Ti 2:14
Ọlọ́run ka irúfẹ́ ìjọsìn bẹ́ẹ̀ léèwọ̀. Ẹk 34:14; Mt 4:10
B. A lè bọlá fún ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n Ọlọ́run nìkan ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn
Àwọn ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ bọlá fún àgbàlagbà. 1Ti 5:1, 2, 17; Ef 6:1-3
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run nìkan ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn. Iṣe 10:25, 26; Iṣi 22:8, 9
23. Ìjọsìn Màríà
A. Màríà ìyá Jésù, kì í ṣe “ìyá Ọlọ́run”
Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀. Sm 90:2; 1Ti 1:17
Màríà ni ìyá Ọmọ Ọlọ́run, nínú ipò ẹ̀dá lórí ilẹ̀ ayé. Lk 1:35
B. Màríà kì í ṣe “wúndíá títí lọ”
Ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Jósẹ́fù. Mt 1:19, 20, 24, 25
Ó bí àwọn ọmọ mìíràn yàtọ̀ sí Jésù. Mt 13:55, 56; Lk 8:19-21
Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe “arákùnrin rẹ̀ nípa ti ẹ̀mí” nígbà yẹn. Joh 7:3, 5
24. Ikú
Ènìyàn ní ìbẹ̀rẹ̀ pípé, ìrètí ìyè aláìlópin. Jẹ 1:28, 31
Àìgbọràn mú ìdájọ́ ikú wá. Jẹ 2:16, 17; 3:17, 19
Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti kọjá sórí gbogbo àwọn ọmọ Ádámù. Ro 5:12
A dá Ádámù láti jẹ́ ọkàn kan, a kò fún un ní ọkàn. Jẹ 2:7; 1Kọ 15:45
Ènìyàn, tí í ṣe ọkàn, ni ó máa ń kú. Isk 18:4; Ais 53:12; Job 11:20
Àwọn òkú jẹ́ aláìní ìmọ̀lára, wọn kò mọ nǹkan kan. Onw 9:5, 10; Sm 146:3, 4
Àwọn òkú sùn, wọ́n ń dúró de àjíǹde. Joh 11:11-14, 23-26; Iṣe 7:60
D. Kò ṣeé ṣe láti bá òkú sọ̀rọ̀
Àwọn òkú kò wà láàyè pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí. Sm 115:17; Ais 38:18
A kìlọ̀ fúnni lòdì sí gbígbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀. Ais 8:19; Le 19:31
A-bá-iwin-gbìmọ̀, aláfọ̀ṣẹ, ni a dá lẹ́bi. Di 18:10-12; Ga 5:19-21
25. Ilẹ̀ Ayé
A dá Párádísè sórí ilẹ̀ ayé fún ẹ̀dá ènìyàn pípé. Jẹ 1:28; 2:8-15
Ète Ọlọ́run dájú. Ais 55:11; 46:10, 11
Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ènìyàn àlàáfíà, àwọn ènìyàn pípé. Ais 45:18; Sm 72:7; Ais 9:6, 7
A óò mú Párádísè padà bọ̀ sípò nípasẹ̀ Ìjọba náà. Mt 6:9, 10; Iṣi 21:3-5
B. A kò ní pa á run tàbí sọ ọ́ di òfo láé
Ilẹ̀ ayé gidi yóò wà títí láé. Onw 1:4; Sm 104:5
Aráyé ti ìgbà Nóà ni a pa run, kì í ṣe ilẹ̀ ayé. 2Pe 3:5-7; Jẹ 7:23
Àpẹẹrẹ ń fúnni ní ìrètí lílàájá nígbà tiwa. Mt 24:37-39
Ẹni burúkú pa run; “ogunlọ́gọ̀ ńlá” làájá. 2Tẹ 1:6-9; Iṣi 7:9, 14
26. Ìpadàbọ̀ Kristi
A. Ẹ̀dá ènìyàn kò lè fojú rí ìpadàbọ̀ rẹ̀
Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé ayé kì yóò rí òun mọ́. Joh 14:19
Kìkì ọmọ ẹ̀yìn ni ó rí ìgòkè rẹ̀; ìpadàbọ̀ bákan náà. Iṣe 1:6, 10, 11
Ní ọ̀run, ó jẹ́ ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí. 1Ti 6:14-16; Heb 1:3
Ó padà nínú agbára Ìjọba ti ọ̀run. Da 7:13, 14
B. A fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a lè fojú rí mọ̀ ọ́n
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè fún àmì wíwàníhìn-ín. Mt 24:3
Àwọn Kristẹni “rí” wíwàníhìn-ín nípasẹ̀ òye. Efe 1:18
Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ fi ẹ̀rí wíwàníhìn-ín rẹ̀ hàn. Lk 21:10, 11
Àwọn ọ̀tá “rí i” bí ìparun ti já lù wọ́n. Iṣi 1:7
27. Ìràpadà
A. Ìwàláàyè Jésù bí ènìyàn ni a fi san “ìràpadà fún gbogbo ènìyàn”
Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. Mt 20:28
Ìníyelórí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ pèsè ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Heb 9:14, 22
Ẹbọ kan ti tó títí láé. Ro 6:10; Heb 9:26
Àǹfààní rẹ̀ kì í ṣàdédé dé; a gbọ́dọ̀ mọyì rẹ̀. Joh 3:16
A dá Ádámù ní pípé. Di 32:4; Onw 7:29; Jẹ 1:31
Ó sọ ìjẹ́pípé nù fún ara rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀. Ro 5:12, 18
Àwọn ọmọ di aláìní ìrànlọ́wọ́; a nílò ẹni bí Ádámù gẹ́lẹ́. Sm 49:7; Di 19:21
Ìwàláàyè Jésù bí ènìyàn pípé jẹ́ ìràpadà. 1Ti 2:5, 6; 1Pe 1:18, 19
28. Ìṣe Ìrántí, Máàsì
A. Ṣíṣe ìrántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
A ń ṣe é lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ọjọ́ Ìrékọjá. Lk 22:1, 17-20; Ẹk 12:14
A ń ṣe ìrántí ikú ìrúbọ Kristi. 1Kọ 11:26; Mt 26:28
Àwọn tí ó ní ìrètí ti ọ̀run a máa ṣàjọpín. Lk 22:29, 30; 12:32, 37
Bí ẹnì kan ṣe ń mọ̀ pé òun ní irúfẹ́ ìrètí bẹ́ẹ̀. Ro 8:15-17
Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ń béèrè títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Heb 9:22
Kristi nìkan ni Alárinà májẹ̀mú tuntun. 1Ti 2:5, 6; Joh 14:6
Kristi ń bẹ ní ọ̀run; àlùfáà kò lè mú un sọ̀ kalẹ̀ wá. Iṣe 3:20, 21
Kò sí ìdí láti tún ẹbọ Kristi rú. Heb 9:24-26; 10:11-14
29. Ìṣẹ̀dá
A. Ó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tòótọ́ mu; ó já ẹfolúṣọ̀n ní koro
Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìṣẹ̀dá mu. Jẹ 1:11, 12, 21, 24, 25
Òótọ́ ni òfin Ọlọ́run nípa “àwọn irú.” Jẹ 1:11, 12; Jak 3:12
B. Àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún
“Ọjọ́” lè wulẹ̀ túmọ̀ sí sáà àkókò kan. Jẹ 2:4
Ọjọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run lè jẹ́ àkókò gígùn kan. Sm 90:4; 2Pe 3:8
30. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀
A. 1914 (C.E.) ni òpin Àwọn Ìgbà Kèfèrí
Ìlà àwọn olùṣàkóso ìjọba dáwọ́ dúró, 607 B.C.E. Isk 21:25-27
“Ìgbà méje” ní láti kọjá kí a tó mú ìṣàkóso padà. Da 4:32, 16, 17
Méje jẹ́ 31/2 lọ́nà méjì, tàbí 1,260 ọjọ́ lọ́nà méjì. Iṣi 12:6, 14; 11:2, 3
Ọjọ́ kan fún ọdún kan. [Ó jẹ́ 2,520 ọdún] Isk 4:6; Nu 14:34
Yóò máa bá a lọ títí di ìgbà ìgbékalẹ̀ Ìjọba. Lk 21:24; Da 7:13, 14
31. Ìwà Burúkú, Wàhálà Ayé
Ìṣàkóso burúkú ni ó ń fa àìfararọ òde òní. Owe 29:2; 28:28
Olùṣàkóso ayé jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. 2Kọ 4:4; 1Jo 5:19; Joh 12:31
Èṣù ni ó ń mú ègbé wá, àkókò rẹ̀ kúrú. Iṣi 12:9, 12
A ó de Èṣù, àlàáfíà ológo yóò tẹ̀ lé e. Iṣi 20:1-3; 21:3, 4
B. Ìdí tí a fi fàyè gba ìwà burúkú
Èṣù pe ìdúróṣinṣin ẹ̀dá sí Ọlọ́run níjà. Job 1:11, 12
A fún olùṣòtítọ́ ní àǹfààní láti fi ìdúróṣinṣin hàn. Ro 9:17; Owe 27:11
A fi Èṣù hàn ní òpùrọ́, a ó yanjú àríyànjiyàn. Joh 12:31
A ó fi ìyè àìnípẹ̀kun ṣe èrè fún olùṣòtítọ́. Ro 2:6, 7; Iṣi 21:3-5
D. Àkókò òpin tí a fà gùn jẹ́ ìpèsè aláàánú
Bí ti ọjọ́ Nóà, ó gba àkókò láti ṣe ìkìlọ̀. Mt 24:14, 37-39
Ọlọ́run kò fi nǹkan falẹ̀, ṣùgbọ́n ó láàánú. 2Pe 3:9; Ais 30:18
Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ kí ó má bàa bá wa lójijì. Lk 21:36; 1Te 5:4
Wá ìpèsè Ọlọ́run nísinsìnyí fún ààbò. Ais 2:2-4; Sef 2:3
E. Àtúnṣe sí wàhálà ayé kì í ṣe láti ọwọ́ ènìyàn
Ènìyàn ń bẹ̀rù, wọ́n ń dààmú gidigidi. Lk 21:10, 11; 2Ti 3:1-5
Ìjọba Ọlọ́run ni yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, kì í ṣe ènìyàn. Da 2:44; Mt 6:10
Láti wà láàyè, wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọba náà nísinsìnyí. Sm 2:9, 11, 12
32. Ìwòsàn, Àwọn Ahọ́n Àjèjì
A. Ìwòsàn tẹ̀mí ní àwọn àǹfààní wíwàpẹ́títí
Àìsàn tẹ̀mí ń pani run. Ais 1:4-6; 6:10; Ho 4:6
Ìwòsàn tẹ̀mí ni iṣẹ́ pàtàkì tí a fi ránni. Joh 6:63; Lk 4:18
Ó ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ó ń fúnni láyọ̀, ìyè. Jak 5:19, 20; Iṣi 7:14-17
B. Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìwòsàn ti ara wíwàpẹ́títí wá
Jésù wo àwọn àrùn sàn, ó wàásù ìbùkún Ìjọba náà. Mt 4:23
Ìjọba náà ni a ṣèlérí bí ohun àmúlò fún ìwòsàn wíwàpẹ́títí. Mt 6:10; Ais 9:7
Ikú pàápàá ni a óò mú kúrò. 1Kọ 15:25, 26; Iṣi 21:4; 20:14
D. Ìgbàgbọ́ wò-ó-sàn òde òní kò ní ẹ̀rí ìfọwọ́sí àtọ̀runwá
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò wo ara wọn sàn lọ́nà ìyanu. 2Kọ 12:7-9; 1Ti 5:23
Ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu dópin lẹ́yìn ọjọ́ àwọn àpọ́sítélì. 1Kọ 13:8-11
Ìwòsàn kì í ṣe ẹ̀rí dídájú fún ojú rere Ọlọ́run. Mt 7:22, 23; 2Tẹ 2:9-11
E. Sísọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì jẹ́ ìpèsè onígbà kúkúrú
Ó jẹ́ àmì; ẹ̀bùn títóbi jù ni a ní láti wá. 1Kọ 14:22; 12:30, 31
Ẹ̀bùn ẹ̀mí lọ́nà iṣẹ́ ìyanu ni a sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò kọjá lọ. 1Kọ 13:8-10
Iṣẹ́ ìyanu kì í ṣe ẹ̀rí dídájú fún ojú rere Ọlọ́run. Mt 7:22, 23; 24:24
33. Ìyè
A. Ìyè àìnípẹ̀kun ni a mú dájú fún aráyé onígbọràn
Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí ìyè. Tit 1:2; Joh 10:27, 28
Ìyè ayérayé ni a mú dájú fún àwọn tí ń lo ìgbàgbọ́. Joh 11:25, 26
A ó pa ikú run. 1Kọ 15:26; Iṣi 21:4; 20:14; Ais 25:8
B. Ìyè ti ọ̀run ni a fi mọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó wà nínú ara Kristi
Ọlọ́run yan àwọn mẹ́ńbà bí ó ti wù ú. Mt 20:23; 1Kọ 12:18
Kìkì 144,000 ni a mú láti orí ilẹ̀ ayé. Iṣi 14:1, 4; 7:2-4; 5:9, 10
Àní Jòhánù Oníbàtisí pàápàá kì yóò sí nínú Ìjọba ọ̀run. Mt 11:11
D. Ìyè lórí ilẹ̀ ayé ni a ṣèlérí fún àìníye ènìyàn, “àwọn àgùntàn mìíràn”
Iye kéréje yóò wà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. Iṣi 14:1, 4; 7:2-4
“Àwọn àgùntàn mìíràn” kì í ṣe arákùnrin Kristi. Joh 10:16; Mt 25:32, 40
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń kórajọ nísinsìnyí fún lílàájá lórí ilẹ̀ ayé. Iṣi 7:9, 15-17
A óò jí àwọn mìíràn dìde fún ìyè lórí ilẹ̀ ayé. Iṣi 20:12; 21:4
34. Jèhófà, Ọlọ́run
“Ọlọ́run” kì í ṣe orúkọ pàtó; Olúwa wa ní orúkọ tirẹ̀. 1Kọ 8:5, 6
A ń gbàdúrà fún ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀. Mt 6:9, 10
Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Sm 83:18; Ẹk 6:2, 3; 3:15; Ais 42:8
Orúkọ náà wà nínú KJ. Ẹk 6:3 (Dy àlàyé etí ìwé). Sm 83:18; Ais 12:2; 26:4
Jésù sọ orúkọ náà di mímọ̀. Joh 17:6, 26; 5:43; 12:12, 13, 28
Kò ṣeé ṣe láti rí Ọlọ́run kí a sì yè. Ẹk 33:20; Joh 1:18; 1Jo 4:12
Kò sí ìdí láti rí Ọlọ́run kí a tó lè gbà gbọ́. Heb 11:1; Ro 8:24, 25; 10:17
A mọ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí a fojú rí. Ro 1:20; Sm 19:1, 2
Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run wà. Ais 46:8-11
Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. 1Jo 4:8, 16; Ẹk 34:6; 2Kọ 13:11; Mik 7:18
Ó tayọ nínú ọgbọ́n. Job 12:13; Ro 11:33; 1Kọ 2:7
Olódodo, a máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Di 32:4; Sm 37:28
Ó jẹ́ Olódùmarè, ó ní agbára gbogbo. Job 37:23; Iṣi 7:12; 4:11
E. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ń sin Ọlọ́run kan náà
Ọ̀nà tí ó dára lójú kì í fi ìgbà gbogbo tọ̀nà. Owe 16:25; Mt 7:21
Ọ̀nà méjì, ọ̀kanṣoṣo ni ó lọ sí ìyè. Mt 7:13, 14; Di 30:19
Ọ̀pọ̀ ọlọ́run ṣùgbọ́n Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo. 1Kọ 8:5, 6; Sm 82:1
Mímọ Ọlọ́run tòótọ́ ṣe kókó fún ìyè. Joh 17:3; 1Jo 5:20
35. Jésù
A. Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba tí a yàn
Àkọ́bí Ọlọ́run, ó dá ohun gbogbo. Iṣi 3:14; Kol 1:15-17
A ṣe é ní ènìyàn tí a bí nípasẹ̀ obìnrin, ó rẹlẹ̀ ju áńgẹ́lì. Ga 4:4; Heb 2:9
A fi ẹ̀mí Ọlọ́run bí i, pẹ̀lú ìpín ní ọ̀run. Mt 3:16, 17
A gbé e ga ju bí ó ti wà ṣáájú kí ó tó di ènìyàn. Flp 2:9, 10
B. Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ṣe kókó fún ìgbàlà
Kristi ni Irú-Ọmọ Ábúráhámù tí a ṣèlérí. Jẹ 22:18; Ga 3:16
Jésù nìkan ni Àlùfáà Àgbà, ìràpadà. 1Jo 2:1, 2; Heb 7:25, 26; Mt 20:28
Ìyè nípasẹ̀ mímọ Ọlọ́run àti Kristi, ìgbọràn. Joh 17:3; Iṣe 4:12
D. Ohun tí a ń béèrè ju wíwulẹ̀ gba Jésù gbọ́
Iṣẹ́ gbọ́dọ̀ bá ìgbàgbọ́ rìn. Jak 2:17-26; 1:22-25
A ní láti ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ, ṣe iṣẹ́ tí ó ṣe. Joh 14:12, 15; 1Jo 2:3
Kì í ṣe gbogbo ẹni tí ń lo orúkọ Olúwa ni yóò wọ Ìjọba náà. Mt 7:21-23
36. Mẹ́talọ́kan
A. Ọlọ́run, Baba náà, Ẹnì kan, tí ó tóbi jù lọ ní àgbáyé
Ọlọ́run kì í ṣe ẹni mẹ́ta. Di 6:4; Mal 2:10; Mk 10:18; Ro 3:29, 30
A dá Ọmọ; Ọlọ́run nìkan ni ó wà ṣáájú. Iṣi 3:14; Kol 1:15; Ais 44:6
Ọlọ́run ni olùṣàkóso àgbáyé nígbà gbogbo. Flp 2:5, 6; Da 4:35
A ní láti gbé Ọlọ́run ga lékè ohun gbogbo. Flp 2:10, 11
B. Ọmọ rẹlẹ̀ sí Baba ṣáájú àti lẹ́yìn wíwá sí ilẹ̀ ayé
Ọmọ ṣe ìgbọràn ní ọ̀run, Baba ni ó rán an. Joh 8:42; 12:49
Ó ṣe ìgbọràn lórí ilẹ̀ ayé, Baba tóbi jù ú lọ. Joh 14:28; 5:19; Heb 5:8
A gbé e ga ní ọ̀run, síbẹ̀ ó tẹríba. Flp 2:9; 1Kọ 15:28; Mt 20:23
Jèhófà ni orí àti Ọlọ́run Kristi. 1Kọ 11:3; Joh 20:17; Iṣi 1:6
D. Jíjẹ́ ọ̀kan Ọlọ́run àti Kristi
Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń wà ní ìṣọ̀kan pípé. Joh 8:28, 29; 14:10
Jíjẹ́ ọ̀kan, bí ti ọkọ àti aya. Joh 10:30; Mt 19:4-6
Gbogbo onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ ní ìṣọ̀kan kan náà. Joh 17:20-22; 1Kọ 1:10
Ìjọsìn kan ṣoṣo ti Jèhófà nípasẹ̀ Kristi títí láé. Joh 4:23, 24
E. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni ipá agbéṣẹ́ṣe rẹ̀
Ipá kan ni, kì í ṣe ẹnì kan. Mt 3:16; Joh 20:22; Iṣe 2:4, 17, 33
Kì í ṣe ẹnì kan ní ọ̀run pẹ̀lú Ọlọ́run àti Kristi. Iṣe 7:55, 56; Iṣi 7:10
Ọlọ́run ń darí rẹ̀ láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Sm 104:30; 1Kọ 12:4-11
Àwọn olùsin Ọlọ́run ń rí i gbà, a fi ń darí wọn. 1Kọ 2:12, 13; Ga 5:16
37. Òjíṣẹ́
A. Gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́
Jésù jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Ro 15:8, 9; Mt 20:28
Àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. 1Pe 2:21; 1Kọ 11:1
A gbọ́dọ̀ wàásù láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. 2Ti 4:2, 5; 1Kọ 9:16
B. Àwọn ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà
Ẹ̀mí Ọlọ́run àti ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. 2Ti 2:15; Ais 61:1-3
Tẹ̀ lé àwòkọ́ṣe Kristi ní wíwàásù. 1Pe 2:21; 2Ti 4:2, 5
Ọlọ́run ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí, ètò. Joh 14:26; 2Kọ 3:1-3
38. Ọjọ́ Àjọ̀dún, Ọjọ́ Ìbí
A. Ọjọ́ ìbí, Kérésìmesì, ni àwọn Kristẹni ìjímìjí kò ṣe
Àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn tòótọ́ ni ó ń ṣe é. Jẹ 40:20; Mt 14:6
Ọjọ́ ikú Jésù ni a ní láti máa rántí. Lk 22:19, 20; 1Kọ 11:25, 26
Àríyá aláriwo àjọ̀dún kò tọ̀nà. Ro 13:13; Ga 5:21; 1Pe 4:3
39. Ọjọ́ Ìkẹyìn
A. Ohun tí “òpin ayé” túmọ̀ sí
Ògógóró ètò àwọn nǹkan. Mt 24:3; 2Pe 3:5-7; Mk 13:4
Kì í ṣe òpin ilẹ̀ ayé, bí kò ṣe ti ètò burúkú. 1Jo 2:17
Àkókò òpin wà ṣáájú ìparun. Mt 24:14
Àsálà fún olódodo; Ayé Tuntun tẹ̀ lé e. 2Pe 2:9; Iṣi 7:14-17
B. Àìní wà fún wíwà lójúfò sí àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn
Ọlọ́run pèsè àwọn àmì fún ìtọ́sọ́nà wa. 2Ti 3:1-5; 1Tẹ 5:1-4
Ayé kùnà láti mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀. 2Pe 3:3, 4, 7; Mt 24:39
Ọlọ́run kò fi nǹkan falẹ̀, ṣùgbọ́n ó ń fúnni ní ìkìlọ̀. 2Pe 3:9
Èrè fún wíwà lójúfò, bíbìkítà. Lk 21:34-36
40. Ọkàn
Ènìyàn jẹ́ ọkàn. Jẹ 2:7; 1Kọ 15:45; Joṣ 11:11; Iṣe 27:37
A pe àwọn ẹranko pẹ̀lú ní ọkàn. Nu 31:28; Iṣi 16:3; Le 24:18
Ọkàn ní ẹ̀jẹ̀, ó máa ń jẹun, ó lè kú. Jer 2:34; Le 7:18; Isk 18:4
A máa ń sọ pé ènìyàn ní ọkàn, nítorí pé ó ní ìwàláàyè. Mk 8:36; Joh 10:15
B. Ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ọkàn àti ẹ̀mí
Ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tàbí ẹ̀dá jẹ́ ọkàn. Joh 10:15; Le 17:11
Ipá ìwàláàyè tí ń mú ọkàn ṣiṣẹ́ ni a ń pè ní “ẹ̀mí.” Sm 146:4; 104:29
Nígbà tí ènìyàn bá kú, àkóso ipá ìwàláàyè padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Onw 12:7
Ọlọ́run nìkan ni ó lè mú ipá ìwàláàyè ṣiṣẹ́. Isk 37:12-14
41. Ọ̀run
A. Kìkì 144,000 ní ń lọ sí ọ̀run
Díẹ̀; láti jẹ ọba pẹ̀lú Kristi. Iṣi 5:9, 10; 20:4
Jésù ni aṣáájú; a yan àwọn mìíràn lẹ́yìn náà. Kol 1:18; 1Pe 2:21
Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn yóò gbé orí ilẹ̀ ayé. Sm 72:8; Iṣi 21:3, 4
144,000 wà ní ipò pàtàkì tí àwọn mìíràn kò ní. Iṣi 14:1, 3; 7:4, 9
42. Sábáàtì
A. Ọjọ́ Sábáàtì kò de àwọn Kristẹni
A mú Òfin kúrò lórí ìpìlẹ̀ ikú Jésù. Ef 2:15
Sábáàtì kò de àwọn Kristẹni. Kol 2:16, 17; Ro 14:5, 10
A bá wọn wí fún pípa Sábáàtì mọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ga 4:9-11; Ro 10:2-4
Wọ́n wọ inú ìsinmi Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn. Heb 4:9-11
B. Ísírẹ́lì ìgbàanì nìkan ni a béèrè pé kí ó pa Sábáàtì mọ́
Ẹ̀yìn Ìjádelọ ni a kọ́kọ́ pa Sábáàtì mọ́. Ẹk 16:26, 27, 29, 30
Ó jẹ́ fún kìkì Ísírẹ́lì ti ara bí àmì. Ẹk 31:16, 17; Sm 147:19, 20
Àwọn ọdún Sábáàtì ni a béèrè fún lábẹ́ Òfin pẹ̀lú. Ẹk 23:10, 11; Le 25:3, 4
Sábáàtì kì í ṣe ọ̀ranyàn fún Kristẹni. Ro 14:5, 10; Ga 4:9-11
D. Sábáàtì ìsinmi Ọlọ́run (ọjọ́ keje “ọ̀sẹ̀” ìṣẹ̀dá)
Ó bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìṣẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé. Jẹ 2:2, 3; Heb 4:3-5
Ó wà títí kọjá ọjọ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Heb 4:6-8; Sm 95:7-9, 11
Àwọn Kristẹni sinmi kúrò nínú iṣẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan. Heb 4:9, 10
Yóò dópin nígbà tí Ìjọba náà bá parí iṣẹ́ nípa ilẹ̀ ayé. 1Kọ 15:24, 28
43. Ṣọ́ọ̀ṣì
A. Ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ ti ẹ̀mí, a kọ́ ọ lé orí Kristi
Ọlọ́run kì í gbé tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ ènìyàn kọ́. Iṣe 17:24, 25; 7:48
Ṣọ́ọ̀ṣì tòótọ́ jẹ́ tẹ́ńpìlì ti ẹ̀mí ti àwọn òkúta ààyè. 1Pe 2:5, 6
Kristi, òkúta igun ilé; àwọn àpọ́sítélì, ìpìlẹ̀ onípò kejì. Ef 2:20
A ní láti sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́. Joh 4:24
B. A kò kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì sórí Pétérù
Jésù kò sọ pé a kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì sórí Pétérù. Mt 16:18
A fi hàn pé Jésù ni “àpáta ràbàtà” náà. 1Kọ 10:4
Pétérù fi hàn pé Jésù ni ìpìlẹ̀. 1Pe 2:4, 6-8; Iṣe 4:8-12
44. Wòlíì Èké
A. A sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn wòlíì èké; wọ́n wà nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì
Ìlànà fún mímọ àwọn wòlíì èké. Di 18:20-22; Lk 6:26
A sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; èso wọn ni a ó fi mọ̀ wọ́n. Mt 24:23-26; 7:15-23