Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹyin Ọ̀dọ́—Bawo Ni Ẹyin Ṣe Le Layọ?

Ẹyin Ọ̀dọ́—Bawo Ni Ẹyin Ṣe Le Layọ?

Ori 9

Ẹyin Ọ̀dọ́—Bawo Ni Ẹyin Ṣe Le Layọ?

IGBA ọ̀dọ lè jẹ ọ̀kan ninu awọn akoko amoriya julọ ninu igbesi-aye. Ọjọ-ọla rẹ wà niwaju rẹ. Nitori naa ṣe aṣeyọri pupọ julọ rẹ̀. Lepa ayọ̀.

2 Ṣugbọn eyiini kò rọrun. Dr. Robert S. Brown ṣe iwadii kan nipa awọn géndé ọ̀dọ́ tí, ní ọdun diẹ sẹhin, wọn ronupinnu lati kájú oṣuwọn awọn ero rere wọn fun ẹgbẹ-oun-ọgba ati awọn alakoso. Oun rohin pe eyi tí ó ju idamẹta lọ ninu wọn ni wọn di onibanujẹ ọkàn, onirẹwẹsi ati alaniyan.

3 Igba gbogbo ni iwọ maa ngbọ́ tí a nsọ pe níní ẹkọ-iwe tí ó ṣee gbójúlé ni idahun naa. Ṣugbọn lonii ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ eniyan tí wọn ti kawe ṣì tún ní iṣoro ní rírí iṣẹ ṣe sibẹ. Awọn miiran tí wọn rí towó ṣe wá ríi pe awọn iṣẹ wọn tí nmú owó gọbọi wọle ti kuna lati mú ipa tiwọn ninu igbesi-aye ṣẹ. Bẹẹ ni ọpọ julọ ninu awọn eré-ifẹ igba ọ̀dọ́ kò sinni lọ si ayọ̀. Ní awọn ibikan, ida 80 ninu ọgọrun awọn igbeyawo ọ̀dọ́langba ni wọn nwolulẹ laarin ọdun marun.

4 Kinni iwọ lè ṣe ki tirẹ baa lè yatọ, ki o baa lè gbadun ara rẹ nitootọ nisinsinyi ki o sì ní ọjọ-ọla tí ntẹnilọrun? Tabi bi iwọ bá jẹ obi, bawo ni o ṣe lè ran awọn ọmọ rẹ lọwọ lati jẹ ki ọwọ wọn tẹ gongo-ilepa yẹn?

RIRONU NIPA ẸLẸDAA

5 Awọn ọ̀dọ́ eniyan miiran ni a nsún ṣiṣẹ nipasẹ awọn ojúgbà wọn miiran, tí wọn ní kiki iwọnba iriri diẹ ninu igbesi-aye. Bibeli ṣakiyesi pe:

“Ọlọgbọn eniyan ti rí ibi tẹlẹ, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a sì jẹ wọn níyà.”—Owe 22:3; 13:20.

Ọ̀dọ́ eniyan kan tí ó ó ní oju-iwoye tí ó ṣedeedee yoo gbà pe diẹ péré ninu awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ tabi awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni wọn dàníyàn gidigidi nipa ire pipẹtiti rẹ̀. Iwọ lè beere, ’Ní awọn ọdun tí nbọ̀, wọn yoo ha bikita nigba naa bi ayọ̀ mi bá bajẹ nipasẹ ohun tí mo nṣe nisinsinyi bi?’

6 Ṣugbọn tani ẹni tí ô bikita tí ó sì lè fun ọ ní ìṣíníyé didara julọ? Ẹlẹdaa rẹ ni. Oun nifẹẹ pe ki awọn ọ̀dọ́ gbadun iwalaaye. Oun kò kọ iha òdì si ohun gbogbo tí nfa ọkàn-àyà ati oju-iriran awọn ọ̀dọ́ mọra. Bi o tilẹ jẹ pe oun kii daabobo awọn ọdọ kuro lọwọ awọn abajade kikoro tí nwá lati inu títọ ipa-ọna igbesi-aye elewu, oun nṣe ohun tí iwọ lè fojusọna fun lati òdò ẹnikan tí ô ní inudidun si ọ nitootọ: Oun nkilọ fun ọ nipa awọn ohun tí yoo mú ibanujẹ ati jamba wá, oun sì nfunni ní ìṣíníyẹ̀ lori bi a o ṣe yẹra fun ṣiṣubu sinu awọn òfìn wọnyi. (Owe 27:5; Psalm 119:9) Iwe-mimọ sọ niti eyi pe:

“Maa yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu ẹ̀we rẹ; ki o si jẹ ki [ọkàn-àyà] rẹ ki ô mú ọ laraya ní ọjọ ẹ̀we rẹ, ki o sì maa rìn nipa ọna [ọkàn-àyà] rẹ ati nipa ìrí oju rẹ; ṣugbọn iwọ mọ eyi pe, nitori nkan wọnyi Ọlọrun yoo mú ọ wá sí idajọ. Nitori naa ṣí ibanujẹ kuro ní àyà rẹ, ki o si mú ibi kuro ní ara rẹ.”—Oniwaasu 11:9, 10.

7 Bi o tilẹ rí bẹẹ, idi tún wà sii fun rironu nipa Ẹlẹdaa ju pe oun nifẹẹ si ọ. Bi ô ti ṣeeṣe ki ìwọ ti ṣakiyesi, ọpọ awọn ẹ̀dé eniyan maa npa-ràdìràdì laini ete kan rara ninu igbesi-aye. Wọn kò ní ilepa kan ní pato tabi awọn ọpa-idiwọn diduroṣinṣin lori eyi tí wọn yoo gbé igbesi-aye wọn kà. Loorekoore nì wọn nyiju si awọn oògùn, sìgá mimu ati awọn ohun idunnu elewu lati kún àyẹ̀ ṣiṣofo ninu igbesi-aye wọn tabi lati ṣawari awọn ohun amoriya kan ninu igbesi-aye tí ô kún fun irẹwẹsi ní idakeji. Iwọ pẹlu ti lè ṣe diẹ lara awọn nkan wọnni, yala o mò nipa awọn ewu tí wọn ní ninu tabi bẹẹ kọ. Iwọ ha ní itẹlọrun pẹlu igbesi-aye rẹ titi di isinsinyi ati pẹlu ohun tí iwọ rí ní ọjọ-iwaju bi? Kii’ha iṣe akoko niyii lati sinmẹ̀dò ki o sì ronu nipa igbesi-aye rẹ bi?

8 Bi a ti gbé e yẹwo ṣaaju, fun igbesi-aye ẹnikan lati ní itumọ ati lati wà ní ‘isopọ’ timọtimọ pẹlu awọn otitọ-iṣẹlẹ, oun gbọdọ mọ̀jẹ́wọ̀ pe Ẹlẹdaa kan wà fun agbaye. Ẹni naa, Aṣẹ̀dá wa, ní awọn ọpa-idiwọn. (Psalm 100:3) Awọn ọpa-idiwọn wọnni wà ní ibamu pẹlu ọna tí oun gbà ṣe wa lati walaaye. Wọn gbeṣẹ wọn sì nṣeranwọ fun rírí ayọ̀. Awa rí ẹri eyiini ninu awọn ori iṣaaju nibi tí a ti jiroro nipa ibalopọ ṣaaju igbeyawo, àmujù ọti ati tẹ́tẹ́ títa. * Nitori naa bi iwọ bá fẹ́ igbesi-aye tí ô gbadunmọni, kò ha ní lọgbọn-ninu lati ronu nipa Ẹlẹdaa nigba tí o bá nronu nipa bi iwọ yoo ṣe gbé igbesi-aye, awọn ọpa-idiwọn wo ni iwọ yoo dìmú ati nibo ni igbesi-aye rẹ forile?

IGBESI-AYE PẸLU ETE ATI Ọ̀WỌ̀ ARA-ẸNI

9 A ṣakiyesi ninu Oniwaasu 11:9, 10 awọn alaye Bibeli kan tí a dari rẹ̀ si awọn ọ̀dọ́. Iwe Bibeli naa dé ipari-ero pe:

Opin gbogbo ọrọ naa tí a gbọ́ ni pe: “Bẹru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ̀ mọ́; nitori eyi ni iṣẹ gbogbo eniyan.”—Oniwaasu 12:13.

10 Jakejado ayé ẹgbẹẹgbaarun awọn ọ̀dọ́ eniyan ni wọn wà tí wọn ti ronu gidigidi nipa igbesi-aye wọn. Wọn ti ronu nipa Ẹlẹdaa naa wọn sì ti kẹkọọ Ọrọ rẹ̀. Wọn sì ti tún ríi pe ọ̀kan ninu awọn ohun ipilẹ tí a nbeere fun ayọ̀ ni lati gbé ní isopọ timọtimọ pẹlu Aṣẹ̀dá wọn. Eyiini pẹlu nilati jẹ ẹru-iṣẹ ati ete rẹ ninu igbesi-aye. Gbígbé lọna tí Iwe-mimọ lana rẹ̀ silẹ kii ṣe ohun ajeji, tí ô yọyẹ́ tabi alailadun. Kaka bẹẹ, ô jẹ ọna igbesi-aye tí ô gúnrégé tí ô sì ní itumọ. Ó njẹ ki ẹnikan lè fi pẹlu ọgbọn ati aṣeyọrisi rere bojuto awọn ọran owô, iṣẹ, ọna-iwahihu, igbesi-aye idile, eré-ìnàjú ati awọn ọran miiran tí iwọ dojukọ nisinsinyi tabi tí iwọ yoo ṣì dojukọ sibẹ. Iriri awọn Ẹlẹrii Jehofah ti fì idi otitọ naa mulẹ pe ọgbọn tí a gbeka ori Iwe-mimọ jẹ

igi ìyè fun gbogbo awọn tí wọn dì í mú: ibukun sì ni fun ẹni tí ó dì í mú ṣinṣin.—Owe 3:18.

Bibeli gbani-niyanju pe: “Ọmọkunrin mi, maṣe gbagbe ẹkọ mi, sì jẹ ki ọkàn-àyà rẹ ki ô pa awọn ilana-ipilẹ mi mọ́, nitori eyi yoo fun ọ ni awọn ọjọ gígùn, igbesi-aye ọlọdun-gbọọrọ, ati ayọ̀ nlánlà.”—Owe 3:1, 2, Jerusalem Bible.

11 Nigba tí iwọ bá tẹle ìṣíníyè Bibeli, iwọ lè dádúrô gedegbe bi ẹni tí ô dáyàtọ̀ lọna kan sí púrúntù ọ̀dọ kan. Nitootọ, awọn eniyan kan lè ṣe ariwisi sí ọ nipa eyi. (1 Peter 2:20; 4:4) Iwọ yoo ha jẹ ki eyiini fà ọ sẹhin kuro ní ipa-ọna tí yoo mú ki igbesi-aye rẹ tubọ jẹ aladun bi?

12 Ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ ni wọn wà tí wọn nsọrọ nipa rironu fun ara wọn, sibẹ awọn otitọ-iṣẹlẹ fihan pe ẹ̀rù nbà wọn lati dáyàtọ̀. Bibeli, bi ó tilẹ rí bẹẹ, ní awọn apẹẹrẹ ninu niti awọn ọdọ eniyan tí kò tẹle ogunlọgọ. Nigba tí wọn jẹ awọn ojulowo ọ̀dọ́ eniyan, pẹlu ifẹ, ìdàníyàn ati awọn ireti gan-an gẹgẹ bi iwọ ti ní, wọn ṣakoso ironu ati awọn ihuwa wọn nipasẹ imọran ọlọgbọn Ọlọrun.

13 O lè ka apẹẹrẹ kan ninu Daniel 1:6-20; 3:1-30. Awọn ọ̀dọ Hebrew mẹta tí wọn jẹ alabakẹgbẹ Daniel ní ifẹ sí dídáyàtọ̀ sí pupọ julọ awọn tí wọn yí wọn ká. Nigba tí a paṣẹ fun wọn lati foribalẹ fun ère kan, ohun kan tí Ọrọ Ọlọrun kaleewọ, wọn kòjálẹ̀. Iwọ yoo ha ti lè ṣe eyiini bi? Awọn miiran tilẹ fẹ́ lati pa wọn nitori iduro wọn. Sibẹ wọn rọ̀mọ awọn ilana-ipilẹ tiwọn, iwọ yoo sì ríi lati inu akọsilẹ naa pe Ọlọrun tẹwọgba, ô sì daabobo wọn. Nikẹhin, ọba Babylon bọla fun wọn, ní fifòhùnsí ohun tí Solomon kọwe rẹ̀ pe: ’Emi mọ̀ pe yoo dara fun awọn tí wọn bẹru Ọlọrun tootọ.’—Oniwaasu 8:12; Exodus 20:4, 5.

14 Awọn ọdọkunrin wọnni jèrè ọ̀wọ̀ awọn ẹlomiran, ṣugbọn wọn tún ní ọ̀wọ̀ ara-ẹni pẹlu. Ohun kan naa ni ó jẹ otitọ niti pupọ awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹrii fun Jehofah ní awọn akoko ode-oni. Awọn ọmọ-ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ wọn ti sọrọ-ìyìn fun awọn igbagbọ wọn ati otitọ naa pe awọn Kristian wọnyi mọ ibi tí wọn forile ninu igbesi-aye. Iwọ kò ha gbà pe ki a bọwọ funni ati níní ọ̀wọ̀ fun ara-ẹni nmú ki igbesi-aye tubọ ní itumọ bi?

AYỌ̀ IDILE

15 Imọran Bibeli pẹlu tún nfikun awọn igbesi-aye tí ó tubọ lérè ninu fun awọn ọ̀dọ́ eniyan nipa mímú ki ìdè idile tubọ sunmọra sii.

16 Laisi iyemeji iwọ mọ̀ nipa awọn idile nibi tí iyapa wà laarin awọn obi ati awọn ọmọ, yala wọn jẹ ọmọ kekere tabi wọn jẹ ọ̀dọ́langba. Nigba gbogbo alafo yii maa ndagba nigba tí awọn obi bá gbiyanju lati dari awọn ọmọ wọn, awọn tí wọn maa nbinu si ki a sọ fun wọn ohun tí wọn yoo ṣe tabi tí wọn kò gbọdọ ṣe.

17 Bibeli rannilọwọ lati bori iṣoro yii ni fifi itọsọna tí ô ṣedeedee fun awọn ọ̀dọ́ ati awọn obi, iru bii:

“Ẹyin ọmọ, ẹru-iṣẹ Kristian yin ni ô jẹ lati ṣegbọran si awọn obi yin, nitori eyi ni ô tọ́ lati ṣe. ’Bọwọ fun baba ati iya rẹ, tiiṣe ofin kìn-ín-ní pẹlu afikun ileri: ’Ki ohun gbogbo baa lè dara fun ọ, ki iwọ ki ô sì lè walaaye pẹ́ ní ilẹ naa.’ Ẹyin obi, ẹ maṣe bá awọn ọmọ yin lò lọna tí yoo mú wọn binu. Kaka bẹẹ, ẹ kọ wọn pẹlu ibawi ati itọni Kristian.”—Ephesus 6:1-4, Good News Bible.

18 Amọ ṣa o, kò si awọn obi tí ô pé. Sibẹ ô jẹ “ohun tí ô tọ́” fun awọn ọ̀dọ́ lati bọwọ fun awọn obi wọn. Eeṣe? Lapakan, nitori pe awọn obi wa ti ṣe pupọ fun wa—fifun wa ní ounjẹ, bibojuto wa nigba tí a nṣaisan, ṣiṣiṣẹ lati pese ibugbe ati lati kún awọn aini wa. Awa kò lè gba awọn alagbaṣe kan lati ṣe gbogbo ohun tí wọn ti ṣe ati pẹlu ifẹ atinuwa tí wọn ti fihan. Nitori naa ô tọ́ niti ọna-iwahihu lati bọ̀wọ̀ fun wọn, ani bi awa yoo ti fẹ́ lati rí ọ̀wọ̀ gbà lati ọ̀dọ̀ awọn ọmọ tí awa lè ní ní ọjọ kan.

19 Awọn ọ̀dọ tí wọn fi pẹlu otitọ-inu gbiyanju lati lo iru imọran Bibeli bẹẹ yoo ní imọlara ailewu pupọ sii. Wọn yoo dákún idile tí ô sunmọra sii, tí yoo mú ki igbesi-aye wọn tubọ ní alaafia ati ayọ̀ sii. A o si daabobo wọn kuro lọwọ awọn ọran-iṣoro kan tí awọn obi lè rí tẹlẹ nitori iriri titobi jù wọn ninu igbesi-aye. (Owe 30:17) Eyi tí a kò tún ní gbojufoda ni itẹlọrun tí awọn ọ̀dọ eniyan lè jere lati inu mímọ̀ pe awọn nhuwa ní ibamu pẹlu ifẹ-inu Ẹlẹdaa wọn.

20 Titẹwọgba awọn imọran Bibeli nṣanfaani fun awọn ọ̀dọ́ eniyan ní awọn ọna miiran, pẹlu. Ní mimọriri iniyelori ifọwọsowọpọ ati ti níní ọ̀wọ̀ fun ọla-aṣẹ, wọn lè fi pẹlu irọrun ṣe nkan lọna tí ô gúnrégé julọ ní ile-ẹkọ, ninu ibalo agbanisiṣẹ-ati-oṣiṣẹ nigbẹhin ati nigba tí wọn bá nbá oniṣẹ-ọba lò. (Matthew 5:41) Ati pẹlu, fifi imọran Bibeli sọkàn yoo mú ayọ̀ wá nigba tí wọn bá ní ẹnikeji ati awọn ọmọ tiwọn funraawọn.

AWỌN OBI NKÓ IPA PATAKI

21 Ní fifun bi awọn ọdọ eniyan ṣe lè ní ayọ̀ ní afiyesi, awa kò lè ṣaibikita fun ipa pataki tí awọn obi nkó. Pupọ julọ ninu awọn obi ní imọlara ẹru-iṣẹ wọn lati gbiyanju lati pese ounjẹ didara, aṣọ ati ibugbe tí ô gbadunmọni fun awọn ọmọ wọn. Ṣugbọn bi awọn ọ̀dọ́ yoo bá di awọn eniyan daradara, wọn yoo nilo itọni obi, atunṣe ati itọsọna ọna-iwahihu. O ti hàn pe Bibeli ni ipilẹ tí ó dara julọ fun eyi. (Matthew 11:19) Deuteronomy 6:6, 7 ṣalaye pe ìru itọni bẹẹ nilati jẹ apakan igbesi-aye idile tí ó ṣedeedee, kii ṣe ohun tí a nmẹnukan lẹẹkọọkan ṣá. Ati pẹlu, itọni yii lè, ó sì nilati, bẹrẹ ní kùtùkùtù ọjọ-ori.—2 Timothy 3:15; Mark 10:13-16.

22 Awọn obi kan pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ yoo ní iyalẹnu lati kà pe: “Ní àyà ọmọde ni wèrè dì sí; ṣugbọn paṣan itọni ni yoo lé e jinna kupro lọdọ rẹ̀.” (Owe 22:15) Ṣugbọn kinni ohun tí eyiini tumọsi? Awọn obi kan lekoko debi pe wọn nṣe ipalara ti ara fun awọn ọmọ wọn nipa lílù. Awọn miiran nsọ pe awọn ọmọ ni a nilati yọnda fun lati dagba funraawọn. Aṣejù ninu mejeeji ni kò tọna.

23 Ṣaaju a kà pe awọn obi nilati ‘tọ́ awọn ọmọ wọn pẹlu ibawi ati itọni Kristian. (Ephesus 6:4, Good News Bible) Iwa onroro kii ṣe ibawi Kristian. (Owe 16:32; 25:28) Ibawi onifẹẹ ni a lè fihan pẹlu ọrọ diduroṣinṣin. Eyi rí bẹẹ ní pataki bi awọn obi bá mú un ṣe kedere idi fun aṣẹ wọn ati bi wọn bá sì nduro ti ohun tí wọn bá sọ deedee. Nigba tí wèrè tí ô wà ní ọkàn-àyà ọdọmọkunrin tabi ọdọmọbinrin kan bá sì nsún un lati ṣaigbọran—tí eyiini sì nṣẹlẹ leralera—iru ìjẹníyà kan yoo tẹ iru iwa bẹẹ wọlẹ̀. Gbigba anfaani kan kuro lè ṣiṣẹ. Ọrọ Ọlọrun sọ, bi o tilẹ rí bẹẹ, pe ninu awọn ọran kan ìjẹníyà gidi niti ara—gbígbá lábàrá, tí kii ṣe pẹlu ibinu—ni a lè nilo.—Owe 23:13, 14; 13:24.

24 Bi awọn ọmọ keekeeke tí ndagba sii, ọna tí a gbà nbá wọn lò yoo yipada. Bi ô ti ṣe pe gbígbá lábàrá ti lè ṣiṣẹ daradara fun ọmọ kekere kan, bi oun ti ndagba awọn ọna miiran lè sàn jù ki ô sì baamu jù. Bakan naa, awọn obi nilati rọra maa yọnda ominira ihuwa ati ẹru-iṣẹ fun ọmọkunrin tabi ọmọbinrin kan sii..—1 Corinth 13:11.

25 Ifẹ fun awọn ọmọ rẹ ṣe pataki lati lè ràn wọn lọwọ pẹlu awọn ọran-iṣoro wọn. Eyi nilati jẹ ete-isunniṣe tí ó wà lẹhin ibawi, ó sì nmú ki atunṣe tubọ rọrun lati gbà. Ikuna lati pese itọsọna ati ibawi fun awọn ọmọ ẹni dabi sísẹ́ jíjẹ́ obi fun wọn. Eyi ni a ṣalaye rẹ̀ ninu Hebrew 12:5-11, eyi tí ô tọka jade pe Jehofah funraarẹ̀ nfunni ní ibawi lati inu ifẹ.

26 Ifẹ fun Ọlọrun tún ṣe pataki pẹlu. Eyi yoo sún awọn obi lati korira awọn ohun tí Ọlọrun dẹbi fun, bii irọ́ pípa, ìwọra, jijale, bíbá ẹyà kan naa lopọ ati agbere. (1 Corinth 6:9, 10; Psalm 97:10) Awọn obi tí wọn tipa bayii fi ifẹ wọn fun Ọlọrun hàn yoo fi apẹẹrẹ yiyẹ lelẹ fun awọn ọmọ, eyi tí ô sì ṣe pataki. Ní isopọ pẹlu eyi, awọn obi nilati mú dagba ninu awọn ọmọ wọn iru ikorira kan naa fun ohun tí ô buru ati ifẹ fun Ọlọrun ati ohun tí ô dara bakan naa.

27 Niwọn bi idile ti jẹ ayé alakọkọ-bẹrẹ fun ọ̀dọ́ eniyan kan, awọn obi nilati ṣiṣẹ lati mú ki eyiini jẹ alailewu. A ti sọ pe ọ̀kan ninu awọn ohun titobi julọ tí baba kan lè ṣe fun awọn ọmọ rẹ̀ ni lati nifẹẹ mama wọn. Nigba ti igbesi-aye idile bá jẹ eyi tí a gbeka ori ifẹ ati ọgbọn Kristian, awọn ọ̀dọ eniyan yoo ní ipilẹ diduroṣinṣin tí wọn yoo duro lé lori. Wọn yoo ní awọn ọpa-idiwọn yiyekooro a o si ràn wọn lọwọ lati ronu nipa Ẹlẹdaa wọn lati igba ọ̀dọ́ siwaju.—Oniwaasu 12:1, 13, 14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 8 Ohùn-orin, dida-ọjọ ajọrode, iwọṣọ, ere-idaraya, ile-ẹkọ ati awọn aniyan miiran ti o gba ọkàn awọn èwe ni a jiroro loju-iwoye Bibeli ninu iwe naa Igba Ewe Rẹ—Bí O Ṣe Le Gbadun Rẹ̀ Julọ, tì a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí ayọ̀ fi jẹ ipenija fun awọn ọ̀dọ́ eniyan? (1-4)

Eeṣe tí iwọ fi nilati ronu nipa Ọlọrun? (5-8)

Eeṣe tí ó fi jẹ iwa adanida fun ọ lati dàníyàn nipa ifẹ-inu Ọlọrun? (Psalm 128:1, 2) (9, 10)

Bi gbígbé pẹlu ninu ọkàn bá mú ki o yatọ, eyiini ha buru bi? (11-14)

Awọn ìdi wo ni iwọ ní lati tẹle Iwe-mimọ ninu idile rẹ?(15-20)

Bawo ni awọn obi ṣe lè ran awọn ọmọ wọn lọwọ lati tẹle ipa-ọna ọgbọn? (21)

Iru ibawi wo ni awọn obi nilati pese? (22-24)

Bawo ni ifẹ idile yoo ṣe kan awọn ọran-iṣoro ọ̀dọ? (25-27)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 89]

RÍRÍ ETE NINU IGBESI-AYE

Ẹka kan ninu Office of Prime Minister ti ilẹ Japan ṣe iwadii ní oniruuru ilẹ. Ô ṣe ayẹwo ohun ti oju-iwoye awọn òdẹ jẹ nipa ete igbesi-aye ati ọjọ-ọla. Ní kikẹkọọ awọn abajade, Professor Sanshiro Shirakashi pari-ero sí pe “awọn ọ̀dọ́ ayé ní iwa ainireti-rere” nipa ọjọ-ọla, eyi ti ndabarú ihuwa wọn ati irisi wọn ní gbogbogboo lori igbesi-aye. Ṣugbọn eyiini lè yipada.

Akẹkọọ kan tí orukọ rẹ̀ njẹ Linda rohin pe: “Lati inu awọn ẹkọ mi ní college, mo lè rii pe ọna igbesi-aye tí a fi ntẹ mi npò ó rá lọ. Awọn ipo nibi gbogbo ninu ayé nburu siwaju, emi kò sì ní awọn idahun bẹẹ ni kò si sí ero-inu kan nipa ibi ti mo lè yijusi fun awọn idahun.”

Nigba tí obinrin naa ṣì wà nílé ní California lakoko isinmi awọn Ẹlẹrii Jehofah meji ṣe ikesini lẹnu-ọna rẹ̀. Oun wipe: “Wọn sọ fun mi pe awọn idahun naa ni a o rí ninu Bibeli. A jiroro nipa paradise ilẹ-aye tí Ọlọrun yoo gbekalẹ labẹ eto titun rẹ̀ ati ileri rẹ̀ lati mú awọn olubi kuro. A kò tiì fi kẹ mi rí pe iru awọn otitọ agbayanu bẹẹ ni a o rí ninu Bibeli.”

Lẹhin ti Linda pada sí Arisona, oun bá ijọ adugbo naa ti awọn Ẹlẹrii Jehofah sọrọ ò sì tẹwọgba ifilọni ikẹkọọ Bibeli ọsọọsẹ lọfẹẹ. Eyiini ràn án lọwọ lati kẹkọọ awọn ọpa-idiwọn eyi tí ó fun un ní igbesi-aye ti ó fẹsẹmulẹ. Ati pẹlu, ó jere ete ninu igbesi-aye tí ó fi jẹ pe lonii igbesi-aye rẹ̀ tubọ layọ sii ti o ó sì ní ẹ̀rẹ̀-ẹ̀san sii.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 92]

Tani ẹni tí ó tọju rẹ nigba tí ara rẹ kò dá?

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 93]

Kikẹkọọ Ọrọ Ọlọrun nran awọn ọ̀dọ́ lọwọ lati rí ayọ̀