Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iru Igbesi-aye Wo Ni Iwọ Nfẹ́?

Iru Igbesi-aye Wo Ni Iwọ Nfẹ́?

Ori 20

Iru Igbesi-aye Wo Ni Iwọ Nfẹ́?

BI ẸNIKAN bá bi ọ leere pe, ‘Bawo ni mo ṣe lè rí ayọ̀ lonii?’ Kinni yoo jẹ idahun rẹ? Iwọ lè sọ pẹlu ìdálojú-igbagbọ pe: ‘Fun igbesi-aye tí ó kunrẹrẹ, tí ó layọ tí ó sì wà pẹtiti, ṣe awọn nkan lọna Ọlọrun!’

2 Ninu awọn ori-iwe iṣaaju a ti ṣayẹwo pe Ẹlẹdaa wà nitootọ, pe oun nfunni ní isọfunni ati amọna tí gbogbo wa nilo nipasẹ Bibeli, ati pe fifi Ọrọ rẹ̀ sílò gbeṣẹ lonii. Gbígbé gẹgẹ bi awọn Kristian tootọ le ràn wa lọwọ lati koju awọn ọran-iṣòro iru bii pákánleke ati idanikanwa. Wiwo Bibeli fun amọna lè daabobo wa lọwọ awọn ọran-ìṣoro onirora eyi tí imutipara, iwa-pálapàla, àbòsí ati awọn iwa abuku miiran nṣokunfa rẹ̀. (Owe 4:11-13) Gbigba oju-iwoye Bibeli lò lori owó njẹ ki a tubọ ní itẹlọrun sii ki a si “di ìyé tootọ mú [ṣinṣin].”—1 Timothy 6:19.

3 Nigba tí a bá ṣe igbọran si ohun tí Ẹlẹdaa wi, igbesi-aye wa yoo jere itumọ yoo sì ní ìdarísọnà. Awa loye idi tí Ọlọrun fi fi àyè gba iwa-buruku ati ijiya. Bi a sì ti loye imuṣẹ awọn asọtẹlẹ Bibeli ninu awọn iṣẹlẹ ọjọ wa, a mọ pe a ngbé ninu “awọn ọjọ ikẹhin” ti eto-igbekalẹ awọn nkan buruku isinsinyi. (2 Timothy 3:1-5) Eyiini tumọsi pe laipẹ Ọlọrun yoo ké gbogbo awọn ijọba ẹda-eniyan kuro pẹlu ọrọ-itan tí ó kún fọ́fọ́ fun iwa-ibajẹ oloṣelu wọn ati awọn ẹgbẹ ologun tí a nbojuto nipasẹ ẹru-inira owó-orí tí nwọnilọrun. (Daniel 2:44; Iṣipaya 16:14, 16) Nipa bayii Ọlọrun yoo fi opin si itẹlera awọn isapa ẹda-eniyan lati ṣakoso ayé tí yoo sì dari iyoku araye tí wọn laaja nipasẹ ijọba rẹ̀ ọrun.—Iṣipaya 11:17, 18; 21:1-4.

EYIINI HA NI OHUN TÍ IWỌ NFẸ́ BI?

4 Pupọ julọ ninu wa ni yoo sọ pe: ’Yoo jẹ ohun agbayanu lati gbé laarin awọn eniyan tí wọn jẹ onifẹẹ, olubẹru Ọlọrun ninu paradise.’ (Isaiah 11:9) Ṣugbọn lati ṣe bẹẹ ifẹ wa fun ododo ati ifẹ-ọkàn wa lati mú ara wa bá awọn ọpa-idiwọn Ọlọrun mu gbọdọ lagbara tó lati ronupinnu ohun tí yoo jẹ apapọ apẹẹrẹ-awokọṣe ọna-igbesi wa isinsinyi. (Matthew 12:34; 15:19) Eyiini ha ni ohun tí iwọ nfẹ́ nitootọ bi? Lori koko yii, a misi ọmọ-ẹhin James lati kọwe si awọn Kristian pe:

“Ẹ kò mọ̀ pe ìbárẹ̀ ayé iṣọta Ọlọrun ni? Nitori naa enikẹni tí ó bá fẹ́ lati jẹ ọ̀rẹ́ ayé di ọta Ọlọrun.”—James 4:4

5 James tún tẹnumọ ọn pe iru “isin mímọ ati aileeri niwaju Ọlọrun wa” ní ninu ’pipa ara wa mọ lailabawọn kuro ninu ayé. (James 1:27) Awa nilati ṣaaapọn lati ṣe eyiini. Dajudaju, niwọn bi awọn Kristian ti ngbé laarin iwa-ipá ati iwa-ibajẹ ayé, awọn ìpèterìkíṣí oniwa-pálapàla rẹ̀, iṣelu ati ifẹ orilẹ-ede ẹni, kò rọrun lati wà laifaragbá ohun kan nibẹ rara páàpáà. Ani Kristian tí ó ní ifọkansin julọ le yọ̀tẹ̀rẹ́ tabi ṣe aṣiṣe nigba tí oun ngbiyanju lati yẹra fun didi alabawọn nipasẹ ọna ayé. Idi niyii tí aini fi wà fun awọn Kristian lati maa bá a lọ ní ṣiṣe iṣẹ lati mú ara wọn sunwọn siwaju sii. (Colossae 3: 5-10) Ṣugbọn koko naa ni pe, kinni ohun tí awa nfẹ́?

6 Gẹgẹ bi apejuwe, awa lè ronuwoye awọn ọkunrin meji tí wọn njẹ ounjẹ alẹ papọ. Ọkan lara awọn ọkunrin naa ṣèèṣì rí abawọn omi-ọbẹ lara tie tirẹ̀. Ekeji mú tie rẹ̀ ó sì mọ̀-ọ́n-mọ̀ tì í bọ inu omi-ọbẹ; oun nfẹ̀ ẹ lọna yẹn. Ewo ni awa farajọ? Nipasẹ ohun tí a yọnda fun ki ó ní agbara-idari lori wa ati ohun tí a yàn lati ṣe, awa ha nfihan pe a nfẹ́ lati jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé bi? Tabi ọ̀rẹ́ Ọlọrun?

7 Ọ̀rẹ́ pẹlu ayé ni a le fihan ní ọpọlọpọ ọna. Awọn eniyan kan ní isopọ tí ó lagbara gidigidi pẹlu idile wọn tabi awọn aladugbo debi pe wọn ntẹle, wọn tilẹ nṣe alabapin ninu, awọn ohun tí wọn mọ̀ pe Ọlọrun kò tẹwọgba, iru bii awọn aṣeyẹ tí kò bá iwe-mimọ mu, ọti amuyíràá, ìṣẹ̀fẹ̀ awọn ohun tí kò tọ́ tabi ẹ̀tanú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. (1 Peter 4:3, 4; Ephesus 5:3-5; Iṣe 10:34, 35) Bi awa bá fẹ́ lati wu Ọlọrun, nigba naa níní itẹwọgba Ọlọrun yoo ní itumọ pupọ fun wa ju ti awọn ibatan wa lọ paapaa.—Luke 14:26, 27; 11:23.

8 Bakan naa, eré idaraya tí a yàn lé fi ẹri hàn yala a fẹ lati jẹ ọ̀rẹ́ ayé. Awọn Kristian ijimiji kò jẹ lọ sibi afihan eré ìjà-iku tabi woran awọn eré tí npe afiyesi sori iwapálapàla. Awa nkọ́ lonii? Ó yẹ ki a ronu lori awọn ohun tí a yàn ṣaaju niti ọran eré ori pápá, awọn itolẹsẹẹsẹ telefision, awọn aworan ara ogiri tabi iwe kíkà. Bi a bá wòyemọ̀ pe a fẹsọyi wa leropada lati fẹ ohun tí Ọlọrun gbani-ni-mọran lodisi, aini wà fun wa lati ṣe àtúntò awọn ohun-àyàn-ṣaaju wa. Itanjẹ ayé yii lè ní ipa lori awọn ọ̀dọ́ eniyan tí wọn dagba sinu awọn idile Kristian ati awọn Kristian tí wọn ti kẹkọọ Bibeli fun ọjọ pípẹ sẹhin.

9 Ọran ọ̀rẹ̀ pẹlu Ọlọrun tabi ọ̀rẹ́ pẹlu ayé yii tumọsi ìyè tabi iku. (1 John 2:15-17) Awa kò tún lè gbé ẹsẹ kanṣoṣo si iha mejeeji ju bi eniyan kan tí ó wà ní orita kò ti lè rìn ní ipa-ọna meji tí ó pinya sira.

10 Ní awọn ọjọ Elijah, ijọsin Baal awọn orilẹ-ede tí wọn wà ní agbegbe naa ní ipa lori awọn Hebrew kan. Ani bi ó tilẹ jẹ pe wọn ní awọn isopọ kan pẹlu Ọlọrun otitọ naa, Jehofah, wọn kò rọ̀mọ́ ọn patapata. Elijah sọ pe wọn “nṣiyemeji.” Wọn nilati pinnu yala awọn yoo rọ̀mọ́ Jehofah ati awọn ọna rẹ̀ tabi bẹẹ kọ. Ò jẹ yíyàn kan tí ó tumọsi ìyè tabi iku.—1 Awọn Ọba 18:21-40; Deuteronomy 30:19, 20.

11 Awa kò lè sún ṣiṣe ipinnu ohun tí a nfẹ nitootọ siwaju. Ní ọrundun kìn-ín-ní C.E., apostle Peter rọ awọn Kristian lati ’fi dídé ọjọ Jehofah sọkan gidigidi’ ninu eyi tí a o ti pa iwa-buruku run kuro ninu ayé. Wíwà ní kanjukanju wọn ni a o fihan nipasẹ “iwa-mímọ gbogbo ati iwa-bi-Ọlọrun,” tí ó ní fifi pẹlu igbonara kede ìhìn-iṣẹ Kristian ninu. (2 Peter 3:11, 12) Nigba tí awọn Kristian kan ngbé igbesi-aye igbeyawo alapẹẹrẹ rere, awọn miiran yàn lati duro laigbeyawo ki wọn lè ’maa sin Oluwa laisi iyapa ọkàn.’—1 Corinth 7:29-35.

12 Bi iru igbesi-aye tí awọn Kristian fẹ́ lati gbé bá ṣe pataki ní ọrundun kìn-ín-ní, ẹ wo bi ó ti jẹ ọran pataki tó nisinsinyi! Awa le ríi pe ijọba Ọlọrun ti bẹrẹ iṣakoso ní lọwọlọwọ bayii ninu ọrun ati pe kiki “akoko kukuru ṣá” ni ó ṣẹku ṣaaju ki Ọlọrun nipasẹ Kristi tó fọ́ awọn orilẹ-ede túútúú, tí yo sì de Satan Eṣu. (Iṣipaya 12:12; 19:11-20:2) Nitorinaa ìsinsinyi ni akoko naa lati pinnu iru igbesi-aye tí awa nfẹ́.

IRU IGBESI-AYE TÍ ỌLỌRUN YOO PESE

13 Iru igbesi-aye tí a bá yàn nisinsinyi ni yoo pinnu yala a o fun wa ní àyọ̀ lati gbadun iru igbesi-aye tí Ọlọrun yoo pese ninu eto-igbekalẹ titun tí nbọ.

14 Ọ́ rọrun lati kọkọ ronu nipa ọpọlọpọ ibukun ti ara ti paradise naa tí a mupadabọsipo. Ninu paradise ti ipilẹṣẹ, Adam ati Efa ní ọpọ ounjẹ afaralokun. (Genesis 2:9, 16) Nipa bayii, ninu eto-igbekalẹ titun ọpọ yanturu ounjẹ didara, afunni-nilera ni yoo wà.—Psalm 72:16; 67:6.

15 Adam ati Efa ní ilera tó dara, nitori pe Ọlọrun dá wọn ní pípé. Eyiini pe afiyesi sori idaniloju tí Bibeli funni pe ninu eto-igbekalẹ titun naa aisan, irora tí arun nṣokunfa rẹ̀ ati omije ibanujẹ yoo di ohun atijọ. (Iṣipaya 21:1-4) Araye yoo dagba dé ijẹpipe ti ara.

16 Awọn ọran-iṣoro ati iku lẹhin 70 ọdun kò tún ní ṣe idiwọ funni mọ, awọn ọkunrin ati obinrin yoo ní idunnu níní agbara lati ṣe iwadii ọpọlọpọ ẹka ẹkọ ati iriri. Iwọ yoo lẹ̀ gbadun ifihan awọn ẹbun rẹ ní kíkún, ani mímú awọn kan dagba tí iwọ kò tilẹ ronu tẹlẹri pe o ní. Ounjẹ sísè, ile kíkọ́, iṣẹ gbẹnagbẹna, òṣọ ile, itọju ọgbà, lilo awọn ohun-elo orin, aṣọ rírán, kikẹkọọ awọn imọ-ẹkọ gbigbooro—ìwọ lè maa bá ṣiṣe itolẹsẹẹsẹ awọn ohun ipenija tí wọn sì ṣanfaani niṣo ṣáá eyi tí iwọ yoo ní agbara lati ṣe. Nigba kan rí Jehofah sọ pe: “Awọn ayanfẹ mi yoo jìfà iṣẹ ọwọ wọn.”—Isaiah 65:22.

17 Ati pẹlu, Bibeli sọ pe ninu ọgba Eden ounjẹ awọn ẹranko ni ewebẹ. (Genesis 1:30) Fun idi yii, iwọ lè maa wọna fun pe ki Ọlọrun ṣeto awọn ọran ki awọn ẹranko maṣe rorò tabi lewu mọ́, wọn yoo wà ní alaafia pẹlu ara wọn ati pẹlu awọn ẹda-eniyan. Tewe-tagba ni yoo gbadun ibakẹgbẹpọ wọn dé ẹkunrẹrẹ.—Fiwe Isaiah 11:6-8; 65:25; Hosea 2:18.

18 Ṣugbọn Bibeli kò bẹrẹsi ṣapejuwe ní kíkún nipa gbogbo ibukun ti ara nipa eto igbekalẹ titun naa. Jehofah, Ẹlẹdaa wa, mọ awọn aini wa. Bibeli mú un dá wa loju nipa Ọlọrun pe: “Iwọ ṣí ọwọ rẹ, iwọ sì tẹ ifẹ gbogbo ohun alaaye lọrun.”—Psalm 45:16.

19 Iwe-mimọ ṣe itẹnumọ daradara, kii ṣe aasiki tabi awọn ibukun ti ara, ṣugbọn awọn ohun ti ẹmi ati ti ọpọlọ eyi tí yoo ṣiṣẹ fun ayọ̀ ninu paradise tí a mú padabọsipo naa. Fun apẹẹrẹ, awa lè fojusọna fun awọn ipo bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ lọna yii:

“Iṣẹ ododo yoo sì jẹ alaafia, ati eso ododo yoo jẹ idakẹjẹẹ ati aabo titilae. Awọn eniyan mi yoo sì maa gbé ibùgbe alaafia, ati ní ibugbe idaniloju ati ní ibi isinmi ìparọrọ.”—Isaiah 32:17, 18.

20 Awa lè mọriri rẹ̀ pe ani bi a bá tilẹ ní ilera tí ó dara, ile tí ó dara ati ọpọlọpọ ounjẹ, awa kò lè ní itẹlọrun niti tootọ bi ô bá jẹ pe àkọlùkọgbà, ikimọlẹ idaamu, owú jíjẹ ati ibinu ló yí wa ká. (Owe 15:1; 21:9) Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan tí Ọlọrun yoo yọnda fun lati gbé ninu Paradise tí nbọ̀ yoo jẹ awọn wọnni tí wọn ti fi tọkantọkan ṣiṣẹ lati bori iru awọn ikuna eniyan bẹẹ. Wọn yoo di idile awọn Kristian kari-aye tí wọn mú awọn eso ẹmi Ọlọrun dagba, ninu wọn ni ifẹ, alaafia, inurere ati ikora-ẹni-nijanu. (Galatia 5:19-23) Wọn yoo fi pẹlu otitọ inu lakaka lati ní awọn akopọ-animọ-iwa tí wọn wà ní ibamu pẹlu akopọ-animọ-iwa Jehofah.—Ephesus 4:22-24

WIWALAAYE LATI WÙ ATI LATI YIN JEHOFAH

21 Awọn ibukun ti ara ati ti ẹmi tí a sọtẹlẹ naa fun wa ní idi lati maa wọna fun eto-igbekalẹ titun naa. Bi o ti wu ki o ri, bi a bá jẹ ki awọn wọnni jẹ awọn idi pataki fun jijọsin Ọlọrun ati gbígbé igbesi-aye Kristian, dé iwọn àyè kan awa yoo dabi iran eniyan oniwa-temi-ṣáá ti isinsinyi tí olori aniyan wọn jẹ nipa ohun tí wọ́n nfẹ́ tí wọn sì lè rí.

22 Kaka bẹẹ, awa nilati mú ifẹ-ọkan dagba fun gbígbé igbesi-aye Kristian—nisinsinyi ati ní ọjọ iwaju—nitori pe Ọlọrun nfẹ ki a ṣe bẹẹ. Oun ni ó gbọdọ gba ipo akọkọ, kii ṣe awa. Jesu fi oju-iwoye tí a nilo hàn, ní wiwipe: “Mo dé . . . lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun,” ati, “Ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni tí ô rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.” (Hebrew 10:7; John 4:34) Imọriri fun ohun tí Ọlọrun ti ṣe gbọdọ sún wa lati fi i si ipo kìn-ín-ní.—Rome 5:8.

23 Lọna tí ó baamu gẹ́ẹ́, Bibeli kò tẹnumọ igbala wa ati awọn ibukun tí a lè rí gbà gẹgẹ bi eyi tí ó ní ijẹpataki tí ó gajulọ. Kaka bẹẹ, ó tẹnumọ idalare orukọ Ọlọrun ati ẹtọ wa fun yiyin Ọlọrun fun ohun tí oun jẹ́ ati ohun tí ó ti ṣe. David kọwe pe:

“Emi yoo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi; emi yoo sì maa fi ibukun fun orukọ rẹ lae ati laelae. Titobi ni [Jehofah], ó sì ní ìyìn pupọpupọ. Àwámárídìí sì ni titobi rẹ̀. Emi yoo sọrọ ìyìn ọlánlá rẹ tí ô logo, ati ti iṣẹ-iyanu rẹ.”— Psalm 145:1, 3, 5.

24 Fifi Ọlọrun ṣaaju ninu igbesi-aye ati fifi taapọn-taapọn yìn ín jẹ ohun tí ô tọna fun Jesu ati David. Ó sì tún tọna fun awa naa pẹlu. Nigba tí a bá pa eyi pọ̀ mọ ọna igbesi-aye Kristian tí ó gbeṣẹ, awa yoo ti rí ayọ̀—nisinsinyi ati ní ọjọ-iwaju pipẹtiti.

Nisinsinyi iwọ ti ṣayẹwo ọpọlọpọ awọn ẹkọ idi-ipilẹ pataki inu Bibeli. Awa yoo gbà ọ niyanju lati maa bá a lọ lati maa dagba ninu imọ Ọrọ Ọlọrun. Awọn aranṣe fun ọ bi o ti nṣe eyi niwọnyi:

[Koko Fun Ijiroro

Eeṣe tí ṣiṣe awọn nkan lọna ti Ọlọrun fi jẹ ọna didara julọ fun rírí ayọ̀? (1-3)

Eeṣe tí awa fi gbọdọ pinnu yala a fẹ́ lati jẹ ọ̀rẹ́ ayé tabi ti Ọlọrun? (4-6).

Ní awọn ọna wo ni ẹnikan lè gbà fihan yala oun nifẹẹ sí ọ̀rẹ́ pẹlu ayé? (7, 8)

Bawo ni ó ti ṣe pataki tó fun wa lati ronupinnu ohun tí a nfẹ nitootọ? (9-12)

Iru igbesi-aye wo ni Ọlọrun yoo pese ninu eto-igbekalẹ titun? (13-18)

Awọn ibukun pataki jù wo ni a ṣeleri fun paradise tí a mú padabọsipo? (19, 20)

Bawo ni a ṣe lè rí ayọ̀ tootọ? (21-24)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 189]

Akoko imudagba ati ilo awọn ẹ̀bùn rẹ dé ẹkunrẹrẹ