Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iwọ Lè Kojú Awọn Ọran-iṣoro Igbesi-aye

Iwọ Lè Kojú Awọn Ọran-iṣoro Igbesi-aye

Ori 5

Iwọ Lè Kojú Awọn Ọran-iṣoro Igbesi-aye

“IGBESI-AYE kún fun awọn ọran-iṣoro,” ni ohun tí awọn eniyan nsọ. Iwọ lè fohunṣọkan.

2 Awọn iṣoro ti owô nyọ Ọpọlọpọ lẹnu—iwe-owó fun sísan, ìfòsôkè owô ọjà, aini ìfàyàbalẹ̀ lẹnu iṣẹ, tabi rírí ile tí ô baramu gbé. Awọn ọran-ìiṣoro wiwuwo ti igbeyawo ati ti idile wọpọ. Ibalopọ takọtabo, ọti tabi oògùn jẹ awọn ọran-iṣoro fun ọpọlọpọ ọdọ. Fun awọn ti wọn lọjọ lori, ilera tí nlọsilẹ sii mú awọn inira dání. Gbogbo awọn wọnyi nṣokunfa àìfararọ ati pákánleke tí npanilara nipa ti ẹmi-ero.

3 Bawo ni o ti ṣe nkoju awọn ọran-iṣoro igbesi-aye daradara tó? Awọn irohin nipa irẹwẹsi tí ô gbodekan kaakiri ati ìpara-ẹni tọkafihan kedere pe ọpọlọpọ eniyan ni wọn kò lè kojú rẹ̀. Ṣugbọn araadọta ọkẹ awọn eniyan wà tí wọn kii ju ipo idurodeedee wọn nù nigba tí túláàsì bá dojukọ wọn. Eeṣe?

4 Awọn tí a ṣapejuwe kẹhin wọnyi ti kẹkọọ lati gbẹkẹle imọran Ẹlẹdaa araye gẹgẹ bi a ti ríi ninu Bibeli. Kò sí onimọ ironu ọgbọn ori eniyan, kò sì ọmọran lori igbeyawo, kò sí imọran onkọwe iwe-irohin kan tí ó mọ pupọ nipa igbesi-aye ju Ọlọrun lọ. Oun ni ó ṣẹda awọn ẹda-eniyan akọkọ, nitori naa ó ní imọ tí ó jinlẹ niti ohun tí a jẹ nipa ti ara, ti ọpọlọ ori ati ti ẹmi-ero. (Psalm 100:3; Genesis 1:27) Ní sisuwọn ju ẹda-eniyan ọlọjọ kukuru eyikeyi lọ, Jehofah mọ ohun tí nlọ ninu wa lọhun ati idi rẹ̀ tí a fi nṣe awọn nkan tí a nṣe.—1 Samuel 16:7.

5 Siwaju sii, ó tún jẹ ojulumọ daradara si awọn ọran-iṣoro tí wọn dojukọ wa ninu ayé ju ẹnikẹni lọ ninu wa. Kii kàn wulẹ ṣe fun kiki awọn ọdun diẹ kan, ṣugbọn lati igba ọkunrin akọkọ, Jehofah ti ṣakiyesi awọn ọran-iṣoro iran ẹda-eniyan​—gbogbo wọn. Bibeli sọ fun wa pe: [Jehofah] wò lati ọrun wá, ô rí gbogbo ọmọ-eniyan. . . . Ó wo gbogbo araye. . . . Ó kiyesi gbogbo iṣe wọn.” (Psalm 33:13-15) Eyiini tumọsi pe ô mọ ohun tí a lè ṣe aṣeyọri ati ohun tí kò lè ṣe aṣeyọri ní kíkojú iru awọn ọran-iṣoro eyikeyi tí a ní.

6 Pẹlu iwa ọlawọ, ô mú ki ô ṣeeṣe fun wa lati jere lati inu imọ ati iriri rẹ̀. Bibeli ní imọran rẹ̀ ninu, tí a gbekalẹ lọna tí ó fi jẹ pe ô bá awọn aini wa mu bi ó ti wu ki awọn ayika-ipo wa rí ninu igbesi-aye, laika ibi tí a ngbé sí. Gẹgẹ bi Psalm 19:7-11 ti sọ: “Ofin [Jehofah] pé, ô nyí [ọkàn-àyà] pada. [Irannileti Jehofah] daniloju, ó nsọ òpè di ọlọgbọn.”

7 Ẹ jẹ ki a yara ṣe ayẹwo bi awọn irannileti wọnni ṣe lè ṣeranwọ fun ẹnikan lati kojú awọn ọran-iṣoro ti ara-ẹni wiwuwo meji kan, eyiini ni, pákánleke lilekoko ati dídánìkanwà. Lẹhin tí a bá ti ṣe ayẹwo iranlọwọ Bibeli tí ó wulo lori awọn ọran wọnyi tán, a o ṣe ayẹwo awọn ọran-iṣoro miiran tí wọn wọpọ—-tí ô niiṣe pẹlu owó, igbeyawo ati oògùn.

BAWO NI IWỌ ṢE LÉ KOJÚ PÁKÁNLEKE?

8 Iwọnba awọn eniyan diẹ pere ni wọn yoo lè sọ pe awọn kò tíì ní iriri pákánleke lilekoko rí lae. Bi awọn ọran-iṣoro ti ẹnikọọkan wa bá ṣe ndagba sii—lori owô, idile, ibalopọ takọtabo, iwa ọdaran—bẹẹ ni pákánleke naa ṣe nlekoko sii. Irohin kan ti lọọlọọ yii ninu iwe-irohin kan sọ pe ohun tí ô mú ki awọn akoko wa yii dádúrô gédégbé kii ṣe ọna tí a gbà nhuwa tabi ọna ìgbà-wọṣọ. Ò jẹ “imọlara tí ó buru jáì ti àìfararọ.

9 Iwọ ha mọ̀ pe pákánleke tilẹ lè mú iwalaaye rẹ kuru bi? Ṣakiyesi:

“Pákánleke tí a npe ní ‘Pani-pani Ọ̀rúndún Ogún,’ maa ndide lati inu awọn ohun tí ironu ọpọlọ nbeere ninu igbesi-aye ti ode-oni. Ailera ti ara tí ô nmujade nisinsinyi nṣe afikun si awọn iye tí ô ga pupọ niti awọn ọran tí ó niiṣe pẹlu ile-itọju-alaisan ati iku lọdọọdun—ô keretan araadọta ọkẹ lọna mẹwa-mẹwa.—To the Point, iwe-irohin ti Africa.

“Pákánleke lilekoko tabi ọlọjọ pípẹ lè mú ki ara wà ní ipo tí kò lagbara lati dena awọn aisan kan, bẹrẹ lati ori àléfẹ ati otutu titi dé ori arun ọkàn-àyà ati cancer.”— The Wall Street Journal, U.S.A.

Ani ô tún kan awọn ọmọ tí a kò tíì bí paapaa. Pákánleke lorì awọn aboyun, iru bii eyi tí ó jẹ jade lati inu ìjọ̀gbòn igbeyawo tabi ibẹru ainiṣẹlọwọ, lè ṣe ipalara ti ara, ti ọpọlọ ati ti ẹmi-ero si awọn ọmọ tí wọn wà ninu ile-ọlẹ̀.

10 Pákánleke pẹlu tún nṣe ipalara niti pe ó nṣokunfa awọn ọran-iṣoro miiran. Nitori rẹ̀ ọpọlọpọ npadanu akoko iṣẹ wọn, tí ô si nfikun awọn ọran-iṣoro owó wọn. Ô nfa iwa-ipá, ani ninu igbeyawo paapaa. Ọkọ kan kọwe pe:

“Lojoojumọ ni nkan maa nlekoko mọ́ mi tí jìnnìjìnnì si nbò mi mọlẹ. Ô maa ndabi pe ki emi maa na gbogbo eniyan ní pàṣán, iyawo mi a sì maa rí eyi gbà deedee. Imọlara mi ni lati mutipara nigba gbogbo, ṣugbọn kò ṣe rere kankan.”

11 Awọn pákánleke kan jẹ lọna ti ẹda ninu igbesi-aye, tí kò sì fi dandan jẹ ohun tí ó buru. Didide kuro lori ibusun lowurọ ní pákánleke ninu, bi ó ti rí nigba tí a bá nworan eré bọọlu kan tí ô kanilara. Pákánleke tí ó ga pupọ, tí ô sì gùn lọ titi (tabi, hilahilo) ni ó npanilara. Amọ ṣa o, ọpọlọpọ awọn ikimọlẹ tí wọn wà lori wa ni wọn lè dabi eyi tí kò ṣee yẹsilẹ, tí wọn kan awọn ẹlomiran tabi awọn ayika-ipo kan ninu igbesi-aye awa tikaraawa. Njẹ, bi o tilẹ rí bẹẹ, kò ha sí ohun kankan tí a lè ṣe nipa pákánleke tí npanilara bi? Bi a bá lè kojú pákánleke lọna tí ó dara sii, ó lè dín awọn ọran-iṣorò miiran kù, iru bii awọn wọnni tí nnipa lori ilera wa.

12 Aṣiri kan fun kikoju pákánleke ni a funni lati ọ̀dọ̀ ọkunrin kan tí a mọ̀ kari ayé gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn olukọ titobi julọ tí ó tíì gbé lori ilẹ-aye, Jesu kristi. Nigba tí a bi í leere nipa ewo ni ô ṣe pataki julọ ninu gbogbo awọn ofin-aṣẹ Ọlọrun, Jesu dahun pe, ‘Ki iwọ ki ô fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ [Jehofah] Ọlọrun rẹ. Iwọ fẹ́ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.’ (Matthew 22:37-39) Fi eyiini si ìlò, iwọ yoo sì rí iranlọwọ lati kojú pákánleke.

13 Fun apẹẹrẹ, bi o ti nfi pẹlu ifẹ bá ẹnikeji ninu igbeyawo ati awọn mòlẹbí rẹ lò, ô ṣeeṣe gidigidi pe alaafia yoo pọ̀ síi. Ayika onifẹẹ ati ayọ̀ yoo dagbasoke. Àìfararọ yoo dinku. Bẹẹ ni, imọran Iwe-mimọ yii ni a lè tẹle pẹlu awọn abajade rere ní dídín pákánleke kù.

14 Bẹẹ sì ni kò mọ sọdọ idile nikan. Bi o ti nlo imọran Bibeli lati fifẹhan—tí ô ní ninu ’ofin-idiwọn oniwura nì’ ti hihuwa si awọn ẹlomiran bi iwọ yoo ti fẹ́ ki wọn ṣe sí ọ—awọn eniyan yoo fẹran rẹ pupọ sii. (Luke 6:31) Eyiini ti jẹ otitọ lẹnu iṣẹ, ní ile-iwe, ní adugbo. Ôò, ìjọ̀gbòn diẹ lè wà, ṣugbọn dajudaju yoo mọniwọn. Ô rọrun lati ríi pe, gẹgẹ bi abajade kan, iwọ yoo dojukọ pákánleke tí ô dinku sii.

15 Ní agbo awọn onimọ-ijinlẹ paapaa a mọriri rẹ̀ pe Pg46ohun tí Bibeli dabaa yoo ran awọn eniyan lọwọ lati dín pákánleke kù ki wọn si lè kojú rẹ̀. Professor Hans Selye (University of Montreal), ọkan ninu awọn ògbónkangí tí ô gba iwaju julọ ninu imọ nipa awọn ipa tí pákánleke nní lori eniyan, funni ní imọran pe:

“Kaka tí a o fi gbarale awọn oògùn tabi awọn ọna miiran, mo rò pe ohun miiran ṣì wà, ọna kan tí ô sàn jù lati bojuto pákánleke, eyi tí ó ní ninu níní iṣarasihuwa tí ó yatọ si awọn oriṣiriṣi iṣẹlẹ ninu igbesi-aye wa.”

Oun tẹnumọ aini tí ô wà fun ìmọ-ọran iwa híhù nipa eyi tí awọn eniyan fi lè maa gbé, eyi tí yoo iṣe pupọ sii fun iran-eniyan ní gbogbogboo ju awari eyikeyi lọ.” Kinni? Lẹhin 40 ọdun ṣiṣe ìwadii nipa pákánleke, oun sọ pe idahun naa ní pataki fàbòọ sori—ìfẹ.

16 Eeṣe tí ô fi jẹ pe, ani ninu igbesi-aye ojoojumọ, fifi ifẹ hàn bi Bibeli ti dabaa rẹ̀ wulo tobẹẹ? Eeṣe tí ó fi nṣiṣẹ? Dr. Selye sọ pe:

“Awọn ẹmi-ero meji titobi tí nfa wíwà tabi aisi pákánleke ni ifẹ ati ikorira. Bibeli sọ koko yii ní asọtunsọ. ìhìn-iṣẹ naa ni pe bi a kò bá ṣe atunṣe iwa imọtara-ẹni-nikan ti ô wà ninú wa, awa yoo maa mú ki ibẹru ati ikorira dagba ninu awọn eniyan miiran. . . . Bi a bá ṣe lè sún awọn ẹlomiran lati fẹran wa sí tô dipo ki wọn korira wa, bẹẹ ni yoo ti ṣalailewu tô fun wa, ati pe pákánleke tí a nilati farada yoo dinku bẹẹ gẹgẹ.”

17 Ibinu jẹ idi miiran kan fun pákánleke. Gbogbo wa ni a maa nbinu ní awọn igba kan, gẹgẹ bi Bibeli ṣe sọ ọ. Sibẹ ô funni ní imọran pe: Ẹni tí ô lọra ati binu ô sàn ju alagbara lọ; ẹni tí ô sì ṣe akoso ẹmì rẹ̀, ô ju ẹni tí ó ṣẹgun ilu lọ. (Owe 16:32; Ephesus 4:26) Nitori naa bi inu ba nbí wa, ikilọ Ọlọrun ni pe ki a yago fun títu itọ soke ki a fojú gbà á tabi ’ki a yári patapata.’ Nigba pupọ awọn wọnni tí wọn bá kọ eti ikún si imọran ni wọn maa nda ọwàrà awọn ọrọ buburu silẹ tabi tí wọn maa nbọ sinu ìwàyá-ìjà oniwa-ipá. Awọn abajade rẹ̀ ní awọn igba miiran maa njẹ ipalara ti ara tabi ti ero buburu, tí ô ní pákánleke tí ô wà pẹtiti ninu. Fun idi yii, dé àyè ibi tí iwọ bá lè tẹle imọran ọlọgbọn Bibeli wiwulo nipa ibinu dé, iranlọwọ ni yoo jẹ fun ọ lati koju pákánleke.

18 Gẹgẹ bi apẹẹrẹ miiran, Bibeli tún ràn wa lọwọ lati dín pákánleke kù nipa fifunni ní iṣiri lati gbé igbesi-aye kan tí kò duro sojukan gbagidi tí ô si wà ní iwọntunwọnsi. Awọn eniyan kan wà tí wọn maa nṣiṣẹ ní àṣekúdôrôgbé, awọn miiran kò tilẹ fẹ ṣiṣẹ rara. Awọn eniyan diẹ maa nwà ní ipo kanjúko ní gbogbo igba, awọn miiran kii tilẹ ṣe bẹẹ rara. Iru ipo eyi tí ô rekọja ààlà eyikeyi bẹẹ lọna aiṣee yẹsilẹ maa nfa awọn ọran-iṣoro tí ô sì nyọrisi pákánleke. Bi o ti wu ki o ri, ka awọn alaye tí wọn wà ninu Oniwaasu 3:1-8, nibi tí Ọlọrun ti sọ pe akoko wà fun olukuluku igbokegbodo-iṣẹ. Ṣe o ríi, Bibeli pese oju-iwoye kan tí ô bá ipo bi nkan ti rí gan-an mu ati pẹlu tí ô sì wà ní iwọntunwọnsi pupọ sii nipa igbesi-aye. Iṣẹ dara, ní iyatọ si ẹlẹ. Bibeli tún rọ awọn eniyan lati ní isinmi-ìdẹ̀ra diẹ ki wọn si gbadun awọn eso iṣẹ wọn. (Oniwaasu 3:12, 13; 10:18; Owe 6:9-11) Anfaani wà tí a lè jere lati inu akoko diẹ tí a lò ninu rironu jinlẹ nipa ohun tí igbesi-aye tumọsi ati bi a ṣe lè maa gbé e. Sibẹ iniyelori tún wà pẹlu ninu níní isinmi-ìdẹ̀ra pẹlu idile ẹni ati awọn òrẹ́. Dé àyè tí a bá lè fi imọran Bibeli sí ìlò nipa iwọntunwọnsi, ni awa yoo fi ní ọran-iṣoro kan tí ô dinku pẹlu pákánleke.

KIKOJU IRORA ÌDÁNÌKANWÀ

19 “Ìdáníkanwà jẹ ohun kari ayé,” ni ohun tí oṣiṣẹ afẹnifẹre ara Toronto Henry Regehr sọ. Dá ẹnikẹni duro ní opopo-ọna ki o si sọ pe ’sọ fun mi nipa ìdáníkanwà rẹ! iwọ yoo si gbọ́ itan lẹhin itan ati itan sii. Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu awọn 52,000 eniyan, eyi tí ô ju ida 40 lori ọgọrun lọ ni wọn sọ pe awọn “saba maa nnimọlara ti dídánìkanwà.” Ò jẹ imọlara tí ó saba maa nṣokunfa aini idunnu, tí ô si maa nba ayọ̀ jẹ julọ. Bẹẹ ni kò dá ẹnikan mọ̀ yatọ, ô maa nkọlu tewe-tagba, ọkunrin ati obinrin. Bi o tilẹ jẹ pe a lẹ ronu nipa àpôn kan iru bii opobinrin kan, gẹgẹ bi apẹẹrẹ pataki kan nipa ẹni tí ó dáwà ní oun nikan, awọn kan lara awọn tí wọn dánìkanwà lọna tí ô buru jai ni awọn eniyan tí wọn jẹ tọkọtaya tí wọn kò lè bá ara wọn sọrọ.

20 Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn ngbiyanju lati ṣe idena fun ìdánìkanwà pẹlu ibalopọ takọtabo lọna àìtọ́, tabi tí wọn fẹ́ lati fi ọti bò ó mọlẹ tabi lati pa á kú nipa didi wònbílíkí-wòbìà. Ṣugbọn awọn ohun tí wọn ṣokunfa naa ṣì wà nibẹ sibẹ. Idi kan ni idagbasoke awọn ilu nlanla, nibi tí awọn eniyan tilẹ lè wà ní ayika rẹ sibẹ ki o sì ní imọlara dídánìkanwà gidigidi. Iwolulẹ awọn igbeyawo ti fikun ọran-iṣoro naa. Ani tẹlefision paapaa dabi eyi tí ó ti fikun ìdánìkanwà nipa mímú ki ijumọsọrọpọ lọsilẹ.

21 Kinni ohun tí a lè ṣe lati ṣeranwọ lati kojú ìdánìkanwà? Niwọn bi kii tíi ṣe pe a nifẹẹ lati sọ ọran-iṣoro naa di ohun tí ô rọrun julọ, a lè sọ pe Bibeli lè ṣeranwọ fun ẹnikẹni lati kojú ìdánìkanwà lọna tí ô sàn jù. Eeṣe tí eyiini fi rí bẹẹ? Fun ohun kan, ìdánìkanwà saba maa nyọrisi ikimọlẹ onirẹwẹsi ati ipadanu ọ̀wọ̀ ara-ẹni. Mímú ibatan rere dagba pẹlu Ẹlẹdaa ẹni lè ṣe iranlọwọ lati dá iru eniyan bẹẹ padabọsipo. Oun lè mú imọlara jíjẹ ẹni tí o loye pupọ sii dagba, ní mimọriri rẹ̀ pe Ọlọrun nifẹẹ oun, eyi tí ó lè ṣamọna si oju-iwoye tí ô ṣe taarata nipa igbesi-aye. (Matthew 18:10) Siwaju sii, Bibeli ṣe itolẹsẹẹsẹ fun awọn Kristian ọna igbesi-aye kan tí ó lè ṣe iranlọwọ lati funni ní itura kuro lọwọ ìdánìkanwà.

22 Awọn eniyan tí wọn dánìkanwà ni a saba maa nsọ fun pe ki wọn jẹ ki ọwọ dí fun iṣẹ. Eyi ní iniyelori diẹ ninu. Ṣugbọn Bibeli funni ní imọran tí ô bá bi ọran naa ti rí mu tí ó si gbeṣẹ julọ. Ô rọ awọn Kristian lati kún fun iṣẹ pẹrẹu ní ṣiṣe rere fun awọn ẹlomiran eyi tí ô tún nmú ayọ̀ wá. (Iṣe 20:35) A rí apẹẹrẹ kan ninu Dorcas, ẹni tí ó lo akoko rẹ̀ ní ṣiṣe awọn nkan fun awọn Kristian miiran, tí pupọ ninu wọn jẹ awọn opobinrin. Awọn isapa rẹ̀ ràn wọn lọwọ nipa ti ara, tí i sì ṣeeṣe ki ô ràn wọn lọwọ lati bori ìdánìkanwà pẹlu. Lakoko kan naa Dorcas kò dá wà ní oun nikanṣoṣo ṣugbọn a nifẹẹ rẹ̀. Iwọ lè gbadun kíkà nipa rẹ̀ ninu Iṣe 9:36-42.

23 Igbokegbodo-iṣẹ kan tí ó léré ninu gidigidi ọpọ awọn Kristian ti jẹ ti riran awọn ẹlomiran lọwọ lati kẹkọọ nipa Ọlọrun ati Bibeli. Niti tootọ, apostle Paul sọ pe ominira lati ṣe eyiini dé àyè-ipo tí ô tobi pupọ sii jẹ anfaani tí awọn àpọ̀n ní, eyi tí, dajudaju, yoo tún ràn wọn lọwọ lati kojú ìdánìkanwà. (1 Corinth 7:32-35) Paul tikaraarẹ̀ jẹ apẹẹrẹ iru eyi kan. Kà ninu Iṣe 17:1-14 bi, laika atako àràmàndà sí, ọwọ Paul ti dí ní riran awọn ọpọlọpọ lọwọ ní ilu Thessalonica. Lẹhin naa ṣakiyesi imọlara ti sisunmọra-ẹni pẹkipẹki tí ó jẹ abajade rẹ̀ laarin wọn, tí a mẹnukan ninu 1 Thessalonica 2:8. Ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn Ẹlẹrii Jehofah lonii lè jẹrii si bi ô ti lérè ninu tó lati jẹ ki ọwọ ẹni dí fun kíkọ́ awọn ẹlomiran ní Bibeli.

24 Pẹlupẹlu, awọn Ẹlẹrii Jehofah npadepọ deedee ní ẹgbẹẹgbẹ lati kẹkọọ Iwe-mimọ. Nigba tí wọn bá nkẹkọọ, wọn ngbadun ibakẹgbẹpọ ọlọyaya ti Kristian. Nitootọ, wiwulẹ wà laarin awọn eniyan miiran kii ṣe idahun si ìdánìkanwà, gẹgẹ bi pupọ awọn olugbe ilu-nla ti ṣe mọ̀. Ṣugbọn awọn wọnni tí wọn nlọ si iru awọn ipade bẹẹ wà lara awọn Kristian tí wọn nlakaka lati inu ọkàn-àyà wá lati fi iṣiri Bibeli sílò lati ní ojulowo ifẹ ninu awọn ẹlomiran. (Philippi 2:4) Awọn ipade wọnyi jẹ awọn akoko-iṣẹlẹ amoriya ati alayọ. Awọn tí wọn wà nibẹ ndarapọ ninu adura kukuru si Ọlọrun, ohun kan tí awọn pupọ ti ríi pe ô ṣe iranlọwọ lati mọ̀ pe awọn kò dáwà lae ní ẹnikanṣoṣo. (John 16:32) A fun ọ ní iṣiri lati lọ si ipade awọn Ẹlẹrii Jehofah. Nibẹ o lè ṣakiyesi bi titẹle imọran Bibeli ti nran awọn eniyan pupọ lọwọ lati kojú ìdánìkanwà ati awọn ọran-iṣoro miiran, bii iru awọn wọnni tí ó niiṣe pẹlu owò tabi idile.

[Koko Fun Ijiroro]

Àwọn idi wo ni a ní lati lérò pe ohun tí ó dara yoo ṣẹlẹ niti awọn ọran-ìṣoro igbesi-aye? Bawo ni ọran naa ṣe kan Ọlọrun? (1-7)

Bawo ni ọran-iṣoro ti pákánleke ti lekoko tó? (8-11)

Bawo ni imọran Bibeli ṣe lè ràn wa lọwọ lati kojú pákánleke? (12-14)

Kinni ohun tí awọn onimọ-ijinlẹ ti rí nipa imọran Bibeli lori ifẹ? (15, 16)

Lọna miiran wo ni imọran Bibeli lè gbà ràn wa lọwọ ninu ọran pákánleke? (17, 18)

Bawo ni ọran-iṣoro ìdánìkanwà ti wuwo tó? (19, 20)

Imọran Bibeli wo ni ó lè ṣe iranlọwọ niti ọran ìdánìkanwà? Bawo ni? (21-23)

Iniyelori wo ni ibakẹgbẹpọ Kristian ní ninu? (Oniwaasu 4:9, 10) (24)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 45]

AWỌN IPO IGBESI-AYE ‘ONIPAKANLEKE’ JULỌ

ÌṢÒRO IṢẸLẸ IGBESI-AYE

1 Iku ẹnikeji ẹni ninu igbeyawo

2 ikọsilẹ

3 Ipinya tọkọtaya

4 Ifisẹwọn

8 Iku memba idile kan tí ó sunmọni pẹkipẹki

6 Ipalara tí ara-ẹni tabi aisan

7 Igbeyawo

8 Lílé kuro lẹnu iṣẹ

9 Ìlàjà laarin tọkọtaya

10 Ifẹhinti lẹnu isẹ

11 Iyipada ninu ilera memba idile

12 Liloyun

13 Awọn iṣoro ọran ibalopọ takọtabo

14 Jijere memba idile titun

15 Atunṣe ninu iṣowo

A gbé e ka ori iṣẹ-iwadii lati ọdọ̀ awọn Dokita T. Holmes ati R. H. Rahhne—“Modern Maturity.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 50]

“Ninu igbesi-aye wọn laarin ijọ awọn Ẹlẹrii parapọ jẹ ojulowo ẹgbẹ eniyan niti igbẹkẹle ati itẹwọgba. . . . Awọn Ẹlẹrii Jehofah nfunni ní ọna ọgbọn igbesi-aye miiran kan ti nfun awọn tí wọn bá rọ̀mọ ọn ní ọna kan lati ri iru ẹni tí wọn jẹ pato ati ọ̀wọ̀ ara-ẹni, ẹgbẹ eniyan kan nibi tí itẹwọgba wà, tí ireti fun ọjọ-ọla sì nbẹ.”​—“Religious Movement in Contemporary America.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 41]

IFOSOKE OWÓ ỌJA

AISAN

IPO ELEWU LẸNU IṢẸ

ỌRAN-IṢORO IDILE

ILE GBÍGBÉ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 49]

Ṣiṣe rere fun awọn ẹlomiran, gẹgẹ bi Dorcas ti ṣe, nṣeranwọ lati dena ìdánìkanwà.