Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iwa-buruku—Eeṣe Tí Ọlọrun Fi Fi Àyé Gbà Á?

Iwa-buruku—Eeṣe Tí Ọlọrun Fi Fi Àyé Gbà Á?

Ori 14

Iwa-buruku—Eeṣe Tí Ọlọrun Fi Fi Àyé Gbà Á?

BI A bá fi ipá ja ọ̀rẹ́ rẹ lólè, tí a fi ipá bá a lopọ tabi ṣekupa a tí a sì jẹ ki ọdaran naa lọ lọfẹẹ, iwọ ki yoo ha ní imọlara ìjakulẹ, ipalara ati ibinu bi? Iru awọn iwa-ọdaran ati aiṣododo bẹẹ wulẹ jẹ kiki ifihan kekere nipa ohun tí ó ti ṣubu tẹ araye.

2 Ọrọ-itan jẹ akọsilẹ gigun ti awọn ogun oníkà, ipo òṣì apanirun, iwa-ọdaran ati ìpọnnilójú. Ní iyọrisi, awọn eniyan kan tí wá bẹrẹsi ṣiyemeji nipa wíwà Ọlọrun paapaa. Awa mọ̀ pe ami-ẹri ìdálójú-ìgbagbọ wà nipa pe Ẹlẹdaa wà. (Hebrew 3:4; Rome 1:20) Ṣugbọn iwa-buruku tún wà pẹlu. Fun idi yii, ani ọpọlọpọ awọn tí wọn gbagbọ ninu Ọlọrun maa nṣe kayefi pe, ‘Oun ha bikita nipa wa nitootọ bi?’ Wọn beere pe, ’Bi Ọlọrun bá bikita, eeṣe tí oun fi gba iwa-buruku láyè fun igba pípẹ́ tobẹẹ?’

3 Awọn ọmọran ati awọn alufaa ti fi igba gbogbo ṣiṣẹ lori ọran yii, ṣugbọn wọn kò ní idahun tí ntẹnilọrun. Kinni ohun tí Ọlọrun funraarẹ̀ sọ?

ỌLỌRUN DAHUN PE: ‘MO BIKITA’

4 Lori ipilẹ iriri tiwa, awa lè mọrirì ihuwapada wolii Hebrew naa Habakkuk sí iwa-ipá ati aiṣododo. Oun walaaye ní akoko kan nigba tí awọn Jew ṣubu sinu ṣiṣe ọpọlọpọ ohun buburu, eyi tí ó dabi ọgbẹ́ nla kan ní ọkàn-àyà Habakkuk tí ó sì sún un lati beere lọwọ Ọlọrun pe:

“Eeṣe tí o mú mi rí aiṣododo? Eeṣe tí ó fi fàyègba iwa-àìtọ? Iparun ati iwa-ipá wà niwaju mi; aáwọ̀ ati ìjà wọpọ. Nitori naa, ni ofin ṣe di arọ, tí idajọ-ododo kò sì tún lékè mọ́. Awọn ẹni ẹṣẹ yí olododo ká, nitori naa a yí idajọ-ododo po.”Habakkuk 1:3, 4 New International Version.

Bi o tilẹ jẹ pe ó ní ìdálójú-igbagbọ nipa ododo Jehofah, Habakkuk banujẹ nitori iwa-ipá ati aiṣododo tí ó wà laarin awọn eniyan rẹ̀. Pẹlupẹlu, lakoko naa awọn ara Babylon wà lẹnu ìwọ́de-kiri oniwa-ipa, tí wọn ndáyàfò tí wọn sì nfi awọn orilẹ-ede miiran ṣẹ̀jẹ. Ó farahan pe iwa-buruku wọpọ nibi gbogbo. Wolii Habakkuk ṣe kayefi niti idi tí Ọlọrun, ẹni tí ó lè ríi, fi dabi ẹni tí kò ṣe nkankan.—Habakkuk 1:13.

5 Ninu iran-ifihan kan Jehofah mú un dá Habakkuk loju pe eyi tí ó dabi aasiki awọn eniyan buruku jẹ kiki fun igba diẹ péré. Kii ṣe kiki pe Ọlọrun rí ohun tí nṣẹlẹ nikan ni, ṣugbọn oun bikita pẹlu. Oun ní igba kan tí a yànfun gbígbé idajọ atọrunwa jade. Ani bi awọn ẹda-eniyan tilẹ lérò pe a nfi eyi falẹ̀, a mú un dá Habakkuk loju pe, “Nitori ní dídé yoo dé, ki yoo pẹ́.”—Habakkuk 2:3.

6 Ní fifi ibikita Ọlọrun hàn siwaju sii, oun pe afiyesi Habakkuk si ipenija kan tí ó dojukọ araye ní lọwọlọwọ, Jehofah wipe: Ṣugbọn olododo yoo wà nipa igbagbọ rẹ̀.(Habakkuk 2:4) Habakkuk yoo ha koju ipenija naa bi, ní ṣiṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì jẹ ti iwarere laika ohun tí awọn tí wọn yí i ká nṣe sí? Oun nilati fi igbagbọ hàn pe Ọlọrun yoo bojuto awọn ọran daradara ní akoko [rẹ̀] tí a yàn.

7 Ọrọ-itan sọ ohun tí ó ṣẹlẹ fun wa. Nigba tí akoko naa dé, Ọlọrun gbé igbesẹ lati fi opin si iwa-ipá ati aiṣododo laarin awọn Jew. A ṣẹgun ilẹ naa ọpọlọpọ ninu awọn eniyan naa ni a sì kò ní igbekun. Nikẹhin, Ọlọrun yọ oró rẹ̀ lara Babylon. Gẹgẹ bi Jehofah ti sọtẹlẹ nipasẹ awọn wolii rẹ̀, awọn ara Media ati Persia labẹ Cyrus ṣẹgun Ilẹ-ọba Babylon tí ó dabi alagbara-gbogbo naa.—Jeremiah 51: 11, 12; Isaiah 45:1; Daniel 5:22-31.

8 Apejuwe ránpẹ yii fihan pe Ẹlẹdaa wa kò di oju rẹ̀ si iwa-buruku. Oun wà lojufo nipa rẹ̀, ó sì bikita. (Fiwe Genesis 18:20, 21; 19:13.) Bi eyiini bá rí bẹẹ, eeṣe tí Ọlọrun fi gba iwa-buruku láyé lati maa bá a lọ titi di isinsinyi? Lati loye alaye Bibeli tí ó wà ní ibamu pẹlu ọgbọn-ironu tí ó tọna, a nilati pada sẹhin si akoko tí awọn ìjọ̀gbọ̀n ẹda-eniyan bẹrẹ.

ARIYANJIYAN AGBAYE DIDE

9 Gẹgẹ bi a ti fi tó wa létí ninu Genesis ori kẹta, Eṣu beere lọwọ Efa nipa ṣiṣe igbọran rẹ̀ sí ofin-aṣẹ Ọlọrun lati maṣe jẹ ninu igi kan tí a pilẹ̀ yasọtọ. Efa dahun pe aigbọran yoo mú idalẹbi iku wá. Ṣugbọn Satan fèsì pe:

“Ẹyin, ki yoo kú iku kíkú kan. Nitori Ọlọrun mọ pe, ní ọjọ tí ẹyin bá jẹ ninu rẹ̀, nigba naa ni [ojuiriran] yin yoo là, ẹyin yoo sì dabi Ọlọrun, ẹ o mọ rere atì buburu.”Genesis 8:1-9.

Nihin Satan gbé awọn ipenija tabi awọn ariyanjiyan dide eyi tí ó kan gbogbo awọn ẹda Ọlọrun, awọn eniyan ati awọn angeli.

10 Fun ohun kan Eṣu pe àìlábòsí Ọlọrun níjà. Ronu lori awọn ohun tí eyiini ní ninu. Bi Ọlọrun kò bá ṣe olootọ ninu ọran yii, a ha lè gbẹkẹle e ninu ohunkohun miiran bi? Awọn ẹda rẹ̀ ori ilẹ-aye tabi ní ọrun yoo ha maa fi igba gbogbo fura nipa ohun tí Ọlọrun bá sọ bi? Lonii awa mọ bi awọn eniyan ti di onifura tó si awọn oṣelu tí nṣakoso nipasẹ irọ́ pípa.—Fiwe Psalm 5:9.

11 Ijẹwọsọ Satan pe Ọlọrun jẹ ẹlẹtan ati pe ó maa nfawọ ohun rere sẹhin fun awọn ẹda, rẹ̀ tún gbé ariyanjiyan naa dide, Ọlọrun ha lẹtọ lati ṣakoso bi? Ibeere naa nipa ẹ̀tọ ọna tí Ọlọrun gbà nṣakoso kan gbogbo agbaye.

12 Ní afikun, Satan njiyan pe awọn ẹda-eniyan lè maa baa lọ laisi Ọlọrun, pe wọn lè wọn sì nilati maa ṣakoso ara wọn. A gbé ibeere naa ka iwaju awọn eniyan ati awọn angeli. Awọn ẹda-eniyan ha ṣakoso awọn ọran wọn pẹlu aṣeyọrisi rere laifarati Ọlọrun bi?

13 Awọn ariyanjiyan ọna-iwahihu wiwuwo wọnni beere fun yiyanju latoke-delẹ. Ọna tí Ọlọrun yàn lati gbà ṣe eyiini fi ọgbọn rẹ̀ ati ifẹ rẹ̀ ninu ire wa hàn kedere, nisinsinyi ati ní ọjọ-iwaju. Ọlọrun yọnda ki akoko kọja, laarin eyi tí gbogbo awọn ẹda oloye yoo fi lè rí ami-ẹri naa. Lati mọriri eyi, ronu nipa bi iwọ yoo ṣe huwa bi ẹnikan bá nilati sọ ní gbangba pe iwọ kii ṣe memba rere kan ninu idile, pe o maa npurọ tí o sì maa nlo ọlá-àṣẹ nipa gbígbin ibẹru sinilọkan. Eniyan alainidaniloju kan lè kégbàjarè jade tabi ki ó tilẹ bá olufisun naa jà. Ṣugbọn pẹlu níní idaniloju ninu imọ naa pe ẹ̀sùn naa jẹ eke, iwọ lè tú awọn ibeere naa ká kiki nipa yiyọnda akoko fun ẹni gbogbo lati ṣakiyesi awọn ọna rẹ ati awọn iyọrisi rere ninu idile rẹ.—Matthew 12:33.

14 Ami-ẹri wo ni akoko ti fihan lori awọn ariyanjiyan tí a gbé dide ní Eden? Gẹgẹ bi Ọlọrun ti kilọ ṣaaju, aigbọran araye ti yọrisi iku, eyi tí aisan ati ọjọ-ogbo nṣaaju rẹ̀. Nitori naa Ọlọrun kii ṣe alábòsí ninu ikilọ rẹ̀, kò sì sí ipilẹ kankan ninu eyi fun pipe ẹtọ iṣakoso rẹ̀ níjà. Ẹri tún wà pẹlu pe eniyan kò lè gbé ọpa-idiwọn ti ara rẹ̀ kalẹ, ki ó maa ṣakoso ara rẹ̀ laifarati Ọlọrun. Kò tíì sí iru akoso ẹda-eniyan kan tí ó tíì dá ogun, iwa-ibajẹ, ìpọ́nnilójú, iwa-ọdaran ati aiṣododo duro. Eyi fohùnsí ohun tí Bibeli wi pe: Ọna eniyan kò sí ní ipa ara rẹ̀; kò sí ní ipa eniyan tí nrìn lati tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.(Jeremiah 10:23) Siwaju sii, akoko ti fi ẹri hàn pe eniyan kò lè fi opin si ijiya, kaka bẹẹ, pe wọn maa nfi igba gbogbo ṣokunfa rẹ̀.

15 Ijiya naa ni awọn eniyan olootọ-ọkàn awọn ẹni tí wọn nifẹẹ lati tẹwọgba iṣakoso Ọlọrun ati awọn ọpa-idiwọn rẹ̀ nní imọlara rẹ̀. Pẹlu wọn lọkàn, Ọlọrun yoo huwa lodisi awọn tí nbá hihu iwa-buruku niṣo, ani bi oun ti ṣe ní ọna ránpẹ́ tí a mẹnukan ninu iwe Habakkuk. Jehofah yoo ṣe ìkékúrò gbogbo awọn tí wọn nṣokunfa iwa-buruku ati ijiya ní ọrun ati lori ilẹ-aye. Gan-an gẹgẹ bi Ọlọrun ti sọ fun Habakkuk, akoko tí a yànkan wà fun eyi. Awa lè ní idaniloju nitori ní dídé yoo dé, ki yoo pẹ́.Habakkuk 2:3.

JIJERE ANFAANI NINU AKOKO TÍ A YỌNDA

16 Niti pe Ọlọrun yọnda ibi, ọpọlọpọ eniyan nronu kiki nipa ijiya eniyan. Wọn kuna lati mọriri awọn ariyanjiyan pataki tí a nyanju. Ati pẹlu, wọn lè gbojufo awọn èrè-anfaani tí wọn lè rí gbà nitori pe Ọlọrun ti yọnda akoko fun yiyanju ọran.—2 Peter 3:9.

17 Akoko tí Ọlọrun yọnda fun yiyanju awọn ọran wọnyi ti gùn pupọ tó ki a baa lè bí wa. Awọn igbadun yowu ki a ti gbadun rẹ̀, ó jẹ nitori iyọnda akoko Ọlọrun. Siwaju sii, a ti fun wa ní anfaani lati fi ẹri ifẹ ati iṣotitọ wa si Ọlọrun hàn. Gẹgẹ bi ipenija, Satan jiyan pe kò ní sí eniyan kankan tí yoo duro bi olootọ si Ọlọrun, kò tilẹ ní sí ẹnikan nipa ẹni tí Ọlọrun yoo lè wipe, Kò sí ekeji rẹ̀ ní ayé, ọkunrin tiiṣe olootọ tí ó sì duroṣinṣin, ẹni tí ó bẹru Ọlọrun tí ó sì korira iwa-buburu.A rí eyi ninu iwe Bibeli ti Job ori 1 ati 2. Nipa ọkunrin aduroṣinṣin naa Job, Eṣu wipe: “Job ha bẹru [Ọlọrun] ní asan bi?” Satan sọ pe Job ṣe bẹẹ nitori awọn idi imọtara-ẹni, nitori Ọlọrun fun un ní aasiki, ṣugbọn pe bi Job bá padanu eyiini oun yoo bú Ọlọrun. (Job 1:7-12) Satan yoo ha lè yí gbogbo eniyan pada kuro lọdọ Ọlọrun bi?

18 Ọlọrun jẹ ki Satan mú ọpọlọpọ iṣoro débá Job. Job padanu ọlà rẹ̀. Awọn ọmọ rẹ̀ ni a pa. Arun ẹlẹgbin kọlu ú. Bi o tilẹ jẹ pe oun kò mọ̀ pe Satan nsọ oun di ẹni ikọlu ara-ọtọ, Job duro bii olootọ si Ọlọrun. (Job 27:5) Oun ní idaniloju pe Jehofah kò ní gbagbe oun ati pe Ẹlẹdaa yoo tilẹ jí oun dide bi oun bá kú. (Job 14:13-15) Jehofah kii kọ awọn ẹni olootọ rẹ̀ silẹ lae. Laipẹ laijinna ni oun dá sii tí ó sì ṣatunṣe awọn ipalara tí Satan ti dasilẹ. A mú ilera Job padabọsipo. Ó tún ní awọn ọmọ mẹwa arẹwa sii, papọ pẹlu aasiki nlánlà ati iwalaaye gigun. Iwọ lè ka ẹkunrẹrẹ alaye tí ó ṣínilórí naa ninu Job 42:10-17.

19 Akọsilẹ yii tún ràn wa lọwọ pẹlu lati rí idi tí Ọlọrun fi gba iwa-buruku láyè. Lọna yii a fi ẹri rẹ̀ hàn pe awọn eniyan kan yoo fẹran Ọlọrun laika awọn iṣoro igbesi-aye sí ki wọn sì jẹ olootọ sii labẹ idanwo eyikeyi. A ṣe rere lati bi ara wa leere pe, ’Ṣé bẹẹ ni awa ti ṣe huwapada laika ijiya sí? Ṣé bi awa ti fẹ́ lati jẹ́ niyii, ki a sì tipa bẹẹ ṣeranwọ ní didahun ipenija tí Satan gbé dide?’ (Owe 27:11) Iwe Job tún fun wa ní idi fun níní igbẹkẹle pe Ọlọrun lè mú ijiya eyikeyi tí ó dojukọ araye kuro nigba tí a ṣì nfàyègba iwa-buruku.—Fiwe 2 Corinth 4:16, 17.

20 Gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣakiyesi tí ó sì tẹwọgba Job ati Habakkuk, Oun tún nkiyesi awọn eniyan tí wọn jẹ olootọ sii loju awọn ipo buburu, oun kò sì ní kuna lati san èrè fun wọn.—Malachi 3:16-18.

IWỌ HA FẸ́ LATI WALAAYE NIGBA TÍ IWA-BURUKU BÁ TI LỌ BI?

21 Bibeli mú un dá wa loju pe Ọlọrun pete lati mú ayé padabọ si ipo paradise, iru eyi tí Adam ati Efa gbadun rẹ̀ ki wọn tó di alaiṣootọ. (Luke 23:43; Iṣipaya 21:4, 5) Nigba naa ni imuṣẹ ní kikun awọn ileri Bibeli yoo wà iru bii:

“Awọn ẹni buruku yoo ’pòórá; ìwọ wá wọn kiri, Ṣugbọn iwọ ki yoo rí wọn; ṣugbọn onirẹlẹ [tabi, ọlọkantutu] ni yoo jogun ilẹ naa wọn yoo sì maa gbadun aasiki ati alaafia.”—Psalm 37:10, 11, Good News Bible; Òwe 24:1, 20.

22 Ọpọlọpọ eniyan ni nṣaroye nipa ibi ati ijiya, tí wọn tilẹ ndẹbi fun Ọlọrun fun iwọnyi. Ṣugbọn wọn ha fẹ ìmúkúrò iwa-buruku nitootọ bi, tabi kiki awọn abajade rẹ̀? Eniyan ló nṣe àfọwọfà pupọ ijiya wá sori ara rẹ̀; ó nká ohun tí ó ti gbìn. (Galatia 6:7; Owe 19:3) Iwa pálapàla nso eso arun-abẹ, oyún ṣíṣẹ́ ati ikọsilẹ. Siga mimu nyọrisi aisan ẹ̀dọ̀fóró. Imutipara ati oògùn ilokulo nba ẹ̀dọ̀-ki ati ọpọlọ jẹ. Rírú awọn ofin irinna nfa awọn jamba moto biburu jáì. Njẹ awọn wọnni tí wọn sọ pe, ’Eeṣe tí Ọlọrun fi fi àyè gba iwa-buruku? Nigba wo ni oun yoo fi opin sii? O ha fẹ́ ki Ọlọrun ṣe bẹẹ nitootọ bi? Bi oun bá ṣe bẹẹ nisinsinyi gan-an, nipa didena awọn iwa wọnyi, ọpọlọpọ ni yoo ṣaroye pe ó nká awọn lọwọko.

23 Fun ìdi yii, fifi tí Ọlọrun fi àyè gba iwa-buruku jẹ ki a fi ibi tí a duro sí hàn, ohun tí ó wà ninu ọkàn-àyà wa. Ọlọrun sọ fun Habakkuk pe: Olododo yoo wà nipa igbagbọ rẹ̀.Eyiini nbeere mímú ikorira dagba fun ohun tí Ọlọrun fihan pe ó jẹ buburu tabi ibi. (Habakkuk 2:4; Psalm 97:10) Gbígbé lọna yẹn lè sọ wa di alaigbajumọ pẹlu awọn aladugbo ati alabakẹgbẹ kan. (1 Peter 4:3-5) Job ati Habakkuk nifẹẹ lati dáyàtọ̀ ki wọn baa lè jẹ olootọ si Ọlọrun ki wọn sì rí itẹwọgba rẹ̀. Araadọta ọkẹ awọn Ẹlẹrii Jehofah lonii bakan naa nfi ẹri hàn pe a lè ṣe e, wọn sì ngbadun igbesi-aye tí ó tubọ lọràá sii tí ó sì ntẹnilọrun.

24 Awọn eniyan tí ntẹle ipa-ọna yii nfikun ẹri naa pe Satan jẹ àgbáàràgbá opurọ. Wọn nfi ẹri hàn pe ẹda-eniyan lè jẹ olootọ si Ọlọrun, pẹlu idaniloju pe ọna iṣakoso rẹ̀ jé ẹ̀tọ́ ati ododo. Ọlọrun, ní idakeji ẹwẹ, mọ̀ pe a lè fun iru awọn ẹni bẹẹ ní ẹru-iṣẹ bibojuto paradise tí a o mú padabọsipo sori ilẹ-aye. Igbesi-aye nigba naa yoo gbadunmọni débi pe awọn ibanujẹ ati iwa-ibi atẹhinwa kò ní wá sí ero-inu. A o gbagbe wọn gan-an gẹgẹ bi a ti ṣe gbagbe irora ati ibanujẹ tí a nimọlara ní ọpọ ọdun sẹhin nigba tí, gẹgẹ bi ọmọ kekere, a ti lè fi orókún bó.—Isaiah 65:17; John 16:21.

25 Ireti rere tí ó gbadunmọni ni eyiini, ó sì ràn wa lọwọ lati ríi pe iyọnda Ọlọrun fun iwa-buruku wulẹ jẹ iṣẹlẹ-alafo-akoko onigba-kukuru ninu ìkẹ̀sẹjárí ete ayeraye rẹ̀. Awọn ariyanjiyan ọran ofin, ti ọna-iwahihu tí ó gbé dide ni a o yanju rẹ̀ lẹẹkan ati titi laelae.

26 Ṣugbọn bi a tilẹ ti loye idi tí Ọlọrun fi fi àyè gba iwa-buruku, lọna ẹ̀tọ́ a nifẹẹ lati mọ: Nigba wo ni yoo dopin? Nigba wo ni akoko tí a yàn,fun Ọlọrun lati mú opin débá iwa-buruku jakejado ayé? Ẹ jẹ ki a wò ó nisinsinyi.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí ó fi lọgbọn-ninu lati ṣayẹwo ohun tí Bibeli sọ nipa iwa-buruku? (1-3)

Kinni a lè kẹkọọ rẹ̀ lọdọ Habakkkuk lori ọran yii? (4-8)

Bawo ni ọran ariyanjiyan pataki fun gbogbo agbaye ṣe dide ní Eden? Kinni wọn jẹ? (9-12)

Ní awọn ọna wo ni a o fi yanju awọn ariyanjiyan naa? (13-15)

Bawo ni awa tún ṣe wọnú ariyanjiyan miiran tí ó nfẹ́ ìyanjú? (16-20)

Ireti rere wo ni Bibeli ní ninu? Ó tumọsi kinni fun wa? (21-23)

Bawo ni awa ṣe lè jere anfaani pipẹtiti ninu pe Ọlọrun yọnda fun iwa-buruku? (24-26)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 131]

Dr. W. R. inge, ẹni tí o jẹ alaboojuto agba ní St. Paul’s Cathedral, London, ní ọdun melokan sẹhin sọ pe:

“Ní gbogbo igbesi-aye mi ni mo ti jà fitafita lati ṣawari ete wiwalaaye. Mo ti gbiyanju lati dahun awọn ọran-iṣoro mẹta tí ó dabi ohun pataki loju temi: ọran-iṣoro ayeraye; ọran-iṣoro akopọ-animọ-iwa ẹda-eniyan; ati ọran-iṣoro iwa-ibi. Mo ti kuna. Emi kò yanju eyikeyi ninu wọn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 137]

Ijiya kò yí Job pada lodisi Ọlọrun, oun farada á a sì bukun fun un