Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kikẹkọọ Nipa Ohun Tí Iwọ Kò Lé Fojuri

Kikẹkọọ Nipa Ohun Tí Iwọ Kò Lé Fojuri

Ori 4

Kikẹkọọ Nipa Ohun Tí Iwọ Kò Lé Fojuri

PUPỌ awọn nkan tí nfanimọra ni a kò lé fojuri. Fun apẹẹrẹ, nitori pe ohun iyanu nipa ọmọ-ọwọ ti ndagba ninu ile-ọlẹ̀ iya rẹ̀ ti fi igba pipẹ jẹ iṣẹ iyanu tí a kò lè fojuri, awọn aworan rẹ̀ akọkọ jẹ eyi tí nyanilẹnu pupọ julọ.

2 Awọn ohun pataki miiran wà tí kò ṣeeṣe fun wa lati fojuri, bi iru agbara òòfà-mọra ati òòfà-mọ́lẹ̀. Sibẹ wọn jẹ ohun gidi. A lé kẹkọọ pupọ nipa wọn nipa ṣiṣakiyesi awọn ipa tí wọn nmujade. Bakan naa ni ô rí pẹlu Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, bia bá ní ifẹ si kikẹkọọ nipa Ẹlẹdaa wa—eyi tí ô sì yẹ ki a ṣe bẹẹ—a nilati lo gbogbo okun-inu ati afiyesi wa ní ṣiṣe bẹẹ.—Fiwera pẹlu John 3:12.

3 Ní pataki, awọn ọna meji ló wà fun kikẹkọọ nipa Ọlọrun, ẹni tí a kò lè fojuri. Paul, apostle Jesu Kristi, mẹnukan ọ̀kan, ní kikọwe pe: “Ohun rẹ̀ tí ó farasin lati igba dídá ayé a rí wọn gbangba, a nfi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n, ani agbara ati ìwa-Ọlọrun rẹ̀ ayeraye. (Rome 1:20) Bẹẹ ni, iṣẹda jẹrii si wíwà Ẹni Giga Julọ kan. Ní afikun, ô funni ní ohun tí a fi mọ awọn animọ rẹ̀, ohun tí oun jẹ. Ọna keji ṣe pataki pupọ ju bẹẹ lọ, nitori pe ô pese isọfunni tí ó rí bẹẹ gẹgẹ nipa Ọlọrun. Eyi ni iṣipaya alakọsilẹ tí a rí ninu Bibeli.

BAWO NI OUN TI RÍ?

4 Gẹgẹ bi a ti ṣe akọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli, Jesu sọ pe Ọlọrun jẹ ẹmi.” (John 4:24, NW) Eyiini tumọsi pe Ẹlẹdaa kò ní ẹran-ara gẹgẹ bi tiwa. Eyi kò yẹ ki ô nira lati tẹwọgba fun awọn eniyan tí wọn ti di ojulumọ awọn ohun gidi kan tí a kò lè fojuri bii òòfà-mọlẹ̀, agbara òòfà-mọra ati awọn ìgbì radio. Iyatọ pataki kan niti Ọlọrun, bi o ti wu kì o ri, ni pe oun jẹ Ẹni alaaye, ọlọgbọn-òye pẹlu awọn animọ tí a lè wòyemò. Kinni diẹ ninu awọn wọnyi?

5 Njẹ o ha ti ṣakiyesi ìgbì nlánlà tí nwó lu bèbè òkun alapata kan? Tabi o ha ti ṣakiyesi ipá tí ó lékenkà ti irujade oke onina? Awọn wọnyi kàn wulẹ jẹ awọn ami ifihan lọna kekere agbara, tí Ẹlẹdaa gbọdọ ní, nitori pe oun ni ô dá ilẹ-aye ati awọn ipá rẹ̀.

6 Pẹlu alaye oniṣiro olokiki ti Einstein E=mc2, awọn onimọ-ijinlẹ ṣalaye pe gbogbo ohun-wíwà kò yatọ si agbara kan tí a tìpa mọlé sinu awọn atom ipilẹ kan. Awọn eniyan ti fi eyi hàn pe ô jẹ otitọ pẹlu imujade ìbúgbàù awọn afọnja oloro wọn. Sibẹ njẹ iwọ ha mọ̀ pe iru awọn ìbúgbàù nlánlà bawọnni tú kiki agbara tí kò tô ida kan ninu ọgọrun agbara tí ô wà ninu awọn atom naa bi? Ronuwoye nipa agbara ẹlẹru-jẹnjẹn tí Ẹlẹdaa naa ẹni tí ó to gbogbo awọn atom agbaye jọ papọ. Ẹgbẹgbẹẹrun ọdun ṣaaju ki a tó bí Einstein, Iwe-mimọ mọ̀ pe Ẹni Giga Julọ naa ni orisun agbara tí ô lékenkà. (Isaiah 40:29) Pẹlu idi rere Iwe-mimọ pé é lápètúnpè ní Ọlọrun Olodumare.—Genesis 17:1; Iṣipaya 11:17.

7 Ọlọrun ti saba maa nlo agbara rẹ̀ ní awọn ọna tí ô kan awọn ẹda-eniyan ní taarata. Apẹẹrẹ kan ni ti Ijadelọ, nigba tí Ọlọrun dá Moses ati awọn ọmọ Israel silẹ kuro ní Egypt. Iwọ lè fẹ́ lati ka akọsilẹ kukuru ti Ekodus 13:21-14:31 naa soke ketekete. Fi oju-inu wo ara rẹ pe o wà laarin awọn wọnnì tí a ndaabobo nipasẹ ọwọn awọsanma ẹlẹru-jẹnjẹn lọsan ati nipasẹ ọwọn ina tí njô fòfò ní alẹ. Bawo ni ìbá ti ri lara rẹ nigba tí ô dabi pe ẹgbẹ-ogun tí nlé yin bọ ti sé yin mọ́ Òkun Pupa? Ronuwoye ná, sibẹsibẹ, ní wiwo bi Ọlọrun tì lo agbara rẹ̀ lati mú ki omi di ogirì tí ó gasoke fiofio ní ẹ̀gbé mejeeji kì ẹ baa lè yebọ. Ẹ wo iru Ọlọrun ti oun jẹ́!—Exodus 15:1, 2, 11: Daniel 4:35.

8 Ijadelọ naa tún fi agbara-ìṣe Ọlọrun nhàn pẹlu lati ṣe aṣeyọri awọn nkan lati okeere. Lati ṣe eyi, oun nlô ipá ìṣìṣẹ rẹ̀ tí a kò lè fojurì, ẹmi rẹ̀, tabì ẹmì mímọ́. Bì o tilẹ jẹ ipá iṣiṣẹ yìì kii ṣe eniyan kan, ó lè, gẹgẹ bì èemí afẹfẹ alagbara kan, ló agbara. Ọlọrun lo ẹmi rẹ̀ lati ṣẹda agbaye ti a lè fojuri naa. (Psalm 33:6: Genesis 1:2) Ṣugbọn oun tún lè lò ô pẹlu lati fi fun awọn eniyan lokun ati lati ràn wọn lọwọ.—Awọn Onidaajọ 14:5, 6; Psalm 143:10.

9 Ẹni naa ti ó ṣe igbekalẹ ati lẹhin naa tí ô ṣe awọn ẹrọ kan dajudaju ni imọ awọn apá ati iṣiṣẹ ẹrọ naa. Nitori bẹẹ, njẹ awọn nkan ti a nri lori ìlẹ-aye ati ní awọn ọrun kò ha mú un daniloju pe Ọlọrun ní imọ ti ó kàmàmà? Awọn onimọ nipa egboogi oyinbo nlo gbogbo akoko igbesi-aye wọn ní ṣìṣe iwakiri latì loye awọn nkan tí wọn parapọ di awọn ohun adánìdá. Ẹ wo iru ìmọ ti Ẹni naa ti ó ṣẹda awọn nkan wọnyi gbọdọ ní! Pẹlupẹlu, awọn onimọ-ìjìnlẹ nkẹkọọ nipa awọn cell ati awọn nkan abẹ̀mí ti wọn kere pupọ julọ. Ẹlẹdaa ti nilati kọkọ mọ awọn pápá wọnyì daradara kì ô tò lè mú iwalaaye jade lakọkọ na!

10 Imọ Ọlọrun tànká gbogbo apá agbaye. Oun lè fi orukọ pe awọn àìmọye billion irawọ tí oun dá. (Isaiah 40:26) Lẹhìn mimú kiki diẹ ninu ìmọ rẹpẹtẹ ti Ọlọrun ní wá si ojutaye tán, ọkunrin kan tí orukọ yẹ̀ njẹ Job jẹwọ pe: “Emi mọ̀ pe, ìwọ lé ṣe ohun gbogbo, ati pe, kò si iro-inu tí a lè fasẹhin kuro lọdọ rẹ.” (Job 42:2) Awa kò ha ní idi tí ô pọ tô lati ní imọlara bakan naa bi?

11 Ọlọrun pẹlu tún fi ọgbọn bo ara rẹ̀ bi aṣọ, nitori pe o nlo imọ rẹ̀ pẹlu aṣeyọrisi rere. Fun apẹẹrẹ, ô ṣeto awọn eweko tí ó fi jẹ pe wọn le pa omi ati afẹfẹ carbon dioxide lati inu afẹfẹ, papọ lati mú awọn sugar ati starch jade, tí awọn ẹda-eniyan ati awọn ẹranko nilo fun ounjẹ. Awọn eweko tún lè mú awọn ọ̀rá, awọn eroja afaralokun (protein) ati awọn eroja omi-ara (vitamin) tí ó lọjupọ jade tí a nlò lati lè wà ní ilera. Gbogbo ounjẹ wa ló sinmi lori iyipo agbayanu tí ó niiṣe pẹlu oòrùn, òjò, manamana ati awọn kokoro tintintin inu ilẹ. (Jeremiah 10:12; Isaiah 40:12-15) Bi ẹnikan bá ti nkọ́ nipa awọn ibalo Ọlọrun, oun yoo wá mọriri rẹ̀ ninu ọkàn-àyà rẹ̀ idi rẹ̀ tí akọwe Bibeli kan fi sọ pe: Áà! ijinlẹ ọrọ ati ọgbọn ati imọ Ọlọrun!” (Rome 11:33) Eyiini kii ha iṣe bi iwọ yoo ti fẹ́ lati nimọlara nipa Ọlọrun kan tí ntẹwọgba ijọsin rẹ?

AKOPỌ-ANIMỌ-IWA KAN TÍ NFANIMỌRA

12 Ô rọrun lati ríi pe Ẹlẹdaa jẹ olugbatẹniro ati olupese lọpọ-yanturu. A ti mẹnukan diẹ ninu awọn nkan tí ô niiṣe pẹlu iṣeto rẹ̀ fun ounjẹ. Ṣugbọn akọwe psalm Bibeli sọ pe:

“Ó mú ki awọn orisun omi maa tujade lati inu awọn ọ̀gbun, tí wọn nṣàn lọ laarin awọn oke-nla, tí wọn fun awọn ẹranko igbẹ ní omi, ... ô mú ki koriko tí ô tùtù-yọ̀yọ̀ hù fun ẹran ati awọn eweko wọnni tí awọn eniyan nlò, fun wọn lati lè rí ounjẹ lati inu ilẹ: ọti-waini lati mú ki inu wọn dùn, ororo lati mú ki wọn layọ ati bread lati mú wọn lokun.—Psalm 104:10-15, Jerusalem Bible.

Ọlọrun ti mura ilẹ-aye silẹ lọna tí ó fi jẹ pe ounjẹ tí ô pọ̀ tô fun gbogbo araye ni a pese. Awọn àìtó ounjẹ tí nbani-ninujẹ yii tí ó sì nfa ọpọ ijiya saba maa nwá lati inu iwa ọ̀kánjúwà ati ikuna eniyan lati ṣe abojuto lọna rere.

13 Ẹlẹdaa wa ṣe ju kiki pipese ohun tí a nfẹ́ lati so ẹmi ró lọna yanturu. O tún mú ki ó ṣee gbadun. Ọlọrun ti lè pese ounjẹ tí ó lọ́ràá ninu ṣugbọn tí ô tẹ́ lẹnu patapata. Kaka bẹẹ, a ní oriṣiriṣi ailopin awọn adùn tí ndùnmọ́ni ninu awọn ounjẹ tí nfuni nilera. Pẹlupẹlu, ẹ maṣe jẹ ki a gbojufo o dá pe Ọlọrun dá wa lọna tí a fi lé gbadun ẹwà awọn àwọ̀, bii ti iru awọn òdòdò ati awọn eso. Oun sì fun wa ní agbara lati gbadun ìró orin. Bawo ni gbogbo eyi ti mú ki iwọ nimọlara nipa Ọlọrun?

14 Ní rironu lori eyi, ọpọlọpọ awọn eniyan ni a ti sún lati pari ero si pe Ọlọrun gbọdọ jẹ onifẹẹ gidi-gidi gan-an ni. Wọn ní ìdálójú-igbagbọ pe bẹẹ ni oun rí. Bibeli gbà bẹẹ, nitori pe apostle John kọwe pe: “Ọlọrun jẹ ifẹ.” (1 John 4:8, NW) Lọna ìfohun-pénìyàn Ẹlẹdaa naa jẹ ifẹ; eyi jẹ animọ rẹ̀ tí ô ṣe pataki julọ. Bi ẹnikan bá beere lọwọ rẹ pe bawo ni Ọlọrun ti rí, iyẹn ni yoo jẹ idahun rẹ akọkọ. Ô fi tifẹtifẹ fi ifẹni ọlọyaya hàn si awọn eniyan. Ọlọrun kii ṣe ero-inu kan lasan tí kò wà gẹgẹ bi ohun gidi kan tabi oriṣa jijinna-réré sini kan. Oun jẹ ọlọyaya ẹda kan ẹni tí a lè ní ibatan onifẹẹ pẹlu. Jesu sọ pe awọn ọmọlẹhin oun lè gbadura si Ọlọrun gẹgẹ bi Baba Wọn, ẹnikan tí ô wà nitosi ọ̀dọ̀ wọn, tí ô sì ní ìnudidun si wọn.—Matthew 6:9.

15 Bi ìwọ bá ní ifẹ ẹnikan nitootọ, iwọ yoo maa fẹ́ lati ríi pe ire ni ô wá sọdọ ẹni naa. Ọlọrun nimọlara lọna bayii si awọn ẹda-eniyan. Lati inu ifẹ ó kilọ fun wa niti awọn nkan tí wọn lẹ̀ ṣe ipalara fun wa. Awọn ikilọ wọnyi jẹ aabo kan. Pẹlupẹlu, wọn ràn wa lọwọ lati loye awọn ọpa-idiwọn Ọlọrun ati bi oun yoo ṣe huwa tabi huwapada. Fun apẹẹrẹ, Bibeli sọ fun wa pe ô korira irọ́ pípa. (Owe 6:16-19; 8:13; Zechariah 8:17) Eyi fun wa ní idaniloju pe Ọlọrun tikaraarẹ̀ kò lè purọ; a lè ní igbagbọ patapata ninu ohun gbogbo tí oun bá sọ. (Titus 1:2; Hebrew 6:18) Nitori naa nigba tí a bá ṣe alabapade awọn ọrọ Bibeli tí ẹnikan lè fojuwo bi eyi tí nkanilọwọko, a nilati mọ̀ pe wọn jẹ ifihan iru ẹni onifẹẹ ati olododo tí Ọlọrun jẹ ati aniyan tí oun ní ninu wa.

16 Ní ríràn wa lọwọ siwaju sii lati fojuwo Ọlọrun gẹgẹ bi ẹnikan tí a lè ní ibalo pẹlu rẹ̀, Bibeli fihan pe ô ní awọn imọlara ní afikun si ifẹ. Fun apẹẹrẹ, ô maa ‘ndùn ún’ nigba tí eniyan bá ṣọtẹ lodisi awọn ọna ododo rẹ̀. (Psalm 78:8-12, 32, 41, NW,) Oun maa ‘nyọ̀’ nigba tí awọn eniyan bá di ohun tí ô tọna mú. (Owe 27:11; Luke 15:10) Nigba tí a bá ṣe awọn aṣiṣe, oun jẹ abanikẹdun, alaaanu ati oloye. Iwọ yoo ríi pe ó jẹ ohun tí ô kún fun iṣiri lati kà nipa eyi ninu Psalm 103:8-14. Ati pe Ẹlẹdaa naa jẹ aláìṣègbè, tí npese oòrùn ati òjò fun ẹni gbogbo, ati pe ô sì ntẹwọgba ijọsin lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan laika ẹya-iran tabi orilẹ-ede sí.—Iṣe 14:16, 17; 10:34, 35.

17 Ayò jẹ ohun kan tí pupọ julọ ninu wa nfẹ́. Nipa bayii a ní idi lati wá lati mọ Ọga Ogo Julọ naa. Bibeli ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun alayọ ati pe ô fihan pe oun nfẹ́ ki awa naa layọ. (1 Timothy 1:11, NW; Deuteronomy 12:7) Titilae ni oun jẹ olusẹsan fun awọn wọnni tí wọn nfi igbagbọ hàn ninu rẹ̀. (Hebrew 11:6; 13:5) Ati pe Ọlọrun ti ṣe ọna kan fun awọn ẹda-eniyan lati wà ní ilera ki wọn sì ní ayọ̀ tí kò lopin, gẹgẹ bi a o ti jiroro rẹ̀ ninu awọn ori-iwe nikẹhin.

ỌLỌRUN “NAA”

18 Ohun pataki miiran kan tí Bibeli fihan nipa Ẹlẹdaa naa ni pe ô ní orukọ ara-ẹni kan. Lede Hebrew a kọ ọ́ pẹlu awọn konsonant mẹrin, lọna yii: YHWH. Ọpọ julọ awọn ede ode-oni ni wọn ní ọna kan naa tí wọn ngbà ṣe ẹ̀dàya orukọ afiyatọhàn yii. Lede Yoruba Jehofah ni. Psalm 83:18 sọ fun wa pe awọn eniyan nilati mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹnikanṣoṣo tí ijẹ Jehofah, iwọ ni Ọga Ogo lori ayé gbogbo. (Fiwe John 17:6.) Ṣakiyesi pe oun nikanṣoṣo ni Ọga Ogo. Kiki Ẹni Giga Julọ kanṣoṣo ni ô wà. Awọn ọmọ Israel igbaani ti fi igba gbogbo sọ ọ lọna yii pe: [Jehofah] Ọlọrun wa, [Jehofah] kan ni. Ki iwọ ki ó si fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ [Jehofah] Ọlọrun rẹ.—Deuteronomy 6:4, 5; fiwe John 17:3.

19 Ọlọrun wa, Jehofah, jẹ ẹni atayebaye, gẹgẹ bi ọgbọn ironu yoo ti tọkafihan. Awọn onimọ-ijinlẹ sọ pe agbaye ti wà ní nkan bii ẹgbẹẹgbẹrun lọna araadọta ọkẹ ọdun sẹhin. Nitori naa Ẹlẹdaa agbaye ni ó hàn gbangba pe ô ti nilati wà ṣaaju eyiini. Eyi wà ní ibamu pẹlu bi Bibeli ti pé é ní Ọba ayeraye, tí kò ní ibẹrẹ tabi opin. (1 Timothy 1:17; Iṣipaya 4:11; 10:6) Awọn ẹgbẹẹgbẹrun ọdun diẹ tí eniyan lò lori ilẹ-aye jẹ sáà kukuru kan ní ifiwera pẹlu jíjẹ́ ẹni atayebaye Jehofah.—Psalm 90:2, 4.

AWỌN ẸDA MIIRAN TÍ A KÒ LÈ FOJURI

20 Bibeli fihan pe awọn ẹda kan wà tí wọn jẹ ẹmi. Lẹhin tí Olodumare ti wà ní oun nikan fun igba pipẹ, ô yàn lati dá awọn ẹda ẹmi miiran. Lakọkọ, ô ṣẹda akọbi gbogbo ẹda ati olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun. (Colossae 1:15; Iṣipaya 3:14) Akọbi yii wà pẹlu Ọlọrun Olodumare ní ibẹrẹ iṣẹda. Jehofah yoo lò ô pẹlu lọjọ iwaju gẹgẹ bi agbọrọsọ kan, tabi Ọrọ, ní bíbá awọn ẹlomiran sọrọpọ. (John 1:1-3; Colossae 1:16, 17) Lẹhin-ọ-rẹhin, Ọmọkunrin akọbi yii ni a rán wá si ori ilẹ-aye lati di ọkunrin kan. A mọ̀ ọ́n gẹgẹ bi Jesu Kristi.—Galatia 4:4; Luke 1:30-35.

21 Ní ṣiṣiṣẹ nipasẹ Ọmọkunrin tí a kọkọ ṣẹda rẹ̀ yii, Ọlọrun dá awọn ẹda miiran, tí a mọ ní gbogbogboo gẹgẹ bi awọn angeli. Awọn wọnyi nṣiṣẹṣeranwọ gẹgẹ bi awọn iranṣẹ, wọn sì nṣe awọn iṣẹ ní agbaye, iwọnyì ní awọn iṣẹ-isin fun ire awọn ẹda-eniyan ninu.—2 Peter 2:11; Hebrew 2:6, 7; Psalm 34:7; 103:20.

22 Ọgbọn ironu tí ô tọna ati Bibeli tọkafihan pe Ọmọkunrin akọbi tí a dá tí a sì rán wá si ilẹ-aye kò’ lè bá Baba rẹ̀ dọgba. Awọn eniyan diẹ kan tí wọn sọ pe awọn ní igbagbọ ninu Bibeli nkọni pe Jesu ati Baba rẹ̀ jẹ awọn apá tí wọn wà ní ọgbọọgba ninu ọlọrun alápá pupọ kan. Eyi kii ṣe ero titun kan, nitori pe ọpọ awọn isin igbaani ni wọn njọsin oriṣiriṣi awọn ọlọrun. Ṣugbọn lodisi eyi, Bibeli fihan ní kedere pe Jesu, gẹgẹ bi ẹnikan tí ó dá wà gédégbé lọtọ, gba agbara lati ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ Olodumare. Ô mú un dá wa loju pe Olodumare mọ awọn ohun tí Jesu kò mọ̀, ati pe yala igba tí ó wà lori ilẹ-aye tabi lẹhin igba naa Jesu Kristi kò fi igba kan rí lae dọgba pẹlu Baba rẹ̀.—John 5:30; 8:28; 14:10, 28; Mark 13:32.

23 Fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun ní ọrun, Ọmọkunrin naa ní ipo ibatan timọtimọ pẹlu Ọlọrun Olodumare, tí ô fi jẹ pe ô lè kẹkọọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ki ô si maa ṣafarawe awọn ọna rẹ̀. Nipa bayii nigba tí ọmọ-ẹhin kan beere pe, Fi Baba naa hàn wa, Jesu dahun pe: “Ẹni tí ô bá ti rí mi, ó ti rí Baba.” (John 14:8, 9; 1:18) Nipa kikẹkọọ akọsilẹ Bibeli nipa igbesi-aye Jesu Kristi ti ori ilẹ-aye awa lè kẹkọọ pupọ nipa Baba naa, iru bii idi tí Ọlọrun fi nṣe awọn nkan ati ohun tí oun nreti pe ki a jẹ. Jesu sọ nigbakan rí pe: Emi ni ọna, ati otitọ, ati ìyé. (John 14:6) Ô jẹ ohun tí ó ṣe pataki pupọ fun wa lati mọ̀ ọ́n daradara sii, ati nipa bẹẹ pẹlu ki a tún mọ Baba. Kika Ihinrere John jẹ iranlọwọ titayọ kan. Ní ṣiṣe bẹẹ, maṣe pọkànpọ̀ sori kiki awọn koko tabi awọn ẹkunrẹrẹ alaye nikan, ṣugbọn gbiyanju lati jẹ́ ki ẹmi ohun tí Kristi jẹ́ wọle jinlẹ sinu rẹ. Oun ti jẹ ẹda-eniyan tí ó ṣe pataki julọ tí o lè kẹkọọ nipa rẹ̀.

A NILO ỌLỌRUN

24 Bi a ti nkẹkọọ nipa Olodumare nipasẹ ṣiṣakiye iṣẹda ati kika Bibeli, ó ṣe kedere pe a kò dá awọn eniyan lati gbé igbesi-aye olominira kuro lọdọ rẹ̀. A dá wa lati ní ibatan kan pẹlu Ọlọrun, lati ọ̀dọ̀ ẹni tí a ti gba iwalaaye ati ẹni tí ó jẹ pe awọn ipese ojoojumọ rẹ̀ ló nso igbesi-aye wa ró. Gbigbiyanju lati wà lominira kuro lọdọ rẹ̀ ati Ọrọ rẹ̀, Bibeli, ni a lè fiwera pẹlu ẹnikan tí ngbiyanju lati wá ọna la inu aginju kan já laini aworan afinimọ̀nà daradara kan. Lopin rẹ̀ oun lè sọnu patapata ki ô sì kú nitori aini awọn ipese lati so ẹmi rô. Bakan naa ni ô rí nigba tí awọn ẹda-eniyan bá mú Ọlọrun ati itọsọna kuro ninu igbesi-aye wọn. Bibeli ati ọrọ-itan mú ki ô daniloju pe lati gbadun igbesi-aye tí ô dara julọ a nilo ohun tí ó ju ounjẹ, aṣọ wíwọ̀ ati ile lọ. Fun wa lati layọ nitootọ, a nilo itọsọna ati iranlọwọ lati ọ̀dọ̀ Ẹni naa tí ó dá wa.—Matthew 4:4; John 4:34.

25 Ọpọlọpọ awọn eniyan miiran ni imọ wọn nipa Ẹlẹdaa naa kò ju bín-ín-tín lọ. Bi o bá ti nṣalabapade iru awọn eniyan bawọnni ati bi anfaani bá ti ṣe ṣisilẹ tó, eeṣe tí o kò fi ta atare diẹ ninu awọn nkan rere tí a ti jiroro nihin? Ô jẹ ohun tí ô dara nigba tí awọn eniyan bá ní itẹsi lati ṣe ajọpin awọn otitọ pataki tí wọn ti mọ̀ nipa Jehofah, Baba wa ọrun onifẹẹ pẹlu awọn ẹlomiran.—Psalm 40:5.

[Koko Fun Ijiroro]

Bawo ni ó ti ṣeeṣe lati kẹkọọ nipa Ọlọrun airi kan? (1-3)

Eeṣe tí iwọ fi lè ní ìdálójú nipa agbara ẹlẹru-jẹnjẹn Ọlọrun ati agbara-iṣe rẹ̀ lati lò ó? (4-8)

Kìnnì ô yẹ kì a mọ nipa Ọlọrun niti imọ? Ati ọgbọn? (9-11)

Bawo ni iwọ ṣe njere lati inu ifihan akopọ-animọ-iwa Ọlọrun? (12-14)

Bawo ni Ọlọrun ṣe nfi aniyan onifẹẹ rẹ̀ hàn ninu rẹ? Kinni imọlara rẹ si eyi? (Psalm 30:4, 5) (15-17)

Kinni ohun tí a lè mọ̀ nipa orukọ Ọlọrun ati gígùn ọjọ iwalaaye rẹ̀? (18, 19)

Eeṣe tí Ọlọrun kò fi dánikànwà ní ọrun? (20, 21)

Kinni ibatan tí ô wà laarin Baba ati Ọmọkunrin naa? (22, 23)

Eeṣe tí Ọlọrun fi gbọdọ ṣe pataki ninu igbesi-aye rẹ? (24, 25)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 33]

Agbara Ọlọrun pín Òkun pupa niyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 36]

Kinni ohun tí oòrùn, òjò ati ilẹ eleso ntọkafihan nipa Ọlọrun?

Oun kii ha iṣe Olupese onifẹẹ kan tí npese lọpọ-yanturu bi?