Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aisan ati Iku—Kilo Fa A?

Aisan ati Iku—Kilo Fa A?

Ori 11

Aisan ati Iku—Kilo Fa A?

OHUN yowu ki awọn eniyan lè ṣe lati bojuto ilera wọn, wọn ndagba di arugbo, wọn nṣaisan wọn sì nkú nikẹhin. Kò sí ẹni tí ó lè yẹ̀ ẹ́ silẹ. Ani awọn eniyan olufọkansin sí Ọlọrun paapaa kò lè ṣe e. (1 Awọn Ọba 1:1; 2:1, 10; 1 Timothy 5:23) Eeṣe tí ó fi rí bẹẹ?

2 Awọn cell inu ara wa dabi eyi tí ó ní agbara fun pipaarọ awọn tí wọn kọṣẹ́ fun igba pípẹ́ ju bi wọn ti nṣe nisinsinyi, ọpọlọ wa pẹlu ní agbara-àyè tí ó pọ̀ ju eyi tí a lè lò ninu ọpọlọpọ gígùn iwalaaye. Eeṣe—bi ó bá jẹ pe a kò dá wa lati lo awọn agbara-àyè wọnyi? Niti gasikia, awọn onimọ-ijinlẹ kò lè ṣalaye idi tí a fi ndagba darugbo, tí a nṣaisan tí a sì nkú. Ṣugbọn Bibeli ṣe bẹẹ.

OKUNFA AISAN ATI IKU

3 Apostle Paul tọka wa si ọna-ìhà titọna, ní sisọ pe: “Ninu Adam ni gbogbo wa ti nkú.” (1 Corinth 15:21, 22, NW) Paul nihin tọkasi akọsilẹ Bibeli nipa Adam ati Efa, akọsilẹ yii tí Jesu Kristi kàn níṣòó pe ó ṣedeedee. (Mark 10:6-8) Ẹlẹdaa naa fi tọkọtaya naa sinu ile ọgba kan, pẹlu ireti rere alayọ ti iwalaaye ailopin ní ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀. Wọn ní ọpọlọpọ ounjẹ afunni-nilera lati ara oniruuru igi ati awọn eweko miiran. Siwaju sii, Adam ati Efa jẹ awọn eniyan pípé. Awọn ero-inu’ ati ara wọn jẹ alailabuku, kò sì sí idi kankan fun Iwọnyi lati bẹrẹsi jó àjérẹ̀hìn, bi ó ti nṣẹlẹ si awọn eniyan nisinsinyi.—Deuteronomy 32:4; Genesis 1:31.

4 Kiki ikalọwọko kanṣoṣo péré ni a fun eniyan meji akọkọ naa. Ọlọrun wipe: “Ninu igi imọ rere ati buburu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; nitori pe ní ọjọ tí iwọ bá jẹ ninu rẹ̀, kíkú ni iwọ yoo kú.” (Genesis 2:17) Nipa hihuwa ní ibamu pẹlu ikalọwọko yii, wọn yoo fi ijẹwọ itẹwọgba wọn hàn fun ipo aṣẹ Ọlọrun lati ronupinnu ohun tí ó jẹ rere ati ohun tí ó jẹ buburu fun ẹda-eniyan. Nigba tí ó ṣe, wọn gbé ọpa-idiwọn tiwọn kalẹ nipa rere ati buburu. (Genesis 3:6, 7) Nipa ṣiṣaigbọran sí ofin Ọlọrun tí a ṣalaye rẹ̀ kedere, wọn kó sinu ohun tí Bibeli pè ní “ẹṣẹ.” Ninu ede Hebrew ati ti Greek, “lati dẹṣẹ” tumọsi “lati tàsé (ami naa).” Adam ati Efa tàsé ami naa tabi kuna lati dọgba pẹlu igbọran pípé. Wọn kò tún fi ijẹpipe bii ti Jehofah hàn, wọn sì mú wá sori ara wọn idalẹbi ododo Ọlọrun.—Luke 16:10.

5 Ẹṣẹ Adam ati Efa ní ipa lori awọn ati awa naa. Kinni tiwa ti jẹ́? Họọwu, Ọlọrun kò yẹgi mọ́ wọn lẹsẹkẹsẹ. Ní fifi igbatẹniro hàn fun gbogbo awọn ẹni tí ọran naa kàn, Jehofah jẹ ki awọn eniyan meji akọkọ naa bí awọn ọmọ. Ṣugbọn Adam ati Efa kò tún jẹ pípé mọ́; nigba tí wọn ti dẹṣẹ wọn bẹrẹsi jó àjòrẹ̀hìn niti ara ati ti ọpọlọ. Nitori naa wọn kò lé mú awọn ọmọ pípé jade. (Job 14:4) Ipo naa ni a lè fiwe ti tọkọtaya kan lonii tí wọn ní abuku ninu ẹya ibimọ wọn eyi tí wọn ti ta atare rẹ̀ si awọn ọmọ wọn. A jogun abuku ẹṣẹ, nitori pe gbogbo wa ni a pẹ̀ka lati inu ẹda-eniyan meji akọkọ tí wọn jẹ alaipe. Paul ṣalaye pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹṣẹ ti ti ipa ọ̀dọ̀ eniyan kan wọ ayé, ati iku nipa ẹṣẹ; bẹẹ ni ẹṣẹ si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.”—Rome 5:12; Psalm 51:5.

6 Ipo naa ha jẹ ti alainireti bi? Ọrọ-itan ati Bibeli kàn án níṣòó pe bi a bá fi i silẹ fun awọn ẹda-eniyan bẹẹ ni ìbá ti jẹ́. Awa kò lè wẹ ara wa mọ́ kuro ninu abawọn ẹṣẹ tabi lati tú ara wa silẹ kuro ninu idalẹbi Ọlọrun. Bi itusilẹ yoo bá wà, Ọlọrun ni yoo pese rẹ̀. Ofin rẹ̀ ni a rú, nitori naa oun ni yoo jẹ Ẹni naa tí yoo ronupinnu bi a o ṣe dé oju-iwọn idajọ ododo pípé ki ó sì pese itusilẹ. Jehofah Ọlọrun fi ojurere àìlétòọsí rẹ̀ hàn nipa ṣiṣe ipese fun ìdánídé fun awọn ọmọ Adam ati Efa, tí ó ní awa naa ninu. Bibeli ṣalaye ohun tí ipese naa jẹ ati bi a ṣe lè janfaani rẹ̀.

7 Awọn ẹsẹ wọnyi funni ní ipilẹ fun liloye ọran naa:

“Nitori Ọlọrun fẹ araye tobẹẹ gẹ́ẹ́, tí ò fi [Ọmọkunrin] bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni tí ó bá gbà á gbọ má baa ṣegbe, ṣugbọn ki ó ní ìyè ainipẹkun.”—John 3:16.

“Nitori Ọmọ-eniyan tikaraarẹ̀ kò ti wá ki a baa maa ṣe iranṣẹ fun wn, bikoṣe lati maa ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada fun ọpọlọpọ eniyan.Mark 10:45.

“Gbogbo eniyan ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọn sì kuna ogo Ọlọrun; awọn ẹmi tí a ndalare lọfẹẹ nipa oore ọfẹ rẹ̀, nipa idande tí ó wà ninu, Kristi Jesu ẹni ti Ọlọrun ti gbekalẹ lati jẹ etutu nipa igbagbọ ninu, ẹjẹ rẹ̀.”—Rome 8:23-25.

KINNI “IRAPADA NAA”?

8 Meji ninu awọn ẹsẹ wọnni mẹnukan “irapada.” Eyiini, ní itumọ taarata, jẹ iye-owo kan tí a san lati sọ ẹni tí a kólẹrú di ominira. (Isaiah 43:3) A saba maa ngbọ ọrọ naa tí a nlò ó ní itọkasi owó tí a san fun dídá ẹni tí ó jẹ́ ẹran-ọdẹ ìjínigbé nídè. Ninu ọran tiwa, òndè naa ni araye. Adam tà wa sinu ìdè si ẹṣẹ, pẹlu aisan ati iku ní iyọrisi rẹ̀. (Rome 7:14) Kinni ohun iyebiye naa tí yoo ra araye pada ki ó sì ṣi ọna silẹ fun ireti rere ti iwalaaye tí ó ní ominira kuro lọwọ awọn ìiyọrisi ẹṣẹ?

9 Ati pe Bibeli sọ pe Jesu ’fi iwalaaye rẹ̀ lelẹ gẹgẹ bi irapada.’ (Mark 10:45) A lè ríi lati inu eyi pe iwalaaye eniyan ni a nilo. Nipa didẹṣẹ, Adam ti padanu iwalaaye eniyan pípé. Lati ṣí ọna silẹ fun araye lati tún jere ìyé pada ninu ijẹpipe iwalaaye eniyan pípé miiran ni a nilo lati mú ki ó ṣedeedee tabi ra ohun tí Adam ti sọnu pada. Eyi tẹnumọ idi tí kò fi sí atọmọdọmọ Adam alaipe tí ó lè pese irapada naa. Gẹgẹ bi Psalm 49:7, 8 ti wi: “Eniyan kò lè ṣe idande ara rẹ̀ laelae tabi san owó irapada ara rẹ̀ fun Ọlọrun; ó ṣe iyebiye pupọ lati ṣe idande iwalaaye rẹ̀, ó rekọja rẹ̀.”—Jerusalem, Bible.

10 Lati pese iye-owó irapada naa, Ọlọrun rán Ọmọkunrin ẹmi pípé rẹ̀ lati ọrun wá ki a sì bíi gẹgẹ bi eniyan. Angeli kan ṣalaye fun Mary Wundia alailabuku naa bii Ọlọrun yoo ṣe ríi daju pe Jesu yoo jẹ ẹni pípé nigba ìbí: “Agbara Ọga Ogo yoo ṣiji bò ọ. Nitori ohun mímọ́ tí a o ti inu rẹ bí, ọmọ[kunrin] Ọlọrun ni a o maa pè é.” (Luke 1:35; Galatia 4:4) Jesu tí kò ní eniyan alaipe ní baba ní omìnira kuro ninu ẹṣẹ ajogunba.—1 Peter 2:22; Hebrew 7:26.

11 Lẹhin gbígbé gẹgẹ bi eniyan ní ibamu kikun pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun, Kristi fi iwalaaye eniyan pípé rẹ̀ lelẹ. Ó jẹ iwalaaye iru eyi tí Adam ní nigba tí a dá a, nitori naa Jesu di “irapada tí ó baramu fun gbogbo eniyan.” (1 Timothy 2:5, 6; 1 Corinth 15:45) Bẹẹ ni, ó jẹ “fun gbogbo eniyan” niti pe oun san iye-owó naa lati ra idile ẹda-eniyan lapapọ. Bẹẹ gẹgẹ, Bibeli sọ pe a ti “rà wa ní iye kan.” (1 Corinth 6:20) Ọlọrun, nipasẹ iku Jesu, nipa bayii fi ipilẹ lelẹ fun ṣiṣe idakeji ohun tí Adam ṣe ní mímú ẹṣẹ, aisan ati iku wá sori araye. Otitọ yii lè ní itumọ gidi ní mímú ki igbesi-aye wa layọ.

BAWO NI A ṢE LÈ DÁRÍ AWỌN ẸṢẸ WA JÌ WA?

12 Ó dara lati mọ̀ lati inu Bibeli pe Jesu san iye-owo irapada naa. Ṣugbọn ohun kan ṣì wà sibẹ tí ó lè jẹ idena fun wa ní rírí itẹwọgba ati ibukun Ọlọrun. Eyiini ni otitọ naa pe awa funraawa jẹ ẹlẹṣẹ. Awa ’ntàsé ami naa’ ní ọpọlọpọ igba. Paul kọwe pe: “Gbogbo eniyan ni ó sá ti ṣẹ̀, wọn sì ti kuna ogo Ọlọrun.” (Rome 3:23) Kinni a lè ṣe nipa eyiini? Bawo ni a ṣe lè di ẹni itẹwọgba fun Ọlọrun ododo wa, Jehofah?

13 Dajudaju a kò ní reti pe ki Ọlọrun fi oju itẹwọgba wò wa bi a bá nbá a lọ ní ipa-ọna kan tí awa mọ̀ pe ó lodisi ifẹ-inu rẹ̀. A gbọdọ fi pẹlu otitọ-inu ronupiwada awọn ifẹ-ọkan àìtọ́, ọrọ ati iwa wa, lẹhin naa ki a sì sapa lati mú ara bá ọpa-idiwọn rẹ̀ tí a là lẹsẹẹsẹ ninu Bibeli mu. (Iṣe 17:30) Sibẹ, awọn ẹṣẹ wa—ti atẹhinwa ati ti isinsinyi—ni a ṣì nilati mú kuro. Ẹbọ irapada Jesu ṣiṣẹ ṣeranwọ fun wa nihin. Paul funni ní itọkafihan nipa eyi, ní kikọwe pe Ọlọrun ’gbé Jesu kalẹ lati jẹ etutu nipa igbagbọ ninu ẹjẹ rẹ̀.’Rome 3:24, 25.

14 Apostle naa nihin ntọkasi ohun kan tí Ọlọrun ṣeto rẹ̀ tipẹtipẹ ṣaaju lati yaworan tabi lati tọka siwaju si Kristi. Ní Israel igbaani awọn irubọ ẹranko fun ẹṣẹ ni a nṣe deedee fun ire awọn eniyan naa. Awọn eniyan naa lẹnikọọkan funraawọn lè rú ẹbọ ẹbi fun awọn ọran iwa-àìtọ́ pataki kan. (Leviticus 16:1-34; 5:1-6, 17-19) Ọlọrun tẹwọgba awọn ẹbọ ẹjẹ wọnyi gẹgẹ bi etutu fun tabi fifagile awọn ẹṣẹ ẹda-eniyan. Ṣugbọn eyi kò mú itusilẹ pipẹtiti wá, nitori Bibeli wipe “nitori kò ṣeeṣe fun ẹjẹ akọmalu ati ti ewurẹ lati mú ẹṣẹ kuro.” (Hebrew 10: 3, 4) Bi o tiwu ki o ri, awọn apá ijọsin wọnyi tí ó ní ninu awọn alufaa, awọn temple, awọn pẹpẹ ati awọn ohun irubọ jẹ “apejuwe” tabi “ojiji awọn ohun rere tí nbọ̀” tí ó niiṣe pẹlu ẹbọ Jesu.—Hebrew 9:6-9, 11, 12; 10:1.

15 Bibeli fi bi eyi ti ṣe pataki tó hàn fun wa lati rí idariji gbà, ní sisọ pe: “Ninu ẹni tí awa rí irapada, wa nipa ẹjẹ rẹ̀ [Jesu], idariji ẹṣẹ wa.” (Ephesus 1:7; 1 Peter 2:24) Nitori naa, ní afikun si pe iku rẹ̀ pese irapada, ó lè mú awọn ẹṣẹ wa kuro; a lè dárí awọn ẹṣẹ wa jì wa. Ṣugbọn a nbeere ohun kan lọwọ wa. Niwọn bi a ti rà wa, bẹẹ ni, “rà wa ní iye kan” nìpasẹ irapada Kristi, a gbọdọ nifẹẹ lati tẹwọgba Jesu gẹgẹ bi Oluwa wa tabi Oni-nkan ki a sì gbọran sii lẹnu. (1 Corinth 6:11, 20; Hebrew 5:9) Lẹhin eyi, aini naa wà fun wa lati ronupiwada awọn ẹṣẹ wa ki a sì jẹ ki igbagbọ ninu ẹbọ Jesu Oluwa wa bá eyi rìn.

16 Bi awa bá ṣe bẹẹ, awa kò nilati duro de idariji titi di igba tí Ọlọrun bá dá araye nídè kuro lọwọ gbogbo awọn ìyọrisi ẹṣẹ, ni fifi opin si aisan ati iku. Iwe-mimọ sọrọ nipa idariji yii gẹgẹ bi ohun kan tí a lè gbadun rẹ̀ nisinsinyi gan-an, tí ó nyọrisi ẹri-ọkan mímọ́gaara niwaju Ọlọrun.—1 John 2:12.

17 Nitori naa, ẹbọ Jesu nilati ní itumọ ti ara-ẹni gidi fun wa lojoojumọ. Nipasẹ rẹ̀ Ọlọrun lè dárí awọn aṣiṣe wa jì wa. Apostle John ṣalaye pe: “Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si yin, ki ẹ má baa dẹṣẹ. Bi ẹnikẹni bá sì dẹṣẹ, awa ní alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo.” (1 John 2:1; Luke 11:2-4) Eyi jẹ ẹkọ ipilẹ Bibeli ó sì ṣe pataki fun ayọ̀ wa pipẹtiti.—1 Corinth 15:3.

KINNI IWỌ YOO ṢE?

18 Bawo ni iwọ ṣe nhuwapada si ohun tí Bibeli wi nipa okunfa aisan ati iku, irapada naa ati ipese fun idariji nipasẹ Jesu Kristi? Ẹnikan lè gba ẹkunrẹrẹ alaye wọnyi sinu ọpọlọ lasan ki ó má sì ní ipa kankan lori ọkàn-àyà ati igbesi-aye rẹ̀. Ṣugbọn a nbeere pupọ sii lọwọ wa.

19 Awa ha mọriri ifẹ Ọlọrun ní pipese irapada naa bi? Apostle John kọwe pe: “Nitori Ọlọrun fẹ́ araye tobẹẹ gẹ́ẹ́, tí ó fi Ọmọ[kunrin] bíbí kanṣoṣo funni.” (John 3:16) Ranti pe awọn eniyan tí ọran kàn naa jẹ ẹlẹṣẹ, tí wọn ti di ajeji si Ọlọrun. (Rome 5:10; Colossae 1:21) Iwọ yoo ha fi ẹni ọ̀wọ́n julọ rẹ lelẹ nitori awọn ẹni tí pupọ julọ wọn ní ifẹ diẹ tabi ṣaini rara si ọ? Sibẹ Jehofah mú ki Ọmọkunrin rẹ̀ alailẹṣẹ ati olootọ, Akọbi rẹ̀ olufẹ, wá si ayé lati dojukọ itẹmbẹlu, itiju ati iku lati lè pese itusilẹ fun iran ẹda-eniyan. Eyiini sún Paul lati kọwe pe: “Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ Oun paapaa si wa hàn ní eyi pe, nigba tí awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.”—Rome 5:8.

20 Ọmọkunrin naa fi ifẹ tirẹ̀ hàn, pẹlu. Nigba tí akoko naa dé, ó fi tifẹtifẹ rẹ ara rẹ̀ silẹ lati di eniyan. Ó sinru fun awọn eniyan alaipe, ó nkọ́ ó sì nwò wọn sàn. Ati pe, ní jíjẹ́ ọmọluwabi sibẹ, oun gba ẹgan, idaloro ati iku itiju lati ọwọ awọn ọta otitọ. Gẹgẹ bi iranlọwọ si fifi imọriri hàn si eyi, lo akoko lati ka akọsilẹ naa nipa ifihan, ìgbẹ́jọ, èébú ati iṣekupa Jesu, gẹgẹ bi a ti ṣe akọsilẹ rẹ̀ ninu Luke 22:47 titi dé 23:47.

21 Bawo ni iwọ yoo ṣe dahunpada si gbogbo eyi? Dajudaju ẹnikan kò nilati jẹ ki titẹwọgba tí oun tẹwọgba ipese onifẹẹ ti irapada naa di awawi fun iwa-àìtọ. Eyiini yoo jẹ títàsé ete naa, yoo sì tún yọrisi ẹṣẹ tí ó rekọja idariji. (Hebrew 10:26, 29; Numbers 15:30) Kaka bẹẹ, ó yẹ ki a sapa lati gbé lọna tí yoo mú ọlá wá fun Ẹlẹdaa wa. Ati pe igbagbọ ninu ipese nlánlà tí ó ṣe nipasẹ Ọmọkunrin rẹ̀ nilati sún wa lati bá awọn ẹlomiran sọrọ nipa rẹ̀, ki a ràn wọn lọwọ lati mọriri bi awọn pẹlu ṣe lè jèrè-anfaani.—Iṣe 4:12; Rome 10:9, 10; James 2:26; 2 Corinth 5:14, 15.

22 Nigba tí Jesu Kristi wà lori ilẹ-aye oun wipe oun lè funni ní idariji Ọlọrun fun ẹṣẹ. Awọn ọta kan ṣe awawi ọlọfintoto sii nitori eyiini. Nitori naa Jesu fi ẹri eyi hàn nipa ṣiṣe iwosan fun ọkunrin arọ kan. (Luke 5:17-26) Nipa bẹẹ, gan-an gẹgẹ bi ẹṣẹ ṣe nmú aiṣedeedee ti ara wá sori araye, idariji ẹṣẹ lè yọrisi awọn èrè-anfaani. Ó ṣe pataki lati mọ eyiini. Ohun tí Jesu ṣe lori ilẹ-aye fihan pe Ọlọrun lè mú opin bá aisan ati iku. Eyiini wà ní ibamu pẹlu ohun tí Jesu Kristi funraarẹ̀ sọ, eyiini ni, pe Ọlọrun fi Ọmọkunrin rẹ̀ funni ki awọn ẹni tí wọn ní igbagbọ baa lè ní “Ìyè ainipẹkun.” (John 3:16) Ṣugbọn bawo? Nigba wo? Ati pe kinni nipa ti awọn ololufẹ wa tí wọn ti kú ṣaaju isinsinyi?

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí aisan ati iku fi nrúnilójú? (1, 2)

Bawo ni aisan ati iku ṣe wá di eyi tí ó kàn wa? (3-5)

Eeṣe tí atunṣe si aisan ati iku fi kù sọwọ Ọlọrun? (6, 7)

Bawo ni a ṣe pese irapada kan? (8-11)

Ipilẹ wo ni ó wà fun dídárí awọn ẹṣẹ wa jì wa? (12-17)

Bawo ni iwọ ṣe dahunpada si ohun tí Ọlọrun ati Jesu ti ṣe? (1 John 4:9-11) (18-21)

Idariji awọn ẹṣẹ wa lè ní ifojusọna-rere wo ninu? (22)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 103]

Akọwe imọ-ijinlẹ naa Isaac Asimov ṣalaye pe awọn eroja molecule RNA tí wọn wà ninu ọpọlọ eniyan pese “eto-iṣiṣẹ ti nto awọn nkan jọ papọ ti ó dángájiá tó lati bojuto ẹrù ẹkọ ati agbara iranti eyi tí ó ṣeeṣe ki ẹda-eniyan tò lé e lori lọna ti òó pegedé—ati iye ti ó pọ̀ ju eyiini lọna ẹgbẹẹgbẹrun ọkẹ, pẹlu.”—“Times Magazine” ti New York.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 108]

8Awọn ẹbọ ní Israel tọka siwaju sí ẹbọ irapada Jesu