Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ofin Tani Iwọ Yoo Fi Ṣaaju?

Awọn Ofin Tani Iwọ Yoo Fi Ṣaaju?

Ori 17

Awọn Ofin Tani Iwọ Yoo Fi Ṣaaju?

AWA ngbé pẹlu ofin—awọn ofin adanida, tabi iṣẹda, awọn ofin lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun lori awọn ọna-iwahihu ati iwa, awọn ofin ayé. A maa nfi pẹlu irọrun tẹwọgba, a sì njere anfaani lati inu pupọ ninu awọn wọnyi. Ṣugbọn bi ó bá dabi ẹnipe ofin kan kún fun ikanilọwọko laiyẹ nkọ́? Tabi bi iforigbari bá wà laarin awọn ofin meji tí ó ní ipa lori rẹ?

2 Niwọn bi awọn ofin adanida ti farahan gidigidi bi eyi tí kii ṣe ti ẹnikẹni, awọn eniyan kan ní awọn ọran-iṣoro ní titẹwọgba wọn. Tani jẹ́ tẹmbẹlu ofin òòfà-mọ́lẹ̀ nipa fífò silẹ lati ori oke giga olokuta kan? Ofin yẹn sì nṣanfaani fun wa; ó ndi awọn ẹsẹ wa mú mọ́lẹ̀ ati ounjẹ tí ó wà ninu àwo wa. Awọn ofin adanida miiran kan atare iwa ninu ibimọ, eyi tí ó ní ipa lori bi awọn ọmọ wa yoo ti rí. Nipa wíwà lojufo si awọn atare iwa ninu ibimọ ati ṣiṣai gbé ibatan tí ó sunmọni niyawo, awa yoo yẹ awọn ewu tita atare awọn abuku ara fun awọn ọmọ wa silẹ. (Fiwe Leviticus 18:6-17.) Ṣugbọn nipa ti awọn ofin lori iwa ati ọna-iwahihu nkọ?

3 Ọpọlọpọ eniyan ló nmú ibinu dagba fun awọn ofin tí a ṣe. Idi kan ni pe awọn eniyan ti ní itẹsi lati ṣe awọn ofin tí kò wulo ati lati tẹ awọn miiran lóríba nipasẹ awọn ofìn. (Matthew 15:2; 23:4) Bio ti wu ki o ri, ewu wà ninu níní oju-iwoye pe gbogbo ofin ló buru tabi ninu sisọ ọ di iṣe-aṣa lati ṣaika wọn si.

4 Ipo kíkú tí araye wà ni a lè tọpasẹ rẹ̀ titi kan iṣọtẹ lodisi ofin. Ọlọrun kà á leewọ fun Adam ati Efa lati maṣe jẹ ninu igi imọ rere ati buburu. Ṣugbọn Satan damọran rẹ̀ fun Efa pe ofin Ọlọrun wulẹ nkanilọwọko laiyẹ ni. (Genesis 3:1-6) Ìdẹlọ Satan ni pe—’Kò sí ofin-idiwọn. Gbé awọn ọpa-idiwọn tirẹ kalẹ̀.’ Ẹmi iṣodi-sofin naa ti lokiki la gbogbo ọrọ-itan já, ani titi di oni-oloni.

5 Jehofah kò tẹ awọn eniyan rẹ̀ lóríba pẹlu ikalọwọko tabi awọn ofin inira tí kò wulo, nitori “nibi tí Ẹmi (Jehofah) bá sì wà, nibẹ ni ominira gbé wà’’ (2 Corinth 3:17; James 1:25) Sibẹ, ní ilodisi ohun tí Satan nfẹ ki awọn eniyan gbagbọ, Jehofah ni Alakoso Ọba Alaṣẹ Agbaye. Oun ni Ẹlẹdaa rẹ̀ tí ó sì tún jẹ Olufunni ní ìyè ati olupese wa. (Iṣe 4:24; 14:15-17) Nitori naa oun ní ẹ̀tọ́ lati dari wa ki ó sì ṣe awọn ofin niti iwa wa.

6 Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn gbà pe, gẹgẹ bi alaṣẹ patapata, Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ lati paṣẹ awọn ohun tí ẹda eniyan lè ṣe ati eyi tí wọn kò lè ṣe. Eyiini ni pe, wọn fohunṣọkan titi di igba tí wọn bá fi tagbara-tagbara fẹ lati ṣe ohun kan tí Ọlọrun kaleewọ. Dajudaju, eyiini lewu. Ọgọọrọ awọn ẹri ló wà pe awọn aṣẹ-ofìn Ọlọrun jẹ fun ire wa. Fun apẹẹrẹ, yiyẹra fun imutipara, ibinu ati ojukokoro yoo ràn wa lọwọ lati gbadun ilera tí ó sàn jù ati lati ní itẹlọrun pupọ sii. (Psalm 119:1-9, 105) Ati pẹlu, awọn ofin Ọlọrun lè ràn wa lọwọ lati jere itẹwọgba rẹ̀ ati igbala. (Owe 21:30, 31) Nitori naa bi awọn eniyan kò bá tilẹ tíì loye idi tí ó wà lẹhin awọn aṣẹ-ofin Jehofah kan paapaa, fun wọn lati kọ̀ lati ṣegbọran, boya nitori ominira onigberaga, jẹ iwa omugọ.

7 Apẹẹrẹ kan ti awọn aṣẹ-ofin Ọlọrun fun awọn Kristian ni aṣẹ kan tí a gbé jade nipasẹ igbimọ awọn apostle ati awọn agba ọkunrin ní Jerusalem, awọn tí wọn parapọ di ẹgbẹ alakoso ìjọ Kristian ijimiji:

“Nitori ó dara loju ẹmi mímọ́, ati loju wa, ki a maṣe di ẹrù kà yin, ju ohun tí a kò lè ṣe alaiṣe wọnyi lọ. Ki ẹyin ki ó fasẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹjẹ ati ninu ohun ilọlọrunpa ati kuro ninu agbere.”—Iṣe 15:22-29.

8 Awa ní awọn idi tí ó yekooro lati ṣegbọran si ofin Ọlọrun lori “agbere” —aabo kuro lọwọ arun, ọmọ-àlè, igbeyawo tí ó wolulẹ. Ofin yẹn tumọsi pe awọn eniyan kò ní maa lọwọ ninu bíbá ẹya kan naa lopọ tabi awọn iwa-pálapàla ti ibalopọ takọtabo miiran, gbogbo eyi tí ede Greek naa porneia (agbere) tí a lò ninu Iṣe 15:29 kó papọ. (Rome 1:24-27, 32) Ṣugbọn bi a bá lè yẹra fun awọn ewu, “agbere” nkọ? Awa yoo ha ṣegbọran si aṣẹ Ọlọrun nitori pe oun ni Alakoso Ọba Alaṣẹ wa sibẹ bi? Bi a bá ṣe bẹẹ, a nṣeranwọ ní fifihan pe Satan jẹ eleke, pe awọn ẹda-eniyan yoo ṣegbọran si Jehofah nitori pe wọn nifẹẹ rẹ̀.—Job 2:3-5; 27:5; Psalm 26:1,11

9 Aṣẹ-ofìn naa tí a gbé jade ninu Iṣe 15:22-29 fi apá ibomiran hanni nibi tí a ti lè fi igbọran wa hàn. Ò jẹ aṣẹ Ọlọrun lati ’fasẹhin-takete kuro ninu ẹjẹ’ ati kuro ninu ẹran ẹranko tí a lọ lọrunpa lati lè jẹ ki ẹjẹ wà ninu wọn. Ọlọrun sọ fun babanla wa Noah pe awọn ẹda-eniyan lè jẹ ara ẹranko, ṣugbọn wọn kò gbọdọ mú iwalaaye tiwọn duro nipa ẹjẹ ẹda miiran. (Genesis 9:3-6) Nigba tí ó nsọ asọtunsọ ofin yii fun awọn ọmọ Israel, Ọlọrun sọ pe “Ọkàn tabi, iwalaaye ẹran naa wà ninu ẹjẹ.” Ọna kanṣoṣo tí wọn yoo fì maa lo ẹjẹ ni lori pẹpẹ lati ṣetutu fun ẹṣẹ. Lọna miiran, ẹjẹ lati ara ẹda miiran wá ni a nilati dà jade silẹ, ní dídá a pada fun Ọlọrun lọna iṣapẹẹrẹ. Ṣiṣegbọran si ofin yii tumọsi ìyè tabi iku.—Leviticus 17:10-14.

10 Awọn irubọ wọnni ṣapẹẹrẹ itujade ẹjẹ Jesu fun ire wa. (Ephesus 1:7; Iṣipaya 1:5; Hebrew 9:12, 23-28) Ani lẹhin tí Kristi ti pada sí ọrun, Ọlọrun pa á laṣẹ fun awọn Kristian lati “fasẹhin-takete kuro ninu ẹjẹ.” Ṣugbọn awọn eniyan melo ninu awọn tí wọn jẹwọ pe Kristian ni awọn ló nṣegbọran si Olofin ati Olufunni ní ìyé Atọrunwa naa ninu ọran yii? Ní awọn ibikan ó wọpọ pe ki awọn eniyan fì ẹran tí a kò dúmbú rẹ̀, akara ẹlẹjẹ tabi ounjẹ miiran tí a mọ̀-ọ́n-mọ̀ jẹ ki ẹjẹ wà ninu rẹ̀ sinu ounjẹ wọn.

11 Bakan naa, ọpọlọpọ eniyan ni wọn ti gbẹjẹsara ninu isapa lati pẹ́ láyé. Nigba gbogbo wọn kii mọ̀ pe awọn igbẹjẹsara funraawọn nmú ifiwewu ilera lilekoko wá ati pe niti gidi oriṣi iṣẹ-abẹ eyikeyi ni a lè ṣe laisi ẹjẹ nipa lilo oriṣi ọna iṣegun miiran. * Ṣugbọn bi ó tilẹ dabi ẹnipe iwalaaye wà ninu ewu, yoo ha jẹ aṣiṣe lati ṣe igbọran si Ọlọrun bi? A kò gbọdọ pa ofin atọrunwa tì sapakan ani loju ipo pajawiri eyikeyi.—1 Samuel 14:31-35.

12 Ní didi igbagbọ wọn mú ninu ominira ọrọ-sisọ tabi ti ijọsin, tabi ninu ero-rere niti iṣelu, ọpọlọpọ eniyan ti foríla ewu iku. Wọn ti ṣegbọran si alakoso kan tabi apàṣẹ ologun kan laika iru ewu tí ó lè ní ninu sí. Awa kò ha ní awọn ìdi alagbara julọ fun ṣiṣe igbọran sí Ọba Alaṣẹ agbaye? ’Patapata porogodo,’ ni idahun akọsilẹ iwa-títọ tí ọpọlọpọ awọn ẹni-igbagbọ fi lelẹ. (Daniel 3:8-18; Hebrew 11:35-38) Wọn mọ̀, bi awa naa ti nilati mọ̀, pe Jehofah ni Olufunni ní ìyè ati pe yoo ranti yoo sì san èrè fun awọn wọnni tí wọn ṣegbọran sii—bi ó bá pọndandan ki ó mú wọn padabọsipo si ìyè nipasẹ ajinde nigba tí akoko rẹ̀ bá tó. (Hebrew 5:9; 6:10; John 11:25) Awa lè ní idaniloju pe, labẹ ipokipo, ṣiṣe igbọran si Jehofah ni ipa-ọna títọ́ tí ó sì dara pẹtiti julọ.—Mark 8:35.

ṢEGBỌRAN SI AWỌN OFIN ALAKOSO KẸ̀?

13 Ọpọ awọn ofin miiran tí wọn kàn wa lojoojumọ nwá lati ọ̀dọ̀ awọn alakoso ayé. Bawo ni Kristian ṣe nilati wò ki ó sì huwapada si awọn ofin wọnyi? Apostle Paul kọwe pe: “Rán awọn eniyan leti lati jẹ ọmọ-abẹ olootọ si awọn alakoso ati awọn oniṣẹ-ọba, lati maa ṣegbọran sí awọn ofin.”—Titus 3:1, The Neto American Bible.

14 Ní ọrundun kìn-ín-ní C.E., ijọba-akoso Rome kii fi igba gbogbo ṣe idajọ-ododo, awọn kan ninu awọn alakoso rẹ̀ sì jẹ oniwa-ibajẹ ati alábòsí. Sibẹ Paul wipe: ”Ki olukuluku ọkàn ki ó foribalẹ fun awọn alaṣẹ tí ó wà ní ipo giga. Nitori kò sí aṣẹ kan, bikoṣe lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.” “Awọn alaṣẹ tí ó wà ní ipo giga” naa ni awọn ijọba-akoso ayé tí wọn wà lonii.”—Rome 13:1.

15 Jehofah jẹwọ gbígbà pe titi di igba tí a bá mú iṣakoso rẹ̀ pada sori ilẹ-aye ní kíkún, awọn ijọba-akoso ìlu nṣiṣẹ fun awọn ete wiwulo kan. Wọn nṣeranwọ ní pipa iwọn wíwà létòlétò mọ laarin ẹgbẹ-oun-ọgba, ó sì npese aimọye awọn iṣiṣẹṣeranwọ, tí ó ní ninu iforukọsilẹ ti igbeyawo ati ìbí. (Fiwe Luke 2:1-5.) Nipa bayii awọn Kristian ní gbogbogboo lè “maa lo ayé wọn ní idakẹjẹẹ ati pẹ̀lẹ ninu gbogbo iwa-bi-Ọlọrun ati iwa agba.”—1 Timothy 2:2.

16 Bi wọn ti nduro de akoko naa nigba tí ijọba Ọlọrun yoo yanju awọn ọran-iṣoro ogun, aiṣododo ati ìpọnnilójú, awọn Kristian kò nilati ’tako ọla-aṣẹ! awọn ijọba-akoso ilu. Wọn nilati san awọn owo-ori tí a beere fun lọna àìṣàbòsí, ṣegbọran si awọn ofin ki wọn sì bọwọ fun awọn alakoso. Fun ipa-ọna yii ni a ti maa nfi igba gbogbo yin awọn Kristian tootọ tí awọn oniṣẹ-ọba sì maa nràn wọn lọwọ, kò sì wọpọ ki a fi “idà naa” jẹ wọn níyà eyi tí a nlò fun awọn arufin.—Rome 13:2-7.

WÍWÀ NÍ ITẸRIBA TÍ Ó NÍ ÀÀLÀ

17 Nigba miiran iforigbari maa nwà laarin awọn ofin. Ijọba-akoso ilu lè beere fun ohun kan tí Ọlọrun kaleewọ. Tabi ofin ilu lè ṣe ikaleewọ ohun kan tí Ọlọrun pa awọn Kristian laṣẹ lati ṣe. Kinni nigba naa?

18 Iru iforigbari bẹẹ ṣẹlẹ nigba tí awọn alakoso kà á leewọ fun awọn apostle lati maṣe waasu nipa Jesu Kristi tí a ti jí dide. Ka akọsilẹ afúngbagbọ-lokun naa ninu Iṣe 4:1-23; 5:12-42. Bi o tilẹ jẹ pe a jù wọn sẹwọ̀n a sì nà wọn ní pàṣán, awọn apostle naa kò ṣíwọ́ wiwaasu. Peter wipe: “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.”—Iṣe 5:29.

19 Nitori naa itẹriba Kristian kan si awọn alaṣẹ ijọba jẹ itẹriba tí ó ní ààlà. Iṣẹ rẹ̀ akọkọ ni lati ṣegbọran si Ọla-aṣẹ Giga Julọ. Bi, gẹgẹ bi abajade, onitọhun bá faragba ìjẹníyà, oun lè jèrè itunu ní mímọ̀ pe Ọlọrun tẹwọgba ohun tí oun nṣe.—1 Peter 2:20-23.

20 Awọn Kristian ijimiji dojukọ awọn ipinnu ní apá ibomiran tí ó niiṣe pẹlu ohun tí Ọlọrun dari-tọsọna ati ohun tí akoso Rome fojusọna fun. Eyi ní nkan iṣe pẹlu ṣiṣe itilẹhin tabi wíwà ninu ẹgbẹ-ogun Rome. Ọlọrun ti sọ nipa awọn eniyan rẹ̀ pe: “Wọn yoo sì fi idà wọn rọ ohun-eelo itulẹ; wọn yoo sì fì ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orilẹ-ede ki yoo gbé idà soke si orilẹ-ede, bẹẹ ni wọn ki yoo kọ́ ogun jíjà mọ.” (Isaiah 2:4; Matthew 26:52) Nigba naa, bi akoso Rome bá fi dandan-gbọn beere pe ki Kristian kan wà ninu ẹgbẹ-ogun rẹ̀ tabi ki ó ṣe itilẹhin fun awọn isapa ogun rẹ̀, iforigbari yoo wà laarin ofin Kesari ati ti Ọlọrun.

21 Awọn Kristian ijimiji tún fi ofin Ọlọrun ṣaaju pẹlu nigba tí awọn eniyan paṣẹ fun wọn lati sun turari si oriṣa àkúnlẹ̀bọ Kesari Rome. Awọn miiran ti lè ronu pe iṣẹ naa jẹ ifihan ifẹ orilẹ-ede ẹni. Ṣugbọn ọrọ-itan fihan wa pe awọn Kristian rí i gẹgẹ bi ọna ibọriṣa kan. Wọn kò ní ṣe awọn ohun tí ó mú ibọriṣa lọwọ si eniyan kankan tabi ohun kan, ní mímọ̀ pe ifọkansin wọn jẹ ti Jehofah. (Matthew 22:21; 1 John 5:21) Dipo ki wọn sì lọwọ ninu iṣelu, ani nipa pipariwo ìbùyìn-funni onibọriṣa si alakoso kan paapaa, wọn wà laidasi tọtuntosi ki ó baa lè jẹ pe wọn “kii ṣe apakan ayé,” gẹgẹ bi Jesu ti rọ̀ wọn.—John 15:19; Iṣe 12:21-23.

22 Iwọ yoo ha tẹwọgba ironu Ọlọrun ati awọn idaritọsọna rẹ̀ lori ọran ofin bi? Ṣiṣeẹẹ yoo daabobo ọ kuro lọwọ ọpọlọpọ ìkárísọ tí awọn ẹni tí wọn ṣe afojudi si awọn ofin Ọlọrun lori iwa ati ọna-iwahihu nní iriri rẹ̀. Iwọ ki yoo sì ní iriri ìjẹni-níyà laiyẹ lati ọ̀dọ̀ awọn alaṣẹ ilu tí wọn wà bayii. Ṣugbọn ironu Ọlọrun lori ọran naa ní ninu, leke gbogbo rẹ̀, mímọ̀ ọ́n ní àmọ̀dunjú gẹgẹ bi Alakoso Giga Julọ. Bi iwọ yoo bá ṣe eyiini labẹ gbogbo ayika-ipo, nigba naa iwọ yoo jẹ ẹni yiyẹ nigba tí awọn ofin ijọba Ọlọrun yoo bá bori laipẹ ní gbogbo ilẹ-aye.—Daniel 7:27.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 11 Awọn apá ti isin, ọna-iwahihu ati ti iṣegun nipa eyi ni a fi funni ninu iwe kekere naa Jehovah’s Witnesses and the Question of Blood, tí a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí a fi nilati ronu lori oju tí awa yoo fì wo awọn ofin? (1-4)

Kinni ohun tí a nilati mọ ní àmòdunjú nipa awọn ofin Ọlọrun? (5, 6)

Awọn idi wo ni a ní fun ṣiṣe igbọran si ofin Ọlọrun lodisi “agbere”? (7, 8)

Bawo ni a ṣe lè ṣegbọran si ofin Ọlọrun nipa ẹjẹ? (9-11)

Eeṣe tí a fi nilati ṣegbọran si Ọlọrun ani bi a tilẹ nhalẹ mọ iwalaaye wa? (12)

Oju wo ni awọn Kristian fi nilati wo awọn ìjọba-akoso ayé, eesitiṣe? (Matthew 22:19-21) (13-16)

Kinni ipa-ọna tí ó tọ́ nigba tí ofin Ọlọrun ati awọn ofin ayé bá forigbari? Ṣapejuwe. (17-21)

Idanwo wo ni awa dojukọ nisinsinyi? (22)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 167]

“Atunyẹwo oniṣọra kan nipa gbogbo isọfunni tí ó wà larọwọto ntẹsiwaju lati fihan pe, titi di akoko Marcus Aurelius (ọba-nla kan lati 161 si 180 C.E.), kò sí Kristian kankan tí ó di jagunjagun; kò sì sí jagunjagun kan, lẹhin ti ó di Kristian, ti ó tún ṣì wà ninu iṣẹ ologun.”—“The Rise of Christianity.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]

Owò-orí rẹ wà fun. . .

Aabo Ọlọpaa

Imọtoto

Eto-ekọ

Ifiweranṣẹ

Omi Ẹrọ

Iṣẹ Panápaná