Iku Kii Ṣe Ọ̀tá kan Tí A Kò Lè Biṣubú
Ori 12
Iku Kii Ṣe Ọ̀tá kan Tí A Kò Lè Biṣubú
IKU jẹ ọ̀tá iwalaaye. Isinku kọọkan fihan pe iku lè dabi ọba kan tí ó dabi ẹnipe ó káwọ ẹni gbogbo. (Rome 5:14) Awọn igi kan maa ngbé ju 1,000 ọdun; awọn ẹja kan, 150; sibẹ iye ọdun eniyan jẹ 70 tabi 80 ki iku tó gbé e mì.—Psalm 90:10.
2 Pẹlu idi rere ni Bibeli fi gbé iku kalẹ gẹgẹ bi ọ̀tá kan. Bi o tilẹ jẹ pe ó dabi ẹnipe a ní ifẹ-ọkan tí a dámọ́ni lati walaaye ki a sì maa kẹkọọ lailopin, ohun yowu ki eniyan kan ti kẹkọọ rẹ̀, ohun tí awọn ìmọ-iṣẹ rẹ̀ jẹ, bi o ti wu ki awọn ọ̀rẹ́ ati ẹbí lero pe ó ga tó, iku npa á. (Oniwaasu 3:11; 7:2) Ọpọlọpọ eniyan, ní gbígbà pe iku jẹ ọtá, nfi pẹlu ìgbékútà gbiyanju lati fawọ́ iṣẹgun rẹ̀ sẹhin. Awọn miiran nṣe kìtàkìtà ninu wíwá gbogbo igbadun tí ó ṣeeṣe ninu igbesi-aye kiri ki a tó bori wọn.
3 Jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ọrọ-itan, sibẹ, ọpọlọpọ eniyan ni wọn ti gbagbọ pe iwalaaye wà lẹhin iku. Plato olumọran Greek naa kọni pe a ní ọkàn aileeku eyi tí nfi ara silẹ. A ha ní in bi? Idunnu ninu eyi ni a ti rusoke nipasẹ awọn itan lọọlọọ nipa awọn eniyan tí a lérò pe wọn ti kú, tí a musọji lẹhin naa tí wọn ṣapejuwe ohun tí wọn ’rí rekọja ẹnu-ọna iku.’ Awọn oku ha walaaye nibikan bi? A ha lè bori iku bi?
IṢẸGUN AKỌKỌ TÍ IKU NÍ
4 Bibeli fihan pe a dá awọn eniyan lati walaaye, kii ṣe lati kú. Ọlọrun fi Adam ati Efa sinu ọgba tí ó gbadunmọni kan nibi tí wọn ti lè gbadun iwalaaye. Oun pe orukọ ọ̀kan lara awọn igi naa ní “igi ìyè.” Ó ṣeeṣe pe bi Adam ati Efa bá ti fi ẹri imọriri ati iṣotitọ wọn sí Ọlọrun hàn, oun ìbá jẹ ki wọn jẹ ninu igi naa, tí ó duro fun pe oun fọwọsi ìyè ainipẹkun fun wọn. (Genesis 1:30; 2:7-9) Bi o ti wu ki o ri, Adam ati Efa yàn lati ṣaigbọran si Ọlọrun. Ẹṣẹ wọn mú idalẹbi iku wá sori wọn.—Genesis 3:17-19.
5 Fun wa lati loye boya iku jẹ ọtá kan tí a kò lè biṣubu nitootọ, a nilati ṣayẹwo abajade iṣẹgun iku lori Adam ati Efa. Wọn ha “kú” patapata bi? Tabi pe “kíkú” naa jẹ kiki iṣipopada sinu iru iwalaaye miiran?
6 Lẹhin igba tí Adam fi pẹlu iwa òmùgọ̀ dẹṣẹ, Jehofah duro ti ọrọ onidalare ati ododo rẹ̀. Oun sọ fun Adam pe:
“Ní òógùn oju rẹ ni iwọ yoo maa jẹun, titi iwọ yoo fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ ni a ti mu ọ wá, erupẹ sáà ni iwọ, iwọ yoo sì pada di erupẹ.”—Genesis 3:19.
Kinni ohun tí eyiini tumọsi fun Adam ati fun wa lonii?
7 Akọsilẹ iṣaaju nipa iṣẹda Adam sọ fun wa pe: “Ọlọrun sì fi erupẹ ilẹ mọ eniyan; ó sì mí èémí ìyè sí iho-imú rẹ̀; eniyan sì di alaaye ọkàn.” (Genesis 2:7) Ronu ohun tí eyiini tumọsi. Ṣaaju ki Ọlọrun tó dá a lati inu erupẹ, kò sí Adam. Fun idi yii, lẹhin tí oun kú tí ó sì pada di erupẹ, kò ní sí Adam.—Genesis 5:3-5.
AWỌN OKU HA MỌ NKANKAN BI?
8 Ọpọlọpọ eniyan ni ẹnu lè yà sí ironu naa pe nigba tí Adam ti kú oun kò tún walaaye mọ. Sibẹ ijiya ẹṣẹ tí a ṣalaye rẹ̀—kíkú Adam ati pipada sinu erupẹ—kò ní ìtani-lólobó rara nipa iwalaaye tí nbá a lọ. Iku ni odikeji ìyè, yala fun eniyan kan tabi ẹranko kan. “Ẹmi” tabi agbara iwalaaye kan naa ni awọn mejeeji ní. Nipa bayii Bibeli ṣalaye pe:
“Nitori pe ohun tí nṣe ọmọ-eniyan nṣe ẹran; ani ohun kan naa ni ó nṣe wọn; bi ẹ̀kínní ti nkú, bẹẹ ni ekeji nkú; nitootọ ẹmi kan naa ni gbogbo wọn ní, bẹẹ ni eniyan kò ní ọlá ju ẹran lọ . . . Lati inu erupẹ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn sì tún pada di erupẹ.”—Oniwaasu 3:19, 20.
9 Eyiini ha tumọsi pe awọn oku kò ní ironu tabi imọlara rara? Oniwaasu 9:4, 5 dahun: “Aàyé ajá sàn ju òkú kinniun lọ. Nitori alaaye mọ̀ pe awọn yoo kú; ṣugbọn awọn oku kò mọ ohun kan.” Nigba tí ẹnikan bá kú, “Ìrò inu rẹ̀ run”, oun kò tún ní agbara mọ yala lati nimọlara tabi lati ṣiṣẹ.—Psalm 146:3, 4; 31:17.
10 Niwọn bi Bibeli ti mú un dá wa loju pe awọn oku kò mọ ohunkohun ati laisi imọlara, eyiini tumọsi pe iku fi opin sí irora ati ijiya. Job, olootọ iranṣẹ Ọlọrun, mọ eyi. Nigba tí oun njiya lọwọ arun onirora kan ó wipe:
“Eeṣe tí emi kò fi kú lati inu wá? . . . Eeṣe tí eékún wá pade Job 3:11-13.
mi, tabi ọmú tí emi yoo mu? Njẹ nisinsinyi, emi ìbá ti dubulẹ jẹ, emi a sì dakẹ. Emi ìbá ti sùn, emi ìbá ti sinmi.”—11 Ṣugbọn eyi ha nṣiro ọkàn mọ́ ọn bi?
12 Ki a sọ ọ lọna tí ó rọrun, Iwe-mimọ kọni pe ọkàn rẹ ni ọ. Ohun tí a kà ninu Genesis 2:7 fi eyiini hàn. Ranti pe Ọlọrun ṣe ara eniyan lati inu erupẹ wá. Nigba naa Ọlọrun pese iwalaaye ati èémí tí a nilo lati mú un duro. Kinni iyọrisi rẹ̀? Ní ibamu pẹlu Ọrọ Ọlọrun funraarẹ̀, ọkunrin naa “di alaaye ọkàn [Hebrew, nephesh].” (Genesis 2:7) A kò fun Adam ní ọkàn, bẹẹ ni oun kò dẹ̀hìn wá ní ọkàn. Oun jé ọkàn kan. Ní kikọni ní eyi, Bibeli wà ní iṣedeedee-ṣọkan-delẹ. Ní ọpọlọpọ ọrundun lẹhin naa apostle Paul fa ọrọ yọ lati inu Genesis 2:7, ní kikọwe pe: “Adam ọkunrin iṣaaju, alaaye ọkàn ni a dá a [Greek, psykhe].”—1 Corinth 15:45.
13 Ọrọ Hebrew naa nephesh ati ọrọ Greek naa psykhe, tí a rí ninu awọn ẹsẹ wọnyi, ni a tumọ ní oniruuru ọna. Ninu Ezekiel 18:4 ati Matthew 10:28 ìwọ yoo ríi pe, ninu ọpọlọpọ awọn itẹjade Bibeli, a tumọ wọn gẹgẹ bi “ọkàn.” Nibomiran awọn ọrọ ipilẹ wọnni ni a tumọ gẹgẹ bi “ìwà,” “ẹda,” tabi “eniyan.” Iwọnyi jẹ awọn itumọ tí wọn fẹsẹmulẹ fun awọn ọrọ ipilẹ naa, ati pe ifiwera wọn fihan pe ọkàn naa ni ẹda tabi eniyan naa funraarẹ̀, kii ṣe apakan tí kò ṣee fojuri ninu eniyan. Bibeli lo awọn ọrọ ede ipilẹ kan naa fun awọn ẹranko, tí ó nfihan pe wọn jẹ awọn ọkàn tabi ní iwalaaye bi awọn ọkàn.—Genesis 2:19; Leviticus 11:46; Iṣipaya 8:9.
14 Gẹgẹ bi ọkàn, Adam, tabi ẹnikẹni ninu wa, lè jẹun, ki ebi pa wa ki ó sì rẹ̀ wa. Ninu Hebrew ti ipilẹsẹ, Bibeli sọ pe awọn ọkàn maa nṣe gbogbo nkan wọnyi. (Deuteronomy 23:24; Owe 19:15; 25:25) Ní ṣiṣalaye ikalọwọko kan tí ó wulo fun awọn ọmọ Israel nipa iṣẹ ṣiṣe ní ọjọ pataki kan, Ọlọrun mú ki koko pataki miiran nipa ọkàn ṣe kedere, ní wiwipe: “Ati ọkànkọ́kàn tí ó bá ṣe iṣẹ kan ní ọjọ naa, ọkàn naa ni emi yoo run kuro laarin awọn eniyan rẹ̀.” (Leviticus 23:30) Fun idi yii, Bibeli, nihin ati ninu ọpọlọpọ awọn ẹsẹ miiran, fihan pe ọkàn lè kú.—Ezekiel 18:4, 20; Psalm 33:19.
15 Mímọ iru awọn otitọ Bibeli bẹẹ lè ràn wa lọwọ lati wadii otitọ awọn itan lọọlọọ yii nipa awọn eniyan tí wọn lérò pe wọn ti kú (lai lè rí ilukiki ọkàn-àyà ati iṣiṣẹ ọpọlọ wọn), ṣugbọn tí a musọji ati lẹhin naa tí wọn sọ nipa pe awọn ti léfòó lẹhin ode ara wọn. Ohun tí ó ṣeeṣe ni pe wọn ti lè ní iran-itanjẹ tí oógùn lílò ṣokunfa rẹ̀ tabi ipo àìlátẹ́gùn oxygen ọpọlọ. Yala eyiini ni alaye kíkún tabi bẹẹ kọ, awa mọ̀ pẹlu idaniloju pe kò sí ọkàn alaiṣee fojuri kankan tí ó fi ara silẹ.
16 Pẹlupẹlu, bi ó bá jẹ pe awọn oku kò mọ ohunkohun patapata tí kò sì sí “ọkàn” tí ó léfòó kuro ninu ara, nigba naa kò lè sí hell onina tí nduro de ọkàn awọn ẹni buruku, ó ha lè wà bi? Sibẹ ọpọlọpọ awọn ṣọọṣi ni wọn nkọni pe a o dá awọn ẹni buruku lóró lẹhin tí wọn bá kú. Ní kikẹkọọ otitọ nipa awọn oku, awọn eniyan kan ti ní idaamu bi ó ti yẹ ki ó rí, tí wọn beere pe: ’Eeṣe tí isin wa kò fi sọ otitọ fun wa nipa awọn oku?’ Kinni ihuwapada tirẹ?—Fiwe Jeremiah 7:31.
ỌJỌ-ỌLA WO FUN AWỌN OKU?
17 Bi ó bá jẹ pe kiki ọjọ-ọla tí ó wà fun awọn ẹni tí wọn walaaye nisinsinyi ni àìmọ ohunkohun ninu ìku, nigba naa iku yoo jẹ ọta kan tí a kò lè biṣubu. Ṣugbọn Bibeli fihan pe kii ṣe bẹẹ.
18 Ọjọ-ọla oju-ẹsẹ fun ẹnikan lẹhin iku jẹ inu sàréè. Awọn ede tí a fi kọ Bibeli ní awọn ọrọ fun ibi tí awọn oku wà, sàréè gbogbo araye. Lede Hebrew a pè é ní Sheol. A pè é ní Hades ní Greek. Awọn ọrọ wọnyi ni a ti tumọ ninu awọn Bibeli kan pẹlu awọn ọrọ-ede iru bii “ipo oku,” “iho,” “ọrun apaadi” tabi “hell.” Laika bi a ṣe tumọ wọn sí, itumọ awọn ọrọ-ede ipilẹṣẹ naa kii ṣe ibi ijiya kan tí ó gbona ṣugbọn ó jẹ sàréè awọn oku tí kò mọ ohunkohun. A ka pe:
“Ohunkohun tí ọwọ rẹ rí ní ṣiṣe, fì agbara rẹ ṣe e; nitori tí kò sí ete, bẹẹ ni kò sí imọ, tabi ọgbọn ni ipo-oku [hell, Douay Version; sàréé, Authoried Version], nibi tí iwọ nré.”—Onìwaasu 9:10.
Apostle Peter mú un dá wa loju pe nigba iku ani Jesu paapaa lọ sinu sàréé, sinu Sheol, Hades tabi hell.—Iṣe 2:31; fiwe Psalm 16:10.
19 Nitootọ, ẹnikan tí ó ti kú kò ní agbara lati yí ipo rẹ̀ pada. (Job 14:12) Nitori naa ṣé àìmọ ohunkohun ninu iku ni gbogbo ọjọ-ọla tí ó wà bi? Fun awọn kan, bẹẹ ni. Bibeli kọni pe awọn ẹni tí Ọlọrun kọ̀ jálẹ̀jálẹ̀ yoo wà ní oku laelae.—2 Thessalonica 1:6-9.
20 Awọn Jew igbaani gbagbọ pe awọn olubi tí wọn buru kọja ààlà kò lè ní ọjọ-ọla kan yatọ si iku. Matthew 5:29, 30) Fun apẹẹrẹ, oun wipe:
Awọn Jew kii sinku iru awọn eniyan bẹẹ. Kaka bẹẹ, wọn maa nfi awọn oku naa sọ̀kò sinu afonifoji kan lẹhin ode Jerusalem nibi tí a ti nmú ki iná jó lati palẹ̀ awọn pantiri mọ́. Eyi ni Afonifoji Hinnom, tabi Gehenna. Ní mímú iṣe-aṣa yii wá gẹgẹ bi apẹẹrẹ, Jesu lo Gehenna gẹgẹ bi ami-apẹẹrẹ fun iparun yán-án-yán-án, laisi awọn ireti rere ọjọ-ọla kankan. (“Ẹ má fòyà awọn ẹni tí npa ara, ṣugbọn tí wọn kò lè pa ọkàn; [tabi ifojusọna-ireti lati walaaye gẹgẹ bi ọkàn]; ṣugbọn ẹ kúkú fòyà ẹni tí ó lè pa, ara ati ọkàn run ní [Gehenna].”—Matthew 10:28.
Awọn ọrọ Jesu, bi o ti wu ki o ri, fun wa ní idi fun ireti pe ọpọlọpọ awọn tí wọn ti kú yoo tún walaaye lẹẹkan sii lọjọ iwaju, tí a o sì tipa bayii bori iku.
IṢẸGUN NIPASẸ AJINDE
21 Ọlọrun, ninu ọ̀kan lara awọn àdáwọ́léṣe pataki-pataki ninu ọrọ-itan, jí Jesu Kristi dide sí ìyè lẹhin igba tí oun ti jẹ oku fun awọn ọjọ diẹ. Jesu di ẹda ẹmi alaaye gẹgẹ bi oun ti ṣe jẹ ṣaaju ki ó tó wá sí ayé. (1 Corinth 15:42-45; 1 Peter 3:18) Ọgọrọọrun awọn eniyan ni wọn rí Jesu tí ó farahan lẹhin tí a ti jí i dide. (Iṣe 2:22-24; 1 Corinth 15:3-8) Awọn ẹlẹrii wọnyi nifẹẹ lati fi ẹmi ara wọn wewu ní itilẹhin fun igbagbọ wọn ninu ajinde Jesu. Ajinde Jesu fi ẹri hàn pe iku kii ṣe ọta kan tí a kò lè biṣubu. Iṣẹgun lori iku ṣeeṣe!—1 Corinth 15:54-57.
22 Awọn iṣẹgun siwaju sii lori iku tún ṣeeṣe. Awọn eniyan lè pada wá si iwalaaye eniyan lori ilẹ-aye. Jehofah, ẹni tí kò lè ṣeke, mú un dá wa loju ninu Ọrọ rẹ̀ “pe ajinde oku nbọ, ati ti olootọ [awọn ẹni tí wọn ti mọ̀ tí wọn sì ti ṣe ifẹ Ọlọrun] ati ti alaiṣootọ [awọn tí kò huwa ododo].”—Iṣe 24:15.
Psalm 147:4) Oun ti ṣaṣefihanni eyi ṣaaju isinsinyi. Bibeli ní iye awọn akọsilẹ kan ninu nipa bi Ọlọrun ti ṣe lo Ọmọkunrin rẹ̀ lati mú awọn ẹda-eniyan padabọ si ìyè. Iwọ lè ka meji ninu awọn akọsilẹ amunilaraya wọnyi ninu John 11:5-44 ati Luke 7:11-17. Pẹlu idi rere awọn eniyan tí wọn ti jọsin Ọlọrun nigba atijọ ti fojusọna si akoko naa nigba ti oun yoo ranti tí yoo sì jí wọn dide. Yoo dabi jíjí wọn dide kuro loju oorun àìmọ ohunkohun.—Job 14:13-15.
23 Awa lè ní igbẹkẹle ninu agbara-iṣe Ọlọrun lati mú awọn eniyan pada wá si iwalaaye. Awọn eniyan lè gba aworan, ohùn ati ọna ihuwa ẹnikan silẹ lori okùn sinima tabi videotape. Ọlọrun kò ha lè ṣe pupọpupọ jù bẹẹ lọ bi? Iranti rẹ̀ gbooro pupọ ju ti okùn sinima tabi tape eyikeyi, nitori naa oun lè ṣe àtúndá pípé pérépéré awọn wọnni tí oun fẹ́ lati jí dide. (24 Awọn ajinde igbaani ti nilati fi ayọ̀-idunnu àkúnwọ́sílẹ̀ kún inu awọn ibatan ati ọ̀rẹ́. Ṣugbọn awọn ajinde wọnyẹn bori iku kiki fun igba diẹ péré, nitori awọn ẹni tí a jí dide naa tún pada kú nikẹhin. Bi o tilẹ rí bẹẹ, wọn fun wa ní apẹẹrẹ-àkọ́wò tí nmunilarayá-gaga, nitori Bibeli tọkasi “ajinde tí ó dara jù” tí nbọ̀. (Hebrew 11:35) Yoo dara jù niti gidi gan-an ni nitori pe awọn wọnni tí npadabọ sí ìyè lori ilẹ-aye kò tún ní pada kú mọ́. Eyiini yoo jẹ iṣẹgun tí ó tobi jù gidigidi lori iku.—John 11: 25, 26.
25 Ohun tí Bibeli sọ nipa bi Ọlọrun ṣe lè, tí yoo sì bori iku dajudaju fi idunnu onifẹẹ rẹ̀ ninu eniyan hàn. Ó nilati ràn wa lọwọ lati loye akopọ-animọ-iwa Jehofah ki ó sì fà wa sunmọtosi rẹ̀. Awọn otitọ wọnyi tún ràn wa lọwọ lati wà ní iwọn-deedee, nitori a daabobo wa lodisi ibẹrubojo nipa iku tí ó ti di ọpọlọpọ ní ìgbèkùn. Awa lè ní ireti alayọ ti rírí awọn ibatan ati awọn ololufẹ wa tí wọn ti kú lẹẹkan sii nigba tí, nipasẹ ajinde, a bá bori iku.—1 Thessalonica 4:13; Luke 22:43.
[Koko Fun Ijiroro]
Eeṣe tí a fi nilati ṣayẹwo “ọta” naa iku? (Job 14:1, 2) (1-3)
Bawo ni iku ṣe wá sori araye? (4, 5)
Kinni ohun tí “iku”? tumọsi fun Adam? (6, 7)
Bawo ni ìwọ ṣe lè fihan ẹnikan ninu Bibeli boya awọn oku mọ ohunkohun? (8-11)
Ní ibamu pẹlu Bibeli, kinni “ọkàn” kan jẹ́? (12, 13)
Ọkàn kan ha lè kú bi, itumọ wo sì ni eyi ní? (14-16)
Kinni ohun tí nṣẹlẹ si ẹnikan lẹhin iku? (17-20)
Bawo ni iṣẹgun lori iku ti ṣe ṣeeṣe? (21, 22)
Eeṣe tí ọjọ-ọla fi lé dunmọni? (23-25)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 117]
‘Ó yẹ fun afiyesi pe ninu Majẹmu Titun awa kò ri hell onina gẹgẹ bi apakan iwaasu igba ijimiji. Awọn itọkafihan kan wà ninu Majẹmu Titun pe kádàrá awọn wọnni ti wọn kọ igbala tí Ọlọrun fi funni silẹ lè jẹ ìkékúrò dipo ìjẹníiyà ayeraye.’—“A Dictionary of Christian Theology,” tí Alan Richardson jẹ onkọwe-alatunṣe rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]
ERUPẸ
ADAM
ERUPẸ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 119]
Ajinde Lasarus fihan pe a le bori iku