Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ijọba-akoso kan Tí Yoo Mú Alaafia Kari-ayé Wá

Ijọba-akoso kan Tí Yoo Mú Alaafia Kari-ayé Wá

Ori 16

Ijọba-akoso kan Tí Yoo Mú Alaafia Kari-ayé Wá

IJỌBA-AKOSO kankan ha wà tí ó lè mú alaafia pipẹtiti wá sori ilẹ-aye bi? Tí ó lè pese ailewu ati omìnira kuro lọwọ iwa-ọdaran? Tí ó lè mú ki ọpọ yanturu ounjẹ didara wà larọwọto fun ẹni gbogbo? Tí ó lè fọ ayika mọ tónítóní ki ó sì ṣẹ́pá arun?

2 Ṣayẹwo akọsilẹ ẹda-eniyan ninu pápá ijọba-akoso. Awọn ijọba-akoso ọlọba kanṣoṣo, awọn dẹmọ ati awọn afẹ̀nifere tabi ti Tiwa-ntiwa. Kò sí eyikeyì ninu iwọnyi, tabi gbogbo wọn lapapọ, tí ó tíì ṣe awọn ohun didara tí a ṣẹṣẹ mẹnukan wọnyi; kii tilẹ ṣe ní iwọn kekere, ki a má wulẹ sọ nipa jakejado ayé rara. Bi o tilẹ rí bẹẹ, idi wà fun ọ lati ní ireti.

ỌLỌRUN PETE IJỌBA-AKOSO KAN—IJỌBA NAA

3 Jehofah Ọlọrun funraarẹ̀ ṣeleri lati funni ní ohun tí a nilo. Bawo ni a ṣe lè ní idaniloju eyiini? Ranti pe ní ibẹrẹ oun pete paradise kari-ayé kan ninu eyi tí awọn eniyan yoo ti lè gbadun alaafia ati ayọ̀. (Genesis 1:28; 2:8, 9) Nigba naa ni iṣọtẹ ṣẹlẹ ní ọgba Eden. Ṣugbọn iwọ ha ronu pe Ọlọrun yoo yọnda awọn ẹda alaimọriri lati bi ete rẹ̀ ṣubu? Dajudaju bẹẹ kọ. Nitootọ, kò pẹ́ kò jinna lẹhin tí Adam ati Efa ti ṣọtẹ, Jehofah sọ asọtẹlẹ oludande kan tí nbọ̀, ‘’iru-ọmọ” kan tí yoo rún awọn olùdí-alaafia-lọ́wọ́ wómúwómú ní ọrun ati lori ilẹ-aye. (Genesis 3:15) ’Ṣugbọn,’ ni iwọ lé ṣe kayefi, ’nibo ni “ijọba-akoso” ti wá sí ojutaye?’ “Iru-ọmọ” yẹn ni yoo di Messiah, Ọmọ-alade Alaafia, nipa ẹni tí a misi wolii Isaiah lati kọwe pe: “Ijọba (rẹ̀) yoo bisii, alaafia ki yoo sì ní ipẹkun.”—Isaiah 9:6, 7; 11:1-5.

4 Bẹẹ ni, ileri Jehofah jẹ fun iṣakoso kan eyi tí yoo ṣe ẹ̀tọ́ tí yoo sì mú alaafia wá. Bibeli pe iṣakoso yii ní ijọba Ọlọrun. Araadọta ọkẹ ni ó ti gbadura pe: “Baba wa . . . ki ijọba rẹ dé.” (Matthew 6:9, 10) Bi iwọ bá ti gba adura yii rí, iwọ ti ngbadura fun ijọba-akoso gidi kan—ijọba ọrun—eyi tí yoo mú alaafia wá si ayé. (Psalm 72:1-8) Ṣugbọn nigba wo ni Ọlọrun yoo mú ki ijọba-akoso naa bẹrẹ iṣẹ? Bawo ni oun yoo ṣe yàn tí yoo sì mú ki awọn alakoso rẹ̀ kún oju ìwọ̀n ohun tí a nbeere?

5 La awọn ọrundun já ni a ti ṣí awọn ete Ọlọrun payá. Fun apẹẹrẹ, oun fihan pe Messiah yoo dé nipasẹ Abraham, nipasẹ Jacob, ati pe yoo jẹ lati inu ẹya Judah. (Genesis 22:18; 49:10) Nigba naa ni Jehofah fi idi ijọba kan kalẹ lori Israel tí ó jẹ ti ilana alasọtẹlẹ awọn ohun tí nbọ̀. Israel jẹ orilẹ-ede ti a ṣakoso lati ọrun wá (tí Ọlọrun nṣakoso). Ọba wọn ni a sọ pe ó jokoo lori itẹ Jehofah. (1 Chronicles 29:23) Jehofah ni alaṣẹ patapata awọn ofìn ati ọpa-idiwọn rẹ̀ ndarì orilẹ-ede naa. Bi akoko ti nlọ, Ọlọrun sọ fun Ọba David pe nipasẹ idile rẹ̀ ni ẹnikan yoo ti wá tí yoo jẹ ọba pìpẹ titi.—Psalm 89:20, 21, 29.

6 Iru ẹkunrẹrẹ alaye bẹẹ ati awọn isọfunni Bibeli miiran nipa ọrọ-itan awọn ọmọ Israel ṣe pataki nitori pe wọn fihan pe Ọlọrun nfi ipilẹ alailewu tí ó bofinmu lelẹ fun ijọba naa tí nbọ. Ní ibamu pẹlu eyi, Ọlọrun lẹhin naa rán angeli kan si ọdọmọbinrin wunida kan ti ile David lati sọ fun un pe:

“Iwọ yoo sì bí ọmọkunrin kan, ìwọ yoo sì pe orukọ rẹ̀ ní Jesu. Oun yoo pọ̀, ọmọ Ọga-ogo Julọ ni a o maa pè é. (Jehofah) Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ David baba rẹ̀ fun un: yoo sì jọba ní ile Jacob titi ayé; ijọba rẹ̀ ki yoo sì ni ipẹkun’’.—Luke 1:28-33.

7 Eyi ni Messiah naa ti a sọtẹlẹ, ẹni tí Ọlọrun ṣeleri lati fi iṣakoso pipẹtiti fun lori ìran ẹda-eniyan. Kinni ohun tí a lè reti lati ọdọ Jesu gẹgẹ bi alakoso? Ẹ jẹ ki a ṣe ayẹwo diẹ ninu akọsilẹ rẹ̀.

8 Nigba gbogbo ni Jesu maa nní ifọkansin kíkún sí Ọlọrun ati ṣiṣe ifẹ-inu Rẹ̀. (Hebrew 10:9: Isaiah 11:3) Ọna kan tí oun gbà fi iduroṣinṣin rẹ̀ sí Ọlọrun hàn ni nipa kikọ abẹtẹlẹ ti ọlà tabi okiki silẹ, odikeji patapata ni eyi jẹ si ọpọlọpọ awọn alakoso ẹda-eniyan. (Luke 4:5-8) Oun kii bẹru lati di otitọ mú, nitori naa oun kò fawọsẹhin lati tú aṣiri agabagebe isin.—John 9:13-17; Mark 7:1-13.

9 Kristi pẹlu ní ifẹ ara-ọtọ fun araye, gẹgẹ bi otitọ-iṣẹlẹ ti fihan pe ó fi iwalaaye araarẹ̀ lelẹ fun ire tiwa. (John 13:34; 15:12, 13) Bi aanu ti ṣe é, Jesu wo alaisan san, jí awọn oku dide ó sì pese ounjẹ fun awọn alaini. (Luke 7:11-15, 22; 9:11-17) Oun tilẹ tún ní agbara lori awọn iṣẹlẹ kan tí wọn rekọja agbara ẹda-eniyan oun sì lò wọn lati ṣanfaani fun awọn eniyan. (Matthew 8:23-27) Sibẹ oun jẹ ẹni tí ó ṣee sunmọ, ani awọn ọmọde paapaa wà ní irọrun pẹlu ọkunrin onirẹlẹ-ọkàn yii.—Matthew 11:28-30; 19:13-15.

10 Ronuwoye lori ibukun níní in gẹgẹ bi Alakoso, pẹlu awọn animọ yiyẹ ati agbára-iṣe rẹ̀! Eyiini ni ireti rere nlánlà tí awọn olujọsin Jehofah ní.

IṢAKOSO LATI ỌRUN WÁ

11 Nigba tí gomina Rome beere lọwọ Jesu nipa ipo-ọba rẹ̀, oun fèsì pe: “Ijọba mi kii ṣe ti ayé yii.” (John 18:36) Jesu pa ara rẹ̀ mọ́ laidasi tọtun-tosi patapata niti ọran iṣelu awọn orilẹ-ede, tí ó nfi apẹẹrẹ lelẹ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (John 6:15; 2 Corinth 5:20) Siwaju sii, kii ṣe ete Ọlọrun fun aye. Oun yoo nilati ṣakoso lati ọrun wá, nibi tí oun yoo ti lè lo ipo-aṣẹ tí ó ga ju ẹda-eniyan lọ, ọla-aṣẹ agbaye.

12 Pẹlu ireti rere yii lọkàn, lẹhin tí Jesu ti kú bi olootọ si Ọlọrun, Baba rẹ̀ jí i dide si ìyè gẹgẹ bi ẹda ẹmi aileeku. (Iṣe 10:39-43; 1 Corinth 15:45) Kristi farahan fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ó sì fun wọn ní idaniloju pe oun walaaye oun sì wà lẹnu iṣẹ. Lẹhin naa ni Jesu goke re ọrun. Nipa eyi, apostle Peter kọwe pe: “Ẹni tí ó ti lọ si ọrun, tí ó sì nbẹ ní ọwọ ọtun Ọlọrun; ati awọn angeli, ati awọn ọlọla, ati awọn alagbara sì ntẹriba fun un.”—1 Peter 3:22; Matthew 28:18.

13 Bẹrẹ lati akoko naa, ní 33 C.E., Kristi bẹrẹsi ṣakoso lori ijọ Kristian, awọn ọmọlẹhin rẹ̀ sì fi tayọtayọ jẹwọ ipo-oluwa ati ipo ọrun rẹ̀. (Colossae 1:13, 14) Sibẹ kii ṣe ete Ọlọrun fun Jesu lati bẹrẹsìi ṣakoso lori ayé araye ati agbaye nigba naa.

14 Ọlọrun yọnda fun awọn eniyan lati rí awọn eso iṣakoso ẹda-eniyan funraawọn. Nipa bayii, Kristi nilati duro titi di akoko kan tí a yàn fun iṣakoso Ijọba lori ilẹ-aye. Apostle Paul kọwe pe: “Ṣugbọn oun, lẹhin igba tí ó ti rú ẹbọ kan fun ẹṣẹ titilae, ó jokoo ní ọwọ ọtún Ọlọrun. Lati isinsinyi lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọta rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀”—Hebrew 10:12, 13.

15 Ṣugbọn bi Jesu bá jẹ alaiṣee fojuri ní ọrun, bawo ni a o ti ṣe mọ̀ nigba tí akoko naa bá dé fun un lati bẹrẹsi ṣakoso? Bi a ti jiroro rẹ̀ ninu ori-iwe iṣaaju, Jesu funni ní “ami” tí a lè fojuri ki awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lori ilẹ-aye baa lè mọ̀ nigba tí akoko naa bá dé. (Matthew 24:3-31) Awọn ogun, ìyàn, awọn ìsẹ̀lẹ̀, inunibini si awọn Kristian ati iwaasu ihinrere Ijọba naa ní gbogbo ayé eyi tí a ti rí lati igba Ogun Agbaye Kìn-ín-ní (1914-1918) kàn án níṣòó pe a ngbé ní ipari-opin eto-igbekalẹ awọn nkan. Awọn iṣẹlẹ wọnyi tún fihan pẹlu pe Kristi ti nṣakoso nisinsinyi ní ọrun, nitori, lẹhin ṣiṣapejuwe ogun kan ní ọrun lodisi Satan, Bibeli wipe:

“Nigba yii ni igbala dé, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọlá ti Kristi rẹ̀. ... . Nitori naa ẹ maa yọ, ẹyin ọrun, ati ẹyin tí ngbé inu wọn. Egbé ni fun ayé ati fun òkun! Nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ yin wá ní ibinu nla, nitori ó mò pe igba kukuru ṣáá ni oun ní.”—Iṣipaya 12:7-12.

16 Fun idi yii, Jesu Kristi ti nṣakoso nisinsinyi. Eyi tumọsi pe yoo jẹ kiki “akoko kukuru” tí oun yoo fi lo ipo-aṣẹ rẹ̀ lati ké gbogbo atako sì Ijọba naa kuro, titi kan Eṣu ati gbogbo awọn ijọba-akoso atọwọda eniyan. (Daniel 2:44) Nigba naa a o lè yọ̀ ninu iṣakoso Ijọba Ọlọrun tí yoo mú alaafia pipẹtiti wá.

AWỌN ALAJUMỌ-ṢAKOSO NINU IJỌBA NAA

17 Apá miiran ninu Ijọba naa tí ó fanimọra ni a ṣipaya ninu Bibeli. Daniel 7:13, 14 fun wa ní apejuwe bi Ọmọkunrin Ọlọrun ṣe ngba “iṣakoso ati ọlá ati ijọba.” Iran-ifihan naa sọ pe:

“Ati ijọba, ati agbara ijọba ati ipá gbogbo ijọba ní gbogbo abẹ-ọrun, ni a o sì fi fun eniyan, awọn eniyan mímọ ti Ọga-ogo, ìjọba ẹni tiiṣe ijọba ainipẹkun, ati gbogbo awọn alakoso ni yoo maa sìn ín, tí wọn yoo sì maa tẹriba fun un.”—Daniel 7:27.

Nitori naa Ọlọrun pete rẹ̀ fun Jesu Kristi lati ní awọn alajumọ-ṣakoso. Eyiini tumọsi pe awọn ẹda eniyan kan yoo lọ si ọrun. Nigba tí Jesu wà lori ilẹ-aye oun bẹrẹsi ṣe yíyàn awọn ọkunrin ati obinrin lati di alajumọ-ṣakoso pẹlu rẹ̀. Oun sọ pe oun nlọ si ọrun lati lọ pese àyẹ̀ silẹ fun wọn.—John 14:1-3.

18 Eyi ṣeranwọ lati mú un ṣe kedere ohun kan tí ọpọlọpọ awọn tí wọn ti nfi gbogbo igbesi-aye wọn lọ si ṣọọṣi kò loye rẹ̀: Lapakan, Bibeli fihan pe Ọlọrun pete fun araye lati gbé lori ilẹ-aye; sibẹ, lápá keji, Bibeli sọ nipa awọn ẹda-eniyan kan tí nlọ si ọrun. Bawo ni eyi yoo ṣe ṣiṣẹ? Ó dara, Ọlọrun ti ṣeleri lati mú awọn ẹda-eniyan kan lọ si ọrun lati wà pẹlu Ọmọkunrin rẹ̀ ninu iṣakoso Ijọba. Ṣugbọn ayé yoo jẹ paradise kan tí ó kún fun awọn eniyan alayọ, alalaafia.—Wo Psalm 37:29: Isaiah 65:17, 20-25.

19 Ẹni melo ni yoo lọ si ọrun gẹgẹ bi apakan akoso Ijọba naa? Jesu funni ní itọkafihan, ní wiwipe: “Má bẹru, agbo kekere; nitori dídùn inu Baba yin ni lati fi ijọba fun yin.” (Luke 12:32) Bẹẹ ni, iye naa mọniwọn. Iwe Iṣipaya fihan pe awọn wọnni tí a “rapada lati inu awọn eniyan wá” lati ṣakoso pẹlu “Ọdọ-agutan” naa (Jesu Kristi) ni iye wọn jẹ 144,000. (Iṣipaya 14:1-5) Eyiini kò ṣoro lati loye. Ani awọn ijọba-akoso eniyan kan ní ẹgbẹ awọn eniyan tí a yàn lọkunrin lobinrin tí wọn yoo lọ si olu-ilu gẹgẹ bi apakan ijọba-akoso naa.

20 Sugbọn Ọlọrun kò fi i silẹ fun awọn ẹda-eniyan lati pinnu awọn tí yoo lọ si ọrun. Oun ni ó nyàn wọn. (1 Peter 2:4, 5, 9; Rome 8:28-30; 9:16) Nigba tí Ọlọrun yan apostle Paul, oun tú ẹmi rẹ̀ jade lé e lori, tí ó fun Paul ní ìdálójú naa pe oun yoo jẹ apakan “ijọba ọrun” naa. (2 Timothy 4:18) Paul kọwe pe: “Ẹmi tikaraarẹ̀ ni ó nbá ẹmi wa jẹrii pe ọmọ Ọlọrun ni awa iṣe. Bi awa bá sì jẹ ọmọ, njẹ àjògún ni awa; àjògún Ọlọrun ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi.”—Rome 8:16; 2 Corinth 1:22; 5:5.

21 Kiki iwọnba diẹ pere ninu awọn olujọsin Ọlọrun ni a ti yàn fun ìyè ní ọrun, niwọn bi ó ti jẹ ete Ọlọrun fun araye lati walaaye ninu ayọ lori ilẹ aye. Jesu ni ẹni akọkọ tí a gbé lọ si ọrun. (Hebrew 6:19, 20; Matthew 11:11) Lẹhin naa Ọlọrun nbá ṣiṣe yíyàn 144,000 yoku niṣo. Kinni ohun tí yoo ṣẹlẹ nigba tí iye naa bá pé?

22 Lẹhin tí a fun un ní iran-ifihan nipa iye tí ó mọniwọn naa (144,000) tí ó wà ní ọrun pẹlu Kristi, a fi “ogunlọgọ eniyan, tí ẹnikẹni kò lè kà” han apostle John. (Iṣipaya 7:4, 9, 10) Ọlọrun yoo daabobo awọn wọnyi la opin oniparun eto-igbekalẹ awọn nkan isinsinyi já. Wọn ní ireti rere agbayanu ti iye ayeraye lori ilẹ-aye, ireti rere kan naa ti wà fun awọn ẹni-igbagbọ iru bii Noah, Abraham ati David, tí wọn ti kú ṣaaju ki Ọlọrun tó ṣí ọna iwalaaye ti ọrun silẹ fun awọn 144,000 naa.—Iṣe 2:34.

AWỌN IDI FUN ÌGBỌKÀNLÉ NINU AWỌN ALAKOSO NAA

23 Lonii pupọ julọ awọn eniyan ní ìgbọkànlé bín-ín-tín ninu awọn alakoso wọn. Bi o ti wu ki o ri, awọn wọnni tí yoo ṣakoso ninu Ijọba Ọlọrun yatọ patapata si awọn alakoso ayé. La awọn ọrundun já ni Ọlọrun ti nyan awọn eniyan tí wọn ti fi ẹri igbagbọ wọn hàn. Labẹ oniruuru iṣoro ati idanwo, wọn ti rọ̀ timọtimọ mọ ohun tiiṣe otitọ ati ododo. Wọn jere ìgbọkànlé Ọlọrun, nitori naa awa kò ha ní ní ìgbọ́kànlé ninu wọn bi?

24 Ati pẹlu, ti pe wọn ti jẹ ẹda-eniyan tẹlẹri yoo jẹ ki wọn lè loye ki wọn sì kẹdun pẹlu wa. (Fiwe Hebrew 4:15, 16.) Wọn mọ ohun tí ó tumọsi lati ní àárẹ̀, idaamu, irẹwẹsi. Wọn mọ isapa tí a nilo lati tubọ lè di onisuuru, oninuure ati alaaanu. Awọn kan ninu wọn sì jẹ obinrin; wọn loye awọn imọlara ati awọn aini ara-ọtọ fun obinrin lori ilẹ-aye.—Galatia 3:28.

25 Araadọta ọkẹ awọn Ẹlẹrii Jehofah lonii nfi ẹri ìgbọ̀kànlé wọn ninu Kristi ati awọn alajumọ-ṣakoso rẹ̀ hàn wọn sì nfi bi Ijọba naa ti jẹ gidi sí wọn hàn. Wọn nṣe eyi nipa jíjẹ ọmọ-abẹ aduroṣinṣin ti ijọba Ọlọrun. (Owe 14:28) Wọn tẹwọgba wọn si nsọrọ-ìyìn áwọn ofin rẹ̀ tí a kọ sinu Bibeli funni, tí wọn sì fi tootọ-tootọ gbagbọ pe isin Kristian nì ọna igbesi-aye tí o dara julọ. Wọn nṣe alabapin ninu itolẹsẹẹsẹ idanálẹkọọ akoso yii. Bibeli ní pataki ni iwe-ikẹkọọ, tí a nlò papọ pẹlu awọn ìṣẹ itọka Kristian ati awọn ohun iranlọwọ fun ikẹkọọ. Ninu awọn ipade ijọ wọn nkẹkọọ ohun pupọ nipa Ijọba naa ati igbe-aye Kristian. Wọn sì ngbé ìtolẹsẹẹsẹ idanilẹkọọ naa lọ sọdọ awọn ẹlomiran nipa kikọni ní gbangba ati ninu awọn ile.—Iṣe 20:20.

26 Jesu sọ pe apakan ami “awọn ọjọ ikẹhin” yoo jẹ: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si dé.” (Matthew 24:14) Ṣaaju ki Jesu tó goke re ọrun oun tẹnumọ aini naa fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati ní ipin alakikanju ninu iṣẹ ajihinrere yii.—Matthew 28:19, 20; Iṣe 1:8.

27 Awọn Kristian lonii mọ̀ pe ṣiṣe alabapin ninu iṣẹ iwaasu ati ikọni yii jẹ ọna pataki kan ninu eyi tí wọn lè ṣe aṣefihan ifẹ wọn fun Ọlọrun ati fun awọn aladugbo wọn. (Mark 12:28-31) Iwalaaye wemọ ọn, nitori naa ó jẹ ẹru-iṣẹ wiwuwo. (Iṣe 20:26, 27; 1 Corinth 9:16) Ó tún jẹ orisun ayọ ati itẹlọrun oniwọtunwọnsi. (Iṣe 20:35) Inu awọn Ẹlẹrii Jehofah yoo dùn lati ràn ọ lọwọ lati kọ́ awọn ẹlomiran nipa Ijọba Ọlọrun tí nṣakoso.

[Koko Fun Ijiroro]

Awọn ohun fífẹ wo ni awọn ijọba-akoso ẹda-eniyan kò tíì lè ṣe aṣeyọri rẹ̀? (1, 2)

Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Jehofah pete ijọba-akoso kan tí yoo mú alaafia wá? (3, 4)

Awọn igbesẹ wo ni Jehofah gbé ní pipese Ijọba naa? (5, 6)

Eeṣe tí a fi lè ní idaniloju pe Jesu yoo jẹ alakoso ara-ọtọ kan? (7-10)

Awọn idi wo ló wà lati mọ pe Jesu kò nilati ṣakoso lati ori ilẹ-aye? (11, 12)

Awọn idi wo ló wà niti akoko tí Kristi bẹrẹsi ṣakoso lori araye? (13-16)

Tani yoo ṣakoso pẹlu Jesu ninu Ijọba naa? (17, 18)

Awọn melo ni yoo lọ si ọrun, eesitiṣe tí kò fi jẹ gbogbo araye? (19-22)

Awọn idi wo ni a ní fun ìgbọ́kànlé ninu awọn alajumọ-ṣakoso wọnyi? (23, 24)

Bawo ni a ṣe lé fi itilẹhin wa fun Ijọba naa hàn? (25-27)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 151]

“Ikuna lati dá ojulowo ipilẹ fun alaafia ayé silẹ ...ni taarata ni a lè ṣiro sọrùn kíkọ̀ ti awọn orilẹ-ede kọ̀, awọn orilẹ-ede nlanla ní pataki, lati tẹwọgba ọla-aṣẹ kan tí ó lé sọ ohun ti wọn yoo ṣe fun wọn ninu awọn igbokegbodo-iṣẹ laarin awọn orilẹ-ede.

“Eyi, nigba naa, jẹ ipilẹ ipenija naa lonii—bi a o ṣe dá ọla-aṣẹ gbogbo ayé silẹ lati pa alaafia mọ eyi tí ò ní lẹhin rẹ̀ ìgbọkànlé awọn eniyan ayé.”—Onkọwe-alatunṣe Norman Cousins, ninu ”Saturday Review.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 159]

OTITỌ PATO NIPA IJỌBA-AKOSO

“Awọn ohun ija wa ni kùmọ̀, ọ̀gọ tí a yọ òjé sí lara, awọn ẹ̀wọ̀n ati ibọn,” ni Stelvio sọ funni, ẹni tí ó jẹ ogboṣaṣa ninu ìwọde-iṣelu ní awọn ọdun 1970 ní iha guusu Europe. Ninu awọn àgọ ìkòkò tí ó dabi ti ologun oun ti kẹkọọ nipa bi a ti nṣeto awọn jàndùkú ki wọn sì maa bá ogun jíjà ní ilu-nla niṣo.

Ṣugbọn lẹhin awọn ọdun diẹ iyipada dé. Ọ̀kan ninu awọn Ẹlẹrii Jehofah ṣe ibẹwo si ile Stelvio, fun kíkọ ọ lẹkọọ Bibeli. Ki sì ni iyọrisi rẹ̀? “Ó là mi loju lati ríi pe ifẹ orilẹ-ede ẹni ati awọn ẹgbẹ iṣelu npín awọn eniyan níyà. Mo kẹkọọ lati inu Bibeli pe Ọlọrun dá gbogbo orilẹ-ede lati inu ọkunrin kanṣoṣo wá, lati maa gbé lori ilẹ-aye. (Iṣe 17:26) Imọ yii jẹ agbara asonipọṣọkan. Ò sọ mi di ominira kuro ninu kikorira awọn ẹlomiran kiki nitori pe awọn ero wọn niti ọran iṣelu yatọ.”

Ọkunrin yii tí é ti fi igba kan rí jẹ ogboṣaṣa ninu ìwọde-iṣelu fikun un pe: “Mo bẹrẹsi bi ara mi leere pe, Bawo ni eniyan ṣe lè yanju awọn ọran-iṣoro rẹ̀ lae nipasẹ iṣelu, niwọn bi iṣelu funraarẹ̀ ti ṣokunfa iyapa laarin araye? Fun awọn eniyan lati parapọ, awọn idi fun iyapa nilati pòórá. Mo ti rí awọn eniyan aláwọ̀ dudu ati funfun laarin awọn Ẹlẹrii Jehofah tí a nbaptisi ninu omi kan naa, awọn onisin Protestant ati Catholic tẹlẹri ní Ireland ṣíwọ kikorira ara wọn, awọn Arab ati Jew padepọ nigba tí Ogun Ọlọjọ-Mẹfa ṣì njà lọwọ. Mo ti kẹkọọ lati nifẹẹ awọn wọnni tí mo ti korira tẹlẹri.

“Kò sí ẹnikẹni tí ó lè sọ pe ijọba Ọlọrun, tí awọn Ẹlẹrii Jehofah nyánhànhàn fun, jẹ àlá àbámodá tí kò lẹ̀ ṣẹ, nitori pe ní lọwọlọwọ bayii ẹgbẹ-agbo awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ti wà tí a sopọṣọkan labẹ ijọba yẹn. Fi fi awọn ilana-ipilẹ Bibeli sílò ti mú awọn iyọrisi wá iru eyi tí ọwọ ẹgbẹ isin, ti iṣelu tabi ti ẹgbẹ-oun-ọgba kankan kò tìi tẹ̀ rí.

“Sí awọn wọnni tí, bii temi nigba atijọ, wọn njijakadi lati mú idajọ-ododo, alaafia ati wíwà létòlétò ẹgbẹ-oun-ọgba wá, mo sọ pe: ’Ẹ tẹwọgba otitọ pato ki ẹ sì gbà pe ó ti di àbàtì fun eniyan lati mú wọn wá. Ṣugbọn, ẹ wo awọn Ẹlẹrii Jehofah. Wọn kò ha ti ṣẹpá awọn ọran-iṣoro ogun, awọn iyapa iṣelu, kẹlẹgbẹ-mẹgbẹ, alaafia ati iṣọkan bi? Awọn eniyan ngbẹkẹle eniyan wọn sì nní awọn ọran-iṣoro. Awọn Ẹlẹrii Jehofah njuwọsilẹ-tẹriba fun ijọba Ọlọrun wọn sì ti yanju awọn ojulowo ọran-iṣoro igbe-aye.”