Ibalopọ Takọtabo—Ìṣíníyè Wo Ló Nṣiṣẹ Nitootọ?
Ori 7
Ibalopọ Takọtabo—Ìṣíníyè Wo Ló Nṣiṣẹ Nitootọ?
BI IWỌ̇ bá nilati ṣe ifọrọwanilẹnuwo kan lori Kinni ohun tí nfunni layọ? pupọ ninu awọn idahun naa yoo niiṣe pẹlu ibalopọ takọtabo. Eyiini jẹ ohun tí a lè reti, nitori pe awọn imọlara ati ìfẹ fun ibalopọ takọtabo jẹ apakan ninu ohun tí Ọlọrun fun eniyan eyikeyi tí ó wà ní ilera pípé lọna ti ẹda.
2 Ijiroro ibalopọ takọtabo ti di ohun tí a nṣe ni gbangba ju ti awọn iran-eniyan tí wọn ti kọja lọ. Pẹlupẹlu, ìwa ibalopọ takọtabo ti yipada. Pupọ ati pupọ sii awọn ọ̀dọ́ nì wọn nbẹrẹ ibalopọ takọtabo ní ọjọ-ori tí ô kere pupọ, ani ní kùtùkùtù ìgba ọ̀dọ́langba wọn. Araadọta ọkẹ awọn tọkọtaya, tí ó ní ninu awọn eniyan tí wọn ti fẹhinti lẹnu iṣẹ, ngbé papọ, tí wọn sì nní ibalopọ takọtabo laiṣe igbeyawo. Laarin awọn eniyan tí wọn ti ṣe igbeyawo, pupọ ninu wọn ti gbiyanju ibalopọ takọtabo ọlọpọ eniyan, ṣiṣe paṣipaarọ iyawo tabi “igbeyawo ajumọgbọjẹgẹ,” ninu eyi ti tọkọtaya fohunṣọkan lati maa ní ibalopọ takọtabo lẹhin ode igbeyawo.
3 Ìṣínìyè lori ọran wọnyi nwá lati ọ̀kan-kò-jọ̀kan awọn orisun. Ohun tí a fi oju wò bi eyi tí ó lokiki lonii ni a ti fun ní iṣiri tabi ô keretan fọwọsi lati ọ̀dọ̀ ọpọlọpọ dokita, awọn oludamọran igbeyawo ati awọn alufaa. Awọn eniyan kan nrí awọn ero-ìnu wọn gbà lati inu awọn iwe tabi awọn akori-ọrọ inu iwe-irohin ti bi a ṣe
nṣe é. Awọn ipa-ọna-ẹkọ nipa ibalopọ takọtabo ní ile-iwe ti nípa lori ironu awọn ẹlomiran. Sibẹ awọn miiran kàn wulẹ he awọn ero-inu wọn lati inu awọn iwe itan arosọ, awọn aworan ara ogiri ati awọn eré ori telefision tí ó jẹ pe kiki ọran ibalopọ takọtabo nikan ni wọn dálé lori.4 Gẹgẹ bi awọn eniyan tí wọn pọ̀ julọ ti ṣe mọ̀, Bibeli pẹlu jiroro ọran naa. Ọpọlọpọ awọn eniyan lonii ní ìtẹsi lati yàgò fun awọn ọpa-idiwọn Bibeli, wọn ní imọlara pe iwọnyi kún fun ikanilọwọko lọna tí ó rekọja ààlà. Ṣugbọn njẹ bẹẹ ha ni ọran yii rí bi? Tabi ô ha lè jẹ pe fifì ìṣíníyé Bibeli sílò niti gidi gan-an ndaabobo ẹnikan lọwọ ọpọ irora ọkàn-àyà tí o sì nmú ki ô ṣeeṣe lati rí ayọ tí ó ga pupọ sii ní igbesi-aye?
IBALOPỌ ṢAAJU IGBEYAWO—EEṢE TÍ KÒ FI YẸ?
5 Ifẹ-ọkan ati agbara-iṣe fun ibalopọ takọtabo lọna ti ẹda maa nsọji tí ô sì ndagba lakoko awọn ọdun tí ô ṣaaju didi ọmọ ogún ọdun. Nitori naa la gbogbo ọrọ-itan já ọpọlọpọ ọ̀dọ́ eniyan ni wọn ti ní ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo. (Genesis 34:1-4) Ṣugbọn ní awọn ọdun lọọlọọ yii ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo ti wá di ohun tí wiwọpọ rẹ̀ tubọ nga sii. Ní awọn ibikan ô ti fẹrẹẹ di ofin-idiwọn fun gbogbogboo. Eeṣe?
6 Idi kan fun igasoke ninu ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo tan mọ ipolongo tí a fi fun ibalopọ takọtabo ninu awọn aworan ara ogiri ati awọn iwe itan arosọ olokiki. Ọpọlọpọ ọ̀dọ́ ni wọn nṣofintoto, wọn ’fẹ́ lati mọ bi ô ṣe rí.’ Eyi, ní odikeji ẹwẹ, nfa ikimọlẹ awọn ojúgbà-ẹni tí ó sì nlo agbara-idari lori awọn ẹlomiran lati juwọsilẹ. Bi ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo ati ibalopọ takọtabo laisi igbeyawo ti di ohun tí ô tankalẹ, ọpọlọpọ alufaa nisinsinyi ni wọn nsọ pe ô jẹ ohun tí a lè yọnda fun niwọn igba tí awọn tí ọran naa kàn bá ti ’fẹran ara wọn.’ Pupọ ati pupọ sii awọn eniyan tí wọn kò tíì ṣe igbeyawo nipa bayii ni wọn ndojukọ ibeere
naa, ‘Eeṣe tí emi kò fi ní ibalopọ takọtabo, ní pataki julọ bi a bá lo ìfẹ̀tò-sọmọ-bíbí?’7 Onkọwe oniṣegun Dr. Saul Kapel ṣe itolẹsẹẹsẹ awọn idi miiran tí wọn wà lẹhin ibalopọ takọtabo gaaju igbeyawo, ô si fi awọn akiyesi rẹ̀ hàn niti awọn ipa tí wọn nní:
‘A ti ṣi ibalopọ takọtabo lò gẹgẹ bi ọna kan ní iṣọtẹ si awọn obi. A ti ṣì í lò lati pe afiyesi sí ara-ẹni, gẹgẹ bi iru sipo kan fun iranlọwọ. A ti ṣì í lò gẹgẹ bi ọna kan lati ṣe afihan pe ẹni naa jẹ ọkunrin tabi obinrin. A ti ṣì í lò gẹgẹ bi itilẹhin oniwarere ti ẹgbẹ-oun-ọgba kan ninu awọn igbidanwo asan lati jere itẹwọgba.
‘Nigba tí a bá ṣi ibalopọ takọtabo lò lọna bayii, kò lè yanju awọn ọran-iṣoro tí ô sunni ṣe é laelae. Bii ti atẹhinwa, ó wulẹ nmú ki wọn pokudu ni.’
8 Idi yowu ki ô fa ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo, bi o ti wu ki ô wọpọ tô, bi o ti wu ki awọn oludamọran ati awọn alufaa tí wọn tẹwọgba a ti pò tó, Bibeli funni ní imọran pe:
“Eyi ni [ifẹ-inu] Ọlọrun, . . . pe ki ẹyin ki ô takete si agbere; . . . ki ẹníkẹni maṣe rekọja, ki ô má sì ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan naa.—1 Thessalonica 4:3-6.
Awọn diẹ lè ní imọlara pe Ọlọrun nihin wulẹ nkanilọwọko lainidii ni. Ṣugbọn maṣe gbagbe pe ibalopọ takọtabo tikaraarẹ̀ jẹ ẹbun kan lati ẹdọ Jehofah Ọlọrun; oun ni Ẹni naa tí ôó dá awọn eniyan pẹlu awọn agbara ibimọ. (Genesis 1:28) Njẹ kò ha bá ọgbọn ironu tí ô tọna mu pe Aṣẹda ibalopọ takọtabo ẹda-eniyan nilati ní agbara-iṣe lati pese imọran tí ó dara julọ lori rẹ̀, ìṣíníyè tí ô lè daabobo wa lodisi ẹdun-ọkan?
AWỌN ABAJADE—WỌN HA DUNMỌNI TABI RONILARA BI?
9 Ifanimọra ati ifẹ-ọkan fun ibalopọ takọtabo. lè, Genesis 4:1) Ninu idile kan, awọn ọmọ tí wọn jẹ abajade lè jẹ orisun kan fun ayọ̀ gidi. Kinni, laika eyiini si, bi ibalopọ takọtabo bá wáyé laarin awọn eniyan kan tí wọn kò tíì ṣe igbeyawo? Abajade rẹ̀ saba maa njẹ òkan naa—liloyun ati awọn ọmọ.
ninu igbekalẹ tí ó tọna, ní awọn abajade rere. Ọ̀kan, dajudaju, ni awọn ọmọ. Akọsilẹ akọkọ nipa ibalopọ takọtabo sọ pe: Adam si mọ Efa aya rẹ̀, ô sì loyun. (10 Pupọ ninu awọn wọnni tí wọn ṣe ajọpin ninu ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo maa nní imọlara pe eyi kò yẹ ki ô jẹ ọran kan tí ô wuwo. Wọn mọ gbogbo awọn ìdíyún tí wọn wà larọwọto patapata. Ní awọn ibikan ọwọ awọn òdọlangba lè tẹ awọn oògùn wọnyi laidi mímọ̀ fun awọn obi wọn. Sibẹsibẹ, oyún níní ngbilẹ ani laarin awọn òdọlangba tí wọn gbôwọ, awọn ẹni tí nwipe, Kò lè ṣẹlẹ sí mi.? Awọn irohin bi iru awọn wọnyi jẹrii sii:
Eyi tí ó ju ẹyọkan lọ ninu gbogbo awọn ọmọ marun tí a bí ní New Zealand ní ọdun 1979 ni a bí fun obi kan tí kò ṣe igbeyawo.
Lara gbogbo awọn obinrin mẹta ilẹ Britain tí kò tíì pé ẹni ogún ọdun tí nka awọn ẹ̀jẹ igbeyawo rẹ̀, ọ̀kan jẹ aboyun ṣaaju akoko naa.
“Ọ̀kan ninu marun awọn ọdọmọbinrin ọ̀dọ́langba [ní U.S.A.] ni yoo loyun ṣaaju ki ó tô gboyejade ní ile-ẹkọ giga”
11 Abajade onirora tí ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo yii ti mú ikimọlẹ wá sori ọpọlọpọ ọdọkunrin ati ọdọbinrin. Awọn kan nyijusi ìṣẹ́yún. Sibẹ awọn eniyan ọlọkan-ojo maa nní idaamu lilekoko niti ironu nipa pipa ọmọ tí ó ṣẹṣẹ ndagba ninu ikùn iya rẹ̀ run. (Exodus 20:13) Ẹmi-ero ati ẹri-ọkan jíjẹ obinrin tún wemọ ọn pẹlu. Awọn wọnyi lagbara tobẹẹ tí ó fi jẹ pe awọn pupọ tí wọn ti fi àyè gba ìṣéyún ti kabamọ rẹ̀ nigbẹhin gidigidi.—Rome 2:14, 15.
12 Ìlóyún laarin awọn ọ̀dọ́langba nmú awọn ewu nlánlà wá fun iya ati ọmọ ju awọn oyún laarin awọn agbalagba obinrin lọ. Ewu tí ô ga pupọ sii ti àìtó ẹjẹ
wà, irusoke ẹjẹ aboyun, ẹjẹ dídà, ìrọbí ọlọjọ-pípẹ́ ati ibimọ tipátipá, ati iku lakoko ibimọ pẹlu. Ọmọ kan tí a bí lati ọ̀dọ̀ iya kan tí kò tô ẹni 16 ọdun ní ewu ilọpo meji lori lati kú ní ọdun akọkọ igbesi-aye rẹ̀. Awọn ọmọ-àlè tún nmú awọn ọran-iṣoro pupọ ti ara-ẹni, ti ẹgbẹ-oun-ọgba ati iṣuna-owo bá awọn obi wọn. Siwaju sii, aabo ati idagbasoke ọmọ kan lọna titobi sinmi lé ayika ile kan tí ô wà ní deedee. Awọn ọmọ tí a fi eyiini dù nitori pe wọn jẹ ọmọ-àlè ni a lè ṣe ipalara wiwuwo fun ní gbogbo ọjọ ayé wọn. Njẹ iwọ yoo ha sọ, nigba naa, pe awọn abarebabọ abajade ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo jẹ eyi tí ô dunmọni tabi ronilara bi? Ati pe njẹ ìṣíníyẹ Bibeli naa, Ẹ takete si agbere, ha jẹ aabo ọlọgbọn bi?13 Ṣiṣai ka ìṣíníyè Bibeli naa sí ti tún fi ọpọlọpọ sinu abajade onirora miiran—arun. Awọn obinrin tí wọn bẹrẹ igbesi-aye onibalopọ takọtabo wọn nigba tí wọn ṣì jẹ ọ̀dọ́langba pẹlu ọgọrọọrọ awọn àlé ní iye tí ô ga pupọ ninu arun cancer ti ẹya ibimọ: Ohun tí ô wà, pẹlupẹlu, ni ewu tí ô jẹ gidi gan-an ti arun abẹ. Awọn eniyan kan ntan ara wọn jẹ nipa rironu pe àtọ̀sí ati arun rẹ̀kórẹkó ni a lè tete ṣawari wọn ki a sì wò wọn sàn. Ṣugbọn awọn ọjọgbọn Eto Ilera Agbaye ti U.N. rohin pe awọn iru arun abẹ kan nisinsinyi ti yigbì si awọn oògùn arun. Idaamu bá awọn oniṣegun, pẹlupẹlu, nipa ti irusoke ninu arun abẹ tí a npè ní herpes. Ó saba maa nṣe ipalara fun awọn ọmọde tí awọn obinrin tí wọn ní arun naa bá bí. Bẹẹ ni, ọpọlọpọ ọ̀dọ̀ ni wọn nkẹkọọ otitọ ikilọ Bibeli naa si ibanujẹ ara wọn pe:
“Gbogbo ẹṣẹ tí endayan ndá ó wà lode ara; ṣugbọn ẹni tí ó nṣe agbere nṣẹ̀ sí ara oun tikaraarẹ̀.”—1 Corinth 6:18.
14 Awọn kan ronu pe ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo pese iriri tí ó lè mú ki ô ṣeeṣe fun atunṣe nipa ibalopọ takọtabo ninu igbeyawo. Ò jẹ ohun tí ó wọpọ
ní awọn ilẹ kan fun awọn baba tí wọn jẹ ọlọrọ lati mú awọn ọmọ wọn lọ sọdọ awọn aṣewo fun ẹkọ. Awọn eniyan lè ronu pe eyi ṣe iranlọwọ. Ṣugbọn niti gidi gan-an kò rí bẹẹ, ní idọgba pẹlu ọla-aṣẹ Ẹlẹdaa wa, ẹni tí ô ti ṣakiyesi gbogbo iriri ẹda-eniyan. Didi ipo iwa-mímọ mú latilẹwá fi ipilẹ sisunwọn lelẹ fun igbeyawo alayọ. Awọn iwadii tí a ṣe ní Canada fihan pe awọn ọ̀dọ́langba tí wọn tete ní ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo ni ô jọ pe lọna tí ó ga julọ wọn yoo rẹ́ awọn ẹnikeji wọn jẹ nigba tí wọn bá ṣe igbeyawo tán. Ṣugbọn awọn eniyan tí wọn di ipo iwa-mímọ mú latilẹwá ni ô jọ pe lọna tí ó ga julọ wọn yoo wà ní mímọ́ ninu igbeyawo; ọ̀wọ̀ ati ọlá tí wọn ní fun igbeyawo ṣaaju ọjọ igbeyawo nbá a niṣo lẹhin rẹ̀.KINNI NIPA PANṢAGA?
15 Imọran kò-kọ̀-kan ti ode-oni nipa ibalopọ takọtabo ti tún sinni lọ si panṣaga pupọ sii. Awọn irohin lati Europe ati North America fihan pe nkan bii idameji awọn ọkunrin tí wọn ti ṣe igbeyawo ni wọn nrẹ́ awọn iyawo wọn jẹ. Pupọ awọn obinrin sii nisinsinyi pẹlu ni wọn ndá panṣaga lare tí wọn sì nṣe ajọpin ninu rẹ̀, nigba pupọ pẹlu ireti pe yoo tubọ fi eré ifẹ kún igbesi-aye wọn.
16 Bibeli funni ní imọran tí ôó ṣe kedere gidi gan-an lori eyi: “Ki ọkọ ki ó maa ṣe ohun tí ô yẹ [nipa ibalopọ takọtabo] si aya rẹ̀; bẹẹ gẹgẹ sì ni aya pẹlu si ọkọ.” (1 Corinth 7:3) Iwọ tún lè ka Owe 5:15-20 pẹlu, eyi tí, lede afiṣapẹẹrẹ, ô sọ pe awọn eniyan tí wọn ti ṣe igbeyawo nilati rí adùn ibalopọ takọtabo gbà ninu igbeyawo wọn, kii ṣe lati ọ̀dọ̀ ẹnikan tí ó wà lẹhin ode igbeyawo. Iriri la awọn ọrundun já ti fi idi rẹ̀ mulẹ pe ìṣíníyé yii jẹ aabo kan. Ô ndaaboboni lọwọ arun ati bíbí ọmọ-àlè ati ohun tí ô lodisi ofin. Ô tún ndaaboboni lọwọ ipalara ati ìkárísọ tí panṣaga saba maa nṣokunfa.
17 Nigba tí ọkunrin kan ati obinrin kan bá ṣe igbeyawo laarin ara wọn, wọn fi ara wọn sabẹ ìdè lẹnikinni-keji. Kinni ohun tí ó maa nṣẹlẹ bi ọ̀kan ninu wọn bá fọ́ igbẹkẹle yẹn nipasẹ ṣiṣe ìréjẹ? Iwadii kan lori awọn iṣekuṣe lẹhin ode igbeyawo rohin pe:
“Ẹbi nlánlà ló wà fun ṣiṣe ohun tí ó lodisi ẹ̀jẹ́ ẹni. Panṣaga jẹ iwa-ọdaran ti ara-ẹni, nitori pe iwọ mọ ẹni naa gan-an tí iwọ ndà tabi tí iwọ npalara.”
Eyi wá di ohun tí ó ṣe kedere sii lẹhin tí ọpọlọpọ tọkọtaya tẹle imọran nipa igbeyawo ajumọgbọjẹgẹ, ninu eyi tí a rò pe ô yẹ ki adehun wà nipa níní ibalopọ takọtabo pẹlu awọn ẹlomiran. Lẹhin akoko gígùn kan awọn agbẹnusọ fun igbeyawo ajumọgbọjẹgẹ ti yí ọrọ wọn pada. Awọn abajade onibanujẹ ti fi tipátipá mú wọn lati pari ero naa sí pe mímú ki iṣotitọ-delẹ daniloju ninu ọran ibalopọ takọtabo ṣì jẹ animọ pataki kan tí ó sì pọndandan ninu igbeyawo pupọ julọ.
18 Panṣaga maa nṣokunfa owú ati aiṣeefọkàntẹ̀. Ọlọrun fi pẹlu ọgbọn funni ní ìṣíníyè nipa ipalara tí awọn wọnyi nmú wá. (Owe 14:30; 27:4) Nipa bayii, bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan kan rò pe wọn mọ pupọ jù tí wọn sì dá panṣaga ṣiṣe lare, awọn otitọ-iṣẹlẹ fi odikeji eyiini hàn. Onimọ nipa ọgbọn ijinlẹ ti agbara ọpọlọ Dr. Milton Matz fi ọ̀dájú jẹwọ pe:
Ọpọ julọ ninu wa ni jìnnìjìnnì maa nbò nigba tí ibalopọ takọtabo lẹhin ode igbeyawo bá ṣẹlẹ ninu igbesi-aye wa, yala awa jẹ olùkópa tabi ẹran-ọdẹ. . . .
Iriri mi ninu rẹ̀ ni pe awọn iṣekuṣe takọtabo lẹhin ode igbeyawo jẹ onirora lọna tí ô ga pupọ gan-an fun gbogbo ẹni tí ọran naa kàn. Gẹgẹ bi oògùn kan fun ayọ̀, eyi kò ṣiṣẹ.
IBALOPỌ TAKỌTABO NINU IGBEYAWO
19 Nipa ti ibalopọ takọtabo, Bibeli kò kàn wulẹ funni ní imọran kiki lori ohun tí a nilati yẹra fun. Ô tún funni ní ìṣíníyè lori ohun tí a o ṣe lọna rere tí yoo ṣe afikun si igbesi-aye kan tí ó lérè ninu.
20 Kaka ti ìbá fi gbé ibalopọ takọtabo kálẹ̀ gẹgẹ bi kiki iṣẹ ẹya-ara kan lasan, Iwe-mimọ fihan lọna tí ô tọna pe ô lè jẹ orisun igbadun fun tọkọtaya. Bibeli mẹnukan wíwà ní ipo ayọ̀ pupọ jọjọ ati jíjẹ́ ki awọn ọrọ-asọjade onibalopọ takọtabo ninu igbeyawo ’pani bi ọti. (Owe 5:19) Iru ṣiṣai fi ọrọ bọpo-bọyò bayii ṣe iranlọwọ lati kásẹ̀ ẹmi ìjémímọ́ aṣeleke tabi itiju nipa ibatan onifẹẹ tí ó tọna laarin ọkọ ati aya kuro nílẹ̀.
21 Ẹlẹdaa fun awọn ọkọ ní imọran pe: Ẹ maa fẹran awọn aya yin, ẹ má sì ṣe korò si wọn. (Colossae 3:19) Fun ibalopọ takọtabo lati jẹ́ eyi tí nfunni lérè nitootọ, tọkọtaya naa kò gbọdọ ní ohun idena kan bii ikorira tabi ìkùnsínú laarin ara wọn. Nigba naa awọn ibatan lókọláya ni a lè gbadun fun ohun tí wọn jẹ́ niti gidi gan-an, ọna kan lati fi ifẹ tí ô jinlẹ, wíwà labẹ aabo ati ibalo onípẹ̀létù hàn.
22 Siwaju sii, Ọlọrun rọ awọn ọkọ lati maa bá awọn aya wọn gbé pẹlu òye. (1 Peter 3:7) Bẹẹ gẹgẹ ọkọ kan nilati gba awọn ẹmi-ero ati ipo ti ara tí nyipada ti iyawo rẹ̀ rò. Bi, dipo fifi pẹlu idagunla beere ní tipátipá, oun bá nfi pẹlu ironujinlẹ loye awọn imọlara ati aini iyawo rẹ̀, ireti wà pe iyawo naa yoo tubọ ní imọlara pupọ si awọn aini ọkọ naa. Eyi yoo yọrisi itẹlọrun tọtun-tosi.
23 Àròyé kan tí ó wọpọ ni pe awọn iyawo kan tutù tabi wọn kii dahunpada. Ohun kan tí ó lè ṣe afikun si mímú ki eyi ṣẹlẹ ni ọkọ kan tí ô dabi pe ô jinna-réré, tí ô dakẹ jẹ tabi tí ô lekoko ayafi nigba tí ô bá nfẹ́ ibalopọ. Ṣugbọn iwọ kò ha fohunṣọkan pe aidahunpada iyawo yẹn yoo dinku bi ọkọ kan bá jẹ ọlọyaya tí ó sì wà ní pẹkipẹki pẹlu iyawo rẹ̀ deedee bi? Ô jẹ ohun tí ô bá iwa ẹda mu pupọ sii fun iyawo kan lati dahunpada si ọkọ kan tí ô tẹle imọran naa lati gbé ọkàn ìyọnú wò, iṣeun, irẹlẹ, inututu, ipamọra.—Colossae 3:12, 13.
24 Bibeli sọ pe: A ti funni ó ní ibukun ju a ti gbà lọ. (Iṣe 20:35) Eyiini nṣiṣẹ ní ọpọlọpọ ọna, ati niti ilana ô ti jẹ iranlọwọ kan tí ó gbeṣẹ fun adùn ibalopọ takọtabo. Bawo ni ô ṣe rí bẹẹ? Gbigbadun tí iyawo kan gbadun ibalopọ takọtabo sinmi pupọ lori ọkàn-àyà ati ero-inu. Ní awọn akoko lọọlọọ yii itẹnumọ pupọ ni a ti gbéka ori ki awọn obinrin kô ironu wọn papọ sori imọlara amoriya ati igbadun ti ara wọn, ṣugbọn itẹlọrun sibẹ ṣì jẹ ohun kan tí ọwọ ọpọlọpọ kò tẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, Dr. Marie Robinson, ẹni tí ô ṣe iwadii ọran naa, tọka jade pe nigba tí iyawo kan bá gbé ọ̀wọ̀ ró fun ọkọ rẹ̀ tí ó sì fi oju wo ibalopọ takọtabo gẹgẹ bi ọna kan lati fi ’funni’ kaka tí ìbá fi jẹ lati gbà, ô ṣeeṣe pe ki ó rí itẹlọrun pupọ sii funraarẹ̀. Dokita yii ṣalaye pe:
Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ [iyawo naa] yoo ríi pe oun ti fi àyẹ̀ gba iwa oníkẹ̀ẹ titun ati aniyan fun ọkọ oun lati di apakan itumọ fun igbadun ibalopọ takọtabo naa. Oun nrí ô sì nní imọlara adùn ti ìtúraká nipa jijọwọ ara-ẹni silẹ fun ibalopọ takọtabo nmú wá fun ọkọ rẹ, ati pe tí ọna ìgbà-ṣe-nkan yii sì di ti tọtun-tosi, adùn ọkọ tí ó ga sii nfun oun naa ní adùn ti ô peleke sii.
Nitori naa imọran Bibeli lati jẹ ẹni tí nfunni tí ô si ní ifẹ ninu awọn ẹlomiran nfikun ayọ, ani ninu apá igbesi-aye tí ó niiṣe pẹlu ibalopọ takọtabo paapaa.— Philippi 2:4.
25 Titẹle imọran yii nṣanfaani fun wa lọna miirain kan pẹlu. Oju-iwoye wa nipa ibalopọ takọtabo, tí ô ní ninu agbara-iṣe lati ta atare iwalaaye, ní ipa lori ibatan wa pẹlu Ọlọrun, ẹni tí ô jẹ Olufunni ní ìwalaaye naa. Nipa bayii, yiyẹra fun agbere ati panṣaga jẹ iwa ọgbọn, kii ṣe kiki nitori pe ô ṣanfaani fun wa nipa ti ara, ti ọpọlọ, ati ti ẹmi-ero nikan ni, ṣugbọn pẹlupẹlu nitori pe gbogbo awọn nkan wọnyi jẹ ẹṣẹ si Ọlọrun.” (Genesis 39:9) Ati pe nipa iṣotitọ si ẹnikeji ẹni ninu igbeyawo, Hebrew 13:4 sọ pe:
Ki igbeyawo ki ó ní ọlá laarin gbogbo eniyan, ki akete sì jẹ alaileeri; nitori awọn agbere ati awọn panṣaga ni Ọlọrun yoo dálẹ́jọ́.
26 Nigba tí a bá ronu lori bi ibalopọ takọtabo ṣe tan mọ ayọ̀ ẹnikan, a nilati wò rekọja òní. Pẹlu ire tí ô wà pẹtiti lọkan, Bibeli ràn wa lọwọ lati ronu lori bi ohun tí a ṣe yoo ṣe kan awa tikaraawa ati awọn ẹlomiran ní ọla, ní ọdun tí nbọ̀ ati la gbogbo igbesi-aye wa já.
[Koko Fun Ijiroro]
Kinni idi tí ô wá nisinsinyi lati ronu nipa ìṣíníyè Bibeli lori ibalopọ takọtabo? (Owe 2:6-12) (1-4)
Eeṣe tí ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo fi nga sii? (5-7)
Kinni oju-iwoye Ọlọrun nipa ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo? (8)
Kinni awọn abajade ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo? (9-12)
Awọn idi miiran wo ni iwọ lè fi funni fun kika imọran Bibeli lori ibalopọ takọtabo si iyebiye? (13, 14)
Kinni ẹri fihan nipa ìṣíníyè Bibeli lori panṣaga? (15-18)
Kinni ohun tí Bibeli nawọ rẹ̀ jade nipa ibalopọ takọtabo ninu igbeyawo? (19-22)
Bawo ni fifi ìṣíníyè yii sílò ṣe lè ṣanfaani fun ẹnikan? (23-26)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 70]
“Boya ‘ominira ibalopọ takọtabo’ titun jẹ ohun tí ’ntúnisílẹ̀,’. . . ṣugbọn ohun ti mo ngbọ, nibi gbogbo, jẹ ohun kan tí ô yatọ patapata. Ohun tí mo ngbọ ni pe ibalopọ takọtabo olominira niti gidi gan-an nṣe ohun kan fun awọn eniyan tí wọn pò julọ. Ibalopọ takọtabo olominira npanilara.—Onkọwe iwe-irohin G. A. Geyer, The Oregonian.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 71]
“Aiṣotitọ-delẹ ninu igbeyawo maa nṣokunfa ẹbi, irora, ati ìfura, nigba tí ô jẹ pe iṣotitọ-delẹ nṣe atilẹhin fun ìfọkàntẹ̀ ati idunnu-nla jijinlẹ.”—Dr. C. B. Broderick, oludari ile-iṣẹ tí nbojuto ọran igbeyawo ati idile.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 69]
Imọran Bibeli nran awọn eniyan lọwọ lati yẹra fun awọn abajade onibanujẹ ti iwa pálapàla—awọn oyún tí a kò fẹ̀ ati arun abẹ