Igbesi-aye Idile—Bi Iwọ Ṣe Lè Ní Aṣeyọri
Ori 8
Igbesi-aye Idile—Bi Iwọ Ṣe Lè Ní Aṣeyọri
Ọ̇PỌ julọ awọn eniyan ni wọn fohunṣọkan pe igbesi-aye idile ati ayọ̀ tanmọ ara wọn. Ninu iwadii kan, ida 85 lori ọgọrun lara awọn ọkunrin sọ pe wọn ní imọlara pe ‘igbesi-aye idile’ ṣe pataki pupọ si igbesi-aye kan tí ô layọ ninu tí ó sì tẹnilọrun. Sibẹ iwọ lè mọ pupọ awọn ọkunrin tí wọn ti yan ikọsilẹ. Pupọ ati pupọ sii ninu awọn obinrin, pẹlupẹlu, ni wọn yàn lati ṣe ikọsilẹ lati fi opin si awọn igbeyawo tí ó kún fun ìsúni, iforigbari tabi inilara.
2 A kò lè yí awọn nkan tí awọn ẹlomiran nṣe pada. Ṣugbọn ô yẹ ki a ni ọkan-ifẹ ninu mímú ki igbesi-aye idile tiwa tubọ sunwọn sii, paapaa julọ ipo ibatan tí ô wà laarin ọkọ ati aya. Gbogbo wa lè beere pe: ‘Bawo ni ipo ibatan yii ti rí ninu ile temi?’
3 Ẹlẹdaa ni Olupilẹṣẹ eto idile. (Ephesus 3:14, 15) Ô pese imọran tí ô gbeṣẹ tí ó ti ran pupọ, pupọ awọn tọkọtaya lọwọ lati gbadun aṣeyọri ninu igbesi-aye idile. Imọran kan naa yẹn lè jẹ ere-anfaani fun iwọ naa.
ẸKỌ-ÀRÍKỌ́GBỌN GBIGBEṢẸ LATI INU IGBEYAWO AKỌKỌ
4 Ní apá akọkọ tí ô bẹrẹ Bibeli, a rí akọsilẹ kan nipa bi Ọlọrun ṣe bẹrẹ idile ẹda-niyan akọkọ. Lẹhin
akoko kan tí Jehofah Ọlọrun ti dá ọkunrin akọkọ, Adam, Oun sọ pe:“‘Kò dara, ki ọkamrin naa ki ô màkàn maa, gbé; emi yoo ṣe oluranlọwọ tí ô dabi rẹ̀ fun un.’ [Jehofah] Ọlọrun sì fi egungun ìhà, tí ô mú ní ìhà ọkunrin naa, mọ. obúnrìn, ô sì mú un tọ ọkunrin naa wá. Adam sì wipe, ‘Eyiiyi ni egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi. . . . ‘Nitori naa ni ọkunrin yoo ṣe maa fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yoo sì fi ara mọ́ aya rẹ̀; wọn yoo sì di ara kan.”—Genesis 2:18, 22-24.
5 Ṣakiyesi pe idile akọkọ yẹn kii ṣe abajade lati inu awọn ẹni meji kan tí wọn kàn wulẹ pinnu lati maa jumọ gbé papọ. Ọlọrun ni ó fi aṣẹ si igbeyawo naa tí a sì so wọn papọ ninu isopọ kan tí ô wà pẹtiti. Niwaju Ọla-aṣẹ tí ô ga julọ lagbaye, Adam tẹwọgba Efa lati jẹ iyawo rẹ̀.
Genesis 24:4, 34-67; Matthew 25:1-10) Iru fifi ara-ẹni sabẹ ìdé bẹẹ kò tíì di ṣiṣe nigba tí awọn tọkọtaya kan bá kàn wulẹ ngbé papọ laiṣe ẹ̀tọ́ igbeyawo. Kaka bẹẹ, ipo ibatan wọn jẹ eyi tí Bibeli pè ní agbere” tabi panṣaga. (Hebrew 13:4) Ani ki a tilẹ sọ pe wọn fẹnusọ pe wọn fẹran ara wọn, ô pẹ́ ni ô yá ni ipo ibatan wọn ni ô ṣeeṣe ki ô jiya nitori pe kò ní ifara-ẹni-sabẹ ìdé tí ô fẹsẹmulẹ gbọn-in tí igbeyawo beere fun tí Bibeli sì sọ pe ô ṣe pataki. Fun apẹẹrẹ:
6 Nigba tí ọkunrin kan ati obinrin kan bá gbà lati gbé awọn igbesẹ tí a beere fun lati mú ki igbeyawo kan tí ô lésẹ̀ nílẹ̀ tí a sì fun ní akanṣe-afiyesi ṣẹlẹ, wọn fi ara wọn sabẹ ìdé lẹnikinni-keji ní gbangba. (Obinrin kan ẹni 34 ọdun ṣalaye pe: Boya ọrọ igba ayé ojú dúdú ni mo nsọ, ṣugbọn ifara-ẹni-sabẹ ìdé igbeyawo nṣeranwọ fun mi lati ní imọlara ìfọkàntẹ̀ siwaju sii. . . . Mo nifẹẹ itunu ti jijẹwọ fun ara wa ati fun ayé pe a petepero lati faramọra.
Olukọ kan ẹni 28 ọdun ṣe ajọpin ohun tí ô ní iriri rẹ̀: “Lẹhin awọn ọdun diẹ, mo bẹrẹsi ní imọlara ibanujẹ tí iku ololufẹ ẹni maa nṣokunfa rẹ̀. Jijumọ gbepọ [laisi igbeyawo] kò pese ibatan tí ô ṣe kedere lati loye fun ọjọ-iwaju.
Ninu iwadii kan nipa ọran naa, onimọ ẹkọ nipa ẹgbẹ-oun-ọgba Naney M. Clatworthy ríi pe awọn tọkọtaya tí wọn fi ara wọn sabẹ ìdé nipa ṣiṣe igbeyawo, ṣugbọn tí wọn kò tíì gbé papọ ṣaaju igbeyawo, maa nfi ẹnu ara wọn jẹwọ imọlara titobi niti ayọ̀ ati itẹlọrun.
7 Akọsilẹ Bibeli nipa igbeyawo akọkọ tún lè ràn wa lọwọ lati yẹra fun awọn ọran-iṣoro tí wọn niiṣe pẹlu awọn obi ati awọn àna. Iru awọn iṣoro bawọnnìi, gẹgẹ bi oludamọran igbeyawo kan ti sọ, wà lara awọn tí wọn wọpọ julọ. Sibẹ ṣaaju ki awọn ọran-iṣoro eyikeyi tô lè wà pẹlu awọn obi ati awọn àna, Bibeli sọ nipa igbeyawo akọkọ naa pe: Ọkunrin yoo fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yoo sì fi ara mọ aya rẹ̀.—Genesis 2:24.
1 Timothy 5:8; Deuteronomy 27:16; Owe 20:20) Ṣugbọn Iwe-mimọ tẹnumọ ọn pe, nigba tí a bá ti ṣe igbeyawo tán, ẹnikeji rẹ ninu igbeyawo di ibatan rẹ timọtimọ julọ. Ọkọ rẹ tabi iyawo rẹ di ẹni akọkọ’ tí o gbọdọ fẹran, bojuto ki o fẹ̀ràn lòotọ.
8 Lọna ti ẹda, pupọ julọ ninu wa fẹran awọn obi wa. Ani Bibeli tilẹ fun wa ní iṣiri lati pese fun wọn pẹlu awọn ohun iranlọwọ nipa ti ara nigba ọjọ ogbô wọn, bi aini bẹẹ bá wà. (9 Oju-iwoye yii kò fun ẹni tí ô ti ṣe igbeyawo ní iṣiri lati ’sare lọ sile’ lọdọ awọn obi rẹ̀ bi awọn ọran-iṣoro bá jẹ jade. Ati pe ó ṣe iranlọwọ fun awọn obi lati mọriri pe, nigba tí wọn bá ti ṣe igbeyawo tán, awọn ọmọ wọn ’nfìi wọn silẹ̀ wọn sì ndá awọn idile alaifarati-ẹnikan silẹ, ani bi aṣa tabi awọn inawo bá tilẹ mú ki ô jẹ pe wọn nilati gbé nitosi tabi pẹlu awọn obi fun akoko kan. Ô jẹ ohun tí ô baamu fun awọn ọmọ lati mọriri tabi boya ki, wọn gbà ninu ọgbọn ati iriri awọn obi wọn. (Job 12:12; 32:6, 7) Sibẹ ohun tí Genesis 2:24 sọ jẹ ikilọ lodisi awọn obi tí wọn ngbiyanju lati ṣakoso tabi ṣe itọsọna igbesi-aye awọn ọmọ wọn tí wọn ti ṣe igbeyawo. Bẹẹni, fifi imọran Bibeli sílò lè fikun aṣeyọri igbeyawo.
ẸNI MELO NI A LÈ BÁ ṢE IGBEYAWO?
10 A tún lè ríi lati inu akọsilẹ Genesis pe Ọlọrun pese kiki ẹnikẹji kanṣoṣo fun Adam. Ninu awọn eto iṣẹdalẹ igbesi-aye miiran ọkunrin kan ni a fi àyè gbà lati kô obinrin jọ. Ṣugbọn njẹ kíkó obinrin jọ ha nyọrisi ayọ̀ idile bi? Si odikeji rẹ̀, iriri fihan pe ô saba maa nyọrisi owú tí ô jinlẹ pupọ tabi ìjà orogún, ati pẹlupẹlu ibalo-oníkà pẹlu awọn ìyálé. (Owe 27:4; Genesis 30:1) Iwa ikobinrinjọ ati lílé awọn iyawo dànù nipasẹ ikọsilẹ wà laarin awọn Hebrew igbaani. Ọlọrun, niwọn bi ô ti faramọ eyiini, fun awọn ọmọ Israel ní awọn ofin lati ṣe idilọwọ fun aṣilo tí kò láàlà. Ní jijiroro ọrọ naa, bi ó tilẹ rí bẹẹ, Jesu dari afiyesi si ifẹ-inu Ọlọrun bi a ti ṣe itọkafihan rẹ̀ ninu Genesis. Nigba tí a beere lọwọ rẹ̀ nipa ikọsilẹ tí a gbeka ori awọn oriṣiriṣi idi, Jesu sọ pe:
“Ẹyin kò ti kà, á, pe, ẹná tí ô dá wọn nigba atetekọṣe ô dá wọn ti akọ ati abo. Ó si wipe, ‘Nitori eyi ni ọkunrin yoo ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yoo fàmọ aya rẹ̀.’? . . . Nitori naa, ohun tú Ọlọrun bá so ṣọkan, ki eniyan ki ô maṣe yà wọn. . . . Nitori líle àyà [awọn Hebrew], ni Moses [ninu ofin Ọlọrun], ṣe jẹ fun yin lati maa kọ aya yin silẹ, ṣugbọn, lati ìgba atetekọṣe oô, kò rí bẹẹ. Mo sì wi fun yin, ẹnikẹni tí ô bá kọ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe pe nitorì agbere, ti ô sì gbé òmíràn ní iyawo, ô ṣe panṣaga.—Matthew 19:3-9.
11 Jesu mú ki ô ṣe kedere pe laarin awọn ọmọlẹhin oun ọpa-ìdiwọn naa yoo jẹ, kii ṣe iwa ikobinrinjọ, ṣugbọn níní ẹnikanṣoṣo péré ninu igbeyawo, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣeto rẹ̀ ní atetekọṣe. (1 Timothy 3:2) Pípe akanṣe-afiyesi sorì ọgbọn Ọlọrun ati ọla-aṣẹ rẹ̀ ninu ọran yii yoo jẹ igbesẹ kan sí ayọ̀.
12 Ohun kan naa ni ô jẹ otitọ nipa ohun tí Jesu sọ nipa ikọsilẹ. Nigba tí ô bá ṣeeṣe lati rí ikọsilẹ gbà pẹlu irọrun, ikọsilẹ maa npọ. A rí eyiini lonii. Ṣugbọn Ọlọrun fi oju wo igbeyawo gẹgẹ bi ohun tí ô wà pẹtiti kan. Nitootọ, Jesu sọ pe bi ẹnikeji ẹni ninu igbeyawo bá j;ẹ agbere (lede Greek, porneia, tí ô tumọsi iwa pálapàla nipa ibalopọ takọtabo), nipa bayii tí ó di ara kan pẹlu ẹlomiran, ẹnikeji aláìmọwọ-mẹsẹ̀ naa lè gba ikọsilẹ ki ô sì tún igbeyawo ṣe. Sibẹ, yatọ si eyiini, Ẹlẹdaa naa fi oju wo awọn tọkọtaya tí wọn ṣe igbeyawo gẹgẹ bi awọn tí a so papọ pẹtiti. Awọn tí wọn tẹwọgba aṣẹ Ọlọrun ninu ọrọ Oniwaasu 4:11, 12; Rome 7:2, 3) Fun idi yii, kaka tí ìbá fi fa ailayọ, oju-iwoye yii jẹ iranlọwọ kan sí ṣiṣe aṣeyọri ninu igbeyawo. Iriri fi eyiini hàn.
naa nipa bayii ní idi tí ó tobi pupọ sii lati ṣiṣẹ lati mú ki igbeyawo wọn tubọ lokun sii ki wọn sì lè maa bori ọran-iṣoro eyikeyi. (13 ’Ṣibẹ,’ ni awọn eniyan kan lè ní imọlara, ’awọn igbeyawo kan ní awọn ọran-iṣoro wiwuwo, tabi pe awọn tọkọtaya naa kò kàn lè wulẹ bá ara wọn gbépọ̀ ni.’ Kinni nigba naa? Awọn ohun miiran tí ô gbeṣẹ wà tí a lè kẹkọọ rẹ̀ lati inu Bibeli.
ỌKỌ KAN TÍ Ô FẸRAN IYAWO RẸ̀ NITOOTỌ
14 Aṣiri kan sí aṣeyọri idile ni bi ọkọ kan ṣe fi oju wo iyawo rẹ̀ ati bi ô ṣe nbá a lò. Ṣugbọn tani ẹni tí yoo sọ eyi tí ô jẹ ọna tí ô dara julọ? Ohun tí Bibeli sọ nipa igbeyawo akọkọ tún wà fun iranlọwọ wa. Akọsilẹ naa sọ pe Ọlọrun lo diẹ ninu ara Adam funraarẹ̀ lati pese ẹnikeji kan fun un. Bibeli lẹhin naa tún tanmọlẹ siwaju sii sori ọran naa pe:
Bẹẹ ni ó tọ́ ki awọn ọkunrin ki ô maa FẸRAN AWỌN AYA WỌN GẸGẸ BI ARA AWỌN TIKARAAWỌN. Ẹni tí ô bá fẹran aya rẹ̀, áá fẹran oun tikaraarẹ̀. Nitori kò si ẹnikan tí ô tíì korira ara rẹ̀; bikoṣe pe ki ô maa bọ́ ọ ki ô sì maa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi sì ti nṣe sí ijọ.”
Nigba naa, lẹhin ṣíṣàyọlò ọrọ tí óô wà ninu Genesis 2:24, Paul nbá a niṣo pe: Ṣugbọn ki olukuluku yin ki ó fẹran aya rẹ̀ bẹẹ gẹgẹ bi oun tikaraarẹ̀.—Ephesus 5:28-33.
15 Awọn ọkunrin kan lè ronu pe óô yẹ ki awọn lekoko tabi ki awọn fasẹhin jinna-réré ní bíbá awọn iyawo wọn lò. Ṣugbọn Olupilẹṣẹ igbeyawo sọ pe ô yẹ ki ọkọ ki ô fẹran iyawo rẹ̀ gidi gan-an ki ô sì fi ifẹ naa hàn. Lati ní ayọ̀ tí ó jẹ ojulowo, iyawo kan nilati ní imọlara idaniloju pe niti gidi gan-an ni a nifẹẹ oun.
16 ‘Bíbọ ati ṣíṣìkẹ́ tí ọkọ kan bá nṣe fun iyawo rẹ̀ gẹgẹ bi ara rẹ̀’ wemọ gbigbiyanju lati jẹ olupese rere. Sibẹ kò yẹ ki ọwọ rẹ̀ dí tobẹẹ fun pipese àtijẹ-àtimu tí yoo fi gbojufo lilo akoko pẹlu iyawo rẹ̀ ati fifi ifẹ ọlọyaya hàn ninu rẹ̀ gẹgẹ bi eniyan kan. Psalm 11:5; 37:8.
Siwaju sii, kò sí ọkunrin kan tí ori rẹ̀ pé, ani nigba tí a bá mú un binu paapaa, tí yoo korira tabi ki ô huwa ìkà si ara oun tikaraarẹ̀. Fun idi yii, ohun tí Bibeli sọ fagile pe ki ọkunrin kan fi pẹlu iwa-ipá binu si iyawo rẹ̀.—17 A dá obinrin akọkọ lati jẹ ‘àṣekún fun ọkọ rẹ̀.’ (Genesis 2:18, NW) Ọlọrun mọ̀ pe ọna tí a gbà dá ọkunrin ati obinrin yatọ sira. Eyiini ṣì jẹ otitọ sibẹ. Awọn obinrin saba maa nyatọ si awọn ọkunrin ninu awọn animọ ati ọna wọn. Ọkunrin lẹ jẹ ẹni tí npinnu, tí obinrin sì ní suuru ti iwa ẹda-eniyan. Obinrin lè fẹ wíwà laarin awọn ẹgbẹ eniyan, ki ọkunrin sì fẹran dídánìkanwà julọ. Ọkunrin lè tẹnumọ dídé ibikan ní akoko pato tí a dá, ki obinrin sì fi ọwọ “jẹlẹnkẹ” mú ọran nipa akoko. Alaye Bibeli nipa pe Ọlọrun ṣẹda Efa lati jẹ ’àṣekún’ yẹ ki ô ran awọn ọkọ lọwọ lati loye iru awọn iyatọ bawọnni.
18 Apostle Peter rọ awọn ọkọ lati ’maa fi òye bá awọn aya wọn gbé, ki wọn sì maa fi ọlá fun aya bi ohun-elo tí kò lagbara. (1 Peter 3:7) Ọlá yẹn ní ninu fifi àyè gba awọn ohun tí ó yatọ tí iyawo lè fẹ́. Ọkọ kan lè fẹran eré idaraya, ṣugbọn iyawo rẹ̀ lè gbadun lilọ ná ọjà wò tabi wiwo iran ijó jíjó. Ohun tí ô wù ú lẹ̀sẹ̀ nílẹ̀ gidi bii ti ọkọ. Ọlá nfi àyè silẹ fun iru awọn iyatọ bawọnni.
19 Awọn iṣarasihuwa iyawo kan, tí awọn iyipo ara rẹ̀ lè ní ipa lé lori, lè rú ọkọ kan lójú, ati boya iyawo naa paapaa. Ṣugbọn ọkọ lè ṣe iranlọwọ fun ayọ̀ awọn mejeeji nipa gbigbiyanju lati loye ’kí ô sì fi òye bá aya rẹ̀ gbé.’ Nigba pupọ ohun tí ô nbeere fun ni pe ki a fi pẹlu ìkẹ fà á mọra nigba tí ọkọ naa bá nbá a sọrọ lọna ifẹ.
IYAWO KAN TÍ NBỌWỌ FUN ỌKỌ RẸ̀
20 Niwọn bi iyawo naa ti nilati ṣe ipa tirẹ̀ bi idile alayọ kan yoo bá wà,
Ẹlẹdaa naa funni ní amọna fun awọn iyawo pẹlu.21 Kete lẹhin tí ô ti sọ fun awọn ọkọ lati fẹran awọn aya wọn, Bibeli fikun un pe: Ní ọwọ keji ẹwẹ, ki aya ki ó ní ọ̀wọ̀ tí ô jinlẹ fun ọkọ rẹ̀. (Ephesus 5:33) Ninu ọran ti igbeyawo akọkọ, awọn idi wà tí ô yẹ lọna ti ẹda lati mú ki Efa maa wojú ọkọ rẹ̀ fun itọsọna. Adam ni a kọkọ dá. Ô ní imọ ati iriri tí ô pẹ jù ninu igbesi-aye, ani tí ó tilẹ ti gba awọn itọsọna lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
22 Ṣugbọn kinni nipa ti awọn igbeyawo lọjọ òní? Bi ọkọ kan bá fi tọkan-tọkan gbiyanju lati fi imọran Bibeli tí a ti jiroro ní iṣaaju sílò, ô ṣeeṣe pupọ pe ki eyi sún iyawo lati bọwọ fun un. Ani nibi tí iyawo ti lè gba iwaju ninu awọn ọna pataki kan, tabi nibi tí ọkọ rẹ̀ tilẹ kuna, idi wà lati gbé ibọwọ ró—lati inu ibọwọ fun eto Jehofah, eyi tí idile jẹ apakan rẹ̀. Apostle Paul kọwe pe:
“Ẹyin aya, ẹ maa tẹriba fun àwọn ọkọ yin, gẹgẹ bi fun Oluwa, nitori pe ọkọ niiṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi tiiṣe ori ijọ eniyan rẹ̀.”—Ephesus 5:22, 23.
23 Ẹyi kii ṣe lati sọ pe ki ọkọ kan wá di onroro alámọ̀tán ninu idile. Eyiini yoo lodisi apẹẹrẹ onifẹẹ, ti igbatẹniro ati ìlóye Kristi. Ọlọrun rọ awọn aya lati maa woju awọn ọkọ wọn fun ìfọ̀nàhanni. Lori awọn ọran idile tí ô ṣe pataki ọkọ ati aya lè jumọ fi ọran lọ ara wọn papọ, gẹgẹ bi ti awọn ẹya-ara kan tí nṣiṣẹ. Sibẹ ọkọ ni yoo jíhìn fun Ọlọrun nipa idile naa ní pataki.—Colossae 3:18, 19.
24 Iriri fihan pe ohun ti Bibeli sọ lori ọran yii pe gedé. Bi iyawo kan bá ti nṣiṣẹ lati jèrè ifẹ ati itọju ọkọ rẹ̀, tí ó sì nwojú rẹ̀ fun amọna ninu awọn ọran idile, oun yoo saba maa ríi pe yoo maa fi tinutinu tubọ gbé ẹru-iṣẹ rẹ̀ tí yoo sì maa ṣe é pẹlu ifẹ.—JIJUMỌ ṢIṢẸ PAPỌ FUN AṢEYỌRI IDILE
25 Ijumọsọrọpọ jẹ ohun pataki kan tí a ṣe alaini ninu awọn idile pupọ. Onimọ-ijinlẹ ti ẹgbẹ-oun-ọgba kan ṣakiyesi pe: “Pupọ julọ ninu awọn tọkọtaya ni wọn kii tẹtisilẹ si ara wọn, tí awọn pupọ sì maa nwọ ijakadi gẹgẹ bi abajade eyi.” Kò sí bi a ṣe lè ṣe ki a maṣe ní awọn nkan tí nrí wa lára ati awọn ijakulẹ ninu igbesi-aye. Bawo ni a ṣe lè ṣe idiwọ fun awọn wọnyi ki wọn maṣe pa igbeyawo wa lara? Ijumọsọrọpọ rere nṣeranwọ. Ṣọra ki o maṣe rò pe ohun tí kò tô nkan ni, tí yoo fi wá jẹ pe iwọ yoo kàn ríi pe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni bíbá ara yin sọrọpọ ndinku siwaju ati siwaju sii.
26 Ṣiṣẹ lori jijumọsọrọpọ. Njẹ niti gidi gan-an ni iwọ sọ ọ di iṣe-aṣa lati maa jiroro awọn igbokegbodo ati awọn imọlara rẹ bi? Nigba pupọ julọ ni a maa nwà ninu ìkánjú tí ô ga rekọja lati sọrọ tí a sì nkuna lati gbọ ohun tí ẹlomiran nsọ. (Owe 10:19, 20; James 1:19, 26) Kaka tí ìbá fi jẹ pe a kàn wulẹ nfi eku-káká wá àyè lati sọrọ, fetisilẹ, gbiyanju lati loye, boya tí o nfesi pe, ‘Ṣe ohun tí o ní lọkan ni pe . . . ?’ tabi, ’Ṣe ohun tí o nsọ ni pe . . .?’ (Owe 15: 30, 31; 20:5; 21:28) Ọkọ kan tabi iyawo kan tí ó fi tootọ-tootọ fetisilẹ si awọn ero tabi awọn imọlara ti ẹnikeji kò dabi ẹni tí yoo huwa lọna ti imọtara-ẹni-nikan tabi lọna kan tí kò ní ṣee yipada rara.
27 Ijumọsọrọpọ tubọ tilẹ maa ndi ohun tí ô jẹ iyebiye sii bi tọkọtaya kan bá njiroro awọn ọran-iṣoro tọtun-tosi loju imọlẹ imọran Bibeli. Fun apẹẹrẹ, ipilẹ titayọ kan fun jijiroro owó tí nwọle fun idile ati 1 Timothy 6: 6-10, 17-19 ati Matthew 6:24-34. Awọn ìṣíníyè Iwe-mimọ pupọ sii nipa awọn nkan wìwọpọ nipa igbesi-aye idile ni a rí ninu iwe naa Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ. *
awọn iwewee ti iṣuna-owo ni a rí ní28 Niwọn bi ìṣíníyé Bibeli ti wá lati ọ̀dọ̀ alaṣẹ tí ô dara julọ lori ọran igbeyawo ati igbesi-aye idile, Jehofah Ọlọrun, ô bá ọgbọn ironu mu pe, ìmọran rẹ̀ lè ràn wa lọwọ ní ṣiṣiṣẹ fun aṣeyọri. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn tọkọtaya Kristian yika ayé ni wọn ti ṣe eyi pẹlu awọn abajade alayọ ninu igbeyawo wọn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 27 A tẹ̀ ẹ́ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society.
[Koko Fun Ijiroro]
Bawo ni a ṣe lè ṣiṣẹ fun aṣeyọri pupọ síi ninu igbesi-aye idile? (1-3)
Ipa wo ni fifi ara-ẹni sabẹ ìdé kó ninu igbeyawo akọkọ, eeṣe ti ó sì fi ṣe pataki? (4-6)
Kinni ohun tí a lè kẹkọọ rẹ̀ lati inu igbeyawo akọkọ nipa awọn obi ati awọn àna? (7-9)
Ẹkọ-àríkọ́gbọn tí ô gbeṣẹ wo ni a lè rí kọ lati inu Genesis nipa iye awọn tí a lè bá ṣe igbeyawo? (10, 11)
Kinni oju-iwoye tí Bibeli funni ní iṣiri rẹ̀ nipa ikọsilẹ? (12, 13)
Bawo ni awọn ọkọ ṣe lè fi imọran Bibeli tí ô wà fun wọn sílò? (14-16)
Kinni jíjẹ́ tí iyawo jẹ́ ’àṣekún’ fun ọkọ rẹ̀ yẹ ki ô tumọsi fun ọkọ kan? (17-19)
Bibeli rọ iyawo kan pe ki ô ní iru oju-iwoye wo fun ọkọ rẹ̀? (20-22)
Eeṣe tí awọn aya fi lè ní igbẹkẹle pe imọran yii yoo ṣeranwọ? (23, 24)
Ipa wo ni ijumọsọrọpọ nkô ninu aṣẹyọri idile? (25-28)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 80]
Nigba igbesi-aye mi gẹgẹ bi ọkọ kan, ni ọkunrin kan lati apá iwọ-oorun United States ṣalaye, gbogbo ohun tí mo fẹ̀ nipa ti ara ni mo ti ní tán patapata—ile kan tí ô jẹ oju ní gbèsé, awọn ọkọ̀ ayọkẹlẹ, awọn ọkọ̀ oju-omi ati awọn ẹṣin. Sibẹ awọn nkan wọnyi kò fun mi layọ. Iyawo mi kò ní ifẹ si awọn ohun tí mo ní ifẹ sí. Gbogbo igba ṣáá ni a maa njà. Mo maa nmu marijuana ki emi baa lè ní alaafia ọkàn.
Mo nlo ọpọ julọ ninu awọn opin-ọsẹ mi lẹhin ode ile ní ṣiṣọdẹ. Pẹlupẹlu, iṣẹ mi nmú mi lọ kuto ní ile. Eyi sún mi lọ sinu igbesi-aye panṣaga. Emi kò ronu pe iyawo mi nifẹẹ mi, nitori naa mo kò jade lọ tí mo sì nti ọ̀dọ̀ obinrin kan kọja si omiran titi ô fi jọ pe igbesi-aye mi kò lè ní itẹsiwaju mọ́.
Lakoko yii mo nka Bibeli diẹ. Ori karun iwe Ephesus fun mi ní ìdálòjú-igbagbọ lati gbiyanju lẹẹkan sii pẹlu iyawo mi. Mo mọ̀ pe kò fi igbakan rí tẹriba, bẹẹ ni emi pẹlu kò ti mú ipo iwaju tí òô baamu. Ṣugbọn ninu irin-ajo iṣowo ti ọsẹ ti ô tẹle e mo tún dẹṣẹ panṣaga.
Ọ̀rẹ̀ kan damọran pe bi oun bá ní ifẹ niti gidi ninu Ọlọrun, awọn Ẹlẹrii Jehofah lè ràn án lọwọ. Ô nbá ọrọ naa niṣo pe: Awọn Ẹlẹrii nṣeranwọ. Ọ̀kan ninu awọn alaboojuto ninu ijọ lo akoko pẹlu mi ní ṣiṣe ikẹkọọ Bibeli. Nitori iyipada nlánlà ninu ọna igbesi-aye mi, iyawo mi darapọ mọ mi ninu ikẹkọọ naa. Nisinsinyi fun igba akọkọ igbesi-aye idile wa jẹ alayọ, ani awọn ọmọbinrin wa mejeeji tilẹ rí iyatọ naa. Kò si awọn ọrọ lati ṣapejuwe ayọ̀ agbayanu ti iyawo mi ati emi ti rí ninu fifi Bibeli sílò ninu igbesi-aye wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 85]
ljumọsọrọpọ—ṣe pataki fun igbeyawo alayọ kan