Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ijumọsọrọpọ Pẹlu Ilẹ-ọba Ẹmi-airi

Ijumọsọrọpọ Pẹlu Ilẹ-ọba Ẹmi-airi

Ori 13

Ijumọsọrọpọ Pẹlu Ilẹ-ọba Ẹmi-airi

“AGBARA-IDARI lati jumọsọrọpọ tubọ njinlẹ sii.” Pẹlu gbolohun yẹn, iwe naa Machines bẹrẹ akori kan lori radio. Nipasẹ radio a lè jumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan ní ayika òbírí-ayé tabi ki a tún gbọ́ ọrọ lati ẹnu awọn onimọ-ijinlẹ ofuurufu ninu gbalasa ojude ofuurufu.

2 Ijumọsọrọpọ radio nisinsinyi ti jẹ apakan igbesi-aye tí a tẹwọgba. Ṣugbọn Ọpọlọpọ eniyan ti dagunla tabi ní àṣìlóye iru ijumọsọrọpọ kan tí ó tubọ ṣe pataki jù—pẹlu ìlẹ-ọba ẹmi-airi.

BÍBÁ ẸLẸDAA NAA SỌRỌ

3 Awọn ọrundun ṣaaju ki a tó mú radio jade, Ọba David kọwe pe:

“Fi eti si ọrọ mi, [Jehofah] . . . fi eti sí ohùn ẹkún mi, Ọba mi ati Ọlọrun mi; nitori pe ọ̀dọ̀ rẹ ni emi yoo maa gbadura sí.”—Psalm 5:1, 2.

Kò ha dabi ẹnipe ó lọgbọn-ninu pe ọlọgbọn giga julọ ní gbogbo agbaye lè ’fetisilẹ’ si ohun tí a nwi ninu adura bi oun bá nifẹẹ lati ṣe bẹẹ? Kò ha sì bọgbọnmu fun wa lati wá iranlọwọ sọdọ Ọlọrun, ẹni tí ó lè fun wa ní itọsọna tí ó dara julọ bi?—Psalm 65:2.

4 Agbọ́rọ̀-sáfẹ́fẹ́ kan ati alátagbà-ọrọ kan ṣe pataki ninu ijumọsọrọpọ radio. Ṣugbọn kinni ohun tí a nilo lati lè bá Jehofah sọrọ ninu adura? Ohun akọkọ tí a beere ni igbagbọ. “Ẹni tí ó ntọ Ọlọrun wá kò lè ṣaigbagbọ pe ó nbẹ, ati pe oun ni olusẹsan fun awọn tí ó fi ara balẹ wá a.” (Hebrew 11:6) Ati pẹlu, ẹnikan gbọdọ wà ní iṣọkan pẹlu awọn ọpa-idiwọn ọna-iwahihu ati awọn ọna Ọlọrun. Bi bẹẹ kọ Ọlọrun kò tún ní fetisilẹ si i mọ́ bi eniyan aduroṣinṣin kan kò ṣe ní fetisilẹ si itolẹsẹẹsẹ radio kan tí 6 ṣaiwuni lori ọna-iwahihu.—1 John 3:22; Isaiah 1:15.

5 Jehofah kò ní aṣa-iṣe kan ti ó duro gbagidi fun awọn adura tí wọn ṣe itẹwọgba. Yala iwọ gbadura soke tabi ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, oun lè “gbọ́.” Iwọ lè gbadura nigba tí o bá dide duro, jokoo, kúnlẹ̀ tabi dubulẹ lori ibusun. (1 Samuel 1:12, 13; 1 Awọn Ọba 8:54) Kò sí awọn ọrọ pataki tabi ede isin tí a nilo. Ohun tí ó ṣe pataki jù ni iṣotitọ ati ẹmi irẹlẹ. Ṣakiyesi bi Jesu ṣe ṣapejuwe eyi ninu Luke 18:10-14.

6 Lẹnikọọkan, a lè tọ Jehofah lọ ninu adura nigbakuugba. Bi o ti wu ki o ri, oun tún ntẹwọgba awọn adura alapapọ, iru bii lati inu ijọ Kristian kan. Nipa ifetisilẹ wọn si adura ní awọn ipade ijọ awọn kan tí kò tíì gbadura rí ti kẹkọọ bi wọn ṣe lè lo ijumọsọrọpọ pataki yii. Awọn agbo idile, pẹlu, lè wọn sì nilati gbadura papọ. Anfaani kan ni lakoko ounjẹ, ní titẹle apẹẹrẹ Jesu ninu didupẹ lọwọ Ọlọrun fun ounjẹ naa tí oun mú ki ó wà larọwọto.—Mark 8:6.

7 Iwọ lè mọ awọn ẹni tí wọn ti gbadura ṣugbọn tí wọn ṣàròyé pe awọn kò rí idahun. Eeṣe? Kristi sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ohunkohun tí ẹyin bá beere lọwọ Baba ní orukọ mi, oun yoo fì fun yin.” Jesu Kristi, kii ṣe ẹlomiran, ni ọna tí a ngbà dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Iṣoro naa ha lè jẹ ikuna lati mọriri eyi bi? (John 16:23; 14:6) Ati pẹlu, kinni ohun tí Jesu ní lọkan nipa “ohunkohun”? Apostle John fihan pe ó jẹ “ohunkohun” tí ó ’wà ní ibamu pẹlu ìfẹ-inu Jehofah.’ Yoo nira fun wa lati reti pe ki Ọlọrun ododo kan tẹwọgba awọn adura tí abarebabọ wọn jẹ ti ohun òdì, ẹlẹgbin tabi ti ìwọra. (1 John 5:14) Sibẹ ọpọlọpọ ngbadura fun ọrọ̀ oju-ẹsẹ tabi agbara lori awọn ẹlomiran. Kò yanilẹnu rara, nigba naa, pe Ọlọrun kò dahun si iru awọn adura bẹẹ. Awọn ibeere fun awọn aini ara-ẹni niti gidi nilati wá tẹle awọn ọran iru bii ki a ṣe ìfẹ Ọlọrun lori ilẹ-aye.—Matthew 6:9-11.

8 Adura nfun wa ní awọn anfaani lati sọrọ pẹlu Ọlọrun bii pe pẹlu baba onifẹẹ kan, lati ṣalaye ayọ̀ wa, awọn iṣoro ati awọn aini wa. Bi o kò bá tíì maa ṣe eyiini deedee, maṣe pa á tì sapakan. Níní ibatan tí ó ṣee gbẹkẹle pẹlu Ọlọrún ati níní ìjumọsọrọpọ pẹlu rẹ̀ nigbakuugba yoo fun ọ ní ọpọlọpọ alaafia ọkàn yoo sì mú ayọ̀ wá. Iwọ lè bọ́ ajaga kuro lọrùn ara rẹ, ní níní idaniloju idunnu rẹ̀ sí ọ.—Psalm 86:1-6; Philippi 4:6, 7.

IDAHUNPADA LATI ILẸ-ỌBA ẸMI-AIRI

9 Ọkan ninu awọn akori pataki fun adura nilati jẹ aini wa fun ọgbọn ati itọsọna lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun. (Psalm 27:11; 119:34-36; James 1:5) Lọna wo ni Ọlọrun yoo gbá dahunpada? Nigba atijọ, lẹẹkọọkan oun maa nfunni ní isọfunni ẹnu, ní sisọrọ nipasẹ awọn, angeli tabi awọn wolii eniyan. Ṣugbọn apostle Paul sọ pe nisinsinyi Ọlọrun “ti ipasẹ Ọmọ[kunrin] rẹ̀ bá wa sọrọ,” awọn ẹkọ ati ọna igbesi-aye ẹni tí a tò lẹsẹẹsẹ ninu Bibeli. (Hebrew 1:1, 2; 2:1-3; John 20:31) Nitori naa, dipo ki a maa reti pe ki Ọlọrun bá wa sọrọ funraarẹ̀, a nilati wá iranlọwọ nipasẹ ọna tí oun ti yàn lati lò, Bibeli. Pẹlu eyi ninu ero-inu wa, a nilati jẹ ki ikẹkọọ alaapọn ninu Ọrọ rẹ̀ tẹle awọn adura fun itọsọna. (Owe 2:1-5) Afikun iranlọwọ wà larọwọto nipasẹ awọn Kristian olufọkansin tí wọn npade deedee lati kẹkọọ ki wọn sì jiroro Bibeli.—2 Timothy 2:1, 2.

10 Ní idahun si awọn adura wa, Ọlọrun funraarẹ̀ tún lè ràn wa lọwọ nipasẹ ẹmi rẹ̀. Pẹlu eyi, oun maa nṣeranwọ fun awọn Kristian lati loye Ọrọ rẹ̀ ki wọn sì fi i sílò. (John 16:7-13) David gbadura pe: “Kọ́ mi lati ṣe ohun tí ó wù ọ. . . . Jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ní ilẹ tí ó tẹ́jú.”—Psalm 143:10.

AWỌN ẸNI BURUKU HA WA NINU ILẸ-ỌBA ẸMI-AIRI BI?

11 Kii ṣe kiki pe Bibeli fun wa ní idaniloju pe Jehofah, Ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn angeli walaaye ninu ilẹ-ọba ẹmi-airi nikan ni, ati pe awa lè jumọsọrọpọ pẹlu Ọlọrun nipasẹ adura. Gan-an gẹgẹ bi Iwe-mimọ ti fihanni lọna tí ó ṣee fọkàntẹ̀ pe awọn ọlọgbọn-òye ẹni ẹmi wà tí wọn buru gidigidi nisinsinyi, ní pàtó Satan ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀.

12 Awọn eniyan kan ní imọlara pe “Eṣu” wulẹ jẹ àtagbà lasan lati inu igbagbọ ninu ohun asan ti igba laelae tabi àlá lasan. Awọn miiran lérò pe nigba tí Bibeli bá mẹnukan “Satan” ó wulẹ ntọkasi ilana-ipilẹ iwa ibi kan.

13 Bi o ti wu ki o ri, Matthew 4:1-11 sọ fun wa nipa akoko kan nigba tí Satan dojú awọn idanwo pato mẹta kan kọ Jesu. Dajudaju, Satan tí a tọkasi nihin kii ṣe ilana-ipilẹ iwa ibi ninu Jesu, nitori pe Ọmọkunrin Ọlọrun jẹ ominira kuro lọwọ ìwa ibi ati ẹṣẹ. (Hebrew 7:26; 1:8, 9) Bẹẹ kọ, Satan jẹ ẹni gidi kan. Ẹri eyi ni a tún mujade pẹlu ninu akọsilẹ Job 1:6-12, eyi tí ó sọ nipa bi Satan ṣe farahan niwaju Jehofah.

14 Ṣugbọn nipa ti ipilẹṣẹ Satan nkọ́? Awa mọ̀ pe Jehofah ni Ẹlẹdaa ohun gbogbo ati pe “pípé ni iṣẹ rẹ̀.” (Deuteronomy 32:4; Iṣipaya 4:11) Nigba naa kò ha bojumu pe Satan ti gbọdọ fi igba kan rí jẹ ẹni ẹmi aduroṣinṣin tí Jehofah Ọlọrun dá papọ pẹlu awọn angeli miiran? Bawo, nigba naa ni oun ṣe di oníbàjẹ́? James 1:14, 15 fun wa ní ìlàlóye: Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwo, nigba, ti a bá, ti ọwọ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ. Njẹ, ìfẹkufẹ naa nigba tí ó bá loyun, a bí ẹṣẹ.”

15 Lati inu ohun tí ó ti ṣẹlẹ laarin awọn eniyan, awa mọ̀ pe ẹnikan tí ó wà ní ipo tí a gbẹkẹle paapaa lè rí bi oun ṣe lè ṣe àṣìlò ipo kan lati lè ní agbara tí ó pọ̀ sii. Ó farahan pe ohun tí ó ṣẹlẹ niyii pẹlu ọ̀kan ninu awọn angeli Ọlọrun. Nitori pe ó ni ominira iwa híhù, ẹda ẹmi yii yan ipa-ọna buburu, boya ní gbigbagbọ pe oun lè dabi Ọlọrun, ki awọn ẹda-eniyan sì maa tẹle e lẹhin. Ohun tí ó ṣẹlẹ yii ni a lè fiwera pẹlu iriri ọba Tyre, gẹgẹ bi a ti sọ ọ funni ninu Ezekiel 28:1-19. Ọkunrin yii ti wà ní ipo ojurere ní isopọ pẹlu Israel igbaani, ṣugbọn ó bẹrẹsi wúgẹ̀ pẹlu igberaga, tí ó sì yọrisi iṣubu. rẹ̀, Bakan naa, igberaga yọrisi iparun ẹni naa tí ó sọ ara rẹ̀ di Satan, alatako si Ọlọrun.

16 Liloye wíwà Satan tanmọlẹ sori awọn ohun tí ó ṣẹlẹ ninu ọgba Eden eyi tí ó yọrisi didi alaipe wa, ẹlẹṣẹ, tí nṣaisan tí ó si nkú. Pẹlu ọgbọn rẹ̀ tí ó tayọ ti ẹda-eniyan, Satan lo ejo-nla kan lati bá Efa sọrọ irọ́, àrékendá tí ó buru jáì. (Genesis 3:1-5) Bẹẹ gẹgẹ, Iṣipaya 12:9 pe Satan ní “ejo laelae nì.” Jesu sì sọ pe ẹni yii kò “duro ninu otitọ,” ṣugbọn ó di baba eke ati apaniyan.?”—John 8:44.

17 Satan nikan kọ ni ẹda ẹmi tí ó ṣọtẹ. Ọrọ-itan inu Genesis 6:1-3 ṣalaye pe ní ọjọ Noah awọn angeli kan—boya iṣọtẹ Satan ni ó ru wọn soke—gbé awọn ara eniyan wọ̀ ki wọn baa lè ní igbadun ibalopọ takọtabo pẹlu awọn obinrin. Eyi lodisi iwa adanida ó sì dibajẹ. (Jude 6, 7) Nigba tí Ọlọrun gbá iwa ibi kuro lori ilẹ-aye nipasẹ ikun-omi tí ó kari ayé, awọn angeli alaigbọran wọnyi pada si ilẹ-ọba ẹmi-airi, ṣugbọn nisinsinyi ní iha ọ̀dọ̀ ti Satan, gẹgẹ bi awọn ẹmi-eṣu. (2 Peter 2:4, 5) Awọn itan arosọ Greek ati Rome tí a mọ̀ daradara nipa awọn ọlọrun tí nlọ síwá-sẹhin laarin ọrun ati ilẹ-aye lè jẹ awọn áyídáyidà awọn otitọ-iṣẹlẹ nipa awọn angeli alaigbọran naa gẹgẹ bi a ti sọ ọ funni ninu Bibeli.

AGBARA-IDARI BURUKU LATI ILẸ-ỌBA ẸMI-AIRI

18 Awọn ẹmi buruku kò ní inudidun si ire wa ṣugbọn wọn fi àáké kọ́rí lati maa tanjẹ ki wọn sì maa ṣi awọn eniyan lọna, tí wọn nyí wọn pada kuro lọdọ Ọlọrun. Apostle Paul pe Satan ní “ọlọrun eto-igbekalẹ awọn nkan isinsinyi” ẹni tí ó “ti sọ ọkàn awọn tí kò gbagbọ di afọju” nitori ki wọn má baa lè kẹkọọ “ihinrere” nipa Kristi. (2 Corinth 4:4, NW) Ó ti ṣe aṣeyọri gidigidi ninu eyi.

19 Ọgbọn-ẹwẹ kan tí oun ti lò ni gbígbé oju-iwoye naa ga pe kò sí Eṣu tabi Satan. Oun dabi ọdaran kan tí ó tan ero naa kálẹ̀ pe ẹgbẹ awọn ọdaran kò sí rara tí ó sì nfi bayii rọ awọn eniyan tó sinu aabo eke. Ọgbọn-ẹwẹ miiran farahan ninu awọn iwa buburu jọjọ tí awọn onitara isin ti hù—awọn ogun isin, iwadii-ṣìkà, ìsúre fún awọn ohun-eelo ogun. Eyi ti mú ki ọpọlọpọ awọn eniyan ọlọkan-ojo yipada kuro lọdọ Jehofah Ọlọrun, tí wọn nfi pẹlu aṣiṣe ronu pe awọn ṣọọṣi nṣoju fun un.

20 Ranti, pẹlu, pe apostle Paul sọ pe Satan ni “ọlọrun eto-igbekalẹ awọn nkan isinsinyi.” Awọn eniyan kan ṣẹ̀fẹ̀ nipa ọ̀rọ̀ naa pe Satan ló ndọ́gbọ̀n dari awọn orilẹ-ede. Ṣugbọn nigba tí Satan nawọ aṣẹ lori gbogbo awọn orilẹ-ede sí Kristi, Jesu kò sẹ́ pe Eṣu ní agbara lori awọn ijọba iṣelu. (Luke 4:5-8) Kò ha sì hàn pe agbara buburu kan wà lẹhin awọn ọran ayé lonii? Pẹlu eyi lọkan, ka ohun tí Iṣipaya 12:9, 12 sọ nipa awọn isapa Satan.

YIYẸRA FUN IFARAKANRA PẸLU AWỌN ẸMI-AIRI BURUKU

21 Awọn onimọ-ijinlẹ ti ṣe iwadii nipa ohun tí a mọ sí Ìwòye Imọlara Rekọja Ode-ara (ESP—extrasensory perception). Eyi ní ninu awọn ohun àrà-mérìírí iru bii pe ki ẹnikan mọ ironu awọn ẹlomiran, ṣiṣapejuwe awọn iṣẹlẹ tabi awọn ohun tí oun kò rí tabi kẹkọọ nipa rẹ̀ rara, ati lilo ‘ero-inu lori ipo-ọran’ lati nipa lori awọn ohun bii dída ọmọ ayò eré ludo. Awọn oluwadii nipa iṣiṣẹ ìwòye imọlara rekọja ode ara ọpọlọ ti gbiyanju lati mú ọgbọn ẹtan tí ó ṣeeṣe ki ó wà nidii rẹ̀ kuro, sibẹ wọn! kò lè ṣalaye awọn abàmì iṣẹ-iyanu wọnyi. Ohun tí Iwe-mimọ sọ ha lè jẹ alaye naa bi?

22 Satan ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ lè nípa ní taarata lori awọn ẹda-eniyan ati awọn ọran wọn. Fun apẹẹrẹ, ọdọmọbinrin kan ní Philippi igbaani, ní Greece, lè sọ awọn asọtẹlẹ. Bawo? Akọsilẹ ọrọ-itan sọ pe “ẹmi àfọ̀ṣẹ” ni ó nru ọrọ tí njade lẹnu ọdọmọbinrin naa soke. Apostle Paul ràn án lọwọ lati di ominira kuro lọwọ ẹmi-eṣu naa.—Iṣe 16:16-18.

23 Nitori pe awọn ẹmi-eṣu jẹ ohun gidi tí wọn sì lagbara, leralera ni Ọrọ Ọlọrun ṣe kilọ-kilọ lodisi ibaṣepọ pẹlu wọn. Ó dẹbi fun lilo ìfi-éédì-múnì (iru bii iṣẹ-idán tabi voodoo), lilọ sọdọ awọn abẹmilo tabi ki ẹnikan maa gbiyanju lati bá oku sọrọ. (Deuteronomy 18:10-12; Leviticus 20:6, 27; Galatia 5:19-21) Awọn ikilọ wọnni ṣì bá akoko mu sibẹ. Iwọ ti lè ṣakiyesi itankalẹ idunnu si awọn ohun àra-mérìírí nipa ìwòye imọlara rekọja ode-ara ati ohun ijinlẹ awo. Ọpọlọpọ awọn aworan ara ogiri ati awọn iwe itan arosọ ni wọn ti sọrọ nipa isapa ’awọn ẹmi’ tabi awọn eniyan lati lé awọn ẹmi-eṣu jade. Lilo awọn ọpọ́n Ouija tabi ìràwọ̀-wíwò fun itọsọna wọpọ.

24 Ijumọsọrọpọ pẹlu awọn ẹmi buruku lewu ninu. Awọn irohin fihan pe ní gbàrà tí awọn ẹmi-eṣu bá ti jere agbara lori ẹnikan, wọn lè ṣe ọpọlọpọ ipalara—nipa ti ara, ọpọlọ ati ẹmi-ero. (Fiwe Matthew 8: 28-33.) Wọn ti yọ awọn eniyan lẹnu, tí wọn npariwo ní alaalẹ, tí wọn nmú ki awọn ohun-eelo rìn kiri, wọn nfi awọn ẹya ibimọ takọtabo ṣere wọn sì nṣokufa ailera. “Awọn ohùn” wọn paapaa tilẹ ti ti awọn eniyan sinu isinwi, ìmọ̀-ọ́n-mọ̀ paniyan ati ìpara-ẹni.

25 Amọ ṣa o, awọn iṣẹlẹ “ajeji” kan lè jẹyọ lati inu awọn ọran-iṣoro ti ara iru bii iyọnu lati inu awọn ohun tí ó parapọ dì ara eniyan, eyi tí ó lè ní ipa lori ero-inu ati awọn eto-iṣiṣẹ ọpọlọ. Ṣugbọn yoo jẹ iwa omugọ lati wulẹ pa wíwà Satan ati awọn ẹmi-eṣu tì sapakan. Maṣe foju tẹmbẹlu ìwúwo ikilọ Bibeli nipa

26 Bi awọn ẹmi-eṣu bá nyọ ẹnikan lẹnu, ọna kan kan ha wà lati rí idasilẹ bi? Ọlọrun kò tún lo awọn eniyan nisinsinyi lati ṣe iwosan awọn alaisan, lé awọn ẹmi-eṣu jade tabi jí oku dide, bi oun ṣe lo awọn apostle. Ṣugbọn oun yoo ran ẹnikan lọwọ lati ja àjàbọ́ lọwọ “agbara Satan.” (Iṣe 26:18; Ephesus 6:12) Ò ṣe pataki lati yijusi Jehofah ninu adura, ní Ìilo orukọ rẹ̀ ati fifi tọkantọkan wá iranlọwọ rẹ̀. (Owe 18:10) Ati pẹlu, ẹnikan gbọdọ dojujakọ awọn ironu-dábàá ẹlẹmi-eṣu, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, dídáwọ awọn iṣe-aṣa ibẹmilo ati ibakẹgbẹpọ tí kò wulo pẹlu awọn wọnni tí nlepa ijọsin ẹmi-eṣu duro.—Matthew 4:1-11; 2 Corinth 6:14-17.

27 Ní afikun, awọn irohin fihan pe awọn ẹmi-eṣu maa nní ifarakanra nigba gbogbo pẹlu ẹda-eniyan nipasẹ ohun-eelo kan, nitori naa ó ṣe pataki lati palẹ̀ awọn nkan tí a nlò tẹlẹ fun ibẹmilo mọ́ kuro (oruka, ondé, igbá-ọṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ). Bibeli sọ fun wa pe awọn kan tí wọn ti npidán tẹlẹri ní Ephesus igbaani ṣe eyiini.—Iṣe 19:18-20.

28 Sibẹ kò sí idi fun wíwà ninu ibẹrubojo igba gbogbo nipa awọn ẹmi buruku. Kaka bẹẹ, Bibeli rò wa lati wọ ara wa láṣọ ihamọra ti ẹmì:

“Ẹ duro nitori naa lẹhin tí ẹ ti fi àmùrè OTITỌ di ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà ODODO nì mọra. Tí ẹ sì ti fi imura IHINRERE ALAAFIA wo ẹsẹ yin ní bata: leke gbogbo rẹ̀, ẹ mú apata IGBAGBỌ, nipa eyi tí ẹyin yoo lè maa fi paná, gbogbo ọfà-iná, ẹná-ibí nì. Ki ẹ sì má mu àṣíborí IGBALA, ati ìdà ẹmi tiiṣe ỌRỌ ỌLỌRUN, . . . ki ẹ maa GBADURA nigba gbogbo.”—Ephesus 6:14-18.

Gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti fihan nihin, idaabobo tí ó dara julọ lodisi ijumọsọrọpọ tí a kò fẹ́ pẹlu awọn ẹmi buruku ni ijumọsọrọpọ deedee pẹlu Jehofah nipasẹ adura. Ó baamu gẹ́ẹ́ tí Bibeli sọ pe: “Nitori naa ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọju ija si Eṣu, oun yoo sì sá kuro lọdọ yin.”—James 4:7.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí a fi nilati ní inudidun si ìjumọsọrọpọ pẹlu Ẹlẹdaa? (1-3)

Kinni ohun tí a nilo fun awọn adura tí ó ṣe itẹwọgba? (1 Peter 3:12) (4, 5)

Kinni ohun tí a lẹ kẹkọọ rẹ̀ ninu Bibeli nipa awọn adura wa? (6-8)

Bawo ni a ṣe lè rí ijumọsọrọpọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun gbà? (9, 10)

Bawo ni a ṣe lè mọ̀ pe Satan wà? Ki sì ni ibẹrẹ rẹ̀? (11-15)

Bawo ni mímọ̀ tí a mọ Satan ati awọn ẹmi-eṣu ṣe ràn wa lọwọ? (16, 17)

Lọna wo ni awọn ẹmi buruku ti gbà ní ipa lori awọn ẹda-eniyan? (2 Corinth 11:13-15) (18-20)

Awọn iṣe-aṣa wo ni wọn lè mú ki ẹnikan lọwọ ninu ibalo pẹlu awọn ẹmi buruku? (21-23)

Bawo ni ìwọ ṣe lè daabobo ara rẹ lọwọ ijumọsọrọpọ tí npanilara pẹlu ilẹ-ọba ẹmi-airi? (24-28)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 123]

Lojoojumọ ni a lè jumọsọrọpọ pẹlu Ọlọrun nipasẹ adura