Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilera Sisunwọn ati Iwalaaye Gígùn—Bawo?

Ilera Sisunwọn ati Iwalaaye Gígùn—Bawo?

Ori 10

Ilera Sisunwọn ati Iwalaaye Gígùn—Bawo?

ILERA tí ó dara lè ṣe ọpọlọpọ afikun sí ayọ ẹnikan. Sibẹ gbogbo wa ni a maa nṣaisan nigba miiran. Ailera lilekoko sì lè yọrisi ìku. Awọn iṣoro wọnyi ni a gbeyẹwo ninu Bibeli, eyi tí ó pese amọna tí ó lè ran ẹnikan lọwọ lati lè gbadun ilera sisunwọn ati iwalaaye gigun.

2 Iwe-mimọ rán wa leti pe Jehofah Ọlọrun ni Orìsun iwalaaye. Nitori tirẹ̀ “ni awa gbé wà ni ààyé tí awa nrìn kiri, tí a sì ní ẹmi wa.” (Psalm 36:9; Iṣe 17:25, 28) Oun sì nsọ pupọ fun wa nipa bi a o ṣe bojuto ara wa. Awọn aisan bàntà-banta tí nrápálá wọle wá ni a ti lè yẹra fun nipa fifiyesi imọran Ọ̇rọ rẹ̀. Awọn wọnni tí wọn ti ṣe bẹẹ ní idi lati gbà pẹlu akọwe Bibeli tí ó wipe: “Ofin ẹnu rẹ̀ [Ọ̇lọrun] dara fun mi ju ẹgbẹẹgbẹrun wura ati fadaka lọ.”— Psalm 119:72; 73:28; Owe 4:20-22.

IMỌRAN TÍ NGBÉ ILERA LÁRUGẸ

3 Bibeli kii ṣe iwe tí a pìlẹ̀ ṣe gẹgẹ bi iwe-amọna lori ọran ilera. Ṣugbọn ó ní ninu imọran ti ngbé ilera didara lárugẹ. Eyiini ni a lè rí kedere lati inu awọn ilana Ọlọrun fun orilẹ-ede Israel. Awọn apẹẹrẹ diẹ niyii: Tipẹtipẹ ṣaaju lilo oògùn ode-oni, ofin Ọlọrun fun Israel beere pe kì a se ẹni tí ó bá ni, tabi tí ó dabi ẹnipe ó ní, arun tí ngbèèràn mọ́lé. (Leviticus 13:1-5) Ìgbònsẹ̀ ni a nilati dànù kuro nibi tí eniyan ngbé, nipa bayii a ndena itankalẹ arun tabi sisọ omi di eleeri. (Deuteronomy 23:12-14) Bi awọn aṣọ tabi ohun-elo bá farakan ẹranko tí ó ti kú funraarẹ̀ (boya lati ọwọ́ arun) a o fọ̀ ọ́ ki a tó lè tún un lò tabi ki á run ún kuro. (Leviticus 11:27, 28, 32, 33) Awọn alufaa Israel ni wọn nilati wẹ̀ ki wọn tó ṣiṣẹ nidii pẹpẹ, tí wọn nfi bayii mú ipo iwaju ninu jíjẹ mímọ.—Exodus 30:18-21.

4 Tipẹtipẹ sẹhin ni awọn oniṣegun eniyan ti mọriri iniyelori gbigbeṣẹ iru awọn igbesẹ bẹẹ, eyi tí a ṣì lè lò pẹlu èrè-anfaani. Dídín ifarakanra kù pẹlu awọn ẹlomiran nigba tí ó bá dabi ẹnipe iwọ tabi awọn ní ailera tí ó lè ranni. Ṣiṣọra lati maṣe sọ omi mimu tabi ounjẹ di eleeri pẹlu ohun tí eniyan yà dànù tabi pàntí. Mímú ki ohun-eelo ounjẹ ṣísẹ̀ ati ti ijẹun wà ní mímọ́. Bibojuto imọtoto ara-ẹni nipa wíwẹ̀ deedee, nipa fífọwọ ẹni pẹlu lẹhin lilo ibi-ìgbọnsẹ̀.

5 Arun abẹ saba maa nranni nipasẹ iwa-àìmọ, eyi tí Ọlọrun dalẹbi. (Hebrew 13:4; Ephesus 5:5) Ṣugbọn nipa wíwà ní mímọ́ ṣaaju igbeyawo ati fifi ibalopọ takọtabo mọ sọdọ ẹnikeji ẹni lẹhin igbeyawo, a daabobo awọn Kristian lodisi awọn arun gbẹ̀mígbẹ̀mí wọnyi.

6 Ati pẹlu, ilera tí ó sàn jù le wá lati inu lilo imọran Iwe-mimọ nipa ọna igbesi-aye ẹnikan ní gbogbogboo. Fun apẹẹrẹ, Bibeli gbóríyìn fun iṣẹ alaapọn. Ó sọ pe ọkunrin naa tí ó bá ṣe iṣẹ oojọ daradara yoo sun oorun tí ó sàn jù. Ó sì sọrọ gidigidi nipa rírí igbadun ninu ounjẹ ati ohun mimu tí iwọ lè rí lati inu iṣẹ rẹ, nigba tí o nyẹra fun fifi àjẹkì kẹra rẹ bajẹ. Iwọ kò ha gbà pe bi iwọ bá ṣiṣẹ-kára, tí o sun oorun tí ó pọ̀ tó, gbadun awọn ounjẹ rẹ tí o sì “jẹ oniwọntunwọnsi ninu iwa,” ilera rẹ yoo dara jù, ìwọ yoo sì layọ sii bi” Oniwaasu 2:24; 5:12; 9:7-9; Ephesus 4:28; 1 Timothy 3:2,11.

TÁBÀ, ỌTI-LILE ATI AWỌN OÒGÙN

7 Dr. Joel Posner rohin pe ní United States, fun apẹẹrẹ, ida 60 ninu ọgọrun ninu owó tí a ná fun itọju ilera jẹ fun awọn ailera tí ó jẹmọ lilo tábà ati ọti-lile. Bawo ni Bibeli ti ṣeranwọ tó lọna yii?

8 Ní iṣedeedee-ṣọkan-delẹ pẹlu ìṣíníyé Ọlọrun lori imọtoto tabi jíjẹ mímọ, apostle Paul kọwe si awọn Kristian pe: “Ẹyin ọ̀rẹ ẹ̀wọn, ẹ jẹ ki a wẹ ara wa mọ kuro ninu gbogbo ohun tí nsọ ara ati ẹmi di ibajẹ.” (2 Corinth 7:1, Twentieth Century New Testamemt) Ọpọlọpọ eniyan ni wọn ti ríi pe lilo tábà tako imọran naa. Fifa èéfín sinu ẹ̀dòfóró jẹ ohun tí kò bá iwa ẹda mu. Ó nsọ ara dibajẹ ó sì nké iwalaaye ẹni kuru. Awọn iwadii-ẹkọ ti fidii rẹ̀ mulẹ pe awọn amusiga maa nní aisan ọkàn-àyà, aisan ẹ̀dọ̀fóró, ẹjẹ ríru ati arun pneumonia (aràn-ìhà) lilekoko.

9 Pẹlupẹlu, ronu nipa awọn iyọrisi lori awọn eniyan tí wọn wà yika awọn amusiga—idile ati awọn alabakẹgbẹ rẹ̀. Jesu Kristi sọ pe ofin keji ninu ofin Ọlọrun fun Israel ni: “Fẹ́ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.” (Mark 12:31) Eyiini kọ́ ha ni ohun ti iwọ fẹ lati ṣe bi? Ṣugbọn kinni awọn iyọrisi siga mimu? Ó nṣe ipalara fun ẹni tí nmú un, ó sì nṣe jamba fun ilera awọn ẹlomiran tí nmí èéfín naa símú.

10 Nipa mimu awọn ohun-mímu ọlọti-lile nkọ́? Ọpọlọpọ eniyan ni wọn ríi pe awọn ohun wọnyi maa ndùn wọn sì nmú ara silé. Bibeli kò ṣe ikaleewọ awọn ohun-mímu tí ó ní ọti-lile ninu, eyi tí ara lè “sun” bi epo-ọkọ̀ tabi ounjẹ. (Psalm 104:15; Oniwaasu 9:7) Ṣugbọn ó kilọ pe: “Ẹlẹya ni ọti-waini alariwo ni ọti-lile, ẹnikẹni tí a bá fi tanjẹ kò gbọ́n.” (Owe 20:1) Ní taarata ni Bibeli dẹbi fun imutipara. (1 Corinth 6:9, 10; 1 Peter 4:3) Ẹnikẹni tí ó bá nmuti papọju ní gbogbo igba dajudaju “kò gbọn,” gẹgẹ bi awọn ẹsẹ iwe-mimọ ti wi. Laipẹ, iru eniyan bẹẹ lè pa ẹ̀dọ̀-ki rẹ̀ run, pẹlu awọn iyọrisi lilekoko tabi onijamba kikoro paapaa. Agbẹ̀dù lè bajẹ. Aláṣìlò ọti-lile lè di ẹni tí ó wà ní oju-ọna aisan ọkàn-àyà ati aisan arọnilọ́wọ-lẹ́sẹ̀. Eto-iṣiṣẹ agbara iranti ati ẹran-ara ni a lè ta jamba fun, pẹlu.

11 Imọran Bibeli lori imutipara tún ṣeranwọ pẹlu nipa awọn oògùn iru bii heroin, cocaine, ẹ̀pà betel, marijuana ati LSD. Awọn wọnyi ni a nlò lọna gbigbooro, kii ṣe fun “ounjẹ” tabi fun ete iṣegun, ṣugbọn ní pataki lati mú ki ìpani-bi-ọti “gasoke,” iran-itanjẹ tabi àjàbọ́ kuro ninu otitọ bi ọran ti rí. Iru awọn oògùn bawọnyi ni a lè ṣalailò ní awọn akoko tí a kọ Bibeli. Sibẹsibẹ Bibeli fi tagbara-tagbara sọrọ jade lodisi imutipara ati “iwa wọbia” tí nbá a rìn. Imọran kan naa yẹn kò ha ní wulo fun ohunkohun miiran tí ó lè pani-bi-ọti ki oluwarẹ̀ si maa huwa lainijanu tabi lọna wọbia bi? (Ephesus 5:18) Nigba gbogbo awọn eniyan tí wọn wà labẹ isunniṣe awọn oògùn maa npa ara wọn lara tabi ki awọn ẹlomiran ṣe ipalara fun wọn. (Fiwe Owe 23:29, 35.) Awọn oògùn wọnyi ní isopọ pẹlu awọn ewu ilera miiran, tí ó ní ninu arun ẹ̀dòfóró, ọpọlọ ati ibajẹ ẹya ibimọ, aisan aijẹun-re-kánú ati arun mẹdọ̀wú. Nitori naa lilo imọran tí a rí ninu Bibeli dajudaju lè yọrisi awọn èrè-anfaanì ilera.

IDI ATI BI A ṢE LÉ LO IMỌRAN ỌLỌRUN

12 Ireti rere ti titubọ di onilera sii ati iwalaaye gigun maa nfa gbogbo awọn eniyan ọlọpọlọ pípé mọra. Idi rere kan ni eyiini fun titẹwọgba ati lilo imọran Iwe-mimọ tí a ti gbeyẹwo. (Psalm 16:11) Ṣugbọn idi yẹn ha tó bi? Ó ṣeeṣe ki o mọ awọn eniyan tí yoo tẹwọgba awọn ifiwewu nitori igbadun tabi ìmòríyá tí wọn reti lati rí. Eyi nilati yatọ, bi o tilẹ rí bẹẹ, pẹlu awọn eniyan tí wọn ní igbagbọ ninu Ọlọrun tí wọn sì mọ̀ pe oun ti fi ara rẹ̀ hàn nipasẹ Bibeli. Niwọn bi iwalaaye wa ti jẹ lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, a nilati dàníyàn nipa lílò ó ní ibamu pẹlu itọsọna tí oun fi funni ninu Bibeli. Awa yoo jẹ alaimoore bi ó bá jẹ pe a gba iwalaaye lati ọ̀dọ̀ Jehofah, lẹhin naa ki a sì wá mọ̀-ọn-mọ̀ kọ imọran ọlọgbọn ati onifẹẹ rẹ̀ silẹ lori bi a o ṣe lo iwalaaye wa.

13 Siwaju sii, gẹgẹ bi Olufunni ní ìyè, Ọlọrun kò ha ní ẹ̀tọ́ lati dari bi a o ṣe maa lo igbesi-aye wa bi? Oun ni Alaṣẹ Giga Julọ ní agbaye. Akọwe Bibeli naa James pè é ní ’Olofin ati onidajọ.’ (James 4:12; fiwe Isaiah 45:9.) Fun idi yii, niti awọn iwa ara-ẹni, ó yẹ ki a sún wa lati fi ohun tí Ọlọrun sọ sílò nitori pe Oun ni ó sọ ọ.

14 Oju-iwoye yii ti pese isunniṣe alagbara fun ọpọlọpọ eniyan tí wọn kò lè ṣaṣeyọri fun igba pípẹ́ Pg102sẹhin ninu fifi opin si iwa bárakú tí npanilara. Ohun tí wọn ṣe tubọ wá lekoko sii nigba tí wọn ríi pe wọn nilati yipada, kii ṣe kiki nitori ilera wọn, bikoṣe nitori pe ó wà ní ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe ofin-aṣẹ titobi julọ nì lati fẹ́ Jehofah “pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati gbogbo ọkàn rẹ ati gbogbo ero-inu rẹ.” (Matthew 22:37, NW) Lati ṣe eyiini, ẹnikan gbọdọ já ara rẹ̀ gbà lọwọ awọn ohun tí npa ero-inu lọ́bọlọ̀ tí ó sì nbà á jẹ́ tabi tí nsọ ara dibajẹ.

15 Àlékún iranwọ ni lati kẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan tí wọn nṣaáyan lati gbé ní ibamu pẹlu imọran Ọlọrun. Apostle Peter kọwe pe awọn kan, ki wọn tó di Kristian, ti wà ninu “rírìn ninu iwa wọbia, ifẹkufẹ, ati ọti amupara, ìréde òru, kíkó ẹgbẹ ọmuti, ati ibọriṣa tiiṣe ohun irira.” (1 Peter 4:3) Bi wọn ti nṣiṣẹ lati yipada, a le fun wọn lokun nipa pipade pẹlu awọn Kristian ẹlẹgbẹ wọn. Wọn yoo tipa bayii ní iṣiri lati kẹkọọ ki wọn sì fi Ọrọ Ọlọrun sílò. Ati pe, nigba tí wọn bá nṣe awọn iyipada tí a nilo naa, bi wọn bá káàárẹ̀ tabi ní imọlara àpọ̀jù inira, wọn le rí iranlọwọ gbà. Bawo? Nipa ṣiṣe ibẹwo ati sisọrọ pẹlu awọn Kristian tí wọn dagba-dénú, awọn ẹni tí yoo bani kẹdun, loye ki wọn sì gbeniro.—Oniwaasu 4:9, 10; Job 16:5.

16 Bi iwọ yoo bá fẹ iru iranlọwọ bẹẹ, a kesi ọ lati lọ si awọn ipade awọn Ẹlẹrii Jehofah. Awọn Kristian ẹni-iriri nibẹ yoo layọ lati ràn ọ lọwọ lati kẹkọọ ki o sì fi imọran Bibeli sílò. Bi o ti nní itẹsiwaju ní ṣiṣe bẹẹ, iwọ yoo ní itẹlọrun ní mímọ̀ pe iwọ nlakaka lati mú inu Ẹlẹdaa rẹ dùn. Iwọ yoo sì wà ní oju-ọna sí ilera sisunwọn ati iwalaaye gígùn, pẹlu ayọ.

[Koko Fun Ijiroro]

Àwọn idi wo ni iwọ ní lati mọ̀ pe Ọlọrun ní inudidun ninu ilera rẹ? (1-6)

Imọran Bibeli wo ni ó ní ipa lori lilo tábà? (7-9)

Bawo ni Bibeli ṣe ràn wa lọwọ ninu oju-iwoye wa nipa ọti-lile? Nipa awọn oògùn? (10, 11)

Awọn idi wo ni iwọ ní fun fifi imọran Ọlọrun sílò ninu igbesi-aye rẹ? Iranlọwọ wo ni ó wà larọwọto? (12-16)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 80 99]

“Afikun ẹri ti wà nisinsinyi pe èéfín siga nṣe ipalara kii ṣe kiki fun ẹni ti nmú un nikan ni ṣugbọn awọn tí wọn yi i ká pẹlu. . . . Bi o bá nmu siga o nilati ronu nipa ìyọrisi nipa ti ara ati ti ihuwapada ara eniyan lọna adanida lori ọmọ rẹ ati iwọ funraarẹ bakan naa. Mimu siga ìwọ funraarẹ lewu ninu fun ilera ọmọ rẹ.”—Onkọwe iwe-irohin iṣegun Dr. Saul Kapel.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 101]

“Iṣẹ-iwadii so marijuana pọ̀ mọ ọpọlọpọ awọn ọran-iṣoro ilera lilekoko niti gidi. Wọn ní ninu ibajẹ ẹ̀dòfórò ati aisan jẹjẹrẹ, arun ọpọlọ ati ori-yíyí, abuku ninu agbara tí ara ní lati kọju ija si arun, aisan iṣe-ọkọláya ati ihalẹmọni idibajẹ chromosome ati abuku ibimọ.”​—“Newsweek.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 97]

Ìmọ́tótó jẹ iranlọwọ fun ilera didara