Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iwọ Yoo Ha Jọsin Ọlọrun Lọna TIRẸ Bi?

Iwọ Yoo Ha Jọsin Ọlọrun Lọna TIRẸ Bi?

Ori 19

Iwọ Yoo Ha Jọsin Ọlọrun Lọna TIRẸ Bi?

BIBELI sọtẹlẹ pe, ní “awọn ọjọ ikẹhin,” awọn eniyan yoo “jẹ olufẹ ti ara wọn, afúnnu, agberaga, . . .tí wọn ní afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn tí wọn sẹ agbara rẹ̀.” (2 Timothy 3:1-5) Eyiini kò ha ṣapejuwe ohun tí a nrí ní ayika wa lonii daradara bi?

2 Bẹẹ ni, ní gbogbo apá igbesi-aye ni awọn eniyan ti nhuwa lọna tí nsọ pe, “Temi lakọkọ.”—iwa wọn nibi ọjà rírà tabi ọkọ̀ wíwà, afiyesi tí wọn nfun aṣọ wíwọ̀ ati ọ̀ṣọ́ ṣiṣe, ati ìru ijò tí wọn njó. Ṣugbọn gbogbo eyi kò tíì mú ayọ̀ gidi wá.

3 Ọpọlọpọ eniyan ni wọn tilẹ nwo isin ni ibamu pẹlu ohun tí wọn nfẹ tabi ní imọlara pe wọn nilo. Ẹ wo bi eyi ti jẹ aṣiṣe tó! Kii ṣe awa ni yoo sọ bi ó ti yẹ ki a jọsin Ọlọrun. Gẹgẹ bi Ẹlẹdaa ati Olufunni ní ìye, Jehofah ni ẹni naa tí yoo sọ bi ó ti yẹ ki a jọsin oun. (Rome 9:20, 21) Ohun tí oun sì beere lọwọ wa jẹ fun ire tiwa. Ó nmú itẹlọrun wá nisinsinyi ó si nfi ero-inu ati ọkàn-àyà wa sori awọn ohun agbayanu tí oun ní ní ipamọ fun wa lọjọ-iwaju.—Isaiah 48:17.

4 Jehofah kii dẹrùpa awọn Kristian pẹlu awọn ayẹyẹ tí kò wulo tabi ki ó gbé ikalọwọko alainidii kà wọn. Ṣugbọn Jehofah mọ̀ pe iwalaaye titi lọ sinmi lori ibatan rere pẹlu oun, ati pe aini wà fun wa lati gbé ní ibamu pẹlu awọn ọpa-idiwọn rẹ̀ ki a sì fi ìdàníyàn hàn fun awọn ẹlomiran bi awa bá nilati rí igbadun tootọ ninu igbesi-aye. Nigba tí awa bá jọsin Ọlọrun lọna tí oun nfẹ, igbesi-aye yoo tubọ di ọlọràá sii yoo sì ní itumọ.

ṢIṢE AWỌN NKAN LỌNA ỌLỌRUN

5 Noah jẹ apẹẹrẹ rere kan ti eniyan kan tí ó huwa ní ibamu pẹlu awọn ọna Ọlọrun. Bibeli sọ pe: “Noah ṣe olootọ ati ẹni tí ó pé ní ọjọ ayé rẹ̀. Noah bá Ọlọrun rìn.? Lẹhin igba tí Ọlọrun fun un ní awọn ìtọni lati kan ọkọ̀ ark titobi agbẹ̀mílà kan, “”Bẹẹ ni Noah sì ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyi tí Ọlọrun paṣẹ fun un, bẹẹ ni ó ṣe.” (Genesis 6:9, 22) Ṣiṣe awọn nkan lọna Ọlọrun gba iwalaaye Noah là, ati iwalaaye idile rẹ̀ bakan naa, awọn ẹni tí wọn rọ̀mọ́ ọn gẹgẹ bi wolii Ọlọrun lori ilẹ-aye.—2 Peter 2:5.

6 Ẹlomiran tí ó tẹle ọna Ọlọrun ni Abraham. Ọlọrun sọ fun un lati fi ilu-ibilẹ rẹ̀ silẹ. Iwọ yoo ha ti ṣe igbọran bi? Abraham “lọ, bi (Jehofah) ti sọ fun un,” bi oun tilẹ wà láìmọ ibi tí oun nrè.’’ (Genesis 12:4; Hebrew 11:8) Nitori fifi iṣotitọ ṣe awọn nkan lọna Ọlọrun, a ka Abraham si gẹgẹ bi ’ọ̀rẹ́ Jehofah.’—James 2:23; Rome 4:11.

WÍWA LARA AWỌN ENIYAN ỌLỌRUN

7 Lẹhin akoko gigun kan Ọlọrun yàn lati bá ẹgbẹ titobi kan lò, orilẹ-ede Israel. Wọn di “awọn eniyan rẹ̀,” “eniyan ọ̀tọ̀ fun ara rẹ̀, ju gbogbo orilẹ-ede tí nbẹ lori ilẹ.” (Deuteronomy 14:2) Dajudaju, aini wà fun ọmọ Israel kọọkan lati gbadura si Ọlọrun ki ó sì ní ibatan timọtimọ, ti ara-ẹni pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn wọn tún nilati mọ̀ ní àmọ̀dunjú pe Ọlọrun ló ndari ijọ; wọn nilati tẹle iru ijọsin tí a làsílẹ̀ ninu ofin Ọlọrun fun wọn gẹgẹ bi awọn eniyan kan. Nipa bayii wọn lè gbadun aabo ati ibukun tí Ọlọrun pese fun ijọ naa. (Deuteronomy 28:9-14) Ronu iru anfaani tí ó jẹ lati jẹ apakan awọn wọnni tí Olodumare pè ní “awọn eniyan mi Israel.”—2 Samuel 7:8.

8 Nipa ti awọn tí kii ṣe ọmọ Israel tí wọn fẹ́ jọsin Ọlọrun tootọ nkọ́? Iru awọn eniyan bẹẹ di “ọpọ eniyan tí wọn dapọ mọ́ wọn” tí wọn yàn lati lọ pẹlu Israel nigba tí Moses ṣamọna orilẹ-ede naa kuro ní Egypt. (Exodus 12:38) Ká sọ pe iwọ wà ní Egypt, iwọ yoo ha ti ní imọlara pe iwọ lè duro ki o sì jọsin Ọlọrun ní ìwọ nikan lọna ti ara rẹ bi?

9 Ani nigba tí Israel fidikalẹ ní Ilẹ Ileri naa, awọn ajeji tí wọn mọ Jehofah ní àmọ̀dunjú tí wọn sì fẹ lati jọsin rẹ̀ lẹ̀ ṣe bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, wọn nilati mọriri rẹ̀ pe Ọlọrun nbá awọn eniyan tí a kojọ lò ati pe ibi ikorijọ ijọsin Rẹ̀ wà ní temple ní Jerusalem. (1 Awọn Ọba 8:41-43; Numbers 9:14) Awọn eniyan kò lè ṣe itẹwọgba fun Ọlọrun bi wọn bá jẹ ki igberaga tabi omìnira sún wọn lati ṣe igbekalẹ ọna ijọsin tiwọn funraawọn.

IYIPADA NINU AWỌN IJỌ

10 Nigba tí Jesu wà lẹnu iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ lori ilẹ-aye, Ọlọrun ṣì nbá Israel lọ̀ sibẹ gẹgẹ bi awọn eniyan tí a yasimimọ fun un. Nipa bayii kò pọndandan pe ki olukuluku tí ó tẹwọgba Messiah naa maa padepọ deedee pẹlu Jesu ki wọn sì maa rin irin-ajo pẹlu rẹ̀ bi awọn apostle ti ṣe. (Mark 5:18-20; 9:38-40) Ṣugbọn orilẹ-ede naa lodi-ndi kọ Messiah Jehofah silẹ, tí ó sì sún Jesu lati sọ ní kete ṣaaju iku rẹ̀ pe: “A o si gba ijọba Ọlọrun kuro lọwọ yin a o sì fi fun awọn eniyan kan tí yoo maa mú eso rẹ̀ jade.”—Matthew 21:43, Jerusalem, Bible.

11 Tani awọn eniyan títun yii yoo jẹ, niwọn bi ọna ijọsin Ọlọrun tí a làsílẹ̀ ninu ofin Ọlọrun fun Israel ti di eyi tí a kò beere fun mọ́? (Colossae 2:13, 14; Galatia 3:24, 25) Ní ọjọ Pentecost 33 C.E., a gbé ijọ Kristian kalẹ Ọlọrun sì mú ki ó ṣe kedere si awọn olukiyesi olootọ-ọkan pe iṣẹ-ọwọ oun ni eyi jẹ. (Iṣe 2:1-4, 43-47; Hebrew 2:2-4) Lakọkọ, awọn Jew ati awọn alejo tí wọn ti tẹwọgba isin Juda ati, lẹhin naa, awọn Keferi, tabi awọn eniyan awọn orilẹ-ede, wá di ‘’awọn eniyan fun orukọ rẹ̀.” Nisinsinyi Ọlọrun wá kà wọn sí ẹni tí ó jẹ “iran tí a yàn, olú-alufaa, orilẹ-ede mímọ́, eniyan ọ̀tọ̀.”—Iṣe 15:14-18; 1 Peter 2:9, 10.

12 Bii iwọ bá ti gbé ayé nigba naa tí o sì fẹ ibatan pẹlu Ọlọrun, a bá ti dari rẹ sinu ijọ Kristian. Eyi ni ohun tí ó ṣẹlẹ pẹlu ọkunrin ara Italy naa Cornelius ati idile rẹ̀. (Iṣe 10:1-48) Awọn onigbagbọ jakejado ayé ni wọn parapọ di ijọ Kristian. (1 Peter 5:9) Gbogbo awọn ijọ adugbo, tí wọn npadepọ ninu awọn ile gbígbé tabi ninu awọn gbọngan ilu, jẹ apakan ijọ kanṣoṣo yii tí Ọlọrun nlò nisinsinyi.—Iṣe 15:41; Rome 16:5.

13 Pé oun jẹ Ọlọrun eto, Jehofah ṣeto iwọn eto-ajọ kan kalẹ ninu awọn ìjọ. Lati pese afiyesi tí a nilo fun olukuluku olujọsin, oun yan awọn ọkunrin gẹgẹ bi awọn oluṣọ-agutan tabi awọn alaboojuto. Wọn jẹ awọn ọkunrin tí wọn ní iriri, tí wọn sì tootun, tí wọn lè kọni ní Ọrọ Ọlọrun ki wọn sì kọ awọn memba ijọ naa lati ṣalabapin otitọ Bibeli pẹlu awọn ẹlomiran, lati ṣeranwọ ninu iṣẹ bàntà-banta ti wiwaasu “ihinrere.”—2 Timothy 2:1, 2; Ephesus 4:11-15; Matthew 24:14; Iṣe 20:28.

14 Ní ọpọlọpọ ọna miiran pẹlu, awọn ijọ yoo jere anfaani lọdọ awọn alaboojuto wọnyi. Wọn kò ní maa banilo lọna ìpàṣẹ-wàá tabi ininilara. Kaka bẹẹ, pg180 ìyannìsíṣẹ wọn jẹ tifẹtifẹ lati ran awọn Kristian ẹlẹgbẹ wọn lọwọ lati fun ibatan wọn pẹlu Ọlọrun okun. (Iṣe 14:21-23; 1 Peter 5:2, 3) Ẹnikẹni tí ó ní awọn ọran-iṣoro lè lọ sọdọ awọn agba ọkunrin nipa ti ẹmi wọnyi fun iranlọwọ oninuure, tí a gbeka Iwe-mimọ. (James 5:13-16; Isaiah 32:1, 2) Nitori pe awọn Kristian ṣì jẹ alaipe sibẹ, lẹẹkọọkan awọn iṣoro lè dide ninu awọn ijọ. Awọn alaboojuto nilati wà lojufo lati ṣeranwọ fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ wọn, ki wọn sì wà ní ìgbáradì lodisi ẹnikẹni tí ó lè fẹ́ fi ipo ti ẹmi ijọ naa wewu.—Philippi 4:2, 3; 2 Timothy 4:2-5.

15 Awọn ijọ nrí ìdarísọnà tí a nilo gbà lati ọ̀dọ̀ ẹgbẹ alakoso Kristian ti awọn apostle ati awọn agba ọkunrin ninu ijọ Jerusalem. Wọn nkẹkọọ wọn sì nyanju awọn ibeere tí a fi ranṣẹ lati ọ̀dọ̀ awọn ijọ. Ẹgbẹ alakoso naa sì nfi awọn aṣoju ranṣẹ lati ṣe ibẹwo si awọn ijọ.—Iṣe 15:1-3.

16 Jehofah Ọlọrun ṣì nbá awọn eniyan rẹ̀ lò gẹgẹ bi ẹgbẹ kan tí a kojọ. Jakejado ilẹ-aye ẹgbẹẹgbẹrun ìjọ awọn Ẹlẹrii Jehofah ni wọn wà. Bi iwọ bá fẹ́ wá sinu iṣọkan pẹlú ọna ijọsin Ọlọrun, dahunpada si igbaniniyanju rẹ̀ lati kojọpọ pẹlu awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ:

“Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wò lati ru ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere. Ki a má maa kọ ipejọpọ ara wa silẹ,.... ṣugbọn ki a maa gba ara-ẹni niyanju; pẹlupẹlu bi ẹyin ti ríi pe ọjọ nì sunmọ etile.” —Hebrew 10:24, 25.

JIJỌSIN ỌLỌRUN PẸLU GBOGBO ỌKÀN

17 Ó dara lati ronu lori ohun gbogbo tí Jehofah Ọlọrun ti ṣe fun ọ. Lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni iwọ ti ní iwalaaye ati awọn ipese lati mú iwalaaye rẹ duro lojoojumọ. Ní afikun sí eyiini, Ọlọrun rán Ọmọkunrin rẹ̀ wá si ilẹ-aye lati kú gẹgẹ bi ẹbọ kan. Eyiini jẹ ifihan ifẹ jijinlẹ tí Ọlọrun ní, ifẹ didaju ati alaileyipada. (Rome 5:8; 8:32, 38, 39) Lọna yẹn Ọlọrun mú ki ó ṣeeṣe fun ọ lati jere idariji ẹṣẹ ati ireti rere ti ìyè ayeraye ninu ayọ̀.—John 3:17; 17:3.

18 Bawo ni awa yoo ṣe dahunpada si ifẹ rẹ̀? Dajudaju kò yẹ ki a kẹ̀hìn si Ọlọrun ati ifẹ rẹ̀. Apostle Peter rọ̀ wa pe:

Nitori naa ẹ ronupiwada, ki ẹ sì tún yipada, ki a lè pa ẹṣẹ yin rẹ̀, ki akoko itura baa lè....wà.Iṣe 3:19.

19 Gbogbo wa ni a nilati “ronupiwada,” nitori pe gbogbo wa ni a ti ṣẹ̀, tí a sì ti kuna lati dọgba pẹlu awọn ọpa-idiwọn Ọlọrun ninu ìwa, ọrọ ati awọn ironu wa. (Rome 2:4; 7:14-21; James 3:2) Fun wa lati ronupiwada tumọsi lati mọ̀ ní àmọ̀dunjú pe awa jẹ ẹlẹṣẹ ki a sì ní imọlara ìkárísọ nitori kikuna lati gbé ní ibamu kíkún pẹlu ifẹ-inu Jehofah. Ṣe imọlara rẹ ni eyiini? Lẹhin eyi, a nilati “yipada,” ki a yí ọna igbesi-aye wa pada, lati isinsinyi lọ ki a maa sapa lati fi awọn animọ yiyẹ Jehofah hàn ki a sì maa ṣe awọn nkan ní ọna rẹ̀. Ní ṣiṣe eyiini, awa lè ní igbẹkẹle pe Ọlọrun yoo dariji yoo sì tẹwọgba wa.—Psalm 103:8-14; 2 Peter 3:9.

20 Mímọ ní àmọ̀dunjú pe Jesu pese awokọṣe ki a baa lè maa tẹle ipasẹ rẹ̀ ninu sisin Ọlọrun, awa nilati sapa lati ṣafarawe apẹẹrẹ rẹ̀. (1 Peter 2:21) Hebrew 10:7 sọ fun wa pe ẹmi-ironu Jesu jẹ: “Kiyesii!... Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun.” Bakan naa, ifẹ ati imọriri wa fun Ọlọrun yẹ ki ó sún wa lati ya igbesi-aye wa si mímọ fun un, lati ṣe ifẹ rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn. Dajudaju, a o ṣì maa jẹun, sùn, bikita ki a sì nifẹẹ idile wa, gbadun isinmi-ìdẹ̀ra aladun ati ní awọn ọna miiran ki a ṣalabapin ninu awọn igbokegbodo-iṣẹ igbesi-aye tí wọn bojumu. Ṣugbọn yiya igbesi-aye wa si mímọ fun Ọlọrun tumọsi pe ìifẹ-inu ati ijọsin rẹ̀ nilati ní ijẹpataki akọkọ, ati pe, laika ibi yowu tí a lè wà sí tabi ohun tí a nṣe, a o fi pẹlu ìfọkànsí sapa lati fi imọran Ọlọrun sílò ki a sì tẹle apẹẹrẹ tí Jesu fi lelẹ.—Colossae 3:23, 24.

21 Iwe-mimọ mú ki ó ṣe kedere pe ẹnikan tí ó bá ya igbesi-aye rẹ̀ si mímọ fun Ọlọrun yoo nilati sọ eyiini di mímọ̀ ní gbangba nipa ṣiṣe iribọmi. Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe:

“Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, kí ẹ si maa baptisi wọn ní orukọ Baba, ati niti Ọmọ, ati niti ẹmi mimọ. Ki ẹ sì maa kọ wọn lati maa, kiyesi ohun, gbogbo, ohunkohun tí mo ti pa laṣẹ fun yin.”—Matthew 28:19, 20.

Bi awọn wọnni tí a nbaptisi bá ti nilati kẹkọọ Ọrọ Ọlọrun ki wọn sì di ọmọ-ẹhin Kristi, nigba naa ó ṣe kedere pe wọn kii ṣe ọmọ-ọwọ lasan. Ati pẹlu, iribọmi wọn, ní ami-apẹẹrẹ iyasimimọ wọn fun Ọlọrun, jẹ rírì bọ inu omi patapata, gẹgẹ bi a ti ri Jesu bọmi ní Odò Jordan.—Mark 1: 9-11; Iṣe 8:36-39.

22 Didi ọmọlẹhin Kristi tí a baptisi yoo fi ọ si oju-ìlà fun igbesi-aye isin Kristian gidi tí ó kunrẹrẹ tí ó sì layọ. Kii ṣe igbesi-aye kan tí a nṣakoso rẹ̀ nipasẹ awọn ṣe-eyi ati maṣe-tọhun alailopin. Kaka bẹẹ, ó jẹ igbesi-aye tí idagbasoke rẹ̀ tẹnilọrun. Iwọ lè fi pẹlu imuratan mú oju-iwoye rẹ nipa ti ẹmi ati bi iwọ ṣe nfi Ọrọ Ọlọrun sílò sunwọn sii, eyi yoo maa fi igba gbogbo mú ọ sunmọ apẹẹrẹ tí Jesu fi lelẹ.—Philippi 1:9-11; Ephesus 1:15-19.

23 Eyi yoo ní ipa lori ironu ati iwa rẹ ojoojumọ. Bi o ti nlepa ọna Kristian, ìdálójú-igbagbọ rẹ yoo jinlẹ sii pe laipẹ Ọlọrun yoo pa gbogbo iwa buruku run, tí yoo sì ṣí ọna silẹ fun ’awọn ọrun titun ati ayé titun ninu eyi tí ododo yoo maa gbé.’ Eyi, ní idakeji, yoo fikun isunniṣe rẹ lati ṣe imudagba awọn animọ yiyẹ ti Kristian ati lati lepa ọna igbesi-aye tí yoo ló jẹ ki o rí àyé ninu eto titun naa tí nbẹ. (Ephesus 4:17, 22-24) A misi apostle Peter lati kọwe pe:

“Ẹ ronu iru eniyan wo ni o yẹ ki ẹ jẹ, iru igbesi-aye olufọkansin ati iyasimimọ wo ni ó yẹ ki ẹ gbé! Pẹlu (eto titun) yii lati maa wọ̀nà fun, ẹ sa gbogbo ipá yin lati lè di ẹni tí a rí ní alaafia pẹlu rẹ̀, lailabawọn tí ò sì ga rekọja abuku loju rẹ̀.”—2 Peter 3:11, 14, New English Bible.

24 Ẹ wo bi yoo ti jẹ ibukun tó nigba tí gbogbo igbesi-aye ẹnikan bá nfi otitọ naa hàn pe oun njọsin Jehofah Ọlọrun! Bi o tilẹ jẹ pe lonii ọpọlọpọ ni wọn ngbé kiki lati wu ara wọn ati lọna imọtara-ẹni-nikan ki wọn lè rí gbogbo igbadun tí ó bá ṣeeṣe, iwọ lè walaaye ki o sì jọsin Ọlọrun otitọ lọna tirẹ̀. Eyi ni ọna igbesi-aye tí ó dara julọ.

[Koko Fun Ijiroro]

Tani awọn eniyan pupọ julọ maa nfi si ipo akọkọ, eesitiṣe tí eyiini kò fi lọgbọn-ninu? (1-4)

Bawo ni Noah ati Abraham ṣe yatọ si ọpọ julọ awọn eniyan lonii? (5, 6)

Ní akoko Israel igbaani, bawo ni Ọlọrun ṣe bá awọn eniyan lò? (7-9)

Iyipada wo ni Ọlọrun ṣe ninu awọn ibalo rẹ̀? (10-12)

Bawo ni Ọlọrun ṣe ṣetojọ tí ó sì ndari awọn Kristian ní títọ wọn sọna? (13-15)

Itumọ wo ni ọna ibalo Ọlọrun pẹlu awọn Kristian yẹ ki ó ní fun iwọ? (16)

Ifẹ fun Ọlọrun yẹ ki ó sún wa lati ṣe kinni? (17-19)

Eeṣe tí iribọmi fi jẹ igbesẹ pataki, apẹẹrẹ kinni ó sì nṣe?

(20, 21)

Iwọ ha ti ya igbesi-aye rẹ sí mímọ́ fun Ọlọrun, tí o sì nfẹ lati ṣe iribọmi bi? Kinni eyi yoo tumọsi fun ọ? (22-24)