Awọn Ọran-iṣoro Owó—Iranlọwọ Wọn?
Ori 6
Awọn Ọran-iṣoro Owó—Iranlọwọ Wọn?
“SÍSÀSÉ nmú ọ layọ, ọti-waini sì ndá ọ lárayá gágá, ṣugbọn iwọ kò è ní eyikeyi ninu wọn laisi owó.”—Oniwaasu 10:19, Good News Bible.
2 Owó jẹ aniyan pataki kan nibi gbogbo. Idi kan ni ifosoke owó ọjà. Lojoojumọ lô nnanilowo giga sii lati gbó igbesi-aye. Ọpọlọpọ eniyan kò tilẹ l lè ra ounjẹ tí wọn yoo jẹ. Iye awọn ọkunrin tí npò sii ni wọn nilati maa ṣiṣẹ nibi meji papọ, tí awọn iyawo pupọ sii sì nlọ ṣiṣẹ. Awọn idile njiya. Ilera njiya. Awọn ọran-iṣoro owó naa ni a tún mú buru sii nigba tí rira ọjà ní àwìn bá tún kówọ inu ọran naa. Ní gbigbarale ọjà àwìn, ọpọlọpọ eniyan tí gbẹ̀sṣẹ ti mù wọn dé ọrùn nbá a niṣo lati maa ná ow lori awọn nkan tí ô jẹ pe niti tootọ wọn kò nilo wọn. Eyi jẹ otitọ kii ṣe ní awọn ilẹ tí wọn ti goke agba nikan ni ṣugbọn ní awọn agbegbe ibi tí awọn eniyan ti ní awọn ohun iṣura tí kò tôó nkan pẹlu.
3 Iranlọwọ wiwulo wo ni Bibeli funni? Njẹ ô ha lè ràn ọ lọwọ lati rí iṣẹ kan tabi ki o di kan mú bi? Ô ha lè mú itura bá idaamu idile rẹ nipa owô bi, ní ṣiṣamọna si igbesi-aye tí ó layọ sii?
ÀÌṢÀBÒSÍ ATI IṢẸ AṢEKARA HA NṢERANWỌ BI?
4 “Awọn, eniajan, tí nṣiṣẹ aṣekara, kii rí ẹ̀sàn, tí ó
bojumu gbà. Iwọ ha fohunṣọkan bi?” Ninu iwadii kan, ida 85 lori ọgọrun fohunṣọkan. Ô saba maa ndabi pe aṣeyọrisi rere sinmi lori iwa ìrẹjẹ, ole jíjà, owó ẹ̀hìn ati mímọ awọn eniyan tí wọn lésẹ̀. Sibẹ Iwe-mimọ tẹnumọ iniyelori àìṣàbòsí ati jíjẹ́ oṣiṣẹ alaapọn. Fun apẹẹrẹ, Bibeli sọ pe:“Ki ẹni tí njale maṣe jale mọ́; ṣugbọn, ki ô kuku maa ṣe laalaa, ki ô maa fì ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ ohan tí ó dara.” – Ephesus 4:28.
“Ohun-àrà, nwu ọlẹ eniyan, ṣugbọn kò rí nkankan gbà: oṣiṣẹ eniyan ní ànító awọn nkan. Iwọ rí ẹni tí ô nfi pẹlu aapọn, ṣiṣẹ rẹ̀? A o gbà á síṣẹ̀ lọdọ awọn ọba.—Owe 13:4; 22:29, Moffatt.
“Fi i ṣe gongo rẹ lati maa, gbé igbesi-aaye oniwajẹ̀jẹ̀, ki o gbájúmọ́ okòwò tirẹ, ki o sì ṣiṣẹ ohun, tí ìwọ yoo jẹ, gan-an gẹgẹ bi a ti sọ ọ fun ọ tẹlẹ. Lọna yii iwo yoo jéré ọ̀wọ̀ awọn wọnni tí wọn kii ṣe onigbagbọ, ki yoo sí idi kan fun ọ lati maa wojú ẹnikẹni fun ohun tí iwọ nilo.”—1 Thessalonica 4:11, 12, Good News Bible.
5 Akoko ati iriri tí ó pọ̀ tó ti fihan pe ìṣíníyẹ̀ yii wulo. Óò, otitọ ni pe ô dabi pe diẹ lara awọn òlẹ eniyan a maa ṣe aṣeyọri. Ṣugbọn niti gbogbogboo ô pẹ ni ô yá ni, bi ìwọ bá fi imọran Bibeli sílò iwọ yoo ṣe rere ju awọn wọnni tí wọn ṣalai kà á sí lọ.
6 Awọn agbanisiṣẹ saba maa nfi ẹjọ sùn pe awọn oṣiṣẹ maa npẹ dé ibi iṣẹ, wọn maa nfi ẹsẹ kúlẹ̀ kiri, wọn jẹ onidọti tí wọn kò sì ṣee gbẹkẹle. Nitori naa ẹnikan tí, ní titẹle imọran Bibeli, tí ó tẹ̀tẹ̀ ndé ibi iṣẹ, tí ô jẹ oniṣọra, ẹni tí ô ml, tí ô ṣee gbẹkẹle tí óô sì jẹ oṣiṣẹ alaapọn yoo saba maa rí iṣẹ ṣe. Ati pẹlu ô ṣeeṣe pe ki ô gba owó tí ó pọ̀ sii, nitori pe awọn agbanisiṣẹ saba maa nṣetan lati sanwo fun iṣẹ kan tí a ṣe daradara gan-an. Ọpọlọpọ awọn irohin ló nwá lati òdò awọn Ẹlẹrii Jehofah fun iru iṣẹlẹ bayii.
7 Ṣugbọn njẹ irẹ pípa ati ìrnijẹ kò ha fẹrẹẹ jẹ ohun tí ô di dandan lonii bi? Awọn Kristian tí, nitori fifi awọn ilana Bibeli sílò ti kọ lati jale, purọ́ tabi rẹ̀nijẹ ti ríi pe imọran Iwe-mimọ nṣiṣẹ.
Ile-iṣẹ kan ní Johannesburg, South Africa, tí nta ohun-elo iná manamana ni ọjà kò lọ deedee fun. Idi kan ni pe ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ni wọn njale. Ní ọjọ kan ọga ile-iṣẹ naa pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ọmọ ilẹ Africa papọ tí ô sì dá gbogbo wọn duro lẹnu iṣẹ. Nisinsinyi ní owurọ ọjọ keji oṣiṣẹ kan wà ninu ọkọ̀ oju-irin tí ó saba maa nwọ̀ lọ si ibi iṣẹ ô sì ṣe alabapade oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan. ’Bawo ni tirẹ ti jẹ́ tí ó fi nlọ sibi iṣẹ? ni oun beere. Oṣiṣẹ keji sì sọ pe ọga ile-iṣẹ naa ti sọ fun oun ní ìkẹòkò pe, niwọn bi oun ti jẹ aláìlábòsí, ọran ti oun yatọ si ti awọn yoku. Ọkunrin akọkọ naa sọ pe bakan naa ni ô rí pẹlu oun. Nigba tí wọn dé ibi iṣẹ wọn pade oṣiṣẹ kẹta tí a tún ti sọ fun ní ìkòkò pe ki ô wá sibi iṣẹ bii ti fere. Gbogbo wọn jẹ awọn Kristian tootọ.
Robert nṣiṣẹ fun ile-iṣẹ kan tí nṣe ọna ati afárá tí ó jẹ ti ilẹ Gẹẹsi. Ní ọjọ kan oludari kan sọ pe bi enikeni bá wá oun wá, wá Jin wá, ki Robert ṣalaye pe oun kò sí ní ile. Nisinsinyi nigba tí Robert dahun ikesini kan ó ṣalaye pe ọwọ oludari naa dí fun iṣẹ. Ní gbígbọ́ eyiini, oludari naa bá a wí. Ṣugbọn a fi ọran naa silẹ nibẹ nigba tí Robert ṣalaye pe gẹgẹ bi òkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofah oun kò lè purọ́. (Ephesus 4:25) Lẹhin igba naa, nigba tí ó tô akoko fun Robert lati ní ìgbéga lẹnu iṣẹ, ojúgbà rẹ̀ kan ọlọkanjuwa gbiyanju lati gbé iyemeji dide nipa àìṣàbòsí rẹ̀. Nisinsinyi oludari naa sọrọ jade ní gbígbẹ̀jà àìṣàbòsí Robert. Ô si gba ìgbéga lẹnu iṣẹ naa.
8 Njẹ àìṣàbòsí ha ṣeeṣe bi o bá wà lẹnu iṣẹ-òwò ti ara rẹ bi? Ninu ọran kan jíjé aláìlábòsí lẹ dabi ohun tí kò gbeṣẹ. Ṣugbọn sibẹ oun ṣì ni ipa-ọna tí ô dara julọ. Ó nràn ọ lọwọ lati ní ẹri-ọkan rere pẹlu Ọlọrun ati alaafia ọkàn. Siwaju sii, awọn ọpọlọpọ eniyan ni wọn yàn lati dà òwò pò pẹlu ẹnikan tí wọn ní imọlara pe kò ní rẹ́nijẹ. Gan-an gẹgẹ bi Bibeli ti ṣe ṣọ ọ ni ó rí— iwọ “yoo jẹ̀rẹ̀ òwò lati òdò awọn wọnni tí wọn kii ṣe onigbagbọ.”
IRANLỌWỌ PẸLU ỌRAN ILE GBÍGBÉ
9 Rírí ile tí ó bojumu tún jẹ iṣoro pataki kan.
Ní awọn ilẹ kan gbogbo idile ni a fi tipátipá mú lati maa gbé pọ̀ ní ìhágágá ninu yàrá kan. Tabi, iṣoro naa le jẹ lati rí ile gbígbé kan tí ó mọ́ tí ẹnikan yoo lé sanwo rẹ̀. Njẹ Bibeli ha lé ṣe iranlọwọ pẹlu awọn ọran-iṣoro wọnyi bi?10 Nigba tí iwọ bá háyà ile kan (tabi tí o gbà á fun ọjọ gbọọrọ), iwọ nlo dúkìá ẹlomiran. Ô jẹ ohun tí ô gba afiyesi pe Ọlọrun rọ awọn ọmọ Israel lati bọwọ fun ki wọn sì bojuto dúkìá awọn ẹlomiran. (Deuteronomy 29:1-4) Ò tún funni ní iṣiri fun iwa imọtoto ti ara. (Deuteronomy 23:12-14; Exodus 30:18-21) Bẹẹ gẹgẹ, awọn Kristian tí wọn ní ẹri-ọkan rere ngbiyanu lati yàgò fun bíba dúkìá jé tí wọn sì nmú ki ile eyikeyi tí wọn bá háyà wà ní mímọ tónítóní. Fun idi yii, ati nititori pe wọn ’ngbé igbesi-aye oniwa-jẹ́jẹ́,’ a mọriri wọn yika ibi gbogbo gẹgẹ bi awọn ayálégbé tí ôó sì ti rọrun fun wọn lati ri ile gbígbé.
Idile Kristian kan háyà ile kan lọwọ alakoso tẹlẹri kan ti olu-ilu Africa kan. Wọn mú ki ile naa wà ní mímọ tónítóní wọn sì sanwo wọn lakoko. (Rome 13:8) Nigba tí ó yá ti wọn fẹ lọ kuro nibẹ wọn fi onile naa han idile miiran kan lati inu ijọ. Onile naa sọ pe bi ó ti yẹ ki nkan rí owô ile naa ni a o gbé soke, eyi tí ó tumọsi sisọ ọ di ilọpo meji. Ṣugbọn nitori pe ô mọ̀ pe awọn Kristian wọnyi yoo jẹ awọn eniyan tí wọn ṣee gbarale, tí wọn mọ tónítóní, ô fi iye-owo ile naa silẹ ní bi ó ti ṣe wà tẹlẹri, tí ô jẹ nkan bii idaji ohun tí a dálé awọn ile iru eyiini tí wọn wà ní adugbo ibẹ.
11 Ani nigba tí awọn ayika-ipo nkan tí wọn rekọja ohun tí ẹnikan lè ṣakoso rẹ̀ bá ṣe idilọwọ funni lati maṣe jẹ ki a rí ile gbígbé tí ô sunwọn, èrè-anfaani ṣì wà nibẹ fun onitọhun. Oun yoo mú ki ile rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní tí yoo sì dùn ún wò loju. Eyiini mú ki igbesi-aye tí ô ní ilera pupọ sii, tí ô sì tubọ layọ sii ṣeeṣe.
LILO OWÔ RẸ LỌNA ỌGBỌN
12 Ọlọlà Ọba Solomon kọwe pe: Nitori pe aabo ni ọgbọn, ani bi owó ti jẹ aabo; ṣugbọn èrè imọ ni pe, ọgbọn fi ìyè fun awọn tí ô ní in.—Oniwaasu 7:12.
13 Solomon mọ̀, gẹgẹ bi ô ti yẹ ki awa naa mọ̀, pe owô pese igbeja lodisi awọn ìjọngbọn tí ipo òṣì lè mú wá. Nitori naa a kò gbọdọ fi owô ṣòfò; a gbọdọ fi ọgbọn ṣakoso rẹ̀. Imọran ṣiṣeemulo wo ni Bibeli fi funni lori bi a ṣe lè bojuto owô wa?
14 Jesu beere pe: Nitori tani ninu yìn tí npete. a ti kọ ìlé-ìṣẹ, tí kii yoo kọ jokoo ki ô ṣiro iye-owo rẹ̀, bi oun ní tó tí yoo fi pari rẹ̀. Ki ó má baa jẹ pe nigba tí ô bá fi ipilẹ ile sọlẹ tán, tí kò ní lè pari rẹ̀ mọ́, gbogbo awọn tí ó ríi a bẹrẹsi fi ṣẹlẹya.—Luke 14:28-30.
15 Ẹiyiini ni a lè lò niti awọn inawo idile. Ọpọlọpọ awọn ’tọkọtaya ni wọn ti ríi pe ôó dara lati jokoo ki wọn sì fi pẹlu suuru ṣiro inawo kan lati ríi boya ohun pataki tí wọn fẹ́ rà jẹ ohun tí ô ṣeeṣe tí ô sì bọgbọnmu. A ti tún ṣe iranlọwọ fun wọn sii nipasẹ irannileti Bibeli pe awọn iṣẹlẹ airotẹlẹ maa nṣẹlẹ. (Oniwaasu 9:11) Eyi ti ràn wọn lọwọ lati yẹra fun ríra nkan laironu jinlẹ tó ati kíkô sinu gbèsè ọlọjọ-gbọọrọ.
16 Pẹlupẹlu, ṣakiyesi ọrọ oloye yii: Ajigbese jẹ ẹrú fun onigbese. (Owe 22:7, Revised Standard Version) Nigba tí ó jẹ pe Bibeli kò ṣe ikaleewọ fun yíyá owó tabi yíyánilówó, ó ta wa lôlobô pe yíyá owô lainidii lè, ní itumọ kan naa, sọ ẹnikan di ẹrú fun ile ifowopamọ tabi onigbese kan. Ọlọgbọn ni ẹni naa tí ô ranti pe ní awọn ọjọ wọnyi awọn ọpọ eniyan ni a ntanjẹ lati ra nkan ní àwìn, kiki pe ki wọn pari rẹ̀ si didi ajigbese, tí wọn sì nsan èlé owô giga.
17 Bibeli ti ṣe iranlọwọ fun awọn ọpọlọpọ idile latimú ki awọn ọran-iṣoro owô wọn dinku nipasẹ dídín ohun tí a fi ṣofo kù. Jesu fi apẹẹrẹ rere kan lelẹ. John 6:10-13) Ní titẹle iru apẹẹrẹ bi eyiini, awọn Kristian ní tewe-tagba lè tubọ maa ṣọra sii nipa yiyẹra fun fifi nkan ṣofo.
Lẹhin tí ó ti pese ounjẹ fun ọpọ eniyan nla kan tán, ô sọ pe ki a kó awọn eyi tí ô ṣẹku jọ. (18 Kíkọ́ lati fi imọran Bibeli sílò nipa owó lè beere fun iyipada tí ó tobi kan nipa oju-iwoye, ṣugbọn awọn abajade rẹ̀ yoo léré ninu, gẹgẹ bi ohun tí ó tẹle e yii ti ṣàkàwé rẹ̀:
Kete lẹhin igbeyawo, ọdọ tọkọtaya kan ní Zimbabwe bẹrẹsi ní awọn ọran-iṣoro nipa owô. Owó tí ọkọ ngbà kò tó nkan; tí iyawo sì nfẹ́ awọn nkan titun pupọ ati awọn ounjẹ pataki kan. Iyawo naa pẹlu bẹrẹsi ṣiṣẹ, ṣugbọn eyiini kò dabi ohun tí ô ṣe iranlọwọ pupọ kan. Inira tí ô wà ninu igbeyawo wọn naa ga pupọ tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí ô fi dabi pe àfàìmọ̀ ni wọn fi lè maa bá a niṣo lati maa jùmò wà papọ. Luke 14: 28-30) Tọkọtaya naa rí ìwúlò ti ṣiṣe imurasilẹ itolẹsẹẹsẹ awọn nkan tí wọn fẹ́ rà ní ọjà pẹlu iye owó tí ô yẹ ki wọn náni ati ti rira awọn ounjẹ tí wọn nilo lọpọ fun ọsẹ kan lọna tí ó ndín inawo kù. (Owe 31:14) Awọn alagba naa ṣe ajọpin ìṣíníyé Iwe-mimọ pẹlu wọn nipa itẹlọrun ati aini naa lati yẹra fun fífé awọn nkan faaji tí apá kò tíì ká nisinsinyi. (Luke 12:22-31) Ẹ; wo iru iranlọwọ nlánlà tí imọran Iwe-mimọ yii jẹ́! N ìwọn igba tí ọran wọn ti yanju nipa owó, tọkọtaya naa tubọ layọ sii. Ani awọn aladugbo tilẹ sọrọ-ìyìn nipa ilọsiwaju tí ó wà hinu igbeyawo wọn.
Awọn Kristian alagba diẹ nawọ iranlọwọ si Wọn. Ní lilo Bibeli, wọn jiroro ijẹpataki níní eto inawo kan. (19 Awọn wọnni tí owó tí nwọle fun wọn jẹ iye kan ní pato pẹlu ti janfaani lati inu imọran Bibeli tí ô gbeṣẹ. Eyi rí bẹẹ niti ọran tọkọtaya kan tí wọn ti fẹhinti lẹnu iṣẹ ní Spain:
Owó tí nwọle fun Francisco ati Maria kò tilẹ tô ni. Sibẹ wọn ṣalaye pe yọ̀tọ̀mì ni awọn wà nipa fifi ohun tí wọn ti kẹkọọ rẹ̀ ninu Iwe-mimọ sílò. Fun apẹẹrẹ, Owe 6:6-8 sọ pe: ‘Tọ ẹ̀érà lọ, iwọ ẹlẹ. Kiyesi iṣẹ rẹ̀, ki ìwọ ki ó sì gbọ́n. Tí kò ní onidaajọ, alaboojuto, tabi alakoso, tí npese ounjẹ rẹ̀ ní igba ẹruùn, tí ó sì nkô ounjẹ rẹ̀ jọ ní igba ikore.’ Maria sọ pe oun kọ́ lati ṣe eyi, ní rira awọn nkan nigba tí wọn wà larọwọto daradara tí wọn kò sì wọ́nwó, iru bii eso ní akoko síso wọn. Ô tún maa nduro fun gbànjo ki ó tó ra aṣọ fun ti ọdun tí nbẹ. Wọn ‘npese ounjẹ wọn ní igba ẹrun’ nipa dídá oko lori ilẹ kekere kan tí kò jinna ju ìrìn 45 iṣẹju lọ si ile iwọ. Awọn ọrọ 1 John 2:16 tún ṣeranwọ. Wọn ti kẹkọọ lati ní itẹlọrun pẹlu awọn ohun-elo ẹ̀ṣọ inu ile ani bi ó tilẹ jẹ pe wọn kò bá igba mu mọ́. Dipo eré-ìnàjú olowo gọbọi, wọn ngbadun riran awọn ẹlomiran lọwọ lati kẹkọọ nipa Ọlọrun.
YẸRA FUN ṢIṢE IPALARA FUN ÀSÙNWỌ̀N RẸ
20 Fifi awọn nkan bii aṣilo oògùn ati ọti lile kéra, mímu tábà ati tẹ̀tẹ́ títa lè fa àsùnwòn rẹ gbẹ. Bibeli tún ṣe iranlọwọ ní awọn adugbo wọnyi, pẹlu. *
21 Ronu nipa ọti lile. Bibeli kò dẹbi fun lilo awọn ọti lile ní iwọntunwọnsi. Ṣugbọn ó funni ní ìmọran pe:
“Awọn olufẹ faaji yoo maa wà ní ipo aini, ẹni naa tí ô fẹran ọti waini ati igbesi-aye onifaaji ki yoo di ọlọrọ.”
“Maṣe jẹ ọ̀kan lara awọn wọnni tí wọn nfi gbogbo igba yó fun ọti waini. . . nitori pe ọmuti ati alájẹkì yoo sọ ara wọn di otoṣi, alásùn-ì-sùn-tán, yoo sì di alakisa.—Owe 21:17; 23:20, 21, Jerusalerm Bible.
22 Ọti amupara nṣe ipalara fun àsùnwọ̀n naa ní awọn oriṣiriṣi ọna. Awọn ọti lile niti wọn gbé owô giga pupọ lori, tí awọn eniyan kan sì nná eyi tí ó tô idaji iye owô tí wọn ngbà lọsẹ kan lori ọti. Ní ẹkùn-ipinlẹ Quebec nikan ní Canada iye tí ó ju billion kan dollar ni a nná lori ọti lọdun kan. Billion kan miiran nbá awọn nkan tí wọn sopọ mọ́ ọti amupara lọ—pípa ibi iṣẹ jẹ ati awọn ijamba tí ó niiṣe pẹlu ọti lile.
Ní iha guusu Chile olupolowo bata kan padanu iṣẹ rẹ̀ nitori ọti àmujù. Ò wá bẹrẹsi gbiyanju lẹhin naa lati maa tún bata ṣe labẹ búkà kan lẹba àwóòkù ile tí idile naa háyà. Sibẹ, eyi tí ó pọ̀ julọ ninu owó rẹ̀ ló nbá ọti lọ tí iyawo rẹ̀ lọpọ igba sì nilati maa lọ gbà á silẹ kuro ní ọgba-ẹwọn. Obinrin naa pẹlu sì nilati ṣiṣẹ di ọganjọ oru ní ṣiṣe awọn ìbòrí onirun ki wọn baa lè rí owô ounjẹ. Ṣugbọn obinrin naa bẹrẹsi kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofah, eyi tí ó
mú ki ô tubọ di iyawo kan tí ô nṣe itilẹhin funni tí ó sì tún loye sii. Eyi sún ọkọ rẹ̀ lati bá wọn lọwọ ninu ikẹkọọ naa. Ò kẹkọọ pe ẹnikan kò lè jẹ ọmuti ki ô sì tún jẹ Kristian rere kan, nitori naa ô ṣiwọ ọti mímu. Idile naa wá lè bẹrẹsi jẹun daradara sii lẹhin naa. Nigba tí ô ṣe wọn tilẹ lè ra ile kekere kan ati ile-itaja kan nibi tí ó ti nṣe iṣẹ-òwò ṣiṣe atunṣe bata.23Kinni nipa tẹ́tẹ́ títa, yala eyi tí a ta nibi tí awọn ẹṣin ti nsare ije tabi ti kàlòkàlò tabi tẹtẹ́ títa ní gbogbo igba nipasẹ awọn iwe onítẹ́tẹ́? Ọpọlọpọ awọn eniyan nní ọran-iṣoro owó nitori itẹsihuwa airotẹlẹ lati ta tẹ́tẹ́. Wọn nbá a niṣo lati maa reti pe wọn yoo “jẹ èrè nla” kan, ṣugbọn ohun tí wọn nṣe niti gidi gan-an ni pe wọn nkô owó wọn dànù, tí eyi sì nmú inira nlánlà wá nigba pupọ fun idile wọn.
24 Ọkunrin ara Australia kan sọ pe fun awọn ọdun pupọ tẹ̀tẹ́ títa ti jẹ ohun ti ngbanilọkan patapata. Mo nta tẹ̀tẹ́ fun ọjọ meje laarin ọsẹ, eyi ìbá ti jù bẹẹ lọ kání awọn ọjọ ṣì ṣékù ni. Ô yá owô lọwọ awọn ọ̀rẹ́ titi ó fi di igba tí wọn nyẹra fun un. Ní awọn igba miiran lẹhin ti mo ti padanu tán emi yoo la ori mọ ogiri tí emi yoo sì maa jírẹ̀bẹ̀ fun iyawo mi, ’Sá ti fun mi ní ṣílẹ marun péré. Mo mọ̀ pe emi yoo jẹ.’”
25 Nigba tí ô bẹrẹsi kẹkọọ Bibeli, imọran Jesu wò lọkan ṣinṣin pe: Kiyesara ki ẹ si maa ṣọra nitori ojukokoro. (Luke 12:15; 1 Corinth 6:9, 10) Ní pipari ero si pe iwa tẹtẹ títa rẹ̀ fi ojukokoro tí ô galọla hàn, ọkunrin yii fi ipá mú ara rẹ̀ lati fi i silẹ. Nipa bẹẹ ô lè lo owó tí ô ngbà nigba naa lati fi ṣanfaani fun idile rẹ̀, oun lè tubọ mọriri owe naa síi pe: Ọlà tí a kojọ nipasẹ ìpéte rìkíṣí [“ọlà lati inu tẹ̀té títa,” Living Bible] yoo joro; ṣugbọn ẹni tí nṣakojọpọ nipasẹ ení tere ẹ̀jì tere yoo ní ibisi ninu ile iṣura rẹ̀.—Owe 13:11, An American Translation.
NÍNÍ ITẸLỌRUN JẸ́ KỌKỌRỌ KAN
26 Niti ọran owô, adugbo kan nibi tí Bibeli ti lè pese awọn iranlọwọ titobi julọ niiṣe pẹlu oju-iwoye ti ara-ẹni. Ní 1 Timothy 6:7-10 a kà pe:
“Kinni ohun tí a mu wá si ayé? Kò sí ohun kankan! Kinni ohun tí a lè mú kuro ninu ayé naa? Kò
si ohun kankan! Fan idi yii nigba naa, bi a bá ní ounjẹ ati aṣọ, ô yẹ ki eyiini naa, tó fun wa. Ṣugbọn awọn tí nfé lati di ọlọrọ a maa bọ́ simu idẹwo tí a sì maa nmú wọn ninu tàkúté ọpọlọpọ nkan tí a nfẹ́ tí kò bọgbọnmu tí ô sì npamilara. . . . Ọran níní [owó] ti wọ̀ awọn kan lọkan tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí wọn ti ṣáko lọ kuro ninu, igbagbọ tí wọn sì ti fọ́ ọkàn-àyà wọn pẹlu ọpọ ìkárísọ.”—Good News Bible.27 Yala wọn jẹ ọlọrọ tabi akúṣẹ̀é, awọn wọnni tí wọn nifẹẹ owó kii ní itẹlọrun lae. Ọga ile-iṣẹ awaṣẹ́máyà kan ní California sọ fun iyawo rẹ̀ pe: Mo fẹ lati di ọlọrọ . . . bi ô bá sì di ọran pe ki emi mú ẹ̀kan ninu iwọ ati lile-iṣẹ naal, iwọ yoo padanu. Oun di olori ile-iṣẹ nla kan, tí owó rẹ̀ nlọ si bii araadọta ọkẹ dollar ní ile ifowopamọ, ô si ngbé ninu ile kan tí owô rẹ̀ tú $700,000. Sibẹ oun sọ pe: “Ohunkohun yowu tí mo ní, kò tó.” Otitọ tí ó wà nibẹ ni pe owó kò mú ayọ daniloju. Ọdun meji ṣaaju ki ô tô kú elépo rẹ̀bì alaadọta ọkẹ aimoye dollar J. P. Getty sọ pe: Owô kò fi dandan ní isopọ kan pẹlu ayò, àfàìmò ki ô má jẹ pẹlu ailayọ ni.
28 Bibeli, niwọn bi kò ti dẹbi fun níní owô tabi ohun-ìní, fi tagbara-tagbara kilọ lodisi mímú ifẹ dagba fun wọn. Ò rán wa leti pe iwalaaye kò wá lati inu ohun tí a ni.—Luke 12:16-20.
29 Nitori naa kaka tí iwọ ìbá fi aniyan kún igbesi-aye rẹ nipa lilepa ọlà, ní itẹlọrun pẹlu ohun tí o ní tabi tí ọwó rẹ lè tẹ̀ pẹlu ilọgbọn-ninu. Awọn ọrọ Jesu ní Luke 12:22-31 lè ràn wa lọwọ lati ní oju-iwoye naa:
“Ẹ maṣe ṣaniyan nitori ẹmi yin pe, kinni ẹyìn yoo jẹ; tabi nitori ara yin pe, kinni ẹyìn yoo fi bora. Ẹmi sá ju ounjẹ lọ, ara si ju aṣọ lọ. Ẹ kiyesi awbọn ìwò; wọn kii funrugbin, bẹẹ ni wọn kii kore; wọn kii ní àká, bẹẹ ni wọn kò ní abà; Ọlọrun sáà mbọ́ wọn:
melomelo ni ẹyìn sàn ju ẹyẹ lọ? . . . . [Ẹ jáwọ́ ninu wíwá ohun tí ẹ lè jẹ ati ohun tí ẹ lè mu kiri], ki ẹyin ki ô má, sì ṣiyemeji. Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn, orilẹ-ede ayé nwá kiri. Baba yin si mọ̀ pe, ẹ kò lè ṣalaini nkan wọnyi.”30 Apoti aṣọ olowo iyebiye kan, ounjẹ olowo gọbọi ati ile aláfẹ́ kan lè funni ní faaji, ṣugbọn wọn ki yoo fi ọdun kan kún igbesi-aye rẹ—wọn lè dín awọn ọdun kù ninu rẹ̀. Sibẹ o lè rí ayò pupọ ninu igbesi-aye laini ọrọ.
31 Bẹẹ ni kò di igba tí ô bá ní ọrọ ki o tó lè ní awọn ọ̀rẹ̀. Ẹnikẹni tí ô bá gbéjúlé owó rẹ̀ lati fi fa awọn ọ̀rẹ́ mọra nṣe aṣiṣe kan. Awọn ọ̀rẹ bẹẹ njẹ ounjẹ rẹ wọn sì nṣe ajọpin awọn ohun-ìní rẹ, ṣugbọn nigba tí owô rẹ bá tán bẹẹ naa ni awọn naa yoo ṣe tán.—Oniwaasu 5:11; Owe 19:6.
32 Ṣugbọn nigba tí o bá tẹwọgba oju-iwoye oniwọntunwọnsi Bibeli nipa iṣẹ, yíyò ninu igbesi-aye ati ṣiṣe awọn nkan rere fun awọn ẹlomiran, iwọ yoo ní ẹbun Ọlọrun. Gẹgẹ bi Oniwaasu 3:12, 13 ti sọ ọ: Kò sí rere ninu wọn, bikoṣe ki eniyan ki ô maa yò, ki ô maa ṣe rere nigba ayé rẹ̀. Ati pẹlu ki olukuluku eniyan ki ô maa jẹ, ki ô sì maa mu, ki ô si maa jadùn gbogbo laalaa rẹ̀, ẹbun Ọlọrun ni.
33 Imọran Ọlọrun lori awọn ọran wọnyi lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí ô fi jẹ pe ẹnikan lè ṣe kayefi daradara pe: Njẹ Ọlọrun ní ọjọ kan yoo ha mú opin patapata débá ipo òṣì, àìrí ounjẹ tí ô dara tó jẹ ati ile gbígbé tí kò dara, tí ó jẹ pe nigba pupọ julọ ni wọn maa nniiṣe pẹlu awọn ọran-iṣoro owô? Oun yoo ṣe bẹẹ! Ati pe nikẹhin awa yoo ṣe ayẹwo ami-ẹri tí npese ipilẹ fun iru ìdálójú-igbagbọ bẹẹ. Ṣugbọn, lakọkọ ná, ẹ jẹ ki a wo awọn ọran-iṣoro diẹ miiran tí wọn nní ipa titobi gan-an lori igbesi-aye awọn eniyan nisinsinyi.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 20 Tún wo ori-iwe 10, “Ilera Sisunwọn ati Iwalaaye Gígùn—Bawo?”
[Koko Fun Ijiroro]
Eeeṣe tí aini fun iranlọwọ ṣe wà nipa owó? (1-3)
Oju-iwoye nipa iṣẹ tí ô yatọ tí ó sì gbeṣẹ wo ni Bibeli funni? (Oniwaasu 8:12, 13) (4-6)
Iniyelori wo ni àìṣàbòsí ní? (Rome 2:14, 15) (7, 8)
Bawo ni fifi Bibeli sílò ṣe lè ṣeranwọ pẹlu ọran ile gbígbé? (9-11)
Kinni imọran tí ô gbeṣẹ tí ô wà nipa owó? (12-16)
Bawo ni awọn eniyan ti ṣe fi ìṣíníyè Bibeli sí ìlò lọna rere tó? (17-19)
Eeṣe tí imọran Bibeli nipa ọti mímu fi nṣeranwọ? (20-22)
Bawo nì tẹtẹ títa ṣe dákún awọn ọran-iṣoro? (23-25)
Eeṣe tí ìṣíníyẹ Bibeli lori itẹlọrun fi wulo? (26, 27)
Imọran tí ó jiná dénú wo ni Jesu funni nipa ọlà? (28-30)
Bawo ni imọran Iwe-mimọ ṣe lè ràn ọ lọwọ lati ní igbesi-aye tí ó tubọ lọràá ninu? (31-33)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 53]
OBINRIN ONIṢOWO ARA SOUTH AMERICA KAN
Ní Georgetown, Guyana, Norma ẹni 48 ọdun ní awọn ìsọ̀ ọjà kan nibi tí ô ti nta awọn irè oko ní ọ̀kan ninu awọn ọjà titobi julọ. Oun maa nrẹ̀nijẹ nigba ti oô bá ndiwọn nkan pẹlu oṣuwọn rẹ̀. Bi ẹnikan bá beere fun ìwọ̀n ẹja oniyọ 4 ounces, ô maa nfi oṣuwọn naa sori 3, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Pẹlupẹlu, awọn ìwọ̀n onirin fun awọn oṣuwọn naa kuru. Fun idi yii, awọn onibaara rẹ̀ kò gba ohun tí ô jẹ̀ ẹ̀kún ohun tí ô tọ si wọn rí lae.
Ní ọjọ Sunday kan ni mọlẹbí rẹ̀ kan fun un ní ẹ̀dà “Ilé-ìṣọnà” tí ò jiroro awọn ilana Bibeli nipa iṣowo. Ohun tí ó sọ nipa awọn iṣe-aṣa àbòsí dabi pe oun gan-an ni a doju ọrọ naa kọ. (Owe 20:23; Leviticus 19:35, 36) Ní Monday Norma kò awọn oṣuwọn eke rẹ̀ dànù tí o si lọ ra awọn ti wọn ṣedeedee. Ó bẹrẹsi lọ si awọn ipade ní Gbọngan Ijọba awọn Ẹlẹrii Jehofah, Ô tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli. Laika ifiniṣẹ̀sín awọn ara ile rẹ̀ sí, òô tubọ nní ìdálòju-igbagbọ siwaju sii pe ohun ti o tọna ni oun nṣe.
Bawo ni nkan ti rí fun un niti iṣẹ-òwò rẹ̀? Kò lè jèrè lori awọn ọjà kan laifi ìrẹjẹ kún un, nitori naa oô nilati pa awọn wọnni tì sapakan. Ṣugbọn pẹlu awọn ọjà yoku awọn onibaara rí iyipada kan tí wọn sì sọrọ-akiyesi pe, ‘Lati igba ti iwọ ti di Kristian kan o nfun wa ní ohun pupọ sii fun iye-owo wa.’ Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, òwò rẹ̀ niti gasikia gbèrú siwaju sii ni. Ní jijẹ èrè aláìlàbòsí, Norma ní agbara-iṣe lati san gbèsè tí ò wà lori ile rẹ̀ tí ô sì fi owô diẹ sí ile ifowopamọ tí ô sì nṣe itọrẹ oninuure fun awọn eniyan alaini. Ati pe ilera rẹ̀ ti dara siwaju sii, nitori pe kò tún sí ẹ̀fọrí tí ô ti maa nní tẹlẹ nigba tí ô bá wà ninu ibẹru pe ki ọwọ maṣe tẹ oun nibi ti oun ti nṣe ìrẹ̀jẹ.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 59]
“Ipindọgba ida 87 ninu ọgọrun awọn ara Australia ni wọn ti ní ipa ninu iru tẹ̀tẹ̀ tita kan ní awọn oṣu mẹta tí o kọja.”—“The Sunday Mail” (Brisbane).
“Ó Tẹ̀ Wa Lọrùn Lati Ta Tẹ̀tẹ̀ ju Ki A Jẹun Lọ! Awọn olugbe Queensland nná iye tí a ṣiro sí $12 million lọsẹ kan lori tẹ̀tẹ tita—ò fẹrẹẹ tò iye tí wọn nná lori awọn ohun ìpápánu ati ẹran.”—“The Sunday Mail” (Brisbane).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 57]
Imọran Bibeli ti ṣeranwọ fun eto inawo idile
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 60]
Bawo ni awọn ilana-ipilẹ Bibeli ṣe gbeṣẹ tó nipa imutipara, mímu tábà ati tẹ́tẹ́ títa?